ORÍ KARÙN-ÚN
“Wá Jèhófà” Nípa Jíjọ́sìn Rẹ̀ Lọ́nà Tó Fẹ́
1. Àwọn ìbùkún wo lò ń gbádùn láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run?
O Ò RÍ i pé àǹfààní ńlá ni pé o mọ̀ nípa Ọlọ́run tó ń mú àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ! Ó ṣeé ṣe fún ọ láti jàǹfààní ohun tí Hóséà kọ̀wé nípa rẹ̀ pé: “Èmi yóò sì fẹ́ ọ fún ara mi ní ìṣòtítọ́; dájúdájú, ìwọ yóò sì mọ Jèhófà.” Ohun tí Hóséà ń fi ọ̀rọ̀ yìí ṣàpèjúwe ni ipò ààbò tó dà bíi Párádísè, táwọn èèyàn Ọlọ́run yóò gbádùn tí wọ́n bá padà dé láti ìgbèkùn Bábílónì. Bẹ́ẹ̀ làwọn èèyàn Ọlọ́run lóde òní ṣe ń gbádùn ààbò àti aásìkí tẹ̀mí; wọ́n wà ní ipò tó dà bíi Párádísè. (Hóséà 2:18-20) Ní báyìí tó o ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ò ń jẹ́ orúkọ mọ́ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ya ara wọn sí mímọ́ fún un, kò sì sí àní-àní pé ńṣe lo fẹ́ máa jẹ́ Ẹlẹ́rìí rẹ̀ títí lọ.—Aísáyà 43:10, 12; Ìṣe 15:14.
2, 3. (a) Kí nìdí tí Jèhófà fi kórìíra ọ̀nà táwọn èèyàn rẹ̀ ayé ọjọ́un gbà ń jọ́sìn? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká gbé iṣẹ́ táwọn wòlíì náà jẹ́ yẹ̀ wò?
2 Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ jẹ́ orílẹ̀-èdè tá a yà sí mímọ́ fún Jèhófà, Jèhófà sì fún wọn láwọn ìlànà tí èyíkéyìí nínú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn kò rí gbà rí. (Diutarónómì 4:33-35) Síbẹ̀, nígbà tó fi máa di òpin ọ̀rúndún kẹsàn-án ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ipò tẹ̀mí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti burú débi pé Ọlọ́run ní kí wòlíì Ámósì sọ fún wọn pé: “Mo kórìíra, mo kọ àwọn àjọyọ̀ yín . . . Bí ẹ bá fi odindi àwọn ọrẹ ẹbọ sísun rúbọ sí mi, àní èmi kì yóò ní inú dídùn sí ọrẹ ẹbọ ẹ̀bùn yín.” (Ámósì 5:21, 22) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ò sọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí ìjọ àwọn èèyàn rẹ̀ tó wà jákèjádò ayé lónìí, báwo ló ṣe máa rí lára rẹ tó o bá gbọ́ pé ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìjọsìn rẹ nìyẹn? Ǹjẹ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú èyí?
3 Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, àwọn èèyàn Ọlọ́run sọ pé àwọn ń jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ lára wọn ló ń sin òrìṣà, irú bíi Báálì ti àwọn ará Kénáánì àti oríṣiríṣi ère ọmọ màlúù, tàbí kí wọ́n máa rúbọ láwọn ibi gíga. Wọ́n ń wólẹ̀ fún àwọn ohun tí Ọlọ́run dá tó wà lójú ọ̀run, lọ́wọ́ kan náà wọ́n tún ń búra pé Jèhófà làwọn ń sìn. Ni Jèhófà bá rán àwọn wòlíì sáwọn èèyàn náà láti rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n padà sọ́dọ̀ òun nípa ṣíṣe ìjọsìn mímọ́. (2 Àwọn Ọba 17:7-17; 21:3; Ámósì 5:26) Èyí jẹ́ ká rí i kedere pé, kódà, àwọn nǹkan kan lè wà tó yẹ káwọn tó ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ rẹ̀ kíyè sí, kí wọ́n yẹ ìṣe wọn àti ìwà wọn wò bóyá ó fi hàn pé wọ́n ń jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó fẹ́.
“ÌMỌ̀ NÍPA ỌLỌ́RUN”
4. Báwo ni ipò nǹkan ṣe rí lákòókò ìṣàkóso Ọba Jèróbóámù Kejì?
4 Ronú nípa àkókò tí àwọn tí Ọlọ́run kọ́kọ́ gbé dìde lára àwọn wòlíì méjìlá náà jíṣẹ́ tí Ọlọ́run rán wọn. Àwọn wòlíì náà ń sọ tẹ́lẹ̀ pé ọjọ́ Jèhófà yóò ṣe ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì bí ọṣẹ ṣe ń ṣojú. Àmọ́ téèyàn bá wò ó, ó dà bíi pé orílẹ̀-èdè náà láásìkí. Bí àpẹẹrẹ, bí Jónà ṣe sọ tẹ́lẹ̀, Ọba Jèróbóámù Kejì mú kí ààlà orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì dé ibi tó dé tẹ́lẹ̀, ìyẹn láti Damásíkù ní àríwá títí dé Òkun Òkú. (2 Àwọn Ọba 14:24-27) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèróbóámù ṣe ohun tó burú, Jèhófà ní ìpamọ́ra, kò fẹ́ pa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rẹ́ kúrò lábẹ́ ọ̀run. Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lákòókò láti ronú pìwà dà, láti ‘wá Jèhófà kí wọ́n lè máa wà láàyè nìṣó.’—Ámósì 5:6.
5. Kí ni ohun táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò ní tó mú kí Jèhófà kọ̀ wọ́n?
5 Ṣebí ńṣe ló yẹ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláásìkí wọ̀nyẹn lo àkókò tí Ọlọ́run fún wọn láti túbọ̀ mọ Jèhófà kí wọ́n sì máa lépa ohun tó fẹ́, kí wọ́n lè padà sọ́dọ̀ rẹ̀. Àmọ́ wọn ò ṣe bẹ́ẹ̀ o, ńṣe ni wọ́n dá ara wọn lójú pé ‘àjálù kò ní dé ọ̀dọ̀ àwọn.’ (Ámósì 9:10) Tó o bá sọ pé wọ́n ti gbàgbé Jèhófà, o ò jayò pa, nítorí pé “wọ́n yó, ọkàn-àyà wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ga.” (Hóséà 13:6) A ò gbọ́dọ̀ rò pé ìtàn àtijọ́ tí kò kàn wá lọ̀rọ̀ yìí o. Kíyè sí ìdí tí Jèhófà fi ní ẹjọ́ tó fẹ́ bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe. Jèhófà sọ pé: “Nítorí pé ìmọ̀ ni ìwọ alára ti kọ̀, èmi pẹ̀lú yóò kọ̀ ọ́ ní sísìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà fún mi.” Gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè lódindi, Jèhófà ni wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ fún, àwọn ẹbí wọn tó ya ara wọn sí mímọ́ ló sì wà láyìíká wọn gbogbo. Àmọ́ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, wọn kò ní ojúlówó “ìmọ̀ nípa Ọlọ́run.”—Hóséà 4:1, 6.
6. Ọ̀nà wo ló fi jẹ́ pé òkú ni ìmọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?
6 Kì í kúkú ṣe pé wọn ò gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run rí, nítorí pé nígbà yẹn, ojúṣe àwọn òbí ní Ísírẹ́lì ni láti máa fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ àwọn ọmọ wọn. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ti gbọ́ àwọn nǹkan kan nínú Bíbélì látẹnu àwọn òbí wọn, tàbí nígbà tí wọ́n ń bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀, tàbí nígbà àpéjọ gbogbo gbòò. (Ẹ́kísódù 20:4, 5; Diutarónómì 6:6-9; 31:11-13) Bí àpẹẹrẹ, wọ́n á ti gbọ́ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Áárónì fi wúrà ṣe ère ọmọ màlúù lákòókò tí Mósè lọ gba Òfin Mẹ́wàá lórí Òkè Sínáì. (Ẹ́kísódù 31:18-32:9) Èyí fi hàn pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbà ayé àwọn wòlíì tá à ń gbé yẹ̀ wò yìí ní ìmọ̀ díẹ̀ nípa Òfin Mósè wọ́n sì gbọ́ ìtàn àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá. Àmọ́, òkú ni ìmọ̀ tí wọ́n ní, nítorí pé wọn ò jẹ́ kí ìmọ̀ náà sún wọn láti jọ́sìn Ọlọ́run lọ́na tí Ọlọ́run fẹ́.
7. (a) Báwo ló ṣe rọrùn tó bẹ́ẹ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti di aláìgbọràn? (b) Báwo ni Kristẹni kan ṣe lè dẹni tó ‘bẹ̀rẹ̀ sí í gbàgbé Ẹlẹ́dàá rẹ̀’?
7 O lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Báwo ló ṣe rọrùn tó bẹ́ẹ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti di aláìgbọràn?’ Tóò, Hóséà sọ bọ́rọ̀ ṣe jẹ́ fún wa, ó ní: “Ísírẹ́lì . . . bẹ̀rẹ̀ sí gbàgbé Olùṣẹ̀dá rẹ̀.” (Hóséà 8:14) “Bẹ̀rẹ̀ sí gbàgbé” tí wọ́n fi túmọ̀ ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Hébérù tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ dára gan-an ni, nítorí pé ẹ̀ẹ̀kan náà kọ́ làwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbàgbé Jèhófà, kàkà bẹ́ẹ̀, díẹ̀díẹ̀ ni àlàbọrùn dẹ̀wù sí wọn lọ́rùn. Díẹ̀díẹ̀ ni wọ́n gbàgbé pé ó ṣe pàtàkì pé káwọn máa jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó fẹ́. Ǹjẹ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnì kan tó jẹ́ Kristẹni? Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ ọkùnrin kan tó fọwọ́ pàtàkì mú pípèsè fún ìdílé rẹ̀. (1 Tímótì 5:8) Kí ọkùnrin náà bàa lè máa pèsè fún ìdílé rẹ̀ bó ṣe yẹ, ó ka iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ rẹ̀ sí pàtàkì. Ó ṣeé ṣe kí ìdílé rẹ̀ nílò nǹkan kan kó sì torí ìyẹn parí èrò sí pé òun á pa ìpàdé jẹ fún ọjọ́ mélòó kan láti fi ṣiṣẹ́. Bí àkókò ti ń lọ, pípa ìpàdé jẹ á túbọ̀ rọ̀ ọ́ lọ́rùn, á sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ lemọ́lemọ́. Eré ni, àwàdà ni, àárín òun àti Ọlọ́run ò ní fi bẹ́ẹ̀ gún régé mọ́. Tó bá sì ti dà bẹ́ẹ̀, ó ti ‘bẹ̀rẹ̀ sí í gbàgbé Ẹlẹ́dàá rẹ̀ nìyẹn.’ Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ tún lè ṣẹlẹ̀ sí Kristẹni kan táwọn òbí rẹ̀ tàbí àwọn ìbátan rẹ̀ kì í ṣe onígbàgbọ́. Báwo ni àkókò tí yóò fi máa mú tàwọn òbí rẹ̀ gbọ́ yóò ṣe pọ̀ tó tàbí àkókò tí yóò fi máa mú tàwọn ìbátan rẹ̀ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí gbọ́, ìgbà wo ló sì yẹ kó máa mú tiwọn gbọ́? (Ẹ́kísódù 20:12; Mátíù 10:37) Báwo ló ṣe máa pinnu iye àkókò tó yẹ kó fi rìnrìn àjò, iye àkókò tó yẹ kó fi ṣe àwọn ohun tó nífẹ̀ẹ́ sí, tàbí tó yẹ kó fi najú, báwo ló sì ṣe yẹ kó máa mú tàwọn nǹkan wọ̀nyí gbọ́ tó?
8. Nígbà ayé Ámósì, kí ló túmọ̀ sí láti ní ‘eyín tó mọ́ tónítóní’?
8 A ti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a sì ń fi ohun tá a ti kọ́ sílò. Síbẹ̀, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè ṣàgbéyẹ̀wò gbólóhùn kan tó wà nínú ìwé Ámósì. Gbólóhùn náà ni: “Ìmọ́tónítóní eyín.” Ọlọ́run tipasẹ̀ Ámósì kìlọ̀ fáwọn èèyàn Rẹ̀ pé: “Èmi pẹ̀lú, ní tèmi, sì fún yín ní ìmọ́tónítóní eyín ní gbogbo àwọn ìlú ńlá yín àti àìní oúnjẹ ní gbogbo àyè yín.” (Ámósì 4:6) Kì í ṣe torí pé wọ́n fọ eyín leyín wọn fi mọ́ o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìyàn, àìróúnjẹ jẹ ló fọ eyín wọn mọ́ tónítóní. Kì í tún wá ṣe ìyàn fún oúnjẹ tara, nítorí pé ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ìkìlọ̀ nípa “ìyàn, tí kì í ṣe fún oúnjẹ, àti òùngbẹ, tí kì í ṣe fún omi, bí kò ṣe fún gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.”—Ámósì 8:11.
9, 10. (a) Báwo ni Kristẹni kan ṣe lè dẹni tí ìyàn tẹ̀mí mú? (b) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣọ́ra fún ewu ìyàn tẹ̀mí?
9 Ọ̀rọ̀ tí Ámósì sọ yìí ṣẹ sáwọn oníṣọ́ọ̀ṣì lára. Inú ipò tó ṣeni láàánú ni wọ́n wà nítorí pé wọn kì í rí oúnjẹ tẹ̀mí jẹ. Àmọ́ ńṣe ni “ibodè ibú omi ọ̀run” ṣí sílẹ̀ fáwa èèyàn Jèhófà jákèjádò ayé. Jèhófà ń fún wa ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ tẹ̀mí. (Málákì 3:10; Aísáyà 65:13, 14) Síbẹ̀, Kristẹni kan lè bi ara rẹ̀ pé, ‘Báwo ni mo ṣe ń jẹ oúnjẹ tẹ̀mí tá à ń rí gbà tó?’ Ṣó o rí i, ibì kan wà nínú ọpọlọ tó máa ń jẹ́ kéèyàn mọ̀ pé ebi ń pa òun. Nínú ìwádìí táwọn kan fi ẹranko ṣe, wọ́n rí i pé nígbà tí nǹkan kan ṣe apá ibẹ̀ yẹn nínú ọpọlọ ẹranko náà, kò lè jẹun rárá nítorí pé oúnjẹ ò wù ú jẹ, ńṣe lebi pa á kú, bẹ́ẹ̀ oúnjẹ wà nílẹ̀ rẹ́kẹrẹ̀kẹ! Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí Kristẹni kan má mọ̀ pé ebi ń pa òun nípa tẹ̀mí débi tí ìyàn tẹ̀mí á fi mú un bó tilẹ̀ jẹ́ pé oúnjẹ tẹ̀mí pọ̀ yamùrá?
10 Ronú nípa ipò tó o wà lórí ọ̀rọ̀ yìí bó o ṣe ń gbé kókó tó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀ wò. Kókó náà ni pé: Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ tẹ̀mí. Wọ́n ní Òfin Mósè, èyí tó lè mú kí àjọṣe wọn pẹ̀lú Jèhófà lágbára; ètò wà pé kí wọ́n máa gbin ìmọ̀ Ọlọ́run sínú àwọn ọmọ wọn; àwọn wòlíì sì wà tó ń jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́. Síbẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í gbàgbé Jèhófà. Bíbélì sọ pé nígbà ayé Hóséà, “Wọ́n yó [nípa àwọn ohun ìní tara], ọkàn-àyà wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ga.” (Hóséà 13:6; Diutarónómì 8:11; 31:20) Tá ò bá fẹ́ kí ohun ìní tara di èyí tó ṣe pàtàkì sí wa ju àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run lọ, ojoojúmọ́ la gbọ́dọ̀ máa ṣọ́ra fún ewu yẹn.—Sefanáyà 2:3.
MÁ ṢÀÌ KA ÀWỌN OHUN TÓ TÚBỌ̀ ṢE PÀTÀKÌ SÍ
11, 12. (a) Nígbà ìjọba Ùsáyà, kí nìdí táwọn wòlíì náà fi fún àwọn èèyàn níṣìírí pé kí wọ́n padà sọ́dọ̀ Jèhófà? (b) Kí lohun pàtàkì tó yẹ káwọn èèyàn náà ṣe tí Jóẹ́lì tẹnu mọ́?
11 Ùsáyà (tí Bíbélì tún pè ní Asaráyà) ló ń jọba ní Júdà lákòókò tí Jèróbóámù Kejì ń ṣàkóso ní Ísírẹ́lì. Ùsáyà mú kí ààlà ilẹ̀ Júdà fẹ̀ sí i, ó sì mú Jerúsálẹ́mù gbòòrò. Ó “fi okun hàn dé ìwọ̀n àrà ọ̀tọ̀” nítorí pé ‘Ọlọ́run tòótọ́ ń bá a lọ láti ràn án lọ́wọ́.’ Ó “ń bá a nìṣó ní ṣíṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà” ó sì ‘tẹ̀ sí wíwá Ọlọ́run.’ Síbẹ̀, ní Júdà, ọ̀pọ̀ èèyàn ò jáwọ́ láti máa rúbọ láwọn ibi gíga.—2 Kíróníkà 26:4-9.
12 Látinú àkọsílẹ̀ yìí, wàá rí i pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn Júdà ń jẹ́ orúkọ mọ́ Ọlọ́run, wọ́n sábà máa ń mú àwọn nǹkan tí Ọlọ́run kò fẹ́ mọ́ ìjọsìn wọn. Àwọn wòlíì náà gbìyànjú láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ ìyàtọ̀ láàárín ìjọsìn tòótọ́ àti ìjọsìn èké. Ọlọ́run gbẹnu Jóẹ́lì pàrọwà fún wọn pé: “Ẹ padà sọ́dọ̀ mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà yín, àti pẹ̀lú ààwẹ̀ gbígbà àti pẹ̀lú ẹkún sísun àti pẹ̀lú ìpohùnréré ẹkún.” (Jóẹ́lì 2:12) Kíyè sí i pé: Ọlọ́run fẹ́ káwọn èèyàn òun ‘fi gbogbo ọkàn wọn’ padà sọ́dọ̀ òun. Èyí jẹ́ ká rí i pé ìṣòro wọn ni pé wọn kò fi gbogbo ọkàn wọn jọ́sìn Ọlọ́run. (Diutarónómì 6:5) Ó kàn dà bíi pé wọ́n ń jọ́sìn Jèhófà ni, ọkàn wọn ò sí lọ́dọ̀ rẹ̀. Léraléra ni Ọlọ́run ń tẹnu mọ́ ọn fún wọn nípasẹ̀ àwọn wòlíì rẹ̀ pé inú rere onífẹ̀ẹ́, ìdájọ́ òdodo àti ọkàn tútù ṣe pàtàkì, inú ọkàn sì ni gbogbo àwọn ànímọ́ yìí ti ń wá.—Mátíù 23:23.
13. Kí ló yẹ káwọn Júù tí wọ́n padà dé láti ìgbèkùn Bábílónì máa ṣe?
13 Tún wo ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn táwọn Júù padà sí ilẹ̀ wọn láti ìgbèkùn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù padà bẹ̀rẹ̀ ìjọsìn tòótọ́ lọ́nà tó bá Òfin mu, wọ́n ṣì ń ṣe àwọn nǹkan kan tó kù díẹ̀ káàtó. Wọ́n ń gbààwẹ̀ láwọn àyájọ́ ọjọ́ táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ nígbà ìparun Jerúsálẹ́mù wáyé. Ni Jèhófà bá bi wọ́n pé: “Ẹ ha gbààwẹ̀ sí mi ní tòótọ́, àní sí èmi?” Ìdájọ́ òdodo ni Ọlọ́run ṣe bó ṣe mú kí Jerúsálẹ́mù pa run, nítorí náà kì í ṣe ohun tó yẹ kí wọ́n máa ṣọ̀fọ̀ rẹ̀. Dípò káwọn Júù wọ̀nyẹn máa gbààwẹ̀ ìbànújẹ́ nígbà tí wọ́n rántí àwọn nǹkan tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, ńṣe ló yẹ kínú wọn máa dùn kí wọ́n sì máa yọ̀ láwọn àkókò àjọyọ̀ wọn nítorí ìbùkún tí ìjọsìn tòótọ́ ń mú wá. (Sekaráyà 7:3-7; 8:16, 19) Wọ́n sì tún ní láti kíyè sí àwọn nǹkan pàtàkì mìíràn. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà sọ fún wọn pé: “Ẹ fi ìdájọ́ òdodo tòótọ́ ṣe ìdájọ́ yín; kí ẹ sì máa bá a lọ ní ṣíṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti àánú sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì . . . ẹ má sì pète-pèrò nǹkan búburú sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì nínú ọkàn-àyà yín.” (Sekaráyà 7:9, 10) Gbogbo wa la lè jàǹfààní nínú ohun táwọn wòlíì wọ̀nyẹn kọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run lórí ọ̀rọ̀ fífi gbogbo ọkàn jọ́sìn Ọlọ́run.
14. (a) Kí ló yẹ káwọn Júù tó padà láti ìgbèkùn jẹ́ kó wà lára ìjọsìn wọn? (b) Báwo làwọn wòlíì náà ṣe tẹnu mọ́ àwọn apá tó túbọ̀ ṣe pàtàkì nínú ìjọsìn?
14 Àwọn nǹkan wo ló jẹ́ ara ìjọsìn àfi-gbogbo-ọkàn-ṣe? Ó dáa, kí ni Ọlọ́run béèrè lọ́wọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ kí wọ́n tó lọ sígbèkùn àti lẹ́yìn tí wọ́n ti ìgbèkùn dé? Ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé kí wọ́n máa pa ìlànà òun lórí irú ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù mọ́. Àwọn nǹkan kan sì tún wà tí Òfin tó fún wọn ní kí wọ́n máa ṣe. Ara rẹ̀ ni pé kí wọ́n máa pé jọ pọ̀ láti gbọ́ àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́, kí wọ́n sì mọ̀ ọ́n. Láfikún, Ọlọ́run tún ní káwọn wòlíì tẹnu mọ́ ọn pé ó yẹ kí wọ́n sapá láti ní inú rere onífẹ̀ẹ́, ọkàn tútù àti àánú, kí wọ́n jẹ́ ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà kí wọ́n sì máa ṣe ìdájọ́ òdodo. Kíyè sí bí Jèhófà ṣe tẹnu mọ́ àwọn ànímọ́ wọ̀nyí. Ó sọ pé: “Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ni mo ní inú dídùn sí, kì í sì í ṣe ẹbọ; àti ìmọ̀ nípa Ọlọ́run dípò àwọn odindi ọrẹ ẹbọ sísun.” Ó tún sọ pé: “Ẹ fún irúgbìn fún ara yín ní òdodo; ẹ kárúgbìn ní ìbámu pẹ̀lú inú-rere-onífẹ̀ẹ́.” (Hóséà 6:6; 10:12; 12:6) Bákan náà, Míkà kéde pé: “Kí sì ni ohun tí Jèhófà ń béèrè láti ọ̀dọ̀ rẹ bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo, kí o sì nífẹ̀ẹ́ inú rere, kí o sì jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn?” (Míkà 6:6-8) Wòlíì Sefanáyà pẹ̀lú rọ àwọn èèyàn Ọlọ́run pé: “Ẹ wá Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́kàn tútù ilẹ̀ ayé . . . Ẹ wá òdodo, ẹ wá ọkàn-tútù.” (Sefanáyà 2:3) Àwọn ànímọ́ wọ̀nyẹn pọn dandan nínú ìjọsìn tí Ọlọ́run fẹ́.
15. Níbàámu pẹ̀lú ìṣílétí àwọn wòlíì náà, kí làwa Kristẹni ní láti máa ṣe nínú ìjọsìn wa?
15 Ipa wo làwọn ànímọ́ wọ̀nyẹn ń kó nínú ìjọsìn wa? O mọ̀ pé wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ṣe pàtàkì gan-an. (Mátíù 24:14; Ìṣe 1:8) Àmọ́ o lè bi ara rẹ pé: ‘Ṣé mo máa ń wo jíjẹ́rìí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ mi gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tó le gan-an, pé ó kàn jẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ni? Àbí ńṣe ni mò ń wò ó gẹ́gẹ́ bí àǹfààní láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tó ń fúnni níyè? Ǹjẹ́ mò ń fi àánú hàn?’ Ó yẹ kí àánú àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sún wa láti kìlọ̀ fáwọn èèyàn nípa ọjọ́ Jèhófà. Bákan náà, ó yẹ kí ìdájọ́ òdodo àti òdodo mú ká máa gbìyànjú láti mú ọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ Jèhófà dé ọ̀dọ̀ onírúurú èèyàn.—1 Tímótì 2:4.
16, 17. Kí nìdí tí ọkàn tútù àti ìmẹ̀tọ́mọ̀wà fi ṣe pàtàkì nínú ìjọsìn rẹ?
16 Tún gbé àpẹẹrẹ mìíràn yẹ̀ wò, ìyẹn ojúṣe wa láti máa lọ sí ìpàdé ìjọ, èyí tó o mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì. (Hébérù 10:24, 25) Ǹjẹ́ o ti ronú rí nípa bí ìyẹn ṣe béèrè pé kéèyàn ní ọkàn tútù kó sì jẹ́ ẹni tó mẹ̀tọ́mọ̀wà? Àwọn tí wọ́n ní ọkàn tútù máa ń ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ láti gba ìtọ́ni kí wọ́n sì fi ohun tí wọ́n kọ́ sílò, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ fi ìdájọ́ Jèhófà ṣèwà hù. Ẹni tó bá mẹ̀tọ́mọ̀wà, tàbí lédè mìíràn, ẹni tó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, máa ń mọ ibi tí òun kù sí, ìyẹn á sì jẹ́ kó mọ̀ pé òun nílò ìṣírí àti ìmọ̀ tá a máa ń rí gbà láwọn ìpàdé ìjọ.
17 Nínú àpẹẹrẹ wíwàásù àti lílọ sí ìpàdé ìjọ tá a gbé yẹ̀ wo yìí, wàá rí i pé a lè jàǹfààní nínú ohun táwọn wòlíì náà kọ́ni. Àmọ́, tó o bá rí i pé ó yẹ kó o ṣàtúnṣe ní ìhà kan tàbí méjì nínú àwọn àpẹẹrẹ náà ńkọ́? Tàbí tó o bá ti ṣe àwọn àṣìṣe kan sẹ́yìn, èyí tó máa ń bà ọ́ nínú jẹ́ tó o bá rántí? Ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì méjìlá náà á tù ọ́ nínú wọ́n á sì ràn ọ́ lọ́wọ́.
PADÀ SỌ́DỌ̀ JÈHÓFÀ
18. (a) Àwọn wo ní pàtàkì làwọn wòlíì méjìlá náà jíṣẹ́ tó ń tuni nínú fún? (b) Èrò wo lo ní nípa Jèhófà pẹ̀lú bó ṣe máa ń rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n padà sọ́dọ̀ òun?
18 Gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i, ìdálẹ́bi àti ìdájọ́ nìkan kọ́ làwọn wòlíì tá à ń gbé yẹ̀ wò yìí kéde. Wọ́n fi Jèhófà hàn gẹ́gẹ́ bi ẹni tó ń rọ àwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n padà sọ́dọ̀ òun. Ronú lórí ohun tó mú Hóséà pàrọwà pé: “Ẹ wá, ẹ̀yin ènìyàn, ẹ sì jẹ́ kí a padà sọ́dọ̀ Jèhófà, nítorí òun fúnra rẹ̀ ti fà [wá] ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, ṣùgbọ́n òun yóò mú wa lára dá. Ó ń bá a nìṣó ní kíkọlù [wá], ṣùgbọ́n òun yóò di ọgbẹ́ wa. . . . Àwa yóò sì mọ̀, a óò lépa láti mọ Jèhófà.” (Hóséà 6:1-3) Òótọ́ ni pé ìdájọ́ òdodo Jèhófà Ọlọ́run mú kó mú ìdájọ́ rẹ̀ wá sórí Ísírẹ́lì, àti lẹ́yìn náà sórí Júdà. Àmọ́, ńṣe ló yẹ káwọn èèyàn náà wo ìyà tí Jèhófà fi jẹ wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tó fẹ́ gbà ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè padà sọ́dọ̀ rẹ̀. (Hébérù 12:7-13) Bí àwọn èèyàn Jèhófà tó ya oníwàkiwà wọ̀nyẹn bá padà sọ́dọ̀ Jèhófà, ‘yóò mú wọn lára dá’ yóò sì ‘di ọgbẹ́ wọn.’ Fojú inú wo ọkùnrin kan tó kúnlẹ̀ láti di ọgbẹ́ ẹlòmíràn. Wá rò ó pé Jèhófà ló ń di ọgbẹ́ náà. O ò rí i pé Ọlọ́run aláàánú ni Jèhófà, tó máa ń di ọgbẹ́ àwọn tó bá padà sọ́dọ̀ rẹ̀! Ǹjẹ́ èyí ò mú ká fẹ́ láti padà sọ́dọ̀ rẹ̀ tá a bá dẹ́ṣẹ̀ sí i?—Jóẹ́lì 2:13.
19. Kí ni ohun tó pọn dandan nínú mímọ Jèhófà?
19 Kí lèèyàn ní láti ṣe láti lè padà sọ́dọ̀ Jèhófà? Hóséà rán wa létí pé kì í ṣe pé kéèyàn wulẹ̀ ‘mọ’ Jèhófà o, kàkà bẹ́ẹ̀, èèyàn ní láti ‘lépa mímọ Jèhófà.’ Ìwádìí ẹnu àìpẹ́ yìí kan lórí Hóséà 6:3 sọ pé: “Ìyàtọ̀ gédégédé wà láàárín kéèyàn mọ̀ nípa Ọlọ́run àti kéèyàn mọ Ọlọ́run. A lè fi wé ìyàtọ̀ tó wà láàárín kéèyàn máa ka ọ̀rọ̀ ìfẹ́ nínú ìwé àti kí ìfẹ́ ẹnì kan wọ èèyàn lọ́kàn.” A gbọ́dọ̀ ní ìmọ̀ tó jinlẹ̀ nípa Jèhófà, kó má kàn jẹ́ ìmọ̀ oréfèé lásán. A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí Jèhófà di ẹni gidi sí wa, kó jẹ́ Ọ̀rẹ́ tá a gbẹ́kẹ̀ lé tá a sì lè tọ̀ lọ nígbàkigbà. (Jeremáyà 3:4) Tó o bá ní irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà, nígbà tó o bá ṣe nǹkan kan, wàá lè róye bí nǹkan náà ṣe rí lára rẹ̀, ìrànlọ́wọ́ ńlá sì nìyẹn á jẹ́ fún ọ bó o ṣe ń sapá láti jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tí Jèhófà fẹ́.
20, 21. Báwo ni Jòsáyà Ọba ṣe fi ìmọ̀ tó ní nípa Ọlọ́run sílò?
20 Jòsáyà Ọba jẹ́ àpẹẹrẹ rere nínú kéèyàn máa sapá láti ṣe ìjọsìn tòótọ́. Gbé ọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yẹ̀ wò síwájú sí i. Nígbà tí Jòsáyà fi máa di ọba, ìbọ̀rìṣà, ìwà ipá àti ẹ̀tàn tó ti gbalé gbòde látìgbà ìṣàkóso Mánásè àti Ámónì ti ba orílẹ̀-èdè náà jẹ́. (2 Àwọn Ọba 21:1-6, 19-21) Kò sí àní-àní pé ọ̀rọ̀ ìṣílétí tí Sefanáyà sọ pé káwọn èèyàn náà “wá Jèhófà” ní ipa rere lórí Jòsáyà, nítorí pé “ó bẹ̀rẹ̀ sí wá Ọlọ́run Dáfídì.” Jòsáyà ṣètò bí ìbọ̀rìṣà ṣe máa dàwátì ní Júdà, kódà ó gbé ètò yìí dé ibi tó ti fìgbà kan jẹ́ ilẹ̀ ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì.—Sefanáyà 1:1, 14-18; 2:1-3; 3:1-4; 2 Kíróníkà 34:3-7.
21 Lẹ́yìn iṣẹ́ ìfọ̀mọ́ tí Jòsáyà ṣe, ó ń bá a nìṣó láti wá Jèhófà. Ó pàṣẹ pé kí wọ́n tún tẹ́ńpìlì ṣe. Nígbà tí wọ́n ń ṣàtúnṣe náà, wọ́n rí “ìwé òfin Jèhófà láti ọwọ́ Mósè,” tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìwé Òfin tí Mósè fọwọ́ ara rẹ̀ kọ. Báwo ni Jòsáyà ṣe ṣe nígbà tí wọ́n ka ìwé náà? Àkọsílẹ̀ náà sọ pé, “gbàrà tí ọba gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ òfin náà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó gbọn ẹ̀wù ara rẹ̀ ya.” Ó ‘fa ọkàn rẹ̀ ya’ pẹ̀lú ó sì ṣe ohun tí wọ́n kà lọ́gán. Kò gbìyànjú láti dá ara rẹ̀ láre, pé òun sáà ti ṣe bẹbẹ kó tó di pé wọ́n rí ìwé náà. Ǹjẹ́ o rántí àbájáde iṣẹ́ ìfọ̀mọ́ tó ṣe? Àkọsílẹ̀ náà ń bá a lọ pé, “Ní gbogbo ọjọ́ rẹ̀, [àwọn ọmọ Ísírẹ́lì] kò yà kúrò nínú títọ Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn lẹ́yìn.”—2 Kíróníkà 34:8, 14, 19, 21, 30-33; Jóẹ́lì 2:13.
22. Báwo la ṣe lè jàǹfààní nínú àpẹẹrẹ Jòsáyà?
22 Wàyí o, o lè béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé, ‘ká sọ pé èmi ni Jòsáyà, kí ni ǹ bá ṣe?’ Bẹ́ẹ̀ ni, ǹjẹ́ ìwọ ì bá fetí sáwọn wòlíì náà kó o sì ṣe àwọn àtúnṣe tó bá yẹ nínú ìṣe àti ìrònú rẹ bíi ti Jòsáyà? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbà ayé Sefanáyà àti Jòsáyà kọ́ la wà yìí, a rí ìdí tó fi yẹ ká máa fi àwọn ohun tí Ọlọ́run ń sọ fún wa lónìí àti ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò. Nítorí náà, tí Kristẹni kan bá rí i pé ó yẹ kóun ṣàtúnṣe sí bóun ṣe ń jọ́sìn tàbí ọ̀nà tí òun ń gbà gbé ìgbésí ayé, tó bá gbé ìwé àwọn wòlíì méjìlá náà yẹ̀ wò, èyí lè ràn án lọ́wọ́.—Hébérù 2:1.
23. Tó o bá rí i pé ó yẹ kó o ṣe àwọn àtúnṣe kan, kí lo lè ṣe?
23 Nígbà míì, ó lè máa ṣe ọ́ bó ṣe ṣe Jónà nígbà tó wà nínú ikùn ẹja ńlá náà. Jónà sọ pé: “A ti lé mi kúrò níwájú rẹ! Báwo ni èmi yóò ṣe tún lè tẹjú mọ́ tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ?” (Jónà 2:4) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé aláìpé làwa ẹ̀dá èèyàn tó sì ṣeé ṣe ká ṣàṣìṣe, ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fi wá lọ́kàn balẹ̀ gan-an ni, ó ní: “Ẹ padà sọ́dọ̀ mi, dájúdájú, èmi yóò sì padà sọ́dọ̀ yín.” (Málákì 3:7) Tó o bá rí i pé ó yẹ kó o jẹ́ kí àjọṣe àárín ìwọ àti Jèhófà túbọ̀ gún régé, àwọn alàgbà ìjọ rẹ á ràn ọ́ lọ́wọ́. Ibi pẹlẹbẹ la ti í mọ́ọ̀lẹ̀ jẹ, ibi kékeré ni wàá ti bẹ̀rẹ̀ àtúnṣe tó o fẹ́ ṣe. Tó o bá ti lè bẹ̀rẹ̀ báyìí, kò ní ṣòro fún ọ láti máa bá àtúnṣe náà lọ dórí èyí tó túbọ̀ ṣe pàtàkì. Sì jẹ́ kó dá ọ lójú pé Jèhófà yóò tẹ́wọ́ gbà ọ́ yóò sì ràn ọ́ lọ́wọ́, nítorí pé ó jẹ́ “olóore ọ̀fẹ́ àti aláàánú, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́.” (Jóẹ́lì 2:12-14) Dájúdájú, iṣẹ́ tí àwọn wòlíì náà jẹ́ lè fún gbogbo àwọn tó ń sapá láti máa jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tí Ọlọ́run ń fẹ́ níṣìírí.