Ẹ Gbẹ́kẹ̀lé Jehofa!
“Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀lé Jehofa.”—OWE 3:5, NW.
1. Báwo ni Owe 3:5 ṣe wú ọ̀dọ́mọkùnrin kan lórí, pẹ̀lú ìyọrísí onígbà-pípẹ́ wo sì ni?
MÍṢỌ́NNÁRÌ ọlọ́jọ́-pípẹ́ kan kọ̀wé pé: “‘FI GBOGBO ÀYÀ RẸ GBẸ́KẸ̀LÉ OLUWA; MÁ SÌ ṢE TẸ̀ SÍ ÌMỌ̀ ARA RẸ.’ Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn láti inú Bibeli, tí a kọ sínú férémù oníjígí kan tí a sì gbékọ́ sára ògiri nínú ilé kan tí mo ń bẹ̀wò, gba àfiyèsí mi. Mo ronú lé wọn lórí ṣúlẹ̀ ọjọ́ yẹn. Mo béèrè lọ́wọ́ araami pé, mo ha lè fi gbogbo ọkàn-àyà mi gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun bí?” Ẹni yìí jẹ́ ọmọ ọdún 21 nígbà náà. Ní ẹni 90 ọdún, tí ó sì ń fi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà kan ní Perth, Australia, ó lè wẹ̀yìn wo ìgbésí-ayé kan tí èso ìgbẹ́kẹ̀lé Jehofa tọkàntara ti mú sunwọ̀n síi, títíkan àwọn ọdún 26 lílekoko ti lílànà àwọn pápá ìjíhìn-iṣẹ́-Ọlọ́run titun sílẹ̀ ní Ceylon (Sri Lanka nísinsìnyí), Burma (Myanmar nísinsìnyí), Malaya, Thailand, India, àti Pakistan.a
2. Ìgbẹ́kẹ̀lé wo ni Owe 3:5 níláti gbéró nínú wa?
2 “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀lé Jehofa”—àwọn ọ̀rọ̀ ìwé Owe 3:5, wọ̀nyí, gẹ́gẹ́ bí New World Translation ṣe túmọ̀ wọn, níláti sún gbogbo wa láti máa fi tọkàntara ya ìgbésí-ayé wa sọ́tọ̀ fún Jehofa nìṣó, pẹ̀lú ìgbọ́kànlé pé ó lè fún ìgbàgbọ́ wa lókun, àní títí dórí ṣíṣẹ́pá àwọn ohun-ìdínà tí ó rí bí òkè-ńlá pàápàá. (Matteu 17:20) Nísinsìnyí ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò Owe 3:5 nínú àyíká-ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Ìtọ́ni bíi ti Baba
3. (a) Ìṣírí wo ni a lè rí nínú àwọn orí mẹ́sàn-án àkọ́kọ́ nínú ìwé Owe? (b) Èéṣe tí a fi níláti fiyè gidigidi sí Owe 3:1, 2?
3 Àwọn orí mẹ́sàn-án àkọ́kọ́ ti ìwé Owe nínú Bibeli tànyòò fún ìtọ́ni bíi ti Baba, ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Jehofa fún gbogbo àwọn tí ń wọ̀nà fún gbígbádùn ipò jíjẹ́ ọmọkùnrin nínú àwọn ọ̀run tàbí “òmìnira ògo àwọn ọmọ Ọlọrun” nínú paradise orí ilẹ̀-ayé. (Romu 8:18-21, 23) Níbí ni àwọn ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n wà tí àwọn òbí lè lò fún títọ́ àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin dàgbà. Èyí tí ó tayọ jùlọ ni ìmọ̀ràn inú Owe orí 3, tí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìṣíníyè náà: “Ọmọ mi, máṣe gbàgbé òfin mi; sì jẹ́ kí àyà rẹ kí ó pa òfin mi mọ́.” Bí àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ayé burúkú Satani tí ń súnmọ́ paríparí-òpin wọn, ǹjẹ́ kí a túbọ̀ máa fiyè gidigidi sí àwọn ìránnilétí Jehofa. Ọ̀nà náà ti lè dàbí èyí tí ó jìn, ṣùgbọ́n ìlérí náà fún gbogbo àwọn tí ó bá faradà á ni pé “ọjọ́ gígùn, àti ẹ̀mí gígùn, àti àlááfíà ni wọn ó fi kún un fún ọ”—ìyè ayérayé nínú ètò-ìgbékalẹ̀ titun ti Jehofa.—Owe 3:1, 2.
4, 5. (a) Ipò-ìbátan aláyọ̀ wo ni a ṣàpèjúwe ní Johannu 5:19, 20? (b) Báwo ni ìmọ̀ràn tí ó wà ní Deuteronomi 11:18-21 ṣe ní ìfisílò títí di ọjọ́ wa?
4 Ipò-ìbátan aláyọ̀ láàárìn baba àti ọmọ lè jẹ́ èyí tí ó ṣeyebíye jùlọ. Ẹlẹ́dàá wa, Jehofa Ọlọrun, ti ṣètò rẹ̀ pé kí ó rí bẹ́ẹ̀. Kristi Jesu sọ nípa ipò-ìbátan tímọ́tímọ́ tirẹ̀ pẹ̀lú Jehofa pé: “Ọmọ kò lè ṣe ohunkóhun fún araarẹ̀, bíkòṣe ohun tí ó bá rí pé Baba ń ṣe: nítorí ohunkóhun tí ó bá ń ṣe, wọ̀nyí ni Ọmọ sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. Nítorí Baba fẹ́ràn Ọmọ, ó sì fi ohun gbogbo tí òun tìkáraarẹ̀ ń ṣe hàn án.” (Johannu 5:19, 20) Jehofa pète pé irú ìbárẹ́-tímọ́tímọ́ kan-náà níláti wà láàárín òun àti gbogbo ìdílé tí ó jẹ́ tirẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé, àti bákan-náà láàárín àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ baba àti àwọn ọmọ wọn.
5 Ipò-ìbátan ìdílé onígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé ní a fún ní ìṣírí ní Israeli ìgbàanì. Jehofa gba àwọn baba nímọ̀ràn níbẹ̀ pé: “Ẹ fi ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí sí àyà yín àti sí ọkàn yín, kí ẹ sì so wọ́n mọ́ ọwọ́ yín fún àmì, kí wọn kí ó sì máa ṣe ọ̀já-ìgbàjú níwájú yín. Kí ẹ̀yin kí ó sì máa fi wọ́n kọ́ àwọn ọmọ yín, kí ẹ̀yin máa fi wọ́n ṣe ọ̀rọ̀ ísọ nígbà tí ìwọ bá jókòó nínú ilé rẹ, àti nígbà tí ìwọ ba ń rìn ní ọ̀nà, nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀, àti nígbà tí ìwọ bá dìde. Kí ìwọ kí ó sì kọ wọ́n sára òpó ilé rẹ, àti sára ilẹ̀kùn-ọ̀nà-òde rẹ: kí ọjọ́ yín kí ó lè máa pọ̀ síi, àti ọjọ́ àwọn ọmọ yín, ní ilẹ̀ náà tí OLUWA búra fún àwọn baba yín láti fi fún wọn, bí ọjọ́ ọ̀run lórí ilẹ̀-ayé.” (Deuteronomi 11:18-21) Ọ̀rọ̀ onímìísí Olùkọ́ni wa Atóbilọ́lá, Jehofa Ọlọrun, lè ṣiṣẹ́ nítòótọ́ láti so ó tímọ́tímọ́ pọ̀ mọ́ àwọn òbí àti àwọn ọmọ wọn, àti pẹ̀lú gbogbo àwọn mìíràn tí wọ́n ń sìn ín nínú ìjọ Kristian.—Isaiah 30:20, 21.
6. Báwo ni a ṣe lè rí ojúrere lọ́dọ̀ Ọlọrun àti ènìyàn?
6 Ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n bíi ti baba fún àwọn ènìyàn Ọlọrun, tàgbà-tèwe, ń báa lọ ní ẹsẹ 3 àti 4 nínú ìwé Owe orí 3: “Máṣe jẹ́ kí [ìṣeun-ìfẹ́, NW] àti òtítọ́ kí ó fi ọ sílẹ̀: so wọ́n mọ́ ọrùn rẹ; kọ wọ́n sí wàláà àyà rẹ: bẹ́ẹ̀ni ìwọ óò rí ojúrere, àti ọ̀nà rere lójú Ọlọrun àti ènìyàn.” Jehofa Ọlọrun fúnraarẹ̀ tayọlọ́lá nínú fífi ìṣeun-ìfẹ́ àti òtítọ́ hàn. Gẹ́gẹ́ bí Orin Dafidi 25:10 (NW) ṣe sọ, “ìṣeun-ìfẹ́ àti òtítọ́ ni gbogbo ipa-ọ̀nà Jehofa.” Ní àfarawé Jehofa, a níláti ka àwọn ànímọ́ wọ̀nyí àti agbára ìdáàbòboni wọn sí ìṣúra, ní kíkà wọ́n sí iyebíye bí a ó ti ṣe pẹ̀lú gbẹ̀dẹ̀-ọrùn kan tí kò ṣeédíyelé kí a sì fín wọn sórí ọkàn-àyà wa láìlèṣeéparẹ́. Nígbà náà, a lè fi ìgbóná-ọkàn gbàdúrà pé: “Oluwa: kí ìṣeun-ìfẹ́ rẹ àti òtítọ́ rẹ kí ó máa pa mí mọ́ nígbà gbogbo.”—Orin Dafidi 40:11.
Ìgbẹ́kẹ̀lé Wíwàlọtítí
7. Ní àwọn ọ̀nà wo ni Jehofa ti gbà fi ìṣeégbẹ́kẹ̀lé rẹ̀ hàn?
7 Ìwé atúmọ̀-èdè Webster’s Ninth New Collegiate Dictionary túmọ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé sí “ìfọkàntẹ̀ tí a múdánilójú lórí ìwà, agbára-ìṣe, okun, tàbí òtítọ́ ẹnìkan tàbí ohun kan.” Ìwà Jehofa fìdímúlẹ̀ gbọnyingbọnyin sínú ìṣeun-ìfẹ́ rẹ̀. A sì lè ní ìgbọ́kànlé pátápátá nínú agbára-ìṣe rẹ̀ láti ṣe ohun tí ó ti ṣèlérí, nítorí pé orukọ̀ rẹ̀ gan-an, Jehofa, fi í hàn yàtọ̀ gẹ́gẹ́ bí Olùpète ńlá náà. (Eksodu 3:14; 6:2-8) Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá, òun ni Orísun okun àti okun-inú alágbára. (Isaiah 40:26, 29) Òun jẹ́ ẹ̀dàya-àpẹẹrẹ òtítọ́, nítorí pé “kò . . . ṣeéṣe fún Ọlọrun láti ṣèké.” (Heberu 6:18) Fún ìdí yìí, a fún wa níṣìírí láti fi ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún sínú Jehofa, Ọlọrun wa, Orísun ńlá náà fún gbogbo òtítọ́, tí ó ní agbára ńlá gbogbo láti dáàbòbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e àti láti mú gbogbo àwọn ète títóbilọ́lá rẹ̀ wá sí àṣeyọrí ológo.—Orin Dafidi 91:1, 2; Isaiah 55:8-11.
8, 9. Èéṣe tí ó fi baninínújẹ́ pé kò sí ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ayé, báwo sì ni àwọn ènìyàn Jehofa ṣe fi ìyàtọ̀ hàn ní ìfiwéra?
8 Nínú ayé tí ó yí wa ká tí ìwàrere ti lọsílẹ̀, ó baninínújẹ́ pé ìgbẹ́kẹ̀lé kò sí. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ń rí ìwọra àti ìwà-ìbàjẹ́ níbi gbogbo. Ojú-ewé àkọ́kọ́ ìwé-ìròyìn World Press Review ìtẹ̀jáde May 1993 ni a dárà sí pẹ̀lú ìhìn-iṣẹ́ náà: “ÌBÚRẸ́KẸ́ ÌWÀ-ÌBÀJẸ́—Owó Èrú Nínú Ètò Ayé Titun. Ìgbòkègbodò ìwà-ìbàjẹ́ gbilẹ̀ láti Brazil dé Germany, láti United States dé Argentina, láti Spain dé Peru, láti Italy dé Mexico, láti Vatican dé Russia.” Bí a ti gbé e karí ìkórìíra, ìwọra, àti àìnígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé, bí àyíká-ipò ti fihàn, ètò ayé titun ti ènìyàn tí a fẹnu lásán pè bẹ́ẹ̀ kò kórè ohunkóhun mìíràn bíkòṣe ìṣẹ́ tí ń peléke síi fún aráyé.
9 Ní ìyàtọ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè olóṣèlú, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa láyọ̀ láti jẹ́ “orílẹ̀-èdè náà, Ọlọrun ẹni tí Oluwa íṣe.” Àwọn nìkanṣoṣo ni wọ́n lè fi tòótọ́-tòótọ́ sọ pé, “Ọlọrun ní àwa gbẹ́kẹ̀lé.” Ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn lè fi tayọ̀tayọ̀ ké jádé pé: “Nípa Ọlọrun ni èmi óò máa yin ọ̀rọ̀ rẹ̀. . . . Ọlọrun ni èmi óò gbẹ́kẹ̀ mi lé, èmi kì yóò bẹ̀rù.”—Orin Dafidi 33:12; 56:4, 11.
10. Kí ni ó ti fún ọ̀pọ̀ àwọn Kristian ọ̀dọ́ lókun láti pa ìwàtítọ́ mọ́?
10 Ní ilẹ̀ Asia kan níbi tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí ti jìyà lílù lọ́nà rírorò àti ìfinisẹ́wọ̀n, ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jehofa ti ran iye púpọ̀ rẹpẹtẹ lọ́wọ́ láti faradà. Ni alẹ́ ọjọ́ kan nínú ẹ̀wọ̀n, ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan tí ó ti nírìírí ìdálóró ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ nímọ̀lára pé òun kò lè faradà á mọ́. Ṣùgbọ́n ọ̀dọ́ mìíràn kan yọ́ gúlọ́gúlọ́ gba inú òkùnkùn tọ̀ ọ́ lọ. Ó sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ pé: “Máṣe juwọ́sílẹ̀; mo juwọ́sílẹ̀ n kò sì tíì ní àlááfíà ọkàn kankan láti ìgbà náà wá.” Ọ̀dọ́ àkọ́kọ́ náà sọ ìgbèròpinnu rẹ̀ láti dúró gbọnyingbọnyin dọ̀tun. A lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé pátápátá nínú Jehofa pé yóò ràn wá lọ́wọ́ láti borí gbogbo ìsapá Satani èyíkéyìí láti mú kí ìwàtítọ́ wa yìnrìn.—Jeremiah 7:3-7; 17:1-8; 38:6-13, 15-17.
11. Báwo ni a ṣe ru wá sókè láti gbẹ́kẹ̀lé Jehofa?
11 Òfin-àṣẹ àkọ́kọ́ kà lápákan pé: “Ìwọ sì gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jehofa Ọlọrun rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ.” (Marku 12:30, NW) Bí a ti ń ṣàṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, àwọn òtítọ́ títóbilọ́lá tí a ń kọ́ ń wọlé ṣinṣin sínú ọkàn-àyà wa tí èyí sì ń tipa bẹ́ẹ̀ ru wá sókè láti lo gbogbo ara wa pátá nínú iṣẹ́-ìsìn àgbàyanu Ọlọrun wa, Jehofa Oluwa Ọba-Aláṣẹ. Pẹ̀lú ọkàn-àyà tí ó kúnrẹ́rẹ́ fún ìmọrírì fún un—fún gbogbo ohun tí ó ti kọ́ wa, tí ó ti ṣe fún wa, àti èyí tí òun yóò ṣì ṣe fún wa—ni a fi ru wá sókè láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú ìgbàlà rẹ̀.—Isaiah 12:2.
12. Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, báwo ni ọ̀pọ̀ àwọn Kristian ṣe fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn nínú Jehofa hàn?
12 Ìgbẹ́kẹ̀lé yìí ni a lè mú dàgbà bí ọdún ti ń gorí ọdún. Ẹlẹ́rìí Jehofa kan tí ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tí ó ti fi ìṣòtítọ́ ṣiṣẹ́sìn fún ohun tí ó ju 50 ọdún lọ ní orílé-iṣẹ́ Watch Tower Society ní Brooklyn, bẹ̀rẹ̀ láti April 1927, kọ̀wé pé: “Ní ìparí oṣù yẹn mo gba $5.00 owó-ìyọ̀ǹda ti a fi sínú àpòòwé pẹ̀lú káàdì lílẹ́wà kan tí ń gbé ọ̀rọ̀-ẹsẹ-ìwé inú Owe 3:5, 6 jáde lákànṣe . . . Ìdí gbogbo wà láti gbẹ́kẹ̀lé Jehofa, nítorí mo wá mọrírì láìpẹ́ ní orílé-iṣẹ́ pé Jehofa ní ‘ẹrú olùṣòtítọ́ àti ọlọgbọ́n-inú’ kan tí ń fi ìṣòtítọ́ bójútó gbogbo àwọn àǹfààní-ire Ìjọba náà níhìn-ín lórí ilẹ̀-ayé.—Matteu 24:45-47.”b Ọkàn-àyà Kristian yìí tẹ̀ síhà jíjèrè “ìṣúra tí kìí kùnà láé nínú àwọn ọ̀run,” kìí ṣe sí ìfẹ́ owó. Bákan náà lónìí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún tí ń ṣiṣẹ́sìn ní àwọn ilé Beteli ti Watch Tower Society yíká ayé ń ṣe bẹ́ẹ̀ lábẹ́ irú ẹ̀jẹ́ òfin ti ipò-òṣì kan. Wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Jehofa láti pèsè fún àwọn àìní wọn ojoojúmọ́.—Luku 12:29-31, 33, 34.
Gbáralé Jehofa
13, 14. (a) Kìkì níbo ni a ti lè rí ìmọ̀ràn àgbà? (b) Kí ni a gbọ́dọ̀ yẹra fún kí á baà lè la inúnibíni já?
13 Baba wa ọ̀run gbà wá níyànjú pé: “Má sì ṣe gbáralé òye ara rẹ.” (Owe 3:5, NW) Àwọn olùgbaninímọ̀ràn nínú ayé àti àwọn afìṣemọ̀rònú kò lè retí láé láti súnmọ́ ọgbọ́n àti òye tí Jehofa fihàn. “Òye rẹ̀ kò ní òpin.” (Orin Dafidi 147:5) Dípò gbígbáralé ọgbọ́n àwọn sàràkí ènìyàn nínú ayé tàbí àwọn èrò-ìmọ̀lára aláìmọ̀kan tiwa, ẹ jẹ́ kí a gbójúlé Jehofa, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti àwọn alàgbà nínú ìjọ Kristian fún ìmọ̀ràn àgbà.—Orin Dafidi 55:22; 1 Korinti 2:5.
14 Ọgbọ́n ènìyàn tàbí ìgbéraga nítorí ipò kì yóò gbé wa débì kankan ní ọjọ́ àdánwò mímúná tí ń yárakánkán súnmọ́lé. (Isaiah 29:14; 1 Korinti 2:14) Ní Japan nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, olùṣọ́-àgùtàn àwọn ènìyàn Ọlọrun kan tí ó dáńgájíá ṣùgbọ́n tí ó ní ìgbéraga yàn láti gbáralé òye tirẹ̀. Lábẹ́ ìkìmọ́lẹ̀ ó di apẹ̀yìndà, ọ̀pọ̀ jùlọ nínú agbo pẹ̀lú sì di aláìṣiṣẹ́mọ́ lábẹ́ inúnibíni. Arábìnrin adúróṣinṣin ọmọ Japan kan, tí ó fìgboyà la ìbánilò bíbanilẹ́rù já nínú àwọn iyàrá-ìhámọ́ dídọ̀tí nínú ẹ̀wọ̀n, ṣàlàyé pé: “Àwọn tí wọ́n dúró gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ kò ní àkànṣe ànímọ́, wọn kìí sìí fa àfiyèsí. Dájúdájú gbogbo wa gbọ́dọ̀ máa fi gbogbo ọkàn-àyà wa gbẹ́kẹ̀lé Jehofa nígbà gbogbo.”c
15. Ànímọ́ oníwà-bí-Ọlọ́run wo ni ó ṣekókó bí a bá níláti wu Jehofa?
15 Níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jehofa, dípò kí ó jẹ́ nínú òye tiwa, wémọ́ ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn. Ẹ wo bí ànímọ́ yìí ti ṣe pàtàkì tó fún gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ láti wu Jehofa! Họ́wù, àní Ọlọrun wa pàápàá, bí òun tilẹ̀ jẹ́ Oluwa Ọba-Aláṣẹ gbogbo àgbáyé, ó fi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn hàn nínú àwọn ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú ìṣẹ̀dá rẹ̀ ọlọ́gbọ́nlóye. Àwa lè kún fún ọpẹ́ fún ìyẹn. “Ó rẹ araarẹ̀ sílẹ̀ láti wo ohun tí ó wà ní ọ̀run àti ní ayé! Ó gbé tálákà sókè láti inú erùpẹ̀ wá, ó sì gbé olùpọ́njú sókè láti orí ààtàn wá.” (Orin Dafidi 113:6, 7) Láti inú àánú ńlá rẹ̀, ó ń dárí àwọn àléébù wa jì wá lórí ìpìlẹ̀ ẹ̀bùn rẹ̀ títóbi jùlọ fún aráyé, ẹbọ ìràpadà ṣíṣeyebíye ti Ọmọkùnrin rẹ̀ olùfẹ́, Kristi Jesu. Ẹ wo bí ó ti yẹ kí a kún fún ọpẹ́ tó fún inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí yìí!
16. Báwo ni àwọn arákùnrin ṣe lè nàgà fún àwọn àǹfààní nínú ìjọ?
16 Jesu fúnraarẹ̀ rán wa létí pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbé araarẹ̀ ga, ni a óò rẹ̀ sílẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rẹ araarẹ̀ sílẹ̀ ni a óò gbé ga.” (Matteu 23:12) Ní ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn, àwọn arákùnrin tí wọ́n ti ṣèrìbọmi níláti nàgà fún àwọn ẹrù-iṣẹ́ nínú ìjọ Kristian. Síbẹ̀, àwọn alábòójútó kò níláti ka ìyannisípò wọn sí àmì ipò-ọlá, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí àǹfààní láti ṣe iṣẹ́ kan, pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn, ìmọrírì, àti ìháragàgà, bí Jesu ti ṣe, ẹni tí ó wí pé: “Baba mi ń ṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyí, èmi sì ń ṣiṣẹ́.”—Johannu 5:17; 1 Peteru 5:2, 3.
17. Kí ni gbogbo wa níláti mọrírì, ní ṣíṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò wo?
17 Ǹjẹ́ kí àwa lè máa fi tàdúràtàdúrà àti pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn mọrírì nígbà gbogbo pé a kò ju erùpẹ̀ lọ lójú Jehofa. Báwo ni a ti lè láyọ̀ tó, nígbà náà, pé “àánú Oluwa láti ayérayé ni lára àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀, àti òdodo rẹ̀ láti ọmọ dé ọmọ”! (Orin Dafidi 103:14, 17) Nítorí náà gbogbo wa níláti jẹ́ onítara akẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Àkókò tí a ń lò nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ ti ara-ẹni àti ti ìdílé, àti ní àwọn ìpàdé ìjọ, níláti wà lára àwọn wákàtí tí ó ṣeyebíye jùlọ fún wa lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Ní ọ̀nà yìí a ń kó “ìmọ̀ Ẹni-Mímọ́” jọ. Ìyẹn sì “ni òye.”—Owe 9:10.
“Nínú Ọ̀nà Rẹ Gbogbo . . .”
18, 19. Báwo ni a ṣe lè fi Owe 3:6 sílò nínú ìgbésí-ayé wa, pẹ̀lú ìyọrísí wo sì ni?
18 Ní títọ́ka wa sí Jehofa, Orísun òye àtọ̀runwá, Owe 3:6 (NW) sọ tẹ̀lé e pé: “Máa kíyèsí i nínú ọ̀nà rẹ gbogbo, òun fúnraarẹ̀ yóò sì mú ipa-ọ̀nà rẹ tọ́.” Kíkíyèsí Jehofa wémọ́ sísúnmọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí nínú àdúrà. Ibi yòówù kí a wà àti láìka ipò yòówù tí ó lè dìde sí, ọ̀nà tí a lè gbà dé ọ̀dọ̀ rẹ̀ lójú-ẹsẹ̀ ni àdúrà. Bí a ti ń ṣe àwọn iṣẹ́ òòjọ́ wa, bí a ti ń múrasílẹ̀ fún iṣẹ́-ìsìn pápá, bí a ti ń lọ láti ilé dé ilé láti polongo Ìjọba rẹ̀, àdúrà wa ìgbà gbogbo lè jẹ́ pé kí ó bùkún ìgbòkègbodò wa. Nípa báyìí, a lè ní àǹfààní aláìṣeédíyelé àti ayọ̀ ti ‘bíbá Ọlọrun rìn,’ pẹ̀lú ìdánilójú pé òun yóò ‘mú ipa-ọ̀nà wa tọ́,’ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fún àwọn olùbẹ̀rù Ọlọrun náà Enoku, Noa, àti àwọn ọmọ Israeli olùṣòtítọ́, bíi Joṣua àti Danieli.—Genesisi 5:22; 6:9; Deuteronomi 8:6; Joṣua 22:5; Danieli 6:23; wo Jakọbu 4:8, 10 pẹ̀lú.
19 Nígbà tí a bá sọ ìbéèrè-ẹ̀bẹ̀ wa di mímọ̀ fún Jehofa, a lè ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé ‘àlááfíà Ọlọrun, tí ó ju ìmọ̀ràn gbogbo lọ, yóò ṣọ́ ọkàn àti èrò wa nínú Kristi Jesu.’ (Filippi 4:7) Àlááfíà Ọlọrun yìí, tí ó farahàn nínú ìrísí-ojú tí ó kún fún ayọ̀, lè mú kí ìhìn-iṣẹ́ wà fa àwọn onílé tí a ń bá pàdé nígbà iṣẹ́ ìwàásù wa mọ́ra. (Kolosse 4:5, 6) Ó tún lè fún àwọn wọnnì tí àwọn másùnmáwo tàbí àwọn àìṣèdájọ́-òdodo inú ayé ìwòyí ń pọ́nlójú ní ìṣírí, gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ tí ó tẹ̀lẹ́ e ti fihàn.d
20, 21. (a) Nígbà ìpáyà Nasi, báwo ni ìwàtítọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣe fún àwọn ẹlòmíràn níṣìírí? (b) Ìgbèropinnu wo ni ohùn Jehofa níláti mú sọjí nínú wa?
20 Max Liebster, Ju àbínibí kan tí ó la Ìpakúpa rẹpẹtẹ kan já bí ẹni pé nípasẹ̀ iṣẹ́-ìyanu, ṣàpèjúwe ìrìn-àjò rẹ̀ sí ibùdó ìpanirun Nasi kan pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: “Wọ́n tì wá mọ́ inú àwọn ọkọ ojú-irin tí a ti yípadà sí ọ̀pọ̀ àwọn iyàrá-àhámọ́ kékeré fún ẹni méjì. Bí a ti gbá mi wọnú ọ̀kan nínú wọn, mo dojúkọ ẹlẹ́wọ̀n kan tí ojú rẹ̀ fi ìparọ́rọ́ hàn. Ó wà níbẹ̀ nítorí ọ̀wọ̀ rẹ̀ fún òfin Ọlọrun, ní yíyan ẹ̀wọ̀n àti ikú tí ó lè yọrísí dípò kí ó ta ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mìíràn sílẹ̀. Òun jẹ́ ọkan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Àwọn ọmọ rẹ̀ ni a ti mú kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, aya rẹ̀ ni a sì ti ṣekúpa. Ó ń dúró dé ikú tirẹ̀ pẹ̀lú. Ìrìn-àjò ọlọ́jọ́ mẹ́rìnlá náà pèsè ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè mi, nítorí pé lákòókò ìrìn-àjò lọ sẹ́nu ikú yìí ganan ni mo rí ìrètí náà fún ìyè àìnípẹ̀kun.”
21 Lẹ́yìn tí ó ti nírìírí “ibùba àwọn kìnnìún” ti Auschwitz, gẹ́gẹ́ bí ó ti pè é, tí a sì ti baptisi rẹ̀, arákùnrin yìí fẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tí a ti fi òun fúnraarẹ̀ sẹ́wọ̀n tí baba rẹ̀ sì ti jìyà nínú ibùdó ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ní Dachau. Nígbà tí baba rẹ̀ wà níbẹ̀, ó gbọ́ pé aya òun àti ọmọbìnrin òun kékeré ní a tún ti fàṣẹ ọba mú. Ó ṣàpèjúwe ìhùwàpadà rẹ̀ pé: “Mo ṣàníyàn gidigidi. Lẹ́yìn náà lọ́jọ́ kan nígbà tí mo wà lórí ìlà láti wẹ̀, mo gbọ́ ohùn kan tí ń fa ọ̀rọ̀ ìwé Owe 3:5, 6 yọ . . . Ó dún bí ohùn kan tí ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá. Ó jẹ́ ohun tí mo nílò gan-an láti jèrè ìdúródéédéé mi padà.” Níti gàsíkíá, ohùn náà jẹ́ ti ẹlẹ́wọ̀n mìíràn kan ti ń fa ọ̀rọ̀-ẹsẹ-ìwé yìí yọ, ṣùgbọ́n ìṣẹ̀lẹ̀ náà tẹnumọ́ agbára tí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun lè lò lórí wa. (Heberu 4:12) Ǹjẹ́ kí ohùn Jehofa bá wa sọ̀rọ̀ tagbáratagbára lónìí nípasẹ̀ ẹṣin-ọ̀rọ̀ ọdún wa ti 1994: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀lé Jehofa”!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà “Fífi Gbogbo Ọkàn-Àyà Mi Gbẹ́kẹ̀lé Jehofa,” gẹ́gẹ́ bí Claude S. Goodman ti sọ ọ́, nínú Ilé-Ìṣọ́nà, December 15, 1973, ojú-ìwé 760 sí 765 (Gẹ̀ẹ́sì).
b Wo ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà “Pẹlu Ipinnu Lati Mã Yin Jehofah,” gẹ́gẹ́ bí Harry Peterson ti sọ ọ́, nínú Ilé-Ìṣọ́nà, August 1, 1969, ojú-ìwé 468 sí 471.
c Wo ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà “Jehofah Kìí Kọ Awọn Iranṣẹ Rẹ̀ Tì Sápákan,” gẹ́gẹ́ bí Matsue Ishii ti sọ ọ́, nínú Ilé-Ìṣọ́nà, May 1, 1988, ojú-ìwé 21 sí 25.
d Tún wo ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà “Idande! Fifi Ara-wa Han Ni Olumoore,” gẹ́gẹ́ bí Max Liebster ṣe sọ ọ́, nínú Ilé-Ìṣọ́nà, April 1, 1979, ojú-ìwé 25 sí 29.
Ní Àkópọ̀
◻ Irú ìmọ̀ràn wo ni a gbékalẹ̀ nínú ìwé Owe?
◻ Báwo ni ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jehofa ṣe ṣàǹfààní fún wa?
◻ Kí ni ó wémọ́ gbígbáralé Jehofa?
◻ Èéṣe tí a fi níláti kíyèsí Jehofa nínú gbogbo ọ̀nà wa?
◻ Báwo ni Jehofa ṣe ń mú ipa-ọ̀nà wa tọ́?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ìhìn-iṣẹ́ aláyọ̀ ti Ìjọba náà ń fa àwọn aláìlábòsí ọkàn mọ́ra