ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 24
“Fún Mi Ní Ọkàn Tó Pa Pọ̀ Kí N Lè Máa Bẹ̀rù Orúkọ Rẹ”
“Fún mi ní ọkàn tó pa pọ̀ kí n lè máa bẹ̀rù orúkọ rẹ. Mo fi gbogbo ọkàn mi yìn ọ́, Jèhófà Ọlọ́run mi.”—SM. 86:11, 12.
ORIN 7 Jèhófà Ni Agbára Wa
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn bẹ̀rù Ọlọ́run, kí sì nìdí tó fi yẹ káwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà bẹ̀rù rẹ̀?
ÀWA Kristẹni nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, a sì tún ń bẹ̀rù rẹ̀. Àwọn kan lè ronú pé èèyàn ò lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run kó sì tún bẹ̀rù rẹ̀. Àmọ́, kì í ṣe ìbẹ̀rù tó ń mú kéèyàn gbọ̀n jìnnìjìnnì là ń sọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìbẹ̀rù kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ la máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Àwọn tó nírú ìbẹ̀rù yìí máa ń ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Ọlọ́run. Wọn kì í fẹ́ ṣe ohun tó máa múnú bí Baba wọn ọ̀run torí pé wọn ò fẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́.—Sm. 111:10; Òwe 8:13.
2. Àwọn ohun méjì wo la máa jíròrò bí Ọba Dáfídì ṣe sọ nínú Sáàmù 86:11?
2 Ka Sáàmù 86:11. Ó hàn nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí pé Ọba Dáfídì mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn bẹ̀rù Ọlọ́run. Torí náà, ẹ jẹ́ ká jíròrò bá a ṣe lè fi ẹsẹ Bíbélì yìí sílò. Lákọ̀ọ́kọ́, a máa sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi yẹ ká bẹ̀rù orúkọ Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà, a máa sọ̀rọ̀ nípa bá a ṣe lè fi hàn pé à ń bẹ̀rù orúkọ Ọlọ́run nínú gbogbo nǹkan tá à ń ṣe lójoojúmọ́.
ÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ NÍ Ọ̀WỌ̀ TÓ JINLẸ̀ FÚN ORÚKỌ JÈHÓFÀ
3. Kí ló mú kí Mósè ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún orúkọ Ọlọ́run?
3 Wo bó ṣe máa rí lára Mósè nígbà tó wà nínú ihò àpáta tó sì rí bí ògo Jèhófà ṣe ń kọjá. Ìwé Insight on the Scriptures sọ pé “Ó jọ pé ìran tí Mósè rí yìí ló bani lẹ́rù jù nínú gbogbo ìran táwọn èèyàn rí kí Jésù Kristi tó wá sáyé.” Mósè wá gbọ́ ohùn kan nípasẹ̀ áńgẹ́lì tó sọ pé: “Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú, tó ń gba tẹni rò, tí kì í tètè bínú, tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi, tó ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún, tó ń dárí àṣìṣe, ìṣìnà àti ẹ̀ṣẹ̀ jini.” (Ẹ́kís. 33:17-23; 34:5-7) Ó ṣeé ṣe kí Mósè máa rántí ìran náà nígbàkigbà tó bá dárúkọ Jèhófà. Abájọ tó fi kìlọ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n máa “bẹ̀rù orúkọ ológo, tó ń bani lẹ́rù yìí.”—Diu. 28:58.
4. Àwọn nǹkan wo lá jẹ́ ká túbọ̀ ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Jèhófà?
4 Nígbàkigbà táwa náà bá ń dárúkọ Jèhófà, ó yẹ ká máa ronú nípa irú ẹni tí Jèhófà jẹ́. Ó tún yẹ ká máa ronú nípa àwọn ànímọ́ rẹ̀, ìyẹn bó ṣe jẹ́ alágbára, ọlọ́gbọ́n, onídàájọ́ òdodo àti Ọlọ́run ìfẹ́. Tá a bá ń ronú lórí àwọn ànímọ́ yìí àtàwọn ànímọ́ míì tó ní, àá túbọ̀ ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún un.—Sm. 77:11-15.
5-6. (a) Kí ni ìtumọ̀ orúkọ Ọlọ́run? (b) Bí Ẹ́kísódù 3:13, 14 àti Àìsáyà 64:8 ṣe sọ, báwo ni Jèhófà ṣe ń mú kí nǹkan di?
5 Kí làwọn kan sọ pé orúkọ Ọlọ́run túmọ̀ sí? Àwọn ọ̀mọ̀wé fẹnu kò pé ó ṣeé ṣe kí orúkọ Jèhófà túmọ̀ sí “Ó Ń Mú Kí Ó Di.” Ìtumọ̀ tí wọ́n fún orúkọ yìí jẹ́ ká rí i pé kò sóhun tí Jèhófà ò lè ṣe àti pé kò sóhun tó lè dí i lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó ní lọ́kàn. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀?
6 Jèhófà máa ń mú kí nǹkan di ní ti pé ó máa ń di ohunkóhun tó bá yẹ láti mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ. (Ka Ẹ́kísódù 3:13, 14.) Léraléra ni ètò Ọlọ́run ń gbà wá níyànjú nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa pé ká máa ronú jinlẹ̀ nípa kókó yìí. Yàtọ̀ sí pé Jèhófà fúnra rẹ̀ máa ń di ohunkóhun láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, ó tún máa ń lo àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ tá a jẹ́ aláìpé láti mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ. (Ka Àìsáyà 64:8.) Yálà fúnra rẹ̀ tàbí nípasẹ̀ àwa ìránṣẹ́ rẹ̀, Jèhófà máa ń mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Ó dájú pé kò sí nǹkan kan láyé yìí tó lè dí i lọ́wọ́.—Àìsá. 46:10, 11.
7. Kí la lè ṣe ká lè túbọ̀ mọyì Baba wa ọ̀run?
7 Ká lè túbọ̀ mọyì Baba wa ọ̀run, ó yẹ ká máa ronú nípa àwọn nǹkan tó ti ṣe àtàwọn ohun tó mú káwa náà ṣe. Bí àpẹẹrẹ, a máa ń túbọ̀ mọyì àwọn nǹkan ribiribi tí Jèhófà ṣe bá a ṣe ń ronú lórí àwọn nǹkan tó dá. (Sm. 8:3, 4) Tá a bá sì ronú lórí àwọn ohun tí Jèhófà ti mú ká ṣe láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, ọ̀wọ̀ tá a ní fún un á túbọ̀ jinlẹ̀. Ká sòótọ́, orúkọ tó yẹ kéèyàn bọ̀wọ̀ fún lorúkọ Jèhófà! Ìdí sì ni pé orúkọ yẹn jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́, àwọn ohun tó ti ṣe àtàwọn nǹkan tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú.—Sm. 89:7, 8.
“MÀÁ KÉDE ORÚKỌ JÈHÓFÀ”
8. Kí ni Diutarónómì 32:2, 3 sọ pé Jèhófà fẹ́ káwọn ìránṣẹ́ òun ṣe nípa orúkọ òun?
8 Nígbà tó kù díẹ̀ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, Jèhófà kọ́ Mósè ní orin kan. (Diu. 31:19) Mósè sì wá kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní orin náà. (Ka Diutarónómì 32:2, 3.) Tá a bá fara balẹ̀ kíyè sí ọ̀rọ̀ tó wà ní ẹsẹ 2 àti 3, àá rí i pé Jèhófà kò fẹ́ káwọn èèyàn gbàgbé orúkọ òun, kò sì fẹ́ káwọn èèyàn ronú pé orúkọ náà ti mọ́ ju ohun tó yẹ káwọn máa pè lọ. Ohun tó fẹ́ ni pé kí gbogbo èèyàn pátá mọ orúkọ òun. Ẹ wo bí inú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe máa dùn tó nígbà tí Mósè ń kọ́ wọn nípa Jèhófà àti orúkọ mímọ́ rẹ̀! Ṣe ni orin tó kọ́ wọn dà bí òjò winniwinni tó rọ̀ sórí koríko, ó mára tù wọ́n, ọkàn wọn sì balẹ̀. Báwo làwa náà ṣe lè kọ́ àwọn èèyàn lọ́nà táá mú kára tù wọ́n, kí ọkàn wọn sì balẹ̀?
9. Báwo la ṣe lè sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́?
9 A lè fi orúkọ Jèhófà han àwọn èèyàn nínú Bíbélì wa nígbà tá a bá ń wàásù láti ilé dé ilé tàbí níbi térò pọ̀ sí. A lè fún wọn láwọn ìwé tó fani mọ́ra, àwọn fídíò tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, a sì lè jẹ́ kí wọ́n mọ̀ nípa àwọn ìsọfúnni tó ń gbógo fún Jèhófà lórí ìkànnì wa. Yálà nílé ìwé, níbiiṣẹ́ tàbí tá a bá ń rìnrìn àjò, a lè lo gbogbo àǹfààní tó yọjú láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa Baba wa ọ̀run, ká sì jẹ́ kí wọ́n mọ irú ẹni tó jẹ́. A lè jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí Jèhófà máa ṣe fún aráyé àti bó ṣe máa sọ ayé yìí di Párádísè. Ó sì lè jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tí wọ́n máa gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀, táá sì jẹ́ kó dá wọn lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, ṣe là ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Baba wa ọ̀run, èyí sì ń mú ká sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́. Yàtọ̀ síyẹn, à ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé irọ́ làwọn onísìn fi ń kọ́ni nípa Jèhófà. Ẹ̀kọ́ òtítọ́ tá à ń kọ́ wọn nìkan ló lè mú kí wọ́n ní ojúlówó ìfọ̀kànbalẹ̀ kára sì tù wọ́n.—Àìsá. 65:13, 14.
10. Ṣé àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà nìkan ló yẹ ká máa tẹnu mọ́ tá a bá ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́? Kí nìdí?
10 Tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó máa ń wù wá pé kí wọ́n mọ orúkọ Ọlọ́run, kí wọ́n sì máa lò ó. Bákan náà, a fẹ́ kí wọ́n mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́, ohun tó fẹ́ àtohun tí kò fẹ́. Àmọ́ ṣé wọ́n máa lè mọ Jèhófà tó bá jẹ́ pé àwọn ìlànà àti òfin rẹ̀ nìkan là ń kọ́ wọn? Ká sòótọ́, akẹ́kọ̀ọ́ kan lè mọ àwọn òfin Ọlọ́run, kódà ó lè mọyì wọn. Àmọ́ ṣéyẹn máa mú kí akẹ́kọ̀ọ́ náà nífẹ̀ẹ́ Jèhófà kó sì fi tọkàntọkàn ṣe ohun tó fẹ́? Ẹ rántí pé Ádámù àti Éfà lóye òfin Jèhófà, àmọ́ wọn ò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó fún wọn lófin náà. (Jẹ́n. 3:1-6) Torí náà, kì í ṣe àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà nìkan ló yẹ ká máa tẹnu mọ́ tá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.
11. Báwo la ṣe lè mú káwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà nígbà tá a bá ń kọ́ wọn láwọn òfin àti ìlànà rẹ̀?
11 Àwọn òfin àti ìlànà Jèhófà wúlò gan-an, wọ́n sì ń ṣe wá láǹfààní. (Sm. 119:97, 111, 112) Àmọ́ káwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa tó lè gbà bẹ́ẹ̀, ó gbọ́dọ̀ dá wọn lójú pé ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ló mú kó fún wa lófin. Torí náà, a lè bi akẹ́kọ̀ọ́ wa pé: “Kí lo rò pé ó mú kí Jèhófà ṣòfin pé ká ṣe báyìí tàbí ká má ṣe báyìí? Báwo nìyẹn ṣe jẹ́ ká mọ irú Ẹni tó jẹ́?” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa wọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọ́kàn tá a bá mú kí wọ́n mọyì Jèhófà kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ orúkọ mímọ́ rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, kì í ṣe pé wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ àwọn òfin Jèhófà nìkan ni, kódà gbogbo ọkàn ni wọ́n fi máa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó fún wa lófin náà. (Sm. 119:68) Èyí á mú kí ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ lágbára, wọ́n á sì lè fara da àdánwò èyíkéyìí tó bá yọjú.—1 Kọ́r. 3:12-15.
“ÀWA YÓÒ MÁA RÌN NÍ ORÚKỌ JÈHÓFÀ”
12. Sọ ìgbà kan tí ọkàn Dáfídì kò pa pọ̀. Kí nìyẹn sì yọrí sí?
12 Gbólóhùn pàtàkì kan wà nínú Sáàmù 86:11 tó sọ pé “fún mi ní ọkàn tó pa pọ̀.” Ẹ rántí pé Ọba Dáfídì ni Ọlọ́run mí sí láti sọ gbólóhùn yìí. Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i mú kó mọ̀ pé ó rọrùn kéèyàn ní ìpínyà ọkàn. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà tó ń rìn lórí òrùlé ilé rẹ̀ tó sì tajú kán rí ìyàwó oníyàwó níbi tó ti ń wẹ̀. Lásìkò yẹn, ṣé a lè sọ pé ọkàn Dáfídì pa pọ̀, àbí ó ní ìpínyà ọkàn? Kò sí àní-àní pé ó mọ òfin Jèhófà tó sọ pé: “Ojú rẹ ò . . . gbọ́dọ̀ wọ ìyàwó ọmọnìkejì rẹ.” (Ẹ́kís. 20:17) Síbẹ̀, kò gbójú kúrò. Èyí mú kó máa ronú bóyá kóun ṣe ohun tóun fẹ́ pẹ̀lú Bátí-ṣébà tàbí kóun ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ pẹ́ tí Dáfídì ti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tó sì ń bẹ̀rù rẹ̀, síbẹ̀ ó gba ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ láyè. Èyí mú kó ṣèṣekúṣe, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn mú àjálù bá àwọn míì, títí kan ìdílé òun alára.—2 Sám. 11:1-5, 14-17; 12:7-12.
13. Báwo la ṣe mọ̀ pé ọkàn Dáfídì pa pọ̀ nígbà tó yá?
13 Jèhófà bá Dáfídì wí, ó sì pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀. (2 Sám. 12:13; Sm. 51:2-4, 17) Dáfídì kò jẹ́ gbàgbé wàhálà àti ìṣòro tóun kojú torí pé òun jẹ́ kí ọkàn òun pínyà. Ohun tí Dáfídì sọ nínú Sáàmù 86:11 tún lè túmọ̀ sí: “Má ṣe jẹ́ kí n ní ìpínyà ọkàn.” Ṣé Jèhófà dáhùn àdúrà yẹn? Ó dájú pé ó ṣe bẹ́ẹ̀, torí nígbà tó yá, Jèhófà pe Dáfídì ní ọkùnrin tó “fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sin Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀.”—1 Ọba 11:4; 15:3.
14. Ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa, kí sì nìdí?
14 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì jẹ́ ìkìlọ̀ fún wa lónìí, bó sì ṣe pa dà bá Jèhófà rẹ́ fún wa níṣìírí. Àkọsílẹ̀ náà jẹ́ ká rí i pé kò sẹ́ni tírú ẹ̀ ò lè ṣẹlẹ̀ sí yálà a ti pẹ́ nínú òtítọ́ tàbí a ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Torí náà, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé mò ń ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe kí Sátánì má bàa pín ọkàn mi níyà?’
15. Báwo ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò ṣe ní jẹ́ ká wo ìwòkuwò?
15 Bí àpẹẹrẹ, bí ètò orí tẹlifíṣọ̀n tàbí àwòrán orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó lè gbé èròkerò wá sí ẹ lọ́kàn bá yọjú, kí lo máa ṣe? Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kò burú jù, ó ṣe tán kì í ṣe àwòrán oníhòòhò. Àmọ́ ṣé kì í ṣe pé Sátánì ń wá bó ṣe máa pín ọkàn rẹ níyà? (2 Kọ́r. 2:11) A lè fi ètò orí tẹlifíṣọ̀n tàbí àwòrán orí Íńtánẹ́ẹ̀tì yẹn wé àáké tẹ́nì kan fẹ́ fi la igi ńlá kan. Nígbà tó bá kọ́kọ́ la àáké náà mọ́ igi, ó lè jọ pé igi náà kò ní fọ́ sí wẹ́wẹ́. Àmọ́ tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ léraléra, ó máa la igi náà sọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Ohun tó o rí yẹn ló dà bí ìgbà tí wọ́n kọ́kọ́ fi àáké la igi. Ohun tó dà bíi pé kò léwu níbẹ̀rẹ̀ lè di ohun táá pín ọkàn ẹnì kan níyà táá sì wá mú kó dẹ́ṣẹ̀ sí Jèhófà. Torí náà, má ṣe fàyè gba ohunkóhun tó máa mú kó o ro èròkerò! Ṣe ohun táá jẹ́ kí ọkàn rẹ pa pọ̀ kó o lè máa bẹ̀rù Jèhófà.
16. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa tá a bá dojú kọ ìdẹwò?
16 Yàtọ̀ sí àwòrán tó ń mú kí ọkàn ẹni fà sí ìṣekúṣe, onírúurú nǹkan ni Sátánì lè fi dẹ wá wò. Kí ló yẹ ká ṣe? Ó lè máa ṣe wá bíi pé kò burú jù. Bí àpẹẹrẹ, a lè ronú pé: ‘Ó ṣe tán, kì í ṣe ohun tí wọ́n lè tìtorí ẹ̀ yọ mí lẹ́gbẹ́, torí náà kò burú jù.’ Èrò òdì gbáà nìyẹn. Torí náà, ó máa dáa ká bi ara wa láwọn ìbéèrè yìí: ‘Ṣé kì í ṣe pé Sátánì ń wá bó ṣe máa pín ọkàn mi níyà? Tí n bá ṣe ohun tí ọkàn mi ń fà sí yìí, ṣé mi ò ní kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà? Ṣérú ìwà bẹ́ẹ̀ máa mú kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà ni àbí á mú kí n jìnnà sí i?’ Ó yẹ kó o ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ìbéèrè yìí. Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lọ́gbọ́n tí wàá fi lè dáhùn àwọn ìbéèrè yìí láìtan ara ẹ jẹ. (Jém. 1:5) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, o ò ní kó sínú ìdẹwò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìwọ náà á lè ṣe bíi ti Jésù tó sọ pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì!”—Mát. 4:10.
17. Kí nìdí tó fi burú pé kéèyàn ní ìpínyà ọkàn? Ṣàkàwé.
17 A ò ní jàǹfààní kankan tá a bá jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn wa níyà. Ẹ jẹ́ ká sọ pé èrò àwọn tó wà nínú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù kan ò ṣọ̀kan. Àwọn kan lára wọn ń wá bí wọ́n ṣe máa gbògo, àwọn míì ò tẹ̀ lé òfin eré ìdárayá náà, nígbà táwọn yòókù ò gbọ́rọ̀ sí kóòṣì lẹ́nu. Kò jọ pé irú ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù bẹ́ẹ̀ máa jáwé olúborí. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, tí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù kan bá fìmọ̀ ṣọ̀kan, ó dájú pé wọ́n máa ṣàṣeyọrí. Tó bá jẹ́ pé bó o ṣe máa sin Jèhófà tó o sì máa múnú ẹ̀ dùn ló gbà ẹ́ lọ́kàn, tí èrò yìí sì ń darí gbogbo ohun tó ò ń ṣe, ọkàn ẹ ò ní pínyà, wàá sì ṣàṣeyọrí bíi ti ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù kejì yẹn. Máa rántí pé Sátánì ń wá bó ṣe máa pín ọkàn rẹ níyà. Ó ń wá bó ṣe lè máa darí èrò rẹ, ohun tọ́kàn rẹ ń fà sí àti bí nǹkan ṣe ń rí lára rẹ kó o lè rú òfin Jèhófà. Ìwọ alára sì mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì kí ọkàn rẹ ṣọ̀kan kó o tó lè sin Jèhófà. (Mát. 22:36-38) Torí náà, má ṣe jẹ́ kí Sátánì pín ọkàn rẹ níyà!
18. Kí lo pinnu pé wàá ṣe bó ṣe wà nínú Míkà 4:5?
18 Gbàdúrà sí Jèhófà bíi ti Dáfídì tó sọ pé: “Fún mi ní ọkàn tó pa pọ̀ kí n lè máa bẹ̀rù orúkọ rẹ.” Ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti máa fọ̀rọ̀ inú àdúrà yẹn sílò lójoojúmọ́. Jẹ́ kó máa hàn nínú gbogbo ìpinnu rẹ pé ò ń bọ̀wọ̀ fún orúkọ mímọ́ Jèhófà. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá fi hàn pé ẹlẹ́rìí lo jẹ́ fún Jèhófà lóòótọ́. (Òwe 27:11) Bákan náà, gbogbo wa á lè sọ bíi ti wòlíì Míkà pé: “Àwa yóò máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa títí láé àti láéláé.”—Míkà 4:5.
ORIN 41 Jọ̀ọ́, Gbọ́ Àdúrà Mi
a Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò Sáàmù 86:11, 12 tó jẹ́ apá kan àdúrà tí Ọba Dáfídì gbà. Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn bẹ̀rù orúkọ Jèhófà? Kí nìdí tó fi yẹ ká bẹ̀rù orúkọ Jèhófà? Báwo ni ìbẹ̀rù Jèhófà ò ṣe ní jẹ́ ká kó sínú ìdẹwò?
b ÀWÒRÁN: Mósè kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní orin tí wọ́n á fi máa bọlá fún Jèhófà.
c ÀWÒRÁN: Éfà fàyè gba èròkerò. Àmọ́ àwa kì í wo ìwòkuwò, a ò sì ní fàyè gba ohunkóhun tó lè gbé èròkerò sí wa lọ́kàn torí pé ìyẹn lè kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà.