Báwo Lèèyàn Ṣe Lè Gbé Ìgbé Ayé Rere?
“Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.” —ONÍW. 12:13.
1, 2. Ẹ̀kọ́ wo la máa rí kọ́ látinú ṣíṣàyẹ̀wò ìwé Oníwàásù?
ỌKÙNRIN kan wà tó ń jẹ́ Sólómọ́nì. Ó gbé ayé ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́tà ọdún sẹ́yìn. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má sí ohun tí kò ní. Ọba tó lókìkí ni, ọ̀kan lára àwọn tó lówó jù láyé ni, òun ló sì tún lọ́gbọ́n jù lọ nígbà ayé rẹ̀. Àmọ́, pẹ̀lú gbogbo ohun tó gbé ṣe yìí, ọ̀rọ̀ tó sọ jọ bí ẹní ń bi ara rẹ̀ pé, ‘Báwo léèyàn ṣe lè gbé ìgbé ayé rere?’
2 A óò rí gbogbo ipa tí Sólómọ́nì sà láti lè rí ìtẹ́lọ́rùn nígbèésí ayé nínú ìwé Oníwàásù. (Oníw. 1:13) Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la máa rí kọ́ látinú ìrírí Sólómọ́nì. Dájúdájú, ọgbọ́n tá a óò rí kọ́ nínú ìwé Oníwàásù yóò jẹ́ ká lè máa lépa ohun tá jẹ́ kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀.
“Lílépa Ẹ̀fúùfù”
3. Ọ̀rọ̀ tó ń múni ronú jinlẹ̀ nípa ìgbésí ayé wo ló kan gbogbo wa?
3 Sólómọ́nì ṣàlàyé pé Ọlọ́run dá ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ohun ẹlẹ́wà sórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn ọ̀kẹ́ àìmọye onírúurú ohun àgbàyanu tó fani mọ́ra tí kì í sú wa láti rí. Ṣùgbọ́n, kì í ṣeé ṣe fún wa láti wádìí ohun tí Ọlọ́run dá débi kankan nítorí pé ìgbésí ayé ọmọ èèyàn ti kúrú jù. (Oníw. 3:11; 8:17) Ohun tí Bíbélì sọ ni pé ọjọ́ ayé wa kúrú, kì í sì í pẹ́ kọjá lọ. (Jóòbù 14:1, 2; Oníw. 6:12) Ó yẹ kí ọ̀rọ̀ tó ń múni ronú jinlẹ̀ yìí mú ká fọgbọ́n gbé ìgbésí ayé wa. Èyí kì í ṣe ohun tó rọrùn rárá, torí pé ayé Sátánì máa ń fẹ́ darí wa sọ́nà tí kò tọ́.
4. (a) Kí ni ọ̀rọ̀ náà “asán” túmọ̀ sí? (b) Àwọn ohun táwọn èèyàn ń fọjọ́ ayé wọn lépa wo la óò gbé yẹ̀ wò?
4 Ó lé nígbà ọgbọ̀n tí Sólómọ́nì lo ọ̀rọ̀ náà “asán” nínú ìwé Oníwàásù láti fi jẹ́ ká rí ewu tó wà nínú fífi ìgbésí ayé wa ṣòfò lórí ìlépa ohun tí kò ní láárí. Ọ̀rọ̀ náà “asán” tó wà nínú ìwé Oníwàásù yìí túmọ̀ sí ìmúlẹ̀mófo, àṣedànù, àìnítumọ̀, àìwúlò tàbí ohun tí kò ní láárí. (Oníw. 1:2, 3) Nígbà míì, Sólómọ́nì máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “asán” àti “lílépa ẹ̀fúùfù” pa pọ̀. (Oníw. 1:14; 2:11) Ó dájú pé béèyàn bá fẹ́ mú ẹ̀fúùfù, òfo ló máa mú. Irú ìjákulẹ̀ bẹ́ẹ̀ ló máa ń bá ẹni tó bá ń lépa ohun tí ò bọ́gbọ́n mu. Bẹ́ẹ̀, ọjọ́ ayé wa nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí kúrú ju kéèyàn máa fi ṣòfò lórí ohun tó jẹ́ àṣedànù. Ká má bàa ṣe irú àṣedànù yẹn, ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ nínú ohun tí Sólómọ́nì sọ pé àwọn èèyàn sábà máa ń fọjọ́ ayé wọn lépa. Lákọ̀ọ́kọ́, a ó wo ohun tó sọ nípa ìlépa adùn àti ọrọ̀. Lẹ́yìn náà, a óò wá jíròrò àǹfààní tó wà nínú ṣíṣe iṣẹ́ tó múnú Ọlọ́run dùn.
Ǹjẹ́ Lílépa Adùn Máa Jẹ́ Ká Láyọ̀?
5. Ibo ni Sólómọ́nì wá adùn ayé dé bóyá á lè fún un ní ìtẹ́lọ́rùn?
5 Lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń lépa adùn. Sólómọ́nì náà lépa adùn ìgbésí ayé bóyá ìyẹn á lè fún un ní ìtẹ́lọ́rùn. Ó sọ pé: “Èmi kò fawọ́ ayọ̀ yíyọ̀ èyíkéyìí sẹ́yìn fún ọkàn-àyà mi.” (Oníw. 2:10) Ibo ló wá adùn ayé dé? Oníwàásù orí kejì sọ pé ó ‘fi wáìnì pàápàá mú ara rẹ̀ yá gágá,’ àmọ́ kì í mu àmupara o. Ó tún tara bọ àwọn nǹkan bíi sísọ àyíká di ẹlẹ́wà, kíkọ́ àwọn ààfin mèremère, fífetí sí orin adùnyùngbà, ó sì ń jẹ oúnjẹ aládùn.
6. (a) Kí nìdí tí kò fi burú pé ká gbádùn ara wa dé ìwọ̀n àyè kan? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣe fàájì níwọ̀ntúnwọ̀nsì?
6 Ǹjẹ́ Bíbélì sọ pé ó lòdì kéèyàn máa bá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣe fàájì? Rárá o. Bí àpẹẹrẹ, Sólómọ́nì sọ pé ara ẹ̀bùn Ọlọ́run ni pé kéèyàn fọkàn balẹ̀ jẹ̀gbádùn lẹ́yìn iṣẹ́ àṣekára. (Ka Oníwàásù 2:24; 3:12, 13.) Jèhófà pàápàá sọ pé káwọn ọ̀dọ́ ‘máa yọ̀, kí wọ́n sì jẹ́ kí ọkàn-àyà wọn ṣe wọ́n ní ire.’ (Oníw. 11:9) Lóòótọ́, ó yẹ ká máa wáyè ṣe fàájì àti eré ìnàjú tó bọ́gbọ́n mu. (Fi wé Máàkù 6:31.) Àmọ́, kò yẹ ká wá máa fi gbogbo ọjọ́ ayé wa lépa fàájì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká máa ṣe fàájì níwọ̀nba bí ìgbà téèyàn rọra ń fi iyọ̀ sí ọbẹ̀. Gbogbo wa la mọ̀ pé bí iyọ̀ ṣe dáa tó, tó bá pọ̀ jù nínú ọbẹ̀, èèyàn ò ní gbádùn ọbẹ̀ náà, àti pé ó lè ṣàkóbá fún ìlera ara. Bẹ́ẹ̀ náà ni Sólómọ́nì ṣe rí i pé téèyàn bá fi gbogbo ọjọ́ ayé lépa fàájì ńṣe lèèyàn ń ‘lépa ẹ̀fúùfù.’—Oníw. 2:10, 11.
7. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣọ́ irú eré ìnàjú tá a máa ṣe?
7 Bákan náà, kì í ṣe gbogbo eré ìnàjú ló dára. Ọ̀pọ̀ eré ìnàjú léwu gan-an, ó sì lè ṣàkóbá fún àjọṣe àwa àti Jèhófà tàbí kó múni lọ́wọ́ nínú ìwàkiwà. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ti fi lílo oògùn olóró, àmujù ọtí àti tẹ́tẹ́ títa bayé ara wọn jẹ́ nídìí pé ‘wọ́n ń jayé orí wọn.’ Jèhófà fi inúure kìlọ̀ fún wa pé tá a bá lọ jẹ́ kí ọkàn wa tàbí ojú wa mú wa hùwàkiwà, a ó forí fá ohun tó bá tẹ̀yìn ẹ̀ yọ.—Gál. 6:7.
8. Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé ká ronú lórí ọ̀nà tá a gbà ń gbé ìgbésí ayé?
8 Yàtọ̀ síyẹn, téèyàn ò bá ṣe fàájì mọ níwọ̀n, èèyàn ò ní lè pọkàn pọ̀ sórí àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì. Ká má sì gbàgbé pé ọjọ́ ayé wa kúrú gan-an, kò sì tún dájú pé gbogbo ìgbà ni ara wa á máa le koko, tá ò ní níṣòro kankan. Ìdí nìyí tí Sólómọ́nì fi sọ pé àǹfààní wà nínú lílọ síbi ìsìnkú ju lílọ sí “ilé àkànṣe àsè,” pàápàá tó bá jẹ́ ìsìnkú arákùnrin tàbí arábìnrin wa olóòótọ́. (Ka Oníwàásù 7:2, 4.) Kí nìdí tó fi ṣàǹfààní? Bá a ṣe ń tẹ́tí gbọ́ àsọyé ìsìnkú tá a sì ń ronú nípa ìgbésí ayé ìránṣẹ́ Jèhófà tó kú yẹn, àwa náà lè ṣàyẹ̀wò bá a ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa. Èyí lè mú ká rí i pé ó yẹ ká yí ọ̀nà tá a gbà ń gbé ìgbésí ayé wa padà ká lè lo ìyókù lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu.—Oníw. 12:1.
Ṣé Kíkó Ọrọ̀ Jọ Yóò Fún Wa Ní Ìtẹ́lọ́rùn?
9. Kí ni nǹkan tí Sólómọ́nì rí nípa kíkó ọrọ̀ jọ?
9 Ọ̀kan lára àwọn tó lówó jù láyé ni Sólómọ́nì nígbà tó kọ ìwé Oníwàásù. (2 Kíró. 9:22) Kò sóhun tó fẹ́ ní tágbára rẹ̀ kò ká. Ó sọ pé: “Ohunkóhun tí ojú mi sì béèrè ni èmi kò fi dù ú.” (Oníw. 2:10) Àmọ́, ó rí i pé kéèyàn kàn kó ọrọ̀ jọ nìkan kò lè fúnni nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Ó wá sọ pé: “Olùfẹ́ fàdákà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ olùfẹ́ ọlà kì yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú owó tí ń wọlé wá.”—Oníw. 5:10.
10. Kí ló máa jẹ́ kéèyàn ní ìtẹ́lọ́rùn àti ọrọ̀ tó máa wà títí ayé?
10 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọrọ̀ ò láyọ̀lé, síbẹ̀ ó ń wu àwọn èèyàn láti ní. Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà láìpẹ́ yìí, èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́dún kìíní nílé ẹ̀kọ́ yunifásítì sọ pé “báwọn ṣe máa di ọlọ́rọ̀” lohun tó jẹ àwọn lógún jù lọ. Ká tiẹ̀ wá sọ pé wọ́n di ọlọ́rọ̀ ṣé wọ́n á láyọ̀ lóòótọ́? Kò dájú. Àwọn olùṣèwádìí kan rí i pé téèyàn bá nífẹ̀ẹ́ ọrọ̀ jù, kì í jẹ́ kéèyàn láyọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn. Ohun tí Sólómọ́nì sì ti sọ tipẹ́tipẹ́ sẹ́yìn nìyẹn. Ó ní: “Mo . . . kó fàdákà àti wúrà jọ rẹpẹtẹ fún ara mi, àti dúkìá tí ó jẹ́ àkànṣe ìní àwọn ọba . . . Sì wò ó! asán ni gbogbo rẹ̀ àti lílépa ẹ̀fúùfù.”a (Oníw. 2:8, 11) Ṣùgbọ́n, tá a bá fi gbogbo ọjọ́ ayé wa sin Jèhófà, yóò bù kún wa, a ó sì ní ọrọ̀ tó máa wà títí ayé.—Ka Òwe 10:22.
Iṣẹ́ Wo Ló Ń Fúnni Ní Ojúlówó Ìtẹ́lọ́rùn?
11. Kí ni Ìwé Mímọ́ sọ tó jẹ́ ká rí àǹfààní tó wà nínú iṣẹ́ ṣíṣe?
11 Jésù sọ pé: “Baba mi ti ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyí, èmi náà sì ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́.” (Jòh. 5:17) Kò sí àní-àní pé iṣẹ́ Jèhófà àti ti Jésù ń fún wọn nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Bíbélì jẹ́ ká rí bí iṣẹ́ ìṣẹ̀dá tí Jèhófà ṣe ṣe tẹ́ ẹ lọ́rùn, ó ní: “Ọlọ́run rí ohun gbogbo tí ó ti ṣe, sì wò ó! ó dára gan-an ni.” (Jẹ́n. 1:31) Àní nígbà táwọn áńgẹ́lì rí gbogbo iṣẹ́ tí Ọlọ́run ṣe, wọ́n “bẹ̀rẹ̀ sí hó yèè nínú ìyìn.” (Jóòbù 38:4-7) Bákan náà ni Sólómọ́nì ṣe mọyì iṣẹ́ tó nítumọ̀.—Oníw. 3:13.
12, 13. (a) Báwo làwọn méjì kan ṣe sọ ìtẹ́lọ́rùn téèyàn máa ń ní tó bá ṣe iṣẹ́ rẹ̀ bí iṣẹ́? (b) Kí nìdí tí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ fi máa ń jẹ́ káyé sú àwọn kan?
12 Ọ̀pọ̀ èèyàn mọyì ìtẹ́lọ́rùn téèyàn máa ń ní téèyàn bá ṣe iṣẹ́ rẹ̀ bí iṣẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀gbẹ́ni José tó ti dọ̀gá nídìí iṣẹ́ àwòrán yíyà sọ pé: “Téèyàn bá rí àwòrán tó ní lọ́kàn yà gẹ́lẹ́ bó ṣe wà lọ́kàn rẹ̀, ìdùnnú èèyàn máa ń kọyọyọ.” Oníṣòwò kan tó ń jẹ́ Miguelb sọ pé: “Iṣẹ́ ṣíṣe máa ń fúnni nítẹ̀ẹ́lọ́rùn torí òun léèyàn fi ń gbọ́ bùkátà ìdílé. Ó tún máa ń jẹ́ kí inú èèyàn dùn pé òun ṣàṣeyọrí.”
13 Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ló jẹ́ pé ohun kan náà léèyàn á máa ṣe ṣáá tí kì í sì í jẹ́ kéèyàn lè lo làákàyè rẹ̀ láti fi máa dárà tó wù ú. Nígbà míì, ayé máa ń sú àwọn míì níbi iṣẹ́ wọn tàbí kí wọ́n tiẹ̀ rẹ́ wọn jẹ. Gẹ́gẹ́ bí Sólómọ́nì ṣe sọ, ọ̀lẹ èèyàn lè gba ohun tó jẹ́ tẹnì kan tó ń ṣiṣẹ́ kára, bóyá torí pé ó mọ̀ọ̀yàn tàbí pé ó lo ẹsẹ̀. (Oníw. 2:21) Àwọn nǹkan míì náà lè fa ìjákulẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, òwò téèyàn rò pé ó máa mówó gọbọi wọlé lè fọ́ tí ipò ọrọ̀ ajé orílẹ̀-èdè náà bá dẹnu kọlẹ̀ tàbí nítorí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀. (Ka Oníwàásù 9:11.) Lọ́pọ̀ ìgbà ilé ayé lè sú ẹnì kan kórí rẹ̀ sì kanrin torí pé ó ti forí ṣe fọrùn ṣe kó lè rọ́wọ́ mu, àmọ́ tó wá rí i pé ńṣe lòun “ń ṣiṣẹ́ kárakára fún ẹ̀fúùfù.”—Oníw. 5:16.
14. Iṣẹ́ wo ló máa ń fúnni ní ojúlówó ìtẹ́lọ́rùn?
14 Ǹjẹ́ iṣẹ́ kankan wà tí kò lè jáni kulẹ̀ rárá? Ọ̀gbẹ́ni José, ayàwòrán tá a mẹ́nu kàn lẹ́ẹ̀kan yẹn, sọ pé: “Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, àwòrán téèyàn yà lè sọ nù tàbí kó tiẹ̀ bà jẹ́. Àmọ́ ti iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ò rí bẹ́ẹ̀, ohun téèyàn bá ṣe kò lè sọ nù, kò sì lè bà jẹ́ láéláé. Bí mo ṣe ṣègbọràn sí Jèhófà tí mò ń wàásù ìhìn rere, mo ti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ tí wọ́n fi di Kristẹni tó bẹ̀rù Ọlọ́run, ìyẹn sì máa ṣe wọ́n láǹfààní títí gbére. Ìdùnnú tí èyí sì ń fúnni ò lẹ́gbẹ́.” (1 Kọ́r. 3:9-11) Ọ̀gbẹ́ni Miguel náà sọ pé iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run máa ń fóun nítẹ̀ẹ́lọ́rùn gan-an ju iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ lọ. Ó ní: “Kò sóhun tó tún lè fúnni láyọ̀ bíi pé kéèyàn kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ kéèyàn sì rí i pé òtítọ́ yẹn wọ̀ ọ́ lọ́kàn ṣinṣin.”
“Fọ́n Oúnjẹ Rẹ sí Ojú Omi”
15. Kí lèèyàn máa ṣe tó máa fi hàn pé ó gbé ìgbé ayé rere?
15 Lákòótán, kí lèèyàn máa ṣe tó máa fi hàn pé ó gbé ìgbé ayé rere? A máa ní ojúlówó ìtẹ́lọ́rùn tá a bá fi ọjọ́ ayé kúkúrú tá a ní ṣe iṣẹ́ rere àtohun tó ń múnú Jèhófà dùn. A lè dẹni tó ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run, ká sì kọ́ ọmọ wa láwọn ìlànà Ọlọ́run, ká ran àwọn míì lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà, ká sì máa ṣe ohun tá jẹ́ kí àárín àwa àtàwọn ará wa dán mọ́rán. (Gál. 6:10) Gbogbo iṣẹ́ rere yìí ló máa ṣeni láǹfààní títí láé tó sì máa ń yọrí sí ìbùkún fẹ́ni tó bá ń ṣe wọ́n. Sólómọ́nì lo àfiwé kan tó yani lẹ́nu láti fi ṣàlàyé bó ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn máa ṣe iṣẹ́ rere. Ó sọ pé: “Fọ́n oúnjẹ rẹ sí ojú omi, nítorí lẹ́yìn ọjọ́ púpọ̀, ìwọ yóò tún rí i.” (Oníw. 11:1) Jésù náà rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ sọ fífúnni dàṣà, àwọn ènìyàn yóò sì fi fún yín.” (Lúùkù 6:38) Bákan náà, Jèhófà alára ṣèlérí pé òun yóò sẹ̀san fáwọn tó bá ń ṣe rere fáwọn èèyàn.—Òwe 19:17; ka Hébérù 6:10.
16. Ìgbà wo ló yẹ ká ṣèpinnu nípa bá a ṣe máa lo ìgbésí ayé wa?
16 Bíbélì rọ̀ wá pé látìgbà ọ̀dọ́ ni ká ti ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání nípa bá a ó ṣe lo ìgbésí ayé wa. Nípa bẹ́ẹ̀, a ò ní kábàámọ̀ tó bá dọjọ́ alẹ́. (Oníw. 12:1) Ẹ ò rí i pé ìbànújẹ́ gbáà ló máa jẹ́ tá a bá fi ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ ayé wa lépa adùn àti òkìkí ayé tí kì í tọ́jọ́, tá a wá lọ rí i nígbẹ̀yìn pé ẹ̀fúùfù lásán là ń lé!
17. Kí lo máa ṣe tí wàá fi lè yan ọ̀nà ìgbésí ayé tó dára jù lọ?
17 Gẹ́gẹ́ bí bàbá onífẹ̀ẹ́ ṣe máa ń fẹ́ kó rí fọ́mọ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe ń fẹ́ kó o gbádùn ayé rẹ, kó o máa ṣe ohun rere, kó o má sì kó ara rẹ síyọnu. (Oníw. 11:9, 10) Kí ló máa jẹ́ kí ìyẹn ṣeé ṣe? Ńṣe ni kó o ronú nípa àwọn ọ̀nà tó o máa gbà fi kún iṣẹ́ ìsìn rẹ sí Jèhófà, kó o wá sapá gidigidi kọ́wọ́ rẹ lè tẹ̀ ẹ́. Ní nǹkan bí ogún ọdún sẹ́yìn, Javier ní láti yan èyí tó máa ṣe nínú kó di dókítà tàbí kó ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Ó sọ pé: “Lóòótọ́, iṣẹ́ dókítà lè tẹ́ni lọ́rùn o, àmọ́ ayọ̀ tí mo ń ní pé mo ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ tí wọ́n fi dẹni tó mọ òtítọ́ kò láfiwé. Iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ti jẹ́ kí n gbádùn ayé mi lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Ohun tó kàn ń dùn mí ni pé mi ò tètè bẹ̀rẹ̀.”
18. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jésù gbé ìgbé ayé rere?
18 Kí wá ni ohun tó ṣeyebíye jù lọ tó yẹ ká sapá láti ní? Ìwé Oníwàásù sọ pé: “Orúkọ sàn ju òróró dáradára, ọjọ́ ikú sì sàn ju ọjọ́ tí a bíni lọ.” (Oníw. 7:1) Ọ̀nà tí Jésù gbà gbé ìgbé ayé rẹ̀ jẹ́ ká rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Ó dájú pé ó ní orúkọ rere lọ́dọ̀ Jèhófà. Nígbà tí Jésù ṣe olóòótọ́ dójú ikú, ó tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé Baba òun ló tọ́ kó jẹ́ Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run, ó sì pèsè ìràpadà tó jẹ́ kí aráyé lè rí ìgbàlà. (Mát. 20:28) Láàárín àkókò kúkúrú tí Jésù lò láyé, ó gbé ìgbé ayé rere, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀, èyí tá à ń sapá láti tẹ̀ lé.—1 Kọ́r. 11:1; 1 Pét. 2:21.
19. Ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n wo ni Sólómọ́nì fún wa?
19 Àwa náà lè ní orúkọ rere lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Níní orúkọ rere lọ́dọ̀ Jèhófà ṣe pàtàkì gan-an lójú wa ju pé ká jẹ́ ọlọ́rọ̀ lọ. (Ka Mátíù 6:19-21.) Lójoojúmọ́, ẹ jẹ́ ká máa wá bá a ṣe máa ṣe ohun tó dára lójú Jèhófà àtohun táá mú kí ìgbésí ayé wa sunwọ̀n. Bí àpẹẹrẹ, a lè máa wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn, ká máa ṣe ohun tó máa gbé ara wa ró nínú ìdílé, ká máa lọ sípàdé ká sì máa dá kẹ́kọ̀ọ́ déédéé kí àjọṣe àwa àti Jèhófà lè máa dára sí i. (Oníw. 11:6; Héb. 13:16) Ǹjẹ́ o fẹ́ gbé ìgbé ayé rere? Ńṣe ni kó o tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Sólómọ́nì tó sọ pé: “Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn.”—Oníw. 12:13.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ohun tó ń wọlé sápò Sólómọ́nì lọ́dún jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́fà [666] tálẹ́ńtì wúrà, èyí tó ju ẹgbẹ̀rún méjìlélógún [22,000] kìlógíráàmù wúrà lọ.—2 Kíró. 9:13.
b A ti yí orúkọ rẹ̀ padà.
Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí ló yẹ kó mú wa ronú nípa ohun tá à ń lépa nígbèésí ayé?
• Irú ojú wo ló yẹ ká máa fi wo ìlépa adùn àti ọrọ̀?
• Iṣẹ́ wo ló ń fúnni nítẹ̀ẹ́lọ́rùn tó wà pẹ́ títí?
• Ohun iyebíye wo ló yẹ ká sapá láti ní?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ipò wo ló yẹ ká fi eré ìnàjú sí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Kí ló mú kí iṣẹ́ ìwàásù jẹ́ iṣẹ́ tó ń tẹ́ni lọ́rùn gan-an?