Àìsáyà
7 Láyé ìgbà Áhásì+ ọmọ Jótámù ọmọ Ùsáyà, ọba Júdà, Résínì ọba Síríà àti Pékà+ ọmọ Remaláyà, ọba Ísírẹ́lì wá gbógun ja Jerúsálẹ́mù, àmọ́ kò* ṣẹ́gun rẹ̀.+ 2 Ìròyìn dé ilé Dáfídì pé: “Síríà ti lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ Éfúrémù.”
Jìnnìjìnnì bá ọkàn Áhásì àti ti àwọn èèyàn rẹ̀, wọ́n ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ bí àwọn igi inú igbó tí atẹ́gùn ń fẹ́ lù.
3 Jèhófà wá sọ fún Àìsáyà pé: “Jọ̀ọ́, jáde lọ pàdé Áhásì, ìwọ àti Ṣeari-jáṣúbù* ọmọ rẹ,+ ní ìpẹ̀kun ibi tí adágún omi tó wà lápá òkè ń gbà,+ níbi ọ̀nà tó lọ sí pápá alágbàfọ̀. 4 Kí o sọ fún un pé, ‘Rí i pé o fi ara rẹ lọ́kàn balẹ̀. Má bẹ̀rù, má sì jẹ́ kí ọkàn rẹ domi torí àwọn ìtì igi méjì tó ń rú èéfín yìí, torí ìbínú Résínì àti Síríà àti ọmọ Remaláyà tó ń ru gùdù.+ 5 Torí Síríà pẹ̀lú Éfúrémù àti ọmọ Remaláyà ti gbìmọ̀ ìkà sí ọ, wọ́n ń sọ pé: 6 “Ẹ jẹ́ ká lọ gbógun ja Júdà, ká fà á ya,* ká ṣẹ́gun rẹ̀* ká gbà á, ká sì fi ọmọ Tábéélì jẹ ọba ibẹ̀.”+
7 “‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
“Kò ní ṣàṣeyọrí,
Kò sì ní ṣẹlẹ̀.
8 Torí Damásíkù ni orí Síríà,
Résínì sì ni orí Damásíkù.
Kí ọdún márùndínláàádọ́rin (65) tó pé,
Éfúrémù máa fọ́ túútúú, wọn ò sì ní jẹ́ èèyàn mọ́.+
Tí ìgbàgbọ́ yín ò bá lágbára,
Ẹ ò ní lè fìdí múlẹ̀.”’”
10 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Áhásì lọ pé: 11 “Ní kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fún ọ ní àmì kan;+ ó lè jìn bí Isà Òkú,* ó sì lè ga bí ọ̀run.” 12 Àmọ́ Áhásì sọ pé: “Mi ò ní béèrè, mi ò sì ní dán Jèhófà wò.”
13 Àìsáyà wá sọ pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ fetí sílẹ̀, ilé Dáfídì. Ṣé bí ẹ ṣe tán àwọn èèyàn ní sùúrù ò tó yín ni? Ṣé ẹ tún fẹ́ tán Ọlọ́run ní sùúrù ni?+ 14 Torí náà, Jèhófà fúnra rẹ̀ máa fún yín ní àmì kan: Wò ó! Ọ̀dọ́bìnrin náà* máa lóyún, ó sì máa bí ọmọkùnrin kan,+ ó máa pe orúkọ rẹ̀ ní Ìmánúẹ́lì.*+ 15 Bọ́tà àti oyin ni á máa jẹ nígbà tó bá fi máa mọ béèyàn ṣe ń kọ ohun búburú, kó sì yan rere. 16 Torí kí ọmọkùnrin náà tó mọ béèyàn ṣe ń kọ ohun búburú, tí á sì yan rere, ilẹ̀ àwọn ọba méjèèjì tí ò ń bẹ̀rù ni wọ́n máa pa tì pátápátá.+ 17 Jèhófà máa mú kí ìgbà kan dé bá ìwọ àtàwọn èèyàn rẹ àti ilé bàbá rẹ, èyí tí kò sí irú rẹ̀ rí láti ọjọ́ tí Éfúrémù ti yapa kúrò lára Júdà,+ torí Ó máa mú ọba Ásíríà wá.+
18 “Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà máa súfèé sí àwọn eṣinṣin láti odò Náílì ti ilẹ̀ Íjíbítì lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún àti sí àwọn oyin ilẹ̀ Ásíríà, 19 gbogbo wọn sì máa wá bà lé àwọn àfonífojì tó dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́, àwọn pàlàpálá àpáta, gbogbo igi ẹlẹ́gùn-ún àti sórí gbogbo ibi tó lómi.
20 “Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà máa lo abẹ tí wọ́n yá láti agbègbè Odò,* ó máa lo ọba Ásíríà,+ láti fá orí àti irun ẹsẹ̀, ó sì máa fá irùngbọ̀n kúrò pẹ̀lú.
21 “Ní ọjọ́ yẹn, ẹnì kan máa dá ẹ̀mí ọmọ màlúù kan sí látinú ọ̀wọ́ ẹran àti àgùntàn méjì. 22 Torí pé wàrà pọ̀ gan-an, ó máa jẹ bọ́tà; torí gbogbo èèyàn yòókù nílẹ̀ náà máa jẹ bọ́tà àti oyin.
23 “Ní ọjọ́ yẹn, ibikíbi tí ẹgbẹ̀rún (1,000) àjàrà bá wà tẹ́lẹ̀, tí iye rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún (1,000) ẹyọ fàdákà, àwọn igi ẹlẹ́gùn-ún àti èpò nìkan ló máa wà níbẹ̀. 24 Àwọn èèyàn máa mú ọrun àti ọfà lọ síbẹ̀, torí pé igi ẹlẹ́gùn-ún àti èpò ló máa wà ní gbogbo ilẹ̀ náà. 25 Ẹ ò ní lè sún mọ́ gbogbo òkè tí wọ́n ń fi ọkọ́ ro tẹ́lẹ̀, torí pé ẹ ó máa bẹ̀rù àwọn igi ẹlẹ́gùn-ún àti èpò; wọ́n máa di ibi tí àwọn akọ màlúù á ti máa jẹko àti ibi tí àwọn àgùntàn á máa tẹ̀ mọ́lẹ̀.”