ORÍ KẸRIN
“Ibi Tí O Bá Lọ Ni Èmi Yóò Lọ”
1, 2. (a) Báwo ni ìrìn àjò Rúùtù àti Náómì ṣe rí? Torí kí ni àwọn méjèèjì ṣe ń ṣọ̀fọ̀? (b) Báwo ni ìrìn àjò Rúùtù àti Náómì ṣe yàtọ̀ síra?
RÚÙTÙ àti Náómì jọ ń rìn lọ lórí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ gíga Móábù, tí ẹ̀fúùfù ti ń fẹ́ gan-an. Àwọn méjèèjì ń dá lọ láàárín pápá gbalasa náà. Bí wọ́n ṣe ń bá ìrìn àjò náà lọ, ilẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣú. Rúùtù bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa bí òun àti ìyá ọkọ rẹ̀ á ṣe rí ibi tí wọ́n máa sùn mọ́jú. Ó fẹ́ràn Náómì gan-an ni, ó sì máa sa gbogbo ipá rẹ̀ láti tọ́jú rẹ̀.
2 Àwọn méjèèjì ni wọ́n ń ṣọ̀fọ̀. Ọjọ́ pẹ́ tí Náómì ti di opó. Àmọ́, ó tún ń ṣọ̀fọ̀ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ méjèèjì tí wọ́n kú lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìyẹn Kílíónì àti Málónì. Rúùtù pàápàá ń ṣọ̀fọ̀, torí pé ọkọ rẹ̀ ni Málónì tó kú. Òun àti Náómì wá jọ ń lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Àmọ́, lọ́nà kan ṣá, ìrìn àjò wọn yàtọ̀ síra. Ilé ni Náómì ń pa dà sí ní tiẹ̀. Àmọ́ ní ti Rúùtù, ibi tí kò dé rí ni wọ́n jọ ń lọ. Ó tún ń fi ẹbí, ọ̀rẹ́, ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀ àti gbogbo àṣà ibẹ̀, títí kan àwọn òrìṣà wọn sílẹ̀ lọ.—Ka Rúùtù 1:3-6.
3. Tá a bá fẹ́ ní ìgbàgbọ́ bíi ti Rúùtù, àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká wá ìdáhùn sí?
3 Kí ló mú kí ọ̀dọ́bìnrin yìí gbà láti fi ilé àti ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀? Báwo ni Rúùtù á ṣe máa gbọ́ bùkátà ara rẹ̀, báwo lá sì ṣe máa tọ́jú Náómì? Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí á jẹ́ ká rí ọ̀pọ̀ nǹkan kọ́ tó máa jẹ́ ká ní ìgbàgbọ́ bíi ti Rúùtù, ọmọ ilẹ̀ Móábù. (Tún wo àpótí náà, “Ìwé Kékeré Kan Tó Ṣàrà Ọ̀tọ̀.”) Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun tó fà á tí Náómì àti Rúùtù fi ń rin ìrìn àjò tó jìn lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù.
Ọkùnrin Mẹ́ta Kú Nínú Ìdílé Kan
4, 5. (a) Kí nìdí tí ìdílé Náómì fi kó lọ sí ilẹ̀ Móábù? (b) Àwọn ìṣòro wo ni Náómì dojú kọ ní ilẹ̀ Móábù?
4 Ilẹ̀ Móábù, ìyẹn orílẹ̀-èdè kékeré kan tó wà ní ìlà oòrùn ibi tí Òkun Òkú wà, ni Rúùtù gbé dàgbà. Àwọn ibi gíga tó tẹ́jú pẹrẹsẹ pọ̀ ní orílẹ̀-èdè kékeré náà. Àwọn igi ńláńlá ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ níbẹ̀, ó sì tún ní àwọn ibi tó jẹ́ àfonífojì. Kódà nígbà tí ìyàn mú gan-an ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, “àwọn pápá Móábù” jẹ́ ilẹ̀ tí nǹkan ọ̀gbìn ti máa ń ṣe dáadáa. Ìyẹn gan-an ló jẹ́ kí ìdílé Náómì kó lọ sí ilẹ̀ Móábù. Ibẹ̀ ni Rúùtù sì ti kọ́kọ́ pàdé Málónì àti ìdílé rẹ̀.—Rúùtù 1:1.
5 Ìyàn tó mú ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì ló mú kí Élímélékì kó Náómì aya rẹ̀ àti àwọn ọmọkùnrin wọn méjèèjì kúrò ní ìlú ìbílẹ̀ wọn láti lọ máa gbé gẹ́gẹ́ bí àjèjì ní ilẹ̀ Móábù. Èyí ti ní láti dán ìgbàgbọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn wò torí pé gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ísírẹ́lì, ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n máa pa dà lọ jọ́sìn déédéé ní ibi mímọ́ tí Jèhófà ti yàn fún wọn. (Diu. 16:16, 17) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn, Náómì ò jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ yẹ̀. Ṣùgbọ́n, inú rẹ̀ bà jẹ́ gan-an nígbà tí ọkọ rẹ̀ kú.—Rúùtù 1:2, 3.
6, 7. (a) Kí nìdí tó fi ṣeé ṣe kí Náómì máa kọminú nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ fẹ́ àwọn obìnrin Móábù? (b) Kí nìdí tá a fi lè gbóríyìn fún Náómì torí ọwọ́ tó fi mú Rúùtù àti Ópà?
6 Nígbà tó ṣe, àwọn ọmọkùnrin Náómì méjèèjì fẹ́ àwọn ọmọbìnrin Móábù, ó ṣeé ṣe kí ìyẹn náà bà á nínú jẹ́. (Rúùtù 1:4) Náómì mọ̀ pé ńṣe ni Ábúráhámù tó jẹ́ baba ńlá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sapá gidigidi láti rí i pé àárín àwọn èèyàn rẹ̀ tó jẹ́ olùjọsìn Jèhófà ni wọ́n ti lọ fẹ́ ìyàwó fún Ísákì ọmọ rẹ̀. (Jẹ́n. 24:3, 4) Nígbà tó yá, Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òfin nípasẹ̀ Mósè. Ó kìlọ̀ fún wọn nínú Òfin náà pé àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn kò gbọ́dọ̀ fẹ́ àwọn àjèjì torí wọ́n lè mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bọ̀rìṣà.—Diu. 7:3, 4.
7 Síbẹ̀, àwọn obìnrin Móábù ni Málónì àti Kílíónì fẹ́. Bí ohun tí wọ́n ṣe yẹn bá tiẹ̀ kọ Náómì lóminú tàbí tí kò tẹ́ ẹ lọ́rùn, ó dájú pé ó ṣì fi inú rere àti ìfẹ́ bá Rúùtù àti Ópà lò. Ó ṣeé ṣe kó ronú pé lọ́jọ́ kan àwọn náà á máa sin Jèhófà bíi ti òun. Ohun tó dájú ni pé Rúùtù àti Ópà fẹ́ràn Náómì gidigidi. Bí wọ́n ṣe mọwọ́ Náómì yìí ràn wọ́n lọ́wọ́ gan-an nígbà tí ọ̀fọ̀ ńlá ṣẹ̀ wọ́n. Àwọn méjèèjì ò tíì bímọ tí wọ́n fi di opó ọ̀sán gangan.—Rúùtù 1:5.
8. Kí ló mú kí Rúùtù fẹ́ láti sin Jèhófà?
8 Ǹjẹ́ ẹ̀sìn tí Rúùtù ń ṣe tẹ́lẹ̀ mú kó ronú pé ó lè rí ìtùnú gbà lẹ́yìn ikú ọkọ rẹ̀? Kò jọ bẹ́ẹ̀ rárá. Àwọn ọmọ ilẹ̀ Móábù máa ń bọ ọ̀pọ̀ òrìṣà, Kémóṣì sì ni olórí òrìṣà wọn. (Núm. 21:29) Nínú ẹ̀sìn tí àwọn èèyàn ń ṣe nígbà yẹn, ó wọ́pọ̀ kí wọ́n máa hùwà òǹrorò kí wọ́n sì máa ṣe àwọn nǹkan tó ń bani lẹ́rù, títí kan fífi àwọn ọmọdé rúbọ. Ó jọ pé bó ṣe rí nínú ẹ̀sìn àwọn ọmọ ilẹ̀ Móábù náà nìyẹn. Ó dájú pé Rúùtù rí ọ̀pọ̀ nǹkan kọ́ nípa ìfẹ́ àti àánú Jèhófà, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, lọ́dọ̀ Málónì tàbí Náómì. Àwọn ohun tó kọ́ sì ti ní láti mú kó rí i pé Jèhófà yàtọ̀ sí Kémóṣì tó jẹ́ òǹrorò. Ìfẹ́ ni Jèhófà fi ń ṣàkóso àwọn èèyàn rẹ̀, kì í kó ìpayà bá wọn. (Ka Diutarónómì 6:5.) Lẹ́yìn ikú ọkọ Rúùtù, ó ṣeé ṣe kó túbọ̀ fà mọ́ ìyá ọkọ rẹ̀, kó sì máa tẹ́tí sí obìnrin àgbàlagbà náà bó ṣe ń sọ fún un nípa Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè àti àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ àti bó ṣe ń fi ìfẹ́ àti àánú bá àwọn èèyàn rẹ̀ lò.
9-11. (a) Kí ni Náómì, Rúùtù àti Ópà pinnu láti ṣe? (b) Kí la lè rí kọ́ látinú àjálù tó dé bá Náómì, Rúùtù àti Ópà?
9 Náómì máa ń tẹ́tí léko kó lè mọ bí nǹkan ṣe ń lọ sí ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Lọ́jọ́ kan, ó jọ pé ọ̀kan lára àwọn oníṣòwò tó ń ná ibẹ̀ sọ fún un pé Jèhófà ti ṣíjú àánú wo àwọn èèyàn rẹ̀, ìyàn ò sì mú mọ́ ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Oúnjẹ tún ti pọ̀ yanturu ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ní ìbámu pẹ̀lú orúkọ ìlú náà, tó túmọ̀ sí “Ilé Búrẹ́dì.” Nítorí èyí, Náómì pinnu láti pa dà sí ìlú rẹ̀.—Rúùtù 1:6.
10 Kí ni Rúùtù àti Ópà máa ṣe báyìí? (Rúùtù 1:7) Gbogbo ohun tí àwọn méjèèjì àti Náómì ti jọ là kọjá ti mú kí wọ́n túbọ̀ mọwọ́ ara wọn. Ó jọ pé ohun tó tún mú kí Rúùtù túbọ̀ fà mọ́ Náómì ni pé Náómì jẹ́ onínúure, ìgbàgbọ́ tó ní nínú Jèhófà kò sì yẹ̀. Àwọn obìnrin opó mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí wá gbéra, wọ́n forí lé ilẹ̀ Júdà.
11 Ìtàn Rúùtù yìí máa ń rán wa létí pé àti ẹni rere àti ẹni burúkú ni àjálù máa ń dé bá. (Oníw. 9:2, 11) Ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé bí ìṣòro tí kò ṣeé pa mọ́ra bá dé bá wa, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká wá ìtùnú lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíì. Pàápàá jù lọ, àwọn tó sá di Jèhófà, Ọlọ́run tí Náómì sìn.—Òwe 17:17.
Rúùtù Ní Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀
12, 13. Dípò tí Náómì ì bá fi jẹ́ kí Rúùtù àti Ópà tẹ̀ lé òun, kí nìdí tó fi sọ pé kí wọ́n pa dà sí ilé wọn? Kí ni àwọn ọmọbìnrin náà ṣe nígbà tó kọ́kọ́ sọ fún wọn?
12 Bí àwọn opó mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí ṣe túbọ̀ ń rìn jìnnà, Náómì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn nípa nǹkan kan. Ó ń ronú nípa àwọn ọmọbìnrin méjèèjì tí wọ́n jọ ń lọ àti bí wọ́n ṣe fi ìfẹ́ hàn sí òun àti àwọn ọmọkùnrin òun. Kò fẹ́ kó jẹ́ pé òun lòun máa dá kún ìṣòro wọn. Ìyẹn ló fi ń ṣàníyàn pé tí wọ́n bá fi ìlú wọn sílẹ̀ tí wọ́n sì tẹ̀ lé òun lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, àǹfààní wo ni òun lè ṣe fún wọn táwọn bá débẹ̀?
13 Níkẹyìn, Náómì sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ, ẹ padà, olúkúlùkù sí ilé ìyá rẹ̀. Kí Jèhófà ṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ṣe é sí àwọn ọkùnrin tí ó ti kú àti sí èmi.” Ó tún gbàdúrà pé Jèhófà á fún wọn ní ọkọ rere àti ilé aláyọ̀. Ìtàn náà ń bá a lọ pé: “Ó sì fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì ń sunkún.” Abájọ tí ọkàn Rúùtù àti Ópà fi fà mọ́ obìnrin onínúure tí kò mọ tara rẹ̀ nìkan yìí. Àwọn méjèèjì ò fẹ́ fi í sílẹ̀. Ńṣe ni wọ́n ń sọ fún un pé: “Rárá, ṣùgbọ́n àwa yóò bá ọ padà sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ.”—Rúùtù 1:8-10.
14, 15. (a) Àwọn wo ni Ópà pa dà lọ bá? (b) Kí ni Náómì sọ nígbà tó ń rọ Rúùtù pé kó pa dà lẹ́yìn òun?
14 Ṣùgbọ́n Náómì ò yéé sọ fún Rúùtù àti Ópà pé kí wọ́n pa dà sílé. Nígbà tó yá ó sọ ojú abẹ níkòó. Ó ní kò sí ohun tí òun lè ṣe fún wọn táwọn bá dé Ísírẹ́lì. Ó ṣàlàyé pé kò sí ọkọ tó máa gbọ́ bùkátà òun, òun ò sì ní ọmọ tí wọ́n máa fẹ́. Ó jẹ́ kó yé wọn pé òun ò lè lọ́kọ mọ́ débi tí òun á bímọ. Ó ní ẹ̀dùn ọkàn ló jẹ́ fún òun pé òun kò lágbára láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Ópà gbà pé òótọ́ ọ̀rọ̀ ni Náómì sọ. Ó ṣe tán, òun ṣì ní ẹbí ní Móábù, ìyá òun wà níbẹ̀, ilé sì tún wà tí òun máa gbé. Ó wá gbà pé á dáa kí òun yáa dúró sí ilẹ̀ Móábù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú Ópà bà jẹ́ gan-an, ó fẹnu ko Náómì lẹ́nu láti fi kí i pé ó dìgbóṣe. Lẹ́yìn náà, ó yí pa dà, ó sì bá tirẹ̀ lọ.—Rúùtù 1:11-14.
15 Rúùtù ńkọ́? Ọ̀rọ̀ tí Náómì sọ kan òun náà. Síbẹ̀, Bíbélì sọ pé: “Ní ti Rúùtù, ó fà mọ́ ọn.” Bóyá Náómì ti ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ kó tó wá rí i pé Rúùtù ṣì ń bọ̀ lẹ́yìn òun. Ló bá tún tẹ̀ ẹ́ mọ́ ọn létí pé: “Wò ó! aya arákùnrin ọkọ rẹ tí ó ti di opó ti padà sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ̀ àti àwọn ọlọ́run rẹ̀. Bá aya arákùnrin ọkọ rẹ tí ó ti di opó padà.” (Rúùtù 1:15) Ohun tí Náómì sọ yìí jẹ́ kí àwọn tó bá ń ka ìtàn yìí lóye kókó pàtàkì kan. Kókó náà ni pé kì í wúlẹ̀ ṣe pé Ópà pa dà sọ́dọ̀ àwọn èèyàn rẹ̀ nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún pa dà sọ́dọ̀ “àwọn ọlọ́run rẹ̀” pẹ̀lú. Ó tẹ́ ẹ lọ́rùn láti máa bọ òrìṣà Kémóṣì àti àwọn òòṣà míì. Ṣé ohun tí Rúùtù náà fẹ́ ṣe nìyẹn?
16-18. (a) Báwo ni Rúùtù ṣe fi hàn pé òun ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀? (b) Kí ni ìtàn Rúùtù fi kọ́ wa nípa ìfẹ́ tí kì í yẹ̀? (Tún wo àwòrán àwọn obìnrin méjèèjì.)
16 Bí Rúùtù ṣe ń bá Náómì sọ̀rọ̀ lójú ọ̀nà tó dá páropáro yẹn, kò ṣiyè méjì rárá nípa ohun tó fẹ́ ṣe. Ó nífẹ̀ẹ́ Náómì dénú, ó sì tún nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tí Náómì ń sìn. Torí náà, Rúùtù sọ fún Náómì pé: “Má rọ̀ mí láti pa ọ́ tì, láti padà lẹ́yìn rẹ; nítorí ibi tí o bá lọ ni èmi yóò lọ, ibi tí o bá sì sùn mọ́jú ni èmi yóò sùn mọ́jú. Àwọn ènìyàn rẹ ni yóò jẹ́ ènìyàn mi, Ọlọ́run rẹ ni yóò sì jẹ́ Ọlọ́run mi. Ibi tí o bá kú sí ni èmi yóò kú sí, ibẹ̀ sì ni ibi tí a ó sin mí sí. Kí Jèhófà ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi, kí ó sì fi kún un, bí ohunkóhun yàtọ̀ sí ikú bá ya èmi àti ìwọ.”—Rúùtù 1:16, 17.
17 Mánigbàgbé ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Rúùtù sọ yìí. Kódà, ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] ọdún lẹ́yìn tí Rúùtù ti kú, àwọn èèyàn ṣì ń rántí ohun tó sọ. Àwọn ohun tó sọ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé ó ní ànímọ́ kan tó fani mọ́ra gan-an, ìyẹn ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀. Okùn ìfẹ́ yẹn yi débi pé Rúùtù ṣe tán láti bá Náómì dé ibikíbi tó bá ń lọ. Ikú nìkan ló lè yà wọ́n. Àwọn èèyàn Náómì ni yóò di èèyàn Rúùtù torí ó ṣe tán láti fi ilé àti ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀, tó fi mọ́ àwọn òrìṣà ilẹ̀ Móábù. Rúùtù ò dà bí Ópà, torí tọkàntọkàn ló fi sọ pé Jèhófà tó jẹ́ Ọlọ́run Náómì ni òun fẹ́ kó jẹ́ Ọlọ́run òun.a
18 Torí náà, àwọn méjèèjì ń bá ìrìn àjò wọn lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Ọ̀nà náà jìn gan-an ni. Ìwádìí kan tiẹ̀ fi hàn pé ó lè gbà tó ọ̀sẹ̀ kan kí wọ́n tó débẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn méjèèjì ló ń ṣọ̀fọ̀, ó dájú pé wọ́n á máa tu ara wọn nínú bí wọ́n ṣe jọ ń lọ.
19. Ọ̀nà wo lo rò pé a lè gbà fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn bíi ti Rúùtù nínú ìdílé wa, láàárín àwọn ọ̀rẹ́ wa àti nínú ìjọ?
19 Ohun tó ń fa ìbànújẹ́ pọ̀ jọjọ nínú ayé yìí. Bíbélì pe àkókò tá a wà yìí ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” Torí náà, onírúurú àjálù ló ń dé bá àwa èèyàn, ọ̀pọ̀ nǹkan ló sì ń mú ká banú jẹ́. (2 Tím. 3:1) Ìyẹn ló fi ṣe pàtàkì gan-an nísinsìnyí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ pé ká ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ bíi ti Rúùtù. Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ máa ń mú ká dúró ti ẹni tá a nífẹ̀ẹ́ sí. Ó sì máa ń mú ká ṣe ohun tó lè mára tu àwọn èèyàn nínú ayé tó kún fún ìbànújẹ́ yìí. Kòṣeémánìí ni ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ jẹ́ nínú ìgbéyàwó, nínú ìdílé, láàárín ẹbí, láàárín àwọn ọ̀rẹ́ àti nínú ìjọ. (Ka 1 Jòhánù 4:7, 8, 20.) Bá a ṣe lè máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ títayọ tí Rúùtù fi lélẹ̀ ni pé kí àwa náà ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.
Bí Nǹkan Ṣe Rí fún Rúùtù àti Náómì ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù
20-22. (a) Báwo ni Náómì ṣe rí nígbà tó dé láti ilẹ̀ Móábù? (b) Ta ni Náómì rò pé ó fa àwọn àjálù tó dé bá òun? (Tún wo Jákọ́bù 1:13.)
20 Ọ̀tọ̀ ni kéèyàn máa fi ẹnu lásán sọ pé òun ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, ọ̀tọ̀ sì ni kó hàn nínú ohun téèyàn bá ń ṣe pé òótọ́ ló ní irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀. Àǹfààní nìyí fún Rúùtù láti fi hàn pé ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ ni òun ní sí Náómì àti sí Jèhófà, Ọlọ́run tí òun yàn láti máa sìn.
21 Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Náómì àti Rúùtù dé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, abúlé kan tó wà ní nǹkan bíi kìlómítà mẹ́wàá ní apá gúúsù Jerúsálẹ́mù. Ó jọ pé àwọn tó wà ní ìlú kékeré náà ti mọ ìdílé Náómì dáadáa tẹ́lẹ̀, torí kíá ni ìròyìn ti tàn kálẹ̀ pé Náómì ti pa dà dé. Bí àwọn obìnrin ìlú náà ṣe ń rí i ni wọ́n ń sọ pé, “Ṣé Náómì nìyí?” Ó dájú pé àkókò tí Náómì fi gbé ní ilẹ̀ Móábù ti mú kó yí pa dà gan-an. Ó hàn lójú rẹ̀ pé ó ti fara da ìnira àti ìbànújẹ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún, ìrísí rẹ̀ sì tún yàtọ̀.—Rúùtù 1:19.
22 Náómì sọ bí àjálù tó dé bá a ṣe pọ̀ tó fún àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ obìnrin àti àwọn aládùúgbò rẹ̀ àtijọ́ yẹn. Kódà kò tiẹ̀ fẹ́ káwọn èèyàn máa pe òun ní Náómì tó túmọ̀ sí “Adùn,” mọ́. Márà, tó túmọ̀ sí “Ìkorò,” ló ní kí wọ́n máa pe òun. Ó má ṣe o! Ńṣe ni ọ̀rọ̀ Náómì dà bíi ti Jóòbù tó ti gbé láyé ṣáájú rẹ̀. Òun náà rò pé Jèhófà Ọlọ́run ló fa àwọn àjálù tó dé bá òun.—Rúùtù 1:20, 21; Jóòbù 2:10; 13:24-26.
23. Kí ni Rúùtù bẹ̀rẹ̀ sí í rò? Ètò wo ni Jèhófà ṣe fún àwọn aláìní nínú Òfin Mósè? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
23 Bí àwọn méjèèjì ṣe bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé wọn tuntun ní ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, Rúùtù bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ọ̀nà tó dára jù lọ tí òun lè gbà máa gbọ́ bùkátà ara òun kí òun sì máa tọ́jú Náómì. Ó gbọ́ nípa ètò kan tí Jèhófà ṣe nínú Òfin tó fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ èèyàn rẹ̀. Ètò yẹn fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn tálákà. Ọlọ́run ní kí wọ́n fàyè gba àwọn tálákà láti lọ sí oko nígbà ìkórè. Kí wọ́n máa pèéṣẹ́ lẹ́yìn àwọn tó ń kórè, ìyẹn ni pé kí wọ́n máa ṣa àwọn irè oko tó bá ṣẹ́ kù sílẹ̀. Wọ́n sì tún lè máa kárúgbìn eteetí oko.b—Léf. 19:9, 10; Diu. 24:19-21.
24, 25. Kí ni Rúùtù ṣe nígbà tó ṣàdédé kan oko Bóásì? Kí lo lè sọ nípa iṣẹ́ pípèéṣẹ́?
24 Ní ìgbà ìkórè ọkà báálì, èyí tó máa bọ́ sí oṣù April lóde òní, Rúùtù jáde lọ sí pápá bóyá ó máa rí ẹni táá jẹ́ kó pèéṣẹ́ nínú oko rẹ̀. Ó ṣàdédé kan oko ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Bóásì. Ọlọ́rọ̀ ni Bóásì, ó ní ilẹ̀ tó pọ̀, ó sì tún jẹ́ mọ̀lẹ́bí Élímélékì, ìyẹn ọkọ Náómì tó ti kú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin fàyè gba Rúùtù láti pèéṣẹ́, síbẹ̀ kò kàn wọnú oko olóko. Ó kọ́kọ́ tọrọ àyè lọ́wọ́ ọ̀dọ́kùnrin tó jẹ́ ọ̀gá àwọn olùkórè. Ọ̀dọ́kùnrin náà gbà fún un, Rúùtù sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lójú ẹsẹ̀.—Rúùtù 1:22–2:3, 7.
25 Fojú inú wo Rúùtù bó ṣe ń tẹ̀ lé àwọn olùkórè yẹn lẹ́yìn. Bí wọ́n ṣe ń fi dòjé wọn gé ọkà báálì, bẹ́ẹ̀ ni Rúùtù ń ṣa èyí tó bá já bọ́ tàbí èyí tí wọ́n fi sílẹ̀ fún un. Lẹ́yìn náà, ó dì wọ́n jọ, ó sì kó wọn lọ síbi tó ti máa pa àwọn ọkà náà tó bá yá. Iṣẹ́ tó gba sùúrù ni, ó sì máa ń tánni lókun, àti pé bí ọ̀sán bá ṣe ń pọ́n sí i ló máa ń nira sí i. Síbẹ̀, Rúùtù ń bá iṣẹ́ rẹ̀ lọ, àfi tó bá dáwọ́ dúró láti nu òógùn ojú rẹ̀ tàbí tó bá ṣíwọ́ láti wá nǹkan díẹ̀ panu “nínú ilé,” èyí tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ahéré kan tí wọ́n kọ́ fún àwọn òṣìṣẹ́.
26, 27. Irú èèyàn wo ni Bóásì? Irú ọwọ́ wo ló fi mú Rúùtù?
26 Rúùtù lè má ronú pé ẹnikẹ́ni máa kíyè sí òun, àmọ́ ẹnì kan kíyè sí i. Nígbà tí Bóásì rí i, ó béèrè lọ́wọ́ ọ̀gá àwọn olùkórè pé: “Ta ni ọ̀dọ́bìnrin yìí?” Bóásì ní ìgbàgbọ́ tó ta yọ nínú Jèhófà, ìyẹn sì hàn nínú bó ṣe máa ń kí àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ òòjọ́ ni àwọn míì wá ṣe lọ́dọ̀ rẹ̀ tàbí kó tiẹ̀ jẹ́ pé àjèjì ni wọ́n, tó bá ń kí wọn, á ní: “Kí Jèhófà wà pẹ̀lú yín.” Àwọn náà á sì fèsì pé: “Kí Jèhófà bù kún ọ.” Ojú tí baba fi ń wo ọmọ ni ọkùnrin àgbàlagbà tó fẹ́ràn Jèhófà yìí fi wo Rúùtù.—Rúùtù 2:4-7.
27 Bóásì pe Rúùtù ní “ọmọbìnrin mi,” ó sì sọ fún un pé oko òun ni kó ti wá máa pèéṣẹ́. Ó ní kó má jìnnà sí àwọn ọ̀dọ́bìnrin ilé òun kí èyíkéyìí lára àwọn ọkùnrin tó jẹ́ òṣìṣẹ́ má bàa yọ ọ́ lẹ́nu. Ó tún máa ń rí i dájú pé Rúùtù rí oúnjẹ ọ̀sán jẹ. (Ka Rúùtù 2:8, 9, 14.) Àmọ́ ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó máa ń yin Rúùtù, ó sì máa ń gbà á níyànjú. Lọ́nà wo?
28, 29. (a) Kí ni àwọn èèyàn ń sọ nípa Rúùtù? (b) Báwo ni ìwọ náà ṣe lè sá di Jèhófà bíi ti Rúùtù?
28 Nígbà tí Rúùtù bi Bóásì léèrè ìdí tó fi ṣe àjèjì bíi ti òun ní oore ńlá bẹ́ẹ̀, Bóásì dá a lóhùn pé òun ti gbọ́ nípa gbogbo ohun tó ṣe fún Náómì, ìyá ọkọ rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí Náómì ti yin Rúùtù tó kà sí ẹni ọ̀wọ́n yìí létí àwọn obìnrin ìlú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, kí ìyẹn sì ti dé etígbọ̀ọ́ Bóásì. Bóásì tún mọ̀ pé Rúùtù ti di olùjọsìn Jèhófà, torí ó sọ pé: “Kí Jèhófà san ọ́ lẹ́san fún bí o ṣe hùwà, kí owó ọ̀yà pípé sì wà fún ọ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, lábẹ́ ìyẹ́ apá ẹni tí ìwọ wá láti wá ìsádi.”—Rúùtù 2:12.
29 Rúùtù ti ní láti rí ìṣírí tó pọ̀ gbà látinú ọ̀rọ̀ tí Bóásì sọ yìí! Òótọ́ sì ni pé Rúùtù ti yàn láti wá sábẹ́ ìyẹ́ apá Jèhófà Ọlọ́run láti fi ṣe ibi ìsádi rẹ̀, bí òròmọdìyẹ ṣe máa ń wà láìséwu lábẹ́ ìyẹ́ apá ìyá rẹ̀. Rúùtù dúpẹ́ lọ́wọ́ Bóásì torí pé ọ̀rọ̀ tó bá a sọ fi í lọ́kàn balẹ̀, ó sì ń bá iṣẹ́ rẹ̀ lọ títí di ìrọ̀lẹ́.—Rúùtù 2:13, 17.
30, 31. Kí la lè rí kọ́ lára Rúùtù nípa irú ọwọ́ tó yẹ ká fi mú iṣẹ́, bá a ṣe lè jẹ́ ẹni tó moore àti bá a ṣe lè fi hàn pé a ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀?
30 Bí Rúùtù ṣe fi iṣẹ́ kún ìgbàgbọ́ rẹ̀ yìí jẹ́ àpẹẹrẹ tó ta yọ fún gbogbo wa lóde òní. Ìdí ni pé àwọn nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ rọrùn, ètò ọ̀rọ̀ ajé sì ti dẹnu kọlẹ̀. Rúùtù ò retí pé kí àwọn míì máa bá òun gbọ́ bùkátà òun torí pé òun jẹ́ opó, torí náà ó mọrírì gbogbo oore tí wọ́n ṣe fún un. Torí pé ó nífẹ̀ẹ́ Náómì, kò tijú láti ṣe iṣẹ́ àṣekára fún àkókò gígùn kó bàa lè gbọ́ bùkátà rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ tí kò gbayì ni. Ó mọrírì ìmọ̀ràn tí wọ́n fún un nípa ibi tó dáa kó ti ṣiṣẹ́ àti bó ṣe lè ṣiṣẹ́ láàárín àwọn tí kò ní yọ ọ́ lẹ́nu. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, kò fìgbà kankan gbàgbé pé ọ̀dọ̀ Baba tó ń dáàbò bo òun, ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run, lòun ti lè rí ibi ìsádi tó dájú.
31 Bíi ti Rúùtù, ìgbàgbọ́ tiwa náà lè jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn míì, tá a bá ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, tá a jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, tí a kì í fi iṣẹ́ ṣeré, tá a sì moore. Báwo wá ni Jèhófà ṣe pèsè ohun tí Rúùtù àti Náómì nílò? Ohun tá a máa jíròrò nínú orí tó kàn nìyẹn.
a Ó yẹ ká kíyè sí i pé Rúùtù kò kàn lo orúkọ oyè náà “Ọlọ́run” bí ọ̀pọ̀ àwọn àjèjì ì bá ti ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó lo orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́ gan-an, ìyẹn Jèhófà. Ìtumọ̀ Bíbélì kan tiẹ̀ sọ pé: “Nípa báyìí, ẹni tó kọ ìwé Rúùtù jẹ́ kó ṣe kedere pé bí Rúùtù tilẹ̀ jẹ́ àjèjì, Ọlọ́run tòótọ́ ló ń sìn.”—The Interpreter’s Bible.
b Kò sí irú òfin bẹ́ẹ̀ ní ilẹ̀ Móábù tí Rúùtù ti wá, torí náà, ó máa jọ ọ́ lójú gan-an. Ní àwọn àgbègbè tó yí Ísírẹ́lì ká láyé ìgbà yẹn, ńṣe ni wọ́n máa ń fìyà jẹ àwọn opó. Ìwé ìwádìí kan sọ pé: “Tí ọkọ obìnrin kan bá ti kú, àwọn ọmọkùnrin tí opó náà bí lá máa tọ́jú rẹ̀. Tí kò bá ní ọmọkùnrin kankan, tí kò sì fẹ́ kú, ńṣe ló máa ta ara rẹ̀ sí oko ẹrú tàbí kó di aṣẹ́wó.”