Àwọn Ọba Kìíní
11 Àmọ́ Ọba Sólómọ́nì nífẹ̀ẹ́ ọ̀pọ̀ obìnrin ilẹ̀ àjèjì,+ yàtọ̀ sí ọmọbìnrin Fáráò,+ àwọn tó tún nífẹ̀ẹ́ ni: àwọn obìnrin tó jẹ́ ọmọ Móábù,+ ọmọ Ámónì,+ ọmọ Édómù, ọmọ Sídónì+ àti ọmọ Hétì.+ 2 Wọ́n wá láti àwọn orílẹ̀-èdè tí Jèhófà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ lọ sí àárín wọn,* wọn ò sì gbọ́dọ̀ wá sí àárín yín, torí ó dájú pé wọ́n á mú kí ọkàn yín fà sí títẹ̀lé àwọn ọlọ́run wọn.”+ Àmọ́ ọkàn Sólómọ́nì kò kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì nífẹ̀ẹ́ wọn. 3 Ó ní ọgọ́rùn-ún méje (700) ìyàwó tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọba àti ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) wáhàrì,* ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn ìyàwó rẹ̀ yí i lọ́kàn pa dà.* 4 Nígbà tí Sólómọ́nì darúgbó,+ àwọn ìyàwó rẹ̀ mú kí ọkàn rẹ̀ fà sí títẹ̀lé àwọn ọlọ́run míì,+ kò sì fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sin Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ bíi Dáfídì bàbá rẹ̀. 5 Sólómọ́nì yíjú sí Áṣítórétì,+ abo ọlọ́run àwọn ọmọ Sídónì àti Mílíkómù,+ ọlọ́run ìríra àwọn ọmọ Ámónì. 6 Sólómọ́nì ṣe ohun tí ó burú lójú Jèhófà, kò sì tẹ̀ lé Jèhófà délẹ̀délẹ̀* bí Dáfídì bàbá rẹ̀ ti ṣe.+
7 Ìgbà náà ni Sólómọ́nì kọ́ ibi gíga+ kan fún Kémóṣì, ọlọ́run ìríra Móábù, lórí òkè tó wà níwájú Jerúsálẹ́mù, ó sì tún kọ́ òmíràn fún Mólékì,+ ọlọ́run ìríra àwọn ọmọ Ámónì.+ 8 Ohun tí ó ṣe fún gbogbo ìyàwó ilẹ̀ àjèjì tó fẹ́ nìyẹn, àwọn tó ń mú ẹbọ rú èéfín, tí wọ́n sì ń rúbọ sí àwọn ọlọ́run wọn.
9 Inú bí Jèhófà gan-an sí Sólómọ́nì, nítorí ọkàn rẹ̀ ti kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+ ẹni tó fara hàn án lẹ́ẹ̀mejì,+ 10 tí ó sì kìlọ̀ fún un nípa nǹkan yìí pé kí ó má ṣe tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì.+ Àmọ́ kò ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ. 11 Jèhófà wá sọ fún Sólómọ́nì pé: “Nítorí ohun tí o ṣe yìí, tí o kò pa májẹ̀mú mi àti òfin mi mọ́, bí mo ṣe pa á láṣẹ fún ọ, màá rí i dájú pé mo fa ìjọba náà ya kúrò lọ́wọ́ rẹ, màá sì fún ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ.+ 12 Àmọ́, nítorí Dáfídì bàbá rẹ, mi ò ní ṣe èyí nígbà ayé rẹ. Ọwọ́ ọmọ rẹ ni màá ti fà á ya,+ 13 àmọ́ kì í ṣe gbogbo ìjọba náà+ ni màá fà ya. Màá fún ọmọ rẹ ní ẹ̀yà kan,+ nítorí Dáfídì ìránṣẹ́ mi àti nítorí Jerúsálẹ́mù tí mo yàn.”+
14 Lẹ́yìn náà, Jèhófà gbé alátakò kan dìde sí Sólómọ́nì,+ ìyẹn Hádádì ọmọ Édómù, láti ìdílé ọba Édómù.+ 15 Nígbà tí Dáfídì ṣẹ́gun Édómù,+ Jóábù olórí ọmọ ogun lọ sin àwọn tó kú, ó sì wá ọ̀nà láti pa gbogbo ọkùnrin tó wà ní Édómù. 16 (Nítorí oṣù mẹ́fà ni Jóábù àti gbogbo Ísírẹ́lì fi gbé ibẹ̀ títí ó fi pa gbogbo ọkùnrin tó wà ní Édómù run.*) 17 Àmọ́ Hádádì fẹsẹ̀ fẹ pẹ̀lú àwọn kan lára ìránṣẹ́ bàbá rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọmọ Édómù, wọ́n sì lọ sí Íjíbítì; ọmọdé ni Hádádì nígbà yẹn. 18 Nítorí náà, wọ́n kúrò ní Mídíánì, wọ́n sì wá sí Páránì. Wọ́n kó àwọn ọkùnrin kan láti Páránì,+ wọ́n sì wá sí Íjíbítì, lọ́dọ̀ Fáráò ọba Íjíbítì, ẹni tó fún un ní ilé, tó ṣètò bí á ṣe máa rí oúnjẹ gbà, tó sì fún un ní ilẹ̀. 19 Hádádì rí ojú rere Fáráò débi pé ó fún un ní àbúrò ayaba Tápénésì, ìyàwó rẹ̀, pé kó fi ṣe aya. 20 Nígbà tó yá, àbúrò Tápénésì bí ọmọkùnrin kan fún un, Génúbátì lorúkọ rẹ̀, Tápénésì tọ́ ọ dàgbà* ní ilé Fáráò, Génúbátì sì ń gbé ní ilé Fáráò láàárín àwọn ọmọ Fáráò.
21 Hádádì gbọ́ ní Íjíbítì pé Dáfídì ti sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀+ àti pé Jóábù olórí ọmọ ogun ti kú.+ Torí náà, Hádádì sọ fún Fáráò pé: “Jẹ́ kí n lọ, kí n lè lọ sí ilẹ̀ mi.” 22 Àmọ́ Fáráò sọ fún un pé: “Kí lo fẹ́ tí o kò ní lọ́dọ̀ mi tí o fi fẹ́ lọ sí ilẹ̀ rẹ?” Ó fèsì pé: “Kò sí, àmọ́ jọ̀wọ́ jẹ́ kí n lọ.”
23 Ọlọ́run tún gbé alátakò míì dìde+ sí Sólómọ́nì, ìyẹn Résónì ọmọ Élíádà, ẹni tó sá kúrò lọ́dọ̀ olúwa rẹ̀, Hadadésà+ ọba Sóbà. 24 Ó kó àwọn ọkùnrin jọ sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sì di olórí àwọn jàǹdùkú* nígbà tí Dáfídì ṣẹ́gun*+ àwọn ọkùnrin Sóbà. Nítorí náà, wọ́n lọ sí Damásíkù,+ wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ibẹ̀, wọ́n sì ń ṣàkóso ní Damásíkù. 25 Ó di alátakò Ísírẹ́lì ní ìgbà ayé Sólómọ́nì, ó dá kún jàǹbá tí Hádádì ṣe, ó sì kórìíra Ísírẹ́lì gan-an nígbà tó ń jọba lórí Síríà.
26 Ẹnì kan wà tó ń jẹ́ Jèróbóámù+ ọmọ Nébátì nínú ẹ̀yà Éfúrémù, ó wá láti Sérédà, ìránṣẹ́ Sólómọ́nì+ ni. Sérúà lorúkọ ìyá rẹ̀, opó sì ni. Òun náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ̀tẹ̀* sí ọba.+ 27 Ohun tó jẹ́ kó ṣọ̀tẹ̀ sí ọba ni pé: Sólómọ́nì mọ Òkìtì,*+ ó sì dí àlàfo Ìlú Dáfídì bàbá rẹ̀.+ 28 Ọkùnrin tó dáńgájíá ni Jèróbóámù. Nígbà tí Sólómọ́nì rí i pé ọ̀dọ́kùnrin náà jẹ́ òṣìṣẹ́ kára, ó fi í ṣe alábòójútó+ gbogbo àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ọ̀ranyàn ní ilé Jósẹ́fù. 29 Ní àkókò yẹn, Jèróbóámù jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù, wòlíì Áhíjà+ ọmọ Ṣílò sì rí i lọ́nà. Ẹ̀wù tuntun ló wà lọ́rùn Áhíjà, àwọn méjèèjì nìkan ló sì wà ní pápá. 30 Áhíjà di ẹ̀wù tuntun tó wà lọ́rùn rẹ̀ mú, ó sì fà á ya sí ọ̀nà méjìlá (12). 31 Lẹ́yìn náà, ó sọ fún Jèróbóámù pé:
“Gba mẹ́wàá yìí, torí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: ‘Wò ó, màá fa ìjọba náà ya kúrò ní ọwọ́ Sólómọ́nì, màá sì fún ọ ní ẹ̀yà mẹ́wàá.+ 32 Àmọ́ ẹ̀yà kan ṣì máa jẹ́ tirẹ̀+ nítorí ìránṣẹ́ mi Dáfídì+ àti nítorí Jerúsálẹ́mù, ìlú tí mo yàn nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì.+ 33 Ohun tí màá ṣe nìyí torí pé wọ́n ti fi mí sílẹ̀,+ wọ́n sì ń forí balẹ̀ fún Áṣítórétì, abo ọlọ́run àwọn ọmọ Sídónì, fún Kémóṣì, ọlọ́run Móábù àti fún Mílíkómù, ọlọ́run àwọn ọmọ Ámónì, wọn ò rìn ní àwọn ọ̀nà mi láti máa ṣe ohun tí ó tọ́ lójú mi àti láti máa pa àwọn àṣẹ mi àti àwọn ìdájọ́ mi mọ́ bí Dáfídì bàbá Sólómọ́nì ti ṣe. 34 Àmọ́ mi ò ní gba gbogbo ìjọba náà kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, màá ṣì fi ṣe olórí ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, nítorí Dáfídì ìránṣẹ́ mi tí mo yàn,+ torí ó pa àwọn àṣẹ àti òfin mi mọ́. 35 Ṣùgbọ́n màá gba ìjọba náà kúrò lọ́wọ́ ọmọ rẹ̀, màá sì fi í fún ọ, ìyẹn ẹ̀yà mẹ́wàá.+ 36 Màá fún ọmọ rẹ̀ ní ẹ̀yà kan ṣoṣo, kí Dáfídì ìránṣẹ́ mi lè máa ṣàkóso* níwájú mi nígbà gbogbo ní Jerúsálẹ́mù,+ ìlú tí mo yàn fún ara mi láti fi orúkọ mi sí. 37 Màá yàn ọ́, wàá ṣàkóso lórí gbogbo ohun tí o* fẹ́, wàá sì di ọba lórí Ísírẹ́lì. 38 Tí o bá ṣe gbogbo ohun tí mo pa láṣẹ fún ọ, tí o rìn ní àwọn ọ̀nà mi, tí o sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú mi láti máa pa àwọn òfin àti àṣẹ mi mọ́, bí Dáfídì ìránṣẹ́ mi ti ṣe,+ èmi náà á wà pẹ̀lú rẹ. Màá kọ́ ilé tó máa wà títí lọ fún ọ, bí mo ṣe kọ́ ọ fún Dáfídì,+ màá sì fún ọ ní Ísírẹ́lì. 39 Màá dójú ti àtọmọdọ́mọ Dáfídì nítorí èyí,+ àmọ́ kò ní jẹ́ títí lọ.’”+
40 Torí náà, Sólómọ́nì wá ọ̀nà láti pa Jèróbóámù, àmọ́ Jèróbóámù sá lọ sí Íjíbítì, lọ́dọ̀ Ṣíṣákì+ ọba Íjíbítì,+ ó sì ń gbé ní Íjíbítì títí Sólómọ́nì fi kú.
41 Ní ti ìyókù ìtàn Sólómọ́nì, gbogbo ohun tí ó ṣe àti ọgbọ́n rẹ̀, ǹjẹ́ kò wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé ìtàn Sólómọ́nì?+ 42 Gbogbo ọdún* tí Sólómọ́nì fi jọba lórí gbogbo Ísírẹ́lì ní Jerúsálẹ́mù jẹ́ ogójì (40) ọdún. 43 Níkẹyìn, Sólómọ́nì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sí Ìlú Dáfídì bàbá rẹ̀; Rèhóbóámù+ ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.