Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Òwe
SÓLÓMỌ́NÌ ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì “lè pa ẹgbẹ̀ẹ́dógún òwe.” (1 Àwọn Ọba 4:32) Ǹjẹ́ a lè rí òwe ọlọ́gbọ́n rẹ̀ wọ̀nyẹn kà níbì kankan? Bẹ́ẹ̀ ni, a lè rí i kà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ òwe Sólómọ́nì ló wà nínú ìwé Òwe nínú Bíbélì, èyí tí wọ́n kọ parí ní nǹkan bí ọdún 717 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Orí méjì tó gbẹ̀yìn ìwé Òwe nìkan ni Bíbélì sọ pé àwọn òǹkọ̀wé míì kọ, ìyẹn Ágúrì ọmọ Jákè àti Lémúẹ́lì Ọba. Àmọ́ ṣá o, àwọn kan gbà pé Sólómọ́nì náà ló ń jẹ́ Lémúẹ́lì.
Ìdí pàtàkì méjì làwọn tó kọ ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí tó wà nínú ìwé Òwe fi kọ ọ́. Wọ́n kọ ọ́ “fún ènìyàn láti mọ ọgbọ́n àti ìbáwí.” (Òwe 1:2) Ọ̀rọ̀ inú ìwé Òwe máa ń fúnni lọ́gbọ́n, ìyẹn ni pé èèyàn á lè máa rí òye nǹkan kedere á sì máa lo ìmọ̀ tó ní láti fi yanjú ìṣòro. Ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn tún máa ń bá wa wí, tàbí pé wọ́n ń tọ́ wa sọ́nà. Tá a bá ń fiyè sí àwọn òwe inú rẹ̀ tá a sì ń fi ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò, yóò nípa lórí ọkàn wa, ìyẹn yóò sì jẹ́ ká lè máa láyọ̀, ká sì tún ṣàṣeyọrí sí rere.—Hébérù 4:12.
‘NÍ ỌGBỌ́N KÓ O SÌ DI ÌBÁWÍ MÚ’
Sólómọ́nì sọ pé: “Ọgbọ́n tòótọ́ ń ké sókè ní ojú pópó gan-an.” (Òwe 1:20) Kí nìdí tó fi yẹ ká fetí sí ohùn rẹ̀ tó ń dún ketekete? Orí kejì sọ ọ̀pọ̀ àǹfààní tó wà nínú níní ọgbọ́n. Orí kẹta sì sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà tá a lè gbà sún mọ́ Jèhófà tímọ́tímọ́. Sólómọ́nì tún sọ pé: “Ọgbọ́n ni ohun ṣíṣe pàtàkì jù lọ. Ní ọgbọ́n; pẹ̀lú gbogbo ohun tí o sì ní, ní òye. Di ìbáwí mú; má ṣe jẹ́ kí ó lọ.”—Òwe 4:7, 13.
Kí ló máa jẹ́ ká lè kọ onírúurú ìṣekúṣe inú ayé? Òwe orí karùn-ún jẹ́ ká mọ̀ ọ́n. Ó sọ pé ká jẹ́ onírònú ẹ̀dá, ká mọ àwọn ọ̀nà ẹ̀tàn tí ayé fi ń múni, ká sì máa ronú jinlẹ̀ nípa àkóbá tí ìṣekúṣe ń ṣe fúnni. Orí kẹfà wá kìlọ̀ fún wa nípa àwọn ìwà àti ìṣe tó lè ba àjọṣe ẹni pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Orí keje jẹ́ ká mọ ọ̀nà tí oníṣekúṣe ẹ̀dá gbà ń dẹkùn múni. Ọ̀nà tó fani mọ́ra gan-an ni orí kẹjọ gbà sọ fún wa pé ọgbọ́n dára ó sì ṣeyebíye gan-an. Orí kẹsàn-án tí Sólómọ́nì fi ṣe àkópọ̀ àwọn òwe tó ti ń bá bọ̀ lọ́nà tó wúni lórí, lo àpèjúwe tó tani jí láti fi rọ̀ wá pé ká ní ọgbọ́n.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
1:7; 9:10—Báwo ni ìbẹ̀rù Jèhófà ṣe jẹ́ “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìmọ̀” àti “ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n”? Ẹni tí kò bá bẹ̀rù Jèhófà kò lè ní ìmọ̀, torí pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo, òun ló sì ni Ìwé Mímọ́. (Róòmù 1:20; 2 Tímótì 3:16, 17) Òun gan-an ni Orísun gbogbo ojúlówó ìmọ̀. Nítorí náà, ìgbà téèyàn bá bẹ̀rù Jèhófà tó sì ń bọ̀wọ̀ fún un lèèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìmọ̀. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run sì tún jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n ní ti pé ẹni tí kò bá ní ìmọ̀ kò lè ní ọgbọ́n. Yàtọ̀ síyẹn, ẹni tí kò bá ní ìbẹ̀rù Jèhófà kò ní lo ìmọ̀ tó bá ní láti fi gbé Ẹlẹ́dàá ga.
5:3—Kí nìdí tí ẹsẹ Bíbélì yìí fi pe aṣẹ́wó ní “àjèjì obìnrin”? Ìwé Òwe 2:16, 17 sọ pé àjèjì obìnrin jẹ́ ẹni tó “ti gbàgbé májẹ̀mú Ọlọ́run rẹ̀.” Àjèjì làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ka ẹni tó bá ń bọ̀rìṣà sí àtẹni tó mọ̀ọ́mọ̀ má pa Òfin Mósè mọ́ àtẹni tó jẹ́ aṣẹ́wó.—Jeremáyà 2:25; 3:13.
7:1, 2—Kí làwọn ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí pè ní “àwọn àsọjáde mi” àti “àwọn àṣẹ mi”? Yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀kọ́ inú Bíbélì, ohun tó tún wà níbẹ̀ ni àwọn òfin tàbí ìlànà ìdílé táwọn òbí là kalẹ̀ fún àǹfààní ìdílé wọn. Àwọn ọmọ ní láti máa tẹ̀ lé àwọn nǹkan wọ̀nyí àtàwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì míì táwọn òbí wọn bá kọ́ wọn.
8:30—Ta ni “àgbà òṣìṣẹ́” náà? Ẹnì kan ni ọgbọ́n tó sọ̀rọ̀ nínú ẹsẹ Bíbélì yìí dúró fún, ó sì sọ pé àgbà òṣìṣẹ́ lòun. Kì í ṣe pé ẹni tó kọ ìwé Bíbélì yìí kàn lo ọ̀rọ̀ náà ọgbọ́n lónírúurú ọ̀nà tó wúni lórí láti fi ṣàlàyé àwọn ohun tá a lè fi ọgbọ́n ṣe o. Jésù Kristi àkọ́bí Ọmọ Ọlọ́run ni ọgbọ́n yìí dúró fún, ìyẹn kó tó di pé ó wá gbé láàárín àwa èèyàn lórí ilẹ̀ ayé. Tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí wọ́n tó bí Jésù gẹ́gẹ́ bí èèyàn lórí ilẹ̀ ayé ni Jèhófà ti ‘ṣẹ̀dá rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ọ̀nà Ọlọ́run.’ (Òwe 8:22) Jésù tó jẹ́ “àgbà òṣìṣẹ́” yìí bá Baba rẹ̀ ṣiṣẹ́ gidi gan-an nígbà tí Ọlọ́run ń ṣẹ̀dá gbogbo nǹkan.—Kólósè 1:15-17.
9:17—Kí ni ọ̀rọ̀ náà “omi tí a jí” túmọ̀ sí, kí sì nìdí tó fi ń “dùn”? Bíbélì fi ìgbádùn ìbálòpọ̀ láàárín tọkọtaya wé bí ìgbà téèyàn ń mu omi kànga tó tuni lára. Nítorí náà, omi tí a jí yìí dúró fún ṣíṣe ìṣekúṣe níkọ̀kọ̀. (Òwe 5:15-17) Bí onítọ̀hún ṣe rí ìṣekúṣe yẹn ṣe ní bòókẹ́lẹ́ tó sì dà bíi pé àṣírí rẹ̀ ò tú ló jẹ́ kó dà bíi pé ó dùn.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:10-14. Kò yẹ ká jẹ́ kí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ fi ìlérí pé a máa di ọlọ́rọ̀ tàn wá sínú ìwàkiwà wọn.
3:3. Ó yẹ ká wo inú rere onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun tó ṣe pàtàkì gan-an, ká sì jẹ́ kí nǹkan méjèèjì yìí máa hàn kedere nínú ìwà wa bí ìgbà téèyàn fi ìlẹ̀kẹ̀ iyebíye sọ́rùn. A tún ní láti kọ wọ́n sínú ọkàn wa, ìyẹn ni pé ká rí i pé wọ́n mọ́ wa lára.
4:18. Ńṣe ni ìmọ̀ nípa ìjọsìn Ọlọ́run ń tẹ̀ síwájú sí i. Tá a bá fẹ́ máa wà nínú ìmọ́lẹ̀ yìí nìṣó, a gbọ́dọ̀ ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ká sì jẹ́ ọlọ́kàn tútù.
5:8. A gbọ́dọ̀ jìnnà sí gbogbo ohun tó bá jẹ mọ́ ìṣekúṣe, yálà nínú orin, nínú eré ìnàjú, lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí nínú àwọn ìwé ìròyìn àtàwọn ìwé míì.
5:21. Ǹjẹ́ ẹni tó fẹ́ràn Jèhófà máa jẹ́ fi ìgbádùn ìgbà kúkúrú ba àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́? Rárá o! Olórí ohun tó lè mú ká fẹ́ láti máa bá ìwà mímọ́ nìṣó ni mímọ̀ pé Jèhófà ń rí gbogbo ohun tá à ń ṣe àti pé a máa jíhìn fún un.
6:1-5. Ìmọ̀ràn àtàtà gbáà làwọn ẹsẹ Bíbélì yìí fún wa o pé ká má lọ “ṣe onídùúró” fún ẹlòmíì, ìyẹn ni pé ká má lọ tìtorí ẹlòmíì tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn òwò tí kò bọ́gbọ́n mu! Tá a bá ṣàyẹ̀wò síwájú sí i lẹ́yìn tá a ti tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn kan, tó wá jọ pé ohun tá a ṣe yẹn ò bọ́gbọ́n mu, ńṣe ni ká tètè ‘bẹ ọmọnìkejì wa ní ẹ̀bẹ̀ àbẹ̀ẹ̀dabọ̀,’ ká sì rí i dájú pé a ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ.
6:16-19. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé àkópọ̀ gbogbo ìwàkiwà pátá ni nǹkan méjèèje tí Bíbélì sọ níbí yìí jẹ́. Ó yẹ ká kórìíra wọn pátápátá.
6:20-24. Tí òbí bá fi òfin Ọlọ́run tọ́ ọmọ rẹ̀ láti kékeré, ó lè máà jẹ́ kó kó sí pańpẹ́ ìṣekúṣe. Kò yẹ kí àwọn òbí fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀ràn kíkọ́ ọmọ wọn nírú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀.
7:4. Ó yẹ ká fẹ́ràn ọgbọ́n àti òye gidigidi.
ÀWỌN ÒWE KỌ̀Ọ̀KAN TÓ WÀ FÚN ÌTỌ́SỌ́NÀ WA
Ṣókí-ṣókí làwọn òwe Sólómọ́nì yòókù. Ńṣe ló kàn lo àwọn ìyàtọ̀, ìjọra àtàwọn àfiwé tó wà nínú àwọn nǹkan láti fi kọ́ni láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì nípa ìwà híhù, ọ̀rọ̀ sísọ àti ìṣe ẹni.
Orí kẹwàá títí dé orí kẹrìnlélógún tẹnu mọ́ ọn pé ó ṣe pàtàkì láti bẹ̀rù Jèhófà látọkànwá. “Àwọn ọkùnrin Hesekáyà ọba Júdà” ló da àwọn òwe tó wà nínú orí kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n títí dé orí kọkàndínlọ́gbọ̀n kọ. (Òwe 25:1) Àwọn òwe wọ̀nyí kọ́ wa pé ká gbára lé Jèhófà, wọ́n sì tún kọ́ wa láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì míì.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
10:6.—Báwo ni ‘ẹnu àwọn ẹni burúkú ṣe ń bo ìwà ipá mọ́lẹ̀’? Bí èyí ṣe lè rí bẹ́ẹ̀ ni pé ńṣe làwọn ẹni burúkú máa ń fi ọ̀rọ̀ dídùn-dídùn bojú láti hùwà ìkà. Ó sì tún lè jẹ́ pé kíkanra táwọn èèyàn máa ń kanra mọ́ àwọn ẹni burúkú ló pa wọ́n lẹ́nu mọ́.
10:10—Báwo ni ‘ẹni tí ń ṣẹ́jú’ ṣe ń fa ìrora? Yàtọ̀ sí pé “ènìyàn tí kò dára fún ohunkóhun” máa ń sọ “ọ̀rọ̀ wíwọ́” nígbà míì, ó tún máa ń dọ́gbọ́n fi ìṣesí rẹ̀ bojú káwọn èèyàn má bàa mọ ohun tó fẹ́ ṣe, irú ìṣesí bẹ́ẹ̀ ni ‘ṣíṣẹ́jú.’ (Òwe 6:12, 13) Irú ẹ̀tàn bẹ́ẹ̀ lè kó ìdààmú tó pọ̀ bá àwọn tó bá kó sí i lọ́wọ́.
10:29—Kí ni “ọ̀nà Jèhófà”? Ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń bá ọmọ aráyé lò ló túmọ̀ sí, kì í ṣe ọ̀nà tó yẹ ká gbà gbé ìgbésí ayé wa ló ń sọ. Ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń bá ọmọ èèyàn lò máa ń yọrí sí ààbò fáwọn aláìlẹ́bi ṣùgbọ́n ìparun ló ń yọrí sí fáwọn ẹni ibi.
11:31—Kí nìdí tí wọ́n fi máa san ẹni burúkú lẹ́san ju olódodo lọ? Ìwọ̀n ìyà ẹ̀ṣẹ̀ kálukú wọn nibí yìí ń sọ. Tí olódodo bá ṣàṣìṣe, ìbáwí ni wọ́n máa fi san án lẹ́san. Àmọ́ ńṣe ni ẹni burúkú máa ń mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ ní tiẹ̀, kò sì ní ronú pìwà dà kó lè máa ṣe rere. Nítorí náà, ìyà ńlá tó tọ́ sí i ló máa ń gbà.
12:23—Báwo lèèyàn ṣe “ń bo ìmọ̀”? Bíbo ìmọ̀ tíbí yìí ń sọ kò túmọ̀ sí pé èèyàn ò jẹ́ kó hàn rárá pé òun ní ìmọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó túmọ̀ sí ni pé kéèyàn fi òye lo ìmọ̀ rẹ̀, kó má ṣe jẹ́ kí ìgbéraga mú kóun máa fi ìmọ̀ òun ṣe àṣehàn.
14:17—Ọ̀nà wo làwọn èèyàn gbà ń kórìíra “ènìyàn tí ó ní agbára láti ronú”? Lédè Hébérù, ọ̀rọ̀ tá a tú sí “agbára láti ronú” lè túmọ̀ sí kéèyàn ní ìfòyemọ̀ tàbí kéèyàn máa gbèrò ìkà. Kò sí àní-àní pé àwọn èèyàn máa ń kórìíra elétekéte èèyàn. Ṣùgbọ́n bẹ́ẹ̀ náà làwọn èèyàn ṣe ń kórìíra olóye èèyàn tó ti ronú dáadáa kó tó pinnu pé òun ò ní jẹ́ “apá kan ayé.”—Jòhánù 15:19.
18:19—Báwo ni ‘arákùnrin tí a hùwà ìrélànàkọjá sí ṣe ju ìlú tí ó lágbára’? Ẹni yẹn lè má gbà láti dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ ẹ́, àní gẹ́gẹ́ bí ìlú alágbára tí wọ́n gbógun tì kì í ṣeé gbà káwọn ọ̀tá wọlé. Ó lè máà pẹ́ kí aáwọ̀ àárín òun àti ẹni tó ṣẹ̀ ẹ́ tó di ohun ìdènà bí “ọ̀pá ìdábùú ilé gogoro ibùgbé.”
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
10:11-14. Tá a bá fẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa máa gbéni ró, a ní láti gba ìmọ̀ pípéye sínú ọkàn wa dáadáa, ká rí i pé ìfẹ́ àtọkànwá ló ń mú wa ṣe nǹkan, ká sì tún rí i pé ọ̀rọ̀ tó mọ́gbọ́n dání là ń sọ lẹ́nu.
10:19; 12:18; 13:3; 15:28; 17:28. Ó yẹ ká máa ronú ká tó sọ̀rọ̀, ká sì máa jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa mọ níwọ̀n.
11:1; 16:11; 20:10, 23. Jèhófà fẹ́ ká jẹ́ olóòótọ́ nídìí òwò wa.
11:4. Ìwà òmùgọ̀ ló jẹ́ láti tìtorí ìlépa ọrọ̀ máa pa ìpàdé tàbí òde ẹ̀rí jẹ, ká má sì ráyè fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ nínú Bíbélì àti àdúrà gbígbà.
13:4. Kéèyàn kàn “fọkàn fẹ́” pé kí wọ́n yan òun sípò ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ tàbí pé kóun dénú ayé tuntun nìkan kò tó. Èèyàn tún gbọ́dọ̀ jẹ́ òṣìṣẹ́ aláápọn kó sì sapá gidigidi láti kúnjú òṣùwọ̀n ohun táá jẹ́ kí nǹkan wọ̀nyẹn ṣeé ṣe.
13:24; 29:15, 21. Òbí tó bá fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ kò ní kẹ́ ẹ ní àkẹ́jù kò sì ní ṣàìka àwọn àṣìṣe rẹ̀ sí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ kí bàbá tàbí ìyá máa bá ọmọ wọn wí kó lè jáwọ́ nínú ìwàkiwà kó tó mọ́ ọn lára.
14:10. Nítorí pé ìgbà gbogbo kọ́ la máa ń lè sọ bí ohun tó ń ṣe wá nínú ara ṣe rí gẹ́lẹ́, tí àwọn tó ń rí wa sì lè má lóye bí nǹkan ṣe ń rí lára wa nígbà míì, ìwọ̀nba lohun táwọn èèyàn lè ṣe láti tù wá nínú. Jèhófà nìkan la ní láti gbára lé nígbà tá a bá ń bá àwọn ìṣòro míì yí.
15:7. Kò yẹ kó jẹ́ pé gbogbo ohun tá a mọ̀ la máa sọ tán fẹ́nì kan lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, àní gẹ́gẹ́ bí àgbẹ̀ kì í ṣeé da gbogbo irúgbìn rẹ̀ sójú kan ṣoṣo. Díẹ̀díẹ̀ ni ọlọ́gbọ́n máa ń tan ìmọ̀ rẹ̀ kálẹ̀ bó bá ṣe rí i pé ó yẹ.
15:15; 18:14. Tá a bá ń ní èrò pé nǹkan ṣì ń bọ̀ wá dáa, a ó máa láyọ̀, àní bá a tiẹ̀ wà nínú ìṣòro pàápàá.
17:24. Kò yẹ ká ṣe bíi ti “arìndìn” èèyàn tó jẹ́ pé ojú rẹ̀ kì í gbébìkan dípò kó pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì. Ńṣe ni ká máa wá òye ká lè máa hùwà ọlọ́gbọ́n.
23:6-8. A gbọ́dọ̀ yẹra fún ṣíṣe ojú ayé tá a bá ń ṣàlejò.
27:21. Ìyìn lè fi irú ẹni tá a jẹ́ hàn. Tá a bá fi ọpẹ́ àṣeyọrí wa fún Jèhófà nígbà táwọn èèyàn bá yìn wá, tí ìyìn yẹn sì mú ká máa bá a lọ láti sin Jèhófà, a jẹ́ pé onírẹ̀lẹ̀ ni wá. Ṣùgbọ́n tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ́ńbẹ́lú àwọn míì nítorí pé àwọn èèyàn ń yìn wá, ńṣe nìyẹn máa fi hàn pé agbéraga ni wá.
27:23-27. Àwọn òwe yìí lo àpẹẹrẹ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lágbo àwọn olùṣọ́ àgùntàn láti fi jẹ́ kó yé wa pé téèyàn ò bá lépa nǹkan ńláńlá, tí ò ya ọ̀lẹ, tó sì nítẹ̀ẹ́lọ́rùn, èèyàn á jàǹfààní gan-an. Wọ́n sì tún jẹ́ ká rí i kedere pé ó ṣe pàtàkì pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run.a
28:5. Bá a bá ń gbàdúrà, tá a sì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti lè “wá Jèhófà,” a óò “lè lóye ohun gbogbo” tó yẹ ká mọ̀ láti lè sin Ọlọ́run lọ́nà tí yóò tẹ́wọ́ gbà.
‘ÀWỌN ÌHÌN IṢẸ́ TÓ WÚWO’
“Ìhìn iṣẹ́ wíwúwo,” tàbí ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀, méjì ló parí Ìwé Òwe. (Òwe 30:1; 31:1) Ágúrì lo àwọn àfiwé tó ń múni ronú jinlẹ̀ láti fi jẹ́ ká rí i pé oníwọra kì í ní ìtẹ́lọ́rùn àti láti fi jẹ́ ká rí i pé ọ̀nà tí ẹlẹ̀tàn ẹ̀dá gbà ń tan omidan jẹ ṣòroó lóye.b Ó tún kìlọ̀ fún wa pé ká má ṣe jẹ́ agbéraga àtẹni tó ń sọ̀rọ̀ ìbínú.
Ìmọ̀ràn tó jíire ló wà nínú ìhìn iṣẹ́ wíwúwo tí ìyá Lémúẹ́lì sọ fún un nípa ìlò wáìnì àti ọtí líle àti bó ṣe yẹ kó máa ṣèdájọ́ òdodo. Ọ̀rọ̀ tó fi parí àkàwé rẹ̀ nípa obìnrin rere ni pé: “Ẹ fún un lára èso ọwọ́ rẹ̀, kí àwọn iṣẹ́ rẹ̀ sì máa yìn ín ní àwọn ẹnubodè pàápàá.”—Òwe 31:31.
Ẹ̀kọ́ ńlá gbáà ni àwọn òwe tí Ọlọ́run mí sí yìí kọ́ni o! Wọ́n kọ́ wa pé ó yẹ ká ní ọgbọ́n, ká máa gba ìbáwí, ká bẹ̀rù Ọlọ́run ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká rí i dájú pé à ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn wọ̀nyẹn, ká lè ní ayọ̀ tí “ènìyàn tí ó bẹ̀rù Jèhófà” máa ń ní.—Sáàmù 112:1.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Jèhófà ni Orísun gbogbo ojúlówó ìmọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Kí ni “títan ìmọ̀ kálẹ̀” túmọ̀ sí?