Ti Jèhófà ni Ìgbàlà
“Ọlọ́run tòótọ́ jẹ́ Ọlọ́run oníṣẹ́ ìgbàlà fún wa.”—SÁÀMÙ 68:20.
1, 2. (a) Èé ṣe tí a fi lè sọ pé Jèhófà ni Orísun ìgbàlà? (b) Báwo ni ìwọ yóò ṣe ṣàlàyé Òwe 21:31?
JÈHÓFÀ ni Olùgbàlà àwọn ẹ̀dá ènìyàn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Aísáyà 43:11) Ọba Dáfídì, tí í ṣe gbajúmọ̀ ọba Ísírẹ́lì, mọ èyí láti inú ìrírí ara rẹ̀, ó sì fi tọkàntọkàn kọ ọ́ lórin pé: “Ìgbàlà jẹ́ ti Jèhófà.” (Sáàmù 3:8) Wòlíì náà, Jónà, lo irú àwọn ọ̀rọ̀ kan náà nínú àdúrà àtọkànwá nígbà tó wà nínú ẹja mùmùrara náà.—Jónà 2:9.
2 Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì pẹ̀lú mọ̀ pé Jèhófà ni Orísun ìgbàlà, nítorí ó sọ pé: “Ẹṣin ni ohun tí a pèsè sílẹ̀ fún ọjọ́ ìjà ogun, ṣùgbọ́n ti Jèhófà ni ìgbàlà.” (Òwe 21:31) Ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ìgbàanì, màlúù ní ń fa ohun èlò ìtúlẹ̀, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní ń rẹrù, àwọn ènìyàn ní ń gun ìbaaka, ẹṣin sì ni wọ́n ń lò lójú ogun. Àmọ́ ṣá o, kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wọ Ilẹ̀ Ìlérí, ni Ọlọ́run ti pàṣẹ pé kí ọba wọn ẹ̀yìnwá ọ̀la “má ṣe mú ẹṣin pọ̀ sí i fún ara rẹ̀.” (Diutarónómì 17:16) Àwọn ẹṣin ogun kò ní wúlò nítorí pé Jèhófà yóò gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là.
3. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ kí a gbé yẹ̀ wò?
3 Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ jẹ́ “Ọlọ́run oníṣẹ́ ìgbàlà.” (Sáàmù 68:20) Èrò yìí mà ń múni lọ́kàn le o! Ṣùgbọ́n ‘àwọn iṣẹ́ ìgbàlà’ wo ni Jèhófà ti ṣe? Àwọn wo sì ni ó ti gbà là?
Jèhófà Ń Gba Àwọn Adúróṣánṣán Là
4. Báwo ni a ṣe mọ̀ pé Jèhófà ń gba àwọn olùfọkànsìn là?
4 Gbogbo àwọn tí ń tọ ipa ọ̀nà ìdúróṣánṣán gẹ́gẹ́ bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó ti ṣe ìyàsímímọ́ lè fi ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pétérù tu ara wọn nínú, pé: “Jèhófà mọ bí a ti ń dá àwọn ènìyàn tí ń fọkàn sin Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò, ṣùgbọ́n láti fi àwọn aláìṣòdodo pa mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ láti ké wọn kúrò.” Pétérù fẹ̀rí ti kókó yìí lẹ́yìn, nípa sísọ pé Ọlọ́run kò “fawọ́ sẹ́yìn ní fífìyàjẹ ayé ìgbàanì, ṣùgbọ́n ó pa Nóà, oníwàásù òdodo mọ́ láìséwu pẹ̀lú àwọn méje mìíràn nígbà tí ó mú àkúnya omi wá sórí ayé àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.”—2 Pétérù 2:5, 9.
5. Àwọn ìpo wo ló yí Nóà ká nígbà tó fi jẹ́ “oníwàásù òdodo”?
5 Fojú inú wò ó pé o bá ara rẹ nínú àwọn ipò tó gbòde kan lọ́jọ́ Nóà. Àwọn ẹ̀mí èṣù tó gbára wọ̀ ń bẹ láyé. Ọmọ àwọn áńgẹ́lì aláìgbọràn wọ̀nyí ń ṣe àwọn èèyàn bọ́ṣẹ ṣe ń ṣojú, “ilẹ̀ ayé sì wá kún fún ìwà ipá.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:1-12) Àmọ́ ṣá o, kò sẹ́ni tó lè dún mọ̀huru-mọ̀huru mọ́ Nóà tí yóò fi wá pa iṣẹ́ ìsìn Jèhófà tì. Kàkà bẹ́ẹ̀, òun jẹ́ “oníwàásù òdodo.” Òun àti ìdílé rẹ̀ kan ọkọ áàkì, wọn kò sì ṣiyè méjì rárá pé a óò mú ìwà ibi kúrò nígbà ayé wọn. Ìgbàgbọ́ Nóà dá ayé yẹn lẹ́bi. (Hébérù 11:7) Ipò àwọn nǹkan lóde òní bá ti ọjọ́ Nóà mu, tó fi hàn pé a ti wà ní ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn nǹkan búburú yìí. (Mátíù 24:37-39; 2 Tímótì 3:1-5) Fún ìdí yìí, gẹ́gẹ́ bíi Nóà, ìwọ yóò ha jẹ́ adúróṣinṣin bí oníwàásù òdodo tí ń sìn pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọ́run bí o ti ń dúró de ìgbàlà Jèhófà bí?
6. Báwo ni 2 Pétérù 2:7, 8 ṣe fi hàn pé Jèhófà ń gba àwọn adúróṣánṣán là?
6 Pétérù pèsè àfikún ẹ̀rí tó fi hàn pé Jèhófà ń gba àwọn adúróṣánṣán là. Àpọ́sítélì náà sọ pé: “[Ọlọ́run] dá Lọ́ọ̀tì olódodo nídè, ẹni tí ìkẹ́ra-ẹni-bàjẹ́ nínú ìwà àìníjàánu àwọn aṣàyàgbàǹgbà pe òfin níjà kó wàhálà-ọkàn bá gidigidi—nítorí ohun tí ọkùnrin olódodo yẹn rí, tí ó sì gbọ́ nígbà tí ó ń gbé láàárín wọn láti ọjọ́ dé ọjọ́ ń mú ọkàn òdodo rẹ̀ joró nítorí àwọn ìṣe àìlófin wọn.” (2 Pétérù 2:7, 8; Jẹ́nẹ́sísì 19:1-29) Ìṣekúṣe ti di mọ́líkì fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn lọ́jọ́ ìkẹyìn yìí. Bí Lọ́ọ̀tì, ‘wàhálà-ọkàn ha ń bá ọ gidigidi’ nítorí fífi tí ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ‘ń fi ìwà àìníjàánu kẹ́ra bà jẹ́’? Bí wàhálà ọkàn bá ń bá ọ, bí o bá sì ń fi òdodo ṣèwà hù, o lè wà lára àwọn tí Jèhófà yóò gbà là nígbà tí a bá mú ètò búburú yìí wá sópin.
Jèhófà Ń Gba Àwọn Ènìyàn Rẹ̀ Lọ́wọ́ Àwọn Aninilára
7. Báwo ni ìbálò Jèhófà pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n wà ní Íjíbítì ṣe fi hàn pé ó máa ń gba àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́wọ́ ìnilára?
7 Níwọ̀n ìgbà tí ètò ògbólógbòó yìí bá ṣì ń bá a lọ, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà yóò máa dojú kọ inúnibíni àti ìnilára ọ̀tá. Ṣùgbọ́n ó yẹ kí wọ́n ní ìdánilójú pé Jèhófà yóò dá wọn nídè, nítorí pé ó ti gba àwọn ènìyàn rẹ̀ tí a ń ni lára là nígbà àtijọ́. Ká sọ pé ọmọ Ísírẹ́lì ni ọ́, tí àwọn ọmọ Íjíbítì ọjọ́ Mósè ń ni lára. (Ẹ́kísódù 1:1-14; 6:8) Ọlọ́run wá fi ọ̀kan kò jọ̀kan ìyọnu kọlu Íjíbítì. (Ẹ́kísódù 8:5–10:29) Nígbà tí panipani ìyọnu kẹwàá gbẹ̀mí àwọn àkọ́bí Íjíbítì, Fáráò jọ̀wọ́ Ísírẹ́lì sí, ṣùgbọ́n lẹ́yìn náà ló tún kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ, ó sì gbá tẹ̀ lé wọn. Ṣùgbọ́n láìpẹ́ lòun àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pa run sínú Òkun Pupa. (Ẹ́kísódù 14:23-28) O wá ń bá Mósè àti gbogbo Ísírẹ́lì kọ orin yìí: “Jèhófà jẹ́ akin lójú ogun. Jèhófà ni orúkọ rẹ̀. Àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin Fáráò àti àwọn ẹgbẹ́ ológun rẹ̀ ni ó sọ sínú òkun, ààyò àwọn jagunjagun rẹ̀ sì ni a ti rì sínú Òkun Pupa. Omi ríru bẹ̀rẹ̀ sí bò wọ́n; wọ́n lọ sísàlẹ̀ inú ibú bí òkúta.” (Ẹ́kísódù 15:3-5) Irú àgbákò bẹ́ẹ̀ ń dúró de àwọn tí ń ni àwọn ènìyàn Ọlọ́run lára lọ́jọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí.
8, 9. Láti inú ìwé Onídàájọ́, mú àpẹẹrẹ kan wá tó fi hàn pé Jèhófà ń gba àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn aninilára.
8 Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, àwọn onídàájọ́ ní ń ṣèdájọ́ láàárín wọn. Nígbà mìíràn, àwọn ará ilẹ̀ òkèèrè máa ń tẹ̀ wọ́n lórí ba, síbẹ̀ Ọlọ́run máa ń lo àwọn onídàájọ́ tí wọ́n jẹ́ ẹni ìgbàgbọ́ láti dá wọn nídè. Bí àwa náà tilẹ̀ ń kérora lọ́nà kan náà ‘nítorí àwọn tí ń ni wá lára àti àwọn tí ń tì wá gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n kiri,’ Jèhófà yóò gbà wá pẹ̀lú gẹ́gẹ́ bí ó ti gba àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ̀. (Onídàájọ́ 2:16-18; 3:9, 15) Ní tòótọ́, ìwé Onídàájọ́ nínú Bíbélì mú èyí dá wa lójú, ó sì tún mú un dá wa lójú pé Ọlọ́run yóò pèsè ìgbàlà tó ju èyíinì lọ nípasẹ̀ Jésù Kristi, Onídàájọ́ tí òun yàn.
9 Ẹ jẹ́ ká padà sí ọjọ́ Onídàájọ́ Bárákì. Nítorí ìjọsìn èké àti ìbínú Ọlọ́run, ogún ọdún gbáko ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi jẹ baba ńlá ìyà lọ́wọ́ Ọba Jábínì ti ilẹ̀ Kénáánì. Sísérà ni ààrẹ ọ̀nà kakaǹfò ẹgbẹ́ ogun ńlá ilẹ̀ Kénáánì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó mílíọ̀nù mẹ́rin níye, ṣùgbọ́n “a kò rí apata kan, tàbí aṣóró kan, láàárín ọ̀kẹ́ méjì ní Ísírẹ́lì.” (Onídàájọ́ 5:6-8) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ìrònúpìwàdà ké pe Jèhófà. Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti lànà sílẹ̀ nípasẹ̀ Dèbórà wòlíì obìnrin, Bárákì kó ẹgbàárùn-ún [10,000] ọkùnrin jọ sórí Òkè Tábórì, Jèhófà sì fa àwọn ọ̀tá gòkè àfonífojì tó wà nísàlẹ̀ Tábórì, òkè àwòṣífìlà. Ẹgbàágbèje àwọn ọmọ ogun Sísérà àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún [900] kẹ̀kẹ́ ogun rèé tó rọ́ dé gìrìgìrì, wọ́n ya bo gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà títí lọ dé àfonífojì gbígbẹ ti odò Kíṣónì. Ṣùgbọ́n wábi-wọ́sí òjò wá bẹ̀rẹ̀ sí rọ̀ títí odò Kíṣónì fi kún àkúnya. Bí Bárákì àti àwọn èèyàn rẹ̀ ti ń bọ̀ nísàlẹ̀ Òkè Tábórì nínú ẹ̀fúùfù líle náà, wọ́n rí ọṣẹ́ tí ìbínú Jèhófà ti ṣe. Bí àwọn ọmọ Kénáánì tí ojora ti mú ti ń sá kolobá-kolobà, àwọn èèyàn Bárákì bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n lọ́kọ̀ọ̀kan, ìkankan kò sì sá là. Ìkìlọ̀ pàtàkì lèyí o fún àwọn tí ń pọ́n wa lójú, tí àyà kò fò wọ́n láti bá Ọlọ́run jà!—Onídàájọ́ 4:3-16; 5:19-22.
10. Èé ṣe tí a fi ní ìdánilójú pé Ọlọ́run yóò gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ òde òní lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí ń ni wọ́n lára?
10 Jèhófà yóò gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ọjọ́ òní lọ́wọ́ gbogbo ọ̀tá tí ń ni wọ́n lára, bí ó ti gba Ísírẹ́lì olùbẹ̀rù Ọlọ́run là nígbà ìṣòro. (Aísáyà 43:3; Jeremáyà 14:8) Ọlọ́run dá Dáfídì nídè “kúrò ní àtẹ́lẹwọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀.” (2 Sámúẹ́lì 22:1-3) Nítorí náà, bí a bá tilẹ̀ ń ni wá lára tàbí tí a ń ṣe inúnibíni sí wa gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn Jèhófà, ẹ jẹ́ kí a ní ìgboyà, nítorí pé Mèsáyà Ọba yóò gbà wá lọ́wọ́ ìnilára. Bẹ́ẹ̀ ni, yóò “gba ọkàn àwọn òtòṣì là. Yóò tún ọkàn wọn rà padà lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá.” (Sáàmù 72:13, 14) Ìtúnniràpadà yẹn sún mọ́lé ní tòótọ́.
Ọlọ́run Ń Gba Àwọn Tó Gbẹ́kẹ̀ Lé E Là
11. Àpẹẹrẹ wo ni Dáfídì tó jẹ́ ọ̀dọ́mọdé pèsè ní ti gbígbáralé Jèhófà?
11 Láti rí ìgbàlà Jèhófà, a ní láti gbẹ́kẹ̀ lé e tìgboyà-tìgboyà. Dáfídì gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run tìgboyà-tìgboyà nígbà tó jáde lọ ko Gòláyátì òmìrán lójú. Fojú inú wo Filísínì fìrìgbọ̀ngbọ̀n yẹn tó dúró níwájú Dáfídì kú-ń-tá, ẹni tó wí pé: “Ìwọ ń bọ̀ lọ́dọ̀ mi pẹ̀lú idà àti ọ̀kọ̀ àti ẹ̀ṣín, ṣùgbọ́n èmi ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ pẹ̀lú orúkọ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run àwọn ìlà ogun Ísírẹ́lì, ẹni tí ìwọ ti ṣáátá. Lónìí yìí, Jèhófà yóò fi ọ́ lé mi lọ́wọ́, dájúdájú, èmi yóò sì ṣá ọ balẹ̀, èmi yóò sì mú orí rẹ kúrò lára rẹ; dájúdájú, èmi yóò sì fi àwọn òkú ibùdó àwọn Filísínì fún àwọn ẹ̀dá abìyẹ́ ojú ọ̀run lónìí yìí àti fún àwọn ẹranko ìgbẹ́ ilẹ̀ ayé; àwọn ènìyàn gbogbo ilẹ̀ ayé yóò sì mọ̀ pé Ọlọ́run kan wà tí ó jẹ́ ti Ísírẹ́lì. Gbogbo ìjọ yìí yóò sì mọ̀ pé kì í ṣe idà tàbí ọ̀kọ̀ ni Jèhófà fi ń gbani là, nítorí pé ti Jèhófà ni ìjà ogun náà.” Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, Gòláyátì ti kú, ni àwọn Filísínì bá họ. Dájúdájú, Jèhófà gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là.—1 Sámúẹ́lì 17:45-54.
12. Èé ṣe tí yóò fi dára láti rántí Élíásárì, ọ̀kan lára àwọn akọni Dáfídì?
12 Nígbà tí a bá dojú kọ àwọn onínúnibíni, a ní láti “máyàle,” kí a sì gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run pátápátá. (Aísáyà 46:8-13; Òwe 3:5, 6) Gbé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí yẹ̀ wò, èyí tó ṣẹlẹ̀ níbì kan tí a ń pè ní Pasi-dámímù. Ísírẹ́lì ti sá padà níwájú àwọn ọmọ ogun Filísínì. Ṣùgbọ́n jìnnìjìnnì kò bo Élíásárì, tí í ṣe ọ̀kan lára àwọn akọni mẹ́ta Dáfídì. Kò kúrò ní ibi tó dúró sí nínú oko ọkà báálì kan, ó sì dá nìkan fi idà ṣá àwọn Filísínì balẹ̀. Nípa báyìí, ‘Jèhófà fi ìgbàlà ńlá gba Ísírẹ́lì là.’ (1 Kíróníkà 11:12-14; 2 Sámúẹ́lì 23:9, 10) Kò sẹ́ni tó retí pé ká dá nìkan ṣẹ́gun ẹgbẹ́ ológun. Síbẹ̀, a lè dá wà nígbà mìíràn, kí àwọn ọ̀tá sì bẹ̀rẹ̀ sí dún mọ̀huru-mọ̀huru mọ́ wa. A ó ha fi tàdúrà-tàdúrà gbára lé Jèhófà, Ọlọ́run oníṣẹ́ ìgbàlà bí? A ó ha wá ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ kí a lè yẹra fún fífi àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa han àwọn onínúnibíni bí?
Jèhófà Máa Ń Gba Àwọn Olùpàwàtítọ́mọ́ Là
13. Èé ṣe tó fi ṣòro láti pa ìwà títọ́ mọ́ sí Ọlọ́run nínú ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì?
13 Láti lè rí ìgbàlà Jèhófà, a gbọ́dọ̀ pa ìwà títọ́ mọ́ sí i láìka ohun tó máa gbà sí. Àwọn ènìyàn Ọlọ́run ní ìgbàanì fojú winá onírúurú àdánwò. Ronú nípa ohun tí ìwọ ì bá dojú kọ ká ní o ń gbé ní ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì. Ọwọ́ líle koko tí Rèhóbóámù fi mú àwọn èèyàn mú kí ẹ̀yà mẹ́wàá dẹ̀yìn lẹ́yìn rẹ̀, wọ́n sì para pọ̀ di ìjọba àríwá Ísírẹ́lì. (2 Kíróníkà 10:16, 17; 11:13, 14) Lára ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọba tó jẹ nínú ìjọba yẹn, Jéhù ló ṣe dáradára jù, ṣùgbọ́n òun alára ‘kò fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ̀ rìn nínú òfin Jèhófà.’ (2 Àwọn Ọba 10:30, 31) Síbẹ̀síbẹ̀, ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá náà ní àwọn olùpàwàtítọ́mọ́. (1 Àwọn Ọba 19:18) Wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ó sì wà pẹ̀lú wọn. Láìka àwọn ìdánwò ìgbàgbọ́ rẹ sí, o ha ń pa ìwà títọ́ mọ́ sí Jèhófà bí?
14. Ìgbàlà wo ni Jèhófà pèsè ní ọjọ́ Hesekáyà Ọba, kí sì ni ó fà á tí àwọn ará Bábílónì fi ṣẹ́gun Júdà?
14 Àìka Òfin Ọlọ́run sí nílé-lóko ló mú kí ìjọba Ísírẹ́lì kàgbákò. Nígbà tí àwọn ará Ásíríà ṣẹ́gun rẹ̀ ní ọdún 740 ṣááju Sànmánì Tiwa, láìsí àní-àní, àwọn kan láti inú ẹ̀yà mẹ́wàá sá lọ bá ìjọba ẹ̀yà méjì ti Júdà, níbi tí wọ́n ti lè jọ́sìn Jèhófà nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀. Mẹ́rin lára ọba mọ́kàndínlógún tó jẹ ní ìlà ìdílé Dáfídì—Ásà, Jèhóṣáfátì, Hesekáyà, àti Jòsáyà—ta yọ nínú fífọkànsin Ọlọ́run. Ní ọjọ́ Hesekáyà olùpàwàtítọ́mọ́, àwọn ará Ásíríà kó ogun ńlá wá bá Júdà. Ní ìdáhùn sí ẹ̀bẹ̀ Hesekáyà, Ọlọ́run lo ẹyọ áńgẹ́lì kan ṣoṣo láti pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [185,000] àwọn ará Ásíríà ní òru ọjọ́ kan ṣoṣo, ó tipa báyìí gba àwọn olùjọsìn Rẹ̀ là! (Aísáyà 37:36-38) Lẹ́yìn náà, kíkùnà tí àwọn ènìyàn náà kùnà láti pa Òfin mọ́ àti láti kọbiara sí àwọn ìkìlọ̀ látẹnu àwọn wòlíì Ọlọ́run ló fa ṣíṣẹ́gun tí àwọn ará Bábílónì ṣẹ́gun Júdà àti pípa tí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù, olú ìlú rẹ̀, àti tẹ́ńpìlì run ní ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa.
15. Èé ṣe tí àwọn ìgbèkùn Júù tí ń bẹ ní Bábílónì fi nílò ìfaradà, báwo sì ni Jèhófà ṣe pèsè ìdáǹdè nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín?
15 Àwọn ìgbèkùn Júù nílò ìfaradà kí wọ́n bàa lè pa ìwà títọ́ mọ́ sí Ọlọ́run nígbà tí wọ́n wà ní oko òǹdè Bábílónì fún àádọ́rin ọdún tó kún fún ìbànújẹ́. (Sáàmù 137:1-6) Olùpàwàtítọ́mọ́ kan tó lókìkí ni Dáníẹ́lì. (Dáníẹ́lì 1:1-7; 9:1-3) Sáà ronú nípa bí inú rẹ̀ yóò ti dùn tó nígbà tí àṣẹ Ọba Kírúsì ará Páṣíà jáde ní ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, pé a yọ̀ǹda fún àwọn Júù láti padà lọ sí Júdà láti lọ tún tẹ́ńpìlì kọ́! (Ẹ́sírà 1:1-4) Dáníẹ́lì àti àwọn mìíràn ti fara dà á fún ọ̀pọ̀ ọdún, ṣùgbọ́n níkẹyìn wọ́n rí ìbìṣubú Bábílónì àti ìdáǹdè àwọn ènìyàn Jèhófà. Ó yẹ kí èyí ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìfaradà bí a ti ń dúró de ìparun “Bábílónì Ńlá,” ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé.—Ìṣípayá 18:1-5.
Jèhófà Máa Ń Gba Àwọn Ènìyàn Rẹ̀ Là
16. Ìgbàlà wo ni Ọlọ́run pèsè lọ́jọ́ Ẹ́sítérì Ayaba?
16 Jèhófà máa ń gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là nígbà tí wọ́n bá jẹ́ olóòótọ́ sí orúkọ rẹ̀. (1 Sámúẹ́lì 12:22; Aísáyà 43:10-12) Rántí ọjọ́ Ẹ́sítérì Ayaba—ní ọ̀rúndún karùn-ún ṣááju Sànmánì Tiwa. Ahasuwérúsì Ọba (Sẹ́sísì Kìíní) ti fi Hámánì jẹ Baṣọ̀run. Inú bí Hámánì gan-an nítorí pé Módékáì kọ̀ láti tẹrí ba fún un, ó wá tìtorí èyí pète láti pa àtòun àti gbogbo Júù tó wà ní Ilẹ̀ Ọba Páṣíà. Ó ní arúfin ni wọ́n, kí ọba lè gbà, ó gbà láti gbé owó tí wọn yóò fi ṣiṣẹ́ náà sílẹ̀, ọba sì jẹ́ kí ó lo òrùka òun láti fi fèdìdì di àkọsílẹ̀ kan tó pàṣẹ pé kí a pa àwọn Júù run pátápátá. Láìbẹ̀rù, Ẹ́sítérì ṣí i payá fún ọba pé Júù lòun, ó sì tú ète Hámánì apààyàn fó. Láìpẹ́, Hámánì ni a so rọ̀ sórí òpó náà gan-an tó fẹ́ fi pa Módékáì. A fi Módékáì jẹ Baṣọ̀run, pẹ̀lú àṣẹ láti gba àwọn Júù láyè láti gbèjà ara wọn. Wọ́n ṣẹ́gun ṣẹ́tẹ̀ ọ̀tá wọn. (Ẹ́sítérì 3:1–9:19) Ó yẹ kí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí fún ìgbàgbọ́ wa lókun pé Jèhófà yóò ṣe iṣẹ́ ìgbàlà fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ń ṣègbọràn sí i lóde òní.
17. Iṣẹ́ wo ni ìgbọràn ṣe nínú ìdáǹdè àwọn Kristẹni olùgbé Jùdíà tí í ṣe Júù ní ọ̀rúndún kìíní?
17 Ìdí mìíràn tí Ọlọ́run fi ń gba àwọn ènìyàn rẹ̀ là ni pé wọ́n ń ṣègbọràn sí òun àti Ọmọ rẹ̀. Fi ara rẹ sípò àwọn Júù tí í ṣe ọmọlẹ́yìn Jésù ní ọ̀rúndún kìíní. Ó sọ fún wọn pé: “Nígbà tí ẹ bá rí tí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun adótini bá yí Jerúsálẹ́mù ká, nígbà náà ni kí ẹ mọ̀ pé ìsọdahoro rẹ̀ ti sún mọ́lé. Nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ní Jùdíà bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá.” (Lúùkù 21:20-22) Ọ̀pọ̀ ọdún kọjá, o wá bẹ̀rẹ̀ sí kọminú nípa ìgbà tí ọ̀rọ̀ yẹn yóò ṣẹ. Ni àwọn Júù bá gbé ọ̀tẹ̀ dìde ní ọdún 66 Sànmánì Tiwa. Ni àwọn ọmọ ogun Róòmù lábẹ́ Cestius Gallus bá yí Jerúsálẹ́mù ká, wọ́n kógun wọ̀lú títí débi odi tẹ́ńpìlì. Lójijì, àwọn ará Róòmù kógun wọn lọ láìsídìí tó ṣe gúnmọ́. Kí ni àwọn Kristẹni tí í ṣe Júù yóò ṣe? Nínú ìwé rẹ̀, Ecclesiastical History (Ìwé Kẹta, orí karùn-ún, 3), Eusebius sọ pé wọ́n sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù àti Jùdíà. Wọ́n mórí bọ́ nítorí pé wọ́n ṣègbọràn sí ìkìlọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Jésù. Ó ha máa ń yá ọ bẹ́ẹ̀ láti tẹ̀ lé ìtọ́ni tó bá Ìwé Mímọ́ mu tí a pèsè nípasẹ̀ “olóòótọ́ ìríjú” tí a yàn láti máa bójú tó gbogbo “nǹkan ìní” Jésù?—Lúùkù 12:42-44.
Ìgbàlà Wọnú Ìyè Àìnípẹ̀kun
18, 19. (a) Ìgbàlà wo ni ikú Jésù mú kí ó ṣeé ṣe, àwọn wo sì ni ó ṣeé ṣe fún? (b) Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pinnu láti ṣe?
18 Kíkọbiara sí ìkìlọ̀ Jésù gba ẹ̀mí àwọn Kristẹni tí í ṣe Júù tí ń gbé ní Jùdíà là. Ṣùgbọ́n ikú Jésù mú kí ìyè ayérayé ṣeé ṣe fún “gbogbo onírúurú ènìyàn.” (1 Tímótì 4:10) Ìràpadà di ohun tí aráyé nílò nígbà tí Ádámù dẹ́ṣẹ̀, tó pàdánù ìwàláàyè ara rẹ̀, tó sì ta ìran ènìyàn sí oko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Róòmù 5:12-19) Àwọn ẹran tí a fi rúbọ lábẹ́ Òfin Mósè kàn jẹ́ ètùtù táṣẹ́rẹ́ fún ẹ̀ṣẹ̀ ni. (Hébérù 10:1-4) A bí Jésù láìjẹ́ pé ó jogún ẹ̀ṣẹ̀ tàbí àìpé èyíkéyìí, nítorí pé bàbá rẹ̀ kì í ṣe ènìyàn, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ló sì “ṣíji bo” Màríà láti ìgbà tó ti lóyún Jésù títí ó fi bí i. (Lúùkù 1:35; Jòhánù 1:29; 1 Pétérù 1:18, 19) Nígbà tí Jésù kú gẹ́gẹ́ bí ẹni tó pa ìwà títọ́ mọ́ lọ́nà pípé, ó fi ìwàláàyè rẹ̀ pípé rúbọ láti lè ra aráyé padà, kí ó sì tú wọn sílẹ̀ nínú ìsìnrú. (Hébérù 2:14, 15) Nípa báyìí, Kristi “fi ara rẹ̀ fúnni ní ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí fún gbogbo ènìyàn.” (1 Tímótì 2:5, 6) Kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni yóò mú ìpèsè yìí fún ìgbàlà lò, ṣùgbọ́n Ọlọ́run fọwọ́ sí lílo àǹfààní rẹ̀ fún àwọn tó bá fi ìgbàgbọ́ tẹ́wọ́ gbà á.
19 Kristi tún àwọn ọmọ Ádámù rà padà nípa gbígbé ìtóye ẹbọ ìràpadà rẹ̀ lọ síwájú Ọlọ́run ní ọ̀run. (Hébérù 9:24) Jésù tipa báyìí ní Ìyàwó, tí í ṣe ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ẹni àmì òróró tí a jí dìde sí ìyè ti ọrùn. (Éfésù 5:25-27; Ìṣípayá 14:4; 21:9) Ó tún di “Baba Ayérayé” fún àwọn tó bá tẹ́wọ́ gba ẹbọ rẹ̀, tí yóò sì rí ìyè àìnípẹ̀kun gbà lórí ilẹ̀ ayé. (Aísáyà 9:6, 7; 1 Jòhánù 2:1, 2) Ẹ wo irú ìṣètò onífẹ̀ẹ́ tí èyí jẹ́! Pọ́ọ̀lù fi ìmọrírì rẹ̀ hàn kedere fún ìṣètò yìí nínú lẹ́tà rẹ̀ kejì onímìísí sí àwọn Kristẹni tí ń bẹ ní Kọ́ríńtì, gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò ti fi hàn. Ní tòótọ́, Pọ́ọ̀lù pinnu láti má ṣe jẹ́ kí ohunkóhun dènà ríran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti jàǹfààní àgbàyanu ìpèsè Jèhófà fún ìgbàlà wọnú ìyè àìnípẹ̀kun.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Ẹ̀rí wo ló wà nínú Ìwé Mímọ́ pé Ọlọ́run ń gba àwọn ènìyàn rẹ̀ adúróṣánṣán là?
◻ Báwo ni a ṣe mọ̀ pé Jèhófà ń pèsè ìgbàlà fún àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e, tí wọ́n sì pa ìwà títọ́ mọ́?
◻ Ìpèsè wo ni Ọlọ́run ti ṣe fún ìgbàlà wọnú ìyè àìnípẹ̀kun?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Dáfídì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, “Ọlọ́run oníṣẹ́ ìgbàlà.” Ìwọ ńkọ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Jèhófà máa ń gba àwọn èèyàn rẹ̀ là, bí ó ti ṣe lọ́jọ́ Ẹ́sítérì Ayaba