Báwo La Ṣe Lè Fi Hàn Pé A Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
“Àwa nífẹ̀ẹ́, nítorí òun ni ó kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.”—1 JÒH. 4:19.
1, 2. Gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Jòhánù ṣe sọ, ọ̀nà wo la lè gbà fìfẹ́ hàn sí Ọlọ́run?
Ọ̀PỌ̀ èèyàn gbà pé ọ̀nà tó dáa jù tí bàbá kan lè gbà tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ ni pé kó fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ fun wọn. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Àwa nífẹ̀ẹ́, nítorí [Ọlọ́run] ni ó kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.” (1 Jòh. 4:19) Torí náà, ó ṣe kedere pé Jèhófà ti fi àpẹẹrẹ tó ta yọ lélẹ̀ nípa bó ṣe yẹ kí bàbá nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀, èyí á sì mú kí àwa náà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.
2 Báwo ni Jèhófà ṣe “kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa”? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọlọ́run dámọ̀ràn ìfẹ́ tirẹ̀ fún wa ní ti pé, nígbà tí àwa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.” (Róòmù 5:8) Ọlọ́run yọ̀ǹda kí Ọmọ rẹ̀ kú nítorí àwọn èèyàn tó nígbàgbọ́. Nípasẹ̀ ìrúbọ pàtàkì yìí, Jèhófà fi ohun tí ìfẹ́ tòótọ́ jẹ́ hàn. Àwa náà lè fi irú ìfẹ́ tòótọ́ yìí hàn tá a bá jẹ́ ọ̀làwọ́ tá a sì ń yááfì àwọn nǹkan torí àwọn míì. Ìwà ọ̀làwọ́ Ọlọ́run mú kó ṣeé ṣe fún wa láti tọ̀ ọ́ wá, ká jàǹfààní látinú ìfẹ́ rẹ̀, kí àwa náà sì fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.—1 Jòh. 4:10.
3, 4. Báwo la ṣe lè fi ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run hàn?
3 Ìfẹ́ ni ànímọ́ Jèhófà tó ta yọ jù lọ, torí náà a lè lóye ìdí tí Jésù fi sọ fún ẹnì kan tó ń wádìí ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀ pé òfin àkọ́kọ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni pé: “Kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò-inú rẹ àti pẹ̀lú gbogbo okun rẹ.” (Máàkù 12:30) Ohun tí Jésù sọ yìí mú kó yé wa pé inú ọkàn ni ìfẹ́ fún Ọlọ́run ti ń bẹ̀rẹ̀. Jèhófà ò nífẹ̀ẹ́ sí ẹni tí kò bá fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sin òun. Àmọ́, a kíyè sí i pé ìfẹ́ fún Ọlọ́run tún wé mọ́ gbogbo ọkàn, èrò inú àti okun wa. Èyí túmọ̀ sí pé ojúlówó ìfẹ́ fún Ọlọ́run kì í wulẹ̀ ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán. Yàtọ̀ sí pé ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run gbọ́dọ̀ ti ọkàn wa wá, a tún gbọ́dọ̀ fi hàn pé a fẹ́ràn rẹ̀ nínú èrò àti ìṣe wa. Ohun tí wòlíì Míkà sì sọ pé Jèhófà fẹ́ ká ṣe gan-an nìyẹn.—Ka Míkà 6:8.
4 Báwo la ṣe lè fi hàn pé a fẹ́ràn Baba wa ọ̀run ní tòótọ́? A gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ láìkù síbì kan. Bí Jésù ṣe sọ, a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run lọ́rọ̀, lérò àti nínú gbogbo nǹkan tá a bá ń ṣe. Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, a jíròrò ọ̀nà mẹ́rin tí Jèhófà gbà fìfẹ́ tó ta yọ hàn sí àwa ọmọ rẹ̀. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká jíròrò bá a ṣe lè mú kí ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà jinlẹ̀ sí i àti bá a ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ lọ́nà tó fẹ́.
Ó YẸ KÁ MÁA DÚPẸ́ TORÍ ÀWỌN NǸKAN TÍ JÈHÓFÀ ṢE FÚN WA
5. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọyì gbogbo nǹkan tí Jèhófà ti ṣe fún wa?
5 Tí ẹnì kan bá fún ọ lẹ́bùn, kí lo máa ṣe? Ó dájú pé wàá fi hàn pé o mọrírì ẹ̀bùn náà. Yàtọ̀ síyẹn, wàá tún lo ẹ̀bùn náà lọ́nà tó fi hàn pé o kà á kún. Ọmọ ẹ̀yìn náà, Jákọ́bù sọ pé: “Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé jẹ́ láti òkè, nítorí a máa sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Baba àwọn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá, kò sì sí àyídà ìyípo òjìji lọ́dọ̀ rẹ̀.” (Ják. 1:17) Jèhófà ń fún wa ní àwọn nǹkan tá a nílò láìkùnà ká lè wà láàyè ká sì máa láyọ̀. Ǹjẹ́ kò yẹ kí ìyẹn mú kí àwa náà fẹ́ láti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀?
6. Kí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n lè máa rí ìbùkún Jèhófà gbà?
6 Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún làwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi wà lábẹ́ àbójútó Jèhófà. Ó fìfẹ́ hàn sí wọn, ó sì bù kún wọn lọ́pọ̀ yanturu nípa tara àti nípa tẹ̀mí. (Diu. 4:7, 8) Àmọ́, kí wọ́n lè máa rí irú ìbùkún bẹ́ẹ̀ gbà, wọ́n gbọ́dọ̀ máa pa Òfin Ọlọ́run mọ́. Èyí sì gba pé kí wọ́n máa fi “èyí tí ó dára jù lọ nínú àkọ́pọ́n àwọn èso” ilẹ̀ wọn rúbọ sí Jèhófà. (Ẹ́kís. 23:19) Tí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n á fi hàn pé àwọn mọrírì ìbùkún tí àwọn ń rí gbà àti ìfẹ́ tí Jèhófà ń fi hàn sáwọn.—Ka Diutarónómì 8:7-11.
7. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà nípa lílo àwọn ‘ohun ìní wa tó níye lórí’?
7 Àwa ńkọ́? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kì í fi ẹran rúbọ lónìí, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run nípa fífi àwọn ‘ohun ìní wa tó níye lórí’ bọlá fún un. (Òwe 3:9) Kí ni díẹ̀ lára ọ̀nà tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀? A lè fi àwọn ohun ìní wa ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run tá à ń ṣe nínú ìjọ wa tàbí kárí ayé. Ọ̀nà kan tó dáa láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà nìyẹn yálà a ní ohun díẹ̀ tàbí púpọ̀ nípa tara. (2 Kọ́r. 8:12) Síbẹ̀, àwọn ọ̀nà míì wà tá a lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.
8, 9. Tá a bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, báwo nìyẹn ṣe lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀? Ṣàpèjúwe.
8 Rántí pé Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe máa ṣàníyàn nípa oúnjẹ tàbí aṣọ, àmọ́ kí wọ́n máa wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́. Ó sọ pé Baba wa mọ ohun tá a nílò ní ti gidi. (Mát. 6:31-33) Tá a bá ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú ìlérí yẹn, á fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà dénú torí pé ìfẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé jọ máa ń rìn pọ̀ ni. Ó ṣe tán a ò lè nífẹ̀ẹ́ èèyàn dénú tá ò bá fọkàn tán an. (Sm. 143:8) Torí náà, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ǹjẹ́ àwọn àfojúsùn mi àti bí mo ṣe ń gbé ìgbésí ayé mi fi hàn pé mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lóòótọ́? Ǹjẹ́ àwọn ohun tí mò ń ṣe lójoojúmọ́ fi hàn pé mo gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé á pèsè àwọn ohun tí mo nílò fún mi?’
9 Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Mike ní irú ìgbẹ́kẹ̀lé bẹ́ẹ̀ nínú Ọlọ́run, ó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Nígbà tó wà lọ́mọdé, ó wù ú láti lọ sìn nílẹ̀ òkèèrè. Ó gbéyàwó, ó bímọ méjì, àmọ́ ó ṣì ń wù ú láti lọ sìn ní ilẹ̀ òkèèrè. Nígbà tí Mike ka àwọn ìròyìn àti àpilẹ̀kọ tó dá lórí sísìn ní àwọn ibi tá a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i, òun àti ìdílé rẹ̀ pinnu láti jẹ́ kí ohun ìní díẹ̀ tẹ́ àwọn lọ́rùn. Wọ́n ta ilé wọn, wọ́n sì kó lọ sí ilé tó kéré sí èyí tí wọ́n ń gbé tẹ́lẹ̀. Mike dín bí iṣẹ́ tó ń ṣe tẹ́lẹ̀ ṣe gbòòrò tó kù, ó sì kọ́ bó ṣe lè máa gbókèèrè darí iṣẹ́ náà láti orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ìdílé náà kó lọ síbi tí wọ́n ti fẹ́ lọ sìn, lẹ́yìn tí wọ́n sì ti sìn tayọ̀tayọ̀ níbẹ̀ fún ọdún méjì, Mike sọ pé: “A gbà pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Mátíù 6:33.”
MÁA FIYÈ SÍ ÒTÍTỌ́ TÍ ỌLỌ́RUN Ń KỌ́ WA
10. Kí ni ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì Ọba jẹ́ ká mọ̀ pó lè ṣẹlẹ̀ sí wa tá a bá ń ṣàṣàrò lórí òtítọ́ nípa Jèhófà?
10 Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] ọdún sẹ́yìn, ohun tí Dáfídì Ọba rí lójú ọ̀run mú kó ronú jinlẹ̀. Ó sọ pé: “Àwọn ọ̀run ń polongo ògo Ọlọ́run; òfuurufú sì ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.” Nígbà tó tún ronú nípa ọgbọ́n tó wà nínú Òfin Ọlọ́run, ó sọ pé: “Òfin Jèhófà pé, ó ń mú ọkàn padà wá. Ìránnilétí Jèhófà ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, ó ń sọ aláìní ìrírí di ọlọ́gbọ́n.” Ó dájú pé Dáfídì mọrírì ọgbọ́n Ọlọ́run! Àmọ́, kí ni àbájáde àṣàrò tó ṣe yìí? Dáfídì tún sọ pé: “Kí àwọn àsọjáde ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn-àyà mi dùn mọ́ ọ, ìwọ Jèhófà Àpáta mi àti Olùtúnniràpadà mi.” Ó ṣe kedere pé àṣàrò tí Dáfídì ń ṣe mú kó ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run rẹ̀.—Sm. 19:1, 7, 14.
11. Báwo la ṣe lè lo òye púpọ̀ tá a ní nípa ẹ̀kọ́ inú Ìwé Mímọ́ láti fi ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run hàn? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
11 Lónìí, a ní òye púpọ̀ nípa àwọn ohun tí Jèhófà dá àti bó ṣe ń mú àwọn ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ. Kíkàwé rẹpẹtẹ àti lílọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga layé ń gbé lárugẹ. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ti rí i pé lílọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga sábà máa ń mú kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ àwọn rì, kí ìfẹ́ tí àwọ́n ní fún Ọlọ́run sì jó rẹ̀yìn. Àmọ́ Bíbélì rọ̀ wá pé ká nífẹ̀ẹ́ ìmọ̀ ká sì tún ní ọgbọ́n àti òye. Ìyẹn túmọ̀ sí pé ká kọ́ bá a ṣe máa lo ọgbọ́n tí Ọlọ́run fún wa lọ́nà tó máa ṣe àwa àti àwọn míì láǹfààní. (Òwe 4:5-7) “Ìfẹ́” Ọlọ́run ni “pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:4) A máa ń fi ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà hàn nípa fífi gbogbo ọkàn wa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn èèyàn ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe fún aráyé.—Ka Sáàmù 66:16, 17.
12. Báwo ni ọ̀dọ́ kan ṣe fi hàn pé òun mọyì àwọn ohun tí Jèhófà ń fún wa?
12 Kódà, àwọn ọ̀dọ́ náà lè fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà nípa fífi ìmọrírì hàn fún àwọn ohun tó ń fún wa. Shannon sọ pé nígbà tí òun wà ní ọmọ ọdún mọ́kànlá, òun àti àbúrò òun tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá àtàwọn òbí àwọn jọ lọ sí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìfọkànsìn Oníwà-bí-Ọlọ́run.” Nígbà tí àpéjọ náà ń lọ lọ́wọ́, wọ́n ní kí àwọn ọmọdé jókòó síbì kan tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún wọn. Ó ní àyà òun já àmọ́ òun ṣe bẹ́ẹ̀. Inú rẹ̀ dùn gan-an nígbà tí wọ́n fún àwọn ọ̀dọ́ ní ìwé tó fani mọ́ra náà Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́. Èrò wo ni ìwé yìí mú kí Shannon ní nípa Jèhófà Ọlọ́run? Ó sọ pé: “Ìgbà yẹn ni mo tó mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ ẹni gidi àti pé ó nífẹ̀ẹ́ mi gan-an.” Ó tún sọ pé: “Inú wa mà dùn o pé Ọlọ́run wa, Jèhófà, ń fún wa ní irú ẹ̀bùn rere bẹ́ẹ̀!”
GBA ÌMỌ̀RÀN ÀTI ÌBÁWÍ ỌLỌ́RUN
13, 14. Kí ni ojú tá a fi ń wo ìmọ̀ràn tí Jèhófà bá fún wa fi hàn nípa ìfẹ́ tá a ní fún un?
13 Bíbélì rán wa létí pé: “Ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó ń fi ìbáwí tọ́ sọ́nà, àní gẹ́gẹ́ bí baba ti ń tọ́ ọmọ tí ó dunnú sí.” (Òwe 3:12) Kí ló wá yẹ ká ṣe tí Ọlọ́run bá bá wa wí? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gan-an nígbà tó sọ pé: “Kò sí ìbáwí tí ó dà bí ohun ìdùnnú nísinsìnyí, bí kò ṣe akó-ẹ̀dùn-ọkàn-báni.” Ohun tó sọ yẹn ò túmọ̀ sí pé ìbáwí ò ṣe pàtàkì tàbí pé kò wúlò torí ó tún sọ pé: “Síbẹ̀ nígbà tí ó bá yá, fún àwọn tí a ti kọ́ nípasẹ̀ rẹ̀, a máa so èso ẹlẹ́mìí àlàáfíà, èyíinì ni, òdodo.” (Héb. 12:11) Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a ò ní máa dágunlá tàbí ká máa bínú tó bá bá wa wí. Ó lè ṣòro fún àwọn kan láti gba ìbáwí. Àmọ́, ó dájú pé ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run á ràn wá lọ́wọ́.
14 Nígbà ayé Málákì, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ò mọrírì ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run fún wọn. Wọ́n mọ Òfin tí Jèhófà fún wọn nípa ẹbọ rírú àmọ́ ìwà àìlójútì wọn ò jẹ́ kí wọ́n pa òfin náà mọ́ torí náà Ọlọ́run fún wọn ní ìbáwí líle koko. (Ka Málákì 1:12, 13.) Báwo ni ohun tí wọ́n ṣe yìí ṣe burú tó? Jèhófà sọ fún wọn pé: “Èmi yóò rán ègún sórí yín, èmi yóò sì gégùn-ún fún ìbùkún yín. Bẹ́ẹ̀ ni, mo tilẹ̀ ti gégùn-ún fún ìbùkún náà, nítorí pé ẹ kò fi [àṣẹ mi] sí ọkàn-àyà yín.” (Mál. 2:1, 2) Tá a bá ń mọ̀ọ́mọ̀ kọ̀ láti fetí sí ìmọ̀ràn tó ṣe kedere tí Jèhófà fìfẹ́ fún wa tàbí tó ti di àṣà wa láti máa ṣe bẹ́ẹ̀, ibi tó máa já sí ò ní dáa.
15. Ìwà wo ló wọ́pọ̀ nínú ayé lónìí tó yẹ ká yẹra fún?
15 Nínú ayé onímọtara-ẹni-nìkan táwọn èèyàn kì í ti í rí tẹlòmíì rò yìí, kò rọrùn láti gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn tàbí láti bá wọn wí ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ pé kí wọ́n fara mọ́ ọn. Kódà agbára káká ni àwọn tó jọ pé wọ́n ń gba ìbáwí tàbí ìmọ̀ràn fi ń gbà á. Ṣùgbọ́n, Bíbélì kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni tòótọ́ pé kí wọ́n “jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí.” Kàkà bẹ́ẹ ó yẹ ká máa fòye mọ ‘ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó pé.’ (Róòmù 12:2) Jèhófà ń tipasẹ̀ ètò rẹ̀ fún wa nímọ̀ràn tó bágbà mu nípa bó ṣe yẹ ká máa hùwà pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tiwa, àwọn tó yẹ ká máa bá kẹ́gbẹ́ àti irú eré ìtura tó yẹ ká máa ṣe. Tá a bá ń fara mọ́ irú ìtọ́sọ́nà bẹ́ẹ̀ tá a sì ń fi sílò, ìyẹn á fi hàn pé a moore a sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tọkàntọkàn.—Jòh. 14:31; Róòmù 6:17.
WÁ ÀÀBÒ ÀTI ÌGBÀLÀ LỌ SỌ́DỌ̀ JÈHÓFÀ
16, 17. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ronú nípa ohun tí Jèhófà fẹ́ tá a bá ń ṣèpinnu? (b) Báwo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe fi hàn pé àwọn ò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti pé àwọn ò gbẹ́kẹ̀ lé e?
16 Tí àwọn ọmọdé bá rí ohun tó lè pa wọ́n lára, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n á sá lọ sọ́dọ̀ àwọn òbí wọn. Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, wọ́n máa ń fẹ́ gbára lé òye tara wọn kí wọ́n sì máa dá ṣèpinnu. Ìyẹn fi hàn pé wọ́n ti ń dàgbà. Àmọ́, àwọn tó ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn òbí wọn máa ń fẹ́ mọ èrò wọn kí wọ́n sì gbàmọ̀ràn kí wọ́n tó ṣèpinnu. Bó ṣe yẹ kó rí nípa tẹ̀mí náà nìyẹn. Jèhófà ti fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ kó lè máa sún wa láti “fẹ́ láti ṣe, kí [a] sì gbé ìgbésẹ̀.” Síbẹ̀, tá a bá ń ṣèpinnu láì kọ́kọ́ ronú lórí ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́, èyí á fi hàn pé a ò nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run a ò sì gbẹ́kẹ̀ lé e.—Fílí. 2:13.
17 Ó ṣẹlẹ̀ nígbà kan tí Sámúẹ́lì wà láyé pé àwọn Filísínì ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lójú ogun. Àwọn èèyàn Ọlọ́run nílò ìrànlọ́wọ́ àti ààbò gan-an. Kí ni wọ́n wá ṣe? Wọ́n sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a lọ gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà láti Ṣílò wá sọ́dọ̀ ara wa, kí ó lè wá sí àárín wa, kí ó sì lè gbà wá là kúrò ní àtẹ́lẹwọ́ àwọn ọ̀tá wa.” Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Bíbélì sọ pé: “Ìpakúpa náà sì wá pọ̀ gidigidi, tó bẹ́ẹ̀ tí ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ àwọn ọkùnrin tí ń fẹsẹ̀ rìn fi ṣubú láti inú Ísírẹ́lì. Àpótí Ọlọ́run pàápàá ni a sì gbà.” (1 Sám. 4:2-4, 10, 11) Ó lè dà bíi pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fẹ́ kí Jèhófà ran àwọn lọ́wọ́ ní wọ́n ṣe gbé Àpótí yẹn dání lọ sójú ogun. Àmọ́, wọn ò wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà, èrò ara wọn ni wọ́n ń tẹ̀ lé, ibi tí ọ̀rọ̀ náà já sí ò sì dáa.—Ka Òwe 14:12.
18. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tá a bá wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà?
18 Onísáàmù náà ní ohun tó tọ́ lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Dúró de Ọlọ́run, nítorí pé síbẹ̀síbẹ̀, èmi yóò máa gbé e lárugẹ gẹ́gẹ́ bí ìgbàlà títóbi lọ́lá fún èmi alára. Ìwọ Ọlọ́run mi, àní ọkàn mi ń bọ́hùn nínú mi. Ìdí nìyẹn tí mo fi rántí rẹ.” (Sm. 42:5, 6) Onísáàmù yìí mà nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an o! Ṣé ìwọ náà ní irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ fún Jèhófà, ṣé o sì máa ń gbẹ́kẹ̀ lé Baba wa ọ̀run? Kódà, bó o bá tiẹ̀ dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni, ìdí ṣì lè wà fún ẹ láti túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé e níbàámu pẹ̀lú ohun tí Bíbélì sọ fún wa. Ó ní: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.”—Òwe 3:5, 6.
19. Báwo lo ṣe máa fi han pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?
19 Jèhófà ló kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa, nípa báyìí ó fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa nípa bá a ṣe lè nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká máa fi àpẹẹrẹ ìfẹ́ títayọ yìí sọ́kàn nígbà gbogbo. Ká sì máa fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ‘pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa àti pẹ̀lú gbogbo èrò-inú wa àti pẹ̀lú gbogbo okun wa.’—Máàkù 12:30.