Orí Kẹwàá
“Àkókò Ìtẹ́wọ́gbà”
1, 2. (a) Ìbùkún wo ni Aísáyà rí gbà? (b) Àwọn ta ni ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí wọ́n kọ sínú apá ìlàjì àkọ́kọ́ nínú Aísáyà orí kọkàndínláàádọ́ta kàn?
ÀTAYÉBÁYÉ ni gbogbo àwọn olóòótọ́ èèyàn ti ń rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run, ààbò rẹ̀ sì ń bẹ lórí wọn. Àmọ́, kì í ṣe irú wá ògìrì wá ló ń rí ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà. Èèyàn ní láti tóótun kó tó lè rí ìbùkún aláìlẹ́gbẹ́ yẹn gbà. Aísáyà sì pegedé. Ó rí ojú rere Ọlọ́run, Jèhófà sì lò ó gẹ́gẹ́ bí ohun èlò láti fi sọ ìfẹ́ Rẹ̀ di mímọ̀ fún àwọn ẹlòmíràn. Àpẹẹrẹ èyí ló wà ní àkọsílẹ̀ ní apá ìlàjì àkọ́kọ́ nínú orí kọkàndínláàádọ́ta àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà.
2 Irú ọmọ Ábúráhámù ni wọ́n darí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀. Nígbà tí ọ̀rọ̀ yìí kọ́kọ́ ṣẹ, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù ni irú-ọmọ náà. Àmọ́, ó hàn kedere pé èyí tó pọ̀ jù nínú gbólóhùn inú rẹ̀ ló jẹ mọ́ Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí, Irú-Ọmọ Ábúráhámù táwọn èèyàn ti ń retí tipẹ́tipẹ́. Ọ̀rọ̀ onímìísí yìí tún kan àwọn arákùnrin Mèsáyà nípa tẹ̀mí tí wọ́n di ara irú-ọmọ Ábúráhámù nípa tẹ̀mí, tí wọ́n sì di ara “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Gálátíà 3:7, 16, 29; 6:16) Ní pàtàkì, apá àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yìí ṣàpèjúwe àkànṣe àjọṣe tó wà láàárín Jèhófà àti Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀ àyànfẹ́.—Aísáyà 49:26.
Jèhófà Yàn Án, Ó sì Dáàbò Bò Ó
3, 4. (a) Aláfẹ̀yìntì wo ni Mèsáyà ní? (b) Ta ni Mèsáyà ń bá sọ̀rọ̀?
3 Mèsáyà rí ìtẹ́wọ́gbà tàbí ojú rere Ọlọ́run. Jèhófà fún un ní ọ̀pá àṣẹ àti ẹ̀rí ìtóótun tó nílò láti lè ṣe iṣẹ́ tó yàn fún un láṣeyanjú. Ìyẹn lohun tí Mèsáyà ọjọ́ iwájú náà sọ fi tọ́nà pé: “Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin erékùṣù, kí ẹ sì fiyè sílẹ̀, ẹ̀yin àwùjọ orílẹ̀-èdè tí ó jìnnà réré. Jèhófà tìkára rẹ̀ ni ó pè mí àní láti inú ikùn wá. Láti ìhà inú ìyá mi ni ó ti mẹ́nu kan orúkọ mi.”—Aísáyà 49:1.
4 Àwọn èèyàn láti ibi tí ó “jìnnà réré” ni Mèsáyà darí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí níhìn-ín. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù ni Ọlọ́run ṣèlérí Mèsáyà yìí fún, gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ yóò jẹ́ ìbùkún fún. (Mátíù 25:31-33) Lóòótọ́, ‘àwọn erékùṣù’ àti ‘àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè’ kò bá Jèhófà dá májẹ̀mú, síbẹ̀ kí wọ́n yáa gbọ́ràn sí Mèsáyà Ísírẹ́lì lẹ́nu ni o, nítorí pé òun ni Ọlọ́run rán láti mú ìgbàlà wá fún gbogbo ìran ènìyàn.
5. Báwo ló ṣe jẹ́ pé wọ́n ti sọ Mèsáyà lórúkọ àní kí wọ́n tó bí i sáyé pàápàá?
5 Àsọtẹ́lẹ̀ yìí sọ pé Jèhófà yóò dárúkọ Mèsáyà yìí kí wọ́n tó bí i sáyé. (Mátíù 1:21; Lúùkù 1:31) Tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí wọ́n tó bí Jésù ni wọ́n ti pè é ní “Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn, Ọlọ́run Alágbára Ńlá, Baba Ayérayé, Ọmọ Aládé Àlàáfíà.” (Aísáyà 9:6) Ó ṣeé ṣe kí Ìmánúẹ́lì jẹ́ orúkọ ọmọ kan tí Aísáyà bí, ó sì tún já sí orúkọ alásọtẹ́lẹ̀ kan fún Mèsáyà. (Aísáyà 7:14; Mátíù 1:21-23) Kódà ṣáájú ìbí Mèsáyà yìí ni wọ́n ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ pé Jésù ni yóò jẹ́ orúkọ àbísọ rẹ̀. (Lúùkù 1:30, 31) Inú ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Ìgbàlà” ni wọ́n ti mú orúkọ yẹn wá. Dájúdájú, Jésù kọ́ ló fi ara rẹ jẹ Kristi.
6. Ọ̀nà wo ni ẹnu Mèsáyà gbà dà bí idà mímú, báwo ni Jèhófà ṣe pa Mèsáyà yìí mọ́?
6 Mèsáyà ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ nínú àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Ó sì tẹ̀ síwájú láti ṣe ẹnu mi bí idà mímú. Inú òjìji ọwọ́ rẹ̀ ni ó fi mí pa mọ́ sí. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó sọ mí di ọfà dídán. Ó tọ́jú mi pa mọ́ sínú apó tirẹ̀.” (Aísáyà 49:2) Nígbà tí àsìkò tó tí Jésù, Mèsáyà Jèhófà, yóò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé lọ́dún 29 Sànmánì Tiwa, ńṣe ni ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀ dà bí àwọn ohun ìjà mímú tó ń dán, tó lè wọlé ṣinṣin sínú ọkàn àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Lúùkù 4:31, 32) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ìṣe rẹ̀ sì bí Sátánì, ọ̀tá Jèhófà paraku, àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ nínú. Látìgbà ìbí Jésù ni Sátánì ti ń sapá láti gbẹ̀mí Rẹ̀, ṣùgbọ́n bí ọfà tí Jèhófà fi pa mọ́ sínú apó tirẹ̀ ni Jésù jẹ́.a Ọkàn rẹ̀ balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ pé ààbò Baba òun ń bẹ lórí òun. (Sáàmù 91:1; Lúùkù 1:35) Nígbà tí àkókò tó, Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí ọmọ aráyé. Ṣùgbọ́n ìgbà ń bọ̀ tí yóò jáde lọ bí akọni jagunjagun ọ̀run tó dìhámọ́ra lọ́nà tó yàtọ̀, tòun ti idà mímú tí ń jáde lẹ́nu rẹ̀. Lọ́tẹ̀ yìí, idà mímú yẹn dúró fún àṣẹ tí Jésù ní láti kéde ìdájọ́ sórí àwọn ọ̀tá Jèhófà, àti láti mú ìdájọ́ yẹn ṣẹ.—Ìṣípayá 1:16.
Òpò Àwọn Ìránṣẹ́ Ọlọ́run Kì Í Ṣe Asán
7. Ta ni ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nínú Aísáyà 49:3 ṣẹ sí lára, kí sì nìdí rẹ̀?
7 Jèhófà wá sọ ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí, ó ní: “Ìwọ, Ísírẹ́lì, ni ìránṣẹ́ mi, ìwọ ẹni tí èmi yóò fi ẹwà mi hàn nínú rẹ̀.” (Aísáyà 49:3) Jèhófà pe orílẹ̀ èdè Ísírẹ́lì ní ìránṣẹ́ òun. (Aísáyà 41:8) Àmọ́, Jésù Kristi ni Ìránṣẹ́ Ọlọ́run pàtàkì jù lọ. (Ìṣe 3:13) Kò sí èyíkéyìí nínú ẹ̀dá Ọlọ́run tó lè gbé “ẹwà” Jèhófà yọ tó Jésù. Nítorí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni Jèhófà darí ọ̀rọ̀ yẹn sí, Jésù gan-an lọ̀rọ̀ náà ṣẹ sí lára ní ti gidi.—Jòhánù 14:9; Kólósè 1:15.
8. Ìhà wo ni àwọn èèyàn Mèsáyà alára kọ sí i, ṣùgbọ́n ọ̀dọ̀ ta ni Mèsáyà ń wò fún ìdíwọ̀n bí òun ṣe ṣàṣeyọrí tó?
8 Àmọ́ o, ṣebí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn Jésù alára tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀ tí wọ́n sì kọ̀ ọ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Bẹ́ẹ̀ ni. Lápapọ̀, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì kò gba Jésù gẹ́gẹ́ bí Ìránṣẹ́ tí Ọlọ́run fàmì òróró yàn. (Jòhánù 1:11) Gbogbo ohun tí Jésù gbé ṣe nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé lè dà bí ohun bíńtín, tàbí kó má tilẹ̀ já mọ́ nǹkan kan lójú àwọn èèyàn ìgbà ayé rẹ̀. Mèsáyà yán ìkùnà tó dà bíi pé yóò bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ yìí fẹ́rẹ́ báyìí pé: “Lásán ni mo ṣe làálàá. Òtúbáńtẹ́ àti asán ni mo ti lo gbogbo agbára mi fún.” (Aísáyà 49:4a) Kì í ṣe pé ọ̀ràn sú Mèsáyà ló ṣe sọ gbólóhùn yìí. Wo ohun tó sọ tẹ̀ lé e yìí ná, ó ní: “Lóòótọ́, ìdájọ́ mi ń bẹ lọ́dọ̀ Jèhófà, owó ọ̀yà mi sì ń bẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi.” (Aísáyà 49:4b) Èèyàn kọ́ ló máa díwọ̀n bí Mèsáyà ṣe ṣàṣeyọrí tó, Ọlọ́run ni.
9, 10. (a) Iṣẹ́ wo ni Jèhófà gbé lé Mèsáyà lọ́wọ́, báwo ló sì ti ṣàṣeyọrí sí? (b) Báwo ni ìrírí Mèsáyà ṣe lè jẹ́ ìṣírí fún àwọn Kristẹni òde òní?
9 Rírí ojú rere tàbí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run ló jẹ Jésù lógún. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ yìí, Mèsáyà sọ pé: “Wàyí o, Jèhófà, Ẹni tí ó ṣẹ̀dá mi láti inú ikùn wá gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ tí ó jẹ́ tirẹ̀, ti sọ pé kí n mú Jékọ́bù padà wá sọ́dọ̀ òun, kí a lè kó Ísírẹ́lì pàápàá jọ sọ́dọ̀ rẹ̀. A ó sì ṣe mí lógo lójú Jèhófà, Ọlọ́run mi yóò sì di okun mi.” (Aísáyà 49:5) Mèsáyà wá láti yí ọkàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì padà sọ́dọ̀ Baba wọn ọ̀run. Ọ̀pọ̀ jù lọ wọn sì kọ etí ikún sí i, ṣùgbọ́n àwọn kan gbọ́, wọ́n sì gbà. Àmọ́ ṣá o, Jèhófà Ọlọ́run ni yóò kúkú san án lẹ́san. Kì í ṣe bí ọmọ aráyé ṣe ń wo àṣeyọrí rẹ̀ ló ṣe pàtàkì, ojú tí Jèhófà tìkára rẹ̀ fi wò ó ni kókó.
10 Nígbà mìíràn, lóde òní, àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù lè rò pé ńṣe làwọn kàn ń ṣe làálàá lásán. Ní àwọn ibì kan, àṣeyọrí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn lè dà bí èyí tí kò já mọ́ nǹkan kan rárá ní ìfiwéra pẹ̀lú iṣẹ́ àti ìsapá tí wọ́n ṣe. Síbẹ̀, wọ́n ń forí tì í nìṣó bí àpẹẹrẹ Jésù ṣe ń fún wọn ní ìṣírí. Ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sì tún ń fún wọn lókun, ẹni tó kọ̀wé pé: “Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, ẹ di aláìṣeéṣínípò, kí ẹ máa ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa, ní mímọ̀ pé òpò yín kì í ṣe asán ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Olúwa.”—1 Kọ́ríńtì 15:58.
“Ìmọ́lẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè”
11, 12. Báwo ni Mèsáyà ṣe jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè”?
11 Nínú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Jèhófà fún Mèsáyà níṣìírí nípa rírán an létí pé béèyàn bá ti jẹ́ Ìránṣẹ́ Ọlọ́run, ìyẹn ti “ré kọjá ọ̀ràn tí kò tó nǹkan.” Jésù yóò ní “láti gbé àwọn ẹ̀yà Jékọ́bù dìde, kí [ó] sì mú àwọn tí a fi ìṣọ́ ṣọ́ lára Ísírẹ́lì padà wá.” Jèhófà ṣàlàyé síwájú sí i pé: “Pẹ̀lúpẹ̀lù, mo ti pèsè rẹ gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, kí ìgbàlà mi lè wá títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.” (Aísáyà 49:6) Báwo ni Jésù ṣe wá la àwọn èèyàn lóye “títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé” nígbà tó jẹ́ pé àárín Ísírẹ́lì ló fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé mọ sí?
12 Àkọsílẹ̀ Bíbélì fi hàn pé “ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè” tí Ọlọ́run tàn kò kú nígbà tí Jésù kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Ní nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lẹ́yìn ikú Jésù, Pọ́ọ̀lù àti Bánábà tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì fa ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà 49:6 yọ, wọ́n sì lò ó fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, tí wọ́n jẹ́ arákùnrin rẹ̀ nípa tẹ̀mí. Wọ́n ṣàlàyé pé: “Jèhófà ti pàṣẹ fún wa ní ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pé, ‘Mo ti yàn ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, fún ọ láti jẹ́ ìgbàlà títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.’” (Ìṣe 13:47) Kí ikú tó pa Pọ́ọ̀lù alára, ó fojú rí i pé ìhìn rere ìgbàlà kò mọ sọ́dọ̀ àwọn Júù nìkan, pé ó dé ọ̀dọ̀ “gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run” pẹ̀lú. (Kólósè 1:6, 23) Lóde òní, àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Kristi ló ń bá iṣẹ́ yìí nìṣó. Pẹ̀lú ìtìlẹyìn àwọn “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí iye wọ́n jẹ́ àràádọ́ta ọ̀kẹ́, wọ́n ń tàn bí “ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè” ní àwọn orílẹ̀-èdè tí iye wọn ju igba ó lé ọgbọ̀n [230] lọ káàkiri ayé.—Ìṣípayá 7:9.
13, 14. (a) Kí ni Mèsáyà àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ rí pé ó jẹ́ ìṣarasíhùwà àwọn èèyàn sí iṣẹ́ ìwàásù? (b) Àyípadà wo ló sì wáyé?
13 Dájúdájú, Jèhófà ni alágbára tí ń bẹ lẹ́yìn Mèsáyà Ìránṣẹ́ rẹ̀, lẹ́yìn àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Mèsáyà, àti gbogbo àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá tí wọ́n jọ ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà lọ. Lóòótọ́, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù pẹ̀lú ń fojú winá àtakò àti ìyọṣùtì síni bíi ti Jésù. (Jòhánù 15:20) Ṣùgbọ́n bó bá ti tó àsìkò lójú Jèhófà, ńṣe ló máa ń mú kí ipò yẹn yí padà láti lè gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ sílẹ̀ kí ó sì san àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ lẹ́san. Ní ti Mèsáyà, ẹni tí a “tẹ́ńbẹ́lú nínú ọkàn,” tí “orílẹ̀-èdè ń ṣe họ́ọ̀ sí,” ìlérí tí Jèhófà ṣe ni pé: “Àwọn ọba tìkára wọn yóò rí i, wọn yóò sì dìde dájúdájú, àti àwọn ọmọ aládé, wọn yóò sì tẹrí ba, nítorí Jèhófà, ẹni tí ó jẹ́ olùṣòtítọ́, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì, ẹni tí ó yàn ọ́.”—Aísáyà 49:7.
14 Lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ní Fílípì nípa àyípadà tí àsọtẹ́lẹ̀ sọ pé yóò wáyé yìí. Ó sọ̀rọ̀ nípa Jésù pé wọ́n bẹ̀tẹ́ lù ú nípa kíkàn án mọ́ igi oró, ṣùgbọ́n pé Ọlọ́run gbé e ga lẹ́yìn náà. Jèhófà wá fún Ìránṣẹ́ rẹ̀ yìí ní “ipò gíga, tí ó sì fi inú rere fún un ní orúkọ tí ó lékè gbogbo orúkọ mìíràn, kí ó lè jẹ́ pé ní orúkọ Jésù ni kí gbogbo eékún máa tẹ̀ ba.” (Fílípì 2:8-11) Àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi olóòótọ́ ti gba ìkìlọ̀ tẹ́lẹ̀ pé àwọn náà yóò fojú winá inúnibíni. Ṣùgbọ́n, ó dájú pé wọn yóò rí ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà bákan náà gẹ́gẹ́ bíi ti Mèsáyà.—Mátíù 5:10-12; 24:9-13; Máàkù 10:29, 30.
‘Àkókò Ìtẹ́wọ́gbà Gan-An’
15. “Àkókò” àkànṣe wo ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà mẹ́nu kàn, kí sì ni èyí túmọ̀ sí?
15 Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà wá ń bá àlàyé lọ lórí kókó kan tó ṣe pàtàkì gidigidi. Jèhófà sọ fún Mèsáyà pé: “Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, mo ti dá ọ lóhùn, àti ní ọjọ́ ìgbàlà, mo ti ràn ọ́ lọ́wọ́; mo sì ń fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ kí n lè pèsè rẹ gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn.” (Aísáyà 49:8a) Àsọtẹ́lẹ̀ kan tó jọ èyí wà nínú Sáàmù 69:13-18. Onísáàmù yìí sọ̀rọ̀ nípa “àkókò ìtẹ́wọ́gbà” níbẹ̀. Gbólóhùn yìí ń fi hàn pé Jèhófà a máa nawọ́ ìtẹ́wọ́gbà àti ààbò rẹ̀ lọ́nà àkànṣe, ó sì máa ń jẹ́ ní àkókò pàtó kan tí kì í gùn lọ títí.
16. Ìgbà wo ló jẹ́ àkókò ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà fún Ísírẹ́lì àtijọ́?
16 Ìgbà wo ni àkókò ìtẹ́wọ́gbà yẹn? Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ara àsọtẹ́lẹ̀ ìmúbọ̀sípò, àsọtẹ́lẹ̀ bí àwọn Júù yóò ṣe padà wálé láti ìgbèkùn ló sì sọ. Àkókò ìtẹ́wọ́gbà dé fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nígbà tó ṣeé ṣe fún wọn láti “tún ilẹ̀ náà ṣe,” tí wọ́n sì rí ‘àwọn ohun ìní àjogúnbá wọn tí ó ti di ahoro’ gbà padà. (Aísáyà 49:8b) Wọn kì í ṣe “ẹlẹ́wọ̀n” ní Bábílónì mọ́. Nígbà ìrìn àjò wọn lọ sílé, Jèhófà rí i dájú pé ‘ebi kò pa wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ kò gbẹ wọ́n,’ bẹ́ẹ̀ ni ‘ooru amóhungbẹ hán-ún hán-ún kò mú wọn tàbí kí oòrùn pa wọ́n.’ Ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ti fọ́n káàkiri bá tú yáyá padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn, “láti ibi jíjìnnàréré . . . , láti àríwá àti láti ìwọ̀-oòrùn.” (Aísáyà 49:9-12) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìmúṣẹ àkọ́kọ́ tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní bùáyà, Bíbélì fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí tún ṣẹ láwọn ọ̀nà tó gbòòrò jù bẹ́ẹ̀ lọ.
17, 18. Àkókò ìtẹ́wọ́gbà wo ni Jèhófà yàn ní ọ̀rúndún kìíní?
17 Àkọ́kọ́, nígbà ìbí Jésù, àwọn áńgẹ́lì polongo àlàáfíà àti ìtẹ́wọ́gbà tàbí ojú rere Ọlọ́run fún aráyé. (Lúùkù 2:13, 14) Ọlọ́run kò nawọ́ ìtẹ́wọ́gbà yìí sí aráyé ní gbogbo gbòò, kìkì àwọn tó lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù nìkan ló tẹ́wọ́ gbà. Lẹ́yìn ìgbà náà, Jésù ka àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà 61:1, 2 sétígbọ̀ọ́ àwọn èèyàn, ó sì sọ pé ó ṣẹ sí òun lára gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń polongo “ọdún ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà.” (Lúùkù 4:17-21) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé Jèhófà fi àkànṣe ààbò rẹ̀ bo Kristi ní àsìkò tó fi jẹ́ ẹlẹ́ran ara. (Hébérù 5:7-9) Nípa bẹ́ẹ̀, àkókò ìtẹ́wọ́gbà yìí wé mọ́ ojú rere tí Ọlọ́run ṣe sí Jésù nígbà tó fi jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn.
18 Àmọ́ ṣá o, àsọtẹ́lẹ̀ yìí tún kan ohun mìíràn síwájú sí i. Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù fa ọ̀rọ̀ tí Aísáyà sọ nípa àkókò ìtẹ́wọ́gbà yọ, ó wá sọ pé: “Wò ó! Ìsinsìnyí gan-an ni àkókò ìtẹ́wọ́gbà. Wò ó! Ìsinsìnyí ni ọjọ́ ìgbàlà.” (2 Kọ́ríńtì 6:2) Ọdún méjìlélógún lẹ́yìn ikú Jésù ni Pọ́ọ̀lù kọ ọ̀rọ̀ yìí. Ó wá hàn pé, bó ṣe di pé ìjọ Kristẹni bẹ̀rẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, ńṣe ni Jèhófà fa ọdún ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀ gùn síwájú sí i kí ó fi lè kan àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Kristi.
19. Báwo ni àwọn Kristẹni òde òní ṣe lè jàǹfààní nínú àkókò ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà?
19 Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù òde òní tí kì í ṣe ara àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ ajogún ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀run wá ńkọ́? Ǹjẹ́ àwọn tó ń retí pé ilẹ̀ ayé làwọn yóò jogún lè jàǹfààní nínú àkókò ìtẹ́wọ́gbà yìí bí? Bẹ́ẹ̀ ni o. Nínú Bíbélì, ìwé Ìṣípayá fi hàn pé ní báyìí, a wà ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà fún àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá tí yóò jáde “wá láti inú ìpọ́njú ńlá” láti wá gbádùn ìyè nínú ilẹ̀ ayé tó di Párádísè. (Ìṣípayá 7:13-17) Nípa bẹ́ẹ̀, gbogbo Kristẹni lè lo àǹfààní àkókò kúkúrú yìí tí Jèhófà fi nawọ́ ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀ sí àwọn ọmọ aráyé aláìpé.
20. Ọ̀nà wo ni àwọn Kristẹni lè gbà yẹra fún títàsé ète inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà?
20 Ìkìlọ̀ ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ ṣe kí ó tó polongo àkókò ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà. Ó rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n ‘má ṣe tẹ́wọ́ gba inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run kí wọ́n sì tàsé ète rẹ̀.’ (2 Kọ́ríńtì 6:1) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn Kristẹni a máa lo gbogbo àǹfààní tí wọ́n bá ní láti fi wu Ọlọ́run àti láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Éfésù 5:15, 16) Ì bá sì dára kí wọ́n ṣe bí Pọ́ọ̀lù ṣe rọ̀ wọ́n, pé: “Ẹ kíyè sára, ẹ̀yin ará, kí ọkàn-àyà burúkú tí ó ṣaláìní ìgbàgbọ́ má bàa dìde nínú ẹnikẹ́ni nínú yín láé nípa lílọ kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè; ṣùgbọ́n ẹ máa bá a nìṣó ní gbígba ara yín níyànjú lẹ́nì kìíní-kejì lójoojúmọ́, níwọ̀n ìgbà tí a bá ti lè pè é ní ‘Òní,’ kí agbára ìtannijẹ ẹ̀ṣẹ̀ má bàa sọ ẹnikẹ́ni nínú yín di aláyà líle.”—Hébérù 3:12, 13.
21. Ọ̀rọ̀ ayọ̀ wo ló parí apá àkọ́kọ́ nínú Aísáyà orí kọkàndínláàádọ́ta?
21 Bí ọ̀rọ̀ asọtẹ́lẹ̀ tó ń lọ láàárín Jèhófà àti Mèsáyà rẹ̀ ṣe ń parí ni Aísáyà bá gbẹ́nu lé ọ̀rọ̀ ayọ̀ yìí pé: “Ẹ kígbe ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin ọ̀run, sì kún fún ìdùnnú, ìwọ ilẹ̀ ayé. Kí àwọn òkè ńlá fi igbe ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ tújú ká. Nítorí pé Jèhófà ti tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú, ó sì fi ojú àánú hàn sí àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́.” (Aísáyà 49:13) Ọ̀rọ̀ ìtùnú tó kọyọyọ mà rèé o, fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́, fún Jésù Kristi, àgbà Ìránṣẹ́ Jèhófà, àti fún àwọn ìránṣẹ́ tí Jèhófà fàmì òróró yàn àti àwọn “àgùntàn mìíràn” alábàákẹ́gbẹ́ wọn lóde òní!—Jòhánù 10:16.
Jèhófà Kò Gbàgbé Àwọn Èèyàn Rẹ̀
22. Báwo ni Jèhófà ṣe tẹnu mọ́ ọn pé òun ò ní gbàgbé àwọn èèyàn òun láé?
22 Wàyí o, Aísáyà wá ń bá àwọn ìkéde Jèhófà nìṣó. Ó sọ tẹ́lẹ̀ pé yóò fẹ́ sú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà nígbèkùn, wọn yóò sì fẹ́ sọ̀rètí nù. Aísáyà ní: “Síónì ń wí ṣáá pé: ‘Jèhófà ti fi mí sílẹ̀, Jèhófà tìkára rẹ̀ sì ti gbàgbé mi.’” (Aísáyà 49:14) Ṣé lóòótọ́ ni? Ṣé Jèhófà ti kọ àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ tó sì ti gbàgbé wọn ni? Aísáyà gbẹnu sọ fún Jèhófà, ó ń bọ́rọ̀ lọ pé: “Aya ha lè gbàgbé ọmọ ẹnu ọmú rẹ̀ tí kì yóò fi ṣe ojú àánú sí ọmọ ikùn rẹ̀? Àní àwọn obìnrin wọ̀nyí lè gbàgbé, síbẹ̀, èmi kì yóò gbàgbé.” (Aísáyà 49:15) Èsì onífẹ̀ẹ́ gbáà lèyí jẹ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà! Ìfẹ́ tí Ọlọ́run fẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀ ju ìfẹ́ ìyá sí ọmọ lọ. Gbogbo ìgbà ló ń ro ti àwọn adúróṣinṣin rẹ̀. Bíi pé ó fín orúkọ wọn sí ara ọwọ́ rẹ̀ ló ṣe ń rántí wọn, ó ní: “Wò ó! Àtẹ́lẹwọ́ mi ni mo fín ọ sí. Àwọn ògiri rẹ wà ní iwájú mi nígbà gbogbo.”—Aísáyà 49:16.
23. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe rọ àwọn Kristẹni láti ní ìdánilójú pé Jèhófà kò ní gbàgbé wọn?
23 Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Gálátíà, ó rọ àwọn Kristẹni pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí ní àsìkò yíyẹ àwa yóò kárúgbìn bí a kò bá ṣàárẹ̀.” (Gálátíà 6:9) Ó sì kọ ọ̀rọ̀ ìṣírí yìí sí àwọn Hébérù pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀, ní ti pé ẹ ti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹni mímọ́, ẹ sì ń bá a lọ ní ṣíṣe ìránṣẹ́.” (Hébérù 6:10) Kí á má ṣe rò ó láé pé Jèhófà ti gbàgbé àwọn èèyàn rẹ̀. Ìdí pàtàkì wà fún àwọn Kristẹni láti máa yọ̀ kí wọ́n sì dúró de Jèhófà bíi ti Síónì àtijọ́. Jèhófà kì í yẹhùn rárá lórí májẹ̀mú àti àwọn ìlérí rẹ̀.
24. Ọ̀nà wo ni ìmúbọ̀sípò yóò gbà dé bá Síónì, àwọn ìbéèrè wo ni yóò sì béèrè?
24 Jèhófà gbẹnu Aísáyà mú ìtùnú wá síwájú sí i. Àwọn tó ń “ya [Síónì] lulẹ̀” kò ní dún mọ̀huru-mọ̀huru mọ́ wọn mọ́, ì báà jẹ́ àwọn ará Bábílónì ni o tàbí àwọn Júù apẹ̀yìndà. “Àwọn ọmọ” Síónì, ìyẹn àwọn Júù ìgbèkùn tó dúró ṣinṣin ti Jèhófà, “ti ṣe wéré.” Wọn yóò ‘kó wọn jọpọ̀.’ Bí àwọn Júù tó darí sílé ṣe tara ṣàṣà padà sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n yóò jẹ́ ohun ọ̀ṣọ́ fún olú ìlú wọn yìí bí ìgbà tí “ìyàwó” wọ “àwọn ohun ọ̀ṣọ́.” (Aísáyà 49:17, 18) Wọ́n ti sọ Síónì di ibi “ìparundahoro.” Ẹ wo bí yóò ṣe yà á lẹ́nu tó nígbà tí àwọn èèyàn dédé kún ibẹ̀ fọ́fọ́, tí wọ́n sì pọ̀ débi tó fi dà bí pé àyè ibùgbé há níbẹ̀. (Ka Aísáyà 49:19, 20.) Gẹ́gẹ́ bí ìṣe ẹ̀dá, ó di pé kí ó béèrè ibi tí gbogbo ọmọ wọ̀nyí ti wá: “Ó dájú pé ìwọ yóò sọ nínú ọkàn-àyà rẹ pé, ‘Ta ni ó bá mi bí àwọn wọ̀nyí, níwọ̀n bí mo ti jẹ́ obìnrin tí ó ṣòfò àwọn ọmọ, tí ó sì jẹ́ aláìlè-méso-jáde, tí ó lọ sí ìgbèkùn, tí a sì mú ní ẹlẹ́wọ̀n? Ní ti àwọn wọ̀nyí, ta ni ó tọ́ wọn dàgbà? Wò ó! A ti fi mí sílẹ̀ sẹ́yìn ní èmi nìkan. Àwọn wọ̀nyí—ibo ni wọ́n ti wà?’” (Aísáyà 49:21) Ìdùnnú wá ṣubú lu ayọ̀ gbáà fún Síónì tó fìgbà kan rí jẹ́ àgàn!
25. Ìmúbọ̀sípò wo ló dé bá Ísírẹ́lì tẹ̀mí lákòókò òde òní?
25 Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní ìmúṣẹ ti òde òní. Ní àsìkò kan láàárín àwọn ọdún ìgbónágbóoru Ogun Àgbáyé Kìíní, Ísírẹ́lì tẹ̀mí wà láhoro àti ìgbèkùn. Ṣùgbọ́n ìmúbọ̀sípò dé bá a, ló bá bọ́ sínú párádísè tẹ̀mí. (Aísáyà 35:1-10) Ọ̀ràn rẹ̀ wá rí bíi ti ìlú tí ó dahoro tí Aísáyà ṣàpèjúwe rẹ̀, inú rẹ̀ dùn gan-an ni ká wí, bó ṣe wá rí i pé àwọn aláyọ̀ olùjọsìn Jèhófà tó já fáfá kún inú òun fọ́fọ́.
“Àmì Àfiyèsí fún Àwọn Ènìyàn”
26. Ìtọ́ni wo ni Jèhófà fún àwọn èèyàn rẹ̀ tí ó dá nídè?
26 Nínú àsọtẹ́lẹ̀, Jèhófà mú Aísáyà lọ sí ìgbà tí àwọn èèyàn Rẹ̀ yóò gba ìdáǹdè kúrò ní Bábílónì. Ǹjẹ́ Jèhófà yóò wá fún wọn ní ìtọ́ni kankan? Jèhófà dáhùn pé: “Wò ó! Èmi yóò gbé ọwọ́ mi sókè, àní sí àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì gbé àmì àfiyèsí mi sókè sí àwọn ènìyàn. Wọn yóò sì gbé àwọn ọmọkùnrin rẹ wá ní oókan àyà, èjìká sì ni wọn yóò gbé àwọn ọmọbìnrin rẹ sí.” (Aísáyà 49:22) Nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí kọ́kọ́ ṣẹ, Jerúsálẹ́mù, tó jẹ́ ibùjókòó ìjọba àti ibi tí tẹ́ńpìlì Jèhófà wà ló jẹ́ “àmì àfiyèsí” Jèhófà. Kódà àwọn ẹni kàǹkà-kàǹkà àti àwọn alágbára látinú àwọn orílẹ̀-èdè yòókù, irú bí “àwọn ọba” àti “àwọn ọmọ aládé,” ṣèrànwọ́ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n ń padà lọ sọ́hùn-ún. (Aísáyà 49:23a) Àwọn ọba ilẹ̀ Páṣíà bíi Kírúsì àti Atasásítà Lọngimánọ́sì, àti ìdílé wọn wà lára àwọn tó ṣèrànwọ́ yìí. (Ẹ́sírà 5:13; 7:11-26) Ọ̀rọ̀ Aísáyà sì tún ní ìmúṣẹ mìíràn.
27. (a) Nígbà ìmúṣẹ ńlá rẹ̀, “àmì àfiyèsí” wo làwọn èèyàn yóò dà wìtìwìtì lọ bá? (b) Kí ni yóò jẹ́ àbájáde rẹ̀ nígbà tó bá di dandan gbọ̀n fún gbogbo orílẹ̀-èdè láti tẹrí ba fún ìṣàkóso Mèsáyà?
27 Aísáyà 11:10 sọ̀rọ̀ nípa “àmì àfiyèsí fún àwọn ènìyàn.” Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo ọ̀rọ̀ yìí fún Kristi Jésù. (Róòmù 15:8-12) Nípa bẹ́ẹ̀, nígbà ìmúṣẹ rẹ̀ ńlá, Jésù àti àwọn tí a fi ẹ̀mí yàn láti bá a ṣàkóso ló jẹ́ “àmì àfiyèsí” Jèhófà tí àwọn èèyàn ń dà wìtìwìtì lọ bá. (Ìṣípayá 14:1) Tí àsìkò bá tó, gbogbo èèyàn ilẹ̀ ayé, títí kan àwọn alákòóso òde òní pàápàá, yóò ní láti tẹrí ba fún ìṣàkóso Mèsáyà. (Sáàmù 2:10, 11; Dáníẹ́lì 2:44) Kí ni yóò jẹ́ àbájáde rẹ̀? Jèhófà sọ pé: “Ìwọ yóò ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà, ẹni tí ó jẹ́ pé àwọn tí ó ní ìrètí nínú mi ni ojú kì yóò tì.”—Aísáyà 49:23b.
“Ìgbàlà Wa Sún Mọ́lé Nísinsìnyí”
28. (a) Ọ̀rọ̀ wo ni Jèhófà sọ láti mú un dá àwọn èèyàn rẹ̀ lójú lẹ́ẹ̀kan sí i pé òun yóò dá wọn nídè? (b) Kí ni ẹ̀jẹ́ tí Jèhófà ṣì máa san fún àwọn èèyàn rẹ̀?
28 Àwọn kan lára àwọn tó wà nígbèkùn ní Bábílónì lè bẹ̀rẹ̀ sí rò ó pé, ‘Ṣé Ísírẹ́lì wá lè bọ́ lóko òǹdè báyìí?’ Jèhófà ro ti ìbéèrè yìí pẹ̀lú, ìyẹn ló fi béèrè pé: “A ha lè kó àwọn tí alágbára ńlá ti kó tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀ bí, tàbí kẹ̀, ẹgbẹ́ àwọn òǹdè ti afìkà-gboni-mọ́lẹ̀ ha lè sá àsálà bí?” (Aísáyà 49:24) Bẹ́ẹ̀ ni o. Jèhófà mú un dá wọn lójú pé: “Àní ẹgbẹ́ àwọn òǹdè ti alágbára ńlá ni a óò kó lọ, àwọn tí a sì ti kó tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ afìkà-gboni-mọ́lẹ̀ pàápàá yóò sá àsálà.” (Aísáyà 49:25a) Ìtùnú gbáà ni ìdánilójú tí Jèhófà fún wọn yìí jẹ́ o! Àní sẹ́, Jèhófà tún jẹ́ ẹ̀jẹ́ pé òun yóò dáàbò bo àwọn èèyàn òun láfikún sí títẹ́wọ́ gbà wọ́n. Ó sọ ọ́ ní ṣàkó pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ń bá ọ fà á, èmi tìkára mi yóò bá a fà á, àwọn ọmọ rẹ ni èmi fúnra mi yóò sì gbà là.” (Aísáyà 49:25b) Ẹ̀jẹ́ yẹn kò yí padà. Gẹ́gẹ́ bí Sekaráyà 2:8 ṣe sọ, Jèhófà sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Ẹni tí ó bá fọwọ́ kàn yín ń fọwọ́ kan ẹyinjú mi.” Ní tòótọ́, àkókò ìtẹ́wọ́gbà yẹn la wà báyìí o, àkókò tí àǹfààní ṣí sílẹ̀ fún àwọn èèyàn jákèjádò ayé láti dà wìtìwìtì lọ sí Síónì nípa tẹ̀mí. Ṣùgbọ́n àkókò ìtẹ́wọ́gbà yẹn máa dópin o.
29. Àgbákò ńlá wo ló ń dúró de àwọn tó kọ̀ láti ṣe ohun tí Jèhófà wí?
29 Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó forí kunkun kọ̀ láti ṣe ohun tí Jèhófà wí, tí wọ́n sì ń ṣenúnibíni pàápàá sí àwọn olùjọ́sìn rẹ̀? O sọ pé: “Ṣe ni èmi yóò mú kí àwọn tí ń ṣe ọ́ níkà jẹ ẹran ara wọn; àti gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó mu wáìnì dídùn, wọn yóò mu ẹ̀jẹ̀ ara wọn ní àmupara.” (Aísáyà 49:26a) Àgbákò ńlá ń bẹ níwájú fún wọn! Àwọn alátakò olóríkunkun yìí kò ní pẹ́ láyé rárá. Wọn yóò pa run. Bí yóò ṣe wá hàn lọ́nà méjì pé Jèhófà jẹ́ Olùgbàlà nìyẹn o, ní ti pé ó gba àwọn èèyàn rẹ̀ là ó sì tún pa àwọn ọ̀tá wọn run. Ó ní: “Gbogbo ẹran ara yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi, Jèhófà, ni Olùgbàlà rẹ àti Olùtúnnirà rẹ, Ẹni Alágbára Jékọ́bù.”—Aísáyà 49:26b.
30. Àwọn iṣẹ́ ìgbàlà wo ni Jèhófà ṣe nítorí àwọn èèyàn rẹ̀, kí ló sì máa tó ṣe láìpẹ́?
30 Ìgbà tí Jèhófà lo Kírúsì láti fi dá àwọn èèyàn Rẹ̀ nídè kúrò nígbèkùn Bábílónì lọ̀rọ̀ wọ̀nyí kọ́kọ́ ṣẹ. Wọ́n tún ṣẹ pẹ̀lú lọ́dún 1919 nígbà tí Jèhófà lo Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ tó gorí ìtẹ́ láti fi dá àwọn èèyàn Rẹ̀ nídè kúrò lóko ẹrú nípa tẹ̀mí. Ìyẹn ni Bíbélì fi pe Jèhófà àti Jésù ní olùgbàlà. (Títù 2:11-13; 3:4-6) Jèhófà ni Olùgbàlà wa, Jésù tó jẹ́ Mèsáyà sì jẹ́ “Olórí Aṣojú” rẹ̀. (Ìṣe 5:31) Ní tòdodo, àgbàyanu làwọn iṣẹ́ ìgbàlà tí Ọlọ́run tipasẹ̀ Jésù Kristi ṣe. Jèhófà ń lo ìhìn rere láti fi dá àwọn ọlọ́kàn títọ́ nídè kúrò nínú ìgbèkùn ìsìn èké. Ó ń lo ẹbọ ìràpadà láti fi gbà wọ́n kúrò nígbèkùn ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Lọ́dún 1919, ó gba àwọn arákùnrin Jésù kúrò nígbèkùn nípa tẹ̀mí. Nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì tó sì ń bọ̀ kánkán yìí, yóò gba ogunlọ́gọ̀ ńlá àwọn olóòótọ́ èèyàn là kúrò lọ́wọ́ ìparun tí yóò wá sórí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀.
31. Ìhà wo ló yẹ kí àwọn Kristẹni kọ sí jíjẹ́ ẹni tó rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run?
31 Áà, àǹfààní ńlá mà ló jẹ́ o láti rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run! Kí gbogbo wa lo àkókò ìtẹ́wọ́gbà yìí lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu o. Kí gbogbo wa sì hùwà tó bá àkókò kánjúkánjú tí a ń gbé yìí mu o, kí a kọbi ara sí ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Róòmù pé: “Ẹ mọ àsìkò, pé wákàtí ti tó nísinsìnyí fún yín láti jí lójú oorun, nítorí ìgbàlà wa sún mọ́lé nísinsìnyí ju ìgbà tí a di onígbàgbọ́. Òru ti lọ jìnnà; ojúmọ́ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ mọ́. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a bọ́ àwọn iṣẹ́ tí ó jẹ́ ti òkùnkùn kúrò, kí a sì gbé àwọn ohun ìjà ìmọ́lẹ̀ wọ̀. Gẹ́gẹ́ bí ní ìgbà ọ̀sán, ẹ jẹ́ kí a máa rìn lọ́nà bíbójúmu, kì í ṣe nínú àwọn àríyá aláriwo àti mímu àmuyíràá, kì í ṣe nínú ìbádàpọ̀ tí ó tàpá sófin àti ìwà àìníjàánu, kì í ṣe nínú gbọ́nmi-si omi-ò-to àti owú. Ṣùgbọ́n ẹ gbé Olúwa Jésù Kristi wọ̀, ẹ má sì máa wéwèé tẹ́lẹ̀ fún àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ẹran ara.”—Róòmù 13:11-14.
32. Ìdánilójú wo ló wà fún àwọn èèyàn Ọlọ́run?
32 Jèhófà yóò máa bá a lọ láti ṣojú rere sí àwọn tó bá kọbi ara sí ìmọ̀ràn rẹ̀. Yóò pèsè okun àti agbára tí wọ́n máa lò láti fi wàásù ìhìn rere fún wọn. (2 Kọ́ríńtì 4:7) Jèhófà yóò lo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe lo Jésù tó jẹ́ Aṣáájú wọn. Yóò ṣe ẹnu wọn bí “idà mímú” kí wọ́n fi lè sọ ìhìn rere náà lọ́nà tí yóò wọ àwọn ọlọ́kàn tútù lọ́kàn. (Mátíù 28:19, 20) Yóò fi ààbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ ní “inú òjìji ọwọ́ rẹ̀.” Bí ẹní pa “ọfà dídán” mọ́ ni yóò ṣe fi wọ́n pa mọ́ “sínú apó tirẹ̀.” Dájúdájú, Jèhófà ò mà ní ṣá àwọn èèyàn rẹ̀ tì o!—Sáàmù 94:14; Aísáyà 49:2, 15.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a “Ó dájú pé, gbogbo ipá ni Sátánì sà láti sáà rẹ́yìn Jésù, níwọ̀n bó ti mọ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run ló jẹ́, àti pé òun ni ẹni tí àsọtẹ́lẹ̀ sọ pé yóò pa òun ní orí. (Jẹ 3:15) Ṣùgbọ́n nígbà tí áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì ń sọ fún Màríà nípa bí yóò ṣe lóyún Jésù, ó sọ fún un pé: ‘Ẹ̀mí mímọ́ yóò bà lé ọ, agbára Ẹni Gíga Jù Lọ yóò sì ṣíji bò ọ́. Nítorí ìdí èyí pẹ̀lú, ohun tí a bí ni a ó pè ní mímọ́, Ọmọ Ọlọ́run.’ (Lk 1:35) Jèhófà fi ìṣọ́ ṣọ́ Ọmọ rẹ̀. Gbogbo ìsapá láti rẹ́yìn Jésù ní rèwerèwe sì já sí pàbó.”—Ìwé Insight on the Scriptures, Apá Kejì, ojú ewé ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀rin ó lé mẹ́jọ [868], tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 139]
Mèsáyà dà bí “ọfà dídán” tó wà nínú apó Jèhófà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 141]
Mèsáyà jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 147]
Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí àwọn èèyàn rẹ̀ ju ìfẹ́ ìyá sí ọmọ lọ