Ta Ni Yóò Yà Wá Kúrò Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run?
“Ní tiwa, àwa nífẹ̀ẹ́, nítorí òun ni ó kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.”—1 JÒHÁNÙ 4:19.
1, 2. (a) Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì láti mọ̀ pé àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ wa? (b) Ta lẹni àkọ́kọ́ tá a fẹ́ kó nífẹ̀ẹ́ wa?
BÁWO ló ṣe ṣe pàtàkì tó lójú rẹ láti mọ̀ pé àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ rẹ? Ọ̀ràn ìfẹ́ ṣe kókó látìgbà téèyàn ti wà ní ọmọ ọwọ́ títí téèyàn fi máa dàgbà di géńdé. Ǹjẹ́ o ti kíyè sí ọmọ tí ìyá rẹ̀ rọra gbé mọ́ra lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́ rí? Ohun yòówù kó máa ṣẹlẹ̀ láyìíká ọmọ náà, ńṣe ni ọkàn rẹ̀ á balẹ̀ dẹ́dẹ́, láìsí wàhálà, bó ṣe wà lọ́wọ́ ìyá tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tó ń wo ojú ìyá rẹ̀, bó ṣe ń rẹ́rìn-ín músẹ́ sí i. Tàbí kẹ̀, ǹjẹ́ o rántí bí gbogbo nǹkan ṣe ń tojú súni láwọn ọdún hílàhílo wọ̀nyẹn, nígbà tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí bàlágà? (1 Tẹsalóníkà 2:7) Nígbà míì, o ò ní mọ ohun tó o fẹ́ tàbí ohun tó tiẹ̀ ń ṣe ẹ́ gan-an. Àmọ́ ṣebí o rántí pé ohun tó fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀ ni pé bàbá rẹ àti ìyá rẹ nífẹ̀ẹ́ rẹ! Ǹjẹ́ inú rẹ ò dùn pé o lè sọ gbogbo ìṣòro tàbí ẹ̀dùn ọkàn tó o ní fún wọn? Láìsí àní-àní, jálẹ̀ ìgbésí ayé, ọ̀kan lára ohun tá a nílò jù lọ ni ìfẹ́. Irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ máa ń jẹ́ kó dá wa lójú pé èèyàn àtàtà ni wá.
2 Ìfẹ́ jíjinlẹ̀ táwọn òbí ní fún wa ló ń jẹ́ ká dàgbà bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Ṣùgbọ́n mímọ̀ dájú pé Jèhófà, Baba wa ọ̀run, nífẹ̀ẹ́ wa ṣe pàtàkì gan-an fún ìdúró wa nípa tẹ̀mí àti ní ti èrò orí. A lè rí lára àwọn tó ń ka ìwé ìròyìn yìí tí àwọn òbí wọn kò bìkítà nípa wọn rárá. Bó o bá jẹ́ ọ̀kan lára irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, má bara jẹ́. Bí àwọn òbí rẹ kò bá tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ rẹ tàbí tí ìfẹ́ tí wọ́n ní sí ọ kò tó, ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tí Ọlọ́run ní sí ọ á dí àlàfo yẹn.
3. Báwo ni Jèhófà ṣe mú un dá àwọn èèyàn rẹ̀ lójú pé òun nífẹ̀ẹ́ wọn?
3 Jèhófà gbẹnu Aísáyà wòlíì rẹ̀ sọ pé bí abiyamọ tilẹ̀ “gbàgbé” ìkókó tó ń tọ́ lọ́wọ́, ó lóun ò ní gbàgbé àwọn èèyàn òun. (Aísáyà 49:15) Bákan náà, Dáfídì sọ pẹ̀lú ìfọwọ́sọ̀yà pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé baba mi àti ìyá mi fi mí sílẹ̀, àní Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí.” (Sáàmù 27:10) Èyí mà fini lọ́kàn balẹ̀ o! Ipòkípò tó o bá wà, bó o bá ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run, máa rántí pé ìfẹ́ tó ní sí ọ pọ̀ ju èyí tí ẹ̀dá ènìyàn èyíkéyìí lè ní sí ọ!
Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run
4. Báwo la ṣe mú un dá àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní lójú pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wọn?
4 Ìgbà wo lo kọ́kọ́ mọ̀ nípa ìfẹ́ Jèhófà? Bóyá bó ṣe rí lára rẹ jọ tàwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní. Àlàyé tó gún régé wà ní orí karùn-ún lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Róòmù nípa bí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí wọn kò mọ Ọlọ́run tẹ́lẹ̀ ṣe wá mọ ìfẹ́ Jèhófà. Ẹsẹ karùn-ún kà pé: “A ti tú ìfẹ́ Ọlọ́run jáde sínú ọkàn-àyà wa nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́, èyí tí a fi fún wa.” Pọ́ọ̀lù fi kún un ní ẹsẹ kẹjọ pé: “Ọlọ́run dámọ̀ràn ìfẹ́ tirẹ̀ fún wa ní ti pé, nígbà tí àwa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.”
5. Báwo lo ṣe wá mọrírì bí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe jinlẹ̀ tó?
5 Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tó o gbọ́ òtítọ́ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tó o sì bẹ̀rẹ̀ sí gbà á gbọ́, ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ nínú ọkàn rẹ. O wá bẹ̀rẹ̀ sí mọ ohun ńlá tí Jèhófà ṣe, ní ti pé ó rán Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n pé kí ó wá kú fún ọ. Jèhófà tipa báyìí jẹ́ kí o mọ bóun ṣe nífẹ̀ẹ́ aráyé tó. Nígbà tó o bá rántí pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ẹ̀ṣẹ̀ la bí ọ sí, láìmọ Ọlọ́run, síbẹ̀ tí Jèhófà mú kó ṣeé ṣe pé kí á polongo ẹ̀dá ènìyàn ní olódodo pẹ̀lú ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun, kò ha wú ọ lórí bí? Ǹjẹ́ o ò bẹ̀rẹ̀ sí nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?—Róòmù 5:10.
6. Kí nìdí tó fi lè máa ṣe wá bíi pé a jìnnà sí Jèhófà nígbà míì?
6 Lẹ́yìn tí ìfẹ́ tí Baba rẹ ọ̀run ní sí ọ fà ọ́ mọ́ra, tó o sì ṣe àwọn àtúnṣe tó fẹ́ kó o ṣe nínú ìgbésí ayé, o wá ya ìgbésí ayé rẹ sí mímọ́ fún Ọlọ́run. O wá dẹni tó ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ ó máa ń ṣe ọ́ bíi pé o jìnnà sí Jèhófà nígbà míì? Ìyẹn lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni nínú wa. Àmọ́, máa rántí nígbà gbogbo pé Ọlọ́run kì í yí padà. Ìfẹ́ rẹ̀ kì í yẹ̀, ó sì wà fún wa lọ́jọ́kọ́jọ́, gẹ́gẹ́ bí oòrùn, tí kò lè ṣe kí ó má ràn. (Málákì 3:6; Jákọ́bù 1:17) Àmọ́ àwa la lè yí padà—ì báà tiẹ̀ jẹ́ fún ìgbà díẹ̀. Bí ayé ṣe ń yí, ńṣe ni òkùnkùn máa ń bo apá kan rẹ̀. Bákan náà, bá a bá yí kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kàn rọra sún kẹ́rẹ́ ni, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí ṣe wá bíi pé àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ kò gún régé mọ́. Kí la lè ṣe bí ìyẹn bá wáyé?
7. Báwo ni yíyẹ ara ẹni wò ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run?
7 Bó bá ń ṣe wá bíi pé a ò sí nínú ìfẹ́ Ọlọ́run mọ́, ó yẹ ká bi ara wa pé: ‘Ṣé kì í ṣe pé mi ò ka ìfẹ́ Ọlọ́run kún mọ́? Ṣé kì í ṣe pé mo ti ń ṣáko kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè, Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́, tó ń fi hàn lónírúurú ọ̀nà pé ìgbàgbọ́ mi ti ń di tútù? Ṣé kì í ṣe pé mo ń gbé èrò inú mi ka “àwọn ohun ti ẹran ara,” dípò kí n gbé e ka “àwọn ohun ti ẹ̀mí”?’ (Róòmù 8:5-8; Hébérù 3:12) Bá a bá ti ya ara wa nípa sí Jèhófà, a lè ṣàtúnṣe, ká padà sínú àjọṣe tímọ́tímọ́, àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú rẹ̀. Jákọ́bù rọ̀ wá pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” (Jákọ́bù 4:8) Má gbàgbé ọ̀rọ̀ tí Júúdà sọ pé: “Ẹ̀yin, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, nípa gbígbé ara yín ró lórí ìgbàgbọ́ yín mímọ́ jù lọ, àti gbígbàdúrà pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́, ẹ pa ara yín mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.”—Júúdà 20, 21.
Ìfẹ́ Ọlọ́run Kì Í Yí Padà, Bípò Nǹkan Tiẹ̀ Yí Padà
8. Àwọn ìyípadà wo ló lè ṣàdédé dé bá wa?
8 Ìgbésí ayé wa nínú ètò àwọn nǹkan yìí kò dúró sójú kan. Sólómọ́nì Ọba sọ pé “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo” wa. (Oníwàásù 9:11) Ìgbésí ayé wa lè ṣàdédé yí padà bìrí. Ara wa lè yá lónìí, kí àmódi dé lọ́la. A lè níṣẹ́ tó dáa lọ́wọ́ lónìí, kí iṣẹ́ ọ̀hún bọ́ lọ́la. Ikú lè mú èèyàn wa lọ, láìdọ́jọ́, láìdóṣù. Àwọn Kristẹni tí ń bẹ ní orílẹ̀-èdè kan lè gbádùn àkókò àlàáfíà fún sáà kan, àmọ́ kí inúnibíni gbígbóná janjan kàn bẹ́ sílẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀. Ó sì lè jẹ́ ẹ̀sùn èké ni wọ́n fi kàn wá, kí èyí sì kó ìyà jẹ wá. Àní sẹ́, ayé yìí ò láyọ̀lé.—Jákọ́bù 4:13-15.
9. Èé ṣe tí yóò fi dára láti jíròrò apá kan ìwé Róòmù orí kẹjọ?
9 Nígbà táwọn nǹkan ìbànújẹ́ bá ṣẹlẹ̀ sí wa, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí ṣe wá bíi pé a ò ní alábàárò mọ́, àní ká máa ronú pé Ọlọ́run ò nífẹ̀ẹ́ wa mọ́. Níwọ̀n bí kò ti sẹ́ni tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ò lè ṣẹlẹ̀ sí, á dáa ká fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ tí ń tuni nínú gan-an, tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nínú ìwé Róòmù orí kẹjọ. Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lọ̀rọ̀ yẹn ń bá wí. Ṣùgbọ́n, títí dé àyè kan, ó tún kan àwọn àgùntàn mìíràn, tá a ti polongo ní olódodo gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, bá a ti polongo Ábúráhámù ní olódodo kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé.—Róòmù 4:20-22; Jákọ́bù 2:21-23.
10, 11. (a) Àwọn ẹ̀sùn wo làwọn ọ̀tá ń fi kan àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà míì? (b) Kí nìdí tí irú ẹ̀sùn èké bẹ́ẹ̀ kì í fi í jọ àwọn Kristẹni lójú?
10 Ka Róòmù 8:31-34. Pọ́ọ̀lù béèrè pé: “Bí Ọlọ́run bá wà fún wa, ta ni yóò wà lòdì sí wa?” Ní tòótọ́, Sátánì àti ayé burúkú rẹ̀ ń gbéjà kò wá. Àwọn ọ̀tá lè fẹ̀sùn èké kàn wá, àní nílé ẹjọ́ pàápàá. Wọ́n ti fẹ̀sùn kan àwọn Kristẹni kan tó jẹ́ òbí pé wọ́n kórìíra àwọn ọmọ wọn nítorí pé wọn ò jẹ́ kí wọ́n gba ìtọ́jú tó lòdì sí òfin Ọlọ́run tàbí nítorí pé wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣọdún ìbọ̀rìṣà. (Ìṣe 15:28, 29; 2 Kọ́ríńtì 6:14-16) Wọ́n ti fẹ̀sùn èké kan àwọn Kristẹni olóòótọ́ mìíràn pé wọ́n fẹ́ dojú ìjọba dé nítorí pé wọ́n kọ̀ láti lọ sójú ogun lọ pa èèyàn ẹlẹgbẹ́ wọn tàbí torí pé wọ́n kọ̀ láti dá sọ́ràn ìṣèlú. (Jòhánù 17:16) Àwọn alátakò kan ti tan irọ́ burúkú kálẹ̀ nínú ìròyìn, àwọn kan tilẹ̀ ti parọ́ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé ẹgbẹ́ awo ni wọ́n.
11 Ṣùgbọ́n má gbàgbé pé nígbà ayé àwọn àpọ́sítélì, àwọn èèyàn sọ pé: “Ní ti ẹ̀ya ìsìn yìí, a mọ̀ pé níbi gbogbo ni wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lòdì sí i.” (Ìṣe 28:22) Àmọ́, ṣé ẹ̀gàn wá lè ní kí oyin má dùn ni? Ṣebí Ọlọ́run ló ń polongo àwọn Kristẹni tòótọ́ ní olódodo, lórí ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ wọn nínú ẹbọ Kristi. Kí ló lè sún Jèhófà dẹ́kun nínífẹ̀ẹ́ àwọn tó ń sìn ín, lẹ́yìn tó ti fún wọn ní ẹ̀bùn tó ṣeyebíye jù lọ—ìyẹn Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n? (1 Jòhánù 4:10) Nísinsìnyí tí Kristi ti jíǹde, tó sì ti wà ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, ńṣe ló ń gba ìjà àwọn Kristẹni jà. Ta ló lè ní kí Kristi má gbèjà àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, tàbí kẹ̀, ta ló tóó pe Ọlọ́run níjà nítorí pé ó ṣojú rere sáwọn tó ṣe olóòótọ́ sí i? Kò sẹ́ni tó tó bẹ́ẹ̀!—Aísáyà 50:8, 9; Hébérù 4:15, 16.
12, 13. (a) Àwọn ipò wo ni kò lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run? (b) Kí nìdí tí Èṣù fi ń fayé ni wá lára? (d) Èé ṣe táwọn Kristẹni fi ń di aṣẹ́gun pátápátá?
12 Ka Róòmù 8:35-37. Yàtọ̀ sí àfọwọ́fà, ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Jèhófà àti ti Kristi Jésù, Ọmọ rẹ̀? Èṣù lè máa lo àwọn aṣojú rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé láti han àwọn Kristẹni léèmọ̀. Ní ọ̀rúndún tó kọjá yìí, ọ̀pọ̀ lára àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa ni wọ́n ṣe inúnibíni gbígbóná janjan sí lọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè. Ní àwọn ilẹ̀ kan lónìí, ojoojúmọ́ lọ̀ràn àtijẹ àtimu ń kó ìrònú bá àwọn ará wa. Ebi ń han àwọn kan léèmọ̀, àwọn míì ò sì rí aṣọ gidi wọ̀ sára. Kí nìdí tí Èṣù fi ń kó gbogbo ìnira wọ̀nyí bá wa? Ó kéré tán, ọ̀kan lára ìdí tó fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni láti mú kí ìjọsìn tòótọ́ Jèhófà sú wa. Sátánì fẹ́ ká gbà gbọ́ pé ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa ti di tútù. Àmọ́, ṣóòótọ́ ni?
13 Gẹ́gẹ́ bíi Pọ́ọ̀lù, tó fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Sáàmù 44:22, àwa náà ti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. A mọ̀ pé torí orúkọ Ọlọ́run ni nǹkan wọ̀nyí fi ń ṣẹlẹ̀ sí àwa “àgùntàn” rẹ̀. Ọ̀ràn yìí wé mọ́ sísọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́ àti dídá ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ láre ní ọ̀run òun ayé. Nítorí ọ̀ràn pàtàkì wọ̀nyí ni Ọlọ́run fi yọ̀ǹda kí àdánwò dé bá wa, kì í ṣe tìtorí pé kò fẹ́ràn wa mọ́. Àmọ́ bílé ń jó bí ìjì ń jà, a ní ìdánilójú pé ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní fáwọn èèyàn rẹ̀, títí kan ẹnì kọ̀ọ̀kan wa, kò lè yí padà. Nígbà míì, bó tiẹ̀ dà bíi pé a ti ṣẹ́gun wa, ìjagunmólú ni tiwa nígbẹ̀yìngbẹ́yín bí a bá pa ìwà títọ́ mọ́. Ìfẹ́ alọ́májàá tí Ọlọ́run ní máa ń fún wa lókun, ó sì máa ń mẹ́sẹ̀ wa dúró.
14. Èé ṣe tí ìfẹ́ Ọlọ́run fi dá Pọ́ọ̀lù lójú, láìfi ìṣòro táwọn Kristẹni lè ní pè?
14 Ka Róòmù 8:38, 39. Kí ló mú un dá Pọ́ọ̀lù lójú pé kò sóhun tó lè ya àwọn Kristẹni kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run? Ó dájú pé ohun tí Pọ́ọ̀lù alára rí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà wà lára ohun tó mú kó dá a lójú pé kò sí òkè ìṣòro tó lè mú kí ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa di tútù. (2 Kọ́ríńtì 11:23-27; Fílípì 4:13) Pẹ̀lúpẹ̀lù, Pọ́ọ̀lù mọ̀ nípa ète ayérayé Jèhófà àtohun tó ṣe fáwọn èèyàn Rẹ̀ ìgbàanì. Ǹjẹ́ ikú pàápàá lè borí ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní fáwọn tó fi ìṣòtítọ́ sìn ín? Rárá o! Ọlọ́run, ọba adánimágbàgbé, kò ní gbàgbé irú àwọn olóòótọ́ bẹ́ẹ̀ bí wọ́n bá kú, á sì jí wọn dìde nígbà tákòókò bá tó.—Lúùkù 20:37, 38; 1 Kọ́ríńtì 15:22-26.
15, 16. Mẹ́nu ba díẹ̀ lára nǹkan tí kò lè jẹ́ kí Ọlọ́run dẹ́kun nínífẹ̀ẹ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ láé.
15 Àjálù yòówù kó dé bá wa nínú ayé yìí—ì báà jẹ́ jàǹbá tí ń sọni di ẹdun arinlẹ̀, àrùn kò-gbóògùn, tàbí ìṣòro àìríjẹ àìrímu—kò sóhun tó lè bomi paná ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní fáwọn èèyàn rẹ̀. Àwọn áńgẹ́lì alágbára, bí áńgẹ́lì aláìgbọràn tó di Sátánì, kò lè mú kí Jèhófà dẹ́kun nínífẹ̀ẹ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ń fọkàn sìn ín. (Jóòbù 2:3) Ọ̀pọ̀ ìjọba lè fòfin de àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run, kí wọ́n fi wọ́n sẹ́wọ̀n, kí wọ́n sì fìyà jẹ wọ́n, wọ́n tiẹ̀ lè kà wọ́n sí “ẹni ìtanù láwùjọ” pàápàá. (1 Kọ́ríńtì 4:13) Irú ìkórìíra bẹ́ẹ̀, táwọn orílẹ̀-èdè kórìíra wa láìnídìí, lè wá mú káwọn èèyàn kọjú ìjà sí wa, àmọ́ Ọba Aláṣẹ ọ̀run òun ayé kò ní torí ìyẹn pa wá tì.
16 Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, kò sídìí láti bẹ̀rù pé èyíkéyìí nínú ohun tí Pọ́ọ̀lù pè ní “àwọn ohun tí ó wà níhìn-ín nísinsìnyí”—ìyẹn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àti ipò tó wà nínú ètò nǹkan ìsinsìnyí, tàbí “àwọn ohun tí ń bọ̀” lọ́jọ́ iwájú, lè ya Ọlọ́run nípa sáwọn èèyàn rẹ̀. Bí àwọn agbára ayé àtàwọn agbára òkùnkùn tilẹ̀ ń gbógun, ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í yẹ̀ yóò mẹ́sẹ̀ wa dúró. Bí Pọ́ọ̀lù ti tẹnu mọ́ ọn, kò sí “ibi gíga tàbí ibi jíjìn” tó lè dí ìfẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ ni o, kò sóhun tó ń múni rẹ̀wẹ̀sì tàbí tó ń jẹ gàba léni lórí, tó lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run; bẹ́ẹ̀ náà ni kò sí ẹ̀dá èyíkéyìí tó lè ba àjọṣe tó wà láàárín Ẹlẹ́dàá àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ jẹ́. Ìfẹ́ Ọlọ́run kì í kùnà; títí ayé ni.—1 Kọ́ríńtì 13:8.
Máa Fojú Ribiribi Wo Inú Rere Ọlọ́run Títí Láé
17. (a) Èé ṣe tí níní ìfẹ́ Ọlọ́run fi “sàn ju ìyè” lọ? (b) Báwo la ṣe ń fi hàn pé a ń fojú ribiribi wo inú rere Ọlọ́run?
17 Báwo ni ìfẹ́ Ọlọ́run ti ṣe pàtàkì sí ọ tó? Ṣé bó ṣe rí lára Dáfídì ló ṣe rí lára rẹ, ẹni tó kọ̀wé pé: “Nítorí pé inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ sàn ju ìyè, ètè mi yóò gbóríyìn fún ọ. Bí èmi yóò ṣe máa fi ìbùkún fún ọ nìyẹn ní ìgbà ayé mi; èmi yóò máa gbé àtẹ́lẹwọ́ mi sókè ní orúkọ rẹ”? (Sáàmù 63:3, 4) Ká sọ tòótọ́, ǹjẹ́ nǹkan kan wà láyé yìí tó sàn ju gbígbádùn ìfẹ́ Ọlọ́run àti jíjẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́? Fún àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ lílépa iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tí ń mówó wọlé sàn ju níní ìbàlẹ̀ ọkàn àti ayọ̀ tí ń wá látinú níní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run? (Lúùkù 12:15) Wọ́n ti sọ ọ́ di túláàsì fáwọn Kristẹni kan rí pé kí wọ́n yàn yálà láti sẹ́ Jèhófà tàbí ká pa wọ́n. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìyẹn nínú ọgbà ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ìjọba Násì nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Yàtọ̀ sí àwọn díẹ̀ tó yẹsẹ̀, àwọn Kristẹni arákùnrin wa yàn láti dúró nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, wọ́n ṣe tán láti fi ẹ̀mí wọn dí i, bó bá di kàráǹgídá. Àwọn tó fi ìṣòtítọ́ dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀ ní ìdánilójú pé àwọn yóò rí ọjọ́ ọ̀la ayérayé gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, a sì mọ̀ pé ayé kò lè fún wa ní èyí. (Máàkù 8:34-36) Àmọ́ kì í ṣe ọ̀rọ̀ ìyè ayérayé nìkan ló wé mọ́ ọn.
18. Èé ṣe tí ìyè àìnípẹ̀kun á fi gbádùn mọ́ni gan-an?
18 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ṣeé ṣe láti wà láàyè títí láé láìsí Jèhófà, gbìyànjú láti fojú inú wo bí pípẹ́ láyé yóò ṣe rí láìsí Ẹlẹ́dàá wa. Ìgbésí ayé òfìfo, tí kò ní ète gidi nínú ni yóò jẹ́. Jèhófà ti fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní iṣẹ́ tí ń fúnni láyọ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí. Nítorí náà, ìdánilójú wà pé nígbà tí Jèhófà, Ọba Awíbẹ́ẹ̀-ṣe-bẹ́ẹ̀, bá fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun, yóò kún fún àwọn ohun tó gbámúṣé, tó máa wú wa lórí láti kọ́, tó sì máa wù wá láti ṣe. (Oníwàásù 3:11) Bó ti wù ká ṣèwádìí tó nínú ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún tí ń bọ̀, a ò lè rí gbogbo “ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run” tán láéláé.—Róòmù 11:33.
Baba Nífẹ̀ẹ́ Rẹ
19. Kí ni ọ̀rọ̀ ìdágbére tí ń fini lọ́kàn balẹ̀ tí Jésù Kristi sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?
19 Ní ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù Nísàn, ọdún 33 Sànmánì Tiwa, ní alẹ́ tí Jésù lò kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ́kànlá tó jẹ́ olóòótọ́, ó sọ ọ̀pọ̀ nǹkan láti fún wọn lókun nítorí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Wọ́n ti dúró ti Jésù gbágbáágbá nínú gbogbo àdánwò rẹ̀, àwọn alára sì ti rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn gan-an. (Lúùkù 22:28, 30; Jòhánù 1:16; 13:1) Jésù wá mú un dá wọn lójú pé: “Baba fúnra rẹ̀ ní ìfẹ́ni fún yín.” (Jòhánù 16:27) Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn yóò ti jẹ́ kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rí i bí Baba wọn ọ̀run ti yọ́nú sí wọn tó!
20. Kí ni o ti pinnu láti ṣe, kí ló sì dá ọ lójú?
20 Ọ̀pọ̀ tó wà láàyè lónìí ló ti ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún. Láìsí àní-àní, kí òpin ètò àwọn nǹkan búburú yìí tó dé, ọ̀pọ̀ àdánwò ṣì ń bẹ níwájú. Má ṣe jẹ́ kí irú àdánwò tàbí ìpọ́njú bẹ́ẹ̀ mú kí o mikàn nípa bóyá Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ rẹ ní tòótọ́. A ti sọ ọ́, ṣùgbọ́n a tún fẹ́ tún un sọ pé: Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ sẹ́ẹ̀. (Jákọ́bù 5:11) Kí gbogbo wa máa bá a nìṣó ní ṣíṣe ipa tiwa, ká máa fi tọkàntọkàn pa àṣẹ Ọlọ́run mọ́. (Jòhánù 15:8-10) Ǹjẹ́ kí a máa lo gbogbo àǹfààní tá a bá ní láti yin orúkọ rẹ̀. Ó yẹ ká túbọ̀ múra sí ọ̀ràn sísúnmọ́ Jèhófà nínú àdúrà àti kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ohun yòówù kó dé lọ́la, bá a bá ń sa gbogbo ipá wa láti múnú Jèhófà dùn, a óò ní àlàáfíà, ọkàn wa yóò sì balẹ̀ pé ìfẹ́ tí ó ní fún wa kò lè yẹ̀ láé.—2 Pétérù 3:14.
Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?
• Láti lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ nípa tẹ̀mí àti ní ti èrò orí, ta lẹni àkọ́kọ́ tá a fẹ́ kí ó nífẹ̀ẹ́ wa?
• Kí làwọn nǹkan tí kò lè jẹ́ kí Jèhófà dẹ́kun nínífẹ̀ẹ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láé?
• Èé ṣe tí ìfẹ́ Jèhófà fi “sàn ju ìyè” lọ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Bó bá ń ṣe wá bíi pé a ti yapa kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, á dáa ká ṣàtúnṣe
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Pọ́ọ̀lù mọ ìdí tí wọ́n fi ń ṣe inúnibíni sóun