Má Ṣe Máa Fi Ìrísí Dáni Lẹ́jọ́
“Ẹ dẹ́kun ṣíṣèdájọ́ láti inú ìrísí òde, ṣùgbọ́n ẹ máa fi ìdájọ́ òdodo ṣèdájọ́.”—JÒH. 7:24.
1. Àsọtẹ́lẹ̀ wo ni Aísáyà sọ nípa Jésù, kí sì nìdí tí èyí fi fini lọ́kàn balẹ̀?
AÍSÁYÀ sọ àsọtẹ́lẹ̀ kan tó fini lọ́kàn balẹ̀ nípa Jésù Kristi Olúwa wa. Ó sọ pé, Jésù ò ní “ṣe ìdájọ́ nípasẹ̀ ohun èyíkéyìí tí ó hàn lásán sí ojú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí etí rẹ̀ wulẹ̀ gbọ́.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa “fi òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn ẹni rírẹlẹ̀.” (Aísá. 11:3, 4) Kí nìdí tí èyí fi fini lọ́kàn balẹ̀? Ìdí ni pé inú ayé tí ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ti gbilẹ̀ táwọn èèyàn sì máa ń wojú ṣe nǹkan là ń gbé. Torí náà, gbogbo wa là ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí Jésù tó jẹ́ Onídàájọ́ òdodo máa ṣèdájọ́, torí pé kì í ṣe ohun tó hàn sí ojú ló máa fi ṣèdájọ́!
2. Àṣẹ wo ni Jésù pa fún wa, kí la sì máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
2 Onírúurú èrò la máa ń ní nípa àwọn míì. Àmọ́ torí pé a kì í ṣe ẹni pípé bíi Jésù, èrò wa nípa àwọn míì lè má dáa tó. Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tá a rí ló máa ń pinnu ohun tá a máa rò nípa ẹnì kan. Nígbà tí Jésù wà láyé, ó pàṣẹ pé: “Ẹ dẹ́kun ṣíṣèdájọ́ láti inú ìrísí òde, ṣùgbọ́n ẹ máa fi ìdájọ́ òdodo ṣèdájọ́.” (Jòh. 7:24) Èyí fi hàn pé Jésù fẹ́ ká fara wé òun, ká má ṣe fi ìrísí pinnu irú ẹni téèyàn kan jẹ́. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò ohun mẹ́ta táwọn èèyàn sábà máa ń wò tí wọ́n bá fẹ́ pinnu irú ẹni tẹ́nì kan jẹ́. Àwọn nǹkan náà ni ẹ̀yà tàbí ìlú tẹ́nì kan ti wá, bó ṣe lówó tó àti ọjọ́ orí rẹ̀. Bá a ṣe ń gbé ọ̀kọ̀ọ̀kan yẹ̀ wò, a máa jíròrò ohun tó yẹ ká ṣe ká lè pa àṣẹ Jésù mọ́ pé ká má ṣe fi ìrísí dáni lẹ́jọ́.
MÁ ṢE FI ÌLÚ TÀBÍ Ẹ̀YÀ TẸ́NÌ KAN TI WÁ PINNU IRÚ ẸNI TÓ JẸ́
3, 4. (a) Àwọn nǹkan wo ló ṣẹlẹ̀ tó mú kí àpọ́sítélì Pétérù yí èrò tó ní nípa àwọn tí kì í ṣe Júù pa dà? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.) (b) Òye tuntun wo ni Jèhófà jẹ́ kí Pétérù ní?
3 Ó dájú pé onírúurú èrò lá máa jà gùdù lọ́kàn àpọ́sítélì Pétérù nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ ní kó lọ sílé Kọ̀nílíù ní Kesaréà. Ìdí sì ni pé Kọ̀nílíù kì í ṣe Júù. (Ìṣe 10:17-29) Àwọn Júù gbà pé aláìmọ́ làwọn tí kì í ṣe Júù, irú èrò yìí sì ni Pétérù náà ní. Àmọ́ àwọn nǹkan kan ṣẹlẹ̀ tó mú kí Pétérù yí èrò rẹ̀ pa dà. Bí àpẹẹrẹ, ó rí ìran àgbàyanu kan. (Ìṣe 10:9-16) Nínú ìran yìí, Pétérù rí ohun tó dà bí aṣọ kan tó kún fún àwọn ẹran aláìmọ́ tó sọ̀kalẹ̀ wá síwájú rẹ̀. Ohùn kan láti ọ̀run sì pàṣẹ fún un pé: “Dìde, Pétérù, máa pa, kí o sì máa jẹ!” Àmọ́, ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Pétérù kọ̀ jálẹ̀. Gbogbo ìgbà tó kọ̀ jálẹ̀ ni ohùn náà sọ fún un pé kó “dẹ́kun pípe ohun tí Ọlọ́run ti wẹ̀ mọ́ ní ẹlẹ́gbin.” Nígbà tí Pétérù jí, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe kàyéfì nípa ohun tí ìran náà túmọ̀ sí, bẹ́ẹ̀ làwọn tí Kọ̀nílíù rán wá sọ́dọ̀ rẹ̀ dé. Ẹ̀mí mímọ́ wá fún un ní ìtọ́ni pé kó tẹ̀ lé wọn lọ sílé Kọ̀nílíù, òun náà sì ṣe bẹ́ẹ̀.
4 Ká sọ pé Pétérù ò yí èrò tó ní tẹ́lẹ̀ pa dà, ó dájú pé kò ní wọ ilé Kọ̀nílíù. Ìdí sì ni pé àwọn Júù kì í wọ ilé àwọn tí kì í ṣe Júù. Àmọ́ kí ló mú kí Pétérù fa ẹ̀tanú yìí tu lọ́kàn rẹ̀? Ìran tó rí àti ìtọ́ni tí ẹ̀mí mímọ́ fún un ló mú kó yí èrò rẹ̀ pa dà. Lẹ́yìn tí Pétérù sì gbọ́ àlàyé tí Kọ̀nílíù ṣe, ó sọ lábẹ́ ìmísí pé: “Dájúdájú, mo róye pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Ó dájú pé òye tuntun yìí máa jọ Pétérù lójú gan-an! Àmọ́ báwo ni òye tuntun yìí ṣe kan àwa Kristẹni lónìí?
5. (a) Kí ni Jèhófà fẹ́ kí gbogbo àwa Kristẹni lóye? (b) Irú èrò wo ló ṣì lè wà lọ́kàn wa láìka pé a ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́?
5 Jèhófà lo Pétérù láti jẹ́ kí gbogbo àwa Kristẹni mọ̀ pé òun kì í ṣe ojúsàájú. Lójú Jèhófà, ọ̀kan náà ni gbogbo wa láìka ìlú tá a ti wá, ẹ̀yà tàbí èdè wa sí. Ẹnikẹ́ni tó bá bẹ̀rù Ọlọ́run, tó sì ń ṣe ohun tó tọ́, ì báà jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin ni Ọlọ́run máa tẹ́wọ́ gbà. (Gál. 3:26-28; Ìṣí. 7:9, 10) Ó dájú pé àwa náà gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà àti ẹ̀tanú pọ̀ níbi tá a gbé dàgbà ńkọ́? A lè ronú pé a kì í ṣojúsàájú àmọ́ kó jẹ́ pé a ṣì lẹ́mìí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ká má sì mọ̀. Bí àpẹẹrẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pétérù ni Jèhófà lò láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé òun kì í ṣojúsàájú, síbẹ̀ Pétérù fúnra rẹ̀ tún ṣe ẹ̀tanú sáwọn tí kì í ṣe Júù lẹ́yìn ìgbà yẹn. (Gál. 2:11-14) Báwo wá la ṣe lè ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù, ká má sì fi ìrísí dáni lẹ́jọ́?
6. (a) Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ fa ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tu lọ́kàn wa? (b) Kí ló hàn nínú ìròyìn tí arákùnrin kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ kọ?
6 Ó yẹ ká fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yẹ ara wa wò dáadáa ká lè mọ̀ bóyá ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ṣì wà lọ́kàn wa. (Sm. 119:105) Nígbà míì, a lè bi ẹnì kan tá a fọkàn tán kó lè sọ fún wa tó bá rí i pé a ní ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, ìdí ni pé àwa fúnra wa lè má mọ̀. Ó ṣe tán ìpàkọ́ onípàkọ́ làá rí, ẹni ẹlẹ́ni ló ń báni rí tẹni. (Gál. 2:11, 14) Ẹ̀mí yìí lè ti jingíri sọ́kàn wa ká má sì mọ̀. Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin kan tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ kọ ìròyìn nípa tọkọtaya kan tó ń ṣe dáadáa lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Ọkọ náà wá láti ẹ̀yà kan táwọn èèyàn máa ń fojú yẹpẹrẹ wò. Àmọ́ arákùnrin tó kọ ìròyìn náà ò mọ̀ pé òun fúnra òun ní ẹ̀tanú sí àwọn tó wá láti ẹ̀yà náà. Nínú ìròyìn tó kọ, arákùnrin náà sọ àwọn nǹkan tó dáa nípa ọkọ náà, síbẹ̀ ohun tó fi parí ìròyìn yẹn ni pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yà [báyìí báyìí] ló ti wá, ìwà rẹ̀ àti bó ṣe ń gbé ìgbésí ayé ti jẹ́ káwọn èèyàn rí i pé téèyàn bá tiẹ̀ wá láti ẹ̀yà [náà], kò túmọ̀ sí pé á jẹ́ ọ̀bùn tàbí pé á máa gbé irú ìgbésí ayé tá a mọ ọ̀pọ̀ àwọn tó wá láti ẹ̀yà yìí sí.” Àbí ẹ ò rí nǹkan! Ẹ̀kọ́ wo wá nìyẹn kọ́ wa? Láìka bá a ṣe pẹ́ tó nínú òtítọ́ tàbí àwọn àǹfààní tá a ní, a gbọ́dọ̀ máa yẹ ara wa wò dáadáa, ká sì ṣe tán láti jẹ́ káwọn míì ràn wá lọ́wọ́ ká lè fa ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tu lọ́kàn wa. Kí ni nǹkan míì tá a tún lè ṣe?
7. Kí la lè ṣe tá a bá fẹ́ gbòòrò sí i?
7 Tá a bá jẹ́ kí ọkàn wa túbọ̀ gbòòrò sí i, ìfẹ́ á borí ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tó bá wà lọ́kàn wa. (2 Kọ́r. 6:11-13) Ṣé àwọn ọmọ ìlú rẹ tàbí àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ ẹ̀yà kan náà tàbí tẹ́ ẹ jọ ń sọ èdè kan náà lo sábà máa ń bá kẹ́gbẹ́? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, á dáa kó o túbọ̀ gbòòrò sí i. Lára ohun tó o lè ṣe ni pé kó o bá àwọn tó wá láti ẹ̀yà míì ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí tàbí kó o pè wọ́n wá jẹun nílé rẹ. (Ìṣe 16:14, 15) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ onírúurú èèyàn, ìyẹn á sì jẹ́ kó o borí ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. Àmọ́ nígbà míì, a máa ń fi béèyàn ṣe lówó tó pinnu irú ẹni tó jẹ́. Èyí ni kókó kejì tá a máa jíròrò.
MÁ ṢE FI BÍ ẸNÌ KAN ṢE LÓWÓ TÓ PINNU IRÚ ẸNI TÓ JẸ́
8. Bí Léfítíkù 19:15 ṣe sọ, kí ló yẹ ká ṣọ́ra fún?
8 Bí ẹnì kan ṣe lówó tó lè mú ká máa gbé e gẹ̀gẹ̀ tàbí ká fojú yẹpẹrẹ wò ó. Léfítíkù 19:15 sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi ojúsàájú bá ẹni rírẹlẹ̀ lò, ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ ṣe ojúsàájú ẹni ńlá. Ìdájọ́ òdodo ni kí o fi ṣe ìdájọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ.” Tá ò bá ṣọ́ra, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í fojú pàtàkì wo àwọn olówó, ká sì máa fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn tí kò ní. Kí nìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀?
9. Òótọ́ tí kò ṣeé já ní koro wo ni Sólómọ́nì sọ, kí la sì rí kọ́ nínú òwe náà?
9 Lábẹ́ ìmísí, Sólómọ́nì sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ kan tí kò ṣeé já ní koro nípa àwa èèyàn aláìpé. Nínú Òwe 14:20, ó sọ pé: “Lójú ọmọnìkejì rẹ̀ pàápàá, ẹni tí ó jẹ́ aláìnílọ́wọ́ jẹ́ ẹni ìkórìíra, ṣùgbọ́n púpọ̀ ni ọ̀rẹ́ ọlọ́rọ̀.” Kí ni òwe yìí kọ́ wa? Àwọn èèyàn máa ń sọ pé, ‘olówó layé mọ̀.’ Táwa náà ò bá ṣọ́ra, ó lè máa wù wá láti bá àwọn ará tó lówó ṣọ̀rẹ́, ká sì máa yẹra fáwọn tí kò ní. Àmọ́, ó léwu tá a bá ń fi bí ẹnì kan ṣe lówó tó pinnu irú ẹni tó jẹ́. Kí nìdí?
10. Ewu wo ni Jákọ́bù kìlọ̀ nípa rẹ̀?
10 Tá a bá ń fi bí ẹnì kan ṣe lówó tó pinnu irú ẹni tó jẹ́, ó lè fa ẹ̀mí kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ nínú ìjọ, á wá di pé kólówó máa ṣọ̀rẹ́ olówó. Jákọ́bù kìlọ̀ pé irú nǹkan báyìí ti fa ìyapa nínú àwọn ìjọ kan ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. (Ka Jákọ́bù 2:1-4.) A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra, ká má ṣe fàyè gba èrò yìí torí pé ó lè fa ìyapa nínú ìjọ. Àmọ́ kí la lè ṣe tá ò fi ní fàyè gba èrò yìí lọ́kàn wa?
11. Ṣé ohun tẹ́nì kan ní ló máa pinnu bí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà ṣe máa rí? Ṣàlàyé.
11 Ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn ará wa ló yẹ káwa náà máa fi wò wọ́n. Ti pé ẹnì kan jẹ́ olówó tàbí tálákà kọ́ ló máa mú kí Jèhófà fojúure han sí i. Kì í sì í ṣe bá a ṣe ní tó tàbí bá a ṣe ṣaláìní ló máa pinnu bá a ṣe máa sún mọ́ Jèhófà tó. Lóòótọ́, Jésù sọ pé ó máa “ṣòro fún ọlọ́rọ̀ láti dé inú Ìjọba ọ̀run,” àmọ́ kò sọ pé wọn ò lè wọ Ìjọba ọ̀run rárá. (Mát. 19:23) Lọ́wọ́ kejì, Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹ̀yin òtòṣì, nítorí pé tiyín ni Ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 6:20) Àmọ́, èyí ò túmọ̀ sí pé gbogbo àwọn òtòṣì ló máa fara mọ́ ẹ̀kọ́ Jésù tí wọ́n á sì gba ìbùkún tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ó ṣe tán, ọ̀pọ̀ àwọn òtòṣì ni kò tẹ̀ lé Jésù. Kókó ibẹ̀ ni pé kì í ṣe bóyá ẹnì kan jẹ́ olówó tàbí tálákà ló ń pinnu bí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà ṣe máa rí.
12. Ìtọ́ni wo ni Ìwé Mímọ́ fún gbogbo wa yálà a jẹ́ olówó tàbí tálákà?
12 Inú wa dùn pé a láwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin, olówó àti tálákà tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n sì ń sìn ín tọkàntọkàn. Ìwé Mímọ́ gba àwọn ọlọ́rọ̀ níyànjú pé “kí wọ́n má ṣe gbé ìrètí wọn lé ọrọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run.” (Ka 1 Tímótì 6:17-19.) Lẹ́sẹ̀ kan náà, Bíbélì gba gbogbo àwa èèyàn Ọlọ́run níyànjú pé ká ṣọ́ra fún ìfẹ́ owó yálà a jẹ́ olówó tàbí tálákà. (1 Tím. 6:9, 10) Kò sí àní-àní pé tá a bá ń wo àwọn ará wa bí Jèhófà ṣe ń wò wọ́n, a ò ní máa fi bí wọ́n ṣe lówó tó pinnu irú ẹni tí wọ́n jẹ́. Àmọ́ tó bá kan ti ọjọ́ orí ńkọ́? Ṣó yẹ ká máa fi bí ẹnì kan ṣe dàgbà tó pinnu irú ẹni tó jẹ́? Ẹ jẹ́ ká wò ó.
MÁ ṢE FI ỌJỌ́ ORÍ PINNU IRÚ ẸNI TÉÈYÀN KAN JẸ́
13. Kí ni Ìwé Mímọ́ sọ nípa bíbọ̀wọ̀ fáwọn àgbàlagbà?
13 Léraléra ni Ìwé Mímọ́ sọ pé ká máa bọ̀wọ̀ fàwọn àgbàlagbà. Léfítíkù 19:32 sọ pé: “Kí o dìde dúró níwájú orí ewú, kí o sì fi ìgbatẹnirò hàn fún arúgbó, kí o sì máa bẹ̀rù Ọlọ́run rẹ.” Òwe 16:31 náà sọ ohun tó jọ èyí, ó ní: “Orí ewú jẹ́ adé ẹwà nígbà tí a bá rí i ní ọ̀nà òdodo.” Yàtọ̀ síyẹn, Pọ́ọ̀lù gba Tímótì nímọ̀ràn pé kó má ṣe fi àṣìṣe àgbà ọkùnrin hàn lọ́nà mímúná janjan, kàkà bẹ́ẹ̀ kó máa wo irú àwọn àgbà ọkùnrin bẹ́ẹ̀ bíi bàbá. (1 Tím. 5:1, 2) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Tímótì ní ọlá àṣẹ lórí àwọn àgbà ọkùnrin yìí dé ìwọ̀n àyè kan, síbẹ̀ ó gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún wọn, kó sì fìfẹ́ bá wọn lò.
14. Ìgbà wo ló máa pọn dandan pé ká fún ẹnì kan tó jù wá lọ ní ìbáwí tó yẹ?
14 Àmọ́ kí la máa ṣe tí ẹnì kan tó dàgbà jù wá lọ bá ń mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ tàbí tó ń gbé ohun tí Jèhófà kórìíra lárugẹ? Ohun kan ni pé Jèhófà kì í fi ìrísí dáni lẹ́jọ́, ti pé ẹnì kan dàgbà kò túmọ̀ sí pé Jèhófà máa gbójú fo ẹ̀ṣẹ̀ tẹ́ni náà mọ̀ọ́mọ̀ dá. Ká fi ìlànà tó wà nínú Aísáyà 65:20 sọ́kàn tó sọ pé: “Ní ti ẹlẹ́ṣẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún, a ó pe ibi wá sórí rẹ̀.” Irú ìlànà yìí náà wà nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí. (Ìsík. 9:5-7) Torí náà, ohun tó yẹ kó máa wà lọ́kàn wa nígbà gbogbo ni bá a ṣe máa bọ̀wọ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé. (Dán. 7:9, 10, 13, 14) Tá a bá ń fi èyí sọ́kàn, a ò ní bẹ̀rù láti fún ẹnikẹ́ni ní ìbáwí tó yẹ láìka ọjọ́ orí rẹ̀ sí.—Gál. 6:1.
15. Kí la rí kọ́ lára àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó bá di pé ká bọ̀wọ̀ fáwọn arákùnrin tó kéré lọ́jọ́ orí?
15 Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó wà nínú ìjọ ńkọ́, ojú wo la fi ń wò wọ́n? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba Tímótì tó jẹ́ ọ̀dọ́ nímọ̀ràn pé: “Má ṣe jẹ́ kí ènìyàn kankan fojú tẹ́ńbẹ́lú èwe rẹ láé. Kàkà bẹ́ẹ̀, di àpẹẹrẹ fún àwọn olùṣòtítọ́ nínú ọ̀rọ̀ sísọ, nínú ìwà, nínú ìfẹ́, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́.” (1 Tím. 4:12) Ó ṣeé ṣe kí Tímótì ṣẹ̀ṣẹ̀ lé lẹ́ni ọgbọ̀n [30] ọdún nígbà tí Pọ́ọ̀lù gbà á nímọ̀ràn yìí. Síbẹ̀, iṣẹ́ ńlá ni Pọ́ọ̀lù ní kó máa bójú tó nínú ìjọ. Kókó tó wà nínú ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù yìí ṣe kedere. A ò gbọ́dọ̀ fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn ọ̀dọ́kùnrin torí pé wọ́n kéré lọ́jọ́ orí. Ó ṣe tán, ẹni ọgbọ̀n [30] ọdún ó lé díẹ̀ ni Jésù nígbà tó ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.
16, 17. (a) Kí ni àwọn alàgbà fi ń pinnu bóyá arákùnrin kan kúnjú ìwọ̀n láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà? (b) Báwo ni èrò wa tàbí àṣà ìbílẹ̀ wa ṣe lè tako ìlànà Ìwé Mímọ́?
16 Ní àwọn ilẹ̀ kan, wọ́n máa ń fojú tẹ́ńbẹ́lú àwọn ọ̀dọ́kùnrin. Àwọn alàgbà tó wá láti irú ilẹ̀ bẹ́ẹ̀ lè má fẹ́ dámọ̀ràn àwọn ọ̀dọ́kùnrin láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà. Àmọ́ gbogbo àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn pé Ìwé Mímọ́ ò sọ ọjọ́ orí tẹ́nì kan gbọ́dọ̀ jẹ́ kó tó lè di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà. (1 Tím. 3:1-10, 12, 13; Títù 1:5-9) Tí alàgbà kan bá wá tìtorí àṣà ìbílẹ̀ rẹ̀ gbé ìlànà kan kalẹ̀, á jẹ́ pé irú alàgbà bẹ́ẹ̀ ò tẹ̀ lé ìlànà Ìwé Mímọ́ nìyẹn. A kì í fi èrò wa tàbí àṣà ìbílẹ̀ wa gbé àwọn ọ̀dọ́kùnrin yẹ̀ wò bóyá wọ́n kúnjú ìwọ̀n, kàkà bẹ́ẹ̀ ìlànà Bíbélì là ń lò.—2 Tím. 3:16, 17.
17 Táwọn alàgbà bá ń lo èrò wọn tàbí àṣà ìbílẹ̀ wọn láti gbé àwọn ọ̀dọ́kùnrin yẹ̀ wò, wọ́n lè fi àǹfààní iṣẹ́ ìsìn du àwọn tó kúnjú ìwọ̀n fún àǹfààní náà. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè kan, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan wà tó dáńgájíá, fún ìdí yìí àwọn alàgbà fún un láwọn ojúṣe pàtàkì nínú ìjọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alàgbà yẹn gbà pé ọ̀dọ́kùnrin náà kúnjú ìwọ̀n láti di alàgbà níbàámu pẹ̀lú ìlànà Ìwé Mímọ́, síbẹ̀ wọn ò dámọ̀ràn rẹ̀ láti di alàgbà. Díẹ̀ lára àwọn alàgbà tó dàgbà láàárín wọn sọ pé arákùnrin náà ṣì kéré lójú àti pé àwọn míì lè máa wò ó pé ó ti kéré jù láti di alàgbà. Àbí ẹ ò rí nǹkan, wọn ò dámọ̀ràn arákùnrin náà torí wọ́n gbà pé ó kéré lójú! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àpẹẹrẹ kan la mú wá yìí, ìròyìn fi hàn pé ọ̀pọ̀ ló ní irú èrò yìí kárí ayé. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an ká máa lo ìlànà Ìwé Mímọ́ dípò èrò wa tàbí àṣà ìbílẹ̀ wa tá a bá ń gbé àwọn arákùnrin yẹ̀ wò. Ọ̀nà kan nìyẹn tá a lè gbà tẹ̀ lé àṣẹ Jésù pé ká má ṣe fi ìrísí dáni lẹ́jọ́.
Ẹ MÁA ṢE ÌDÁJỌ́ ÒDODO
18, 19. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ máa wo àwọn míì bí Jèhófà ṣe ń wò wọ́n?
18 Láìka pé a jẹ́ aláìpé, a ṣì lè máa wo àwọn míì bí Jèhófà ṣe ń wò wọ́n. (Ìṣe 10:34, 35) Àmọ́ èyí gba ìsapá, ó sì gba pé ká máa fọkàn sí àwọn ìránnilétí tá à ń gbà látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Tá a bá ń fi àwọn ìránnilétí yìí sílò, àá lè máa ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù pé ká má ṣe máa fi ìrísí dáni lẹ́jọ́.—Jòh. 7:24.
19 Láìpẹ́, Jésù Kristi Ọba wa máa ṣèdájọ́ gbogbo aráyé, inú wa sì dùn pé kì í ṣe ohun tó hàn sí ojú rẹ̀ tàbí ohun tí etí rẹ̀ wulẹ̀ gbọ́ ló máa fi ṣèdájọ́ yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, òdodo ni yóò fi ṣèdájọ́. (Aísá. 11:3, 4) Ó dájú pé àkókò alárinrin nìyẹn máa jẹ́!