Awọn Iwe Akajọ Òkun Òkú—Iṣura Ti Kò Lẹ́gbẹ́
NI APA isalẹ Wadi Qumran, ni apa ariwa iwọ-oorun Okun Òkú, ni àwókù igbaani diẹ wà. Eyi ti a ti kà tipẹtipẹ sí àwókù odi Roomu, afiyesi diẹ ni wọn ti gba lati ọ̀dọ̀ awọn awalẹpitan. Bi o ti wu ki o ri, iṣawari iwe akajọ Okun Òkú ti Aisaya ni 1947 tanná ran titun ibi aaye naa gbeyẹwo lẹẹkan sii.
Laipẹ awọn ọmọwe akẹkọọ jinlẹ dá awọn ile naa mọ̀ gẹgẹ bi eyi ti o jẹ́ ti awujọ onisin awọn Juu. Ero ti wọn ni lẹsẹkẹsẹ ni pe awọn eniyan wọnyi ti fi awọn iwe akajọ naa pamọ sinu iho àpáta laaarin awọn gegele okuta ti kò jinna. Ṣugbọn awọn àwárí lẹhin naa dabi eyi ti o mu iyemeji wa sori iyẹn.
Àwárí Kan Ti Kò Lẹ́gbẹ́
Awọn darandaran ara Arabia ni a mu wa lojufo si iniyelori awọn iwe afọwọkọ ti wọn ti rí tẹlẹtẹlẹ. Nitori naa, ni 1952, nigba ti ọkunrin arúgbó kan sọ nipa pe gẹgẹ bi èwe kan oun ti lé àparò ti o ti gbọgbẹ́ titi ti o fi sa wọ inu iho kan lara àpáta, nibi ti oun ti ri awọn ikoko amọ̀ ati àtùpà elépo igba atijọ, iwakiri titun ni a bẹrẹ loju ẹsẹ.
Ọkunrin arúgbó naa ni o ṣi ṣeeṣe fun lati da ẹnu iho àpáta naa mọ laaarin awọn ẹnu iho okuta kekeke ti o wa lara awọn gegele okuta oni gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ naa. O wa ṣẹlẹ pe o jẹ iho àpáta atọwọda eniyan, ti a mọ yatọ bayii gẹgẹ bi Iho Àpáta 4. Nibẹ ni darandaran ara Arabia naa ti ri awọn ẹyọ ẹyọ iwe afọwọkọ ni iwọn ẹsẹ bata diẹ si isalẹ iwọn ìpele ilẹ̀ ti o wà nigba naa. Ko si eyikeyii ninu ẹyọ ẹyọ naa ti a tii tọju pamọ sinu awọn ìṣà, nitori naa eyi ti o pọ julọ ninu wọn ti jẹrà bajẹ, ti o ti dúdú, ti o sì ti di eyi ti ńrún gan-an. Bi akoko ti nlọ nǹkan bii 40,000 awọn èbúbù ni a tun ṣawari, ti o duro fun nǹkan ti o fẹrẹẹ to 400 awọn iwe afọwọkọ. Gbogbo awọn iwe inu Iwe Mimọ lede Heberu, yatọ si Ẹsiteri, ni a ṣoju fun laaarin ọgọrun-un awọn iwe afọwọkọ Bibeli. Eyi ti o pọju ninu awọn akojọpọ ọrọ ti a ṣawari lati inu Iho Àpáta 4 ni a kò tii tẹjade sibẹsibẹ.
Ọkan ti o tubọ ṣe pataki ninu awọn iwe afọwọkọ naa jẹ awọn iwe Samuẹli, ti a dàkọ sinu iwe kika kanṣoṣo. Ọrọ iwe Heberu rẹ̀, ti a kọ pamọ ni 47 awọn òpó ìlà ọrọ ninu eyi ti o ṣeeṣe ki o jẹ 57, ni o farajọra gidi si eyi ti awọn olutumọ ẹ̀dà Greek Septuagint lò. Awọn àjákù awọ Giriiki ti Septuagint lati inu Lefitiku ati Numeri wà pẹlu ti ọjọ rẹ̀ padasẹhin si ọgọrun-un ọdun kìn-ínní B.C.E. Iwe afọwọkọ Lefitiku lo IAO, fun Heberu naa יהוה, orukọ atọrunwa Ọlọrun, dipo ti Giriiki naa Kyʹri·os, “Oluwa.”a
Ninu àjákù kan lati inu Deuteronomi, ọrọ iwe Heberu naa ni ninu apakan lati inu ori 32, ẹsẹ 43, ti a ri ninu Septuagint ti a sì fayọ ni Heberu 1:6: “Ki gbogbo awọn angẹli Ọlọrun ki o foribalẹ fun un.” Eyi jẹ igba akọkọ ti a o ri ila yii ninu iwe afọwọkọ Heberu eyikeyii, ti o nṣafihan ọrọ iwe ti ntẹnumọ itumọ Giriiki lọna hihan gbangba. Awọn ọmọwe akẹkọọ jinlẹ nipa bayii ti jèrè ijinlẹ oye titun nipa ọrọ iwe ti Septuagint, ti a saba maa nfayọ ninu Iwe Mimọ lede Giriiki.
Iwe akajọ Ẹkisodu kan ni ọjọ rẹ̀ ti jinna to awọn ọdun ti o kẹhin ọrundun kẹta B.C.E., ọkan lara Samuẹli jinna to opin ọrundun kan naa, iwe akajọ Jeremaya sì jẹ́ laaarin 225 ati 175 B.C.E. Akojọ ọrọ ti o pọ to lati ọrundun kẹta si ọrundun kìn-ínní B.C.E. ni a ti ri ti o tọpasẹ awọn iyipada ninu ọna igba kọwe ati olukuluku awọn lẹta ọ̀rọ̀ Heberu ati awọn lẹta Aramaiki, ohun kan ti o tun wulo lọna titobi lati mọ ọjọ awọn ìwé afọwọkọ.
Iyalẹnu Inu Iho Àpáta 11
Asẹhinwa asẹhinbọ, gbogbo agbegbe Qumran ni a ti wá kiri delẹdelẹ, nipasẹ awọn darandaran ara Arabia adugbo ati nipasẹ awọn awalẹpitan. Sibẹsibẹ, ni ọjọ kan ni 1956, awọn darandaran ara Arabia kan ṣakiyesi awọn àdán ti wọn ntu jade lati inu iho ninu awọn gegele àpáta naa ni apa ariwa Ihò Àpáta 1. Wọn gòkè wọn sì rí ihò àpáta miiran, ti a dí ẹnu abawọle rẹ̀ pa. Iwọn tọọnu meji awọn okuta ti wọn wó lulẹ ni a nilati gbé kuro lati ṣi sojutaye. Awọn ohun ti a ṣawari ninu rẹ̀ jẹ ayanilẹnu—awọn iwe afọwọkọ meji pipe perepere ati apá titobi marun-un ninu ti awọn miiran.
Eyi ti o ṣe pataki julọ ti a ṣawari jẹ iwe akajọ didara ti awọn Saamu. Nínípọn ti awọ naa nipọn damọran pe o ṣeeṣe ki o jẹ awọ ọmọ maluu dipo awọ ewúrẹ́. Apapọ wọn jẹ abala marun-un, awọn awẹ́ mẹrin ti o ṣee yà sọtọọtọ, ati awọn àjákù awọ mẹrin fun un ni gígùn ti o ju ẹsẹ bata 13. Bi o tilẹ jẹ pe apa oke iwe akajọ yii ni a tọju pamọ daradara, eti isalẹ ti jẹra lọna ti o pọ̀ gan-an. Ọjọ rẹ pada sẹhin si idaji akọkọ ninu ọrundun kìn-ínní C.E. ti o sì ni awọn apá kan tabi omiran lara awọn saamu ti o jẹ 41 lapapọ ninu. Ikọwe onilẹta mẹrin ti Heberu fun orukọ Ọlọrun ni a kọ ni nǹkan bii 105 ìgbà ni ọna ikọwe Heberu atijọ, ti o mu ki o dá yatọ laaarin ọna ikọwe Heberu onígun mẹrin ti ọ̀rọ̀ inu iwe naa.
Iwe afọwọkọ miiran, ti Lefitiku, ni a kọ gbogbo rẹ̀ latokedelẹ ni ọna ikọwe Heberu atijọ, ṣugbọn ìdí ti eyi fi ri bẹẹ sibẹsibẹ ni a kò tii ṣalaye lẹkun-unrẹrẹ. O jẹ iwe akọsilẹ ti o pẹ́ julọ ti o lo iru ọna ikọwe yii, eyi ti a nlo nigba ti awọn Juu lọ si igbekun ni Babiloni ni ipari ọrundun kẹtadinlogun B.C.E.
Ẹ̀dà iwe Targum, ọ̀rọ̀ atunsọlọrọ miiran ni èdè Aramaiki fun iwe Joobu, pẹlu wá sojutaye. O jẹ ọkan lara awọn Targum ipilẹṣẹ ti a kọ silẹ. Ọpọlọpọ awọn alaye lori awọn iwe Bibeli miiran pẹlu ni a rí ninu awọn ihò àpáta miiran. Bawo ni awọn iwe akajọ wọnyi ṣe wá di eyi ti a tọju pamọ lọna ti o dara bayii ninu awọn iho àpáta wọnyi?
Gẹgẹ bi a ṣe mẹnukan an ni ibẹrẹ, diẹ ninu wọn ni a ti lè tọju pamọ nipasẹ awọn awujọ Qumran. Ṣugbọn lati inu ẹ̀rí, o fẹrẹẹ dabi ẹni pe ọpọlọpọ ninu wọn ni a fi sibẹ nipasẹ awọn Juu ti nsalọ fun idide awọn ara Roomu lodisi Judea ni ọdun 68 C.E., ṣaaju iparun Jerusalẹmu nigbẹhin gbẹhin ni ọdun meji lẹhin naa. Aginju Judea jẹ ibi alailewu ti àdánidá fun awọn iwe afọwọkọ aṣeyebiye naa kii ṣe kiki ninu awọn ihò àpáta ti o wa nitosi Qumran nikan ni ṣugbọn ninu awọn wọnni ti o wà ni ọpọlọpọ ibusọ si ariwa, ni ayika Jericho, ati si guusu, lẹbaa Masada. Bawo ni awa ṣe kun fun ọpẹ to fun itọjupamọ wọn! Wọn pese ẹ̀rí siwaju sii nipa aiṣeeyipada awọn Ọ̀rọ̀ Jehofa ti a mísí. Nitootọ, “ọ̀rọ̀ Ọlọrun wa yoo duro laelae.”—Aisaya 40:8.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Reference Bible, Afikun eti iwe 1C (5) ati alaye eti iwe si Lefitiku 3:12, nibi ti a ti fi iwe afọwọkọ yii hàn yatọ gẹgẹ bii 4Q LXX Levb.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]
A O HA RI PUPỌ SII LAIPẸ BÍ?
Bi o tilẹ jẹ pe a ti ṣe awari wọn ni ọpọ ẹ̀wádún sẹhin, eyi ti o pọju ninu awọn àjákù Iwe akajọ Òkun Òkú ni a kò tẹjade. The New York Times ti December 23, 1990, sọrọ itẹmbẹlu pe: “Koda awọn ẹda wọn ti a yà láwòrán ni a pa mọ́wọ́ nipasẹ awujọ awọn ọmọwe akẹkọọ jinlẹ oniṣe idakọnkọ ti wọn fọwọ́rọ́ awọn alajumọṣiṣẹ wọn tì tí wọn sì kọ̀ lati tẹ eyi ti o pọ̀ ninu akojọ ọ̀rọ̀ ti o wà ni ikawọ wọn.” Iwe naa rohin, bi o ti wu ki o ri, pe iyipada ninu ẹgbẹ́ oṣiṣẹ laaarin awọn ajọ olootu onkọwe yii ni a ti ṣe lẹnu aipẹ yii, eyi ti o lè jẹ igbesẹ si fífòpinsí “iṣe idakọnkọ ti o yi awọn iwe akajọ naa ka . . . ayé yoo sì mọ̀ pupọ sii nipa sanmanni kan ti o jẹ àrà ọ̀tọ̀ ninu ìtàn.”
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 12]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.