Ọjọ́ Jèhófà Sún Mọ́lé
“Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin àgbà ọkùnrin, kí ẹ sì fi etí sí i, gbogbo ẹ̀yin olùgbé ilẹ̀ náà.”—JÓẸ́LÌ 1:2.
1, 2. Nítorí ipò wo ní Júdà ni Jèhófà ṣe mí sí Jóẹ́lì láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ lílágbára?
“PÁGÀ fún ọjọ́ náà; nítorí ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé, yóò sì dé gẹ́gẹ́ bí ìfiṣèjẹ láti ọ̀dọ̀ Ẹni tí í ṣe Olódùmarè!” Ẹ wo irú ìkéde amúnijígìrì tí èyí jẹ́! Iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán sí àwọn ènìyàn rẹ̀, tí wòlíì rẹ̀, Jóẹ́lì, jẹ́ ni.
2 Júdà ni a ti ṣàkọsílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú Jóẹ́lì 1:15 wọ̀nyẹn, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ní nǹkan bí ọdún 820 ṣááju Sànmánì Tiwa. Àwọn òkè eléwéko tútù yọ̀yọ̀ mú kí ilẹ̀ náà lẹ́wà nígbà náà. Èso àti ọkà pọ̀ yanturu. Àwọn pápá oko fẹ̀, wọ́n sì tutù yọ̀yọ̀. Síbẹ̀, nǹkan kan ń ṣẹlẹ̀. Ìjọsìn Báálì gbilẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù àti ní ilẹ̀ Júdà. Àwọn ènìyàn ibẹ̀ kó wọnú àṣà ìmutípara níwájú ọlọ́run èké yìí. (Fi wé 2 Kíróníkà 21:4-6, 11.) Jèhófà yóò ha jẹ́ kí gbogbo èyí máa bá a lọ bí?
3. Kí ni Jèhófà kìlọ̀ nípa rẹ̀, kí sì ni àwọn orílẹ̀-èdè ní láti múra fún?
3 Ìwé Jóẹ́lì nínú Bíbélì mú kí ìdáhùn rẹ̀ ṣe kedere. Jèhófà Ọlọ́run yóò dá ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ láre, yóò sì ya orúkọ mímọ́ rẹ̀ sí mímọ́. Ọjọ́ ńlá Jèhófà ti sún mọ́lé. Ọlọ́run yóò wá mú ìdájọ́ ṣẹ lórí gbogbo orílẹ̀-èdè ní “pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti Jèhóṣáfátì.” (Jóẹ́lì 3:12) Ẹ jẹ́ kí wọ́n múra sílẹ̀ láti bá Ẹni tí í ṣe Olódùmarè, Jèhófà, jagun. Àwa pẹ̀lú ń dojú kọ ọjọ́ ńlá Jèhófà. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ asọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì fún ọjọ́ wa àti ìgbà tí ó ti kọjá ní kínníkínní.
Ìjẹlẹ̀run Àwọn Kòkòrò
4. Báwo ni ìṣẹ̀lẹ̀ tí Jóẹ́lì kìlọ̀ rẹ̀ yóò ṣe tóbi tó?
4 Jèhófà tẹnu wòlíì rẹ̀ sọ pé: “Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yin àgbà ọkùnrin, kí ẹ sì fi etí sí i, gbogbo ẹ̀yin olùgbé ilẹ̀ náà. Èyí ha ti ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọjọ́ yín bí, tàbí ní ọjọ́ àwọn baba ńlá yín pàápàá? Ẹ ṣèròyìn rẹ̀ fún àwọn ọmọ yín, àti àwọn ọmọ yín fún àwọn ọmọ wọn, àti àwọn ọmọ wọn fún ìran tí ó tẹ̀ lé e.” (Jóẹ́lì 1:2, 3) Àwọn àgbààgbà àti gbogbo àwọn ènìyàn náà lè retí ohun kan tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí láti ìgbà tí wọ́n ti dáyé tàbí ní ọjọ́ àwọn baba ńlá wọn. Yóò jẹ́ ohun àrà ọ̀tọ̀ débi tí a óò fi sọ nípa rẹ̀ fún ìran kẹta! Kí ni ìṣẹ̀lẹ̀ arabaríbí yìí? Láti mọ̀ ọ́n, ẹ jẹ́ kí a finú wòye pé a wà ní ọjọ́ Jóẹ́lì.
5, 6. (a) Ṣàpèjúwe ìyọnu àjàkálẹ̀ tí Jóẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀. (b) Ta ni Orísun ìyọnu àjàkálẹ̀ náà?
5 Ẹ fetí sílẹ̀! Jóẹ́lì gbọ́ ìbúramúramù kan láti ọ̀nà jíjìn. Àwọsánmà ṣókùnkùn, ìró bíbanilẹ́rù yẹn sì ń pọ̀ sí i bí òkùnkùn náà ti ń bo òfuurufú. Lẹ́yìn náà, ìkùukùu tí ó jọ èéfín ń bọ̀ nílẹ̀. Ogunlọ́gọ̀ kòkòrò tí iye wọn jẹ́ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ni. Ẹ sì wo irú ìparundahoro tí wọ́n fà! Nísinsìnyí, gbé Jóẹ́lì 1:4 yẹ̀ wò. Àwọn kòkòrò ajẹlẹ̀run wọ̀nyí kì í ṣe eéṣú abìyẹ́ tí ń ṣí kiri nìkan. Rárá o! Ọ̀wọ́ àwọn eéṣú tí kò níyẹ̀ẹ́, tí ń rákò, tí ebi ń pa, ń bọ̀ pẹ̀lú. Àwọn eéṣú tí afẹ́fẹ́ gbé wá náà dé lójijì, ìró wọn sì jọ ti àwọn kẹ̀kẹ́ ogun. (Jóẹ́lì 2:5) Nítorí ìjẹwọ̀mùwọ̀mù wọn, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ wọn lè yára sọ párádísè di aginjù.
6 Àwọn mìíràn tí wọ́n wà lórí ìrìn ni àwọn kòkòrò wùkúwùkú—ìdin àfòpiná tàbí ti labalábá. Wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ ni ogunlọ́gọ̀ kòkòrò wùkúwùkú tí ebi ń pa yóò jẹ gbogbo ewé ohun ọ̀gbìn tán, bẹ̀rẹ̀ láti orí ewé kọ̀ọ̀kan, títí àwọn irúgbìn yóò fi fẹ́rẹ̀ẹ́ máà léwé kankan lórí mọ́. Ohun tí wọ́n bá sì ṣẹ́ kù, ni àwọn eéṣú yóò jẹ. Ohun tí eéṣú sì ṣẹ́ kù, ni àwọn aáyán ayára-bí-àṣá yóò jẹ láìkù kan. Ṣùgbọ́n, kíyè sí èyí: Nínú Jóẹ́lì orí 2, ẹsẹ 11, Ọlọ́run pe ogunlọ́gọ̀ eéṣú ní “ẹgbẹ́ ológun rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni, òun ni Orísun ìyọnu àjàkálẹ̀ eéṣú tí yóò sọ ilẹ̀ náà dahoro, tí yóò sì ṣokùnfà ìyàn líle koko. Nígbà wo? Ní kété ṣáájú “ọjọ́ Jèhófà.”
“Ẹ Jí, Ẹ̀yin Ọ̀mùtípara”!
7. (a) Kí ni ipò àwọn aṣáájú ìsìn ní Júdà? (b) Báwo ni àwọn aṣáájú ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù lónìí ṣe wà nínú irú ipò kan náà tí àwọn aṣáájú ìsìn ní Júdà wà?
7 A dá àwùjọ ènìyàn kan tí kò ní ìfùsì rere, àwọn aṣáájú ìsìn ní Júdà yọ sọ́tọ̀ nígbà tí a pàṣẹ pé: “Ẹ jí, ẹ̀yin ọ̀mùtípara, kí ẹ sì sunkún; kí ẹ sì hu, gbogbo ẹ̀yin olùmu wáìnì, ní tìtorí wáìnì dídùn, nítorí a ti ké e kúrò ní ẹnu yín.” (Jóẹ́lì 1:5) Bẹ́ẹ̀ ni, a sọ fún àwọn ọ̀mùtípara nípa tẹ̀mí ní Júdà láti “jí,” kí ojú wọn dá. Ṣùgbọ́n má ṣe rò pé ìtàn ìgbàanì kan lásán ni èyí jẹ́. Ní báyìí, kí ọjọ́ ńlá Jèhófà tó dé, àwùjọ àlùfáà Kirisẹ́ńdọ̀mù ti mu wáìnì dídùn yó kẹ́ri lọ́nà àfiṣàpèjúwe, débi pé agbára káká ni ojú wọn fi dá láti gbọ́ nípa àṣẹ tí ó ti ọ̀dọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ náà wá. Ẹ wo bí yóò ti yà wọ́n lẹ́nu tó tí ọjọ́ ńlá àti amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà bá mú kí ọtí tí ó ti sọ wọ́n di arìndìn dá mọ́ wọn lójú!
8, 9. (a) Báwo ni Jóẹ́lì ṣe ṣàpèjúwe àwọn eéṣú àti àbájáde ìyọnu àjàkálẹ̀ tí wọ́n dá sílẹ̀? (b) Lónìí, àwọn wo ni àwọn eéṣù náà ṣàpẹẹrẹ?
8 Ẹ wo ogunlọ́gọ̀ ńlá eéṣú yẹn! “Orílẹ̀-èdè kan wà tí ó gòkè wá sí ilẹ̀ mi, alágbára ńlá ni, kò sì níye. Eyín kìnnìún ni eyín rẹ̀, ó sì ní àwọn egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ kìnnìún. Ó ti sọ àjàrà mi di ohun ìyàlẹ́nu, ó sì ti sọ igi ọ̀pọ̀tọ́ mi di kùkùté. Títú ni ó tú u sí borokoto, ó sì gbé e sọ nù. Àwọn ẹ̀ka igi rẹ̀ ti di funfun. Pohùn réré ẹkún, gẹ́gẹ́ bí wúńdíá tí ó sán aṣọ àpò ìdọ̀họ ti máa ń ṣe lórí olúwa ìgbà èwe rẹ̀.”—Jóẹ́lì 1:6-8.
9 Èyí ha wulẹ̀ jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa àwọn eéṣú tí wọ́n jẹ́ “orílẹ̀-èdè kan,” tí wọ́n kógun ti Júdà bí? Rárá, ó ju ìyẹn lọ. Nínú Jóẹ́lì 1:6 àti Ìṣípayá 9:7, àwọn eéṣú náà ṣàpẹẹrẹ àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Ẹgbẹ́ ológun ti àwọn eéṣú ẹni àmì òróró Jèhófà, tí àwọn bí 5,600,000 “àwọn àgùntàn mìíràn” Jésù dara pọ̀ mọ́, ni ogunlọ́gọ̀ eéṣú ti òde òní. (Jòhánù 10:16) Ìwọ kò ha láyọ̀ láti wà lára ẹgbẹ́ tìrìgàngàn ti àwọn olùjọ́sìn Jèhófà yìí bí?
10. Kí ni ipa tí ìyọnu àjàkálẹ̀ eéṣú náà ní lórí Júdà?
10 A kà nínú Jóẹ́lì 1:9-12 nípa ìyọnu àjàkálẹ̀ tí àwọn eéṣú náà mú wá. Ọ̀wọ́ tìrìgàngàn kan lẹ́yìn òmíràn sọ ilẹ̀ náà di ahoro pátápátá. Bí àwọn àlùfáà aláìṣòótọ́ náà kò ti ní ọkà, wáìnì, àti òróró mọ́, wọn kò lè máa bá iṣẹ́ wọn lọ. Kódà ilẹ̀ pàápàá ṣọ̀fọ̀, nítorí pé àwọn eéṣú náà jẹ ọkà inú rẹ̀ run, wọ́n sì jẹ èso orí àwọn igi eléso tán. Níwọ̀n bí wọ́n ti run àwọn ọgbà àjàrà, kò sí wáìnì fún àwọn olùjọ́sìn Báálì tí ń mu wáìnì ní àmuyíràá, tí wọ́n sì jẹ́ ọ̀mùtípara nípa tẹ̀mí.
‘Ẹ Lu Igẹ̀ Yín, Ẹ̀yin Àlùfáà’
11, 12. (a) Àwọn wo ni wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ àlùfáà Ọlọ́run lónìí? (b) Báwo ni ìyọnu àjàkálẹ̀ eéṣú ti òde òní ṣe nípa lórí àwọn aṣáájú ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù?
11 Ẹ gbọ́ iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán sí àwọn àlùfáà aṣetinúuwọn wọ̀nyẹn: “Ẹ di ara yín lámùrè, kí ẹ sì lu igẹ̀ yín, ẹ̀yin àlùfáà. Ẹ hu, ẹ̀yin òjíṣẹ́ pẹpẹ.” (Jóẹ́lì 1:13) Nínú ìmúṣẹ àkọ́kọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì, àwọn àlùfáà Léfì ṣiṣẹ́ nídìí pẹpẹ. Ṣùgbọ́n nínú ìmúṣẹ àṣekágbá ńkọ́? Lónìí, àwùjọ àlùfáà Kirisẹ́ńdọ̀mù ti gbé ọlá àṣẹ wọ̀ láti ṣiṣẹ́ nídìí pẹpẹ Ọlọ́run, wọ́n ń sọ pé òjíṣẹ́ rẹ̀ ni àwọn, “àlùfáà” rẹ̀. Ṣùgbọ́n, kí ní ń ṣẹlẹ̀ nísinsìnyí tí àwọn eéṣú Ọlọ́run ti òde òní fi ń tẹ̀ síwájú?
12 Nígbà tí àwọn “àlùfáà” Kirisẹ́ńdọ̀mù rí àwọn ènìyàn Jèhófà lẹ́nu iṣẹ́, tí wọ́n sì ń gbọ́ ìkìlọ̀ wọn nípa ìdájọ́ àtọ̀runwá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sá kìtàkìtà. Wọ́n lu igẹ̀ wọn tìbínútìbínú àti tìrunútìrunú nítorí àbájáde apanirun tí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà mú wá. Wọ́n sì ń hu bí àwọn agbo wọn ṣe ń padà lẹ́yìn wọn. Nítorí pé àwọn pápá oko wọn ń ṣófo, ẹ jẹ́ kí wọ́n lo òru náà nínú aṣọ ọ̀fọ̀, kí wọ́n máa ṣọ̀fọ̀ nítorí pípàdánù ohun tí ń wọlé wá fún wọn. Láìpẹ́, iṣẹ́ yóò bọ́ lọ́wọ́ wọn pẹ̀lú! Ní gidi, Ọlọ́run wí fún wọn láti ṣọ̀fọ̀ ní gbogbo òru nítorí pé òpin wọn sún mọ́lé.
13. Gbogbo Kirisẹ́ńdọ̀mù lápapọ̀ yóò ha dáhùn padà lọ́nà rere sí ìkìlọ̀ Jèhófà bí?
13 Gẹ́gẹ́ bí Jóẹ́lì 1:14 ti wí, ìrètí kan ṣoṣo tí wọ́n ní ni láti ronú pìwà dà, kí wọ́n sì kígbe “sí Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́.” A ha lè retí pé kí gbogbo ẹgbẹ́ àwùjọ àlùfáà Kirisẹ́ńdọ̀mù yíjú sí Jèhófà bí? A kò lè retí rẹ̀ rárá! Àwọn kọ̀ọ̀kan lára wọn lè kọbi ara sí ìkìlọ̀ Jèhófà. Ṣùgbọ́n ebi tẹ̀mí tí ń pa àwọn aṣáájú ìsìn wọ̀nyí àti àwọn ọmọ ìjọ wọn, gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan, yóò máa bá a lọ. Wòlíì Ámósì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “‘Wò ó! Àwọn ọjọ́ ń bọ̀,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ‘èmi yóò sì rán ìyàn sí ilẹ̀ náà dájúdájú, ìyàn, tí kì í ṣe fún oúnjẹ, àti òùngbẹ, tí kì í ṣe fún omi, bí kò ṣe fún gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.” (Ámósì 8:11) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ẹ wo bí a ti kún fún ìmoore tó fún oúnjẹ tẹ̀mí dídọ́ṣọ̀ tí Ọlọ́run ń pèsè fún wa lọ́nà onífẹ̀ẹ́ nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye”!—Mátíù 24:45-47.
14. Kí ni ìyọnu àjàkálẹ̀ eéṣú náà ń ṣàpẹẹrẹ?
14 Ìyọnu àjàkálẹ̀ eéṣú náà ń ṣàpẹẹrẹ ohun kan nígbà náà àti nísinsìnyí. Kí ni ó ń ṣàpẹẹrẹ? Jóẹ́lì sọ ohun tí ó jẹ́ fún wa ní kedere, ó wí pé: “Págà fún ọjọ́ náà; nítorí ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé, yóò sì dé gẹ́gẹ́ bí ìfiṣèjẹ láti ọ̀dọ̀ Ẹni tí í ṣe Olódùmarè!” (Jóẹ́lì 1:15) Ìjẹlẹ̀run kárí ayé tí ogunlọ́gọ̀ eéṣú Ọlọ́run ń ṣe lónìí fi hàn kedere pé ọjọ́ ńlá àti amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà ti sún mọ́lé. Dájúdájú, gbogbo ọlọ́kàn títọ́ ń yán hànhàn fún ọjọ́ ìjíhìn àkànṣe yẹn, nígbà tí a óò mú ìdájọ́ Ọlọ́run ṣẹ sórí àwọn ẹni búburú, tí Jèhófà yóò sì di aṣẹ́gun gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ Àgbáyé.
15. Lójú ìwòye ipò ìsọdahoro tí ilẹ̀ náà wà, báwo ni àwọn tí ó kọbi ara sí ìkìlọ̀ Ọlọ́run ṣe hùwà padà?
15 Gẹ́gẹ́ bí Jóẹ́lì 1:16-20 ṣe fi hàn, a fòpin sí ìpèsè oúnjẹ ní Júdà ìgbàanì. Bákan náà ni a fòpin sí ipò ìdùnnú. Àwọn ibi tí a ń kó oúnjẹ sí dahoro, a sì ní láti wó àwọn abà palẹ̀. Níwọ̀n bí àwọn màlúù kò ti ní pápá tí wọn yóò ti máa jẹko mọ́, nítorí pé àwọn eéṣú ti jẹ ewéko ilẹ̀ náà tán, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí rìn gbéregbère kiri, àwọn agbo àgùntàn sì pa run. Ẹ wo irú àjálù ńlá tí èyí jẹ́! Nínú irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀, kí ní ṣẹlẹ̀ sí Jóẹ́lì? Ní ìbámu pẹ̀lú ẹsẹ 19, ó wí pé: “Ìwọ, Jèhófà, ni èmi yóò ké pè.” Bákan náà, lónìí, ọ̀pọ̀ ń ṣègbọràn sí ìkìlọ̀ àtọ̀runwá, wọ́n sì ń fi ìgbàgbọ́ kígbe pe Jèhófà Ọlọ́run.
“Ọjọ́ Jèhófà Ń Bọ̀”
16. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí ṣìbáṣìbo bá “àwọn olùgbé ilẹ̀ náà”?
16 Gbọ́ àṣẹ yìí tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run pé: “Ẹ fun ìwo ní Síónì, ẹ̀yin ènìyàn, kí ẹ sì kígbe ogun ní òkè ńlá mímọ́ mi. Kí ṣìbáṣìbo bá gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ náà.” (Jóẹ́lì 2:1) A ṣe ní láti hùwà padà lọ́nà yẹn? Àsọtẹ́lẹ̀ náà dáhùn pé: “Nítorí ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀, nítorí ó sún mọ́lé! Ọjọ́ òkùnkùn àti ìṣúdùdù ni, ọjọ́ àwọsánmà àti ìṣúdùdù tí ó nípọn, gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ ọ̀yẹ̀ tí ó tàn ká orí àwọn òkè ńlá.” (Jóẹ́lì 2:1, 2) A so èrò ìjẹ́kánjúkánjú gidi mọ́ ọjọ́ ńlá Jèhófà.
17. Báwo ni ìyọnu àjàkálẹ̀ eéṣú ṣe nípa lórí ilẹ̀ àti àwọn ènìyàn Júdà?
17 Finú wòye ipa tí ìran tí wòlíì náà rí ń ní bí àwọn eéṣú aláìdẹwọ́ náà ti ń sọ ojúlówó ọgbà Édẹ́nì dahoro. Tẹ́tí sí bí a ṣe ṣàpèjúwe ogunlọ́gọ̀ eéṣú náà: “Ìrísí rẹ̀ dà bí ìrísí àwọn ẹṣin, àti bí àwọn ẹṣin ogun ni bí wọ́n ti ń sáré. Bí ìró àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin lórí àwọn òkè ńlá ni wọ́n ń tọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri, bí ìró iná ajófòfò tí ń jẹ àgékù pòròpórò run. Ó dà bí àwọn ènìyàn alágbára ńlá, tí ó tẹ́ ìtẹ́gun. Nítorí rẹ̀, àwọn ènìyàn yóò jẹ ìrora mímúná. Ní ti gbogbo ojú, dájúdájú, wọn yóò ràn koko fún ìdààmú.” (Jóẹ́lì 2:4-6) Nígbà ìyọnu àjàkálẹ̀ eéṣú tí ó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ Jóẹ́lì, làásìgbò tó bá àwọn olùjọ́sìn Báálì di púpọ̀, a sì ri lójú wọn pé wọ́n wà nínú hílàhílo.
18, 19. Báwo ni ìgbòkègbodò àwọn ènìyàn Ọlọ́run lónìí ṣe dàbí ti ìyọnu àjàkálẹ̀ eéṣú?
18 Ohunkóhun kò dá àwọn eéṣú tí kì í ṣàárẹ̀, tí wọ́n wà létòlétò náà dúró. Wọ́n sáré “bí àwọn ọkùnrin alágbára,” wọ́n tilẹ̀ ń gun ògiri pàápàá. Bí ‘àwọn kan lára wọn bá tilẹ̀ ṣubú sáàárín àwọn ohun ọṣẹ́, àwọn yòókù kì yóò yà kúrò ní ipa ọ̀nà.’ (Jóẹ́lì 2:7, 8) Ẹ wo irú ìtọ́kasí alásọtẹ́lẹ̀ ṣíṣe kedere nípa ogunlọ́gọ̀ eéṣú ìṣàpẹẹrẹ ti Ọlọ́run lóde òní tí èyí jẹ́! Bákan náà, lónìí, ogunlọ́gọ̀ eéṣú Jèhófà ń tẹ̀ síwájú ní tààrà. Kò sí “ògiri” àtakò tí ń dí wọn lọ́wọ́. Wọn kì í fi ìwà títọ́ wọn sí Ọlọ́run báni dọ́rẹ̀ẹ́, ṣùgbọ́n wọ́n múra tán láti kojú ikú, bí ti àràádọ́ta Àwọn Ẹlẹ́rìí tí ‘wọ́n ṣubú sáàárín àwọn ohun ọṣẹ́’ nítorí pé wọ́n kọ̀ láti kókìkí Hitler nígbà ìjọba Nazi ní Germany.
19 Ogunlọ́gọ̀ eéṣú Ọlọ́run ti òde òní ti jẹ́rìí kúnnákúnná nínú “ìlú ńlá” Kirisẹ́ńdọ̀mù. (Jóẹ́lì 2:9) Wọ́n ti ṣe bẹ́ẹ̀ jákèjádò ayé. Síbẹ̀ wọ́n ṣì ń borí gbogbo ìdènà, wọ́n ń wọ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ilé, wọ́n ń tọ àwọn ènìyàn lọ ní òpópónà, wọ́n ń bá wọn sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù, wọ́n sì ń kàn sí wọn ní ọ̀nà èyíkéyìí tí ó bá ṣeé ṣe, bí wọ́n ti ń polongo ìhìn iṣẹ́ Jèhófà. Ní gidi, wọ́n ti pín àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ìtẹ̀jáde Bíbélì, wọn yóò sì pín púpọ̀ púpọ̀ si nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn tí kì í dáwọ́ dúró—ní gbangba àti láti ilé dé ilé.—Ìṣe 20:20, 21.
20. Ta ní ń ti àwọn eéṣú òde òní lẹ́yìn, kí sì ni ó yọrí sí?
20 Jóẹ́lì 2:10 fi hàn pé ọ̀wọ́ àwọn eéṣú púpọ̀ kan dà bí ìkùukùu tí ó lè dí oòrùn, òṣùpá, àti ìràwọ̀ lójú. (Fi wé Aísáyà 60:8.) Iyèméjì kan ha wà nípa ẹni tí ń ti ẹgbẹ́ ológun yìí lẹ́yìn bí? Yàtọ̀ sí ariwo àwọn kòkòrò náà, a gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí ó bo ariwo náà mọ́lẹ̀ tí ó wà nínú Jóẹ́lì 2:11 pé: “Jèhófà alára yóò sì fọ ohùn rẹ̀ níwájú ẹgbẹ́ ológun rẹ̀ dájúdájú, nítorí ibùdó rẹ̀ pọ̀ níye gan-an. Nítorí alágbára ńlá ni ẹni tí ń mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ; nítorí pé ọjọ́ Jèhófà tóbi, ó sì jẹ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù gan-an, ta sì ni ó lè dúró lábẹ́ rẹ̀?” Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà Ọlọ́run ń rán ẹgbẹ́ ológun rẹ̀ ti eéṣú jáde nísinsìnyí—kí ọjọ́ ńlá rẹ̀ tó dé.
“Jèhófà Kò Fi Nǹkan Falẹ̀”
21. Kí ni yóò jẹ́ ìyọrísí rẹ̀ nígbà tí ‘ọjọ́ Jèhófà bá dé gẹ́gẹ́ bí olè’?
21 Bí Jóẹ́lì, àpọ́sítélì Pétérù sọ nípa ọjọ́ ńlá Jèhófà. Ó kọ̀wé pé: “Ọjọ́ Jèhófà yóò dé gẹ́gẹ́ bí olè, nínú èyí tí àwọn ọ̀run yóò kọjá lọ pẹ̀lú ariwo tí ó dún ṣì-ì-ì, ṣùgbọ́n àwọn ohun ìpìlẹ̀ tí ó ti gbóná janjan yóò di yíyọ́, ilẹ̀ ayé àti àwọn iṣẹ́ tí ń bẹ nínú rẹ̀ ni a ó sì wá rí.” (2 Pétérù 3:10) Lábẹ́ ìdarí Sátánì Èṣù, “àwọn ọ̀run” ti ìjọba búburú, ń ṣàkóso “ilẹ̀ ayé,” ìyẹn ni, aráyé tí a sọ dàjèjì sí Ọlọ́run. (Éfésù 6:12; 1 Jòhánù 5:19) Àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé ìṣàpẹẹrẹ yìí kì yóò la ooru gbígbóná janjan ti ìbínú Ọlọ́run tí yóò wáyé ní ọjọ́ ńlá Jèhófà já. Kàkà bẹ́ẹ̀, a óò fi ‘ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, tí òdodo yóò máa gbé,’ rọ́pò wọn.—2 Pétérù 3:13.
22, 23. (a) Báwo ni ó ṣe yẹ kí a hùwà padà sí fífi tí Jèhófà fi sùúrù hàn? (b) Báwo ni ó ṣe yẹ kí a hùwà padà sí ìsúnmọ́lé ọjọ́ Jèhófà?
22 Pẹ̀lú gbogbo ìpínyà ọkàn àti ìdánwò ìgbàgbọ́ tí ó wà lóde òní, a lè gbójú fo ìjẹ́kánjúkánjú àkókò wa. Ṣùgbọ́n bí àwọn eéṣú ìṣàpẹẹrẹ náà ti ń tẹ̀ síwájú, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń dáhùn padà sí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run yọ̀ǹda èyí, a kò gbọ́dọ̀ ṣi sùúrù rẹ̀ lóye sí ìfi-nǹkan-falẹ̀. “Jèhófà kò fi nǹkan falẹ̀ ní ti ìlérí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn kan ti ka ìfi-nǹkan-falẹ̀ sí, ṣùgbọ́n ó ń mú sùúrù fún yín nítorí pé kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.”—2 Pétérù 3:9.
23 Bí a ti ń dúró de ọjọ́ ńlá Jèhófà, ẹ jẹ́ kí a fi ọ̀rọ̀ Pétérù, tí a ṣàkọsílẹ̀ nínú 2 Pétérù 3:11, 12 sọ́kàn, pé: “Níwọ̀n bí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ti di yíyọ́ báyìí, irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ jẹ́ nínú ìṣe ìwà mímọ́ àti àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run, ní dídúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà àti fífi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí, nípasẹ̀ èyí tí àwọn ọ̀run tí wọ́n ti gbiná yóò di yíyọ́, tí àwọn ohun ìpìlẹ̀ tí ó ti gbóná janjan yóò sì yọ́!” Dájúdájú, àwọn ìṣe àti ìwà wọ̀nyí kan kí a máa bá a nìṣó pẹ̀lú ogunlọ́gọ̀ eéṣú ti Jèhófà nípa níní ìpín tí ó nítumọ̀, tí ó sì ṣe déédéé nínú wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà kí òpin tó dé.—Máàkù 13:10.
24, 25. (a) Báwo ni o ṣe dáhùn padà sí àǹfààní nínípìn-ín nínú iṣẹ́ ogunlọ́gọ̀ eéṣú ti Jèhófà? (b) Ìbéèrè tí ó nítumọ̀ wo ni Jóẹ́lì gbé dìde?
24 Ogunlọ́gọ̀ eéṣú ti Ọlọ́run kì yóò dáwọ́ iṣẹ́ wọn dúró títí ọjọ́ ńlá àti amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà yóò fi dé. Wíwà tí ẹgbẹ́ ogun eéṣú tí a kò lè dá dúró wọ̀nyí wà jẹ́ ẹ̀rí tí ó gbàfiyèsí pé ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé. Inú rẹ kò ha dùn láti sìn láàárín àwọn eéṣú Ọlọ́run tí a fòróró yàn àti àwọn alájọṣepọ̀ wọn nínú ìkọlù àṣekágbá náà ṣáájú kí ọjọ́ ńlá àti amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà tó dé bí?
25 Ẹ wo bí ọjọ́ Jèhófà yóò ti tóbi tó! Abájọ tí ìbéèrè náà fi dìde pé: ‘Ta ni ó lè dúró lábẹ́ rẹ̀?’ (Jóẹ́lì 2:11) A óò gbé ìbéèrè yìí àti ọ̀pọ̀ mìíràn yẹ̀ wò nínú àwọn àpilẹ̀kọ méjì tí ó tẹ̀ lé e.
Ìwọ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?
◻ Èé ṣe tí Jèhófà fi kìlọ̀ nípa ìyọnu àjàkálẹ̀ kòkòrò lórí Júdà?
◻ Nínú ìmúṣẹ òde òní ti àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì, àwọn wo ni eéṣú Jèhófà?
◻ Báwo ni àwọn aṣáájú Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣe dàhún padà sí ìyọnu àjàkálẹ̀ eéṣú, báwo sì ni díẹ̀ lára wọ́n ṣe lè yè bọ́ nínú àbájáde rẹ̀?
◻ Báwo ni ìyọnu àjàkálẹ̀ eéṣú náà ti gbòòrò tó ní ọ̀rúndún ogun yìí, yóò sì máa bá a lọ títí di ìgbà wo?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ìyọnu àjàkálẹ̀ kòkòrò ń ṣàpẹẹrẹ ohun tí ó tilẹ̀ tún burú ju ti ìṣáájú lọ
[Credit Line]
Igi aláìléwé: Fọ́tò FAO/G. Singh
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Jèhófà Ọlọ́run ni ó wà nídìí ìyọnu àjàkálẹ̀ eéṣú òde òní
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 8]
Eéṣú: Fọ́tò FAO/G. Tortoli; ọ̀wọ́ eéṣú: Fọ́tò FAO/Desert Locust Survey