Ẹ́sírà
6 Ìgbà náà ni Ọba Dáríúsì pa àṣẹ kan, wọ́n sì ṣe àyẹ̀wò nínú ibi ìkówèésí* tó wà ní àwọn ibi tí wọ́n ń kó ìṣúra sí ní Bábílónì. 2 Wọ́n rí àkájọ ìwé kan nínú ilé ńlá tó wà ní Ekibátánà, ní ìpínlẹ̀* Mídíà, ọ̀rọ̀ ìrántí tó wà nínú rẹ̀ nìyí:
3 “Ní ọdún kìíní Ọba Kírúsì, Ọba Kírúsì pa àṣẹ kan nípa ilé Ọlọ́run ní Jerúsálẹ́mù, ó ní:+ ‘Ẹ tún ilé náà kọ́ kí ẹ lè máa rú àwọn ẹbọ níbẹ̀, kí ẹ sì fi àwọn ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ sí àyè rẹ̀; kí gíga rẹ̀ jẹ́ ọgọ́ta (60) ìgbọ̀nwọ́,* kí fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ọgọ́ta (60) ìgbọ̀nwọ́,+ 4 kí ó ní ipele mẹ́ta òkúta ńlá tí wọ́n yí sí àyè wọn àti ipele kan ẹ̀là gẹdú;+ kí owó tí wọ́n máa fi ṣe é sì wá láti ilé ọba.+ 5 Bákan náà, kí a dá àwọn ohun èlò wúrà àti fàdákà ilé Ọlọ́run pa dà, èyí tí Nebukadinésárì kó kúrò nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì,+ kí wọ́n lè pa dà sí àyè wọn nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù, kí a sì kó wọn sínú ilé Ọlọ́run.’+
6 “Nítorí náà, ìwọ Táténáì gómìnà agbègbè tó wà ní Ìkọjá Odò* àti Ṣetari-bósénáì pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ, ìyẹn àwọn gómìnà kéékèèké tó wà ní Ìkọjá Odò,+ ẹ má ṣe débẹ̀ o. 7 Ẹ má ṣe dí iṣẹ́ ilé Ọlọ́run yẹn lọ́wọ́. Gómìnà àwọn Júù àti àwọn àgbààgbà Júù yóò tún ilé Ọlọ́run kọ́ sí ibi tó wà tẹ́lẹ̀. 8 Yàtọ̀ síyẹn, mo pàṣẹ ohun tí ẹ máa ṣe fún àwọn àgbààgbà Júù, kí wọ́n lè tún ilé Ọlọ́run kọ́, àṣẹ náà nìyí: Látinú ibi ìṣúra ọba,+ ìyẹn látinú owó orí tí ẹ gbà láti agbègbè tó wà ní Ìkọjá Odò ni kí ẹ ti máa fún àwọn ọkùnrin náà lówó tí wọ́n á fi ṣe iṣẹ́ náà, ẹ má sì fi falẹ̀, kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ náà lọ láìsí ìdíwọ́.+ 9 Ohunkóhun tí wọ́n bá nílò, látorí àwọn ọmọ akọ màlúù,+ àwọn àgbò+ àti àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn + fún àwọn ẹbọ sísun sí Ọlọ́run ọ̀run, dórí àlìkámà,*+ iyọ̀,+ wáìnì+ àti òróró,+ gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà tó wà ní Jerúsálẹ́mù ṣe sọ, gbogbo rẹ̀ ni kí ẹ máa fún wọn lójoojúmọ́, kò gbọ́dọ̀ yẹ̀, 10 kí wọ́n lè máa mú ọrẹ tó ń mú inú Ọlọ́run ọ̀run dùn wá déédéé, kí wọ́n sì máa gbàdúrà fún ẹ̀mí ọba àti ti àwọn ọmọ rẹ̀.+ 11 Mo tún pa àṣẹ kan pé ẹnikẹ́ni tó bá rú òfin yìí, kí wọ́n yọ igi kan lára ilé rẹ̀, kí wọ́n gbé onítọ̀hún sókè, kí wọ́n dè é* mọ́ ọn, kí wọ́n sì sọ ilé rẹ̀ di ilé ìyàgbẹ́* gbogbo èèyàn nítorí ohun tó ṣe yìí. 12 Kí Ọlọ́run tó mú kí orúkọ rẹ̀ máa wà níbẹ̀+ gbá ọba tàbí èèyàn èyíkéyìí dà nù tí ó bá gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè láti rú òfin yìí, tí ó sì ba ilé Ọlọ́run yẹn jẹ́, èyí tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Èmi, Dáríúsì ló pa àṣẹ yìí. Kí ẹ ṣe ohun tí mo sọ ní kánmọ́kánmọ́.”
13 Nígbà náà, Táténáì gómìnà agbègbè tó wà ní Ìkọjá Odò àti Ṣetari-bósénáì+ pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, ṣe gbogbo ohun tí Ọba Dáríúsì pa láṣẹ ní kánmọ́kánmọ́. 14 Àwọn àgbààgbà Júù ń bá iṣẹ́ ìkọ́lé náà lọ, wọ́n ń tẹ̀ síwájú,+ àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì Hágáì+ àti Sekaráyà+ ọmọ ọmọ Ídò sì ń fún wọn níṣìírí; wọ́n parí iṣẹ́ ìkọ́lé náà nípa àṣẹ Ọlọ́run Ísírẹ́lì+ àti nípa àṣẹ Kírúsì+ àti Dáríúsì+ àti Atasásítà+ ọba Páṣíà. 15 Wọ́n parí ilé náà ní ọjọ́ kẹta oṣù Ádárì,* ní ọdún kẹfà àkóso Ọba Dáríúsì.
16 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì + pẹ̀lú àwọn tó wà nígbèkùn tẹ́lẹ̀ fi ìdùnnú ṣe ayẹyẹ ṣíṣí* ilé Ọlọ́run yìí. 17 Ohun tí wọ́n mú wá fún ayẹyẹ ṣíṣí ilé Ọlọ́run yìí ni ọgọ́rùn-ún (100) akọ màlúù, igba (200) àgbò àti ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọ̀dọ́ àgùntàn, wọ́n sì tún mú akọ ewúrẹ́ méjìlá (12) wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí iye àwọn ẹ̀yà tó wà ní Ísírẹ́lì.+ 18 Wọ́n mú àwọn àlùfáà ní àwùjọ wọn àti àwọn ọmọ Léfì ní àwùjọ tí wọ́n pín wọn sí, wọ́n sì yàn wọ́n sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ní Jerúsálẹ́mù,+ gẹ́gẹ́ bí ohun tó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé Mósè.+
19 Àwọn tó wà nígbèkùn tẹ́lẹ̀ ṣe Ìrékọjá ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìíní.+ 20 Àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì wẹ ara wọn mọ́,+ láìyọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀, torí náà, gbogbo wọn ló wà ní mímọ́; wọ́n pa ẹran Ìrékọjá fún gbogbo àwọn tó wà nígbèkùn tẹ́lẹ̀, fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ àlùfáà àti fún ara wọn. 21 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n dé láti ìgbèkùn jẹ nínú rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ẹni tó dara pọ̀ mọ́ wọn, tó ti ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ kúrò nínú ohun àìmọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ náà láti jọ́sìn* Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+ 22 Wọ́n tún fi ọjọ́ méje ṣe Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú+ tìdùnnú-tìdùnnú; nítorí Jèhófà ti mú kí wọ́n máa yọ̀, ó sì ti mú kí ọba Ásíríà ṣe ojú rere sí wọn,*+ tí ó fi tì wọ́n lẹ́yìn* lẹ́nu iṣẹ́ ilé Ọlọ́run tòótọ́, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.