“Gbogbo Ẹni Tí Ó Jẹ́ Afọgbọ́nhùwà Yóò Fi Ìmọ̀ Hùwà”
ÌTỌ́SỌ́NÀ tó bá wá láti inú Bíbélì tí í ṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ‘yẹ ní fífẹ́ ju wúrà, àní, ju ọ̀pọ̀ wúrà tí a yọ́ mọ́.’ (Sáàmù 19:7-10) Kí nìdí tó fi yẹ ní fífẹ́? Nítorí pé “òfin ọlọ́gbọ́n [Jèhófà] jẹ́ orísun ìyè, láti yí ènìyàn padà kúrò nínú àwọn ìdẹkùn ikú.” (Òwe 13:14) Nígbà tá a bá fi ìmọ̀ràn inú Ìwé Mímọ́ sílò, kì í wulẹ̀ ṣe pé á mú kí ìgbésí ayé wa sàn sí i nìkan ni, ṣùgbọ́n á tún ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún àwọn ìdẹkùn tó lè fẹ̀mí wa wewu. Ẹ ò wá rí i bó ṣe ṣe kókó tó láti wá ìmọ̀ inú Ìwé Mímọ́ ká sì máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú ohun tá à ń kọ́!
Gẹ́gẹ́ bó ti wà lákọọ́lẹ̀ nínú Òwe 13:15-25, Sólómónì, ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì, fún wa ní àmọ̀ràn tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti fi ìmọ̀ hùwà kí ayé wa lè dára kí ẹ̀mí wa sì gùn.a Nípa lílo àwọn òwe ṣókí ṣókí, ó jẹ́ ká rí bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti rí ojú rere àwọn ẹlòmíì, bá a ṣe lè máa bá a lọ ní jíjẹ́ olóòótọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, bá a ṣe lè máa fojú tó tọ́ wo ìbáwí àti bá a ṣe lè fọgbọ́n yan àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wa. Lára ohun tó tún gbé yẹ̀ wò ni ọgbọ́n tó wà nínú fífi ogún sílẹ̀ fáwọn ọmọ wa àti bá a ṣe lè máa fi ìfẹ́ bá wọn wí.
Ìjìnlẹ̀ Òye Rere Ń Múni Rí Ojú Rere
Sólómọ́nì sọ pé, “ìjìnlẹ̀ òye rere ń fúnni ní ojú rere, ṣùgbọ́n págunpàgun ni ọ̀nà àwọn tí ń ṣe àdàkàdekè.” (Òwe 13:15) Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú ẹ̀ sọ pé èdè tí wọ́n pilẹ̀ máa ń lò fún “ìjìnlẹ̀ òye rere,” tàbí òye rere, “ṣàpèjúwe agbára tí ẹnì kan ní láti lo agbára ìmòye rere, ìrònú yíyè kooro àti èrò ọlọgbọ́n.” Kì í ṣòro fún ẹnì kan tó nírú àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀ láti rí ojúure àwọn ẹlòmíràn.
Ìwọ wo ìjìnlẹ̀ òye tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi bá Fílémónì tó jẹ́ Kristẹni bíi tiẹ̀ lò nígbà tó ń rán Ónẹ́símù, ẹrú rẹ̀ tó sá kúrò nílé ṣùgbọ́n tó ti di Kristẹni, padà sí i. Pọ́ọ̀lù gba Fílémónì níyànjú pé kó finú rere gba Ónẹ́símù padà, bí yóò ṣe gba òun tọwọ́ tẹsẹ̀. Kódà, Pọ́ọ̀lù sọ pé bí Ónẹ́símù bá jẹ Fílémónì ní ohunkóhun, òun ṣe tán láti san án. Pọ́ọ̀lù lágbára láti lo ọlá àṣẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì kó sì pàṣẹ fún Fílémónì pé kó ṣe ohun tó tọ́. Ṣùgbọ́n àpọ́sítélì náà yàn láti fi ìfẹ́ àti ọgbọ́n bójú tó ọ̀ràn náà. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé Fílémónì ò ní kọ̀rọ̀ sí òun lẹ́nu, kódà á ṣe kọjá ohun tí òun ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Ǹjẹ́ kò yẹ kí àwa náà máa bá àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ lò lọ́nà yìí?—Fílémónì 8-21.
Àmọ́, ní ti àwọn tí ń ṣe àdàkàdekè, ńṣe ni ọ̀nà wọ́n rí págunpàgun, ìyẹn ni pé ó le koko. Lọ́nà wo? Gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ṣe sọ, èyí túmọ̀ sí ohun tó “lágbára tàbí tó le koránkorán, ó sì ń sọ nípa ìwà ọ̀dájú táwọn èèyàn búburú máa ń hù. . . . Bí ọkùnrin kan bá kọ̀ láti jáwọ́ nínú ibi ṣíṣe, tó dájú gbáú tí kò sì bìkítà nípa ìtọ́ni ọlọgbọ́n táwọn ẹlòmíì ń fún un, ọ̀nà ìparun ló forí lé yẹn.”
Sólómọ́nì ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “Gbogbo ẹni tí ó jẹ́ afọgbọ́nhùwà yóò fi ìmọ̀ hùwà, ṣùgbọ́n ẹni tí ó jẹ́ arìndìn yóò tan ìwà òmùgọ̀ káàkiri.” (Òwe 13:16) Afọgbọ́nhùwà tá à ń sọ níbí kì í ṣe alárèékérekè ẹ̀dá o. Ìfọgbọ́nhùwà tó ní í ṣe pẹ̀lú ìmọ̀ là ń sọ̀rọ̀ rẹ̀, ọlọgbọ́n èèyàn tó máa ń ro nǹkan kó tó ṣe é ló sì máa ń ní in. Bí wọ́n bá ń ṣe lámèyítọ́ ẹni tó jẹ́ afọgbọ́nhùwà láìtọ́ tàbí tí wọ́n ń bú u, ńṣe ló máa kó ahọ́n ara rẹ̀ níjàánu. Á gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ kó bàa lè lo èso ẹ̀mí mímọ́ kí inú má bàa bí i sódì. (Gálátíà 5:22, 23) Ẹni tó gbọ́n kì í jẹ́ kí àwọn ẹlòmíì tàbí bí ipò nǹkan ṣe rí darí òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìkáwọ́ rẹ̀ ni ohun tó ń ṣẹlẹ̀ wà, ó sì máa ń tipa bẹ́ẹ̀ yẹra fún èdè àìyedè tó máa ń wáyé bí ẹnì kan bá tètè máa ń fara ya nígbà tí wọ́n bá ṣẹ̀ ẹ́.
Ọlọgbọ́n èèyàn tún máa ń fi ìmọ̀ hùwà nígbà tó bá ń ṣe ìpinnu. Ó mọ̀ pé ṣíṣe ohun tó mọ́gbọ́n dání kì í ṣe ọ̀ràn èyí-jẹ́-èyí-ò-jẹ, kì í wáyé nípa wíwulẹ̀ ṣe ohun tó bá ṣáà ti sọ síni lọ́kàn, tàbí wíwulẹ̀ ṣe ohun táwọn ẹlòmíì bá ń ṣe. Ìdí nìyẹn tó fi máa ń fara balẹ̀ yẹ ipò tó bá bá ara rẹ̀ wò dáadáa. Ó máa ń ṣàgbéyẹ̀wò gbogbo nǹkan tó bá yí ọ̀rọ̀ kan ká, á sì pinnu onírúurú ọ̀nà tí òun lè gbé nǹkan gbà. Lẹ́yìn náà, á ṣàyẹ̀wò ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ, á sì pinnu àwọn òfin tàbí ìlànà Bíbélì tí òun lè lò. Ipa ọ̀nà irú ẹni bẹ́ẹ̀ á máa tọ́ ni lọ́jọ́ gbogbo.—Òwe 3:5, 6.
“Olùṣòtítọ́ Aṣojú Jẹ́ Ìmúniláradá”
Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìkáwọ́ wa ni Ọlọ́run fi pípolongo ìhìn iṣẹ́ rẹ̀ sí. Ọ̀rọ̀ tó kàn nínú ìwé Òwe á sì ràn wá lọ́wọ́ tá ò fi ní sá kúrò nídìí iṣẹ́ tá a gbé lé wa lọ́wọ́. Ó sọ pé: “Ońṣẹ́ tí ó jẹ́ ẹni burúkú yóò já sínú ohun búburú, ṣùgbọ́n olùṣòtítọ́ aṣojú jẹ́ ìmúniláradá.”—Òwe 13:17.
Àwọn ànímọ́ tí ońṣẹ́ náà ní là ń pàfiyèsí sí níbí yìí. Bí ẹni tá a rán níṣẹ́ bá fìkà ṣèrú tàbí tó yí iṣẹ́ tá a rán an padà ńkọ́? Ǹjẹ́ kò ní gba ìdájọ́ líle koko báyìí? Ronú nípa ìránṣẹ́ wòlíì Èlíṣà, Géhásì, tó fi ìwọra jíṣẹ́ èké fún Náámánì, olórí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Síríà. Ara Géhásì ni ẹ̀tẹ̀ tí wọ́n wò sàn lára Náámánì lẹ̀ mọ́. (2 Àwọn Ọba 5:20-27) Bí aṣojú bá wá di aláìṣòótọ́ ńkọ́, tí ò sì polongo ìhìn iṣẹ́ tá a fi rán an mọ́? Bíbélì sọ pé: “[Bí] ìwọ kò [bá] sọ̀rọ̀ ní tòótọ́ láti kìlọ̀ fún ẹni burúkú náà pé kí ó kúrò ní ọ̀nà rẹ̀, òun alára gẹ́gẹ́ bí ẹni burúkú yóò kú nínú ìṣìnà rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ni èmi [Jèhófà] yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ.”—Ìsíkíẹ́lì 33:8.
Ti olùṣòtítọ́ aṣojú ò rí bẹ́ẹ̀ ṣá o, ìmúniláradá ló jẹ́ fún ara rẹ̀ àti fún àwọn tó ń fetí sílẹ̀ sí i. Pọ́ọ̀lù gba Tímótì níyànjú pé: “Máa fiyè sí ara rẹ nígbà gbogbo àti sí ẹ̀kọ́ rẹ. Dúró nínú nǹkan wọ̀nyí, nítorí nípa ṣíṣe èyí, ìwọ yóò gba ara rẹ àti àwọn tí ń fetí sí ọ là.” (1 Tímótì 4:16) Ronú nípa ìmúláradá tó ti wáyé nípa pípolongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tọkàntọkàn. Ó ń ta àwọn èèyàn tó ní ọkàn rere jí ó sì ń darí wọn sí òtítọ́ tó ń sọ wọ́n dòmìnira. (Jòhánù 8:32) Kódà, báwọn èèyàn bá kọ etí ikún sí ìhìn iṣẹ́ náà, ońṣẹ́ tó jẹ́ adúróṣinṣin “yóò dá ọkàn [rẹ̀] nídè dájúdájú.” (Ìsíkíẹ́lì 33:9) Ǹjẹ́ ká má ṣe kùnà láé láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù tá a gbé lé wa lọ́wọ́. (1 Kọ́ríńtì 9:16) Ẹ sì jẹ́ ká fìṣọ́ra ṣe ká lè máa “wàásù ọ̀rọ̀ náà” nígbà gbogbo, ká má ṣe bomi là á tàbí ká ki àsọdùn bọ̀ ọ́ káwọn èèyàn lè máa tẹ́tí sí wa.—2 Tímótì 4:2.
‘Ẹni Tí Ń Pa Ìbáwí Àfitọ́nisọ́nà Mọ́ Lẹni Tá A Ṣe Lógo’
Ṣé ó yẹ kí ọlọgbọ́n èèyàn bínú sí ìmọ̀ràn èyíkéyìí tó lè ràn án lọ́wọ́ tó bá rí gbà? Òwe 13:18 sọ pé: “Ẹni tí ó ṣàìnáání ìbáwí bọ́ sí ipò òṣì àti àbùkù, ṣùgbọ́n ẹni tí ó pa ìbáwí àfitọ́nisọ́nà mọ́ ni ẹni tí a ṣe lógo.” Ó mọ́gbọ́n dání pé ká fìmọrírì gba ìbáwí tẹ́nì kan kàn ṣàdéédéé fún wa. Ó lè jẹ́ pé ìgbà tá ò tiẹ̀ fọkàn sí rárá ni irú ìbáwí ṣíṣe wẹ́kú bẹ́ẹ̀ máa ràn wá lọ́wọ́ jù lọ. Fífetí sí irú ìbáwí bẹ́ẹ̀ ò ní jẹ́ ká ní ìrora ọkàn ó sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún àjálù. Kíkọ ìbáwí á mú ká kan àbùkù.
Yinniyinni ní í mú kẹ́ni ṣèmíì o. Ṣùgbọ́n, ó yẹ ká máa retí ìbáwí ká sì múra tán láti gbà á. Gbé àwọn lẹ́tà méjì tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì yẹ̀ wò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó gbóríyìn fún un nínú lẹ́tà náà nítorí ìṣòtítọ́ rẹ̀, lẹ́tà náà kún fún àwọn ọ̀rọ̀ ìyànjú tó gba Tímótì. Pọ́ọ̀lù ò ṣẹ́nu po bó ti ń gba ọ̀dọ́mọkùnrin náà níyànjú nípa dídi ìgbàgbọ́ àti ẹ̀rí ọkàn rere mú, bíbá àwọn ẹlòmíràn lò nínú ìjọ, níní ìfọkànsìn Ọlọ́run àti ẹ̀mí ohun-moní-tómi, fífún àwọn mìíràn ní ìtọ́sọ́nà, yíyẹra fún àwọn apẹ̀yìndà àti ṣíṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Ńṣe ló yẹ káwọn ọ̀dọ́ nínú ìjọ máa retí ìmọ̀ràn látọ̀dọ̀ àwọn tó nírìírí jù wọ́n lọ kí wọ́n sì máa gba irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀.
“Bá Àwọn Ọlọ́gbọ́n Rìn”
Ọlọgbọ́n ọba náà sọ pé: “Ìfẹ́-ọkàn, nígbà tí a bá rí ìmúṣẹ rẹ̀, yóò dùn mọ́ ọkàn; ṣùgbọ́n ó jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú àwọn arìndìn láti yí padà kúrò nínú ohun búburú.” (Òwe 13:19) Ní ti ohun tí òwe yìí túmọ̀ sí, ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Bọ́wọ́ ẹnì kan bá tẹ ohun tó ń wá tàbí tí ọ̀rọ̀ bá rí bí ẹnì kan ṣe rò ó lọ́kàn, ńṣe ni inú rẹ̀ á dùn tí ara rẹ̀ á sì yá gágá . . . Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé bọ́wọ́ èèyàn bá tẹ ohun tó ń lé, ó máa ń mú kínú ẹni dùn, kí ara ẹni sì yá gágá, a jẹ́ pé láti yí padà kúrò nínú ohun búburú gbọ́dọ̀ jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lójú àwọn òmùgọ̀. Àyàfi bí wọ́n bá gbé nǹkan gba ọ̀nà búburú nìkan ni wọ́n tó lè mú ìfẹ́ ọkàn wọn ṣẹ, bí wọ́n bá sì kọ ohun búburú sílẹ̀ pẹ́nrẹ́n, a jẹ́ pé wọ́n á pàdánù ayọ̀ tí wọn ì bá ní ká sọ pé ọ̀ràn rí bí wọ́n ṣe fẹ́ kó rí nìyẹn.” Kò mà sí ohun tó dà bíi ká máa ní èrò tó dára lọ́kàn o!
Ipa kékeré mà kọ́ làwọn alábàákẹ́gbẹ́ wa máa ń ní lórí ìrònú wa, ohun tá a fẹ́ àti ohun tí a kò fẹ́! Ohun tó máa ń fìgbà gbogbo jẹ́ òtítọ́ ni Sólómọ́nì ń sọ nígbà tó wí pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” (Òwe 13:20) Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn tá à ń bá kẹ́gbẹ́, kódà ì bá à jẹ́ nígbà eré ìnàjú, lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, àti nípasẹ̀ ohun tá à ń kà, máa nípa lórí ohun tá a jẹ́ àti ohun tá a máa jẹ́. Ó mà ṣe pàtàkì gàn-an ni o pé ká fọgbọ́n yan àwọn tá a ó máa bá kẹ́gbẹ́!
“Fi Ogún Sílẹ̀”
Ọba Ísírẹ́lì náà sọ pé: “Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ìyọnu àjálù ń lépa, ṣùgbọ́n àwọn olódodo ni ohun rere ń san lẹ́san.” (Òwe 13:21) Èrè pọ̀ nínú lílépa òdodo, nítorí pé Jèhófà máa ń tọ́jú àwọn olódodo. (Sáàmù 37:25) Àmọ́ ṣá o, a gbọ́dọ̀ mọ̀ pé “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wa. (Oníwàásù 9:11) Ǹjẹ́ a lè ṣe ohunkóhun láti múra sílẹ̀ fún ìṣẹ̀lẹ̀ àìròtẹ́lẹ̀?
Sólómọ́nì sọ pé: “Ẹni rere yóò fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ-ọmọ.” (Òwe 13:22a) Ogún ṣíṣeyebíye gbáà làwọn òbí fi sílẹ̀ bí wọ́n bá ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ nípa Jèhófà kí wọ́n sì ní àjọṣe rere pẹ̀lú rẹ̀! Ṣùgbọ́n, bí àyè ẹ̀ bá yọ, ǹjẹ́ kò tún ní bọ́gbọ́n mu bí àwọn òbí bá ṣètò sílẹ̀ fún àbójútó ìdílé nípa tara bó bá ṣẹlẹ̀ pé irú òbí bẹ́ẹ̀ kú láìròtẹ́lẹ̀? Ní ọ̀pọ̀ ibi, ó lè ṣeé ṣe fáwọn olórí ìdílé láti ṣètò fún ìbánigbófò, kí wọ́n ṣe ìwé ìhágún tó bófin mu, kí wọ́n sì fi owó díẹ̀ pa mọ́.
Kí la lè sọ nípa ogún àwọn ẹni burúkú? Sólómọ́nì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ọlà ẹlẹ́ṣẹ̀ sì jẹ́ ohun tí a tò pa mọ́ fún olódodo.” (Òwe 13:22b) Láfikún sí àǹfààní èyíkéyìí tó lè jẹ́ tirẹ̀ nísinsìnyí, ọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ yìí á rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ nígbà tí Jèhófà bá mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé òun yóò dá “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” nínú èyí tí “òdodo yóò sì máa gbé.” (2 Pétérù 3:13) Ọlọ́run á ti palẹ̀ àwọn ẹni burúkú mọ́, “àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò [sì] ni ilẹ̀ ayé.”—Sáàmù 37:11.
Ọlọgbọ́n èèyàn a máa fòye hùwà, bí ohun tó ní ò tiẹ̀ ju táṣẹ́rẹ́ lọ. Òwe 13:23 sọ pé: “Ilẹ̀ ríro àwọn aláìnílọ́wọ́ ń mú oúnjẹ púpọ̀ gan-an jáde, ṣùgbọ́n ẹnì kan wà tí a gbá lọ nítorí àìní ìdájọ́.” Nípasẹ̀ iṣẹ́ àṣekára àti àbùsí Èdùmàrè, iṣẹ́ ọwọ́ àwọn aláìnílọ́wọ́ lè mú èrè tó pọ̀ wá. Àmọ́ ṣá o, níbi tí kò bá ti sí ìdájọ́ òdodo, ṣíṣe ojúṣàájú lè gbé ọrọ̀ wọgbó.
“Wà Lójúfò Láti Fún Un Ní Ìbáwí”
Ìbáwí tọ́ sí àwọn èèyàn aláìpé, wọ́n sì nílò rẹ̀ látìgbà ọmọdé. Ọba Ísírẹ́lì sọ pé: “Ẹni tí ó fa ọ̀pá rẹ̀ sẹ́yìn kórìíra ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ni ẹni tí ó wà lójúfò láti fún un ní ìbáwí.”—Òwe 13:24.
Ọ̀pá dúró fún ọlá àṣẹ. Nínú Òwe 13:24, ọlá àṣẹ òbí ló dúró fún. Nínú àyíká ọ̀rọ̀ yìí, lílo ọ̀pá ìbáwí ò fi dandan túmọ̀ sí nína ọmọ kan lẹ́gba. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó dúró fún ọ̀nà tá à ń gbà bá ọmọ wí, irú ọ̀nà yòówù kó jẹ́. Ọmọ kan lè wà tó jẹ́ pé fífi ọ̀rọ̀ ẹnu bá a wí ti tó láti dẹ́kun ìwà kan tí kò tọ́. Òmíràn sì wà tó jẹ́ pé ìbáwí líle koko ló máa tọ́ sí i. Òwe 17:10 sọ pé: “Ìbáwí mímúná ń ṣiṣẹ́ jinlẹ̀ nínú ẹni tí ó ní òye ju lílu arìndìn ní ọgọ́rùn-ún ìgbà.”
Ìfẹ́ àti ọgbọ́n táwọn òbí ní fún ire àwọn ọmọ wọn ló gbọ́dọ̀ máa sún wọn nígbà gbogbo láti bá wọn wí. Òbí tó bá nífẹ̀ẹ́ ọmọ ẹ̀ ò jẹ́ gbójú fo àṣìṣe ọmọ náà dá. Kàkà bẹ́ẹ̀, á máa wá àwọn àṣìṣe náà kó lè mú wọn tọ́ kí wọ́n tó di àràbà tápá ò lè ká. Àmọ́ ṣá o, òbí tó nífẹ̀ẹ́ ọmọ ẹ̀ ò jẹ́ gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú Pọ́ọ̀lù pé: “Ẹ̀yin, baba, ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.”—Éfésù 6:4.
Bí òbí kan bá wá gbọ̀jẹ̀gẹ́ tó sì kọ̀ láti fún ọmọ ní ìbáwí yíyẹ ńkọ́? Ṣé irú òbí bẹ́ẹ̀ á gbọpẹ́ fún irú ìwà ìgbọ̀jẹ̀gẹ́ bẹ́ẹ̀ níkẹyìn? Ó tì o! (Òwe 29:21) Bíbélì sọ pé: “Ọmọdékùnrin tí a jọ̀wọ́ rẹ̀ sílẹ̀ fàlàlà yóò máa kó ìtìjú bá ìyá rẹ̀.” (Òwe 29:15) Bí òbí ò bá lo ọlá àṣẹ rẹ̀ bó ṣe yẹ, a jẹ́ pé irú òbí bẹ́ẹ̀ ò bìkítà kò sì nífẹ̀ẹ́. Àmọ́, fífi pẹ̀lẹ́ lo ọlá àṣẹ lọ́nà tí kò fàyè gbàgbàkugbà, fi hàn pé ìfẹ́ ló sún irú òbí bẹ́ẹ̀ láti di ẹni tó bìkítà.
Ọlọgbọ́n àti adúróṣinṣin èèyàn tó jẹ́ pé ìfẹ́ tòótọ́ ló ń sún un láti ṣe àwọn nǹkan yóò rí ìbùkún gbà. Sólómọ́nì mú un dá wa lójú pé: “Olódodo ń jẹ títí yóò fi tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn, ṣùgbọ́n ikùn àwọn ẹni burúkú yóò ṣófo.” (Òwe 13:25) Jèhófà mọ ohun tó yẹ wá ní apá èyíkéyìí nínú ìgbésí ayé wa, ì báà jẹ́ nínú ọ̀ràn ìdílé, nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn, nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, tàbí nígbà tí wọ́n bá ń bá wa wí. Bá a bá sì ń fi àwọn ìmọ̀ràn inú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sílò, ó dájú hán-ún hán-ún pé a óò gbádùn ìgbésí ayé tó dára jù lọ.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ìjíròrò lórí Òwe 13:1-14, wo ojú ìwé 21 sí 25 nínú ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ September 15, 2003.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Bí wọ́n bá ń ṣe lámèyítọ́ ẹni tó jẹ́ afọgbọ́nhùwà láìtọ́, ńṣe ló máa ń kó ahọ́n ara rẹ̀ níjàánu
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Ẹní tó bá ń polongo ìjọba Ọlọ́run tọkàntọkàn á ṣàṣeyọrí tó pọ̀ gan-an ni
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Lóòótọ́ ni ká yinni máa ń fúnni níṣìírí, síbẹ̀ a gbọ́dọ̀ gba ìbáwí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Òbí tó bá nífẹ̀ẹ́ ọmọ ẹ̀ ò jẹ́ gbójú fo àṣìṣe ẹ̀ dá