Oníwàásù
2 Nígbà náà, mo sọ lọ́kàn mi pé: “Wá, jẹ́ kí n dán ìgbádùn* wò, kí n sì rí ohun rere tó máa tibẹ̀ wá.” Àmọ́ wò ó! asán ni èyí pẹ̀lú.
2 Mo sọ nípa ẹ̀rín pé, “Wèrè ni!”
Àti nípa ìgbádùn* pé, “Kí ni ìwúlò rẹ̀?”
3 Mo mu wáìnì,+ kí n lè fi ọkàn mi ṣèwádìí, àmọ́ ní gbogbo àkókò yìí mi ò sọ ọgbọ́n mi nù; kódà, mo fara mọ́ ìwà ẹ̀gọ̀ kí n lè rí ohun tó dáa jù lọ fún ọmọ aráyé láti máa ṣe láàárín ọjọ́ díẹ̀ tí wọ́n máa lò lábẹ́ ọ̀run. 4 Mo ṣe àwọn iṣẹ́ ńlá.+ Mo kọ́ àwọn ilé fún ara mi;+ mo gbin àwọn ọgbà àjàrà fún ara mi.+ 5 Mo ṣe àwọn ọgbà ọ̀gbìn àti ọgbà ìtura fún ara mi, mo sì gbin oríṣiríṣi igi eléso sínú wọn. 6 Mo ṣe àwọn adágún omi fún ara mi, láti máa fi bomi rin ọgbà* tí àwọn igi tó léwé dáadáa wà. 7 Mo ní àwọn ìránṣẹ́ lọ́kùnrin àti lóbìnrin,+ mo sì ní àwọn ìránṣẹ́ tí wọ́n bí ní agbo ilé mi.* Mo tún ní ọ̀pọ̀ ẹran ọ̀sìn, ìyẹn màlúù àti agbo ẹran,+ tó pọ̀ ju ti ẹnikẹ́ni tó wà ṣáájú mi ní Jerúsálẹ́mù. 8 Mo kó fàdákà àti wúrà jọ fún ara mi,+ ìṣúra* àwọn ọba àti ti àwọn ìpínlẹ̀.+ Mo kó àwọn akọrin lọ́kùnrin àti lóbìnrin jọ fún ara mi, títí kan ohun tó ń múnú ọmọ aráyé dùn gidigidi, ìyẹn obìnrin, àní ọ̀pọ̀ obìnrin.* 9 Torí náà, mo dẹni ńlá, mo sì ga ju gbogbo àwọn tó wà ṣáájú mi ní Jerúsálẹ́mù.+ Bẹ́ẹ̀ ni ọgbọ́n mi kò fi mí sílẹ̀.
10 Mi ò fi ohunkóhun tí mo fẹ́* du ara mi.+ Kò sí irú ìgbádùn* tí ọkàn mi fẹ́ tí mi ò fún un, torí ọkàn mi ń yọ̀ nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára mi, èyí sì ni èrè* mi nínú gbogbo iṣẹ́ àṣekára mi.+ 11 Àmọ́ nígbà tí mo ronú lórí gbogbo iṣẹ́ tí ọwọ́ mi ti ṣe àti gbogbo iṣẹ́ àṣekára tí mo ti sapá láti ṣe yọrí,+ mo rí i pé asán ni gbogbo rẹ̀, ìmúlẹ̀mófo;*+ kò sí ohun gidi kan* lábẹ́ ọ̀run.*+
12 Mo wá fiyè sí ọgbọ́n àti ìwà wèrè àti ìwà ẹ̀gọ̀.+ (Kí ni ẹni tó máa wá lẹ́yìn ọba lè ṣe? Ohun tí àwọn èèyàn ti ṣe tẹ́lẹ̀ ni.) 13 Mo rí i pé àǹfààní wà nínú ọgbọ́n ju ìwà ẹ̀gọ̀ lọ,+ bí àǹfààní ṣe wà nínú ìmọ́lẹ̀ ju òkùnkùn lọ.
14 Ojú ọlọ́gbọ́n wà ní orí rẹ̀;*+ àmọ́ òmùgọ̀ ń rìn nínú òkùnkùn.+ Mo sì wá rí i pé ohun* kan náà ló ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.+ 15 Lẹ́yìn náà, mo sọ lọ́kàn mi pé: “Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí òmùgọ̀ ló máa ṣẹlẹ̀ sí èmi náà.”+ Kí wá ni èrè ọgbọ́n tí mo gbọ́n ní àgbọ́njù? Mo sì sọ lọ́kàn mi pé: “Asán ni èyí pẹ̀lú.” 16 Nítorí a kì í rántí ọlọ́gbọ́n tàbí òmùgọ̀ títí lọ.+ Bó pẹ́ bó yá, a ò ní rántí ẹnikẹ́ni mọ́. Báwo sì ni ọlọ́gbọ́n ṣe máa kú? Á kú pẹ̀lú àwọn òmùgọ̀.+
17 Ayé wá sú mi,+ nítorí gbogbo ohun tí à ń ṣe lábẹ́ ọ̀run* ló ń kó ìdààmú báni lójú tèmi, torí asán ni gbogbo rẹ̀,+ ìmúlẹ̀mófo.*+ 18 Mo wá kórìíra gbogbo iṣẹ́ àṣekára tí mo ti ṣe lábẹ́ ọ̀run,*+ torí mo gbọ́dọ̀ fi í sílẹ̀ fún ẹni tó ń bọ̀ lẹ́yìn mi.+ 19 Ta ló sì mọ̀ bóyá ó máa jẹ́ ọlọ́gbọ́n tàbí òmùgọ̀?+ Síbẹ̀, òun ni yóò máa darí gbogbo ohun tí mo ti fi akitiyan àti ọgbọ́n kó jọ lábẹ́ ọ̀run.* Asán ni èyí pẹ̀lú. 20 Torí náà, ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bẹ̀rẹ̀ sí í bá mi nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára tí mo fi gbogbo agbára mi ṣe lábẹ́ ọ̀run.* 21 Nítorí èèyàn lè fi ọgbọ́n àti ìmọ̀ àti òye ṣiṣẹ́ ní àṣekára, àmọ́ ó gbọ́dọ̀ fi èrè rẹ̀* sílẹ̀ fún ẹni tí kò ṣiṣẹ́ fún un.+ Asán ni èyí pẹ̀lú àti àdánù* ńlá.
22 Kí tiẹ̀ ni èrè tí èèyàn rí jẹ nínú gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ àti gbogbo bó ṣe ń wù ú* láti ṣiṣẹ́ kára lábẹ́ ọ̀run?*+ 23 Torí ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀, iṣẹ́ rẹ̀ ń mú ìrora àti ìjákulẹ̀ bá a,+ kódà kì í rí oorun sùn lóru.+ Asán ni èyí pẹ̀lú.
24 Kò sóhun tó dáa fún èèyàn ju pé kó jẹ, kó mu, kó sì gbádùn* iṣẹ́ àṣekára rẹ̀.+ Èyí pẹ̀lú ni mo ti rí pé ó wá láti ọwọ́ Ọlọ́run tòótọ́,+ 25 àbí ta ló ń jẹ, tó sì ń mu ohun tó dáa ju tèmi lọ?+
26 Ọlọ́run ń fún ẹni tó bá ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní ọgbọ́n àti ìmọ̀ àti ìdùnnú,+ àmọ́ ó ń fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní iṣẹ́ kíkó jọ àti ṣíṣà jọ kí wọ́n lè fún ẹni tó ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tòótọ́.+ Asán ni èyí pẹ̀lú, ìmúlẹ̀mófo* sì ni.