Ayọ̀ Yíyọ̀ Fáwọn Tí Ń Rìn Nínú Ìmọ́lẹ̀
“Ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Jèhófà.”—AÍSÁYÀ 2:5.
1, 2. (a) Báwo ni ìmọ́lẹ̀ ti ṣe pàtàkì tó? (b) Èé ṣe tí ìkìlọ̀ náà pé òkùnkùn yóò bo ilẹ̀ ayé fi ṣe pàtàkì gan-an?
JÈHÓFÀ ni Orísun ìmọ́lẹ̀. Bíbélì pè é ní “Olùfúnni ní oòrùn fún ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán, àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ fún ìmọ́lẹ̀ ní òru.” (Jeremáyà 31:35; Sáàmù 8:3) Òun ló dá oòrùn wa, tí a lè pè ní ìléru ńlá alágbára átọ́míìkì, èyí tó ń tú àgbáàràgbá iná jáde, lára ohun tó ń tú jáde yìí sì máa ń wá gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ àti ooru. Díẹ̀ kíún yẹn, tó ń ràn dé ọ̀dọ̀ wa gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ oòrùn ló ń gbé ìwàláàyè ró lórí ilẹ̀ ayé níhìn-ín. Bí ìmọ́lẹ̀ oòrùn kò bá sí, a ò lè wà láàyè. Ńṣe ni ilẹ̀ ayé máa dá páropáro láìsí ohun alààyè.
2 Pẹ̀lú ìyẹn lọ́kàn, a lè lóye bí ipò kan tí wòlíì Aísáyà ṣàpèjúwe ti wúwo tó. Ó sọ pé: “Wò ó! òkùnkùn pàápàá yóò bo ilẹ̀ ayé, ìṣúdùdù nínípọn yóò sì bo àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè.” (Aísáyà 60:2) Ó dájú pé òkùnkùn tí ibí yìí ń sọ kì í ṣe òkùnkùn táa lè fojú rí. Ọ̀rọ̀ Aísáyà kò túmọ̀ sí pé tó bá dọjọ́ kan oòrùn, òṣùpá, àtàwọn ìràwọ̀ kò ní yọ mọ́. (Sáàmù 89:36, 37; 136:7-9) Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ òkùnkùn tẹ̀mí ló ń sọ. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, òkùnkùn tẹ̀mí ń ṣekú pani. Bó pẹ́ bó yá, a ò ní lè wà láàyè láìsí ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí, gan-an gẹ́gẹ́ bí a kò ti lè wà láàyè láìsí ìmọ́lẹ̀ gidi.—Lúùkù 1:79.
3. Lójú ọ̀rọ̀ tí Aísáyà sọ, kí ló yẹ káwọn Kristẹni máa ṣe?
3 Lójú ohun táa ń sọ bọ̀ yìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ Aísáyà ṣẹ sí Júdà ìgbàanì lára, kò sí bí ọkàn ṣe lè balẹ̀ téèyàn bá gbọ́ pé ọjọ́ òní lọ̀rọ̀ Aísáyà ń ní ìmúṣẹ títóbi jù lọ. Bẹ́ẹ̀ ni o, lákòókò táa wà yìí, ńṣe ni òkùnkùn tẹ̀mí ṣú bo ayé. Nínú ipò eléwu yìí, kòṣeémánìí ni ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ káwọn Kristẹni kọbi ara sí ọ̀rọ̀ ìyànjú Jésù pé: “Kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn.” (Mátíù 5:16) Àwọn Kristẹni olùṣòtítọ́ lè tànmọ́lẹ̀ síbi tó ṣókùnkùn fáwọn ọlọ́kàn tútù, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ fún wọn láǹfààní láti jèrè ìyè.—Jòhánù 8:12.
Àkókò Òkùnkùn ní Ísírẹ́lì
4. Ìgbà wo ni ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà kọ́kọ́ nímùúṣẹ, ṣùgbọ́n ipò wo ló ti gbilẹ̀ nígbà ayé tirẹ̀?
4 Ọ̀rọ̀ tí Aísáyà sọ, pé òkùnkùn yóò ṣú bo ilẹ̀ ayé, kọ́kọ́ nímùúṣẹ nígbà tí Júdà dahoro, táwọn èèyàn rẹ̀ sì lọ sígbèkùn ní Bábílónì. Àmọ́, kó tó dìgbà yẹn pàápàá, nígbà ayé Aísáyà alára, apá tó pọ̀ jù lọ lára orílẹ̀-èdè náà ló ti wà nínú òkùnkùn biribiri nípa tẹ̀mí. Abájọ tó fi rọ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ará ilé Jékọ́bù, ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Jèhófà”!—Aísáyà 2:5; 5:20.
5, 6. Kí làwọn nǹkan tó dá kún òkùnkùn tó ṣú nígbà ayé Aísáyà?
5 Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ ní Júdà “ní àwọn ọjọ́ Ùsáyà, Jótámù, Áhásì àti Hesekáyà, àwọn ọba Júdà.” (Aísáyà 1:1) Nǹkan ò rọgbọ lásìkò yẹn nítorí rògbòdìyàn ìṣèlú, àgàbàgebè ẹ̀sìn, yíyí ìdájọ́ po, àti níni àwọn tálákà lára. Kódà nígbà àkóso àwọn olóòótọ́ ọba, bíi Jótámù, àwọn pẹpẹ òrìṣà wà káàkiri orí ọ̀pọ̀lọpọ̀ òkè. Ó wá lékenkà lábẹ́ àwọn ọba aláìṣòótọ́. Fún àpẹẹrẹ, Áhásì Ọba burúkú, tilẹ̀ bá tirẹ̀ débi pé ó lọ fi ọmọ tirẹ̀ alára rúbọ sí òrìṣà Mólékì. Òkùnkùn biribiri gbáà nìyẹn o!—2 Àwọn Ọba 15:32-34; 16:2-4.
6 Nǹkan ò fara rọ láàárín Júdà àtàwọn orílẹ̀-èdè yòókù pẹ̀lú. Móábù, Édómù, àti Filísíà tó bá Júdà pààlà fẹ́ han Júdà léèmọ̀. Àní ìjọba Ísírẹ́lì níhà àríwá tó bá Júdà tan pàápàá, ti di ọ̀tá rẹ̀ paraku. Síríà tó wà lókè lọ́hùn-ún níhà àríwá ń dún mọ̀huru-mọ̀huru mọ́ Júdà. Ásíríà òṣìkà, tó ń fagbára gba ìpínlẹ̀ kún ìpínlẹ̀, ló tilẹ̀ jẹ́ ewu tó ga jù. Láàárín ìgbà tí Aísáyà ń sọ àsọtẹ́lẹ̀, Ásíríà ṣẹ́gun orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ run Júdà tán. Lásìkò kan, gbogbo ìlú olódi Júdà pátá ni Ásíríà ṣẹ́gun, àfi Jerúsálẹ́mù nìkan.—Aísáyà 1:7, 8; 36:1.
7. Ipa ọ̀nà wo ni Ísírẹ́lì àti Júdà yàn, ìhà wo ni Jèhófà sì kọ sí wọn?
7 Àjálù wọ̀nyí bá àwọn èèyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú nítorí ìwà àìdúróṣinṣin tí Ísírẹ́lì àti Júdà hù sí i. Bíi ti àwọn táa mẹ́nu kàn nínú ìwé Òwe, ṣe ni wọ́n “fi àwọn ipa ọ̀nà ìdúróṣánṣán sílẹ̀ láti rìn ní àwọn ọ̀nà òkùnkùn.” (Òwe 2:13) Ṣùgbọ́n o, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà bínú sáwọn èèyàn rẹ̀, kò pa wọ́n tì pátápátá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló gbé Aísáyà àtàwọn wòlíì mìíràn dìde, kí wọ́n lè pèsè ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí fún ẹnikẹ́ni tó ṣì ń wá ọ̀nà láti fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà lórílẹ̀-èdè yẹn. Ìmọ́lẹ̀ tó tàn nípasẹ̀ àwọn wòlíì wọ̀nyẹn mà kúkú ṣeyebíye o. Ìmọ́lẹ̀ tó ń fúnni níyè ni.
Àkókò Òkùnkùn Lóde Òní
8, 9. Kí ni àwọn nǹkan tó dá kún òkùnkùn tó ṣú bo ayé lónìí?
8 Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lóde òní jọ ti ìgbà ayé Aísáyà gan-an ni. Ní ìgbà tiwa yìí, àwọn aṣáájú tó jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn ti kẹ̀yìn sí Jèhófà àti Jésù Kristi, Ọba rẹ̀ tí ń jọba. (Sáàmù 2:2, 3) Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Kirisẹ́ńdọ̀mù ń tan àwọn ọmọ ìjọ wọn jẹ. Irú àwọn aṣáájú bẹ́ẹ̀ sọ pé Ọlọ́run làwọn ń sìn, ṣùgbọ́n lóòótọ́, àwọn ọlọ́run ayé yìí ni èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wọn ń gbé lárugẹ—ìyẹn, àwọn ọlọ́run bí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni, ìgbélékè ẹ̀mí ogun, ọrọ̀, àtàwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn—ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti àwọn ẹ̀kọ́ kèfèrí tí wọ́n fi ń kọ́ni.
9 Àwọn ẹ̀sìn Kirisẹ́ńdọ̀mù ń lọ́wọ́ sí ogun àti rògbòdìyàn tó kún fún ìwà ìkà àti ìpẹ̀yàrun tí ń jà ràn-ìn lọ́tùn-ún lósì. Síwájú sí i, dípò kí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì rọ̀ mọ́ ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwà rere tí Bíbélì fi kọ́ni, ńṣe ni ọ̀pọ̀ nínú wọn ń gbọ̀jẹ̀gẹ́ fún àwọn ìwà pálapàla bí àgbèrè àti ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀, tàbí tí wọ́n tilẹ̀ ń ṣalágbàwí wọn. Nítorí pé Kirisẹ́ńdọ̀mù kẹ̀yìn sí ọ̀pá ìdiwọ̀n Bíbélì, àwọn ọmọ ìjọ wọn dà bí àwọn tí onísáàmù ìgbàanì sọ̀rọ̀ nípa wọn, pé: “Wọn kò mọ̀, wọn kò sì lóye; inú òkùnkùn ni wọ́n ti ń rìn káàkiri.” (Sáàmù 82:5) Ká sòótọ́, inú òkùnkùn biribiri ni Kirisẹ́ńdọ̀mù wà, bíi ti Júdà ayé ọjọ́un.—Ìṣípayá 8:12.
10. Báwo ni ìmọ́lẹ̀ ṣe ń tàn nínú òkùnkùn lónìí, báwo sì ni àwọn ọlọ́kàn tútù ṣe ń jàǹfààní nínú rẹ̀?
10 Nínú gbogbo òkùnkùn yìí, Jèhófà ń jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ tàn nítorí àwọn ọlọ́kàn tútù. Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ẹni àmì òróró lórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” ni ó ń lò láti ṣe èyí, àwọn wọ̀nyí sì “ń tàn bí atànmọ́lẹ̀ nínú ayé.” (Mátíù 24:45; Fílípì 2:15) Ẹgbẹ́ ẹrú yẹn, tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ “àwọn àgùntàn mìíràn” tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn ń tì lẹ́yìn, ló wá ń gbé ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí yọ, èyí tó ń tinú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wá. (Jòhánù 10:16) Nínú ayé tó ṣókùnkùn biribiri yìí, irú ìmọ́lẹ̀ yẹn ń fún àwọn ọlọ́kàn tútù ní ìrètí, ó ń jẹ́ kí wọ́n ní àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run, ó sì ń jẹ́ kí wọ́n yẹra fún àwọn ọ̀fìn tẹ̀mí. Ìmọ́lẹ̀ tó ṣeyebíye, tí ń fúnni ní ìyè ni.
“Mo Gbé Orúkọ Rẹ Lárugẹ”
11. Ìsọfúnni wo ni Jèhófà gbé jáde ní ọjọ́ Aísáyà?
11 Ní àwọn ọjọ́ ṣíṣókùnkùn tí Aísáyà gbé, àti ní àwọn ọjọ́ tó tilẹ̀ tún ṣókùnkùn jù bẹ́ẹ̀ lọ lẹ́yìn náà, nígbà táwọn ará Bábílónì kó orílẹ̀-èdè Jèhófà lọ sígbèkùn, irú ìtọ́sọ́nà wo ni Jèhófà pèsè? Yàtọ̀ sí pé ó pèsè ìtọ́sọ́nà ní ti ìwà rere, tipẹ́tipẹ́ ló ti tò ó lẹ́sẹẹsẹ bí òun yóò ṣe mú àwọn ète òun fáwọn èèyàn òun ṣẹ. Fún àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká gbé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àgbàyanu tó wà nínú Aísáyà orí 25 sí 27 yẹ̀ wò. Àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú orí wọ̀nyí jẹ́ ká rí i bí Jèhófà ṣe yanjú àwọn nǹkan nígbà yẹn, àti bó ṣe ń yanjú nǹkan lóde òní.
12. Ọ̀rọ̀ àtọkànwá wo ni Aísáyà sọ?
12 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Aísáyà kéde pé: “Jèhófà, ìwọ ni Ọlọ́run mi. Mo gbé ọ ga, mo gbé orúkọ rẹ lárugẹ.” Áà, ìyìn àtọkànwá yìí bùáyà o! Àmọ́ kí ló mú kí wòlíì yìí gba irú àdúrà bẹ́ẹ̀? Ìyókù ẹsẹ yẹn sọ ìdí pàtàkì kan, a rí i kà níbẹ̀ pé: “Nítorí pé o [ìyẹn, Jèhófà] ti ṣe àwọn ohun àgbàyanu, àwọn ìpinnu láti àwọn àkókò ìjímìjí, nínú ìṣòtítọ́, nínú ìṣeégbẹ́kẹ̀lé.”—Aísáyà 25:1.
13. (a) Ìmọ̀ wo ló jẹ́ kí Aísáyà túbọ̀ mọyì Jèhófà? (b) Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ Aísáyà?
13 Nígbà ayé Aísáyà, Jèhófà ti ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan àgbàyanu fún Ísírẹ́lì, gbogbo nǹkan wọ̀nyí sì ti wà lákọọ́lẹ̀. Ó dájú pé Aísáyà mọ ohun tó wà nínú àkọọ́lẹ̀ wọ̀nyẹn dunjú. Bí àpẹẹrẹ, ó mọ̀ pé Jèhófà mú àwọn èèyàn rẹ̀ jáde kúrò lóko ẹrú Íjíbítì, ó sì gbà wọ́n lọ́wọ́ ìrunú ẹgbẹ́ ọmọ ogun Fáráò ní Òkun Pupa. Ó mọ̀ pé Jèhófà mú àwọn èèyàn rẹ̀ la aginjù kọjá, ó sì mú wọn wá sí Ilẹ̀ Ìlérí. (Sáàmù 136:1, 10-26) Irú ìtàn wọ̀nyẹn tó wà lákọsílẹ̀ fi hàn pé olóòótọ́ àti ẹni tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé ni Jèhófà Ọlọ́run. “Àwọn ìpinnu” rẹ̀, ìyẹn gbogbo ohun tó pète, ló ṣẹ. Níní tí Aísáyà ní ìmọ̀ pípéye látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló fún un lókun láti máa rìn nìṣó nínú ìmọ́lẹ̀. Nípa báyìí, àpẹẹrẹ àtàtà ló jẹ́ fún wa. Bí a bá fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ àkọsílẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, táa sì ń mú un lò nínú ìgbésí ayé wa, àwa náà yóò máa rìn nìṣó nínú ìmọ́lẹ̀.—Sáàmù 119:105; 2 Kọ́ríńtì 4:6.
Ìlú Ńlá Kan Pa Run
14. Àsọtẹ́lẹ̀ wo la sọ nípa ìlú ńlá kan, ìlú ńlá wo sì ni ó ṣeé ṣe kó jẹ́?
14 A rí àpẹẹrẹ ìpinnu Ọlọ́run nínú Aísáyà 25:2, ó kà níbẹ̀ pé: “Ìwọ ti sọ ìlú ńlá kan di ìtòjọpelemọ òkúta, o ti sọ ìlú olódi di ìrúnwómúwómú, o ti sọ ilé gogoro ibùgbé àwọn àjèjì di èyí tí kì í ṣe ìlú ńlá mọ́, tí a kì yóò tún kọ́, àní fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Ìlú ńlá wo nìyẹn? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Bábílónì ni Aísáyà ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀. Ìgbà yẹn sì dé lóòótọ́, tí Bábílónì di kìkì ìtòjọpelemọ òkúta.
15. “Ìlú ńlá títóbi” wo ló wà lónìí, kí ni yóò sì ṣẹlẹ̀ sí i?
15 Ǹjẹ́ ìlú ńlá tí Aísáyà mẹ́nu kàn yìí ní alábàádọ́gba lóde òní? Bẹ́ẹ̀ ni o. Ìwé Ìṣípayá sọ̀rọ̀ nípa “ìlú ńlá títóbi tí ó ní ìjọba kan lórí àwọn ọba ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 17:18) “Bábílónì Ńlá,” ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé ni ìlú ńlá yẹn. (Ìṣípayá 17:5) Lónìí, Kirisẹ́ńdọ̀mù ni apá pàtàkì nínú Bábílónì Ńlá. Àwọn àlùfáà Kirisẹ́ńdọ̀mù yìí ló sì ń mú ipò iwájú nínú títako iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà tí àwọn èèyàn Jèhófà ń ṣe. (Mátíù 24:14) Àmọ́ o, bíi ti Bábílónì àtijọ́ lọ̀rọ̀ ti Bábílónì Ńlá yìí ṣe máa rí, yóò pa run láìpẹ́, kò sì ní gbérí mọ́ láé.
16, 17. Báwo làwọn ọ̀tá Jèhófà ṣe yìn ín lógo ní ayé ìgbàanì àti lóde òní?
16 Kí ni nǹkan míì tí Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa “ìlú olódi” náà? Aísáyà ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀, ó ní: “Àwọn alágbára ènìyàn yóò . . . yìn ọ́ lógo; ìlú àwọn orílẹ̀-èdè afìkà-gboni-mọ́lẹ̀, wọn yóò bẹ̀rù rẹ.” (Aísáyà 25:3) Báwo ni ìlú ọ̀tá yìí, “ìlú àwọn orílẹ̀-èdè afìkà-gboni-mọ́lẹ̀,” yóò ṣe wá yin Jèhófà lógo? Tóò, rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Nebukadinésárì, ọba tó lágbára jù lọ ní Bábílónì. Lẹ́yìn tí gbogbo gàlègàlè rẹ̀ rọlẹ̀ nítorí ohun tójú rẹ̀ rí, ó gbà tipátipá pé Jèhófà tóbi lọ́ba àti pé Òun ni alágbára gbogbo. (Dáníẹ́lì 4:34, 35) Nígbà tí Jèhófà bá lo agbára rẹ̀, àwọn ọ̀tá rẹ̀ pàápàá á gbà tipátipá, bí wọ́n fẹ́ bí wọ́n kọ̀, pé oníṣẹ́ àrà ni lóòótọ́.
17 Ǹjẹ́ Bábílónì Ńlá tiẹ̀ fìgbà kan gbà tipátipá pé oníṣẹ́ àrà ni Jèhófà? Bẹ́ẹ̀ ni, ó gbà. Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, àwọn ẹni àmì òróró ìránṣẹ́ Jèhófà wàásù lábẹ́ inúnibíni. Ní 1918, wọ́n dèrò ìgbèkùn tẹ̀mí nígbà tí wọ́n sọ àwọn òléwájú òṣìṣẹ́ Watch Tower Society sẹ́wọ̀n. Iṣẹ́ ìwàásù tí a fètò sí fẹ́rẹ̀ẹ́ dáwọ́ dúró. Nígbà tó wá di ọdún 1919, Jèhófà mú wọn padà, ó sì fún wọn lókun nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀, kété lẹ́yìn èyí ni wọ́n gbéra láti ṣe iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà láṣeparí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé. (Máàkù 13:10) Gbogbo èyí àti ipa tó máa ní lórí àwọn ọ̀tá wọn ni a sọ tẹ́lẹ̀ nínú ìwé Ìṣípayá. Àwọn ọ̀tá wá di àwọn tí ‘jìnnìjìnnì bò, wọ́n sì fi ògo fún Ọlọ́run ọ̀run.’ (Ìṣípayá 11:3, 7, 11-13) Kì í ṣe pé gbogbo wọn yí padà, ṣùgbọ́n wọ́n gbà tipátipá pé oníṣẹ́ àrà ni Jèhófà nínú ọ̀ràn yìí, gẹ́gẹ́ bí Aísáyà ti sọ tẹ́lẹ̀.
“Ibi Odi Agbára fún Ẹni Rírẹlẹ̀”
18, 19. (a) Èé ṣe táwọn alátakò kò fi lè ba ìwà títọ́ àwọn èèyàn Jèhófà jẹ́? (b) Báwo ni “orin atunilára àwọn afìkà-gboni-mọ́lẹ̀” yóò ṣe di ohun tí a tẹ̀ rì?
18 Wàyí o, Aísáyà wá pe àfiyèsí sí ojú àánú tí Jèhófà fi ń bá àwọn tí ń rìn nínú ìmọ́lẹ̀ lò. Ó wí fún Jèhófà pé: “Ìwọ ti di ibi odi agbára fún ẹni rírẹlẹ̀, ibi odi agbára fún òtòṣì nínú wàhálà tí ó dé bá a, ibi ìsádi kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò, ibòji kúrò lọ́wọ́ ooru, nígbà tí ẹ̀fúùfù òjijì àwọn afìkà-gboni-mọ́lẹ̀ dà bí ìjì òjò lára ògiri. Bí ooru ní ilẹ̀ aláìlómi, ariwo àwọn àjèjì ni ìwọ mú rọlẹ̀, ooru pẹ̀lú òjìji àwọsánmà. Àní orin atunilára àwọn afìkà-gboni-mọ́lẹ̀ di ohun tí a tẹ̀ rì.”—Aísáyà 25:4, 5.
19 Látọdún 1919 ni àwọn afìkà-gboni-mọ́lẹ̀ ti ń sa gbogbo ipá tí wọ́n lè sà láti ba ìwà títọ́ àwọn olùjọsìn tòótọ́ jẹ́, àmọ́ pàbó ni gbogbo akitiyan wọn já sí. Èé ṣe? Nítorí pé Jèhófà ni odi agbára àti ibi ìsádi fáwọn èèyàn rẹ̀. Ó pèsè ibòji tó tutù pẹ̀sẹ̀ fún wọn kúrò lọ́wọ́ ooru inúnibíni tó gbóná janjan, ó sì dúró bí odi alágbára tó ń dènà ìjì òjò àtakò. Àwa tí ń rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run ń fi ìdánilójú retí àkókò tí ‘orin atunilára àwọn afìkà-gboni-mọ́lẹ̀ yóò di ohun tí a tẹ̀ rì.’ Bẹ́ẹ̀ ni o, ńṣe là ń hára gàgà pé kí ọjọ́ náà dé, tí àwọn ọ̀tá Jèhófà yóò lọ tèfètèfè.
20, 21. Àkànṣe àsè wo ni Jèhófà sè, kí sì ni yóò wà lára àkànṣe àsè náà nínú ayé tuntun?
20 Ohun tí Jèhófà ń ṣe kò mọ sórí dídáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Ó tún ń pèsè fún wọn gẹ́gẹ́ bíi Baba tó fẹ́ràn wọn. Lẹ́yìn tó dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè kúrò nínú Bábílónì Ńlá ní 1919, ó gbé àsè ìṣẹ́gun kalẹ̀ fún wọn, ìyẹn ìpèsè oúnjẹ tẹ̀mí lọ́pọ̀ yanturu. Aísáyà 25:6 sọ èyí tẹ́lẹ̀, ó kà báyìí pé: “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò sì se àkànṣe àsè tí ó jẹ́ oúnjẹ tí a fi òróró dùn fún gbogbo àwọn ènìyàn ní òkè ńlá yìí, àkànṣe àsè wáìnì tí ń bẹ lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀, ti àwọn oúnjẹ tí a fi òróró dùn, èyí tí ó kún fún mùdùnmúdùn, ti wáìnì sísẹ́, èyí tí ń bẹ lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀.” A mà dúpẹ́ o, pé à ń jẹ nínú àsè yìí! (Mátíù 4:4) Lóòótọ́ ni orí “tábìlì Jèhófà” kún fún oúnjẹ àtàtà. (1 Kọ́ríńtì 10:21) A ń fún wa ní gbogbo ohun táa nílò nípa tẹ̀mí nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” náà.
21 Ohun púpọ̀ ló sì rọ̀ mọ́ àsè tẹ̀mí tí Ọlọ́run sè yìí. Ṣe ni àsè tẹ̀mí táa ń gbádùn báyìí ń rán wa létí pé oúnjẹ ti ara yóò wà lọ́pọ̀ yanturu nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí. Nígbà yẹn, ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tara yóò wà lára “àkànṣe àsè tí ó jẹ́ oúnjẹ tí a fi òróró dùn” náà. Ebi kò ní pa ẹnikẹ́ni nípa tara tàbí nípa tẹ̀mí mọ́. Ìtura gbáà mà ni yóò jẹ́ o, fáwọn olùṣòtítọ́ ọ̀wọ́n, tó ń jìyà nísinsìnyí lọ́wọ́ “àìtó oúnjẹ” táa sọ tẹ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ara “àmì” wíwàníhìn-ín Jésù! (Mátíù 24:3, 7) Ìtùnú gidi lọ̀rọ̀ onísáàmù náà yóò jẹ́ fún wọn. Ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.”—Sáàmù 72:16.
22, 23. (a) “Iṣẹ́ híhun,” tàbí “ìràgàbò” wo ni a óò mú kúrò, báwo sì ni a ó ṣe mú un kúrò? (b) Báwo la ó ṣe mú ‘ẹ̀gàn àwọn ènìyàn Jèhófà’ kúrò?
22 Wàyí o, ẹ tún gbọ́ ìlérí tó túbọ̀ jẹ́ ìyanu. Aísáyà fi ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú wé “ohun híhun,” tàbí “ìràgàbò,” ó sọ pé: “Ní òkè ńlá yìí, dájúdájú, [Jèhófà] yóò gbé ojú ìràgàbò náà mì, èyí tí ó ràgà bo gbogbo ènìyàn, àti ohun híhun tí a hun pọ̀ sórí gbogbo orílẹ̀-èdè.” (Aísáyà 25:7) Ẹ rò ó wò ná! Ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, tó ti bo aráyé mọ́lẹ̀ bíi kúbùsù aséniléèémí, kò ní sí mọ́. Áà, ọjọ́ lọjọ́ náà yóò jẹ́, nígbà tí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àǹfààní ẹbọ ìràpadà Jésù yóò tẹ àwọn ẹ̀dá ènìyàn tó jẹ́ onígbọràn àti olóòótọ́ lọ́wọ́!—Ìṣípayá 21:3, 4.
23 Wòlíì tí a mí sí yẹn wá ń tọ́ka sí àkókò ológo yẹn, ó sì mú un dá wa lójú pé: “Ní ti tòótọ́, [Ọlọ́run] yóò gbé ikú mì títí láé, dájúdájú, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn. Ẹ̀gàn àwọn ènìyàn rẹ̀ ni òun yóò sì mú kúrò ní gbogbo ilẹ̀ ayé, nítorí pé Jèhófà tìkára rẹ̀ ti sọ ọ́.” (Aísáyà 25:8) Ikú àdáyébá kò ní pa ẹnikẹ́ni mọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹkún sísun nítorí pé ikú mú èèyàn ẹni lọ kò ní sí mọ́. Àyípadà yìí mà kọyọyọ o! Síwájú sí i, a kò tún ní gbọ́ ẹ̀gàn àti ìgbékèéyíde tí Ọlọ́run àtàwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ti ń fara gbà látìgbà pípẹ́ wá níbikíbi lórí ilẹ̀ ayé mọ́. Kí ni ìdí tá ò fi ní gbọ́ ọ mọ́? Nítorí pé Jèhófà yóò mú ẹni tí ń bẹ nídìí rẹ̀, ìyẹn Sátánì Èṣù, baba irọ́, àti gbogbo irú ọmọ Sátánì, kúrò.—Jòhánù 8:44.
24. Báwo ni àwọn tí ń rìn nínú ìmọ́lẹ̀ ṣe dáhùn sí àwọn iṣẹ́ àrà tí Jèhófà ṣe fún wọn?
24 Nígbà táwọn tí ń rìn nínú ìmọ́lẹ̀ bá ronú nípa iṣẹ́ wọ̀nyí tó fi agbára Ọlọ́run hàn, wọ́n á polongo pé: “Wò ó! Ọlọ́run wa nìyí. Àwa ti ní ìrètí nínú rẹ̀, òun yóò sì gbà wá là. Jèhófà nìyí. Àwa ti ní ìrètí nínú rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí a kún fún ìdùnnú kí a sì máa yọ̀ nínú ìgbàlà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (Aísáyà 25:9) Láìpẹ́, ayọ̀ àwọn èèyàn tó jẹ́ olódodo yóò kún. Òkùnkùn náà yóò lọ pátápátá, àwọn olóòótọ́ yóò sì máa gbádùn ìmọ́lẹ̀ Jèhófà títí ayérayé. Ǹjẹ́ ìrètí kankan tún wà tó ga ju èyí lọ? Rárá o, kò sí!
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì láti máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ lónìí?
• Èé ṣe tí Aísáyà fi gbé orúkọ Jèhófà lárugẹ?
• Èé ṣe táwọn ọ̀tá kò fi ní lè ba ìwà títọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run jẹ́?
• Àwọn ìbùkún dídọ́ṣọ̀ wo ló ń dúró de àwọn tí ń rìn nínú ìmọ́lẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12, 13]
Àwọn olùgbé Júdà fi àwọn ọmọ rúbọ sí Mólékì
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ìmọ̀ nípa àwọn iṣẹ́ àrà Jèhófà mú kí Aísáyà gbé orúkọ Jèhófà lárugẹ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Àwọn olódodo yóò máa gbádùn ìmọ́lẹ̀ Jèhófà títí láé