Jóòbù
4 Ta ló lè mú ẹni tó mọ́ jáde látinú ẹni tí kò mọ́?+
Kò sẹ́ni tó lè ṣe é!
6 Gbé ojú rẹ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ kó lè sinmi,
Títí ó fi máa lo ọjọ́ rẹ̀ tán+ bí alágbàṣe.
7 Torí ìrètí wà fún igi pàápàá.
Tí wọ́n bá gé e lulẹ̀, ó máa hù pa dà,
Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ á sì máa dàgbà.
8 Tí gbòǹgbò rẹ̀ bá gbó sínú ilẹ̀,
Tí kùkùté rẹ̀ sì kú sínú iyẹ̀pẹ̀,
9 Ó máa hù tó bá gbúròó omi;
Ó sì máa yọ ẹ̀ka bí ewéko tó ṣẹ̀ṣẹ̀ hù.
10 Àmọ́ èèyàn kú, ó sì wà nílẹ̀ láìlágbára;
Tí èèyàn bá gbẹ́mìí mì, ibo ló wà?+
11 Omi dàwátì nínú òkun,
Odò ń fà, ó sì gbẹ táútáú.
12 Bẹ́ẹ̀ ni èèyàn ń dùbúlẹ̀, kì í sì í dìde.+
Títí ọ̀run kò fi ní sí mọ́, wọn ò ní jí,
Bẹ́ẹ̀ ni a ò ní jí wọn lójú oorun.+
13 Ká ní o lè fi mí pa mọ́ sínú Isà Òkú* ni,+
Kí o fi mí pa mọ́ títí ìbínú rẹ fi máa kọjá,
Kí o yan àkókò kan sílẹ̀ fún mi, kí o sì rántí mi!+
14 Tí èèyàn bá kú, ṣé ó tún lè wà láàyè?+
Màá dúró jálẹ̀ gbogbo ọjọ́ tó pọn dandan pé kí n lò,
Títí ìtura mi fi máa dé. +
15 O máa pè, màá sì dá ọ lóhùn.+
Ó máa wù ọ́ gan-an láti rí* iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
16 Àmọ́ ní báyìí, ò ń ka gbogbo ìṣísẹ̀ mi ṣáá;
Ẹ̀ṣẹ̀ mi nìkan lò ń ṣọ́.
17 O sé ẹ̀ṣẹ̀ mi mọ́ inú àpò,
O sì fi àtè lẹ àṣìṣe mi pa.
18 Bí òkè ṣe máa ń ṣubú, tó sì ń fọ́ sí wẹ́wẹ́,
Tí àpáta sì ń ṣí kúrò ní àyè rẹ̀,
19 Bí omi ṣe ń mú kí òkúta yìnrìn,
Tí ọ̀gbàrá rẹ̀ sì ń wọ́ iyẹ̀pẹ̀ ilẹ̀.
Bẹ́ẹ̀ lo ṣe sọ ìrètí ẹni kíkú dòfo.
20 Ò ń borí rẹ̀ títí ó fi ṣègbé;+
O yí ìrísí rẹ̀ pa dà, o sì ní kó máa lọ.
21 A bọlá fún àwọn ọmọ rẹ̀, àmọ́ kò mọ̀;
Wọ́n di ẹni tí kò ní láárí, àmọ́ kò mọ̀.+
22 Ìgbà tó ṣì jẹ́ ẹlẹ́ran ara nìkan ló mọ̀ pé òun ń jẹ̀rora;
Ìgbà tí ó* ṣì wà láàyè nìkan ló ń ṣọ̀fọ̀.”