ORÍ KẸRIN
Jèhófà—Ọlọ́run Tó Ń sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Tó Sì Ń mú Àsọtẹ́lẹ̀ Ṣẹ
1, 2. (a) Kí ló lè mú káwọn kan rò pé kò sẹ́nì kankan tó ń darí ọ̀ràn ọmọ aráyé? (b) Irú ẹni wo làwọn wòlíì méjìlá náà fi hàn pé Jèhófà jẹ́?
Ó MÁA ń ṣe ọ̀pọ̀ èèyàn bíi pé ọ̀rọ̀ ìgbésí ayé wọn ti ń lọ síbi tí wọn ò ti ní lè ṣe àtúnṣe kankan sí i. Bákan náà ni ìròyìn tí wọn máa ń gbọ́ mú kí wọ́n parí èrò sí pé ńṣe ni ipò ìran èèyàn túbọ̀ ń burú sí i. Ó wá dà bíi pé ńṣe ni gbogbo ìgbìyànjú láti mú ìṣòro ayé kúrò túbọ̀ ń dá kún ìṣòro ọ̀hún. Ìdí rèé tó fi yẹ ká mọ̀ pé àwọn kan lára àwọn wòlíì méjìlá náà ní irú àwọn àníyàn tá a ní lónìí, wọ́n sì jíṣẹ́ tó ń fúnni nírètí, èyí tá a lè jàǹfààní nínú rẹ̀ tá a sì lè fi tu àwọn ẹlòmíràn nínú.—Míkà 3:1-3; Hábákúkù 1:1-4.
2 Kókó pàtàkì kan tí wàá rí nínú àwọn ìwé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ni pé, ọwọ́ Jèhófà, Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run, ni àṣẹ dídarí ọ̀ràn ọmọ aráyé wà, ó sì fẹ́ kó dáa fún wa. Kódà, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló lè sọ ọ́ mọ́ ara rẹ̀ pé: “Jèhófà fẹ́ kó dáa fún mi.” Àwọn wòlíì méjìlá náà ṣàpèjúwe “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun” lọ́nà tó fani lọ́kàn mọ́ra. Kò ṣòro fún Ọlọ́run láti ‘fọwọ́ kan ilẹ̀ kí ilẹ̀ sì yọ́,’ síbẹ̀, ó fi dá àwọn èèyàn rẹ̀ lójú pé: “Ẹni tí ó bá fọwọ́ kàn yín ń fọwọ́ kan ẹyinjú mi.” (Sekaráyà 2:8; Ámósì 4:13; 9:5) Ǹjẹ́ inú rẹ kì í dùn tó o bá ń ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ń jẹ́ kéèyàn mọ bí ìfẹ́ ṣe máa ń darí ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń bá èèyàn lò, àti bí Ọlọ́run ṣe máa ń fi àánú hàn tó sì máa ń dárí jini? (Hóséà 6:1-3; Jóẹ́lì 2:12-14) Òótọ́ ni pé àwọn ìwé táwọn wòlíì wọ̀nyí kọ kò sọ̀rọ̀ nípa gbogbo ànímọ́ Ọlọ́run; àfi kéèyàn rí gbogbo ìwé mẹ́rìndínláàádọ́rin tó wà nínú Bíbélì kó tó lè mọ gbogbo rẹ̀. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn ìwé méjìlá wọ̀nyí jẹ́ ká mọ àwọn ànímọ́ rere tí Ọlọ́run ní àti ọ̀nà dáadáa tó gbà ń báni lò.
3. Báwo làwọn wòlíì méjìlá náà ṣe fi hàn pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run tó máa ń mú àwọn ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ?
3 Ìwé àwọn wòlíì méjìlá náà lè mú ká túbọ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà pé ó jẹ́ Ẹni tó lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la àti pé ó jẹ́ Ẹni tó lè mú àwọn ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ láìkùnà. Wọ́n fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Jèhófà yóò mú kí ayé di Párádísè lábẹ́ àkóso àtọ̀runwá. (Míkà 4:1-4) Àwọn kan nínú àwọn wòlíì náà ṣàpèjúwe bí Jèhófà ṣe lànà sílẹ̀ fún dídé Mèsáyà àti bó ṣe lànà sílẹ̀ fún ìràpadà tí yóò mú kí aráyé bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Málákì 3:1; 4:5) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká mọ gbogbo èyí?
ỌWỌ́ ỌBA ALÁṢẸ TÓ JẸ́ ONÍFẸ̀Ẹ́ NI ÀṢẸ DÍDARÍ ÀWỌN NǸKAN WÀ
4, 5. (a) Òtítọ́ pàtàkì wo nípa Ọlọ́run làwọn wòlíì méjìlá náà tẹnu mọ́? (b) Ipa wo ni jíjẹ́ tí Jèhófà jẹ́ Olódùmarè ní lórí rẹ?
4 Rántí ẹ̀sùn tí ẹ̀dá kan fi kan Ọlọ́run nípa ẹ̀tọ́ tí Ọlọ́run ní láti ṣàkóso, bá a ṣe jíròrò rẹ̀ ní Orí Kẹta. Àwọn ẹ̀dá kan ní ọ̀run kò fara mọ́ àṣẹ Jèhófà wọ́n sì ṣiyè méjì pé bóyá ni ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn tó fi ń ṣàkóso ayé dára. Èyí mú kí wọ́n ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, wàhálà ńlá sì ni wọ́n fi àìgbọràn yìí dá sílẹ̀ fún aráyé. Ìyẹn fi hàn pé àfi tí gbogbo ẹ̀dá onílàákàyè láyé àti lọ́run bá gbà pé Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti máa ṣàkóso tí wọ́n sì fi ara wọn sábẹ́ àkóso rẹ̀ nìkan ni nǹkan fi lè máa lọ létòlétò láyé àtọ̀run tí àlàáfíà á sì jọba láàárín àwa èèyàn. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi pinnu pé òun á jẹ́ kó di mímọ̀ pé tòun ni ipò ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run. Jẹ́ ká wo bí àwọn ìwé méjìlá wọ̀nyí tó jẹ́ ìwé àsọtẹ́lẹ̀ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye èyí.
5 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ońṣẹ́ Jèhófà làwọn wòlíì náà, wọ́n sọ̀rọ̀ púpọ̀ nípa ipò gíga tó wà. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà mọ́kànlélógún ni Ámósì lo orúkọ oyè náà, “Olúwa Ọba Aláṣẹ” láti fi gbé orúkọ Ọlọ́run Olódùmarè àti ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run ga. Èyí fi hàn pé gíga Ọlọ́run tòótọ́ ò láfiwé àti pé kò síbi tágbára rẹ̀ ò dé. (Ámósì 9:2-5; wo àpótí náà, “Jèhófà Olódùmarè.”) Jèhófà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run, ó ga fíìfíì ju àwọn òrìṣà aláìlẹ́mìí lọ, a ò tiẹ̀ lè fi wọ́n wé e rárá ni. (Míkà 1:7; Hábákúkù 2:18-20; Sefanáyà 2:11) Jíjẹ́ tí Jèhófà jẹ́ Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo fi í sí ipò ẹnì kan ṣoṣo tó lẹ́tọ̀ọ́ láti máa darí ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ. (Ámósì 4:13; 5:8, 9; 9:6) Kí làǹfààní tí mímọ ìyẹn yóò ṣe fún ọ?
6. Báwo ló ṣe jẹ́ pé gbogbo èèyàn ni ìmúṣẹ àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí kàn?
6 Táwọn kan bá ti hùwà sí ọ rí bíi pé o rẹlẹ̀ sáwọn èèyàn tó kù, tàbí tí wọ́n bá ti rẹ́ ọ jẹ rí, tàbí táwọn kan bá ka ẹ̀yà tiwọn sí èyí tó sàn ju tìẹ lọ, fọkàn balẹ̀, Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́ bìkítà nípa gbogbo èèyàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ní àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú orílẹ̀-èdè kan láyé ọjọ́un, síbẹ̀ ó kéde ìpinnu rẹ̀ láti ṣe gbogbo orílẹ̀-èdè àti gbogbo èdè láǹfààní. Òun ni “Olúwa tòótọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Míkà 4:13) Ọlọ́run ṣèlérí pé orúkọ òun “yóò tóbi láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.” (Málákì 1:11) Bí Baba wa ọ̀run ṣe ń sọ ara rẹ̀ di mímọ̀ fún àwọn èèyàn láìṣojúsàájú, ‘àwọn èèyàn látinú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè’ ń fi ìháragàgà jẹ́ ìpè rẹ̀ pé kí wọ́n wá máa jọ́sìn òun.—Sekaráyà 8:23.
7. Kí nìdí tí ìtumọ̀ orúkọ Jèhófà fi ṣe pàtàkì?
7 Ìmọ̀ nípa irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ àti ohun tí yóò ṣe so pọ̀ mọ́ ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀. (Sáàmù 9:10) Nígbà ayé Míkà, ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà nítorí pé ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tí wọ́n ń jẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà lákòókò náà ya oníwàkiwà. Ni Jèhófà bá mí sí wòlíì náà láti tẹnu mọ́ “ìlọ́lájù orúkọ Jèhófà” àti láti fi hàn pé “ẹni tí ó ní ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ yóò . . . bẹ̀rù orúkọ [Ọlọ́run].” (Míkà 5:4; 6:9) Kí nìdí tí Jèhófà fi mí sí Míkà láti tẹnu mọ́ èyí? Ìdí ni pé ìtumọ̀ pàtàkì tí orúkọ yẹn ní jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ohun tó máa mú kí ìrètí tó o ní fún ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú ṣeé ṣe. Ohun tí orúkọ yẹn túmọ̀ sí ni: “Alèwílèṣe.” O ò ṣe ka Jóẹ́lì 2:26 kó o sì ronú nípa bó ṣe yẹ kó o láyọ̀ tó nítorí pé ò ń jẹ́ orúkọ mọ́ orúkọ yẹn àti bó ṣe yẹ kó o láyọ̀ tó láti máa sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa Ọlọ́run kan ṣoṣo tó lè di ohunkóhun tó bá wù ú kó bàa lè ṣe gbogbo ẹ̀dá rẹ̀ láǹfààní? Ọlọ́run ti fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ní agbára tí kò láàlà láti ṣe nǹkan tó bá fẹ́. Wàá mọ̀ pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí tó o bá rí i pé ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run tipasẹ̀ àwọn wòlíì méjìlá náà sọ ló nímùúṣẹ.
8. Àwọn ọ̀nà wo ni orúkọ Jèhófà ti gbà ṣe ọ́ láǹfààní?
8 Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ti jàǹfààní nínú mímọ̀ pé Jèhófà lágbára láti mú kí ohunkóhun tó bá fẹ́ di ṣíṣe. Jóẹ́lì fi ìyẹn hàn nínú ọ̀rọ̀ kan tó sọ, èyí tí ọ̀pọ̀ mọ̀ bí ẹní mowó, tí àwọn Kristẹni kan tí wọ́n wà lára àwọn tó kọ Bíbélì sì tún sọ lẹ́yìn náà. Ọ̀rọ̀ ọ̀hún ni pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni yóò yè bọ́.” (Jóẹ́lì 2:32; Ìṣe 2:21; Róòmù 10:13) Ǹjẹ́ àwa náà lè sọ ọ̀rọ̀ ìdánilójú tí Míkà sọ pé, “àwa, ní tiwa, yóò máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé”? (Míkà 4:5) Bẹ́ẹ̀ ni, lákòókò inúnibíni tàbí lákòókò ìṣòro, a lè fi ìfọ̀kànbalẹ̀ “sá di orúkọ Jèhófà.”—Sefanáyà 3:9, 12; Náhúmù 1:7.
9. Dé àyè wo ni Ọlọ́run lè darí àwọn alákòóso èèyàn?
9 Bó o ṣe ń ka àwọn ìwé àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí, yóò túbọ̀ dá ọ lójú pé Jèhófà ní agbára, kódà lórí àwọn alákòóso èèyàn àtàwọn abẹnugan nínú ayé. Ó lágbára láti mú kí wọ́n ṣe ohun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. (Òwe 21:1) Gbé àpẹẹrẹ Dáríúsì Ńlá tó ṣàkóso ní Páṣíà láyé ọjọ́un yẹ̀ wò. Àwọn ọ̀tá ìjọsìn tòótọ́ tọ̀ ọ́ lọ pé kó dá àwọn tó ń tún tẹ́ńpìlì Jèhófà tó wà ní Jerúsálẹ́mù kọ́ dúró. Àmọ́ ohun tí wọn ò fẹ́ kó ṣẹlẹ̀ gan-an ló ṣẹlẹ̀! Ní nǹkan bí ọdún 520 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Dáríúsì mú kí àṣẹ tí Kírúsì pa fẹsẹ̀ múlẹ̀ padà ó sì ṣèrànlọ́wọ́ fún wọn lẹ́nu iṣẹ́ tẹ́ńpìlì tí wọ́n ń kọ́. Nígbà táwọn ọ̀tá tún fẹ́ láti dá iṣẹ́ náà dúró, Ọlọ́run ní kí wòlíì rẹ̀ lọ sọ fún Serubábélì Gómìnà Júdà pé: “‘Kì í ṣe nípasẹ̀ ẹgbẹ́ ológun, tàbí nípasẹ̀ agbára, bí kò ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí mi,’ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí. Ta ni ọ́, ìwọ òkè ńlá títóbi? Ìwọ yóò di ilẹ̀ títẹ́jú pẹrẹsẹ níwájú Serubábélì.” (Sekaráyà 4:6, 7) Kò sóhun tó lè dá Jèhófà dúró pé kó má pa ètò àwọn nǹkan búburú yìí run, kò sì sóhun tó lè dí i lọ́wọ́ pé kó máà mú Párádísè wá fún àwọn olùjọsìn rẹ̀.—Aísáyà 65:21-23.
10. Ibo ni agbára tí Ọlọ́run ní láti darí àwọn nǹkan dé, kí sì nìdí tó fi yẹ ká mọ ìyẹn?
10 Tún gbàyí yẹ̀ wò. Jèhófà ní agbára láti darí àwọn ohun alágbára tí kì í ṣe nǹkan ẹlẹ́mìí, irú bí ẹ̀fúùfù. Tó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, ó lè lo àwọn ohun alágbára náà láti fi pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ run. (Náhúmù 1:3-6) Nígbà tí Sekaráyà ń tẹnu mọ́ bí Jèhófà ṣe lè dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀, ó lo èdè ìṣàpẹẹrẹ, ó sọ pé: “A ó sì rí Jèhófà fúnra rẹ̀ lórí wọn, dájúdájú, ọfà rẹ̀ yóò sì jáde lọ bí mànàmáná. Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ fúnra rẹ̀ yóò sì fun ìwo, dájúdájú, òun yóò sì lọ pẹ̀lú ìjì ẹlẹ́fùúùfù ti gúúsù.” (Sekaráyà 9:14) Pẹ̀lú ohun tá a rí yìí, ṣé ó máa wá ṣòro fún Jèhófà láti fi hàn pé òun ga fíìfíì ju àwọn orílẹ̀-èdè tí kò ṣe ìfẹ́ òun nígbà tiwa yìí? Kò lè ṣòro fún un rárá!—Ámósì 1:3-5; 2:1-3.
ẸNI TÓ ṢEÉ GBÁRA LÉ PÉ YÓÒ MÚ ÌLÉRÍ RẸ̀ ṢẸ
11, 12. (a) Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, kí nìdí táwọn èèyàn fi ń wo Nínéfè bí ìlú tí kò ṣeé ṣẹ́gun? (b) Kí ló gbẹ̀yìn Nínéfè, gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run sọ?
11 Ní ọ̀rúndún kẹsàn-án ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìlú ńlá kan wà ní ibi tá a wá mọ̀ báyìí sí Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn. Ìlú wo ni ìlú ńlá yìí lè jẹ́ o? Nínéfè ni. Ó jẹ́ ìlú pàtàkì kan ní Ásíríà. Ó wà nítòsí bèbè odò Tígírísì, ìyẹn bèbè tó wà ní apá ìlà oòrùn odò náà, ó sì jẹ́ nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án kìlómítà sí Jerúsálẹ́mù. Ìlú náà tóbi gan-an, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún kìlómítà ni téèyàn bá rìn ín yí po! Àwọn tó lọ sí ibi tí ìlú Nínéfè wà láyé ọjọ́un sọ pé ó lẹ́wà bíi Bábílónì, nítorí àwọn ààfin ńlá ńlá tó wà ńbẹ̀, àtàwọn tẹ́ńpìlì, àwọn òpópónà tó fẹ̀, àwọn ọgbà ìtura, àti ilé ìkówèésí ńlá kan. Kódà, àwọn tó mọ ọgbọ́n ogun sọ̀rọ̀ nípa odi tó yí ìlú náà pó. Méjì ni odi náà, fífẹ̀ rẹ̀ kàmàmà, kò sì ṣeé dá lu.
12 Kò sí àní-àní pé ọ̀pọ̀ èèyàn á máa sọ nígbà yẹn pé, “Kò sẹ́ni tó lè ṣẹ́gun Nínéfè!” Àmọ́, àwọn wòlíì kan láti orílẹ̀-èdè Júdà tó kéré gan-an ń sọ ṣáá, pé Jèhófà ti pinnu láti pa Nínéfè tó jẹ́ “ìlú ńlá ìtàjẹ̀sílẹ̀” run. Nítorí pé àwọn tó ń gbé ní Nínéfè ṣàtúnṣe nígbà tí Ọlọ́run rán Jónà sí wọn, ìbínú Ọlọ́run kò wá sórí ìlú náà lákòókò yẹn. Àmọ́ nígbà tó yá, àwọn ará Nínéfè tún padà sínú ìwàkiwà wọn. Ni Náhúmù bá sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Nínéfè . . . , idà yóò ké ọ kúrò . . . Kò sí ìtura fún àjálù ibi rẹ.” (Náhúmù 3:1, 7, 15, 19; Jónà 3:5-10) Ní nǹkan bí àkókò yẹn kan náà, Jèhófà lo Sefanáyà láti sọ tẹ́lẹ̀ pé Nínéfè yóò dahoro. (Sefanáyà 2:13) Ṣé wọ́n á sì ṣẹ́gun ìlú ńlá tó dà bíi pé kò ṣeé ṣẹ́gun yìí bí Jèhófà ṣe sọ? Ìdáhùn sí ìbéèrè yìí dé ní nǹkan bí ọdún 632 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, nígbà táwọn ará Bábílónì, àwọn Síkítíánì, àtàwọn ará Mídíà sàga ti Nínéfè. Ìkún-omi tí wọn ò rò tẹ́lẹ̀ wó àwọn ògiri rẹ̀, ìyẹn àwọn odi tó yí ìlú náà po, làwọn tó gbógun lọ síbẹ̀ bá ráyè wọlé. (Náhúmù 2:6-8) Kíákíá ni ìlú tó lágbára nígbà kan yìí di kìkì òkìtì àlàpà. Ahoro ni ìlú Nínéfè ṣì wà dòní olónìí.a “Ìlú ńlá tí ó kún fún ayọ̀ ńláǹlà” yìí ò lè dí ọ̀rọ̀ Jèhófà lọ́wọ́ pé kó má ṣe nímùúṣẹ!—Sefanáyà 2:15.
13. Àpẹẹrẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó nímùúṣẹ wo lo lè rí nínú ìwé àwọn wòlíì méjìlá náà?
13 Ńṣe ni nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí Nínéfè wulẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ kan lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ti nímùúṣẹ. Ìwọ wo àwòrán ilẹ̀ Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn. Ǹjẹ́ o rí Ámónì, Ásíríà, Bábílónì, Édómù, tàbí Móábù nínú rẹ̀? O ò lè rí nǹkan tó jọ ọ́! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ibi tá a dárúkọ yìí jẹ́ orílẹ̀-èdè tó lókìkí nígbà láéláé, àwọn wòlíì méjìlá náà sọ tẹ́lẹ̀ pé wọn ò ní sí mọ́. (Ámósì 2:1-3; Ọbadáyà 1, 8; Náhúmù 3:18; Sefanáyà 2:8-11; Sekaráyà 2:7-9) Eré ni àwàdà ni, àfẹ́kù bẹ̀rẹ̀ sí bá wọn níkọ̀ọ̀kan. Kò sí ọ̀kan nínú wọn tó tún wà mọ́. Jèhófà sọ pé wọ́n á pòórá, bó sì ṣe rí náà nìyẹn! Àsọtẹ́lẹ̀ táwọn wòlíì wọ̀nyí sì sọ nípa àwọn àṣẹ́kù Júù, pé wọ́n á padà sí ilẹ̀ wọn láti ìgbèkùn Bábílónì, nímùúṣẹ!
14. Kí nìdí tó fi yẹ kó o gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìlérí Jèhófà kó o sì máa fi ìgbésí ayé rẹ ṣe ìfẹ́ rẹ̀?
14 Ǹjẹ́ àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí, tó fi hàn pé Jèhófà lágbára láti sọ àsọtẹ́lẹ̀, kò mú kó o túbọ̀ ní ìgbọ́kànlé nínú Jèhófà? Jẹ́ kó dá ọ lójú pé Jèhófà yóò mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ; ó jẹ́ Ọlọ́run “tí kò lè purọ́.” (Títù 1:2) Jèhófà sì sọ ohun tó yẹ ká mọ̀ fún wa nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. O ò lè rí ìjákulẹ̀ tó o bá fi ìgbésí ayé rẹ ṣe ìfẹ́ Jèhófà, tó o sì gbẹ́kẹ̀ lé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tí yóò nímùúṣẹ. Ayé ọjọ́un nìkan kọ́ làwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú àwọn ìwé méjìlá náà nímùúṣẹ o. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló ṣì ń nímùúṣẹ lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, àwọn mìíràn sì máa nímùúṣẹ láìpẹ́. Nítorí náà, àkọsílẹ̀ tó wà nínú àwọn ìwé méjìlá wọ̀nyí lè jẹ́ kó o túbọ̀ ní ìgbọ́kànlé pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa àkókò wa yìí àtàwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ iwájú yóò nímùúṣẹ. Fiyè sí àwọn ìwé náà dáadáa.
BABA TÓ BÌKÍTÀ
15. Tó o bá ní àwọn ìṣòro kan, báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ sí Míkà ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́?
15 Kì í ṣe nínú ọ̀ràn àwọn ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sáwọn orílẹ̀-èdè tàbí àwọn ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ kárí ayé lọ́jọ́ iwájú nìkan lo ti lè gbára lé Jèhófà o. O lè gbára lé e nínú ọ̀ràn tara rẹ náà, nítorí pé Jèhófà máa ń sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ó sì máa ń mú wọn ṣẹ lọ́nà tó gbà kan ìwọ alára. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Ó dáa, ṣé o mọ̀ pé àwọn ìgbà mìíràn wà tó ṣeé ṣe kó o máa gbìyànjú láti yanjú àwọn ìṣòro kan tó o ní. Nírú àkókò bẹ́ẹ̀, o mọ̀ pé kó o sáà kàn ti rí ẹni tó mọ ìṣòro tó ń bá ọ fínra kọ́ lo nílò, kàkà bẹ́ẹ̀, ẹni tó o lè gbẹ́kẹ̀ lé pé á ràn ọ́ lọ́wọ́ lo nílò. Ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ó dájú pé á máa ṣe Míkà bíi pé òun dá nìkan wà bó ṣe ń jíṣẹ́ tí Ọlọ́run fi rán an sáwọn èèyàn agbéraga tó wà ní Júdà. Lójú rẹ̀, ó lè dà bíi pé òun nìkan ni onígbọràn kan ṣoṣo tó kù láyé, pé òun ò tiẹ̀ lè gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ará ilé òun pàápàá. Ibi tó wù kó yíjú sí, àwọn èèyàn tí òùngbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ, àwọn ẹlẹ̀tàn èèyàn àti oníwà ìbàjẹ́ ló ń rí. Síbẹ̀, ọkàn Míkà balẹ̀ nítorí ìlérí Ọlọ́run, pé ohun yòówù káwọn ẹlòmíràn ṣe, Ọlọ́run á tọ́jú àwọn tó ń ṣègbọràn sí i. Ìyẹn lè tu ìwọ náà nínú, pàápàá tó bá jẹ́ pé àwọn tí wọ́n jẹ́ olùjọsìn Jèhófà bíi tìẹ kò pọ̀, tàbí tó jẹ́ pé ìwọ nìkan ni olùjọsìn Jèhófà tó wà láàárín ọ̀pọ̀ àwọn tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run.—Míkà 7:2-9.
16. Kí nìdí tó fi lè dá ọ lójú pé Jèhófà ń rí gbogbo ìwà ìbàjẹ́ àti ìninilára tó wà láyé àti pé yóò dá àwọn olódodo nídè?
16 Bó ṣe sábà máa ń rí lónìí, àwọn ọlọ́rọ̀ àtàwọn tágbára wà lọ́wọ́ wọn ní Júdà àti ní Ísírẹ́lì di oníwọra àti arẹ́nijẹ. Wọ́n ń mú kí àwọn ẹlòmíràn di ẹrú lọ́nà tí kò bá òfin mu nítorí owó orí tó ga lágajù àti gbígbà tí wọ́n ń gba ilẹ̀ onílẹ̀. Wọ́n ń bá àwọn aláìní lò bí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan, kódà pẹ̀lú ìwà ìkà. (Ámósì 2:6; 5:11, 12; Míkà 2:1, 2; 3:9-12; Hábákúkù 1:4) Jèhófà rán àwọn ońṣẹ́ rẹ̀ sí wọn pé òun ò ní fàyè gba ìwà ìbàjẹ́ àti kéèyàn máa fara ni àwọn ẹlòmíràn, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun á fìyà jẹ àwọn ẹni ibi tí kò bá yí padà. (Hábákúkù 2:3, 6-16) Ó sọ tẹ́lẹ̀ pé òun yóò “mú àwọn ọ̀ràn tọ́ ní ti àwọn orílẹ̀-èdè alágbára ńlá,” àti pé àwọn ìránṣẹ́ òun tóun tẹ́wọ́ gbà “yóò . . . jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.” (Míkà 4:3, 4) Ó dájú pé ìtura ńlá lèyí mú bá wọn! Ọ̀pọ̀ nǹkan mìíràn ni Ọlọ́run ti ṣèlérí tó sì ti mú ṣẹ. Ǹjẹ́ kò dá ọ lójú nígbà náà pé ìlérí yìí pẹ̀lú yóò nímùúṣẹ?
17, 18. (a) Kí ló mú kí Ọlọ́run fún àwọn èèyàn rẹ̀ nírètí? (b) Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo ìbáwí Jèhófà?
17 Kì í ṣe pé Jèhófà ń mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ láti fi hàn pé òun lágbára láti sọ tẹ́lẹ̀ káwọn èèyàn lè máa kan sáárá sí òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ tó dá lórí ìlànà ló ń sún un ṣe àwọn ohun tó ń ṣe, nítorí “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Ṣé o rántí Hóséà tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni? Bí Gómérì aya rẹ̀ ṣe jẹ́ aláìṣòótọ́ sí i, bẹ́ẹ̀ làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Jèhófà. Bí ìgbà téèyàn bá ṣe panṣágà ni ìbọ̀rìṣà wọn ṣe rí, wọ́n lọ ń pa ìjọsìn Báálì pọ̀ mọ́ ìjọsìn mímọ́ Jèhófà. Lédè ìṣàpẹẹrẹ, wọ́n tún “ṣe àgbèrè” pẹ̀lú Ásíríà àti Íjíbítì. Kí wá ni Jèhófà á ṣe fún wọn báyìí? Ṣó o rí i, ńṣe ni Hóséà wá ọ̀nà bí aya rẹ̀ tó hùwà àìṣòótọ́ sí i yóò ṣe padà sọ́dọ̀ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe wá ọ̀nà bí àwọn èèyàn òun ṣe máa padà sọ́dọ̀ òun, ìfẹ́ ló sì mú un ṣe bẹ́ẹ̀. Jèhófà sọ pé: “Mo ń bá a nìṣó láti fi àwọn ìjàrá ará ayé fà wọ́n, pẹ̀lú àwọn okùn ìfẹ́, . . . lẹ́sọ̀lẹsọ̀ sì ni mo gbé oúnjẹ wá fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.” (Hóséà 2:5; 11:4) Tí wọ́n bá ronú pìwà dà tọkàntọkàn, Ọlọ́run á dárí jì wọ́n, ìyẹn á sì mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti tún padà ní àjọṣe pẹ̀lú rẹ̀. (Hóséà 1:3, 4; 2:16, 23; 6:1-3; 14:4) Ǹjẹ́ ìfẹ́ tí Jèhófà ní yìí kò wú ọ lórí? Wá bi ara rẹ pé, ‘Níwọ̀n bí Jèhófà ti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn bẹ́ẹ̀ láyé àtijọ́, ǹjẹ́ kò yẹ kó dá mi lójú pé yóò fi ìfẹ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́, ìfẹ́ tí kì í yẹ̀, tí kì í yí padà, tí kì í sì í tán, hàn sí èmi náà?’—Hóséà 11:8.
18 Àwọn ìwé àsọtẹ́lẹ̀ méjìlá náà tún lè jẹ́ kó o rí i pé ohun mìíràn tí ìfẹ́ máa ń sún Ọlọ́run ṣe ni pé kó báni wí. Jèhófà mú un dá àwọn èèyàn rẹ̀ aláìṣòótọ́ lójú pé òun ‘ò ní pa wọ́n rẹ́ ráúráú.’ (Ámósì 9:8) Nígbà tó yẹ kó fìyà jẹ wọ́n, kò ṣaláì ṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́, ó dájú pé wọ́n rí ìtùnú nígbà tí wọ́n mọ̀ pé fúngbà díẹ̀ ni! Málákì 1:6 fi Jèhófà wé bàbá tó nífẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ̀. Bí ìwọ náà ṣe mọ̀, bàbá tó nífẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ̀ lè bá ọmọ náà wí kí ọmọ náà lè ṣàtúnṣe. (Náhúmù 1:3; Hébérù 12:6) Síbẹ̀, ìfẹ́ tí Bàbá wa ọ̀run ní ló mú kó máa lọ́ra láti bínú, Málákì 3:10 sì fi dáni lójú pé yóò san èrè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.
19. Àyẹ̀wò wo ló yẹ kó o ṣe nípa ara rẹ?
19 Ọ̀rọ̀ ìdánilójú tí Málákì fi bẹ̀rẹ̀ ìwé rẹ̀ ni pé: “‘Mo nífẹ̀ẹ́ yín,’ ni Jèhófà wí.” (Málákì 1:2) Bó o ṣe ń ronú nípa ọ̀rọ̀ ìdánilójú tí Ọlọ́run sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì yìí, bi ara rẹ pe: ‘Ǹjẹ́ nǹkan kan wà tí mò ń ṣe tó lè máà jẹ́ kí n jàǹfààní ìfẹ́ Ọlọ́run? Àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà fi ìfẹ́ hàn wo ni mo fẹ́ mọ̀ tí mo sì fẹ́ túbọ̀ jàǹfààní rẹ̀?’ Tó o bá rí i pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ rẹ dáadáa, á túbọ̀ máa dá ọ lójú pé á nífẹ̀ẹ́ rẹ títí láé.
ÌDÁRÍJÌ Ń MÚ KÍ ÌGBÀLÀ ṢEÉ ṢE
20. Báwo ni ìdáríjì Ọlọ́run ṣe máa ń mú kí ìgbàlà ṣeé ṣe?
20 Bó o ṣe ń ka àwọn ìwé àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí, wàá rí i pé nígbà yẹn lọ́hùn-ún, Jèhófà máa ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ àjálù nígbà mìíràn. Kí nìdí? Lọ́pọ̀ ìgbà, ìdí tó fi máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni káwọn èèyàn rẹ̀ lè ronú pìwà dà. Ìdí yìí náà ló fi fàyè gba àwọn ará ilẹ̀ òkèèrè láti pa Samáríà run lọ́dún 740 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, tó tún fàyè gba ìparun Jerúsálẹ́mù lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ìparun tí Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ nímùúṣẹ, àmọ́ ó jẹ́ kí àwọn tó ronú pìwà dà padà sí ilẹ̀ wọn. Dájúdájú, àwọn ìwé wọ̀nyí tẹnu mọ́ ọn pé Jèhófà máa ń fi inú rere dárí ji àwọn tó bá ronú pìwà dà ó sì máa ń gbà wọ́n padà. (Hábákúkù 3:13; Sefanáyà 2:2, 3) Abájọ tí Míkà fi kéde pé: “Ta ni Ọlọ́run bí ìwọ, ẹni tí ń dárí ìrélànàkọjá jì, tí ó sì ń ré ìṣìnà àṣẹ́kù ogún rẹ̀ kọjá? Dájúdájú, òun kì yóò máa bá a lọ nínú ìbínú rẹ̀ títí láé, nítorí ó ní inú dídùn sí inú-rere-onífẹ̀ẹ́.” (Míkà 7:18; Jóẹ́lì 2:13; Sekaráyà 1:4) Ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ fi hàn pé òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yìí.
21. (a) Kí làwọn wòlíì méjìlá náà fi hàn nípa Mèsáyà? (b) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wo nípa Mèsáyà lo nífẹ̀ẹ́ sí jù?
21 Láti lè ṣe ètò tó bá òfin mu, tó máa mú kí ìdáríjì pátápátá ṣeé ṣe, Jèhófà ṣèlérí pé Mèsáyà yóò wá láti fi ìwàláàyè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn rúbọ gẹ́gẹ́ bí “ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí” fún aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀. (1 Tímótì 2:6) Ámósì tọ́ka sí ìmúbọ̀sípò látọwọ́ Mèsáyà ọmọ Dáfídì. (Ámósì 9:11, 12; Ìṣe 15:15-19) Kódà, Míkà sọ ibi tí wọn á ti bí Jésù, ẹni tó máa fi ara rẹ̀ rúbọ kí gbogbo àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ rẹ̀ lè ní ìyè. (Míkà 5:2) Sekaráyà pẹ̀lú sọ̀rọ̀ nípa “Ìrújáde,” ìyẹn Jésù, ẹni tí yóò ‘jókòó tí yóò sì ṣàkóso lórí ìtẹ́ rẹ̀.’ (Sekaráyà 3:8; 6:12, 13; Lúùkù 1:32, 33) Ó dájú pé ìgbàgbọ́ rẹ yóò lágbára sí i tó o bá gbé púpọ̀ sí i lára irú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ yẹ̀ wò.—Wo àpótí náà, “Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Pàtàkì Nípa Mèsáyà.”
22. Báwo lohun táwọn wòlíì méjìlá náà fi hàn nípa Jèhófà ṣe mú kó o túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?
22 Bó o bá ṣe ń ka iṣẹ́ tí Ọlọ́run fi rán àwọn wòlíì náà nínú ìwé méjìlá wọ̀nyí, bẹ́ẹ̀ ni yóò túbọ̀ máa dá ọ lójú pé ìjagunmólú Ọlọ́run tó máa kẹ́yìn yóò wáyé dandan ni. Jèhófà ló máa jà fún wa, ìdájọ́ òdodo sì ni ìdájọ́ rẹ̀. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà títí láé. Ọlọ́run kò gbàgbé àdéhùn tó bá àwọn èèyàn rẹ̀ ṣe, ó máa ń tọ́jú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì máa ń gbà wọ́n lọ́wọ́ gbogbo àwọn tó ń ni wọ́n lára. (Míkà 7:8-10; Sefanáyà 2:6, 7) Jèhófà kì í sì í yí padà. (Málákì 3:6) Ọkàn wa mà balẹ̀ o, pé kò sóhun tó lè dí Ọlọ́run lọ́wọ́ pé kó má ṣe ohun tó sọ pé òun máa ṣe! Ó ti sọ pé ọjọ́ ìdájọ́ ń bọ̀, kò sì sóhun tó lè yẹ̀ ẹ́. Nítorí náà, máa retí ọjọ́ Jèhófà! “Jèhófà yóò . . . di ọba lórí gbogbo ilẹ̀ ayé. Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà yóò jẹ́ ọ̀kan, orúkọ rẹ̀ yóò sì jẹ́ ọ̀kan.” (Sekaráyà 14:9) Ó ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, kò sì ní ṣaláì mú un ṣẹ.
a Ní oṣù November ọdún 2002, ṣáájú ogun tó jà ní Ìráàkì, ọ̀jọ̀gbọ́n Dan Cruickshank ṣèbẹ̀wò sí àgbègbè yìí. Ó sọ lórí tẹlifíṣọ̀n ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì pé: “Ahoro ìlú Nínéfè tó fẹ̀ lọ bí ilẹ̀ bí ẹní wà ní ààlà ìlú Mosul. Gbogbo agbára sì làwọn awalẹ̀pìtàn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fi ń walẹ̀ ahoro ìlú Nínéfè yìí àti ìlú Nímírúdù . . . bẹ̀rẹ̀ látọdún 1840. . . . Dájúdájú, ìwalẹ̀pìtàn ní àwọn ìlú Ásíríà yìí jẹ́ àwárí ayé ọ̀làjú táwọn èèyàn ò mọ̀ nípa rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún tó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di ìtàn lásán; ohun kan ṣoṣo tó sì jẹ́ ká mọ̀ ọ́n ni àpèjúwe ṣókí tá a rí nínú Bíbélì, àpèjúwe ọ̀hún kì í sì í ṣe àsọdùn.”