Ọlọ́run Ló Fún Aráyé Ní Ìrètí Ìyè Àìnípẹ̀kun Lórí Ilẹ̀ Ayé
“A tẹ ìṣẹ̀dá lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo . . . nítorí ìrètí.”—RÓÒMÙ 8:20.
1, 2. (a) Kí nìdí tí ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé fi ṣe pàtàkì sí wa? (b) Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi rò pé ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé kò lè ṣeé ṣe?
Ó ṢEÉ ṣe kó o rántí bí ayọ̀ rẹ ti pọ̀ tó nígbà tó o kọ́kọ́ gbọ́ pé láìpẹ́ àwa èèyàn kò ní máa darúgbó mọ́, a ò sì ní máa kú mọ́, àmọ́ a óò wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé. (Jòh. 17:3; Ìṣí. 21:3, 4) O tiẹ̀ ti lè máa sọ̀rọ̀ nípa ìrètí tó wà nínú Ìwé Mímọ́ yìí fáwọn èèyàn. Ó ṣe tán, ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ kókó pàtàkì kan nínú ìhìn rere tá à ń wàásù. Ó ń mú kí ojú tá a fi ń wo ọ̀ràn ìgbésí ayé yàtọ̀.
2 Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ni kò gbà pé ó ṣeé ṣe fáwa èèyàn láti ní ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kọ́ni pé ọkàn èèyàn máa ń kú, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ló ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ tí kò bá Bíbélì mu pé ọkàn èèyàn kì í kú, pé ńṣe ló máa ń jáde kúrò lára ẹni tó kú, táá sì lọ máa gbé láàárín àwọn ẹ̀mí. (Ìsík. 18:20) Èyí ló mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa rò pé ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé kò lè ṣeé ṣe. Nítorí náà, a lè béèrè pé: Ṣé Bíbélì kọ́ni lóòótọ́ pé ọmọ aráyé ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé? Tí Bíbélì bá kọ́ni bẹ́ẹ̀, ìgbà wo ni Ọlọ́run kọ́kọ́ ṣí ìrètí yìí payá fún aráyé?
“A Tẹ Ìṣẹ̀dá Lórí Ba fún Ìmúlẹ̀mófo . . . Nítorí Ìrètí”
3. Báwo ni ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún aráyé ṣe hàn kedere látìbẹ̀rẹ̀ ìtàn ẹ̀dá èèyàn?
3 Látìbẹ̀rẹ̀ ìtàn ẹ̀dá èèyàn ni ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fún aráyé ti hàn kedere. Ọlọ́run sọ ọ́ gbangba pé Ádámù yóò wà láàyè títí láé tó bá ṣègbọràn. (Jẹ́n. 2:9, 17; 3:22) Láìsí àní-àní, àwọn àtìrandíran tó kọ́kọ́ ṣẹ̀ wá látọ̀dọ̀ Ádámù mọ ohun tó fà á tí èèyàn fi di aláìpé, nítorí wọ́n rí ẹ̀rí èyí. Kò sáyè láti wọnú ọgbà Édẹ́nì mọ́, àwọn èèyàn ń darúgbó, wọ́n sì ń kú. (Jẹ́n. 3:23, 24) Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, iye ọdún táwọn èèyàn ń lò tí wọ́n fi ń kú bẹ̀rẹ̀ sí í dín kù. Ádámù lo ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ó lé ọgbọ̀n [930] ọdún láyé kó tó kú. Ṣémù tó la Ìkún-omi já kò lò ju ẹgbẹ̀ta [600] ọdún lọ, nígbà tí Ápákíṣádì ọmọ rẹ̀ lo irínwó ó lé méjìdínlógójì [438]. Térà baba Ábúráhámù lo ọdún márùnlénígba [205] láyé. Ábúráhámù fúnra rẹ̀ lo ọdún márùn-dín-lọ́gọ́sàn-án [175], Ísákì ọmọ rẹ̀ lo ọgọ́sàn-án [180] ọdún, nígbà tí Jékọ́bù lo ọdún mẹ́tàdínláàádọ́jọ [147]. (Jẹ́n. 5:5; 11:10-13, 32; 25:7; 35:28; 47:28) Ọ̀pọ̀ èèyàn ti ní láti mọ ìdí táwọn èèyàn kì í fi í dàgbà tó ti tẹ́lẹ̀ mọ́ kí wọ́n tó kú. Ohun tó fà á ni pé ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun ti bọ́ mọ́ aráyé lọ́wọ́! Ǹjẹ́ ìdí kankan wà tó lè mú ká nírètí pé a lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun náà pa dà?
4. Kí nìdí táwọn olóòótọ́ ayé ìgbàanì fi gbà gbọ́ pé Ọlọ́run yóò dá àwọn ìbùkún tí Ádámù ti pàdánù pa dà?
4 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “A tẹ [ẹ̀dá èèyàn] lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo, . . . nítorí ìrètí.” (Róòmù 8:20) Ìrètí wo? Àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ nínú Bíbélì sọ nípa “irú-ọmọ” kan tí yóò ‘pa ejò náà ní orí.’ (Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5, 15.) Ìlérí tí Ọlọ́run ṣe nípa Irú-ọmọ náà mú káwọn olóòótọ́ èèyàn ní ìrètí pé Ọlọ́run ṣì máa ṣe ohun tó ní lọ́kàn fún aráyé. Ìlérí yẹn jẹ́ kí àwọn èèyàn bí Ébẹ́lì àti Nóà rí ìdí tí wọ́n fi ní láti gbà gbọ́ pé Ọlọ́run yóò dá ìbùkún tí Ádámù ti pàdánù pa dà. Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ti ní láti mọ̀ pé ‘pípa irú-ọmọ náà ní gìgísẹ̀’ yóò la títa ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ lọ.—Jẹ́n. 4:4; 8:20; Héb. 11:4.
5. Kí ló fi hàn pé Ábúráhámù nígbàgbọ́ nínú àjíǹde?
5 Gbé ọ̀ràn ti Ábúráhámù yẹ̀ wò. Nígbà tí Ọlọ́run dán an wò, Bíbélì ròyìn pé ‘ó tiẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ fi Ísákì ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo rúbọ.’ (Héb. 11:17) Kí nìdí tó fi gbà láti fọmọ rẹ̀ rúbọ? (Ka Hébérù 11:19.) Ìdí ni pé ó nígbàgbọ́ nínú àjíǹde! Ó sì nídìí tí Ábúráhámù fi nígbàgbọ́ nínú àjíǹde. Ó ṣáà mọ̀ pé Jèhófà ti mú kí agbára ìbímọ òun sọ jí pa dà tó sì mú kó ṣeé ṣe fún òun àti Sárà ìyàwó òun láti bí ọmọ kan lọ́jọ́ ogbó àwọn. (Jẹ́n. 18:10-14; 21:1-3; Róòmù 4:19-21) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà ti ṣèlérí fún un tẹ́lẹ̀ pé: “Nípasẹ̀ Ísákì ni ohun tí a ó pè ní irú-ọmọ rẹ yóò wà.” (Jẹ́n. 21:12) Nítorí náà, Ábúráhámù ní ìdí tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ láti retí pé Ọlọ́run yóò jí Ísákì dìde.
6, 7. (a) Májẹ̀mú wo ni Jèhófà bá Ábúráhámù dá? (b) Báwo ni ìlérí tí Jèhófà ṣe fún Ábúráhámù ṣe jẹ́ kí aráyé ní ìrètí?
6 Nítorí pé Ábúráhámù ní ìgbàgbọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀, Jèhófà bá a dá májẹ̀mú kan nípa “irú-ọmọ” rẹ̀. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 22:18.) Jésù Kristi ni olórí lára “irú-ọmọ” náà. (Gál. 3:16) Jèhófà sọ fún Ábúráhámù pé “irú-ọmọ” rẹ̀ yóò di púpọ̀ “bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti bí àwọn egunrín iyanrìn tí ó wà ní etíkun.” Ábúráhámù kò mọ bí “irú-ọmọ” yẹn ṣe máa pọ̀ tó. (Jẹ́n. 22:17) Àmọ́, nígbà tó yá, a mọ iye wọn. Jésù Kristi àti ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000], tí yóò jọba pẹ̀lú rẹ̀ nínú Ìjọba rẹ̀ ló para pọ̀ jẹ́ “irú-ọmọ” náà. (Gál. 3:29; Ìṣí. 7:4; 14:1) Ipasẹ̀ Ìjọba Mèsáyà ni “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò bù kún ara wọn.”
7 Ní àkókò yẹn, kò ṣeé ṣe fún Ábúráhámù láti lóye bí májẹ̀mú tí Jèhófà bá a dá ti ṣe pàtàkì tó. Síbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, “ó ń dúró de ìlú ńlá tí ó ní àwọn ìpìlẹ̀ tòótọ́.” (Héb. 11:10) Ìjọba Ọlọ́run ni ìlú yẹn. Kí Ábúráhámù tó lè rí ìbùkún gbà lábẹ́ Ìjọba náà, dandan ni kó tún pa dà wà láàyè. Ó máa ṣeé ṣe fún un láti ní ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé nípasẹ̀ àjíǹde. Yóò sì ṣeé ṣe fún àwọn tó máa la Amágẹ́dọ́nì já àtàwọn tó máa jíǹde láti ní ìyè ayérayé.—Ìṣí. 7:9, 14; 20:12-14.
“Ẹ̀mí Ti Kó Ìdààmú Bá Mi”
8, 9. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ìwé Jóòbù kì í kàn-án ṣe ọ̀rọ̀ ìtàn nípa bí àdánwò ṣe bá ọkùnrin kan?
8 Láàárín ìgbà ayé Jósẹ́fù tí ọmọ ọmọ Ábúráhámù bí, àti ìgbà ayé wòlíì Mósè, ọkùnrin kan wà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jóòbù. Ìwé Jóòbù, tó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Mósè ló kọ ọ́, ṣàlàyé ìdí tí Jèhófà fi gbà kí ìyà jẹ Jóòbù àti ibi tí ọ̀rọ̀ Jóòbù pa dà wá yọrí sí. Àmọ́ ṣá o, ohun tó wà nínú ìwé Jóòbù kì í kàn-án ṣe ìtàn bí àdánwò ṣe bá ọkùnrin kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó dá lórí ọ̀ràn tó kan gbogbo èèyàn àti àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí. Ìwé náà jẹ́ ká rí i pé Jèhófà ń ṣàkóso lọ́nà ẹ̀tọ́, ó sì tún jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀ràn tó ṣẹlẹ̀ ní ọgbà Édẹ́nì kan ìwà títọ́ àti ìwàláàyè gbogbo àwọn èèyàn Ọlọ́run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jóòbù kò mọ ohun tó wà nídìí ọ̀ràn náà, síbẹ̀ kò jẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta mú kó máa rò pé òun ò pa ìwà títọ́ òun mọ́. (Jóòbù 27:5) Ó yẹ kí èyí fún ìgbàgbọ́ wa lágbára kó sì jẹ́ ká mọ̀ pé a lè pa ìwà títọ́ wa mọ́ ká sì máa fi hàn pé Jèhófà ni ọba aláṣẹ.
9 Lẹ́yìn tí àwọn mẹ́ta tó pe ara wọn ní olùtùnú Jóòbù ti parí ọ̀rọ̀ wọn, “Élíhù ọmọkùnrin Bárákélì ọmọ Búsì bẹ̀rẹ̀ sí dáhùn.” Kí ló mú kó sọ̀rọ̀? Ó sọ ohun tó fà á, ó ní: “Mo ti kún fún ọ̀rọ̀; ẹ̀mí ti kó ìdààmú bá mi nínú ikùn mi.” (Jóòbù 32:5, 6, 18) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé asọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí Élíhù láti sọ ti ṣẹ nígbà tí Ọlọ́run mú Jóòbù pa dà bọ̀ sípò, síbẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣì wúlò fún àwọn ẹlòmíì. Àsọtẹ́lẹ̀ náà jẹ́ káwọn tó ń pa ìwà títọ́ mọ́ ní ìrètí.
10. Àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé nígbà míì Jèhófà máa ń sọ ọ̀rọ̀ kan fún ẹnì kan tí ọ̀rọ̀ náà yóò wá kan gbogbo aráyé lápapọ̀?
10 Nígbà míì Jèhófà máa ń sọ ọ̀rọ̀ kan fún ẹnì kan tí ọ̀rọ̀ náà yóò sì wá kan gbogbo aráyé lápapọ̀. A rí àpẹẹrẹ èyí nínú àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì nípa àlá tí Nebukadinésárì ọba Bábílónì lá, tó ní í ṣe pẹ̀lú igi ńlá kan tí wọ́n gé lulẹ̀. (Dán. 4:10-27) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àlá náà ṣẹ sí Nebukadinésárì lára, ó tún kan ohun tó jùyẹn lọ fíìfíì. Àlá náà fi hàn pé ìṣàkóso Ọlọ́run lórí ayé nípasẹ̀ ìjọba ìdílé Dáfídì, èyí tó dópin lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni yóò tún pa dà bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn okòó-lé-lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá [2,520] ọdún.a Ìṣàkóso Ọlọ́run lórí ayé tá a sọ yìí pa dà bẹ̀rẹ̀ lákọ̀tun nígbà tí Ọlọ́run fi Jésù Kristi jẹ ọba ní ọ̀run lọ́dún 1914. Tiẹ̀ wo bí Ìjọba náà ṣe máa mú ohun tí àwọn ẹ̀dá onígbọràn ti ń retí ṣẹ ná!
“Gbà Á Sílẹ̀ Lọ́wọ́ Sísọ̀kalẹ̀ Sínú Kòtò!”
11. Kí ni ọ̀rọ̀ tí Élíhù sọ fi hàn pé Ọlọ́run yóò ṣe?
11 Nígbà tí Élíhù ń dá Jóòbù lóhùn, ó sọ̀rọ̀ nípa ‘ońṣẹ́, agbọ̀rọ̀sọ, ọ̀kan nínú ẹgbẹ̀rún, láti sọ fún ènìyàn nípa ìdúróṣánṣán rẹ̀.’ Bí ońṣẹ́ yìí bá “pàrọwà sí Ọlọ́run kí ó lè ní ìdùnnú sí òun” ńkọ́? Élíhù fèsì pé: “Nígbà náà, [Ọlọ́run] a ṣe ojú rere sí i, a sì wí pé, ‘Gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ sísọ̀kalẹ̀ sínú kòtò! Mo ti rí ìràpadà! Kí ara rẹ̀ jà yọ̀yọ̀ ju ti ìgbà èwe; kí ó padà sí àwọn ọjọ́ okun inú ti ìgbà èwe rẹ̀.’” (Jóòbù 33:23-26) Ọ̀rọ̀ tó sọ yìí fi hàn pé Ọlọ́run ṣe tán láti gba “ìràpadà,” torí tàwọn ẹ̀dá èèyàn tó bá ronú pìwà dà.—Jóòbù 33:24.
12. Ìrètí wo ni ọ̀rọ̀ Élíhù mú kí aráyé lápapọ̀ ní?
12 Ó ṣeé ṣe kí Élíhù má mọ bí ìràpadà ti ṣe pàtàkì tó, bí àwon wolíì míì náà kò ṣe lóye gbogbo ohun tí wọ́n kọ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. (Dán. 12:8; 1 Pét. 1:10-12) Síbẹ̀, ọ̀rọ̀ tí Élíhù sọ yẹn fi hàn pé, ìrètí wà pé Ọlọ́run yóò gba ìràpadà lọ́jọ́ kan, yóò sì dá àwa èèyàn sílẹ̀ lọ́wọ́ ìdààmú ọjọ́ ogbó àti ikú. Gbólóhùn tó sọ yìí mú ká ní ìrètí àgbàyanu ti ìyè àìnípẹ̀kun. Ìwé Jóòbù tún fi hàn pé àjíǹde yóò wà.—Jóòbù 14:14, 15.
13. Báwo ni àwọn ọ̀rọ̀ Élíhù ṣe wúlò fún àwọn Kristẹni?
13 Lónìí, ọ̀rọ̀ Élíhù yẹn ṣì wúlò fún ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù àwọn Kristẹni tí wọ́n nírètí láti la ìparun ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí já. Àwọn arúgbó tó wà lára àwọn tó máa la ìparun náà já yóò pa dà lókun bíi ti ìgbà èwe wọn. (Ìṣí. 7: 9, 10, 14-17) Yàtọ̀ síyẹn, ohun ìdùnnú ló ń jẹ́ fáwọn olóòótọ́ bí wọ́n ṣe ń retí ìgbà tí wọ́n á máa rí i tí ara àwọn tó jíǹde yóò pa dà sí ti ọjọ́ ìgbà èwe wọn. Àmọ́ ṣá o, tí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró bá máa rí àìleèkú gbà ní ọ̀run, tí “àwọn àgùntàn mìíràn” bá sì máa ní ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n gbọ́dọ̀ lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Kristi.—Jòh. 10:16; Róòmù 6:23.
Yóò Gbé Ikú Mì ní Ilẹ̀ Ayé
14. Kí ló fi hàn pé Òfin Mósè nìkan kò tó fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun?
14 Àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù di odindi orílẹ̀-èdè kan nígbà tí wọ́n bá Ọlọ́run dá májẹ̀mú. Nígbà tí Jèhófà fún wọn ní Òfin náà, ó sọ pé: “Kí ẹ sì máa pa àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ mi àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ mi mọ́, èyí tí ó jẹ́ pé, bí ènìyàn bá pa wọ́n mọ́, ẹni náà yóò sì wà láàyè nípasẹ̀ wọn.” (Léf. 18:5) Àmọ́ nítorí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò lè pa ìlànà pípé tó wà nínú Òfin náà mọ́, Òfin náà dá wọn lẹ́bi, wọ́n sì nílò ohun tí yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ẹ̀bi náà.—Gál. 3:13.
15. Ìbùkún ọjọ́ ọ̀la wo ni Ọlọ́run mí sí Dáfídì láti kọ̀wé nípa rẹ̀?
15 Lẹ́yìn Mósè, Jèhófà mí sí àwọn míì tó kọ Bíbélì láti sọ̀rọ̀ nípa ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun. (Sm. 21:4; 37:29) Bí àpẹẹrẹ, Dáfídì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Sáàmù fi ọ̀rọ̀ nípa ìṣọ̀kan àárín àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ ní Síónì parí sáàmù kan, ó ní: “Nítorí pé ibẹ̀ ni Jèhófà pàṣẹ pé kí ìbùkún wà, àní ìyè fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Sm. 133:3.
16. Kí ni Jèhófà tipasẹ̀ Aísáyà ṣèlérí nípa ọjọ́ ọ̀la “gbogbo ilẹ̀ ayé”?
16 Jèhófà mí sí Aísáyà láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé. (Ka Aísáyà 25:7, 8.) Ikú àti ẹ̀ṣẹ̀ ti “ràgà bo” aráyé, bí aṣọ nínípọn tó bo èèyàn lórí mọ́lẹ̀ tí ò fi lè ráyè mí. Jèhófà mú un dá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lójú pé òun yóò gbé ikú mì, ìyẹn ni pé òun á mú un kúrò “ní gbogbo ilẹ̀ ayé.”
17. Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ sọ pé Mèsáyà máa ṣe tó máa mú kó ṣeé ṣe fọ́mọ aráyé láti rí ìyè àìnípẹ̀kun?
17 Tún ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí Òfin Mósè là kalẹ̀ nípa ewúrẹ́ Ásásélì. Lẹ́ẹ̀kan lọ́dún ní Ọjọ́ Ètùtù, olórí àlùfáà ‘yóò gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé orí ààyè ewúrẹ́ náà, á sì jẹ́wọ́ gbogbo ìṣìnà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, á sì fi wọ́n lé orí ewúrẹ́ náà, ewúrẹ́ náà á sì fi orí ara rẹ̀ ru gbogbo ìṣìnà wọn lọ sí ilẹ̀ aṣálẹ̀.’ (Léf. 16:7-10, 21, 22) Wòlíì Aísáyà ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa dídé Mèsáyà, pé yóò ṣe ohun tó jọ bẹ́ẹ̀, ìyẹn ni pé yóò ru “àìsàn,” “ìrora” àti “ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn” lọ, tí yóò sì tipa báyìí mú kó ṣeé ṣe fọ́mọ aráyé láti rí ìyè àìnípẹ̀kun.—Ka Aísáyà 53:4-6, 12.
18, 19. Ìrètí wo ni ìwé Aísáyà 26:19 àti Dáníẹ́lì 12:13 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀?
18 Jèhófà tipasẹ̀ Aísáyà sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì pé: “Àwọn òkú rẹ yóò wà láàyè. Òkú tèmi—wọn yóò dìde. Ẹ jí, ẹ sì fi ìdùnnú ké jáde, ẹ̀yin olùgbé inú ekuru! Nítorí pé ìrì rẹ dà bí ìrì ewéko málò, ilẹ̀ ayé pàápàá yóò sì jẹ́ kí àwọn tí ó jẹ́ aláìlè-ta-pútú nínú ikú pàápàá jáde wá nínú ìbímọ.” (Aísá. 26:19) Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù fi hàn kedere pé ìrètí àjíǹde àti ti ìwàláàyè lórí ilẹ̀ ayé wà. Bí àpẹẹrẹ nígbà tí Dáníẹ́lì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹni ọgọ́rùn-un ọdún, Jèhófà fi dá a lójú pé: “Ìwọ yóò sì sinmi, ṣùgbọ́n ìwọ yóò dìde fún ìpín rẹ ní òpin àwọn ọjọ́.”—Dán. 12:13.
19 Nítorí pé Màtá ní ìrètí pé àjíǹde ń bọ̀, nígbà tó ń bá Jésù sọ̀rọ̀ nípa Lásárù àbúrò rẹ̀ tó kú, ó ní: “Mo mọ̀ pé yóò dìde nínú àjíǹde ní ọjọ́ ìkẹyìn.” (Jòh. 11:24) Ǹjẹ́ ẹ̀kọ́ Jésù àti ìwé tí Ọlọ́run mí sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti kọ fi hàn pé ìrètí aráyé ti yí pa dà? Ǹjẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé ṣì jẹ́ ìrètí tí Jèhófà fún aráyé? A óò jíròrò ìdáhùn sí ìbéèrè wọ̀nyí nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Nítorí ìrètí wo ‘la ṣe tẹ ẹ̀dá èèyàn lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo’?
• Kí ló fi hàn pé Ábúráhámù nígbàgbọ́ nínú àjíǹde?
• Ìrètí wo ni ọ̀rọ̀ tí Élíhù sọ fún Jóòbù mú kí aráyé ní?
• Báwo ni Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ṣe tẹnu mọ́ ìrètí àjíǹde àti ti ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Ọ̀rọ̀ tí Élíhù sọ fún Jóòbù mú ká ní ìrètí pé Ọlọ́run yóò dá àwa èèyàn sílẹ̀ lọ́wọ́ ìdààmú ọjọ́ ogbó àti ikú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Jèhófà mú un dá Dáníẹ́lì lójú pé ‘yóò dìde fún ìpín rẹ ní òpin àwọn ọjọ́’