Ti Dáfídì, nígbà tó ń ṣe bí ayírí+ níwájú Ábímélékì, tí Ábímélékì fi lé e jáde, tí ó sì lọ.
א [Áléfì]
34 Èmi yóò máa yin Jèhófà ní gbogbo ìgbà;
Ìyìn rẹ̀ yóò máa wà ní ẹnu mi nígbà gbogbo.
ב [Bétì]
2 Èmi yóò máa fi Jèhófà yangàn;+
Àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ yóò gbọ́, wọn yóò sì máa yọ̀.
ג [Gímélì]
3 Ẹ bá mi gbé Jèhófà ga;+
Ẹ jẹ́ ká jọ gbé orúkọ rẹ̀ ga.
ד [Dálétì]
4 Mo wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, ó sì dá mi lóhùn.+
Ó gbà mí sílẹ̀ nínú gbogbo ohun tó ń bà mí lẹ́rù.+
ה [Híì]
5 Ojú àwọn tó gbára lé e ń dán;
Kò sí ohun tó lè kó ìtìjú bá wọn.
ז [Sáyìn]
6 Aláìní yìí pe Jèhófà, ó sì gbọ́.
Ó gbà á nínú gbogbo wàhálà rẹ̀.+
ח [Hétì]
7 Áńgẹ́lì Jèhófà pàgọ́ yí àwọn tó bẹ̀rù Rẹ̀ ká,+
Ó sì ń gbà wọ́n sílẹ̀.+
ט [Tétì]
8 Ẹ tọ́ ọ wò, kí ẹ sì rí i pé ẹni rere ni Jèhófà,+
Aláyọ̀ ni ọkùnrin tí ó fi í ṣe ibi ààbò.
י [Yódì]
9 Ẹ bẹ̀rù Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ẹni mímọ́ rẹ̀,
Nítorí àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀ kò ní ṣaláìní.+
כ [Káfì]
10 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ebi máa ń pa àwọn ọmọ kìnnìún tó lágbára,
Àmọ́ ní ti àwọn tó ń wá Jèhófà, wọn kò ní ṣaláìní ohun rere.+
ל [Lámédì]
11 Ẹ wá, ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ fetí sí mi;
Màá kọ́ yín ní ìbẹ̀rù Jèhófà.+
מ [Mémì]
12 Ta ló fẹ́ máa gbádùn ìgbésí ayé rẹ̀ nínú yín
Tí ó sì fẹ́ ẹ̀mí gígùn, kó lè máa rí ohun rere?+
נ [Núnì]
13 Nígbà náà, ṣọ́ ahọ́n rẹ, má ṣe sọ ohun búburú,+
Má sì fi ètè rẹ ṣẹ̀tàn.+
ס [Sámékì]
14 Jáwọ́ nínú ohun búburú, kí o sì máa ṣe rere;+
Máa wá àlàáfíà, kí o sì máa lépa rẹ̀.+
ע [Áyìn]
15 Ojú Jèhófà wà lára àwọn olódodo,+
Etí rẹ̀ sì ṣí sí igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́.+
פ [Péè]
16 Àmọ́, Jèhófà kọjú ìjà sí àwọn tó ń ṣe ohun búburú,
Láti pa wọ́n rẹ́ kúrò láyé kí wọ́n sì di ẹni ìgbàgbé.+
צ [Sádì]
17 Wọ́n ké jáde, Jèhófà sì gbọ́;+
Ó gbà wọ́n sílẹ̀ nínú gbogbo wàhálà wọn.+
ק [Kófì]
18 Jèhófà wà nítòsí àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn;+
Ó ń gba àwọn tí àárẹ̀ bá ẹ̀mí wọn là.+
ר [Réṣì]
19 Ìṣòro olódodo máa ń pọ̀,+
Àmọ́ Jèhófà ń gbà á sílẹ̀ nínú gbogbo rẹ̀.+
ש [Ṣínì]
20 Ó ń dáàbò bo gbogbo egungun rẹ̀;
Kò sí ìkankan nínú wọn tí a ṣẹ́.+
ת [Tọ́ọ̀]
21 Àjálù ló máa pa ẹni burúkú;
A ó sì dẹ́bi fún àwọn tó kórìíra olódodo.
22 Jèhófà ń ra ẹ̀mí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pa dà;
Kò sí ìkankan lára àwọn tó fi í ṣe ibi ààbò tí a ó dá lẹ́bi.+