13 Ọlọ́gbọ́n ọmọ máa ń gba ẹ̀kọ́ bàbá rẹ̀,+
Àmọ́ ẹlẹ́gàn kì í fetí sí ìbáwí.+
2 Ọ̀rọ̀ ẹnu èèyàn máa jẹ́ kó rí ohun rere gbà,+
Àmọ́ ìfẹ́ ọkàn àwọn oníbékebèke máa ń jẹ́ kí wọ́n hùwà ipá.
3 Ẹni tó ń ṣọ́ ẹnu rẹ̀ ń dáàbò bo ẹ̀mí rẹ̀,+
Àmọ́ ẹni tó ń la ẹnu rẹ̀ gbàgà yóò pa run.+
4 Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ọ̀lẹ ń fẹ́, síbẹ̀ kò ní nǹkan kan,+
Àmọ́ ẹni tó ń ṣiṣẹ́ kára yóò ní ànító.+
5 Olódodo kórìíra irọ́,+
Àmọ́ ìwà ẹni burúkú ń fa ìtìjú àti àbùkù.
6 Òdodo ń dáàbò bo ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ tọ́,+
Àmọ́ ìwà burúkú máa ń dojú ẹlẹ́ṣẹ̀ dé.
7 Ẹnì kan wà tó ń ṣe bíi pé òun jẹ́ ọlọ́rọ̀, síbẹ̀ kò ní nǹkan kan;+
Ẹlòmíì sì wà tó ń ṣe bíi pé aláìní lòun, síbẹ̀ ó ní ọrọ̀ rẹpẹtẹ.
8 Ọrọ̀ ni ọlọ́rọ̀ fi ń ra ẹ̀mí rẹ̀ pa dà,+
Àmọ́ ẹnikẹ́ni kì í halẹ̀ mọ́ aláìní.+
9 Ìmọ́lẹ̀ àwọn olódodo mọ́lẹ̀ rekete,+
Àmọ́ fìtílà àwọn ẹni burúkú ni a ó pa.+
10 Wàhálà ni ìkọjá àyè máa ń dá sílẹ̀,+
Àmọ́ ọgbọ́n jẹ́ ti àwọn tó ń wá ìmọ̀ràn.+
11 Ọrọ̀ tí èèyàn fi ìkánjú kó jọ kì í pẹ́ tán,+
Àmọ́ ọrọ̀ tí èèyàn ń kó jọ díẹ̀díẹ̀ á máa pọ̀ sí i.
12 Ìrètí pípẹ́ máa ń mú ọkàn ṣàìsàn,+
Àmọ́ nígbà tí ìfẹ́ ọkàn ẹni bá ṣẹ, igi ìyè ni.+
13 Ẹni tí kò bá ka ìtọ́ni sí á jìyà rẹ̀,+
Àmọ́ ẹni tó bá bọ̀wọ̀ fún àṣẹ yóò gba èrè rẹ̀.+
14 Ẹ̀kọ́ ọlọgbọ́n jẹ́ orísun ìyè+
Kì í jẹ́ kéèyàn kó sínú ìdẹkùn ikú.
15 Ìjìnlẹ̀ òye ń mú kéèyàn jèrè ojú rere,
Àmọ́ ọ̀nà àwọn oníbékebèke korò.
16 Aláròjinlẹ̀ máa ń fi ìmọ̀ hùwà,+
Àmọ́ òmùgọ̀ máa ń fi ìwà òmùgọ̀ rẹ̀ hàn.+
17 Òjíṣẹ́ burúkú máa ń kó sínú ìjàngbọ̀n,+
Àmọ́ aṣojú tó jẹ́ olóòótọ́ ń mú ìwòsàn wá.+
18 Ẹni tí kò bá ka ìbáwí sí á di òtòṣì, á sì kan àbùkù,
Àmọ́ ẹni tó bá ń gba ìtọ́sọ́nà ni a ó gbé ga.+
19 Nígbà tí ìfẹ́ ọkàn ẹni bá ṣẹ, ó máa ń dùn mọ́ni,+
Àmọ́ òmùgọ̀ kì í fẹ́ jáwọ́ nínú ìwà burúkú.+
20 Ẹni tó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n,+
Àmọ́ ẹni tó ń bá òmùgọ̀ da nǹkan pọ̀ yóò rí láburú.+
21 Àjálù kì í dẹ̀yìn lẹ́yìn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,+
Àmọ́ aásìkí ni èrè àwọn olódodo.+
22 Ẹni rere máa ń fi ogún sílẹ̀ fún àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀,
Àmọ́ ọrọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni a ó kó jọ fún àwọn olódodo.+
23 Ọ̀pọ̀ oúnjẹ ló ń jáde látinú oko tí àwọn aláìní dá,
Àmọ́ àìsí ìdájọ́ òdodo lè gbá a lọ.
24 Ẹni tó bá fa ọ̀pá sẹ́yìn kórìíra ọmọ rẹ̀,+
Àmọ́ ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ̀ máa ń bá a wí dáadáa.+
25 Olódodo ń jẹ àjẹtẹ́rùn,+
Àmọ́ inú àwọn ẹni burúkú ṣófo.+