Ẹ̀KỌ́ 29
Kí Ló Ń Ṣẹlẹ̀ Sáwọn Tó Ti Kú?
Báwo ló ṣe máa ń rí lára ẹ tí èèyàn ẹ kan bá kú? Nírú àkókò bẹ́ẹ̀, inú ẹ máa bà jẹ́ gan-an, o sì lè máa béèrè pé: ‘Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú? Ṣé a ṣì lè rí àwọn èèyàn wa tó ti kú?’ Nínú ẹ̀kọ́ yìí àtèyí tó tẹ̀ lé e, wàá rí àwọn ìdáhùn tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ látinú Bíbélì.
1. Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú?
Jésù fi ikú wé oorun àsùnwọra. Ẹni tó sùn wọra kì í mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyìíká ẹ̀. Báwo ni ikú ṣe jọ oorun? Lẹ́yìn tẹ́nì kan bá ti kú, kò mọ nǹkan kan lára mọ́. Kò ní mọ̀ bóyá òun dá nìkan wà tàbí bóyá àwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ tóun nífẹ̀ẹ́ gan-an ò sí lọ́dọ̀ òun. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé: “Àwọn òkú kò mọ nǹkan kan rárá.”—Ka Oníwàásù 9:5.
2. Àǹfààní wo ló máa ṣe wá tá a bá mọ ohun tí Bíbélì sọ pé ikú jẹ́?
Ọ̀pọ̀ èèyàn ń bẹ̀rù ikú, kódà wọ́n tún ń bẹ̀rù àwọn òkú! Àmọ́, ọkàn ẹ máa balẹ̀ tó o bá mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ikú. Jésù sọ pé: ‘Òtítọ́ á sọ yín di òmìnira.’ (Jòhánù 8:32) Àwọn ẹlẹ́sìn kan ń kọ́ni pé ohun kan máa ń kúrò nínú èèyàn lẹ́yìn tó bá kú, tí ohun náà á sì máa wà láàyè nìṣó, àmọ́ Bíbélì ò sọ bẹ́ẹ̀. Torí náà, èèyàn kì í jẹ̀rora lẹ́yìn tó bá ti kú. Yàtọ̀ síyẹn, torí pé àwọn tó ti kú ò mọ nǹkan kan, wọn ò lè ṣe wá níkà. Èyí fi hàn pé kò yẹ ká máa tu àwọn òkú lójú tàbí ká máa jọ́sìn wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni kò yẹ ká máa gbàdúrà fún wọn.
Àwọn kan sọ pé àwọn lè bá òkú sọ̀rọ̀. Àmọ́ ìyẹn ò ṣeé ṣe. A ti kà á nínú Bíbélì lẹ́ẹ̀kan pé “àwọn òkú kò mọ nǹkan kan rárá.” Àwọn kan rò pé àwọn èèyàn wọn tó ti kú làwọn ń bá sọ̀rọ̀, àmọ́ wọn ò mọ̀ pé àwọn ẹ̀mí èṣù làwọn ń bá sọ̀rọ̀, torí àwọn ẹ̀mí èṣù máa ń ṣe bíi pé àwọn lẹni tó ti kú. Torí náà, tá a bá mọ ohun tí Bíbélì sọ pé ikú jẹ́, ó máa dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù. Jèhófà kìlọ̀ fún wa pé a ò gbọ́dọ̀ bá àwọn òkú sọ̀rọ̀ torí ó mọ̀ pé tá a bá ń bá àwọn ẹ̀mí èṣù da nǹkan pọ̀, ó máa ṣe wá ní jàǹbá.—Ka Diutarónómì 18:10-12.
KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
Kẹ́kọ̀ọ́ sí i kó o lè mọ ohun tí Bíbélì sọ pé ikú jẹ́, kó o lè túbọ̀ nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run ìfẹ́ tí kì í dá àwọn tó ti kú lóró.
3. Ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn tó ti kú
Kárí ayé, oríṣiríṣi nǹkan làwọn èèyàn gbà gbọ́ pé ó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo ohun tí wọ́n gbà gbọ́ yẹn ló jóòótọ́.
Lágbègbè ẹ, kí làwọn èèyàn gbà gbọ́ nípa àwọn tó ti kú?
Kó o lè mọ ohun tí Bíbélì kọ́ni, wo FÍDÍÒ yìí.
Ka Oníwàásù 3:20, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Bí ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe sọ, kí ló ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú?
Ṣé ohun kan máa ń kúrò nínú èèyàn lẹ́yìn tó bá kú, tí ohun náà á sì máa wà láàyè nìṣó?
Bíbélì sọ nípa ikú Lásárù. Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni òun àti Jésù. Bó o ṣe ń ka Jòhánù 11:11-14, kíyè sí ohun tí Jésù sọ pé ó ṣẹlẹ̀ sí Lásárù. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Kí ni Jésù fi ikú wé?
Kí ni àfiwé yìí jẹ́ ká mọ̀ nípa àwọn tó ti kú?
Ṣé o gbà pé ohun tí Bíbélì sọ nípa ikú bọ́gbọ́n mu?
4. Ohun tí Bíbélì sọ nípa ikú ń ṣe wá láǹfààní
Tá a bá mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ikú, a ò ní máa bẹ̀rù àwọn òkú. Ka Oníwàásù 9:10, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Ṣé àwọn tó ti kú lè ṣe wá níkà?
Tá a bá gbà pé òótọ́ ni ohun tí Bíbélì sọ nípa ikú, a ò ní máa ṣe bí àwọn aláìmọ̀kan tí wọ́n máa ń tu àwọn òkú lójú tàbí tí wọ́n ń jọ́sìn wọn, Ka Àìsáyà 8:19 àti Ìfihàn 4:11, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Ojú wo lo rò pé Jèhófà máa fi wo ẹni tó ń jọ́sìn àwọn òkú tàbí tó ń wá ìrànwọ́ látọ̀dọ̀ àwọn òkú?
5. Ohun tí Bíbélì sọ nípa ikú fi wá lọ́kàn balẹ̀
Ohun tí wọ́n fi kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé tí wọ́n bá kú, wọ́n máa jìyà àwọn nǹkan burúkú tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn. Àmọ́ ọkàn wa balẹ̀ bá a ṣe mọ̀ pé, èèyàn ò ní jìyà àwọn nǹkan burúkú tó ti ṣe lẹ́yìn tó bá kú, títí kan àwọn tó ṣe nǹkan tó burú gan-an. Ka Róòmù 6:7, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:
Bíbélì sọ pé tí ẹnì kan bá ti kú, Ọlọ́run ti dá a sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ tó dá. Ṣé o rò pé ẹni tó ti kú ṣì ń jìyà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá sẹ́yìn?
Bá a bá ṣe ń mọ Jèhófà sí i, á túbọ̀ máa yé wa pé kì í fìyà jẹ àwọn tó ti kú. Ka Diutarónómì 32:4 àti 1 Jòhánù 4:8, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:
Ṣé o rò pé Ọlọ́run tó láwọn ìwà àti ìṣe táwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn sọ á máa dá àwọn tó ti kú lóró?
Ṣé ohun tí Bíbélì sọ nípa ikú fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Ẹ̀rù ń bà mí, torí mi ò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí mi nígbà tí mo bá kú.”
Àwọn ẹsẹ Bíbélì wo lo lè kà tó máa fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀?
KÓKÓ PÀTÀKÌ
Tẹ́nì kan bá ti kú, kò sí mọ́ nìyẹn. Àwọn tó ti kú kì í jẹ̀rora, wọn ò sì lè ṣe wá níkà.
Kí lo rí kọ́?
Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú?
Báwo ni ohun tí Bíbélì sọ nípa ikú ṣe ń ṣe wá láǹfààní?
Báwo ni ohun tí Bíbélì sọ nípa ikú ṣe fi wá lọ́kàn balẹ̀?
ṢÈWÁDÌÍ
Ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun tí Bíbélì sọ pé “ọkàn” jẹ́.
Wo fídíò yìí kó o lè mọ̀ bóyá Ọlọ́run ń dá àwọn ẹni burúkú lóró nínú ọ̀run àpáàdì.
Ṣé Òótọ́ Ni Pé Àwọn Ẹni Burúkú Máa Joró Nínú Ọ̀run Àpáàdì? (3:07)
Ṣó yẹ ká máa bẹ̀rù àwọn òkú?
Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi? (ìwé pẹlẹbẹ)
Ka ìwé yìí kó o lè rí bí ọkùnrin kan ṣe rí ìtùnú nígbà tó mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú.
“Àwọn Ìdáhùn Tó Bọ́gbọ́n Mu Tí Mo Rí Nínú Bíbélì Wú Mi Lórí Gan-an” (Ilé Ìṣọ́, February 1, 2015)