“Ìbẹ̀rù Jèhófà Ìyẹn Ni Ọgbọ́n”
“ÒPIN ọ̀ràn náà, lẹ́yìn gbígbọ́ gbogbo rẹ̀, ni pé: Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn.” (Oníwàásù 12:13) Kò sí àní-àní pé ohun tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run mú kí Sólómọ́nì ọba Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un fi kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí wọni lọ́kàn ṣinṣin! Jóòbù baba ńlá mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì kéèyàn bẹ̀rù Ọlọ́run, ó sọ pé: “Wò ó! Ìbẹ̀rù Jèhófà—ìyẹn ni ọgbọ́n, yíyípadà kúrò nínú ìwà búburú sì ni òye.”—Jóòbù 28:28.
Bíbélì fi hàn pé ìbẹ̀rù Jèhófà ṣe pàtàkì gan-an. Kí nìdí tí bíbẹ̀rù Jèhófà látọkànwá fi jẹ́ ìwà ọgbọ́n? Báwo ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run ṣe lè ṣe àwa tá à ń fi òótọ́ ọkàn sin Ọlọ́run láǹfààní, ì báà jẹ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan tàbí lápapọ̀? A óò rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú ìwé Òwe orí 14 ẹsẹ 26 sí 35.a
Ẹni Tí A Lè ‘Gbọ́kàn Lé’
Sólómọ́nì sọ pé: “Inú ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìgbọ́kànlé lílágbára wà, ibi ìsádi yóò sì wá wà fún àwọn ọmọ rẹ̀.” (Òwe 14:26) Kò sẹ́lòmíì tí ẹni tó bá ń bẹ̀rù Ọlọ́run gbára lé ju Jèhófà, Ọlọ́run Olódùmarè tó jẹ́ adúróṣinṣin. Abájọ tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò fi ní fòyà ohunkóhun tó lè ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú torí pé ó ní ìgbọ́kànlé tó lágbára! Lọ́jọ́ iwájú, onítọ̀hún á wà láàyè títí láé, ayé rẹ̀ á sì dùn bí oyin.
Àmọ́, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tó gbára lé ayé yìí, ìyẹn àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé ọgbọ́n ayé, ìpètepèrò rẹ̀, àwọn àjọ inú rẹ̀ àti ọrọ̀ ayé? Ìgbésí ayé wọn ò lè gùn lọ títí torí pé Bíbélì sọ pé: “Ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” (1 Jòhánù 2:17) Ṣé ó wá ỵẹ ká “máa nífẹ̀ẹ́ yálà ayé tàbí àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé”?—1 Jòhánù 2:15.
Kí làwọn òbí tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run lè ṣe tí ‘ibi ìsádi yóò fi wà’ fáwọn ọmọ wọn? Onísáàmù kọrin pé: “Ẹ wá, ẹ̀yin ọmọ, ẹ fetí sí mi; ìbẹ̀rù Jèhófà ni èmi yóò kọ́ yín.” (Sáàmù 34:11) Bí àwọn òbí bá ń fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ tí wọ́n sì ń kọ́ àwọn ọmọ wọn láti bẹ̀rù Ọlọ́run, ó dájú pé àwọn ọmọ wọn lọ́kùnrin lóbìnrin á gbọ́kàn lé Jèhófà bí wọ́n bá dàgbà.—Òwe 22:6.
Sólómọ́nì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ìbẹ̀rù Jèhófà jẹ́ kànga ìyè, láti yí padà kúrò nínú àwọn ìdẹkùn ikú.” (Òwe 14:27) Ìbẹ̀rù Jèhófà jẹ́ “kànga ìyè” torí pé Ọlọ́run tòótọ́ ni “orísun omi ààyè.” (Jeremáyà 2:13) Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àti Jésù Kristi, a óò lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòhánù 17:3) Bákan náà, ìbẹ̀rù Ọlọ́run kò ní jẹ́ ká kó sínú àwọn ìdẹkùn ikú. Lọ́nà wo? Òwe 13:14 sọ pé: “Òfin ọlọ́gbọ́n jẹ́ orísun ìyè, láti yí ènìyàn padà kúrò nínú àwọn ìdẹkùn ikú.” Bí a ṣe ń bẹ̀rù Jèhófà, tí à ń pa òfin rẹ̀ mọ́, tí a sì ń jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tọ́ wa sọ́nà, ǹjẹ́ èyí kì í dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn ohun tó lè ṣekú pa wá láìtọ́jọ́?
“Ọ̀ṣọ́ Ọba”
Sólómọ́nì bẹ̀rù Ọlọ́run ó sì pa òfin rẹ̀ mọ́ ní èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ọdún tó fi ṣàkóso. Èyí jẹ́ kí ìjọba rẹ̀ dára gan-an. Kí ló máa fi hàn bóyá ọba kan ń ṣàkóso dáadáa? Òwe 14:28 dáhùn pé: “Inú ògìdìgbó àwọn ènìyàn ni ọ̀ṣọ́ ọba wà, ṣùgbọ́n inú àìsí àwùjọ ènìyàn ni ìparun onípò àṣẹ gíga.” Bí ara bá ṣe tu àwọn èèyàn sí nígbà ìṣàkóso ọba kan ló máa fi hàn bóyá ọba rere ni àbí kì í ṣe ọba rere. Bó bá wu ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn pé kí ọba kan máa ṣàkóso àwọn, ìyẹn fi hàn pé alákòóso rere nirú ọba bẹ́ẹ̀. Sólómọ́nì ní “àwọn ọmọ abẹ́ láti òkun [Pupa] dé òkun [Mẹditaréníà] àti láti Odò [Yúfírétì] dé òpin ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 72:6-8) Ńṣe ni gbogbo ìlú tòrò minimini nígbà ìjọba rẹ̀, àwọn èèyàn sì ní ànító àti àníṣẹ́kù. Kò tíì sí ìjọba kankan tó dà bíi tirẹ̀ yìí. (1 Àwọn Ọba 4:24, 25) Nǹkan lọ déédéé nígbà tí Sólómọ́nì ń ṣàkóso. Àmọ́, báwọn èèyàn ò bá fẹ́ alákòóso kan, ìtìjú gbáà ni irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa jẹ́ fún un.
Lórí kókó yìí, kí la lè sọ nípa ògo Jésù Kristi tó jẹ́ Mèsáyà Ọba àti Sólómọ́nì Gíga Jù? Ronú nípa àwọn tó ń ṣàkóso lé lórí lónìí ná. Kárí ayé, àwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run lọ́kùnrin lóbìnrin tí wọ́n lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà ló fi ara wọn sábẹ́ ìṣàkóso Kristi. Wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù, wọ́n sì ń fi ìṣọ̀kan sin Ọlọ́run alààyè. (Jòhánù 14:1) Nígbà tí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi bá fi máa dópin, gbogbo àwọn tí Ọlọ́run fẹ́ jí dìde yóò ti jíǹde. Àwọn èèyàn aláyọ̀ tí wọ́n jẹ́ olódodo tí wọ́n sì ti fi hàn pé àwọn mọyì Ọba wọn ló máa kúnnú Párádísè orí ilẹ̀ ayé nígbà náà. Dájúdájú, ìyẹn á fi hàn pé ìjọba Kristi dára gan-an! Ẹ jẹ́ ká máa fi ìrètí Ìjọba Ọlọ́run tó ṣeyebíye gan-an yìí sọ́kàn nígbà gbogbo.
Àwọn Àǹfààní Tẹ̀mí àti Ti Ara
Tá a bá bẹ̀rù Ọlọ́run látọkànwá, a óò ní ìfọkànbalẹ̀. Ohun tó jẹ́ kí èyí rí bẹ́ẹ̀ ni pé làákàyè àti ìfòyemọ̀ wà lára ohun tó ń fi hàn pé ẹnì kan jẹ́ ọlọgbọ́n. Òwe 14:29 sọ pé: “Ẹni tí ó bá lọ́ra láti bínú pọ̀ yanturu ní ìfòyemọ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́ aláìnísùúrù ń gbé ìwà òmùgọ̀ ga.” Ìfòyemọ̀ ló máa jẹ́ ká mọ̀ pé ìbínú tá ò bá kápá lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Àwọn nǹkan bí “ìṣọ̀tá, gbọ́nmi-si omi-ò-to, owú, ìrufùfù ìbínú [àti] asọ̀” wà lára àwọn ohun tí Bíbélì sọ pé kò ní jẹ́ kéèyàn “jogún ìjọba Ọlọ́run.” (Gálátíà 5:19-21) Ìwé Mímọ́ sì gbà wá níyànjú pé ká má ṣe máa di èèyàn sínú, bá a bá tiẹ̀ jàre pàápàá. (Éfésù 4:26, 27) Bákan náà, àìnísùúrù lè mú ká sọ̀rọ̀ òmùgọ̀ tàbí ká hùwà tí kò bọ́gbọ́n mu tí a óò wá kábàámọ̀ tó bá yá.
Nígbà tí ọba Ísírẹ́lì ń sọ ohun tó lè tìdí ìbínú yọ, ó ní: “Ọkàn-àyà píparọ́rọ́ ni ìwàláàyè ẹ̀dá alààyè ẹlẹ́ran ara, ṣùgbọ́n owú jẹ́ ìjẹrà fún àwọn egungun.” (Òwe 14:30) Lára àwọn ìṣòro tí ìbínú àti ìrunú máa ń fà ni ẹ̀jẹ̀ ríru, àrùn ẹ̀dọ̀, kéèyàn má lè mí dáadáa, tàbí kí ẹ̀yà ara tí à ń pè ní àmọ́ má ṣiṣẹ́ dáadáa. Àwọn dókítà tún sọ pé ìbínú àti inú fùfù máa ń fa àwọn nǹkan bí ọgbẹ́ inú, ìléròrò, ikọ́ fée, àwọn àrùn tí ń bani láwọ̀ jẹ́ àti kí oúnjẹ inú ẹni má lè dà dáadáa, tàbí kí wọ́n dá kún àìsàn wọ̀nyí. Àmọ́, “ọkàn-àyà píparọ́rọ́ ni ìwàláàyè ẹ̀dá alààyè ẹlẹ́ran ara.” (Òwe 14:30) Nítorí náà, ó dára ká “máa lépa àwọn ohun tí ń yọrí sí àlàáfíà àti àwọn ohun tí ń gbéni ró fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.”—Róòmù 14:19.
Ìbẹ̀rù Ọlọ́run Kò Ní Jẹ́ Ká Máa Ṣe Ojúsàájú
Sólómọ́nì sọ pé:“ Ẹni tí ń lu ẹni rírẹlẹ̀ ní jìbìtì ti gan Olùṣẹ̀dá rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ń fi ojú rere hàn sí àwọn òtòṣì ń yìn Ín lógo.” (Òwe 14:31) Ẹni tó bá bẹ̀rù Ọlọ́run mọ̀ pé Olùṣẹ̀dá kan náà ló dá gbogbo ọmọ aráyé. Jèhófà Ọlọ́run ni Olùṣẹ̀dá náà. Torí náà, àwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wa làwọn ẹni rírẹlẹ̀ tí ibí yìí ń sọ. Ìwà tá a bá sì hù sí wọn lè múnú Ẹlẹ́dàá aráyé dùn tàbí kó múnú bí i. Tá a bá fẹ́ máa ṣe ohun tó máa fògo fún Ọlọ́run, a ò ní máa ṣe ojúsàájú. Bí Kristẹni kan bá tiẹ̀ jẹ́ tálákà pàápàá kò yẹ ká ṣe ojúsàájú, ńṣe ló yẹ ká máa ṣe ohun tó máa ràn án lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú. Síwájú sí i, àtolówó àti tálákà la sì gbọ́dọ̀ wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún.
Nígbà tí ọba ọlọgbọ́n náà ń sọ̀rọ̀ nípa àǹfààní mìíràn tó wà nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run, ó ní: “A ó ti ẹni burúkú lulẹ̀ nítorí ìwà búburú rẹ̀, ṣùgbọ́n olódodo yóò rí ibi ìsádi nínú ìwà títọ́ rẹ̀.” (Òwe 14:32) Báwo ni a ṣe ń ti ẹni burúkú lulẹ̀? Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé irú ẹni bẹ́ẹ̀ ò ní lè rí ọ̀nà àbáyọ bí àjálù bá ṣẹlẹ̀ sí i. Àmọ́ nígbà ìṣòro, ìwà títọ́ ẹni tó bá bẹ̀rù Ọlọ́run máa ń mẹ́sẹ̀ rẹ̀ dúró. Nítorí pé ó fi gbogbo ọkàn gbára lé Jèhófà dójú ikú, ńṣe lòun náà yóò máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nìṣó bíi ti Jóòbù tó sọ pé: “Títí èmi yóò fi gbẹ́mìí mì, èmi kì yóò mú ìwà títọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi!”—Jóòbù 27:5.
Èèyàn gbọ́dọ̀ ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run àti ọgbọ́n kó tó lè jẹ́ adúróṣinṣin. Ibo la sì ti lè rí ọgbọ́n? Òwe 14:33 sọ pé: “Inú ọkàn-àyà olóye ni ọgbọ́n fìdí kalẹ̀ sí, ní àárín àwọn arìndìn sì ni ó ti di mímọ̀.” Dájúdájú, ọkàn ẹni tó bá jẹ́ olóye èèyàn la ti lè rí ọgbọ́n. Àmọ́, báwo ni ọgbọ́n ṣe lè di mímọ̀ láàárín àwọn arìndìn? Ìwé kan sọ pé “àwọn òpònú máa ń sọ ọ̀rọ̀ tí wọ́n rò pé ó jẹ́ ọ̀rọ̀ ọgbọ́n káwọn èèyàn lè rò pé ọlọ́gbọ́n ni wọ́n, àmọ́ ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ lèyí máa ń já sí.”
Ohun Tí “Ń Gbé Orílẹ̀-Èdè Ga”
Ní báyìí, ọba Ísírẹ́lì mẹ́nu kúrò lórí ọ̀rọ̀ bí ìbẹ̀rù Ọlọ́run ṣe lè ṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan láǹfààní, ó wá dẹ́nu lé ọ̀rọ̀ nípa bó ṣe kan orílẹ̀-èdè lódindi. Ó ní: “Òdodo ní ń gbé orílẹ̀-èdè ga, ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ jẹ́ ohun ìtìjú fún àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè.” (Òwe 14:34) Kedere kèdèrè lohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi hàn pé òótọ́ pọ́ńbélé ni ọ̀rọ̀ Bíbélì yìí! Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run tí kò fàyè gba ìgbàkugbà ló gbé wọn ga ju àwọn orílẹ̀-èdè tó wà láyìíká wọn lọ. Àmọ́ o, ìwà àìgbọràn tó ti mọ́ wọn lára ló jẹ́ kí wọ́n di ẹni àbùkù lójú Jèhófà, òun ló sì mú kí Jèhófà kọ̀ wọ́n sílẹ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Ìlànà yìí kan àwa èèyàn Ọlọ́run lóde òní. Àwa tá a wà nínú ìjọ Kristẹni yàtọ̀ sáwọn èèyàn ayé torí pé àwọn ìlànà òdodo tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ là ń tẹ̀ lé. Àmọ́ o, kí ìyàtọ̀ yìí lè máa hàn nìṣó, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa gbọ́dọ̀ máa gbé ìgbé ayé ìwà mímọ́. Bí a bá sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà, ńṣe lèyí yóò sọ wá di ẹni àbùkù, yóò sì kó ẹ̀gàn bá ìjọ Kristẹni àti Ọlọ́run.
Nígbà tí Sólómọ́nì ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó máa ń múnú ọba dùn, ó ní: “Ìdùnnú ọba ń bẹ nínú ìránṣẹ́ tí ń fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà, ṣùgbọ́n ìbínú kíkan rẹ̀ wá wà lórí èyí tí ń hùwà lọ́nà tí ń tini lójú.” (Òwe 14:35) Òwe 16:13 sì sọ pé: “Ètè òdodo jẹ́ ìdùnnú atóbilọ́lá ọba; ó sì nífẹ̀ẹ́ ẹni tí ń sọ àwọn ohun adúróṣánṣán.” Bẹ́ẹ̀ ni o, inú Jésù Kristi tó jẹ́ Aṣáájú wa àti Ọba wa máa ń dùn gan-an tá a bá ń hùwà òdodo, tí à ń fi òye hùwà, tí a sì ń fi ètè wa ṣe iṣẹ́ wíwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká sa gbogbo ipá wa nínú iṣẹ́ yìí bí Ọlọ́run tòótọ́ ṣe ń bù kún wa torí pé a bẹ̀rù rẹ̀.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bó o bá fẹ́ mọ àlàyé tá a ṣe lórí Òwe 14:1-25, wo Ilé Ìṣọ́ November 15, 2004, ojú ìwé 26 sí 29 àti Ilé Ìṣọ́ July 15, 2005, ojú ìwé 17 sí 20.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
A lè kọ́ àwọn ẹlòmíràn ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run