Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
FEBRUARY 3-9
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 12-14
“Májẹ̀mú Kan Tó Kàn Ẹ́”
it-1 522 ¶4
Májẹ̀mú
Májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá. Májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nígbà tí Ábúrámù (Ábúráhámù) sọdá Odò Yúfírétì bó ṣe ń lọ sí ilẹ̀ Kénáánì. Ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ọgbọ̀n (430) ọdún lẹ́yìn náà ni Ọlọ́run bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú Òfin. (Ga 3:17) Jèhófà bá Ábúráhámù sọ̀rọ̀ nígbà tó ń gbé ní Mesopotámíà, ìyẹn ní ìlú Úrì àwọn ará Kálídíà, ó sì sọ fún un pé kó lọ sí orílẹ̀-èdè tóun máa fi hàn án. (Iṣe 7:2, 3; Jẹ 11:31; 12:1-3) Ẹ́kísódù 12:40, 41 (LXX) sọ pé nígbà tí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ọgbọ̀n (430) ọdún tí wọ́n lò ní Íjíbítì àti ní ilẹ̀ Kénáánì pé, “ní ọjọ́ yìí” àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n wà lóko ẹrú jáde kúrò ní Íjíbítì. Wọ́n jáde ní Nísàn 14, ọdún 1513 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìyẹn ọjọ́ Ìrékọjá. (Ẹk 12:2, 6, 7) Èyí jẹ́ ká rí i pé ó ṣeé ṣe kí Ábúráhámù sọdá Odò Yúfírétì ní Nísàn 14, ọdún 1943 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìgbà yẹn sì ní májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Ọlọ́run tún bá Ábúráhámù sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tó dé Ṣékémù ní ilẹ̀ Kénáánì, ó sì fi kún ìlérí tó ṣe fún un pé, “Ọmọ rẹ ni èmi yóò fún ní ilẹ̀ yìí.” Èyí jẹ́ ká rí bí májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Ábúráhámù dá ṣe tan mọ́ ìlérí tó ṣe nínú ọgbà Édẹ́nì, ó sì jẹ́ ká rí i pé “ọmọ” náà máa jẹ́ èèyàn, ìyẹn ni pé á wá láti ìlà ìdílé kan. (Jẹ 12:4-7) A lè rí àwọn ìlérí míì tí Jèhófà ṣe tó fìdí májẹ̀mú yìí múlẹ̀ nínú Jẹ́nẹ́sísì 13:14-17; 15:18; 17:2-8, 19; 22:15-18.
w89 7/1 3 ¶4
Ìdí Tí Ìwọ fi Níláti Mọ Òtítọ́ Nípa Ábúráhámù
Ìlérí amọ́kànyọ̀ lèyí jẹ́, ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sì ni Jèhófà ṣèlérí yìí fún Ábúráhámù. (Jẹ́nẹ́sísì 18:18; 22:18) Kí ìlérí yìí lè ṣẹ, Ọlọ́run máa jí àwọn olórí ìdílé tó ti kú tipẹ́tipẹ́ dìde. Ìbùkún ńlá lèyí máa jẹ́ fáwọn tó bá jíǹde torí pé wọ́n á pa dà sínú ayé táá ti di Párádísè, irú èyí tá a pàdánù tẹ́lẹ̀. Wọ́n á sì tún kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí wọ́n máa ṣe kí wọ́n lè gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun.—Jẹ́nẹ́sísì 2:8, 9, 15-17; 3:17-23.
it-2 213 ¶3
Òfin
Nígbà tí wọ́n ṣàyẹ̀wò ohun táwọn awalẹ̀pìtàn rí, àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé tí wọ́n bá fẹ́ ta ilẹ̀ kan, ẹni tó fẹ́ ta ilẹ̀ á mú ẹni tó fẹ́ ra ilẹ̀ náà lọ síbi táá ti rí gbogbo ilẹ̀ náà dáadáa. Tí ẹni tó fẹ́ ra ilẹ̀ náà bá ti sọ pé, “Mo rí i,” ìyẹn fi hàn pé ó ti gbà láti ra ilẹ̀ náà. Nígbà tí Jèhófà ṣèlérí fún Ábúráhámù pé òun máa fún un ní ilẹ̀ Kénáánì, ó kọ́kọ́ sọ pé kí Ábúráhámù wo igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ náà. Ábúráhámù ò sọ pé “Mo rí i,” bóyá torí pé ọmọ rẹ̀ ni Jèhófà sọ pé òun máa fún ní ilẹ̀ náà tó bá yá. (Jẹ 13:14, 15) Nígbà tó yá, Jèhófà sọ fún Mósè tó ń ṣojú fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kó fi ojú ara rẹ̀ “rí” ilẹ̀ náà. Tó bá sì jẹ́ pé bọ́rọ̀ ṣe rí làwọn ọ̀mọ̀wé náà sọ, á jẹ́ pé ilẹ̀ náà máa di táwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́nà òfin, wọ́n á sì gbà á lábẹ́ ìdarí Jóṣúà. (Di 3:27, 28; 34:4; tún ṣàyẹ̀wò ohun tí Sátánì fi lọ Jésù nínú Mt 4:8.) Ohun míì tó tún máa ń fi hàn pé ilẹ̀ kan tí di tẹnì kan ni pé, kẹ́nì náà rin ilẹ̀ náà já tàbí kó wọ ibẹ̀ láti gbà á. (Jẹ 13:17; 28:13) Nínú àwọn ìwé àtijọ́ kan tí wọ́n ṣàwárí, wọ́n máa ń kọ iye igi tó wà lórí ilẹ̀ kan tí wọ́n bá fẹ́ tà á—Fi wé Jẹ 23:17, 18.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ẹ Máa Fìfẹ́ Yanjú Aáwọ̀
12 Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa báwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣe yanjú ọ̀rọ̀ kan tó lè dá aáwọ̀ sílẹ̀ láàárín wọn, ọ̀kan lára rẹ̀ ni ti Ábúráhámù àti ìbátan rẹ̀ Lọ́ọ̀tì. Àwọn méjèèjì ní ẹran ọ̀sìn, àmọ́ àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọn ń bá ara wọn jà lórí ilẹ̀ táwọn ẹran náà ń jẹ̀ sí. Torí pé Ábúráhámù ò fẹ́ wàhálà, ó ní kí Lọ́ọ̀tì kọ́kọ́ mú apá ibi tóun àti ìdílé rẹ̀ máa wà. (Jẹ́n. 13:1, 2, 5-9) Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ rere ló fi lélẹ̀ fún wa! Bí wọ́n ṣe máa wà lálàáfíà ni Ábúráhámù ń wá, kì í ṣe bó ṣe máa tẹ́ ara rẹ̀ lọ́rùn. Ṣé ó wá jìyà ohun tó ṣe yẹn? Rárá. Kété lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, Jèhófà ṣèlérí ìbùkún rẹpẹtẹ fún Ábúráhámù. (Jẹ́n. 13:14-17) Ọlọ́run ò ní jẹ́ káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jìyà àjẹgbé torí pé wọ́n tẹ̀ lé ìlànà Ìwé Mímọ́ láti fìfẹ́ yanjú aáwọ̀.
it-2 683 ¶1
Àlùfáà
Àlùfáà (ko·henʹ) tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni Melikisédékì ọba Sálẹ́mù. Bíbélì ò to àwọn baba ńlá rẹ̀, ìgbà tí wọ́n bí i àti ìgbà tó kú. Bákan náà, kò jogún ipò àlùfáà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sẹ́nì tó wà nípò yẹn ṣáájú rẹ̀ tàbí lẹ́yìn rẹ̀. Melikisédékì tún jẹ́ ọba àti àlùfáà. Ipò àlùfáà rẹ̀ ga ju táwọn ọmọ Léfì lọ torí pé Léfì san ìdá mẹ́wàá fún Melikisédékì, ní ti pé Ábúráhámù baba ńlá rẹ̀ fún Melikisédékì ní ìdá mẹ́wàá, ó sì gba ìbùkún. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ara Ábúráhámù ni Léfì ti jáde. (Jẹ 14:18-20; Heb 7:4-10) Lọ́nà yìí, Melikisédékì ń ṣàpẹẹrẹ Jésù Kristi tó “jẹ́ àlùfáà títí láé ní ọ̀nà ti Melikisédékì.”—Heb 7:17.
Bíbélì Kíkà
FEBRUARY 10-16
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 15-17
“Kí Nìdí Tí Jèhófà Fi Yí Orúkọ Ábúrámù àti Sáráì Pa Dà?”
it-1 817
Ẹ̀bi, Wíwá Ẹ̀bi
Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àṣìṣe máa ń pọ̀ nínú ohun téèyàn bá ṣe. Ìdí ni pé ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé la jogún látọ̀dọ̀ Ádámù. (Ro 5:12; Sm 51:5) Àmọ́ Jèhófà tóun fúnra rẹ̀ jẹ́ aláìlẹ́bi “mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá,” ó sì máa ń ṣàánú wa. (Sm 103:13, 14) Ó ka Nóà tó jẹ́ olóòótọ́ àti onígbọràn sí “aláìlẹ́bi láàárín àwọn tí wọ́n jọ gbé láyé.” (Jẹ 6:9) Ó pàṣẹ fún Ábúráhámù pé, “Máa bá mi rìn, kí o sì fi hàn pé o jẹ́ aláìlẹ́bi.” (Jẹ 17:1) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé làwọn méjèèjì, wọ́n sì kú, Jèhófà tó ń “rí ohun tó wà nínú ọkàn” kà wọ́n sí aláìlẹ́bi. (1Sa 16:7; fi wé 2Ọb 20:3; 2Kr 16:9.) Ó pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Kí ẹ rí i pé ẹ jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín.” (Di 18:13; 2Sa 22:24) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà fún wa ní Ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ aláìlẹ́bi (Heb 7:26) gẹ́gẹ́ bí ìràpadà. Nípasẹ̀ ìràpadà yìí, Ọlọ́run lè pe ẹnikẹ́ni tó bá nígbàgbọ́ tó sì ń ṣègbọràn ní “olódodo” tàbí aláìlẹ́bi láìtẹ ìlànà ìdájọ́ òdodo tó gbé kalẹ̀ lójú.—Ro 3:25, 26; wo ÌṢÒTÍTỌ́; ÌJẸ́PÍPÉ.
it-1 31 ¶1
Ábúráhámù
Ọjọ́ ń gorí ọjọ́. Wọ́n sì ti lo nǹkan bí ọdún mẹ́wàá ní ilẹ̀ Kénáánì báyìí, síbẹ̀ Sérà ò bímọ. Sérà wá sọ fún un pé kó fẹ́ Hágárì ìránṣẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ Íjíbítì kó lè bímọ fún un, Ábúráhámù sì gbà. Torí náà Ábúráhámù bí Íṣímáẹ́lì lọ́dún 1932 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìyẹn nígbà tí Ábúráhámù jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínláàádọ́rùn-ún (86). (Jẹ 16:3, 15, 16) Nígbà tó di ọdún 1919 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìyẹn nígbà tí Ábúráhámù jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún (99), Jèhófà pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn ọkùnrin tó wà nílé rẹ̀ dádọ̀dọ́, kó lè jẹ́ àmì àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ tó wà láàárín òun àti Ábúráhámù. Lẹ́sẹ̀ kan náà, Jèhófà yí orúkọ ẹ̀ pa dà láti Ábúrámù sí Ábúráhámù torí Jèhófà sọ pé, “màá mú kí o di bàbá ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.” (Jẹ 17:5, 9-27; Ro 4:11) Kò pẹ́ sígbà yẹn ni àwọn áńgẹ́lì mẹ́ta wá lórúkọ Jèhófà, Ábúráhámù ṣe wọ́n lálejò, wọ́n wá ṣèlérí fún un pé Sérà máa lóyún, á sì bí ọmọkùnrin kan ní ọdún tó máa tẹ̀ lé e!—Jẹ 18:1-15.
Ilé Là Ń Wò Ká Tó Sọmọ Lórúkọ?
Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yí orúkọ àwọn àgbàlagbà kan pa dà kó lè fi sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ Ábúrámù tó túmọ̀ sí “Ọlọ́run Gbé Bàbá Ga” di Ábúráhámù tó túmọ̀ sí “Bàbá Ogunlọ́gọ̀.” Orúkọ yìí sì ro Ábúráhámù lóòótọ́ torí pé nígbà tó yá ó di bàbá fáwọn orílẹ̀-èdè tó pọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 17:5, 6) Tún wo orúkọ ìyàwó Ábúráhámù, ìyẹn Sáráì, tó ṣeé ṣe kó túmọ̀ sí “Àríyànjiyàn.” Ó dájú pé inú ẹ̀ máa dùn gan-an, nígbà tí Ọlọ́run sọ orúkọ ẹ̀ di “Sérà” tó túmọ̀ sí “Ìyá Ọba,” ìyẹn sì jẹ́ kó mọ̀ pé òun ṣì máa di ìyá ńlá fáwọn ọba.—Jẹ́nẹ́sísì 17:15, 16.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-1 460-461
Ọjọ́ Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Inú Bíbélì
Jèhófà sọ fún Ábúrámù (Ábúráhámù) pé: “Mọ̀ dájú pé àwọn ọmọ rẹ máa di àjèjì ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tiwọn, àwọn èèyàn ibẹ̀ á fi wọ́n ṣe ẹrú, wọ́n á sì fìyà jẹ wọ́n fún ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọdún.” (Jẹ 15:13; tún wo Iṣe 7:6, 7.) Jèhófà sọ̀rọ̀ yìí ṣáájú kí wọ́n tó bí “ọmọ” tá a ṣèlérí náà, ìyẹn Ísákì. Lọ́dún 1932 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Ábúrámù bí Íṣímáẹ́lì nípasẹ̀ Hágárì tó jẹ́ ìránṣẹ́ àti ọmọ Íjíbítì, nígbà tó sì di ọdún 1918 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Sérà bí Ísákì. (Jẹ 16:16; 21:5) Tá a bá wá ka ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọdún tí ‘ìfìyàjẹni’ náà dópin wá sẹ́yìn, (Jẹ 15:14) ìyẹn ìgbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò nígbèkùn ní Íjíbítì, á mú wa wá sí ọdún 1913 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìyẹn sì jẹ́ ìgbà tí Ísákì wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún márùn-ún. Ó jọ pé ìgbà yẹn ni wọ́n gba ọmú lẹ́nu Ísákì, ó sì jẹ́ “àjèjì” ní ilẹ̀ tí kì í ṣe tirẹ̀. Àsọtẹ́lẹ̀ ìfìyàjẹni yìí bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Íṣímáẹ́lì tó ti pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún (19) bẹ̀rẹ̀ sí í fi Ísákì “ṣe yẹ̀yẹ́.” (Jẹ 21:8, 9) Ohun tí Íṣímáẹ́lì ń ṣe sí Ísákì tó máa jogún Ábúráhámù lè dà bí ohun tí kò tó nǹkan lójú wa lónìí, àmọ́ ká fi sọ́kàn pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ láyé ìgbà yẹn. Ìdí nìyẹn tí Sérà fi takú pé àfi kí Ábúráhámù lé Hágárì àti Íṣímáẹ́lì lọ, Jèhófà náà sì fọwọ́ sí ohun tí Sérà sọ. (Jẹ 21:10-13) Bákan náà, ti pé wọ́n ṣàkọsílẹ̀ ìtàn yìí sínú Ìwé Mímọ́ jẹ́ kó hàn gbangba pé àsìkò yẹn ni àsọtẹ́lẹ̀ ìfìyàjẹni tó máa gba ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọdún náà bẹ̀rẹ̀, ó sì parí nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lóko ẹrú ní Íjíbítì.—Ga 4:29.
it-1 778 ¶4
Wọ́n Kúrò Nígbèkùn
“Ìran wọn kẹrin.” Ká rántí pé Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé ní ìran kẹrin, àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ máa pa dà sí ilẹ̀ Kénáánì. (Jẹ 15:16) Àmọ́, tá a bá ka àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù látìgbà tí Ọlọ́run ti bá a dá májẹ̀mú títí dìgbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò nígbèkùn Íjíbítì, èyí tó jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ọgbọ̀n (430) ọdún, a máa rí i pé ó ju ìran mẹ́rin lọ láìka pé ẹ̀mí wọn máa ń gùn nígbà yẹn. Àmọ́ ọgọ́rùn-ún ọdún méjì ó lé mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (215) gangan làwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò ní Íjíbítì. ‘Ìran mẹ́rin’ yìí bẹ̀rẹ̀ látìgbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti wọ ilẹ̀ Íjíbítì. Ká lè lóye kókó yìí, ẹ jẹ́ ká lo àpẹẹrẹ ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, ìyẹn Léfì. (1) Léfì bí (2) Kóhátì, Kóhátì bí (3) Ámúrámù, Ámúrámù sì bí (4) Mósè.—Ẹk 6:16, 18, 20.
Bíbélì Kíkà
FEBRUARY 17-23
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 18-19
“‘Onídàájọ́ Gbogbo Ayé’ Pa Sódómù àti Gòmórà Run”
‘Onídàájọ́ Ilẹ̀ Ayé’ Máa Ń Ṣe Ohun Tó Tọ́ Nígbà Gbogbo
Ó DÁ Ábúráhámù lójú pé Jèhófà máa ṣèdájọ́ tó tọ́ fáwọn èèyàn Sódómù àti Gòmórà. Ìdí nìyẹn tó fi béèrè pé: “Onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé kì yóò ha ṣe ohun tí ó tọ́ bí?” (Jẹ́n. 18:25) Ábúráhámù mọ̀ dájú pé Jèhófà kò ní ṣe ohun tí kò tọ́ láé, kò ní “fi ikú pa olódodo pẹ̀lú ẹni burúkú.” Lójú Ábúráhámù, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ “kò ṣeé ronú kàn.” Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [400] ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ nípa ara rẹ̀ pé: “Àpáta náà, pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀, nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo. Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀; Olódodo àti adúróṣánṣán ni.”—Diu. 31:19; 32:4.
Ìpamọ́ra—Fífaradà Á Pẹ̀lú Ìrètí
Jèhófà ló fi àpẹẹrẹ tó ga jù lọ lélẹ̀ tó bá di pé ká ní sùúrù. (2 Pét. 3:15) Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ló wà nínú Bíbélì nípa bí Jèhófà ṣe fi sùúrù bá àwọn èèyàn lò. (Neh. 9:30; Aísá. 30:18) Bí àpẹẹrẹ, ṣé Jèhófà bínú nígbà tí Ábúráhámù bi í ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè nípa ìdí tó fi fẹ́ pa ìlú Sódómù run? Rárá o, Jèhófà ò dá ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu nígbà tó ń béèrè ìbéèrè. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló fara balẹ̀ tẹ́tí sí ọ̀kọ̀ọ̀kan ìbéèrè tí Ábúráhámù béèrè. Lẹ́yìn náà, Jèhófà tún àwọn ọ̀rọ̀ Ábúráhámù sọ kí Ábúráhámù lè mọ̀ pé òun gbọ́ gbogbo ohun tó sọ, ó sì fi dá Ábúráhámù lójú pé òun ò ní pa ìlú Sódómù run tóun bá rí olódodo mẹ́wàá péré níbẹ̀. (Jẹ́n. 18:22-33) Èyí jẹ́ ká rí i pé Jèhófà máa ń fara balẹ̀ tẹ́tí sí wa, kì í sì í fi ìwàǹwara gbé ìgbésẹ̀. Àpẹẹrẹ tó dáa nìyẹn jẹ́ fún wa.
Jèhófà Ni Olúwa Ọba Aláṣẹ Wa!
12 Ó yẹ kó dá wa lójú pé láìpẹ́, Jèhófà máa lo agbára rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run torí pé kò ní máa fàyè gba ìwà ibi títí gbére, a sì mọ̀ pé ọjọ́ ìkẹyìn là ń gbé yìí. Jèhófà pa àwọn ẹni ibi run nígbà Ìkún-omi. Ó pa ìlú Sódómù àti Gòmórà run, ó sì tún pa Fáráò àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ náà run. Sísérà àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀, Senakéríbù àtàwọn ẹgbẹ́ ogun Ásíríà tó kó sòdí kò rọ́wọ́ mú níwájú Ẹni Gíga Jù Lọ. (Jẹ́n. 7:1, 23; 19:24, 25; Ẹ́kís. 14:30, 31; Oníd. 4:15, 16; 2 Ọba 19:35, 36) Torí náà, ẹ jẹ́ ká fọkàn balẹ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run kò kàn ní máa wo àwọn tó ń hùwà àìlọ́wọ̀ sí orúkọ rẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣe àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ níṣekúṣe níran títí láé. Síwájú sí i, a ti ń rí ẹ̀rí àmì wíwàníhìn-ín Jésù àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan búburú yìí.—Mát. 24:3.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
w88 5/15 23 ¶4-5
Ẹnikẹ́ni Ha Ti Rí Ọlọ́run Bí?
Nísinsìnyí, ó ṣeé ṣe láti lóye ìdí tí Ábúráhámù fi bá áńgẹ́lì tó ń ṣojú fún Ọlọ́run sọ̀rọ̀ bíi pé Jèhófà gan-an ló ń bá sọ̀rọ̀. Níwọ̀n bí áńgẹ́lì yìí ti sọ ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ kí ó sọ gẹ́lẹ́ fún Ábúráhámù, tó sì wà níbẹ̀ láti ṣojú fún Ọlọ́run, Bíbélì lè sọ nígbà náà pé “Jèhófà fara hàn án.”—Jẹ́nẹ́sísì 18:1.
Ká rántí pé áńgẹ́lì yìí lè jíṣẹ́ tí Jèhófà rán an bí fóònù kan tàbí rédíò ṣe lè ta àtaré ọ̀rọ̀ látọ̀dọ̀ ẹnì kan sí ẹlòmíì. Ìyẹn jẹ́ ká rí ìdí tí Ábúráhámù, Mósè, Mánóà àtàwọn míì fi lè bá àwọn áńgẹ́lì sọ̀rọ̀ bíi pé Ọlọ́run ni wọ́n ń bá sọ̀rọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn yìí lè rí àwọn áńgẹ́lì náà àti ògo Jèhófà tó hàn lára wọn, síbẹ̀ wọn ò lè rí Ọlọ́run. Torí náà, ẹsẹ Bíbélì yìí ò ta ko ohun tí àpọ́sítélì Jòhánù sọ, pé: “Kò sí èèyàn tó rí Ọlọ́run rí.” (Jòhánù 1:18) Àwọn áńgẹ́lì làwọn ọkùnrin yìí rí, kì í ṣe Ọlọ́run fúnra rẹ̀.
Máa Ṣèrànwọ́ Fáwọn Tó Ní Ìdààmú Ọkàn
3 Ìpinnu tí kò bọ́gbọ́n mu ni Lọ́ọ̀tì ṣe nígbà tó yàn láti máa gbé láàárín àwọn ará Sódómù tí wọ́n jẹ́ oníṣekúṣe. (Ka 2 Pétérù 2:7, 8.) Òótọ́ ni pé nǹkan rọ̀ṣọ̀mù lágbègbè yẹn, àmọ́ Lọ́ọ̀tì jìyà ìpinnu tó ṣe. (Jẹ́n. 13:8-13; 14:12) Ó jọ pé ọkàn ìyàwó rẹ̀ ò kúrò nílùú yẹn tàbí kó jẹ́ pé kò fẹ́ fi àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sílẹ̀. Èyí mú kó ṣàìgbọràn sí Jèhófà, ó sì pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nígbà tí Jèhófà rọ̀jò iná àti imí ọjọ́ sórí ìlú náà. Bákan náà, àwọn ọmọbìnrin Lọ́ọ̀tì méjèèjì pàdánù àwọn àfẹ́sọ́nà wọn nígbà tí Jèhófà pa ìlú Sódómù run. Lọ́ọ̀tì pàdánù ilé rẹ̀ àti gbogbo ohun tó ní, èyí tó sì dunni jù ni pé ó pàdánù ìyàwó rẹ̀, ó mà ṣé o! (Jẹ́n. 19:12-14, 17, 26) Àmọ́ ṣé Jèhófà mú sùúrù fún Lọ́ọ̀tì ní gbogbo àsìkò tí nǹkan nira yìí? Bẹ́ẹ̀ ni.
Bíbélì Kíkà
FEBRUARY 24–MARCH 1
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JẸ́NẸ́SÍSÌ 20-21
“Gbogbo Ìgbà Ni Jèhófà Máa Ń Mú Àwọn Ìlérí Rẹ̀ Ṣẹ”
Ọlọ́run Pè É Ní “Ìyá Ọba”
Ṣé ẹ̀rín tí Sérà rín fi hàn pé kò ní ìgbàgbọ́ ni? Rárá o. Torí Bíbélì sọ pé: “Ìgbàgbọ́ mú kí Sérà náà gba agbára láti lóyún ọmọ, kódà nígbà tí ọjọ́ orí rẹ̀ ti kọjá ti ẹni tó lè bímọ, torí ó ka Ẹni tó ṣe ìlérí náà sí olóòótọ́.” (Hébérù 11:11) Sérà mọ̀ pé kò sí ìlérí tí Jèhófà ṣe tí kò ní nímùúṣẹ. Gbogbo wa la nílò irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀. Ohun tó dáa ni pé ká mọ Ọlọ́run tó ṣe Bíbélì lámọ̀dunjú. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa jẹ́ ká rí i pé Sérà tọ̀nà láti nírú ìgbàgbọ́ tó ní. Olóòótọ́ ni Jèhófà, ó sì máa ń mú gbogbo ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Nígbà míì, ó máa ń mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ lọ́nà tó máa yà wá lẹ́nu débì pé àá fẹ́ẹ̀ lè máa ṣiyèméjì pàápàá!
“FETÍ SÍ OHÙN RẸ̀”
Nígbà tí Sérà wà lẹ́ni àádọ́rùn-ún [90] ọdún, ọwọ́ rẹ̀ tẹ ohun tó ti ń fojú sọ́nà fún látìgbà tó ti wà nílé ọkọ. Ó bí ọmọkùnrin kan fún olólùfẹ́ rẹ̀ tó ti pé ẹni ọgọ́rùn-ún [100] ọdún! Ábúráhámù sọ ọmọ náà ní Ísákì tàbí “Ẹ̀rín,” bí Ọlọ́run ṣe sọ fún un. Àwa náà lè fọkàn yàwòrán bí Sérà ìyá arúgbó ṣe ń rẹ́rìn-ín músẹ́ nígbà tó sọ pé: “Ọlọ́run ti pa mí lẹ́rìn-ín; gbogbo ẹni tó bá gbọ́ nípa rẹ̀ á bá mi rẹ́rìn-ín.” (Jẹ́nẹ́sísì 21:6) Ó dájú pé ẹ̀bùn ìyanu tí Jèhófà fún un yìí máa múnú rẹ̀ dùn títí tó fi kú. Àmọ́ ṣá, iṣẹ́ ńlá ló já lé Sérà léjìká yìí o.
Nígbà tí Ísákì wà lọ́mọ ọdún márùn-ún, ìdílé náà ṣe ayẹyẹ tí wọ́n fi já a lẹ́nu ọmú. Àmọ́, nǹkan ò lọ dáadáa. Bíbélì sọ pé Sérà “kíyè sí” ìwà kan tó ń kọni lóminú. Íṣímáẹ́lì ọmọ Hágárì ti pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19], ó sì máa ń fi Ísákì ṣe yẹ̀yẹ́. Èyí kì í ṣọ̀rọ̀ pé ó kàn ń bá a dá àpárá o. Kódà nígbà tó yá, Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti sọ pé inúnibíni ni Íṣímáẹ́lì ń ṣe sí Ísákì. Lójú Sérà, ìwà burúkú gbáà ni Íṣímáẹ́lì ń hù yìí, torí pé ó máa ṣàkóbá fún ìlera Ísákì. Sérà mọ̀ pé Ísákì kì í kàn ṣe ọmọ òun lásán; ó ní ojúṣe pàtàkì tí Jèhófà yàn fún un. Torí náà, Sérà ṣọkàn akin, ó sì sojú abẹ níkòó fún Ábúráhámù ọkọ rẹ̀. Ó sọ fún un pé kó lé Hágárì àti ọmọ rẹ̀ jáde.—Jẹ́nẹ́sísì 21:8-10; Gálátíà 4:22, 23, 29.
Báwo lọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára Ábúráhámù? Bíbélì sọ pé: “Ohun tó sọ nípa ọmọ yìí kò dùn mọ́ Ábúráhámù nínú rárá.” Torí pé ó fẹ́ràn Íṣímáẹ́lì, àjọṣe bàbá sọ́mọ tó wà láàárín wọn kò jẹ́ kó ronú nípa ewu tó ṣeé ṣe kó wáyé. Àmọ́, Jèhófà lóye ọ̀rọ̀ náà kedere, torí náà ó bá wọn dá sí i. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run wá sọ fún Ábúráhámù pé: ‘Má ṣe jẹ́ kí ohun tí Sérà ń sọ fún ọ nípa ọmọ náà àti ẹrúbìnrin rẹ bà ọ́ nínú jẹ́. Fetí sí ohun tó sọ, torí látọ̀dọ̀ Ísákì ni ọmọ rẹ yóò ti wá.’” Jèhófà ṣèlérí fún Ábúráhámù pé òun máa bojú tó Hágárì àti ọmọ rẹ̀. Ábúráhámù tó jẹ́ olóòótọ́ sì gbà.—Jẹ́nẹ́sísì 21:11-14.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
wp17.3 12, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé
“O Jẹ́ Obìnrin Kan Tí Ó Lẹ́wà ní Ìrísí”
Ọbàkan Ábúráhámù ni Sérà. Térà ló bí àwọn méjèèjì, àmọ́ wọn kì í ṣọmọ ìyá kan náà. (Jẹ́nẹ́sísì 20:12) Irú ìgbéyàwó yìí kò bẹ́tọ̀ọ́ mu lóde òní, àmọ́ ó yẹ ká rántí pé nǹkan ò rí bó ṣe rí báyìí nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Ìdí ni pé àwọn èèyàn ṣì ní ìlera tó jí pépé, irú èyí tí Ádámù àti Éfà gbádùn àmọ́ tí wọ́n gbé sọnù. Fún àwọn èèyàn tó ní ìlera tó jí pépé, ìgbéyàwó láàárín ìbátan kò lè fa ìṣòro àìlera fáwọn ọmọ wọn. Àmọ́ ní nǹkan bí irínwó [400] ọdún lẹ́yìn náà, ẹ̀mí àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í kúrú bíi tiwa lóde òní. Torí náà, òfin tí Ọlọ́run fún Mósè nígbà yẹn kò fàyè gba ìbálòpọ̀ láàárín ìbátan.—Léfítíkù 18:6.
w89 7/1 20 ¶9
Ábúráhámù—Àpẹẹrẹ Àtàtà Fáwọn Tó Fẹ́ Dọ̀rẹ́ Ọlọ́run
9 Ábúrámù tún fi hàn pé òun nígbàgbọ́. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Ó sì mọ pẹpẹ kan síbẹ̀ fún Jèhófà.” (Jẹ́nẹ́sísì 12:7) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ó fi ẹran rúbọ níbẹ̀, torí pé ọ̀rọ̀ Hébérù tá a tú sí “pẹpẹ” túmọ̀ sí “ibi ìrúbọ.” Nígbà tó yá, Ábúrámù tún mọ pẹpẹ sáwọn ibòmíì nílẹ̀ náà, èyí sì fi hàn pé ó nígbàgbọ́. Láfikún sí i, ó “bẹ̀rẹ̀ sí í pe orúkọ Jèhófà.” (Jẹ́nẹ́sísì 12:8; 13:18; 21:33) Ọ̀rọ̀ Hébérù náà “pe orúkọ” tún lè túmọ̀ sí “polongo (kéde) orúkọ.” Ó ṣeé ṣe kí ìdílé Ábúrámù àtàwọn ọmọ Kénáánì máa gbọ́ bó ṣe ń fìtara kéde orúkọ Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 14:22-24) Bákan náà lónìí, gbogbo àwọn tó bá fẹ́ dọ̀rẹ́ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ máa fìgbàgbọ́ pe orúkọ Jèhófà. Lára ohun tó yẹ ká ṣe ni pé ká máa wàásù fáwọn èèyàn, ‘ká máa rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run nígbà gbogbo, ìyẹn èso ètè wa tó ń kéde orúkọ rẹ̀ ní gbangba.’—Hébérù 13:15; Róòmù 10:10.
Bíbélì Kíkà