“Ẹ Sún Mọ́ Ọlọ́run”
“Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”—JÁKỌ́BÙ 4:8.
1, 2. (a) Kí làwọn èèyàn sábà máa ń sọ pé àwọn ní? (b) Ọ̀rọ̀ ìyànjú wo ni Jákọ́bù fúnni, kí sì nìdí tó fi pọn dandan?
“ỌLỌ́RUN wà pẹ̀lú wa.” Wọ́n máa ń kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn sára àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ orílẹ̀-èdè, kódà ó wà lára aṣọ àwọn sójà pàápàá. Wọ́n tún fín ọ̀rọ̀ náà “Ọlọ́run la gbẹ́kẹ̀ lé” sára àwọn ẹyọwó àti owó oníbébà òde òní. Ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ ni pé àwọn ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. Àmọ́, ǹjẹ́ o ò ní gbà pé ohun tí níní irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ ń béèrè kọjá kéèyàn kàn máa sọ ọ́ lẹ́nu tàbí kéèyàn kàn máa kọ àwọn ọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
2 Bíbélì fi hàn pé ó ṣeé ṣe láti ní àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run. Àmọ́ ó gba ìsapá. Kódà àwọn ẹni àmì òróró kan ní ọ̀rúndún kìíní ní láti mú kí àjọṣe àárín àwọn àti Jèhófà Ọlọ́run túbọ̀ lágbára sí i. Jákọ́bù tó jẹ́ Kristẹni alábòójútó tiẹ̀ kìlọ̀ fún àwọn kan nípa bí wọ́n ṣe ń ní ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, tí ìjẹ́mímọ́ wọn nípa tẹ̀mí sì ń lọọlẹ̀. Inú ìmọ̀ràn yẹn ni ọ̀rọ̀ ìyànjú lílágbára yìí wà pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” (Jákọ́bù 4:1-12) Kí ni Jákọ́bù ní lọ́kàn pẹ̀lú gbólóhùn náà, “ẹ sún mọ́”?
3, 4. (a) Kí ni gbólóhùn náà “sún mọ́ Ọlọ́run” ti lè rán àwọn kan lára àwọn òǹkàwé Jákọ́bù ní ọ̀rúndún kìíní létí rẹ̀? (b) Kí nìdí tó fi lè dá wa lójú pé ó ṣeé ṣe láti sún mọ́ Ọlọ́run?
3 Jákọ́bù lo gbólóhùn kan tí kò ṣàjèjì sí ọ̀pọ̀ lára àwọn òǹkàwé rẹ̀. Òfin Mósè fún àwọn àlùfáà ní àwọn ìtọ́ni pàtó lórí bí wọ́n ṣe máa “sún mọ́” Jèhófà tàbí bí wọ́n ṣe máa tọ̀ ọ́ lọ nítorí àwọn ènìyàn rẹ̀. (Ẹ́kísódù 19:22) Ìyẹn ti lè rán àwọn òǹkàwé Jákọ́bù létí pé sísún mọ́ Jèhófà kì í ṣe ohun tá à ń fọwọ́ yẹpẹrẹ mú. Jèhófà ni ẹni gíga jù lọ ní ọ̀run òun ayé.
4 Yàtọ̀ síyẹn, ohun tí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ kan sọ ni pé, “ọ̀rọ̀ ìyànjú [tó wà nínú Jákọ́bù 4:8] yìí fi ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára hàn lọ́nà tó lágbára.” Jákọ́bù mọ̀ pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ké sí ẹ̀dá èèyàn aláìpé láti sún mọ́ Òun. (2 Kíróníkà 15:2) Ẹbọ Jésù ṣí ọ̀nà sílẹ̀ láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. (Éfésù 3:11, 12) Lóde òní, ọ̀nà láti sún mọ́ Ọlọ́run ti ṣí sílẹ̀ fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn! Àmọ́, báwo la ṣe lè lo àǹfààní àgbàyanu yìí? Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀nà mẹ́ta tá a lè gbà sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run yẹ̀ wò ní ṣókí.
Má Ṣe Dẹ́kun ‘Gbígba Ìmọ̀’ Ọlọ́run
5, 6. Báwo ni àpẹẹrẹ Sámúẹ́lì ọ̀dọ́ ṣe ṣàpèjúwe ohun tí ‘gbígba ìmọ̀’ Ọlọ́run ní nínú?
5 Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Jòhánù 17:3 wí, Jésù sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.” Ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ ẹsẹ yìí ló yàtọ̀ díẹ̀ sí bí Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ṣe túmọ̀ rẹ̀. Dípò kí wọ́n sọ pé “gba ìmọ̀” Ọlọ́run, wọ́n kàn rọra lo ọ̀rọ̀ ìṣe náà “láti mọ” Ọlọ́run tàbí “mímọ” Ọlọ́run. Àmọ́, àwọn ọ̀mọ̀wé bíi mélòó kan kíyè sí i pé ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò nínú èdè Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ yẹn ní ohun tó jù bẹ́ẹ̀ lọ nínú—ó jẹ́ ohun téèyàn ní láti máa bá lọ láìdáwọ́dúró, èyí tó tiẹ̀ lè yọrí sí àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ẹlòmíràn.
6 Mímọ Ọlọ́run dáadáa kì í ṣe ohun tuntun nígbà ayé Jésù. Bí àpẹẹrẹ, a kà á nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù pé nígbà tí Sámúẹ́lì wà lọ́mọdé “kò tíì mọ Jèhófà.” (1 Sámúẹ́lì 3:7) Ǹjẹ́ èyí túmọ̀ sí pé ìwọ̀nba díẹ̀ ni ohun tí Sámúẹ́lì mọ̀ nípa Ọlọ́run rẹ̀? Rárá o. Ó dájú pé àwọn òbí rẹ̀ àtàwọn àlùfáà á ti kọ́ ọ ni ohun púpọ̀. Àmọ́, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n lò ni ẹsẹ yẹn ni èyí tá a lè “lò fún ẹni tá a mọ̀ dáadáa.” Sámúẹ́lì kò tíì mọ Jèhófà dáadáa tó bó ṣe máa wá mọ̀ ọ́n níkẹyìn nígbà tó bá bẹ̀rẹ̀ sí sìn gẹ́gẹ́ bí agbọ̀rọ̀sọ fún Jèhófà. Bí Sámúẹ́lì ṣe ń dàgbà ló wá ń mọ Jèhófà ní ti tòótọ́, tó sì ń ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀.—1 Sámúẹ́lì 3:19, 20.
7, 8. (a) Èé ṣe tí kò fi yẹ káwọn ìjìnlẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì máa dáyà fò wá? (b) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìjìnlẹ̀ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó yẹ ká kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀?
7 Ǹjẹ́ ò ń gba ìmọ̀ Jèhófà kí o bàa lè mọ̀ ọ́n dáadáa? Tó o bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀, o gbọ́dọ̀ “ní ìyánhànhàn” fún oúnjẹ tẹ̀mí tí Ọlọ́run ń pèsè. (1 Pétérù 2:2) Má ṣe jẹ́ kí ìmọ̀ rẹ mọ sórí àwọn ohun téèyàn kọ́kọ́ ń mọ̀ nínú Bíbélì. Gbìyànjú láti mọ àwọn ìjìnlẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì. (Hébérù 5:12-14) Ǹjẹ́ irú àwọn ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀ máa ń dáyà fò ọ́, tó o máa ń rò pé wọ́n ti ṣòro jù? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, rántí pé Jèhófà ni “Olùkọ́ni rẹ Atóbilọ́lá.” (Aísáyà 30:20) Ó mọ bá a ṣe ń gbin ìjìnlẹ̀ òtítọ́ sínú ọkàn ẹ̀dá ènìyàn aláìpé. Ó sì lè bù kún ìsapá tó ò ń fi tọkàntọkàn ṣe láti lóye ohun tó ń kọ́ ẹ.—Sáàmù 25:4.
8 O ò ṣe fúnra rẹ ṣàyẹ̀wò díẹ̀ lára “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run”? (1 Kọ́ríńtì 2:10) Àwọn kókó wọ̀nyí kì í ṣe èyí tí kò dùn mọ́ni bí èyí táwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn àtàwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì lè máa ṣàríyànjiyàn lé lórí. Wọ́n jẹ́ ẹ̀kọ́ tó ṣe pàtàkì tó sì wúlò tó ń jẹ́ ká ní òye tó jinlẹ̀ nípa èrò inú àti ọkàn Baba wa onífẹ̀ẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ìràpadà, “àṣírí ọlọ́wọ̀,” àti onírúurú májẹ̀mú tí Jèhófà ti lò láti bù kún àwọn èèyàn rẹ̀ àti láti mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ—àwọn kókó wọ̀nyí àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn bẹ́ẹ̀ jẹ́ àwọn kókó tó dùn tó si gbéṣẹ́ gan-an fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti ṣíṣe ìwádìí.—1 Kọ́ríńtì 2:7.
9, 10. (a) Kí nìdí tí ìgbéraga fi léwu, kí ni yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún un? (b) Tí ọ̀rọ̀ bá dórí ìmọ̀ Jèhófà, kì nìdí tó fi yẹ ká sapá láti lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀?
9 Bí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ òtítọ́ tẹ̀mí tó o ní ṣe ń pọ̀ sí i, ṣọ́ra fún ewu tí ìmọ̀ lè fà—ìyẹn ni ìgbéraga. (1 Kọ́ríńtì 8:1) Ìgbéraga léwu nítorí pé ó máa ń sọ ẹ̀dá èèyàn dọ̀tá Ọlọ́run. (Òwe 16:5; Jákọ́bù 4:6) Rántí pé kò sí ẹ̀dá ènìyàn kan tó nídìí kankan láti máa fi ìmọ̀ rẹ̀ ṣògo. Bí àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tó wà nínú apá ìbẹ̀rẹ̀ ìwé kan tó sọ nípa bí ìran ènìyàn ti ṣe tẹ̀ síwájú nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ó ní: “Bá a ṣe ń mọ̀ sí i la wá ń rí i bí ohun tá a mọ̀ ṣe kéré tó. . . . Gbogbo ohun tá a mọ̀ kò ju bíńtín lára ohun tá ò tíì mọ̀.” Irú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ yẹn mà dára o! Wàyí o, nígbà tọ́rọ̀ wá dórí ìmọ̀ tó ga jù lọ—ìyẹn ìmọ̀ Jèhófà Ọlọ́run—ó wá ṣe pàtàkì gan-an fún wa láti lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀. Nítorí kí ni?
10 Kíyè sí díẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí Bíbélì sọ nípa Jèhófà. “Ìrònú rẹ jinlẹ̀ gidigidi.” (Sáàmù 92:5) “Òye [Jèhófà] ré kọjá ríròyìn lẹ́sẹẹsẹ.” (Sáàmù 147:5) “Kò sí àwárí òye [Jèhófà].” (Aísáyà 40:28) “Ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà pọ̀ o!” (Róòmù 11:33) Ó hàn gbangba pé a ò lè mọ gbogbo ohun tó yẹ ní mímọ̀ nípa Jèhófà tán láéláé. (Oníwàásù 3:11) Ó ti kọ́ wa ní ọ̀pọ̀ nǹkan àgbàyanu, síbẹ̀ ìmọ̀ ṣì pọ̀ rẹpẹtẹ tá a ní láti kọ́. Ǹjẹ́ a ò rí i pé ìfojúsọ́nà yẹn fúnni láyọ̀ ó sì jẹ́ kéèyàn lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀? Nítorí náà, bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́, ẹ jẹ́ ká máa fi gbogbo ìgbà lo ìmọ̀ tá a ní gẹ́gẹ́ bí olórí ohun tó ń mú wa sún mọ́ Jèhófà àti ohun tá a ó fi ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ káwọn náà lè ṣe bẹ́ẹ̀—ká má ṣe lò ó láti gbé ara wa ga ju àwọn ẹlòmíràn lọ láé.—Mátíù 23:12; Lúùkù 9:48.
Fi Ìfẹ́ Tó O Ní fún Jèhófà Hàn
11, 12. (a) Báwo ló ṣe yẹ kí ìmọ̀ nípa Jèhófà tá à ń gbà nípa lórí wa? (b) Kí la fi ń mọ̀ bóyá ìfẹ́ tí ẹnì kan ní fún Ọlọ́run jẹ́ ojúlówó?
11 Lọ́nà tó bá a mu gẹ́ẹ́, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa bí ìmọ̀ ṣe tan mọ́ ìfẹ́. Ó kọ̀wé pé: “Èyí sì ni ohun tí mo ń bá a lọ ní gbígbàdúrà, pé kí ìfẹ́ yín lè túbọ̀ máa pọ̀ gidigidi síwájú àti síwájú pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye àti ìfòyemọ̀ kíkún.” (Fílípì 1:9) Dípò tá a ó fi máa gbéra ga, ńṣe ló yẹ kí gbogbo òtítọ́ ṣíṣeyebíye tá a kọ́ nípa Jèhófà àtàwọn ète rẹ̀ mú kí ìfẹ́ tá a ní fún Baba wa ọ̀run túbọ̀ pọ̀ sí i.
12 Àmọ́ o, ọ̀pọ̀ tó sọ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ni ò nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ní ti gidi. Ó lè jẹ́ pé lóòótọ́ ni wọ́n nírú èrò bẹ́ẹ̀ nínú ọkàn wọn. Irú èrò bẹ́ẹ̀ dáa, ó tiẹ̀ tó ká tìtorí rẹ̀ gbóríyìn fúnni pàápàá, nígbà tó bá wà níbàámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye. Àmọ́ ìyẹn yàtọ̀ pátápátá sí ojúlówó ìfẹ́ fún Ọlọ́run. Kì nìdí? Kíyè sí bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe túmọ̀ irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀, ó ní: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.” (1 Jòhánù 5:3) Nítorí náà, kìkì ìgbà tá a bá fi ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà hàn nípa ṣíṣègbọràn ni ìfẹ́ yìí tó lè jẹ́ ojúlówó.
13. Báwo ni ìbẹ̀rù Ọlọ́run ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti fi ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà hàn?
13 Ìbẹ̀rù Ọlọ́run yóò jẹ́ ká ṣègbọràn sí Jèhófà. Ìbẹ̀rù jíjinlẹ̀ yìí àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Jèhófà ń wá látinú gbígba ìmọ̀ rẹ̀, kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa ìjẹ́mímọ́, ògo, ìdájọ́ òdodo, ọgbọ́n, àti ìfẹ́ rẹ̀ tó ga lọ́lá. Irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì tá a bá fẹ́ sún mọ́ ọn. Kíyè sí ohun tí Sáàmù 25:14 sọ pé: “Ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ ti àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.” Nítorí náà, a lè sún mọ́ Baba wa ọ̀run olùfẹ́ ọ̀wọ́n bá a bá ní ìbẹ̀rù jíjinlẹ̀ pé a ò fẹ́ bà á nínú jẹ́. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run yóò ràn wá lọ́wọ́ láti kọbi ara sí ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó wà nínú Òwe 3:6 pé: “Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” Kí nìyẹn túmọ̀ sí?
14, 15. (a) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìpinnu tá à ń dojú kọ nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́? (b) Báwo la ṣe lè ṣe àwọn ìpinnu lọ́nà tó máa fi hàn pé a ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run?
14 O ní láti ṣe ìpinnu lójoojúmọ́, ì báà jẹ́ ìpinnu ńlá tàbí kékeré. Bí àpẹẹrẹ, kí lo máa ń bá àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́, àwọn ọmọ ilé ìwé rẹ, àtàwọn aládùúgbò rẹ jíròrò? (Lúùkù 6:45) Ṣé wàá fi taápọntaápọn ṣiṣẹ́ kó o lè parí iṣẹ́ tó wà níwájú rẹ, tàbí ńṣe ni wàá máa wá ọ̀nà láti parí iṣẹ́ náà láìfi taratara ṣe é? (Kólósè 3:23) Ṣé àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ni wàá sún mọ́, tàbí wàá gbìyànjú láti fún àjọṣe rẹ pẹ̀lú àwọn tí ohun tẹ̀mí jẹ lọ́kàn lókun? (Òwe 13:20) Kí lo máa ṣe, láti gbé ire Ìjọba Ọlọ́run ga, ì báà jẹ́ láwọn ọ̀nà kéékèèké? (Mátíù 6:33) Bí irú àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ tá a kọ sókè wọ̀nyí bá ń darí àwọn ìpinnu rẹ ojoojúmọ́, ó túmọ̀ sí pé ò ń kíyè sí Jèhófà “ní gbogbo ọ̀nà rẹ” nìyẹn.
15 Lẹ́nu kan, nínú gbogbo ìpinnu tá a bá ń ṣe la ti gbọ́dọ̀ máa jẹ́ kí èrò yìí darí wa pé: ‘Kí ni Jèhófà yóò fẹ́ kí n ṣe? Ipa ọ̀nà wo ni yóò múnú rẹ̀ dùn jù lọ?’ (Òwe 27:11) Fífi ìbẹ̀rù Ọlọ́run hàn lọ́nà yìí jẹ́ ọ̀nà tó dára jù lọ láti fìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà hàn. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run yóò tún sún wa láti mọ́ tónítóní—nípa tẹ̀mí, nípa ti ìwà rere, àti nípa tara. Rántí pé nínú ẹsẹ kan náà tí Jákọ́bù ti rọ àwọn Kristẹni láti “sún mọ́ Ọlọ́run,” ó tún gbani níyànjú níbẹ̀ pé: “Ẹ wẹ ọwọ́ yín mọ́, ẹ̀yin ẹlẹ́ṣẹ̀, kí ẹ sì wẹ ọkàn-àyà yín mọ́ gaara, ẹ̀yin aláìnípinnu.”—Jákọ́bù 4:8.
16. Kí ni fífún tá à ń fún Jèhófà ní nǹkan kò lè túmọ̀ sí láé, síbẹ̀ kí la lè máa ṣe ní gbogbo ìgbà?
16 Láìsí àní-àní, ohun tí fífi ìfẹ́ wa hàn sí Jèhófà ní nínú ju yíyàgò fún ohun búburú nìkan lọ. Ìfẹ́ tún ń sún wa láti ṣe ohun tí ó tọ́. Bí àpẹẹrẹ, ojú wo la fi ń wo ẹ̀mí ọ̀làwọ́ gíga lọ́lá tí Jèhófà ní? Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé jẹ́ láti òkè, nítorí a máa sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Baba àwọn ìmọ́lẹ̀ àtọ̀runwá.” (Jákọ́bù 1:17) Ní ti tòótọ́, nígbà tá a bá fún Jèhófà ní ohun ìní wa, kì í ṣe pé à ń dá a lọ́lá. Òun ló ni gbogbo ohun rere àti àwọn nǹkan àmúṣọrọ̀ tó wà. (Sáàmù 50:12) Nígbà tá a bá sì fún Jèhófà ní àkókò wa àti agbára wa, kì í ṣe pé à ń bá a kájú àìní kan tí ọwọ́ rẹ̀ kò lè ká. Kódà, bá a bá yarí pé a ò ní wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ó lè pàṣẹ fún àwọn òkúta láti kígbe jáde! Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, kí nìdí tá a fi wá ń fún Jèhófà ní nǹkan ìní wa, àkókò wa, àti agbára wa? Olórí ìdí tá a fi ń ṣe é ni ká lè tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wa, ọkàn wa, èrò inú wa, àti okun wa.—Máàkù 12:29, 30.
17. Kí ló lè sún wa láti fún Jèhófà ní nǹkan tọ̀yàyàtọ̀yàyà?
17 Nígbà tá a bá ń fún Jèhófà ní nǹkan, a gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ tayọ̀tayọ̀, “nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.” (2 Kọ́ríńtì 9:7) Ìlànà tó wà nínú Diutarónómì 16:17 lè ràn wá lọ́wọ́ láti fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà ṣètọrẹ: “Kí ẹ̀bùn ọwọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan jẹ́ ní ìwọ̀n ìbùkún Jèhófà Ọlọ́run rẹ èyí tí ó ti fi fún ọ.” Nígbà tá a bá ronú nípa bí Jèhófà ti ṣe fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ hàn sí wa, ó máa ń wù wá láti fún un ní nǹkan tọ̀yàyàtọ̀yàyà. Irú ọrẹ bẹ́ẹ̀ máa ń mú ọkàn rẹ̀ yọ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn kékeré kan látọ̀dọ̀ ọmọ kan tó jẹ́ olùfẹ́ ọ̀wọ́n ṣe máa múnú òbí dùn. Fífi ìfẹ́ wa hàn lọ́nà yìí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti sún mọ́ Jèhófà.
Ní Ìbárẹ́ Tímọ́tímọ́ Nípasẹ̀ Àdúrà
18. Èé ṣe tó fi tọ́ láti ronú nípa bí a ṣe lè mú kí àdúrà wa sunwọ̀n sí i?
18 Àwọn àkókò tá à ń gbàdúrà láwa nìkan jẹ́ àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ fún wa—ó jẹ́ àkókò láti sọ ohun tó wà nínú wa, ìyẹn ọ̀rọ̀ àṣírí ara wa fún Baba wa ọ̀run. (Fílípì 4:6) Níwọ̀n bí àdúrà ti jẹ́ ọ̀nà pàtàkì láti sún mọ́ Ọlọ́run, ó yẹ ká sinmẹ̀dọ̀ nígbà náà, ká ronú lórí bí àdúrà wa ṣe tẹ̀wọ̀n tó. Kì í ṣe pé wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tá a fi ohùn dídùn sọ tá a sì tò lẹ́sẹẹsẹ, àmọ́ wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ tá a sọ látọkànwá. Báwo la ṣe lè mú kí àdúrà wa túbọ̀ sunwọ̀n sí i?
19, 20. Èé ṣe tó fi yẹ ká ṣe àṣàrò ká tó gbàdúrà, kí sì ni àwọn kókó tó tọ́ láti ṣe irú àṣàrò bẹ́ẹ̀ lé lórí?
19 A lè gbìyànjú láti kọ́kọ́ ṣe àṣàrò ká tó gbàdúrà. Bá a bá kọ́kọ́ ṣe àṣàrò, ìyẹn lè jẹ́ kí àdúrà wa ṣe pàtó, kó nítumọ̀, a ó sì tipa bẹ́ẹ̀ yẹra fún àṣà ká máa tún gbólóhùn kan tá a ti há sórí sọ ṣáá. (Òwe 15:28, 29) Bóyá ríronú lórí àwọn kókó kan tí Jésù mẹ́nu kàn nínú àdúrà àwòṣe rẹ̀, ká sì wá ṣàyẹ̀wò bí ìwọ̀nyí ṣe kan ipò tiwa fúnra wa lè ṣèrànwọ́. (Mátíù 6:9-13) Bí àpẹẹrẹ, a lè bi ara wa léèrè irú ipa díẹ̀ tó ń wù wá láti kó nínú ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé. Ǹjẹ́ a lè sọ fún Jèhófà pé ó wù wá láti wúlò fún un bó bá ṣe lè ṣeé ṣe tó, ká sì bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí tó bá yàn fún wa? Ǹjẹ́ àwọn àìní wa nípa tara máa ń kó àníyàn bá wa? Àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wo la fẹ́ ká dárí rẹ̀ jì wá, àwọn wo ló sì yẹ ká dárí jì? Àwọn ìdẹwò wo ló ń pọ́n wa lójú, ǹjẹ́ a sì mọ bó ṣe jẹ́ ọ̀ràn kánjúkánjú tó láti wá ààbò Jèhófà nítorí wọn?
20 Ní àfikún sí i, a lè ronú nípa àwọn èèyàn tá a mọ̀, tí wọ́n dìídì nílò ìrànlọ́wọ́ Jèhófà. (2 Kọ́ríńtì 1:11) Àmọ́ ohun mìíràn tí kò yẹ ká gbàgbé ni ọ̀rọ̀ nípa ìdúpẹ́. Bá a bá ronú dáadáa, ó dájú pé a óò rí àwọn ìdí tó fi yẹ ká dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà ká sì yìn ín fún ọ̀pọ̀ ohun rere tó ń ṣe fún wa lójoojúmọ́. (Diutarónómì 8:10; Lúùkù 10:21) Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ ní àǹfààní púpọ̀—ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ ní ẹ̀mí ìmọrírì àti ojú ìwòye tó dára nípa ìgbésí ayé.
21. Kíkẹ́kọ̀ọ́ àwọn àpẹẹrẹ wo nínú Ìwé Mímọ́ ló lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá tọ Jèhófà lọ nínú àdúrà?
21 Bẹ́ẹ̀ náà ni ìkẹ́kọ̀ọ́ lè mú kí àdúrà wa sunwọ̀n sí i. Àwọn àdúrà títayọ táwọn ọkùnrin àtobìnrin ìgbàgbọ́ gbà wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, bí òkè ìṣòro kan bá wà níwájú wa, tó ń jẹ́ ká ṣe àníyàn tá a sì ń bẹ̀rù nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí wa tàbí sí àwọn èèyàn wa, a lè ka àdúrà tí Jékọ́bù gbà nígbà tó fẹ́ lọ pàdé Ísọ̀, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tínú ń bí. (Jẹ́nẹ́sísì 32:9-12) Tàbí ká ka àdúrà tí Ásà Ọba gbà nígbà tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun bí àádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ará Etiópíà ń halẹ̀ mọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run. (2 Kíróníkà 14:11, 12) Bí a bá ń dààmú nípa ìṣòro kan tó fẹ́ mú ẹ̀gàn bá orúkọ rere Jèhófà, àdúrà tí Èlíjà gbà níwájú àwọn olùjọsìn Báálì ní Òkè Ńlá Kámẹ́lì ló yẹ ká gbé yẹ̀ wò, bẹ́ẹ̀ náà ni àdúrà tí Nehemáyà gbà nípa ipò tí ń múni banú jẹ́ tí Jerúsálẹ́mù wà. (1 Àwọn Ọba 18:36, 37; Nehemáyà 1:4-11) Kíka irú àwọn àdúrà bẹ́ẹ̀ àti ṣíṣe àṣàrò lé wọn lórí lè fún ìgbàgbọ́ wa lókun, kó sì jẹ́ ká mọ àwọn ọ̀nà tá a lè gbà kó àwọn àníyàn tó ń bà wá nínú jẹ́ tọ Jèhófà lọ.
22. Kí ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2003, kí ló sì yẹ ká máa bi ara wa látìgbàdégbà jálẹ̀ ọdún náà?
22 Ní kedere, kò sí ọlá tàbí ohun mìíràn tá a lè máa lépa tó lè ju kíkọbiara sí ìmọ̀ràn Jákọ́bù pé ká “sún mọ́ Ọlọ́run.” (Jákọ́bù 4:8) Ǹjẹ́ kí a ṣe bẹ́ẹ̀ nípa títẹ̀síwájú nínú ìmọ̀ Ọlọ́run, nípa wíwá ọ̀nà tá a lè gbà láti túbọ̀ fi ìfẹ́ wa hàn síwájú àti síwájú sí i, àti nípa níní ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀ nínú àdúrà wa. Látìbẹ̀rẹ̀ dópin ọdún 2003, bá a ṣe ń fi Jákọ́bù 4:8 tó jẹ́ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún yìí sọ́kàn, ẹ jẹ́ ká máa bá a lọ ní yíyẹ ara wa wò bóyá à ń sún mọ́ Jèhófà ní ti tòótọ́. Apá tó kẹ́yìn nínú ẹsẹ yẹn wá ńkọ́? Ọ̀nà wo ni Jèhófà yóò gbà ‘sún mọ́ wa’ ìbùkún wo nìyẹn yóò sì mú wá? Àpilẹ̀kọ tó kàn yóò ṣàlàyé èyí.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Èé ṣe tí sísúnmọ́ Jèhófà fi jẹ́ ohun tó yẹ ká fọwọ́ dan-indan-in mú?
• Kí ni àwọn góńgó díẹ̀ tá a lè gbé ka iwájú wa nínú ọ̀ràn gbígba ìmọ̀ Jèhófà?
• Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ní ojúlówó ìfẹ́ fún Jèhófà?
• Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà láti túbọ̀ ní ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà nínú àdúrà?
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 12]
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2003 yóò jẹ́: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”—Jákọ́bù 4:8.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Bí Sámúẹ́lì ṣe ń dàgbà, ó wá mọ Jèhófà dáadáa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Àdúrà tí Èlíjà gbà lórí Òkè Ńlá Kámẹ́lì jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún wa