Sí Àwọn Ará Gálátíà
2 Ọdún mẹ́rìnlá (14) lẹ́yìn náà, mo tún lọ sí Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú Bánábà,+ mo sì mú Títù dání.+ 2 Mo lọ nítorí ìfihàn kan tí mo rí, mo sì sọ ìhìn rere tí mò ń wàásù láàárín àwọn orílẹ̀-èdè fún wọn. Àmọ́, ó jẹ́ níkọ̀kọ̀, níwájú àwọn èèyàn pàtàkì,* kí n lè rí i dájú pé eré tí mò ń sá tàbí èyí tí mo ti sá kì í ṣe lásán. 3 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Gíríìkì ni Títù+ tó wà pẹ̀lú mi, wọn ò fi dandan mú un pé kó dádọ̀dọ́.*+ 4 Àmọ́ ọ̀rọ̀ yìí jẹyọ nítorí àwọn èké arákùnrin tó wọlé ní bòókẹ́lẹ́,+ àwọn tó yọ́ wọlé láti ṣe amí òmìnira+ tí a ní nínú Kristi Jésù, kí wọ́n lè sọ wá di ẹrú pátápátá;+ 5 a kò gbà fún wọn,+ rárá o, kì í tiẹ̀ ṣe fún ìṣẹ́jú* kan, kí òtítọ́ ìhìn rere lè máa wà pẹ̀lú yín.
6 Àmọ́ ní ti àwọn tó dà bíi pé wọ́n ṣe pàtàkì,+ irú ẹni tí wọ́n jẹ́ tẹ́lẹ̀ kò jẹ́ nǹkan kan lójú mi, torí Ọlọ́run kì í wo bí ẹnì kan ṣe rí lóde, kò sí ohun tuntun kankan tí àwọn tó gbayì yẹn kọ́ mi. 7 Dípò bẹ́ẹ̀, nígbà tí wọ́n rí i pé a ti fi sí ìkáwọ́ mi láti sọ ìhìn rere fún àwọn tó jẹ́ aláìdádọ̀dọ́,*+ gẹ́gẹ́ bí a ṣe fi sí ìkáwọ́ Pétérù láti sọ ọ́ fún àwọn tó dádọ̀dọ́,* 8 nítorí ẹni tó fún Pétérù lágbára láti ṣe iṣẹ́ àpọ́sítélì láàárín àwọn tó dádọ̀dọ́, fún èmi náà lágbára láti ṣe é láàárín àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè,+ 9 nígbà tí wọ́n rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tí a fún mi,+ Jémíìsì+ àti Kéfà* àti Jòhánù, àwọn tó dà bí òpó nínú ìjọ, bọ èmi àti Bánábà+ lọ́wọ́ láti fi hàn pé wọ́n fara mọ́ ọn pé* kí a lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, kí àwọn sì lọ sọ́dọ̀ àwọn tó dádọ̀dọ́. 10 Ohun kan ṣoṣo tí wọ́n béèrè ni pé kí a fi àwọn aláìní sọ́kàn, mo sì ń sapá gan-an láti ṣe bẹ́ẹ̀.+
11 Àmọ́ ṣá o, nígbà tí Kéfà*+ wá sí Áńtíókù,+ mo ta kò ó lójúkojú,* nítorí ó ṣe kedere pé ohun tó ṣe kò tọ́.* 12 Torí kí àwọn kan látọ̀dọ̀ Jémíìsì+ tó dé, ó máa ń bá àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè jẹun;+ àmọ́ nígbà tí wọ́n dé, kò ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́, ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀, torí ó ń bẹ̀rù àwọn tó dádọ̀dọ́.*+ 13 Àwọn Júù yòókù náà dara pọ̀ mọ́ ọn láti máa díbọ́n,* débi pé Bánábà pàápàá bẹ̀rẹ̀ sí í bá wọn díbọ́n.* 14 Àmọ́ nígbà tí mo rí i pé wọn kò rìn lọ́nà tó bá òtítọ́ ìhìn rere mu,+ mo sọ fún Kéfà* níṣojú gbogbo wọn pé: “Bí ìwọ tí o jẹ́ Júù, bá ń gbé ìgbé ayé àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè, tí o kò ṣe bíi ti àwọn Júù, kí ló wá dé tí o fi ń sọ ọ́ di dandan pé kí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè máa tẹ̀ lé àṣà àwọn Júù?”+
15 Àwa tí wọ́n bí ní Júù, tí a kì í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ látinú àwọn orílẹ̀-èdè, 16 mọ̀ pé kì í ṣe àwọn iṣẹ́ òfin ló ń mú ká pe èèyàn ní olódodo, bí kò ṣe nípasẹ̀ ìgbàgbọ́+ nínú Jésù Kristi+ nìkan. Ìdí nìyẹn tí a fi ní ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jésù, kí a lè pè wá ní olódodo nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Kristi, kì í ṣe nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ òfin, nítorí kò sí ẹni* tí a máa pè ní olódodo nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ òfin.+ 17 Ní báyìí, tí wọ́n bá ń rí wa ní ẹlẹ́ṣẹ̀ níbi tí a ti ń wá bí Ọlọ́run ṣe máa pè wá ní olódodo nípasẹ̀ Kristi, ṣé Kristi wá jẹ́ òjíṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ ni? Ká má ri! 18 Tó bá jẹ́ pé àwọn ohun tí mo ti wó lulẹ̀ rí ni mo tún ń gbé ró, ṣe ni mò ń fi hàn pé arúfin ni mí. 19 Torí nípasẹ̀ òfin, mo ti di òkú sí òfin,+ kí n lè di alààyè sí Ọlọ́run. 20 Wọ́n ti kàn mí mọ́gi pẹ̀lú Kristi.+ Kì í ṣe èmi ló wà láàyè mọ́,+ Kristi ló wà láàyè nínú mi. Ní tòótọ́, ìgbésí ayé tí mò ń gbé báyìí nínú ara ni mò ń gbé nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run,+ ẹni tó nífẹ̀ẹ́ mi, tó sì fi ara rẹ̀ lélẹ̀ fún mi.+ 21 Mi ò kọ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run,*+ nítorí tí òdodo bá jẹ́ nípasẹ̀ òfin, á jẹ́ pé lásán ni Kristi kú.+