Àìsáyà
Jèhófà ti pè mí kí wọ́n tó bí mi.*+
Ó ti dárúkọ mi látìgbà tí mo ti wà nínú ikùn ìyá mi.
Ó ṣe mí ní ọfà tó ń dán;
Ó fi mí pa mọ́ sínú apó rẹ̀.
4 Àmọ́ mo sọ pé: “Lásán ni mo ṣe wàhálà.
Lásán ni mo lo okun mi tán lórí ohun tí kò sí rárá.
5 Ní báyìí, Jèhófà, Ẹni tó ṣe mí ní ìránṣẹ́ rẹ̀ látinú oyún,
Ti sọ pé kí n mú Jékọ́bù pa dà wá sọ́dọ̀ òun,
Kí a lè kó Ísírẹ́lì jọ sọ́dọ̀ rẹ̀.+
A máa ṣe mí lógo lójú Jèhófà,
Ọlọ́run mi á sì ti di okun mi.
6 Ó sọ pé: “Ti pé o jẹ́ ìránṣẹ́ mi nìkan ò tó,
Láti gbé àwọn ẹ̀yà Jékọ́bù dìde,
Kí o sì mú àwọn tí a dá sí lára Ísírẹ́lì pa dà.
7 Ohun tí Jèhófà, Olùtúnrà Ísírẹ́lì, Ẹni Mímọ́+ rẹ̀ sọ nìyí, fún ẹni tí wọ́n kórìíra,*+ ẹni tí orílẹ̀-èdè náà kórìíra, fún ìránṣẹ́ àwọn alákòóso:
“Àwọn ọba máa rí i, wọ́n sì máa dìde,
Àwọn ìjòyè máa tẹrí ba,
Nítorí Jèhófà, ẹni tó jẹ́ olóòótọ́,+
Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì, ẹni tó yàn ọ́.”+
8 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Mo dá ọ lóhùn ní àkókò ojúure,*+
Mo sì ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ọjọ́ ìgbàlà;+
Mò ń ṣọ́ ọ kí n lè fi ọ́ ṣe májẹ̀mú fún àwọn èèyàn náà,+
Láti tún ilẹ̀ náà ṣe,
Láti mú kí wọ́n gba àwọn ohun ìní wọn tó ti di ahoro,+
Àti fún àwọn tó wà nínú òkùnkùn+ pé, ‘Ẹ fara hàn!’
Etí ọ̀nà ni wọ́n ti máa jẹun,
Ojú gbogbo ọ̀nà tó ti bà jẹ́* ni wọ́n ti máa jẹko.
11 Màá sọ gbogbo òkè mi di ọ̀nà,
Àwọn ojú ọ̀nà mi sì máa ga sókè.+
12 Wò ó! Àwọn yìí ń bọ̀ láti ọ̀nà jíjìn,+
Sì wò ó! àwọn yìí ń bọ̀ láti àríwá àti ìwọ̀ oòrùn
Àti àwọn yìí láti ilẹ̀ Sínímù.”+
13 Ẹ kígbe ayọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, sì máa yọ̀, ìwọ ayé.+
Kí inú àwọn òkè dùn, kí wọ́n sì kígbe ayọ̀.+
14 Àmọ́ Síónì ń sọ ṣáá pé:
“Jèhófà ti pa mí tì,+ Jèhófà sì ti gbàgbé mi.”+
15 Ṣé obìnrin lè gbàgbé ọmọ rẹ̀ tó ṣì ń mu ọmú
Tàbí kó má ṣàánú ọmọ tó lóyún rẹ̀?
Tí àwọn obìnrin yìí bá tiẹ̀ gbàgbé, mi ò jẹ́ gbàgbé rẹ láé.+
16 Wò ó! Àtẹ́lẹwọ́ mi ni mo fín ọ sí.
Iwájú mi ni àwọn ògiri rẹ máa ń wà.
17 Àwọn ọmọ rẹ pa dà kíákíá.
Àwọn tó ya ọ́ lulẹ̀, tí wọ́n sì sọ ọ́ di ahoro máa kúrò lọ́dọ̀ rẹ.
18 Gbé ojú rẹ sókè, kí o sì wò yí ká.
Gbogbo wọn ń kóra jọ.+
Wọ́n ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ.
“Bó ṣe dájú pé mo wà láàyè,” ni Jèhófà wí,
“O máa wọ gbogbo wọn bí ẹni wọ ohun ọ̀ṣọ́,
O sì máa dè wọ́n mọ́ra bíi ti ìyàwó.
19 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ilé rẹ ti pa run, ó ti di ahoro, ilẹ̀ rẹ sì ti di àwókù,+
Ó máa wá há jù fún àwọn tó ń gbé ibẹ̀,+
20 Àwọn ọmọ tí wọ́n bí nígbà tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ ọ́ máa sọ ní etí rẹ pé,
‘Ibí yìí ti há jù fún mi.
Wá àyè fún mi, kí n lè máa gbé ibí.’+
21 O sì máa sọ lọ́kàn rẹ pé,
‘Ta ni bàbá àwọn ọmọ mi yìí,
Ṣebí obìnrin tó ti ṣòfò ọmọ ni mí, tí mo sì yàgàn,
Tí mo lọ sí ìgbèkùn, tí wọ́n sì mú mi ní ẹlẹ́wọ̀n?
Ta ló tọ́ àwọn ọmọ yìí?+
22 Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
Wọ́n máa tẹrí ba fún ọ, wọ́n á sì dojú bolẹ̀,+
Wọ́n máa lá iyẹ̀pẹ̀ ẹsẹ̀ rẹ,+
Wàá sì mọ̀ pé èmi ni Jèhófà;
Ojú ò ní ti àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé mi.”+
24 Ṣé a lè gba àwọn tí alágbára ọkùnrin ti mú kúrò lọ́wọ́ rẹ̀,
Àbí ṣé a lè gba àwọn tí ìkà mú lẹ́rú sílẹ̀?
25 Àmọ́ ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Kódà, a máa gba àwọn tí alágbára ọkùnrin mú lẹ́rú kúrò lọ́wọ́ rẹ̀,+
A sì máa gba àwọn tí ìkà mú sílẹ̀.+
Màá ta ko àwọn alátakò rẹ,+
Màá sì gba àwọn ọmọ rẹ là.
26 Màá mú kí àwọn tó ń fìyà jẹ ọ́ jẹ ẹran ara tiwọn,
Wọ́n sì máa mu ẹ̀jẹ̀ ara wọn yó bí ẹni mu wáìnì tó dùn.