Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ẹ́sírà
IBI tí ìwé Kíróníkà Kejì parí sí ni ìwé Ẹ́sírà ti bẹ̀rẹ̀. Ẹ́sírà àlùfáà ló kọ ọ́. Ohun tó fi bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ni ìtàn nípa bí Kírúsì ọba Páṣíà ṣe pàṣẹ pé kí àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn Júù tí àwọn ará Bábílónì kó nígbèkùn ṣe padà lọ sí ìlú ìbílẹ̀ wọn. Ibi tí ìtàn náà parí sí ni bí Ẹ́sírà ṣe gbé àwọn ìgbésẹ̀ pàtàkì kan láti rí i dájú pé àwọn tó ti fi àjọṣe pẹ̀lú àwọn èèyàn ilẹ̀ Bábílónì sọ ara wọn di ẹlẹ́gbin di ẹni mímọ́ lójú Jèhófà. Tá a bá wò ó lọ wò ó bọ̀, a óò rí i pé àárín àádọ́rin ọdún ni gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìwé náà wáyé, ìyẹn láti ọdún 537 sí 467 ṣáájú Sànmánì Kristẹni.
Ìdí tí Ẹ́sírà fi kọ̀wé yìí ni pé, ó fẹ́ fi hàn bí Jèhófà ṣe mú ìlérí tó ṣe ṣẹ, ìyẹn ìlérí tó ṣe pé òun máa dá àwọn èèyàn òun sílẹ̀ kúrò nígbèkùn tí wọ́n wà ní Bábílónì, òun á sì tún mú kí ìjọsìn tòótọ́ fìdí múlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó jẹ mọ́ nǹkan wọ̀nyí ló kọ̀wé nípa rẹ̀. Ìwé Ẹ́sírà jẹ́ ìtàn nípa bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe tún tẹ́ńpìlì kọ́ àti bí ìjọsìn Jèhófà ṣe tún fìdí múlẹ̀ níbẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀tá ń gbógun tí àwọn èèyàn Ọlọ́run sì ní kùdìẹ̀-kudiẹ tiwọn. Ó yẹ ká túbọ̀ fẹ́ mọ̀ nípa ìtàn yìí torí pé ìgbà ìmúpadàbọ̀sípò ni àwa náà ń gbé yìí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló ń rọ́ lọ sí “òkè ńlá Jèhófà,” gbogbo àgbáyé sì ni “yóò kún fún mímọ ògo Jèhófà” láìpẹ́.—Aísáyà 2:2, 3; Hábákúkù 2:14.
WỌ́N TÚN TẸ́ŃPÌLÌ KỌ́
Àwọn Júù tó wà nígbèkùn tí iye wọn tó nǹkan bí ọ̀kẹ́ méjì ààbọ̀ [50,000] ló padà sí Jerúsálẹ́mù, Gómìnà Serubábélì tó tún ń jẹ́ Ṣẹṣibásà sì ni alábòójútó wọn. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ làwọn tó padà dé láti ìgbèkùn náà mọ pẹpẹ síbi tó wà tẹ́lẹ̀, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí rúbọ sí Jèhófà.
Ọdún tó tẹ̀ lé e làwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ìpìlẹ̀ ilé Jèhófà lélẹ̀. Àwọn ọ̀tá ò jẹ́ kí wọ́n rímú mí bí wọ́n ṣe ń tún tẹ́ńpìlì náà kọ́. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n ṣe ohun tó mú kí ọba pàṣẹ pé kí iṣẹ́ ìkọ́lé náà dúró. Wòlíì Hágáì àti Sekaráyà fún àwọn èèyàn náà níṣìírí, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà padà bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọba ò tíì gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí iṣẹ́ náà. Ẹ̀rù tó sì ń ba àwọn ọ̀tá wọn pé àwọn ò fẹ́ tàpá sí òfin Páṣíà kan tí kò ṣeé yí padà, èyí tí Kírúsì ṣe, ló jẹ́ káwọn ọ̀tá náà fi wọ́n sílẹ̀. Nígbà táwọn aláṣẹ ní kí wọ́n ṣèwádìí, wọ́n rí i pé Kírúsì ti pàṣẹ kan “nípa ilé Ọlọ́run ní Jerúsálẹ́mù.” (Ẹ́sírà 6:3) Iṣẹ́ náà lọ geerege, wọ́n sì parí rẹ̀ pátápátá.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
1:3-6—Ǹjẹ́ a lè sọ pé àìní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run ni kò jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn? Ó lè jẹ́ pé ìfẹ́ owó ni kò jẹ́ káwọn kan padà sí Jerúsálẹ́mù tàbí kó jẹ́ pé wọn ò ka ìjọsìn tòótọ́ sí mọ́, àmọ́ kì í ṣe tìtorí ìyẹn làwọn kan ò ṣe padà o. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ìrìn àjò yẹn kì í ṣe kékeré torí pé ẹgbẹ̀jọ [1,600] kìlómítà ni, yóò sì gba oṣù mẹ́rin sí márùn-ún kí wọ́n tó dé Jerúsálẹ́mù. Ìyẹn nìkan kọ́ o, kéèyàn tó lè máa gbé ilẹ̀ tó ti wà ní ahoro fún àádọ́rin ọdún kéèyàn sì tún ṣe iṣẹ́ ìkọ́lé níbẹ̀, onítọ̀hún gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹni tí ara rẹ̀ le. Látàrí èyí, ó dájú pé àwọn ipò tí kò rọgbọ, irú bí àìsàn, ọjọ́ ogbó àti bùkátà ìdílé ni kò jẹ́ káwọn kan lè padà.
2:43—Àwọn wo làwọn Nétínímù? Wọn kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, ẹrú tàbí ìránṣẹ́ ni wọ́n nínú tẹ́ńpìlì. Àwọn kan lára wọn jẹ́ àtọmọdọ́mọ àwọn ará Gíbéónì tí wọ́n gbé láyé nígbà ayé Jóṣúà àtàwọn mìíràn “tí Dáfídì àti àwọn ọmọ aládé fi fún iṣẹ́ ìsìn àwọn ọmọ Léfì.”—Ẹ́sírà 8:20.
2:55—Àwọn wo làwọn ọmọkùnrin àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì? Wọn kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì àmọ́ wọ́n yan àwọn iṣẹ́ pàtàkì fún wọn nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé akọ̀wé tàbí adàwékọ ni wọ́n nínú tẹ́ńpìlì tàbí kí wọ́n wà ní ipò mìíràn tí wọ́n á ti máa ṣe àbójútó.
2:61-63—Ǹjẹ́ àwọn tó padà dé láti ìgbèkùn rí Úrímù àti Túmímù lò, èyí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń lò láti fi wádìí àwọn nǹkan lọ́dọ̀ Jèhófà? Àwọn tó sọ pé ìdílé àlùfáà làwọn ti wá ṣùgbọ́n tí wọn kò lè fi ìdí ìtàn ìran wọn múlẹ̀ ì bá ti lo Úrímù àti Túmímù láti fi ẹ̀rí hàn pé àlùfáà làwọn lóòótọ́. Ńṣe ni Ẹ́sírà kàn ń sọ pé ohun tí wọn ì bá ṣe nìyẹn. Kò sí àkọsílẹ̀ kankan nínú Ìwé Mímọ́ tó fi hàn pé wọ́n lo Úrímù àti Túmímù lásìkò yẹn tàbí lẹ́yìn ìgbà yẹn. Ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù sọ pé ìgbà tí wọ́n pa tẹ́ńpìlì run lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni Úrímù àti Túmímù ò ti sí mọ́.
3:12—Kí nìdí tí “àwọn àgbààgbà tí ó rí [ilé Jèhófà nígbà] àtijọ́” fi ń sunkún? Àwọn ọkùnrin náà rántí bí tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì kọ́ ṣe dára tó. Nígbà tí wọ́n wá rí ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì tuntun náà, tí wọ́n fi wé ti ìṣáájú, ńṣe ló dà bí “asán ní ojú” wọn. (Hágáì 2:2, 3) Wọ́n á máa rò ó pé bóyá ni àwọn tún lè kọ́ tẹ́ńpìlì tuntun tó máa ní irú ògo tí tẹ́ńpìlì ti tẹ́lẹ̀ ní. Inú wọn ti ní láti bà jẹ́ gan-an, ìdí nìyẹn tí wọ́n sì fi ń sunkún.
3:8-10; 4:23, 24; 6:15, 16—Ọdún mélòó ni wọ́n fi ṣàtúnkọ́ tẹ́ńpìlì náà? Ọdún 536 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì náà lélẹ̀, ìyẹn “ní ọdún kejì tí wọ́n wá.” Wọ́n dáwọ́ iṣẹ́ náà dúró lọ́dún 522 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, nígbà ìṣàkóso Atasásítà Ọba. Ọdún 520 ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n tó gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí iṣẹ́ náà, ìyẹn ọdún kejì tí Dáríúsì Ọba ti ń ṣàkóso. Ọdún kẹfà tó ti ń ṣàkóso ni wọ́n parí tẹ́ńpìlì náà pátápátá, lọ́dún 515 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. (Wo àpótí tó ní àkọlé yìí, “Àwọn Ọba Ilẹ̀ Páṣíà Láti Ọdún 537 sí Ọdún 467 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni”) Nítorí náà, nǹkan bí ogún ọdún ni wọ́n fi kọ́ tẹ́ńpìlì náà.
4:8-6:18—Kí nìdí tí wọ́n fi fi èdè Árámáíkì kọ àwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyí?—Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé àwọn ẹ̀dà lẹ́tà táwọn lọ́gàálọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba kọ sáwọn ọba àtàwọn lẹ́tà táwọn ọba fi fèsì nìkan ló wà nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí. Inú àwọn ìwé àkọsílẹ̀ tó jẹ́ ti gbogbo gbòò, èyí tí wọ́n fi èdè Árámáíkì kọ, ni Ẹ́sírà ti ṣe àdàkọ wọn. Èdè Árámáíkì yìí sì ni wọ́n ń lò lágbo àwọn oníṣòwò àtàwọn òṣìṣẹ́ ọba láyé ìgbà yẹn. Àwọn ẹsẹ Bíbélì mìíràn tí wọ́n fi èdè Árámáíkì kọ ni Ẹ́sírà 7:12-26, Jeremáyà 10:11, àti Dáníẹ́lì 2:4b–7:28.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:2. Ọ̀rọ̀ tí Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ ní nǹkan bí igba ọdún ṣáájú ṣẹ. (Aísáyà 44:28) Èyí fi hàn pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì yóò ṣẹ dandan ni.
1:3-6. Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan ò ṣe lè kúrò ní Bábílónì ni ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lónìí ò ṣe lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún tàbí kí wọ́n lọ máa wàásù níbi tí kò ti fi bẹ́ẹ̀ sí àwọn oníwàásù, síbẹ̀ wọ́n máa ń ṣètìlẹyìn fáwọn tó ń ṣiṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún wọ́n sì ń fún wọn níṣìírí. Wọ́n tún ń fi tinútinú fi ọrẹ ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ wíwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti sísọ àwọn èèyàn di ọmọlẹ́yìn kí iṣẹ́ yẹn lè máa tẹ̀ síwájú.
3:1-6. Lóṣù keje ọdún 537 ṣáájú Sànmánì Kristẹni (ìyẹn oṣù Tíṣírì, èyí tó bọ́ sáàárín oṣù September àti oṣù October lónìí), àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ tó padà wálé rú ẹbọ wọn àkọ́kọ́. Àwọn ará Bábílónì wọ ìlú Jerúsálẹ́mù lóṣù karùn-ún ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni (ìyẹn oṣù Ábì tó bọ́ sáàárín oṣù July àti oṣù August lónìí), oṣù méjì lẹ́yìn ìyẹn ló sì pa ìlú náà run pátápátá. (2 Àwọn Ọba 25:8-17, 22-26) Àkókò tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé ìsọdahoro Jerúsálẹ́mù tó jẹ́ àádọ́rin ọdún yóò dópin gan-an ló dópin. (Jeremáyà 25:11; 29:10) Gbogbo ohun tí Bíbélì bá sọ tẹ́lẹ̀ ló máa ń ṣẹ.
4:1-3. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ tó padà dé láti ìgbèkùn kọ̀ jálẹ̀ nígbà tí àwọn kan dábàá ohun kan tó máa yọrí sí bíbá àwọn olùjọsìn èké ṣe ẹ̀sìn pọ̀. (Ẹ́kísódù 20:5; 34:12) Bákan náà, àwọn olùjọsìn Jèhófà òde òní kì í lọ́wọ́ sí ètò èyíkéyìí tó máa túmọ̀ sí ṣíṣe àmúlùmálà ìsìn.
5:1-7; 6:1-12. Jèhófà lè yí ipò nǹkan padà kí nǹkan lè yọrí sí rere fáwọn èèyàn rẹ̀.
6:14, 22. Bá a bá ń fi ìtara kópa nínú iṣẹ́ Jèhófà, yóò fojúure hàn sí wa yóò sì bù kún wa.
6:21. Rírí bí iṣẹ́ Jèhófà ṣe ń tẹ̀ síwájú ló mú káwọn ará Samáríà tí wọ́n ń gbé nílẹ̀ àwọn Júù lásìkò náà àtàwọn tó padà dé láti ìgbèkùn tí wọ́n ti ń lọ́wọ́ nínú ìbọ̀rìṣà ṣe àwọn àyípadà tó yẹ nígbèésí ayé wọn. Ǹjẹ́ kò yẹ ká máa fi ìtara lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún wa, irú bí iṣẹ́ wíwàásù ìjọba Ọlọ́run?
Ẹ́SÍRÀ WÁ SÍ JERÚSÁLẸ́MÙ
Ẹ́sírà àtàwọn kan lára àwọn èèyàn Ọlọ́run tí wọ́n wà nígbèkùn Bábílónì padà sí Jerúsálẹ́mù lọ́dún 468 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìyẹn àádọ́ta ọdún lẹ́yìn tí wọ́n ṣe ìyàsímímọ́ ilé Jèhófà tí wọ́n tún kọ́. Ẹ́sírà tún kó owó tí wọ́n fi ṣètọrẹ dání nígbà tó ń lọ. Kí ló bá lọ́hùn-ún?
Àwọn ọmọ aládé sọ fún Ẹ́sírà pé: “Àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì àti àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì kò ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn ilẹ̀ wọnnì ní ti àwọn ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí wọn.” Ìyẹn nìkan kọ́ o, “ọwọ́ àwọn ọmọ aládé àti ti àwọn ajẹ́lẹ̀ sì ni ó wà ní iwájú pátápátá nínú ìwà àìṣòótọ́ yìí.” (Ẹ́sírà 9:1, 2) Ọ̀rọ̀ yìí ya Ẹ́sírà lẹ́nu gan-an. Wọ́n wá rọ̀ ọ́ pé kó “jẹ́ alágbára, kí [ó] sì gbé ìgbésẹ̀.” (Ẹ́sírà 10:4) Ẹ́sírà gbé àwọn ìgbésẹ̀ kan kí nǹkan lè rí bó ṣe yẹ kó rí, àwọn èèyàn náà sì tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
7:1, 7, 11—Ṣé ọ̀rọ̀ Atasásítà tó dáwọ́ iṣẹ́ ìkọ́lé náà dúró ni àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ń sọ? Rárá o. Atasásítà jẹ́ orúkọ oyè méjì lára àwọn ọba ilẹ̀ Páṣíà. Ó ṣeé ṣe kí ọ̀kan lára wọn jẹ́ Bádíyà, tí wọ́n tún ń pè ní Gáúmátà, ẹni tó pàṣẹ pé kí wọ́n dáwọ́ iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ńpìlì dúró lọ́dún 522 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Atasásítà Lọngimánọ́sì ni Atasásítà tó ń ṣèjọba nígbà tí Ẹ́sírà wá sí Jerúsálẹ́mù.
7:28–8:20—Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ àwọn Júù tó wà ní Bábílónì ò fi fẹ́ bá Ẹ́sírà lọ sí Jerúsálẹ́mù? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé ní ọgọ́ta ọdún táwọn Júù tó kọ́kọ́ kúrò ní Bábílónì ti padà sí ilẹ̀ wọn, síbẹ̀ ìwọ̀nba àwọn èèyàn díẹ̀ ló ṣì wà nílùú Jerúsálẹ́mù. Ẹni tó bá fẹ́ padà sí Jerúsálẹ́mù ní láti ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí wá nǹkan ṣe ni, ní ibi tí nǹkan ti nira gan-an tí ẹ̀mí àwọn èèyàn sì ti wà nínú ewu. Àwọn Júù tó ti rí ṣe ní Bábílónì kò ní fẹ́ padà sí Jerúsálẹ́mù torí pé nǹkan kò fi bẹ́ẹ̀ rọ̀ṣọ̀mù níbẹ̀ nígbà náà. Ká má sì gbàgbé pé ewu ń bẹ lójú ọ̀nà tí wọ́n máa gbà débẹ̀. Kí wọ́n tó lè padà sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà, kí wọ́n ní ìtara fún ìjọsìn tòótọ́, kí wọ́n sì jẹ́ onígboyà. Kódà, ńṣe ni Ẹ́sírà fún ara rẹ̀ lókun ní ìbámu pẹ̀lú ọwọ́ Jèhófà lára rẹ̀. Ìṣírí tí Ẹ́sírà fún àwọn èèyàn náà mú kí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] ìdílé gbà láti bá a padà, àfàìmọ̀ ni gbogbo wọn lápapọ̀ ò sì tó ẹgbàata [6,000]. Lẹ́yìn tí Ẹ́sírà tún gbé àwọn ìgbésẹ̀ mìíràn, àwọn ọmọ Léfì méjìdínlógójì àtàwọn Nétínímù tí iye wọn jẹ́ igba ó lé ogún [220] tún gbà láti bá wọn lọ.
9:1, 2—Báwo ni ọ̀rọ̀ fífẹ́ lára àwọn èèyàn ilẹ̀ náà ṣe burú tó? Orílẹ̀-èdè tí Ọlọ́run mú padà bọ̀ sípò náà ló yẹ kó máa mójú tó ìjọsìn Jèhófà títí dìgbà tí Mèsáyà á fi dé. Bí wọ́n ṣe lọ ń fẹ́ lára àwọn olùgbé ilẹ̀ náà jẹ́ àkóbá ńlá fún ìjọsìn tòótọ́. Ìdí ni pé bí àwọn kan ṣe lọ ń fẹ́ lára àwọn abọ̀rìṣà náà lè sọ gbogbo orílẹ̀-èdè náà látòkèdélẹ̀ di ara àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà. Ìyẹn ì bá sì jẹ́ kí ìjọsìn mímọ́ pòórá lórí ilẹ̀ ayé. Ọ̀dọ̀ àwọn wo ni Mèsáyà náà ti máa wá jáde nígbà náà? Abájọ tó fi ya Ẹ́sírà lẹ́nu gan-an pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè máa ṣẹlẹ̀!
10:3, 44—Kí nìdí tí wọ́n fi lé àwọn aya àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ tọmọtọmọ? Ká ní àwọn ọmọ náà ò bá wọn lọ ni, ó ṣeé ṣe kí èyí mú kó rọrùn fáwọn ìyàwó tí wọ́n ní kó máa lọ náà láti padà wá torí àwọn ọmọ wọn. Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ káwọn ọmọ kéékèèké wà lọ́dọ̀ ìyá kí wọ́n lè tọ́jú wọn.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
7:10. Tó bá dọ̀rọ̀ ká fi ìtara kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ká sì fi kọ́ àwọn èèyàn lọ́nà tó máa yé wọn, Ẹ́sírà jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà fún wa. Ó máa ń fi tàdúrà-tàdúrà múra ọkàn rẹ̀ sílẹ̀ tó bá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Òfin Jèhófà. Nígbà tí Ẹ́sírà bá ń ka Òfin náà, ohun tí Jèhófà ń sọ ló máa ń jẹ ẹ́ lọ́kàn jù lọ. Ẹ́sírà fi ohun tó ń kọ́ sílò, ó sì sa gbogbo ipá rẹ̀ láti fi kọ́ àwọn ẹlòmíràn.
7:13. Àwọn ìránṣẹ́ tó ń fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn ni Jèhófà fẹ́.
7:27, 28; 8:21-23. Ẹ́sírà fọpẹ́ fún Jèhófà, ó fi tọkàntọkàn rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí i kó tó rìnrìn àjò ọ̀nà jíjìn lọ sí Jerúsálẹ́mù bó tilẹ̀ jẹ́ pé ewu pọ̀ gan-an lójú ọ̀nà, ó sì múra tán láti fẹ̀mí ara rẹ̀ wewu fún ògo Ọlọ́run. Àpẹẹrẹ tó dára ló fi lélẹ̀ fún wa yẹn.
9:2. A ò gbọ́dọ̀ fojú kéré ìkìlọ̀ tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe pé “kìkì nínú Olúwa” ni ká ti ṣe ìgbéyàwó.—1 Kọ́ríńtì 7:39.
9:14, 15. Tá a bá ń kẹ́gbẹ́ búburú, Jèhófà yóò bínú sí wa.
10:2-12, 44. Àwọn tó ti lọ fẹ́ aya ilẹ̀ òkèèrè fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ronú pìwà dà, wọ́n sì tún ìwà wọn ṣe. Àwa náà lè kẹ́kọ̀ọ́ látinú ẹ̀mí tí wọ́n fi hàn àti ìgbésẹ̀ tí wọ́n gbé.
Jèhófà Máa Ń Mú Ìlérí Rẹ̀ Ṣẹ
Ìwé Ẹ́sírà mà wúlò fún wa o! Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ pé òun yóò dá àwọn èèyàn òun sílẹ̀ kúrò nígbèkùn tí wọ́n wà ní Bábílónì, òun yóò sì mú kí ìjọsìn tòótọ́ fìdí múlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù. Àkókò tó sọ tẹ́lẹ̀ gan-an ni èyí sì ṣẹlẹ̀. Ǹjẹ́ èyí ò mú kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Jèhófà àtàwọn ìlérí rẹ̀ lágbára sí i?
Ronú nípa àpẹẹrẹ àwọn èèyàn tá a rí nínú ìwé Ẹ́sírà. Ẹ́sírà àtàwọn tó padà dé láti ìgbèkùn kí wọ́n lè kópa nínú iṣẹ́ fífi ìdí ìjọsìn mímọ́ múlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i ní Jerúsálẹ́mù fi hàn pé tọkàntọkàn làwọn ń sin Ọlọ́run. Ó yẹ ká fìwà jọ wọ́n. Ìwé yìí tún jẹ́ ká mọ̀ nípa ìgbàgbọ́ táwọn ará ilẹ̀ òkèèrè tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run fi hàn àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ táwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà ní. Ká sòótọ́, ohun tí Ọlọ́run mí sí Ẹ́sírà láti kọ sílẹ̀ jẹ́ ká rí i kedere pé “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára.”—Hébérù 4:12.
[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
ÀWỌN ỌBA ILẸ̀ PÁṢÍÀ LÁTI ỌDÚN 537 SÍ ỌDÚN 467 ṢÁÁJÚ SÀNMÁNÌ KRISTẸNI (Ṣ.S.K.)
Kírúsì Ńlá (Ẹ́sírà 1:1) kú lọ́dún 530 Ṣ.S.K.
Kanbáísísì, tàbí Ahasuwérúsì (Ẹ́sírà 4:6) ọdún 530 sí ọdún 522
Ṣ.S.K.
Atasásítà—Bádíyà tàbí Gáúmátà (Ẹ́sírà 4:7) ọdún 522 Ṣ.S.K. (Wọ́n
pa á lẹ́yìn tó ṣèjọba
fún oṣù méje péré)
Dáríúsì Kìíní (Ẹ́sírà 4:24) ọdún 522 sí ọdún 486
Ṣ.S.K.
Sásítà, tàbí Ahasuwérúsìa ọdún 486 sí ọdún 475
Ṣ.S.K. (Òun àti
Dáríúsì Kìíní jùmọ̀
ṣàkóso láti ọdún 496
sí ọdún 486 Ṣ.S.K.)
Atasásítà Lọngimánọ́sì (Ẹ́sírà 7:1) ọdún 475 sí ọdún 424
Ṣ.S.K.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé Ẹ́sírà ò mẹ́nu kan Sásítà. Ahasuwérúsì ni ìwé Ẹ́sítérì pè é nínú Bíbélì.
[Àwòrán]
Ahasuwérúsì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Kírúsì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ohun rìbìtì tí wọ́n fi amọ̀ ṣe tó sọ nípa ètò tí Kírúsì ṣe nípa bí àwọn tó wà nígbèkùn á ṣe padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn
[Credit Line]
Ohun rìbìtì tí wọ́n fi amọ̀ ṣe: British Museum ló yọ̀ǹda ká lo fọ́tò yìí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Ǹjẹ́ o mọ ohun tó jẹ́ kí Ẹ́sírà mọ èèyàn kọ́ dáadáa?