Ẹ Pa Ọjọ Jehofa Mọ́ Sọ́kàn Pẹkipẹki
“Ọjọ Jehofa ti sunmọle ni ibi pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ipinnu naa.”—JOẸLI 3:14, NW.
1. Eeṣe ti ogun mímọ́ ti ń bọ̀ tí Jehofa polongo yoo fi yatọ si awọn ogun “mímọ́” ti araye?
“ẸPOLONGO eyi, ẹyin eniyan, laaarin awọn orilẹ-ede, ‘Ẹ sọ ogun di mímọ́!’” (Joẹli 3:9, NW) Eyi ha tumọsi ogun mímọ́ bi? Ni bíbojú wẹ̀hìn wo awọn Ogun-Mímọ́, awọn ogun onisin, ati awọn ogun agbaye meji—ninu eyi ti Kristẹndọmu ti kó ipa iwaju—a lè wárìrì nipa wiwulẹ ronu nipa ogun “mímọ́.” Bi o ti wu ki o ri, ogun mímọ́ inu asọtẹlẹ Joẹli kì í ṣe ogun laaarin awọn orilẹ-ede. Kì í ṣe ìjàkadì fun ipinlẹ tabi awọn ohun ìní ti ó kún fún ikoriira, ti ń lo isin gẹgẹ bi àwáwí. Ó jẹ́ ogun ododo kan. Ogun Ọlọrun ni lati gba ilẹ̀-ayé kalẹ lọwọ iwọra, rogbodiyan, ibajẹ, ati ìtẹ̀lóríba. Yoo dá ẹ̀tọ́ ipo ọba-alaṣẹ Jehofa lori gbogbo ilẹ akoso iṣẹda rẹ̀ lare. Ogun yẹn yoo pa ọ̀nà mọ́ fun Ijọba Kristi lati mú araye wọnu alaafia agbaye, aásìkí, ati ayọ Ẹgbẹrundun tí awọn wolii Ọlọrun sọtẹlẹ.—Saamu 37:9-11; Aisaya 65:17, 18; Iṣipaya 20:6.
2, 3. (a) Ki ni “ọjọ́ Jehofa” ti a sọtẹlẹ ni Joẹli 3:14 (NW)? (b) Eeṣe ti awọn orilẹ-ede fi lẹ́tọ̀ọ́ sí ohun ti wọn nilati dojukọ ni ọjọ yẹn?
2 Nigba naa, ki ni “ọjọ Jehofa” ti a sọtẹlẹ ni Joẹli 3:14? “Págà fun ọjọ naa,” ni Jehofa funraarẹ kigbe soke, “nitori pe ọjọ Jehofa sunmọle, ati bii ifiṣejẹ kan lati ọdọ Ẹni Olodumare ni yoo wá!” Bawo ni o ṣe jẹ́ ifiṣejẹ kan? Wolii naa ṣalaye lẹhin naa pe: “Awọn ogunlọgọ, awọn ogunlọgọ wà ni ibi pẹ̀tẹ́lẹ̀ rirẹlẹ ipinnu naa, nitori ọjọ́ Jehofa ti sunmọle ni ibi pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ipinnu naa.” (Joẹli 1:15; 3:14, NW) Eyi ni ọjọ naa ninu eyi ti Jehofa mú ipinnu idajọ rẹ̀ ṣẹ lori awọn ogunlọgọ alailọlọrun ti wọn kọ titọna ipo ọba-alaṣẹ rẹ̀ lori ọ̀run ati ilẹ ayé. Ipinnu Jehofa ni lati pa eto igbekalẹ awọn nǹkan ti Satani tí ó ti gbá araye mọra fun akoko pipẹ tobẹẹ ninu awọn ẹ̀mú rẹ̀ run.—Jeremaya 17:5-7; 25:31-33.
3 Eto igbekalẹ oníwà ìbàjẹ́ lori ilẹ̀-ayé gbọdọ dojukọ ipinnu yẹn. Ṣugbọn eto igbekalẹ ayé ha fi bẹẹ buru niti gidi bi? Wíwo akọsilẹ rẹ̀ lẹẹkan ti tó! Jesu sọ ilana kan ni Matiu 7:16 pe: “Eso wọn ni ẹyin yoo fi mọ̀ wọn.” Awọn ilu-nla titobi inu ayé ko ha ti di ibi ẹlẹ́gbin fun awọn oògùn, ìwà ọ̀daràn, ìpayà, ìwà pálapàla, ati ìbàyíkájẹ́ bi? Ni ọpọlọpọ ilẹ awọn ominira ti a ṣẹṣẹ rí ni a ń tẹ̀rì nipasẹ ìdàrúdàpọ̀ oṣelu, ọ̀wọ́n gógó ounjẹ, ati òṣì. Iye awọn eniyan ti wọn ju ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀kẹ́ lọ ń jẹ ounjẹ ti kò yó wọn. Siwaju sii, ajakalẹ àrùn AIDS, tí awọn oògùn ati ọ̀nà igbesi-aye oniwa palapala tanná ràn, ṣokunkun biribiri bo apa titobi ninu ilẹ̀-ayé. Ni pataki lati ìgbà ti Ogun Agbaye I ti bẹ́ silẹ ni 1914, ni ìjórẹ̀hìn ní ìwọ̀n kan ti o kari ayé ti wà ninu gbogbo ìhà igbesi-aye.—Fiwe 2 Timoti 3:1-5.
4. Ọrọ ipenija wo ni Jehofa sọ sí awọn orilẹ-ede?
4 Bi o ti wu ki o ri, Jehofa ti ń kó awọn eniyan kan jọ lati inu gbogbo awọn orilẹ-ede awọn eniyan ti wọn fi tayọtayọ gba itọni nipa awọn ọ̀nà rẹ̀ ti wọn sì ń rìn ni awọn ipa-ọna rẹ̀. Awọn eniyan ti wọn wà yika agbaye yii ti fi awọn idà wọn rọ ohun èèlò ìtúlẹ̀, ni kíkọ awọn ọ̀nà oniwa-ipa ti ayé silẹ. (Aisaya 2:2-4) Bẹẹni, fi idà rọ ohun èèlò ìtúlẹ̀! Ṣugbọn eyi ki i ha ṣe odikeji igbe naa ti Jehofa mú ki a polongo ni Joẹli 3:9, 10 (NW) bi? Nibẹ ni a ti kà pe: “Ẹ polongo eyi, ẹyin eniyan, laaarin awọn orilẹ-ede, ‘Ẹ sọ ogun di mímọ́! Ẹ ru awọn ọkunrin alagbara soke! Ẹ jẹ ki wọn sunmọ tosi! Ẹ jẹ ki wọn sunmọ ibi, gbogbo awọn ọkunrin ogun. Ẹ fi awọn ohun èèlò ìtúlẹ̀ yin rọ idà ati alumọgaji ìpọ̀mùnú yin rọ aṣóró.’” Áà, nihin-in ni Jehofa ti ń pe awọn alakooso ayé nija lati mú àpapọ̀ agbara ologun wọn wá lodi si i ni Amagẹdọni. Ṣugbọn wọn kò lè ṣaṣeyọri! Wọn gbọdọ sọkalẹ lọ sinu iṣẹgunṣẹtẹ yán-án-yán-ań!—Iṣipaya 16:16.
5. Ki ni iyọrisi naa yoo jẹ́ nigba ti Jesu bá kore “àjàrà ilẹ̀-ayé”?
5 Ní ìṣàyàgbàǹgbà si Oluwa Ọba-Alaṣẹ Jehofa, awọn oluṣakoso alagbara ti kó awọn ohun ìjà abanilẹ́rù jọ pelemọ—ṣugbọn lori asán ni! Jehofa fi aṣẹ naa funni ni Joẹli 3:13 (NW) pe: “Ẹ ti dòjé bọ̀ ọ́, nitori ikore ti pọ́n. Ẹ wá, ẹ sọkalẹ, nitori ìfúntí ti kún. Àgbá ọti ti kún àkúnwọ́sílẹ̀ niti gidi; nitori tí buburu wọn ti di pupọ rẹpẹtẹ.” Awọn ọrọ wọnni baradọgba pẹlu Iṣipaya 14:18-20 (NW), nibi ti a ti paṣẹ fun angẹli kan ti o ni dòjé mímú kan lati “kó awọn ṣírí àjàrà ilẹ̀-ayé jọ, nitori pe awọn èso àjàrà rẹ̀ ti pọ́n.” Angẹli naa ti dòjé rẹ̀ bọ̀ ọ́ ó sì bi awọn orilẹ-ede aṣàyà gbàǹgbà wọnni “sinu ìfúntí ńlá ti ibinu Ọlọrun.” Lọna afiṣapẹẹrẹ, ẹ̀jẹ̀ ti o jade lati inu ìfúntí naa ga soke dé ìjánu awọn ẹṣin, ni eyi ti o jinna tó 1,600 iwọn furlong—nǹkan bii 180 ibusọ! Iru ifojusọna bíbanilẹ́rù wo ni ó jẹ́ fun awọn orilẹ-ede ti wọn tabuku si Jehofa!
Awọn Ara-Ilu Ti Ń Pa Ofin Mọ́
6. Oju wo ni Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi wo awọn orilẹ-ede ati awọn oluṣakoso wọn?
6 Eyi ha tumọsi pe Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kò bọ̀wọ̀ fun awọn orilẹ-ede ati awọn oluṣakoso wọn bi? Ki a má ri! Wọn wulẹ ń dẹbi fun ìwà ìbàjẹ́ ti gbogbo eniyan lè rí ni kedere ni, wọn sì ń kilọ nipa ọjọ Jehofa ti ń yara bọ̀ kánkán fun mímú ipinnu rẹ̀ ṣẹ. Ni akoko kan naa, wọn fi tirẹlẹ tirẹlẹ ṣegbọran si aṣẹ apọsiteli Pọọlu ni Roomu 13:1 (NW), pe: “Jẹ ki olukuluku ọkàn wà ní itẹriba fun awọn alaṣẹ onipo-gigaju.” Awọn oluṣakoso eniyan wọnyi, ni wọn fi ọlá ti ó yẹ fun ṣugbọn kì í ṣe ijọsin. Gẹgẹ bi ara-ilu olùpa ofin mọ́, wọn tẹle awọn ọpa idiwọn Bibeli nipa ailabosi, iṣotitọ, imọtonitoni wọn sì gbé iwa rere ró ninu awọn idile tiwọn funraawọn. Wọn a maa ran awọn ẹlomiran lọwọ lati mọ bi awọn pẹlu ṣe lè ṣe eyi. Wọn a maa gbé ni alaafia pẹlu gbogbo eniyan, lai kowọnu awọn ìwọ́de tabi awọn ìdojú ijọba dé lọna oṣelu. Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa wá ọ̀nà lati jẹ́ awofiṣapẹẹrẹ ninu ṣiṣegbọran si awọn ofin awọn alaṣẹ eniyan onipo-gigaju, nigba ti wọn duro de Alaṣẹ Onipo-Ajulọ, Oluwa Ọba-Alaṣẹ Jehofa, lati mu alaafia pipe ati ijọba ododo padabọsipo si ilẹ̀-ayé yii.
Mímú Ipinnu Rẹ̀ Ṣẹ
7, 8. (a) Ni ọ̀nà wo ni a o gbà mi awọn orile-ede jìgìjìgì ti okunkun yoo sì sọkalẹ sori wọn? (b) Awọn wo ni Joẹli ṣapẹẹrẹ lonii, ati ni iyatọ ifiwera pẹlu ayé ni gbogbogboo, bawo ni a ṣe bukun awọn wọnyi?
7 Ni èdè iṣapẹẹrẹ ti o ṣe ketekete, Jehofa funni ni apejuwe siwaju sii yii nipa mímú ipinnu rẹ̀ ṣẹ. “Oòrùn ati oṣupa yoo di okunkun dajudaju, ti awọn irawọ gan-an yoo sì fawọ́ ìmọ́lẹ̀yòò wọn sẹhin. Ati lati Sioni Jehofa funraarẹ yoo ké ramúramù, ati lati Jerusalẹmu oun yoo mú ohùn rẹ̀ jade. Ọrun ati ilẹ ayé yoo sì mì jìgìjìgì dajudaju; ṣugbọn Jehofa yoo jẹ́ ààbò-ìsádi fun awọn eniyan rẹ̀, ati odi-agbara fun awọn ọmọkunrin Isirẹli.” (Joẹli 3:15, 16, NW) Ipo ti o farajọ mímọ́lẹ̀yòò, aláásìkí ti araye yoo yipada si onídàágùdẹ̀, alápẹẹrẹ ibi, eto igbekalẹ ayé ti ń fọ́ sí wẹ́wẹ́ yii ni a o sì mú kuro patapata, a o sọ ọ́ di ahoro bi ẹni pe nipasẹ isẹlẹ ńlá kan!—Hagai 2:20-22.
8 Ṣakiyesi idaniloju alayọ naa pe Jehofa yoo jẹ ààbò-ìsádi ati odi-agbara fun awọn eniyan rẹ̀! Eeṣe ti ó fi rí bẹẹ? Nitori pe awọn ni awọn eniyan kanṣoṣo—awọn eniyan jakejado awọn orilẹ-ede—ti wọn ti dahun pada si awọn ọrọ Jehofa pe: “Ẹyin eniyan yoo nilati mọ̀ pe emi ni Jehofa Ọlọrun yin.” (Joẹli 3:17, NW) Niwọn bi orukọ Joẹli ti tumọsi “Jehofa ni Ọlọrun,” lọna ti ó ṣe wẹ́kú ó duro fun Awọn Ẹlẹ́rìí ẹni ami ororo ode-oni ti Jehofa, awọn ti wọn ṣiṣẹsin pẹlu igboya ninu pipolongo ipo ọba-alaṣẹ Jehofa. (Fiwe Malaki 1:11.) Ní ṣíṣíwèé si awọn ọrọ ibẹrẹ asọtẹlẹ Joẹli, awa yoo rí bi oun ṣe sọ asọtẹlẹ igbokegbodo awọn eniyan Ọlọrun lonii lọna ti o ṣe ketekete.
Àgbájọ Eéṣú
9, 10. (a) Ìyọnu wo ni a sọtẹlẹ lati ẹnu Joẹli? (b) Bawo ni Iṣipaya ṣe ṣe gbohungbohun asọtẹlẹ Joẹli nipa ìyọnu, ipa wo sì ni ìyọnu yii ni lori Kristẹndọmu?
9 Fetisilẹ nisinsinyi si “ọrọ Jehofa tí ó tọ Joẹli wá!”: “Ẹ gbọ́ eyi, ẹyin agbalagba ọkunrin, ẹ sì fetisilẹ, gbogbo ẹyin olùgbé ilẹ naa. Eyi ha ti ṣẹlẹ ni awọn ọjọ yin, tabi ni ọjọ awọn babanla yin bi? Nipa rẹ̀ ẹ fi akọsilẹ irohin kan fun awọn ọmọkunrin tiyin funraayin, ati awọn ọmọkunrin yin fun awọn ọmọkunrin wọn, ati awọn ọmọkunrin wọn fun ìran ti ó tẹle e. Ohun ti ìdin-eéṣú fi silẹ, ni eéṣú ti jẹ; ohun ti eéṣú sì fi silẹ, ni eéṣú tí ń fà, tí kò ní ìyẹ́ ti jẹ; ohun ti eéṣú tí ń fà, ti kò ní ìyẹ́ sì ti fi silẹ, ni aáyán ti jẹ.”—Joẹli 1:1-4.
10 Ìgbétáásì àràmàǹdà-ọ̀tọ̀ kan ni eyi jẹ́, ọ̀kan tí a o ṣe iranti rẹ̀ fun gbogbo ìgbà. Ìgbì lori ìgbì awọn kokoro, tí eéṣú pọ̀ julọ ninu wọn, sọ ilẹ naa dahoro. Ki ni eyi tumọsi? Iṣipaya 9:1-12 (NW) tún sọrọ nipa ìyọnu awọn eéṣú, ti a rán jade lati ọdọ Jehofa labẹ “ọba kan, angẹli ọ̀gbun ainisalẹ,” ti kì í ṣe ẹlomiran ju Kristi Jesu lọ. Awọn orukọ rẹ̀ Abadoni (Heberu) ati Apolioni (Giriiki) tumọsi “Iparun” ati “Apanirun.” Awọn eéṣú wọnyi ṣapẹẹrẹ awọn Kristẹni ẹni ami ororo, nisinsinyi ni ọjọ Oluwa, ti wọn jade lọ lati pa pápá koriko Kristẹndọmu run nipa titudii aṣiri isin èké patapata ati pipolongo ẹsan Jehofa lé e lori.
11. Bawo ni a ṣe fun awọn eéṣú ode-oni lokun, awọn wo ní pataki sì ni kókó àfojúsùn igbejakoni wọn?
11 Gẹgẹ bi Iṣipaya 9:13-21 ti fihan, ìyọnu eéṣú ni ìyọnu agbo agẹṣinjagun titobi ńlá kan ṣaaju rẹ̀. Eyi ti jẹ́ otitọ tó lonii, niwọnbi a ti fi okun fun iwọnba ẹgbẹrun awọn Kristẹni ẹni ami ororo ti wọn ṣẹ́kù nipasẹ iye ti o ju million mẹrin “awọn agutan miiran” ti wọn papọ jẹ́ agbo ẹgbẹ agẹṣinjagun alaiṣee dí lọwọ kan! (Johanu 10:16, NW) Wọn sopọṣọkan ninu pipolongo awọn idajọ Jehofa tí ń tani lé awọn abọriṣa Kristẹndọmu lori ati awọn wọnni ti wọn ‘kò ronupiwada kuro ninu ipaniyan wọn tabi awọn àṣà ìbẹ́mìílò wọn tabi àgbèrè wọn tabi olè jíjà wọn.’ Awujọ alufaa—ati Katoliki ati Protẹstanti—ti wọn ti fi akitiyan ti awọn ogun iṣikapaniyan ti ọrundun yii lẹhin, ati bakan naa awọn alufaa oniwa ibajẹ takọtabo ti a doju rẹ̀ kọ awọn ọmọde ati awọn ajihinrere ori tẹlifiṣọn oniṣekuṣe, wà lara awọn wọnni tí a dari awọn ihin-iṣẹ idajọ wọnyi sí.
12. Eeṣe ti ó fi yẹ fun awọn aṣaaju Kristẹndọmu lati gba awọn ihin-iṣẹ idajọ, ki ni yoo sì ṣẹlẹ si wọn laipẹ, papọ pẹlu gbogbo awọn mẹmba Babiloni Ńlá?
12 Si iru “awọn bọ̀ọ̀kìní” ninu aṣọ bẹẹ, ni awọn ikesini Jehofa dún jade pe: “Ẹ jí dide, ẹyin ọmuti, ki ẹ sì sọkun; ki ẹ sì hu, gbogbo ẹyin ti ń mu waini, nititori waini didun, nitori a ké e kuro ni ẹnu yin.” (Joẹli 1:5, NW) Ni ọrundun lọna 20 yii, isin Kristẹndọmu ti fi ìgbọ̀jẹ̀gẹ́ ayé dipo awọn ilana iwarere mímọ́ ti Ọrọ Ọlọrun. Ó ti dabi ohun ti ó dunmọ isin èké ati awọn ìjọ rẹ̀ lati gba awọn ọ̀nà ayé mọra, ṣugbọn iru ikore aisan tẹmi ati ti ara wo ni wọn ti kó! Laipẹ, gẹgẹ bi a ti ṣapejuwe rẹ̀ ni Iṣipaya 17:16, 17, yoo jẹ́ “èrò” Ọlọrun fun awọn alagbara oṣelu lati kọlu gbogbo ilẹ-ọba isin èké agbaye, Babiloni Ńlá lojiji, ti yoo sì sọ ọ́ dahoro. Kìkì nigba naa, bi ó bá ti ń rí ipinnu Jehofa ti a ń múṣẹ lodi sí i, ni yoo tó “tají” lati inu ìraníyè ìmutí rẹ̀.
“Awọn Eniyan Pípọ̀níye ati Alagbara”
13. Ni ọ̀nà wo ni ẹgbẹ́-ogun eéṣú ṣe dabi “pípọ̀níye ati alagbara” fun Kristẹndọmu?
13 Wolii Jehofa ń ba a lọ lati ṣapejuwe agbo-ogun eéṣú naa gẹgẹ bi “awọn eniyan pípọ̀níye ati alagbara,” bẹẹ sì ni ó jọ loju Babiloni Ńlá. (Joẹli 2:2, NW) Awujọ alufaa rẹ̀, fun apẹẹrẹ, kédàárò otitọ naa pe awọn isin Kristẹndọmu ti kuna lati ní awọn ti a yi lọkan pada ninu isin Buddha ti Japan. Sibẹ, lonii bii ẹgbẹ́ agẹṣin jagun ti kò ṣee dilọwọ kan, iye ti ó ju 160,000 Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ará Japan ń rọ́ yìì kari orilẹ-ede yẹn wọn sì ń dari awọn ikẹkọọ Bibeli àdáṣe ni ohun ti ó ju 200,000 ile awọn eniyan lọ. Ni Italy Awọn Ẹlẹ́rìí 180,000 ti Jehofa ni a ti mọ̀ nisinsinyi gẹgẹ bi awọn ti o ṣe ikeji ni iye si kìkì Awọn Katoliki. Lasan ni alufaa àgbà patapata ti Roman Katoliki kan ni Italy kédàárò otitọ naa pe Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń gba ‘ó keretan 10,000 awọn Katoliki oluṣotitọ’ kuro ninu ṣọọṣi naa lọdọọdun.a Awọn Ẹlẹ́rìí naa layọ lati tẹwọgba iru awọn ẹni bẹẹ.—Aisaya 60:8, 22.
14, 15. Bawo ni Joẹli ṣe ṣapejuwe ẹgbẹ́-ogun eéṣú, ati ni ọ̀nà wo ni eyi gbà ni imuṣẹ lonii?
14 Ni ṣiṣapejuwe agbo-ogun eéṣú ti Awọn Ẹlẹ́rìí ẹni ami ororo naa, Joẹli 2:7-9 (NW) wi pe: “Bii awọn alagbara ọkunrin wọn sáré. Bii awọn ọkunrin ogun wọn gori ogiri. Ẹnikọọkan wọn sì lọ ni awọn ọ̀nà tirẹ, wọn kò sì yí ipa-ọna wọn pada. Ẹnikinni keji ni wọn kò sì bì [siwaju]. Gẹgẹ bi ọkunrin abarapá kan ní ipa-ọna rẹ̀, wọn ń lọ; ati bi awọn kan bá nilati ṣubu ani laaarin awọn ohun ọṣẹ́ naa, awọn tí ó kù kò yapa kuro ni ipa-ọna. Sinu ilu-nla ni wọn rọ́ lọ. Lori ogiri ni wọn sáré. Sinu awọn ile ni wọn lọ. Oju awọn ferese ni wọn gbà wọle bi olè.”
15 Nitootọ, ó jẹ́ ìṣàpèjúwe ẹgbẹ́ ọmọ-ogun “awọn eéṣú,” ẹni ami ororo, ni kedere, tí iye awọn alabaakẹgbẹ, awọn agutan miiran ti ó pọ ju million mẹrin darapọ mọ nisinsinyi! Kò si “ogiri” iṣọta isin ti ó lè fa awọn wọnyi sẹhin. Pẹlu igboya, wọn “ń ba a lọ ni rírìn ni ọ̀nà ìgbàṣiṣẹ́ deedee kan naa yii” ti ijẹrii itagbangba ati awọn igbokegbodo Kristẹni miiran. (Fiwe Filipi 3:16, NW.) Dipo jijuwọsilẹ, wọn ti muratan lati dojukọ iku, gẹgẹ bi ẹgbẹẹgbẹrun Awọn Ẹlẹ́rìí ti wọn ‘ṣubu laaarin awọn ohun ọṣẹ́’ nitori pe wọn kọ̀ lati kigbe igbala niti Hitler Katoliki ará Germany naa. Ẹgbẹ́-ogun eéṣú naa ti funni ni ijẹrii kúnnákúnná ninu “ilu-nla” Kristẹndọmu, ní fífò rekọja gbogbo awọn ìdènà, ní yíyọ́ wọ inu awọn ile bí olè, gẹgẹ bi a ṣe lè sọ pe o jẹ́, ti pín araadọta-ọkẹ lọna ẹgbẹẹgbẹrun awọn itẹjade Bibeli kiri nipasẹ igbokegbodo ile-de-ile wọn. Ifẹ-inu Jehofa ni pe ki a jẹ́ ẹ̀rí yii, kò sì sí agbara kankan ni ọ̀run tabi lori ilẹ̀-ayé ti ó lè dá a duro.—Aisaya 55:11.
“Kún Fun Ẹmi Mimọ”
16, 17. (a) Nigba wo ni awọn ọrọ Joẹli 2:28, 29 ni imuṣẹ titayọ kan? (b) Awọn ọrọ alasọtẹlẹ ti Joẹli wo ni kò ní imuṣẹ patapata ni ọrundun kìn-ín-ní?
16 Jehofa sọ fun Awọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ pe: “Ẹyin eniyan yoo nilati mọ̀ pe emi wà laaarin Isirẹli [tẹmi], ati pe emi ni Jehofa Ọlọrun yin kò sì sí ẹlomiran.” (Joẹli 2:27) Awọn eniyan rẹ̀ wá sinu ìgbádùn ìmúṣẹ ṣiṣeyebiye yii nigba ti Jehofa bẹrẹ sii mu awọn ọrọ rẹ̀ ni Joẹli 2:28, 29 (NW) ṣẹ pe: “Ó gbọdọ ṣẹlẹ pe emi yoo tú ẹmi mi dà sori oriṣi ẹran-ara gbogbo, ati awọn ọmọkunrin rẹ ati awọn ọmọbinrin rẹ yoo sọtẹlẹ dajudaju.” Eyi ṣẹlẹ ni Pẹntikọsi 33 C.E., nigba ti a fami ororo yan awọn ọmọ-ẹhin Jesu ti wọn péjọ “wọn sì kún fun ẹmi mimọ.” Ni agbara ẹmi mimọ, wọn waasu, ati ni ọjọ kanṣoṣo naa, “ìwọ̀n ẹgbẹẹdogun kún wọn.”—Iṣe 2:4, 16, 17, 41.
17 Ni akoko alayọ yẹn, Peteru tun ṣayọlo ọrọ Joẹli 2:30-32 (NW) pe: “Emi yoo sì funni ni awọn apẹẹrẹ ìyanu ninu awọn ọ̀run ati lori ilẹ̀-ayé, ẹ̀jẹ̀ ati iná ati ọwọ̀n èéfín. Oòrùn funraarẹ ni a o yipada di okunkun, ati oṣupa sí ẹ̀jẹ̀, ṣaaju dídé ọjọ ńlá ati amuni kun fun ẹ̀rù ti Jehofa. Ó sì gbọdọ ṣẹlẹ pe olukuluku ẹni ti ó ba képe orukọ Jehofa yoo móríbọ́ laisewu.” Awọn ọrọ wọnni ní imuṣẹ ní apákan nigba ti a pa Jerusalẹmu run ni 70 C.E.
18. Nigba wo ni imuṣẹ titobi ju ti Joẹli 2:28, 29 bẹrẹ sii ṣẹlẹ?
18 Bi o ti wu ki o ri, ifisilo siwaju sii ti Joẹli 2:28-32 yoo wà. Nitootọ, asọtẹlẹ yii ti ní imuṣẹ pípẹtẹrí lati September 1919. Ni akoko yẹn apejọpọ manigbagbe ti awọn eniyan Jehofa ni a ṣe ni Cedar Point, Ohio, U.S.A. Ẹmi Ọlọrun farahan kedere, awọn iranṣẹ rẹ̀ ẹni ami ororo ni a sì ru soke lati kówọnú ìgbétáásì ijẹrii yika ayé ti ó nasẹ dé ọjọ oni. Igbooro ńláǹlà wo ni ó ti yọrisi! Iye ti ó ju 7,000 ti wọn wà nibẹ ni apẹjọpọ Cedar Point yẹn ti dagba di àròpọ̀ 10,650,158 ti wọn wá si Iṣe-Iranti iku Jesu ni March 30, 1991. Lara awọn wọnyi, kìkì 8,850 jẹwọ jíjẹ́ awọn Kristẹni ẹni ami ororo. Ayọ gbogbo awọn wọnyi ti pọ tó lati rí eso tí ẹmi alagbara iṣẹ́ ti Jehofa mú jade wa yika ayé!—Aisaya 40:29, 31.
19. Ni oju-iwoye isunmọtosi ọjọ Jehofa, ki ni ó gbọdọ jẹ́ iṣarasihuwa ẹnikọọkan wa?
19 Gan-an ni iwaju ni “dídé ọjọ ńlá ati amuni kun fun ẹ̀rù ti Jehofa” ti yoo sọ eto igbekalẹ awọn nǹkan Satani dahoro wà. (Joẹli 2:31, NW) Lọna ti ó muni layọ, “olukuluku ẹni ti ó bá ké pe orukọ Jehofa ni a o gbàlà.” (Iṣe 2:21, NW) Bawo ni o ṣe rí bẹẹ? Apọsiteli Peteru sọ fun wa pe “ọjọ Oluwa [“Jehofa,” NW] ń bọ̀ wá bi olè” ó sì fikun un pe: “Ǹjẹ́ bi gbogbo nǹkan wọnyi yoo ti yọ́ nì, iru eniyan wo ni ẹyin ìbá jẹ́ ninu ìwà mimọ gbogbo ati iwa-bi-Ọlọrun, ki ẹ maa reti, ki ẹ sì maa mura giri de dídé ọjọ Ọlọrun.” Ni fifi sọ́kàn pe ọjọ Jehofa sunmọle, awa yoo yọ̀ pẹlu lati ri imuṣẹ ileri Jehofa nipa “ọ̀run titun ati ayé titun” ododo.—2 Peteru 3:10-13.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a La Repubblica, Rome, Italy, November 12, 1985 ati La rivista del clero italiano, May 1985.
Iwọ Ha Lè Ṣalaye Bi?
◻ Ki ni “ọjọ Jehofa”?
◻ Bawo ni Jesu yoo ṣe kórè ‘àjàrà ilẹ̀-ayé,’ eesitiṣe?
◻ Ni ọ̀nà wo ni ìyọnu eéṣú ti gbà pọ́n Kristẹndọmu loju lati 1919 wá?
◻ Bawo ni a ṣe tú ẹmi Jehofa jade sori awọn eniyan rẹ̀ ni 33 C.E., ati lẹẹkan sii ni 1919?