Jẹ́nẹ́sísì
6 Nígbà tí àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ lórí ilẹ̀, tí wọ́n sì ń bí àwọn ọmọbìnrin, 2 àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́*+ wá bẹ̀rẹ̀ sí í kíyè sí i pé àwọn ọmọbìnrin èèyàn rẹwà. Wọ́n sì ń fi gbogbo ẹni tó wù wọ́n ṣe aya. 3 Jèhófà wá sọ pé: “Ẹ̀mí mi ò ní gba èèyàn láyè títí láé,+ torí ẹlẹ́ran ara ni.* Torí náà, ọgọ́fà (120) ọdún ni ọjọ́ rẹ̀ yóò jẹ́.”+
4 Àwọn Néfílímù* wà ní ayé nígbà yẹn àti lẹ́yìn ìgbà yẹn. Ní àkókò yẹn, àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́ ń bá àwọn ọmọbìnrin èèyàn lò pọ̀, wọ́n sì bí àwọn ọmọ fún wọn. Àwọn ni alágbára ayé ìgbà yẹn, àwọn ọkùnrin olókìkí.
5 Jèhófà wá rí i pé ìwà burúkú èèyàn pọ̀ gan-an ní ayé, ó sì rí i pé kìkì ohun búburú ló ń rò lọ́kàn ní gbogbo ìgbà.+ 6 Ó dun Jèhófà* pé òun dá èèyàn sáyé, ọkàn rẹ̀ sì bà jẹ́.*+ 7 Torí náà, Jèhófà sọ pé: “Èmi yóò run àwọn èèyàn tí mo ti dá kúrò lórí ilẹ̀, èèyàn àti ẹran ọ̀sìn, ẹran tó ń rákò àti àwọn ẹ̀dá tó ń fò lójú ọ̀run, torí ó dùn mí pé mo dá wọn.” 8 Àmọ́ Nóà rí ojúure Jèhófà.
9 Ìtàn Nóà nìyí.
Olódodo ni Nóà.+ Ó fi hàn pé òun jẹ́ aláìlẹ́bi* láàárín àwọn tí wọ́n jọ gbé láyé.* Nóà bá Ọlọ́run tòótọ́+ rìn. 10 Nígbà tó yá, Nóà bí ọmọkùnrin mẹ́ta, Ṣémù, Hámù àti Jáfẹ́tì.+ 11 Àmọ́ Ọlọ́run tòótọ́ rí i pé ayé ti bà jẹ́, ìwà ipá sì kún ayé. 12 Ọlọ́run wo ayé, àní ó ti bà jẹ́;+ ìwà ìbàjẹ́ ni gbogbo ẹlẹ́ran ara* ń hù ní ayé.+
13 Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run wá sọ fún Nóà pé: “Mo ti pinnu pé màá run gbogbo ẹlẹ́ran ara, torí wọ́n ti fi ìwà ipá kún ayé, torí náà, màá pa wọ́n run pẹ̀lú ayé.+ 14 Ìwọ fi igi olóje*+ ṣe áàkì* fún ara rẹ. Kí o ṣe àwọn yàrá sínú áàkì náà, kí o sì fi ọ̀dà bítúmẹ́nì+ bo inú àti ìta rẹ̀. 15 Bí o ṣe máa ṣe é nìyí: Kí áàkì náà gùn tó ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ìgbọ̀nwọ́,* kó fẹ̀ tó àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́, kó sì ga tó ọgbọ̀n (30) ìgbọ̀nwọ́. 16 Kí o ṣe fèrèsé* tí ìmọ́lẹ̀ á máa gbà wọ* inú áàkì náà, kó jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan láti òkè. Kí o ṣe ẹnu ọ̀nà áàkì náà sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀,+ kí o sì jẹ́ kó ní àjà kìíní, àjà kejì àti àjà kẹta.
17 “Ní tèmi, màá mú kí ìkún omi + bo ayé kí n lè run gbogbo ẹran ara tó ní ẹ̀mí* lábẹ́ ọ̀run. Gbogbo ohun tó wà ní ayé ló máa pa run.+ 18 Mo sì ń bá ọ dá májẹ̀mú, kí o wọ inú áàkì náà, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ àti ìyàwó rẹ pẹ̀lú ìyàwó àwọn ọmọ rẹ.+ 19 Kí o mú méjì-méjì lára gbogbo oríṣiríṣi ohun alààyè+ wọnú áàkì náà, kí ẹ lè jọ wà láàyè. Kí o mú wọn ní akọ àti abo;+ 20 àwọn ẹ̀dá tó ń fò ní irú tiwọn, àwọn ẹran ọ̀sìn ní irú tiwọn àti gbogbo ẹran tó ń rákò lórí ilẹ̀ ní irú tiwọn, méjì-méjì ni kí o mú wọn wọlé sọ́dọ̀ rẹ kí wọ́n lè wà láàyè.+ 21 Ní tìrẹ, kí o kó oríṣiríṣi oúnjẹ+ jọ, kí o sì gbé wọn dání, òun ni ìwọ àti àwọn ẹran náà á máa jẹ.”
22 Nóà sì ṣe gbogbo ohun tí Ọlọ́run pa láṣẹ fún un. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.+