Kọ Awọn Ìrònú-Asán Ti Ayé Silẹ, Lepa Awọn Otitọ Gidi Ti Ijọba
“Ẹ maa ba a niṣo, nigba naa, ni wíwá ijọba naa ati ododo rẹ̀ lakọọkọ, gbogbo nǹkan miiran wọnyi ni a o sì fikun un fun yin.”—MATTEU 6:33, NW.
1. Ikilọ wo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọrun fi funni nipa ọkan-aya iṣapẹẹrẹ, ki sì ni ọ̀kan lara awọn ọ̀nà pataki ti ó ń gbà tàn wá jẹ?
“JU GBOGBO ohun ipamọ, pa àyà rẹ mọ́; nitori pe lati inu rẹ̀ wá ni orisun ìyè.” (Owe 4:23) Eeṣe ti o fi pọndandan fun ọlọgbọn Ọba Solomoni lati funni ni ikilọ yii? Nitori pe “ọkàn eniyan kún fun ẹ̀tàn ju ohun gbogbo lọ, o sì buru jayi!” (Jeremiah 17:9) Ọ̀kan lara awọn ọ̀nà pataki ti ọkan-aya iṣapẹẹrẹ wa lè gbà tàn wá jẹ ni nipa mimu wa lọwọ ninu awọn ìrònú-asán ti ayé. Ṣugbọn ki ni awọn ìrònú-asán jẹ? Wọn jẹ́ awọn ìfinúrò ti kì í ṣe otitọ gidi, awọn ìrònú adánúdùn, rírìn régberègbe èrò inu ti ohunkohun kò gbà láfiyèsí. Nigba ti awọn ìrònú adánúdùn wọnyi bá di ìrònú-asán ti ayé, wọn kì í wulẹ ṣe afi-akoko-ṣòfò nikan ṣugbọn wọn tún kún fun ipalara gan-an. Fun idi yii, a gbọdọ kọ̀ wọn silẹ patapata. Nitootọ, bi a bá koriira iwa-ailofin gẹgẹ bi Jesu ti ṣe, awa yoo pa ọkàn-àyà wa mọ kuro ninu lilọwọ ninu awọn ìrònú-asán ti ayé.—Heberu 1:8, 9.
2. Ki ni awọn ìrònú-asán ti ayé jẹ, eesitiṣe ti a fi gbọdọ kọ̀ wọn silẹ?
2 Ṣugbọn ki ni awọn ìrònú-asán ti ayé jẹ? Wọn jẹ awọn ìrònú-asán ti ó jẹ́ animọ ti ayé yii ti ó wà labẹ agbara Satani. Nipa rẹ̀, aposteli Johannu kọwe pe: “Ohun gbogbo ti ń bẹ ni ayé, ifẹkufẹẹ ara, ati ifẹkufẹẹ oju, ati irera ayé, kì í ṣe ti Baba, bikoṣe ti ayé.” (1 Johannu 2:16; 5:19) Eeṣe ti awọn Kristian fi gbọdọ kọ awọn ìrònú-asán ti ayé silẹ? Nitori pe iru awọn ìrònu-asán bẹẹ ń ru awọn ìfẹ́-ọkàn onimọtara-ẹni-nikan soke ninu èrò inu ati ọkan-aya. Rironu nipa ṣiṣe ohun tí kò tọna lati da ara-ẹni nínúdùn nitootọ lè jẹ́ àṣedánrawò kan ninu èrò inu nipa ohun ti ẹnikan yoo ṣe niti gidi. Ọmọ-ẹhin naa Jakọbu kilọ fun wa pe: “Olukuluku ni a ń danwo, nigba ti a bá ti ọwọ́ ifẹkufẹẹ araarẹ̀ fà á lọ ti a sì tàn án jẹ. Ǹjẹ́, ifẹkufẹẹ naa nigba ti o bá loyun, a bí ẹṣẹ: ati ẹṣẹ naa nigba ti o bá sì dagba tán, a bí ikú.”—Jakọbu 1:14, 15.
Awọn Apẹẹrẹ Onikilọ
3. Ọ̀ràn ta ni o pese apẹẹrẹ ikilọ ti o gba iwaju julọ nipa bi awọn ìrònú-asán onimọtara-ẹni-nikan ti kun fun ipalara tó?
3 Ẹ jẹ ki a gbé awọn apẹẹrẹ ti ń fi idi ti a fi gbọdọ kọ awọn ìrònú-asán ti ayé tì yẹwo. Ọ̀ràn ti Satani Eṣu pese apẹẹrẹ ti o gba iwaju julọ nipa ipalara ti ó lè jẹyọ lati inu lilọwọ ninu awọn ìrònú-asán onimọtara-ẹni-nikan. Ó fààyè gba awọn imọlara ijẹpataki ara-ẹni lati gbèrú ninu ọkan-aya rẹ̀ debi pe ó ṣe ìlara ipo alailẹgbẹ ti Jehofa gẹgẹ bi Ọba-alaṣe Agbaye ó sì fẹ́ ki a maa jọsin oun. (Luku 4:5-8) Ìrònú-asán ti kì í ṣe otitọ gidi ha ni bi? Dajudaju bẹẹ ni! Iyẹn ni a o fihàn rekọja iyemeji nigba ti a bá de Satani fun ẹgbẹrun ọdun ati ni pataki nigba ti a bá jù ú sọ sinu “adagun iná,” iku keji.—Ìfihàn 20:1-3, 10.
4. Bawo ni Satani ṣe tan Efa jẹ?
4 A ni apẹẹrẹ onikilọ miiran ninu ọ̀ràn ti obinrin akọkọ, Efa. Ninu awọn isapa Satani lati rí ohun ti o ni ìfẹ́-ọkàn lilagbara fun gbà, ó yi Efa lero pada dẹṣẹ nipa gbigbe ìrònú-asán kalẹ ninu èrò inu rẹ̀ pe bi o bá jẹ ninu eso ti a kà léèwọ̀ naa, oun ki yoo kú ṣugbọn yoo dabi Ọlọrun, ní mimọ rere ati buburu. Ǹjẹ́ ìrònú-asán yẹn ha jẹ́ alaijootọ gidi, onimọtara-ẹni-nikan bi? Nitootọ ó jẹ́ bẹẹ, gẹgẹ bi a ti lè rí i lati inu dídá ti Jehofa dá Efa ati ọkọ rẹ̀, Adamu lẹbi, nigba ti o ń ṣe ìgbẹ́jọ́. Gẹgẹ bi abajade, wọn padanu ẹ̀tọ́ ti wọn ní fun wiwalaaye ninu Paradise fun araawọn ati fun gbogbo awọn atọmọdọmọ wọn alaipe.—Genesisi 3:1-19; Romu 5:12.
5. Ki ni ó ṣokunfa iṣubu awọn angẹli ọmọkunrin Ọlọrun kan bayii, pẹlu iyọrisi wo sì ni fun wọn?
5 A tún ni apẹẹrẹ onikilọ ti awọn angẹli ọmọkunrin Ọlọrun kan bayii. (Genesisi 6:1-4) Dipo nini itẹlọrun pẹlu awọn ibukun ti wọn gbadun ni iwaju Jehofa ni ọ̀run, wọn ni ìrònú-asán nipa awọn obinrin lori ilẹ̀-ayé ati bi yoo ti gbadunmọni tó lati ni ibalopọ takọtabo pẹlu wọn. Nitori gbigbegbeesẹ lori awọn ìrònú-asán wọnyi, awọn angẹli alaigbọran naa ni a hámọ́ nisinsinyi sinu okunkun tẹmi ti Tartarus, ni diduro de iparun yán-án-yán-án wọn ni opin Iṣakoso Ẹgbẹrun Ọdun ti Jesu Kristi.—2 Peteru 2:4; Juda 6; Ìfihàn 20:10.
Kọ Awọn Ìrònú-Asán ti Ayé Silẹ
6, 7. Eeṣe ti awọn ìrònú-asán ti ayé nipa awọn ọrọ̀ ohun ti ara fi kun fun ipalara ti o si ń tannijẹ?
6 Ẹ jẹ ki a gbé ọ̀kan lara awọn ìrònú-asán ti o wọ́pọ̀ julọ ti o sì lewu julọ ti Satani ń ṣagbatẹru rẹ̀ yẹwo. Nipasẹ gbogbo ọ̀nà ti a ń gbà gbé irohin jade, a ń dẹ wá wò lati lọwọ ninu awọn ìrònú-asán ti ayé. Eyi ni òòfà ọkàn fun ọrọ̀ sábà maa ń fà. Ninu araarẹ̀, kò sí ohun ti o lodi pẹlu níní ọrọ̀. Abrahamu, Jobu, ati Ọba Dafidi oniwa-bi-Ọlọrun, jẹ́ ọlọ́rọ̀ gan-an, ṣugbọn wọn kò ní òòfà ọkàn fun awọn ọrọ̀ ohun ti ara. Awọn ìrònú-asán nipa ọrọ̀ alumọni sún awọn eniyan lati ṣiṣẹ ní àṣekúdórógbó fun ọpọ ọdun lati jere ọrọ̀. Iru awọn ìrònú-asán bẹẹ tun sún wọn lati lọwọ ninu gbogbo oniruuru tẹ́tẹ́ títa, gẹgẹ bii kíkọ́-iyàn lori ẹṣin ati ríra tikẹẹti tẹ́tẹ́ lọtiri. Ẹ maṣe jẹ́ ki a fààyè silẹ fun èrò òdì eyikeyii nipa ọrọ̀. Bi a bá ronu pe awọn ọrọ̀ ohun ti ara yoo pese aabo, gbé owe ti o jẹ́ otitọ gidi yii yẹwo: “Ọrọ̀ kì í ní anfaani ni ọjọ ibinu: ṣugbọn ododo ní í gbani lọwọ ikú.” (Owe 11:4) Nitootọ, awọn ọrọ̀ ohun ti ara kì yoo jamọ ohunkohun ninu lila “ipọnju ńlá” naa ja.—Matteu 24:21; Ìfihàn 7:9, 14.
7 Ọrọ̀ ohun ti ara lè fi tirọruntirọrun tàn wá jẹ. Idi niyẹn ti a fi sọ fun wa pe: “Ọrọ̀ ọlọ́rọ̀ ni ìlú-agbára rẹ̀, ó sì dabi odi giga ni oju araarẹ̀.” (Owe 18:11) Bẹẹni, kìkì “ni oju araarẹ̀,” nitori pe ọrọ̀ ohun ti ara kì í pese aabo ti ó pọ̀ tó ni akoko ifosoke-owo-ọja kikọyọyọ, ìwólulẹ ọrọ̀-ajé, irukerudo oṣelu, tabi aisan ti o lè fa iku. Jesu Kristi kilọ lodisi ìwà-ẹ̀gọ̀ ti gbigbe igbẹkẹle wa kari awọn ọrọ̀ ohun ti ara. (Luku 12:13-21) A tún ní awọn ọ̀rọ̀ ikilọ aposteli Paulu pe: “Ifẹ owo ni gbongbo ohun buburu gbogbo: eyi ti awọn miiran ń lepa ti a sì mu wọn ṣako kuro ninu igbagbọ, wọn sì fi ibinujẹ pupọ gun araawọn ni ọ̀kọ̀.”—1 Timoteu 6:10.
8. Bawo ni awọn ìrònú-asán ti ayé ti wọn jẹ ti ibalopọ takọtabo ti wọ́pọ̀ tó, awọn ewu wo sì ni iwọnyi gbekalẹ?
8 Awọn ìrònú-asán miiran tanmọ ibalopọ takọtabo ti kò bá ofin mu. Ìwọ̀n tí iwa ẹ̀dá eniyan ti o kun fun ẹṣẹ gba ń fẹ́ lati maa ronu lori awọn ìrònú-asán ti ibalopọ takọtabo de ni a lè rí lati inu igbajúmọ̀ ìsọ̀rọ̀ àlùfààṣà ti o wà larọọwọto nipa títẹ awọn nọmba tẹlifoonu kan bayii ati fifetisilẹ si awọn ihin-iṣẹ arufẹ-iṣekuṣe soke. Ni awọn ilu United States, ipese arufẹ-iṣekuṣe soke ti o wà larọọwọto nipasẹ tẹlifoonu jẹ́ iṣẹ́-ajé alaraadọta-ọkẹ lọna ẹgbẹẹgbẹrun owo dọ́là. Bi a bá nilati jẹ ki èrò inu wa maa wà ṣáá lori ibalopọ takọtabo ti ko ba ofin mu, awa ki yoo ha jẹ́ alagabagebe bi, ti a wulẹ ń farahan lati jẹ́ Kristian ti o mọ́ tonitoni? Kò ha sì sí ewu naa pe iru awọn ìrònú-asán bẹẹ lè jalẹ si ìsúnmọ́ra pẹkipẹki oniwa palapala bi? Eyi ti ṣẹlẹ ó sì ti yọrisi awọn kan ti a yọlẹgbẹ kuro ninu ijọ Kristian fun ṣiṣe agbere tabi panṣaga. Ni oju-iwoye awọn ọ̀rọ̀ Jesu ni Matteu 5:27, 28, gbogbo awọn wọnni ti wọn ń fi itẹpẹlẹmọ fi iru awọn ìrònú-asán bẹẹ kẹ́ araawọn bajẹ kò ha jẹbi didẹṣẹ panṣaga ninu ọkan-aya wọn bi?
9. Imọran rere wo ni Iwe Mimọ ní ninu lati kilọ fun wa lodisi awọn ìrònú-asán ti ayé?
9 Lati jà lodisi ìtẹ̀sí ọkan-aya wa ti o kún fun ẹṣẹ lati fi iru awọn ìrònú-asán bẹẹ kẹra ẹni bajẹ, a nilati fi ikilọ Paulu sọkan pe: “Kò sì sí ẹ̀dá kan ti kò farahan niwaju [Ọlọrun], ṣugbọn ohun gbogbo ni o wà nihooho ti a sì ṣipaya fun oju rẹ̀ ẹni ti awa ni iba lo.” (Heberu 4:13) A gbọdọ fẹ́ nigba gbogbo lati dabi Mose, ẹni ti o “duro ṣinṣin bi ẹni ti o ń rí ẹni airi.” (Heberu 11:27) Bẹẹni, a gbọdọ maa sọ fun araawa pe awọn ìrònú-asán ti ayé kò tẹ́ Jehofa lọrun ipalara nikan ni ó sì lè yọrisi fun wa. A gbọdọ daniyan nipa mimu gbogbo awọn eso ẹmi Ọlọrun dagba, ni pataki ikora-ẹni-nijaanu, nitori pe a kò lè bọ́ lọwọ otitọ naa pe bi a bá funrugbin si ipa ti ara, awa yoo ká idibajẹ lati inu ara.—Galatia 5:22, 23; 6:7, 8.
Awọn Otitọ Gidi ti Ijọba Naa
10, 11. (a) Awọn otitọ wo ni o gbe jíjẹ́ otitọ gidi Ẹlẹdaa lẹhin? (b) Ẹ̀rí wo ni o wà nibẹ pe Bibeli jẹ́ Ọrọ Ọlọrun niti tootọ? (c) Ẹ̀rí wo ni o wà nibẹ nipa jíjẹ́ otitọ gidi Ọba Ijọba Ọlọrun?
10 Ọ̀nà ti o dara julọ lati kọ awọn ìrònú-asán ti ayé silẹ ni lati maa lepa awọn otitọ gidi ti Ijọba. Awọn otitọ gidi ti Ijọba naa tí Ọlọrun pese duro ni iyatọ gédégédé si awọn ìrònú-asán ti ayé. Ọlọrun ha jẹ́ otitọ gidi bi? Ko sí tàbí-tàbí nipa wíwà rẹ̀. Iṣẹda ti a lè fojuri jẹrii si otitọ yẹn. (Romu 1:20) A rán wa leti nipa ohun ti a sọ ni nǹkan ti o ju ọgọrun-un ọdun sẹhin lọ ninu iwe naa The Divine Plan of the Ages, ti a tẹjade lati ọwọ Watch Tower Society. Ó sọ pe: “Ẹni ti o lè boju wo ofuurufu pẹlu awò ti a fi ń wo ọ̀nà jíjìn, tabi pẹlu oju gidi nikan, ti ó sì rí ọpọ jantirẹrẹ iṣẹda nibẹ, igunrege, ẹwà, wíwà letoleto, iṣọkan ati ìjọ́lọ́kan-kò-jọ̀kan rẹ̀, sibẹ ti o sì ṣiyemeji pe Ẹlẹdaa awọn nǹkan wọnyi jẹ́ onipo gigaju ní ọgbọ́n ati agbara lọna ti o gadabú, tabi ti ó lè tànmọ́-ọ̀n fun akoko kukuru pe iru awọn ìwà letoleto bẹẹ wà lọna akọsẹba, laisi Ẹlẹdaa kan, dé iru ìwọ̀n giga bẹẹ ti padanu tabi ṣainaani ọgbọn ironu debi ti a fi le kà á sí ohun ti Bibeli pè é lọna ti o bojumu, aṣiwere (ẹnikan ti o ṣainaani tabi ṣalaini ironu).”—Orin Dafidi 14:1.
11 A mọ gbogbo ohun ti o niiṣe pẹlu Ijọba naa ninu Bibeli Mimọ. Ǹjẹ́ Bibeli niti tootọ ha jẹ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti a kọsilẹ bi? Ó daju julọ pe ó jẹ bẹẹ, gẹgẹ bi a ti lè rí i lati inu iṣọkan rẹ̀, ìpéye rẹ̀ niti ìmọ̀ ijinlẹ, ati agbara rẹ̀ lati yi igbesi-aye awọn eniyan pada ati ni pataki nipa imuṣẹ awọn asọtẹlẹ rẹ̀.a Ki ni nipa Ọba Ijọba Ọlọrun, Jesu Kristi? Oun ha wà nitootọ bi? Awọn akọsilẹ Ihinrere ati awọn lẹta onimiisi atọrunwa ti Iwe Mimọ Kristian lede Griki jẹrii si jíjẹ́ ẹni gidi Jesu Kristi ninu ọ̀rọ̀ ìtàn laisi tabi-ṣugbọn ati lọna jijagaara. Niti jíjẹ́ ẹni gidi Jesu ninu ọ̀rọ̀ ìtàn, ẹ̀rí tún wà niti Talmud ti awọn Ju, eyi ti o tọka sí i bi eniyan kan. Bẹẹ pẹlu ni awọn opitan Ju ati Romu ti ọrundun kìn-ín-ní C.E. ti ṣe.
12, 13. Awọn otitọ wo ni wọn jẹrii si otitọ gidi Ijọba Ọlọrun?
12 Ki ni nipa ijotiitọ gidi ti Ijọba naa funraarẹ? Kristẹndọm ṣainaani rẹ̀ lọna ti o gbooro julọ, gẹgẹ bi a ti fihàn ninu ìráhùn onisin Presbyterian ti o yọri ọlá yii pe: “Niti gidi ó ti ju ọgbọ̀n ọdun lọ ti mo ti fetisilẹ gbẹhin si igbiyanju ojiṣẹ kan lati ṣalaye fun awọn eniyan rẹ̀ nipa jíjẹ́ otitọ gidi Ijọba naa fun wọn.” Sibẹ, isọdimimọ orukọ Jehofa nipasẹ Ijọba naa ni ẹṣin-ọrọ Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ọlọrun funraarẹ ṣe ileri Ijọba akọkọ, ni sisọ pe: “Emi yoo sì fi ọ̀tá saaarin iwọ ati obinrin naa, ati saaarin iru-ọmọ rẹ ati iru-ọmọ rẹ̀: oun yoo fọ́ ọ ni ori, iwọ yoo sì pa á ni gigisẹ.” (Genesisi 3:15) Ijọba naa ni orilẹ-ede Israeli jẹ́ ojiji iṣaaju fun, ni pataki ni akoko iṣakoso Ọba Solomoni. (Orin Dafidi 72) Siwaju sii, Ijọba naa ni ẹṣin-ọrọ iwaasu Jesu. (Matteu 4:17) Ó fun un ni afiyesi pataki julọ ninu ọpọ awọn àkàwé rẹ̀, bii iru awọn wọnni ti ó wà ninu Matteu ori 13. Jesu sọ fun wa lati gbadura fun Ijọba naa ki a sì maa baa lọ ni wíwá a lakọọkọ. (Matteu 6:9, 10, 33) Nitootọ, Ijọba Ọlọrun ni a mẹnukan ni ohun ti o sunmọ 150 ìgbà ninu Iwe Mimọ Kristian lede Griki.
13 Ijọba naa jẹ́ akoso gidi kan, ti o ni agbara ati ọla-aṣẹ, yoo sì mu gbogbo awọn ifojusọna titọna ṣẹ. Ó ní ọ̀wọ́ awọn ofin, ti a rí ninu Bibeli. Ijọba naa ti mú ọpọlọpọ nǹkan jásí otitọ gidi. Ó ni awọn ọmọ-abẹ aduroṣinṣin—iye Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti wọn ju 4,000,000 lọ. Ni 211 ilẹ, wọn ń waasu ihinrere Ijọba Ọlọrun, ni imuṣẹ Matteu 24:14. Ni ọdun iṣẹ-isin wọn ti 1991, wọn lo 951,870,021 wakati ninu wiwaasu ihin-iṣẹ Ijọba naa. Igbokegbodo yii ń mú awọn aṣeyọri ti ó tójúúwò, pipẹtiti jade gẹgẹ bi awọn ogidigbo ti ń kẹkọọ “ede mimọgaara” ti otitọ Bibeli.—Sefaniah 3:9, NW.
Lilepa Awọn Otitọ Gidi ti Ijọba
14. Bawo ni a ṣe lè fun imọriri wa fun otitọ gidi ti Ijọba naa lokun?
14 Bawo, nigba naa ni a ṣe lè lepa awọn otitọ gidi ti Ijọba? Ireti wa ni a gbọdọ gbekari idaniloju lilagbara laisewu. Ileri ayé titun Ọlọrun gbọdọ jẹ́ otitọ gidi si wa. (2 Peteru 3:13) A sì gbọdọ ní igbagbọ ninu ileri naa pe Ọlọrun “yoo sì nu omije gbogbo nù kuro ni oju [wa]; ki yoo sì sí ikú mọ́ tabi ọ̀fọ̀, tabi ẹkún, bẹẹ ni ki yoo sí irora mọ́.” (Ìfihàn 21:4) Bawo ni o ṣe lè dá wa loju pe eyi kì í ṣe ìrònú-asán kan? Ó di dandan pe ọwọ́ yoo tẹ̀ ẹ́ ni akoko ti o wọ̀ ni oju Ọlọrun, nitori pe kò ṣeeṣe fun un lati ṣèké. (Titu 1:1, 2; Heberu 6:18) A nilati ronu jinlẹ lori awọn ileri wọnni. Ni yiyaworan araawa pe a wà ninu ayé titun ti Ọlọrun ti a sì ń gbadun awọn ibukun rẹ̀ kì í ṣe ìrònú-asán kan ti kì í ṣe otitọ gidi ṣugbọn ó funni ni ẹ̀rí igbagbọ. Gẹgẹ bi Paulu ti tumọ rẹ̀, “igbagbọ ni ifojusọna ti a mudaniloju ti awọn ohun ti a ń reti, aṣefihan ti o hàn gbangba ti awọn otitọ gidi bi a kò tilẹ rí wọn.” (Heberu 11:1, NW) Ẹ jẹ ki a mú igbagbọ wa lokun nipa jíjẹ ninu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ati awọn itẹjade Kristian ti ń ràn wa lọwọ lati loye ki a sì fi í silo deedee. Bi akoko ti a ń lò ninu sisọ fun awọn ẹlomiran nipa Ijọba naa, lọna bi aṣa ati lọna aijẹ bi aṣa ba ti tubọ pọ̀ tó, bẹẹ ni a ń fun igbagbọ wa lokun tó ti a sì ń mú ireti wa ninu rẹ̀ mọlẹ kedere sii tó.
15. Iṣẹ aigbọdọmaṣe wo ni a ní nipa iṣẹ-ojiṣẹ Kristian?
15 A tun nilati ṣiṣẹ ni ibamu pẹlu awọn otitọ gidi Ijọba naa nipa mimu ojulowo iṣẹ-ojiṣẹ wa sunwọn sii. Niwọn bi pupọ sii ṣì ti wà ti a nilati ṣe, bawo ni awa ṣe lè ṣe eyi? (Matteu 9:37, 38) Otitọ ni ọ̀rọ̀ naa pe ẹnikan kii dagba ju lati kẹkọọ. Kò sí bi o ti wu ki ọdun ti a ti ń ṣajọpin ninu iṣẹ ijẹrii ti pọ tó, a lè sunwọn sii. Nipa titubọ di ọjafafa ninu lilo Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, o tubọ ṣeese fun wa lati ran awọn ẹlomiran lọwọ lati gbọ́ ohùn Ọba naa, Jesu Kristi. (Fiwe Johannu 10:16.) Nigba ti a bá rí i pe kadara ayeraye awọn eniyan wémọ́ ọn, a gbọdọ fẹ́ lati kari ipinlẹ wa kúnnákúnna ki a baa lè fun wọn ni anfaani leralera lati ṣaṣehan apa ibi ti wọn duro si, yala gẹgẹ bi “agutan” tabi gẹgẹ bi “ewurẹ.” (Matteu 25:31-46) Dajudaju, iyẹn tumọsi pípa awọn akọsilẹ ti a fi iṣọra ṣe nipa awọn wọnni ti wọn kò sí nile mọ́ ati ni pataki awọn wọnni ti wọn fifẹhan ninu ihin-iṣẹ Ijọba naa.
Maa Baa Lọ Ni Lilepa Ijọba Naa
16. Awọn wo ni wọn ti gbé apẹẹrẹ rere kalẹ ninu lilepa awọn otitọ gidi Ijọba, bawo sì ni wọn ṣe ‘ń fi ipa gba’ Ijọba naa?
16 Isapa afitọkantọkanṣe ni a beere fun lati maa baa lọ ni lilepa awọn otitọ Ijọba. A kò ha fun wa niṣiiri nipasẹ apẹẹrẹ onitara ti awọn Kristian aṣẹku ẹni-ami-ororo bi? Wọn ti ń lepa otitọ gidi ti Ijọba naa fun ọpọ ẹwadun. Ilepa yii ni a ṣapejuwe ninu awọn ọ̀rọ̀ Jesu pe: “Lati ìgbà ọjọ Johannu Baptisi wá, titi o fi di isinsinyi ni ijọba ọrun di ifi agbara wọ, awọn alagbara sì fi ipá gbà á.” (Matteu 11:12) Nihin-in èrò naa kì í ṣe ti awọn ọ̀tá ti ń fipa gba Ijọba. Kaka bẹẹ, eyi tan mọ igbokegbodo awọn wọnni ti wọn wà ni ìlà fun Ijọba naa. Ọmọwe Bibeli kan sọ pe: “Ni ọ̀nà yii ni a gbà ṣapejuwe iyanhanhan yẹn, ilakaka ti kò ṣee má ṣe ati jíjà fitafita fun Ijọba ti Messia naa ti ń bọ.” Awọn ẹni-ami-ororo kò ṣailo gbogbo isapa ninu sisọ Ijọba naa di tiwọn. Isapa tagbaratagbara bakan naa ni a beere fun lọdọ “awọn agutan miiran” ki wọn baa lè tootun gẹgẹ bi ọmọ-abẹ Ijọba ọ̀run ti Ọlọrun.—Johannu 10:16.
17. Ki ni yoo jẹ́ ìpín ti awọn wọnni ti wọn ń lepa awọn ìrònú-asán ti ayé?
17 Loootọ, a ń gbé ni akoko akanṣe fun anfaani. Awọn wọnni ti wọn lepa awọn ìrònú-asán ti ayé ni oju wọn maa to là gbòò sí awọn otitọ gidi lilekoko ni ọjọ kan. Ìpín wọn ni a ṣapejuwe lọna didara ninu awọn ọ̀rọ̀ wọnyi pe: “Yoo sì dabi ìgbà ti ẹni ebi ń pa ń lá àlá; sì wò ó, ó ń jẹun; ṣugbọn ó jí, ọkàn rẹ̀ sì ṣofo: tabi bi ìgbà ti ẹni ti oungbẹ ń gbẹ ń lá àlá, si wò ó, o ń mu omi, ṣugbọn o ji, si wo o, o dáku, oungbẹ sì ń gbẹ ọkàn rẹ̀.” (Isaiah 29:8) Dajudaju laisi tabi-ṣugbọn, awọn ìrònú-asán ayé ki yoo mú ki ẹnikẹni nitẹẹlọrun ki o si layọ lae.
18. Ni oju iwoye otitọ gidi ti Ijọba naa, ipa-ọna igbesẹ wo ni a gbọdọ lepa, pẹlu ifojusọna wo ni iwaju si ni?
18 Ijọba Jehofa jẹ́ otitọ gidi. Ó ń ṣakoso pẹlu igbekankan, nigba ti o jẹ pe eto igbekalẹ awọn nǹkan buburu yii dojukọ iparun titilọ gbere, ti o rọdẹdẹ. Nitori naa, fi imọran Paulu sọkan: “Ẹ maṣe jẹ ki a sùn, bi awọn iyoku ti ń ṣe; ṣugbọn ẹ jẹ ki a maa ṣọna ki a sì maa wà ni airekọja.” (1 Tessalonika 5:6) Ǹjẹ́ ki a pa ọkan-aya ati èrò inu wa mọ sori awọn otitọ gidi ti Ijọba ki a sì tipa bayii gbadun awọn ibukun ayeraye. Ǹjẹ́ ki o sì di ìpín tiwa lati gbọ́ ki Ọba Ijọba yẹn sọ fun wa pe: “Ẹ wá, ẹyin alabukun fun Baba mi, ẹ jogun ijọba, ti a ti pese silẹ fun yin lati ọjọ ìwà.”—Matteu 25:34.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo iwe naa The Bible—God’s Word or Man’s? ti a tẹjade lati ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?
◻ Ki ni awọn ìrònú-asán ti ayé jẹ, eesitiṣe ti a fi gbọdọ kọ̀ wọn silẹ?
◻ Awọn apẹẹrẹ wo ni o fi ìwà-ẹ̀gọ̀ lilọwọ ninu awọn ìrònú-asán ti ayé hàn?
◻ Awọn otitọ wo ni wọn fẹ̀rí jíjẹ́ otitọ gidi Ẹlẹdaa naa, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti a kọsilẹ, Jesu Kristi, ati Ijọba rẹ̀ hàn?
◻ Bawo ni a ṣe lè fun igbagbọ wa ninu awọn otitọ gidi ti Ijọba lokun?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Awọn ìrònú-asán ti ayé ni òòfà ọkan fun ọrọ̀ ohun ti ara sábà maa ń fà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Wiwaasu ihinrere naa jẹ́ ọ̀nà kan lati lepa awọn otitọ gidi ti Ijọba
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Iwọ ha ń lepa awọn otitọ gidi ti Ijọba nipa fifi taapọntaapọn kẹkọọ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun bi?