Rúùtù
2 Mọ̀lẹ́bí ọkọ Náómì kan wà tó ní ọrọ̀ gan-an, Bóásì+ ni orúkọ rẹ̀, ìdílé Élímélékì ló sì ti wá.
2 Rúùtù ará Móábù sọ fún Náómì pé: “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí n lọ sí oko, kí n lè pèéṣẹ́*+ lára ṣírí ọkà lọ́dọ̀ ẹnikẹ́ni tó bá ṣojúure sí mi.” Torí náà, Náómì sọ fún un pé: “Lọ, ọmọ mi.” 3 Lẹ́yìn náà, ó lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í pèéṣẹ́ lẹ́yìn àwọn olùkórè. Láìmọ̀, ó dé oko Bóásì+ tó wá láti ìdílé Élímélékì.+ 4 Ìgbà yẹn ni Bóásì dé láti Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ó sì sọ fún àwọn olùkórè náà pé: “Kí Jèhófà wà pẹ̀lú yín.” Wọ́n sì dáhùn pé: “Kí Jèhófà bù kún ọ.”
5 Lẹ́yìn náà, Bóásì bi ọkùnrin tó ń bójú tó àwọn olùkórè pé: “Ilé ibo ni obìnrin yìí ti wá?” 6 Ọkùnrin náà dáhùn pé: “Ará Móábù+ ni, òun ló tẹ̀ lé Náómì wá láti ilẹ̀ Móábù.+ 7 Ó bi mí pé, ‘Ẹ jọ̀ọ́, ṣé mo lè pèéṣẹ́+ kí n sì kó àwọn ṣírí* ọkà tí àwọn olùkórè bá fi sílẹ̀?’ Ó sì ti ń ṣiṣẹ́ látàárọ̀, kódà ó ṣẹ̀ṣẹ̀ jókòó sí abẹ́ àtíbàbà kó lè sinmi díẹ̀ ni.”
8 Bóásì wá sọ fún Rúùtù pé: “Gbọ́, ọmọ mi. Má lọ pèéṣẹ́ nínú oko míì, má sì lọ sí ibòmíì, tòsí àwọn òṣìṣẹ́ mi obìnrin+ ni kí o máa wà. 9 Ibi tí wọ́n ti ń kórè ni kí o máa wò, kí o sì máa tẹ̀ lé wọn. Mo ti sọ fún àwọn ọkùnrin tó ń bá mi ṣiṣẹ́ pé wọn kò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kàn ọ́.* Tí òùngbẹ bá ń gbẹ ọ́, lọ síbi ìṣà omi, kí o sì mu nínú omi tí àwọn òṣìṣẹ́ mi pọn.”
10 Torí náà, Rúùtù kúnlẹ̀, ó sì tẹrí ba mọ́lẹ̀, ó wá sọ fún un pé: “Kí nìdí tí o fi ṣojúure sí mi, kí sì nìdí tí o fi kíyè sí mi, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àjèjì+ ni mí?” 11 Bóásì dá a lóhùn pé: “Gbogbo ohun tí o ṣe fún ìyá ọkọ rẹ lẹ́yìn ikú ọkọ rẹ ni wọ́n ti ròyìn fún mi àti bí o ṣe fi bàbá àti ìyá rẹ àti ìlú ìbílẹ̀ rẹ sílẹ̀, tí o sì wá sọ́dọ̀ àwọn èèyàn tí ìwọ kò mọ̀ rí.+ 12 Kí Jèhófà san ẹ̀san ohun tí o ṣe fún ọ,+ kí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ẹni tí o wá ààbò wá sábẹ́ ìyẹ́ apá rẹ̀+ sì fún ọ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ èrè.” 13 Ó fèsì pé: “Jọ̀wọ́ olúwa mi, jẹ́ kí n rí ojúure rẹ torí o ti tù mí nínú, ọ̀rọ̀ rẹ sì ti fi ìránṣẹ́ rẹ lọ́kàn balẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò sí lára àwọn òṣìṣẹ́ rẹ.”
14 Nígbà tí àkókò oúnjẹ tó, Bóásì sọ fún un pé: “Máa bọ̀ níbí, wá jẹ búrẹ́dì, kí o sì ki èyí tí o bá bù bọ inú ọtí kíkan.” Torí náà, ó jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn olùkórè. Lẹ́yìn náà, Bóásì fún un ní ọkà yíyan, ó jẹ, ó yó, oúnjẹ rẹ̀ sì ṣẹ́ kù. 15 Nígbà tó dìde láti pèéṣẹ́,+ Bóásì pàṣẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ jẹ́ kó ṣà lára àwọn ṣírí* ọkà tó bọ́ sílẹ̀ pàápàá, ẹ má sì ni ín lára.+ 16 Kí ẹ sì rí i pé ẹ yọ ṣírí ọkà díẹ̀ sílẹ̀ fún un lára èyí tí ẹ ti dì, kí ẹ sì fi wọ́n sílẹ̀ kó lè ṣà wọ́n, ẹ má ṣe bá a sọ ohunkóhun láti dá a dúró.”
17 Torí náà, ó ń pèéṣẹ́ nínú oko títí di ìrọ̀lẹ́.+ Nígbà tó lu ọkà bálì tó kó jọ, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ kún òṣùwọ̀n eéfà* kan. 18 Lẹ́yìn náà, ó gbé e, ó pa dà sínú ìlú, ìyá ọkọ rẹ̀ sì rí ohun tó pèéṣẹ́. Rúùtù tún gbé oúnjẹ tó ṣẹ́ kù+ lẹ́yìn tó jẹun yó lọ́hùn-ún wá sílé, ó sì gbé e fún ìyá ọkọ rẹ̀.
19 Lẹ́yìn náà, ìyá ọkọ rẹ̀ sọ fún un pé: “Ibo lo ti pèéṣẹ́ lónìí? Ibo lo sì ti ṣiṣẹ́? Kí Ọlọ́run bù kún ẹni tó ṣojúure sí ọ.”+ Torí náà, ó sọ ọ̀dọ̀ ẹni tó ti ṣiṣẹ́ fún ìyá ọkọ rẹ̀, ó ní: “Bóásì ni orúkọ ẹni tí mo ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ rẹ̀ lónìí.” 20 Náómì wá sọ fún ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé: “Ìbùkún ni fún un látọ̀dọ̀ Jèhófà, ẹni tó ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ sí àwọn alààyè àti òkú.”+ Náómì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Mọ̀lẹ́bí wa ni ọkùnrin náà.+ Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùtúnrà* wa.”+ 21 Nígbà náà ni Rúùtù ará Móábù sọ pé: “Ó tún sọ fún mi pé, ‘Ọ̀dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ mi ni kí o wà títí wọ́n á fi parí gbogbo ìkórè oko mi.’”+ 22 Náómì sọ fún Rúùtù ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé: “Ọmọ mi, ó dáa kí o wà lọ́dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ obìnrin ju kí o lọ sí oko ẹlòmíì tí wọ́n á ti máa dà ọ́ láàmú.”
23 Torí náà, ó wà lọ́dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ Bóásì, ó ń pèéṣẹ́ títí ìkórè ọkà bálì+ àti àlìkámà* fi parí. Ọ̀dọ̀ ìyá ọkọ rẹ̀ ló sì ń gbé.+