Jehofa Ń Fúnni ní Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Àlàáfíà àti Òtítọ́
“Èmi óò . . . wò wọ́n sàn, èmi óò sì fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà àti òtítọ́ hàn fún wọn.”—JEREMIAH 33:6.
1, 2. (a) Ní ti àlàáfíà, àkọsílẹ̀ wo ni àwọn orílẹ̀-èdè ni? (b) Ní ọdún 607 Ṣáájú Sànmánì Tiwa, ẹ̀kọ́ wo ni Jehofa kọ́ Israeli nípa àlàáfíà?
ÀLÀÁFÍÀ! Ẹ wo bí ìyẹn ṣe jẹ́ ohun fífani lọ́kàn mọ́ra tó, síbẹ̀ ẹ wo bí ó ṣe ṣọ̀wọ́n tó nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn! Ní pàtàkì, ọ̀rúndún ogún, kì í ṣe ọ̀rúndún alálàáfíà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ti rí ogun méjì tí ó jẹ́ apanirun jù lọ nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn. Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní, a gbé Ìmùlẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè kalẹ̀ láti bójú tó àlàáfíà ayé. Ètò àjọ yẹn kùnà. Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, a dá ètò àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀ pẹ̀lú ète kan náà. Kíka ìwé ìròyìn ojoojúmọ́ lásán lè mú kí a rí bí ó ṣe kùnà pátápátá tó.
2 Ó ha yẹ kí ó yà wá lẹ́nu pé, ètò àjọ ẹ̀dá ènìyàn kò lè mú àlàáfíà wá bí? Rárá o. Ní ohun tí ó lé ní 2,500 ọdún sẹ́yìn, a kọ́ àwọn ènìyàn àyànfẹ́ Ọlọrun, Israeli, lẹ́kọ̀ọ́ kan nípa èyí. Ní ọ̀rúndún keje Ṣáájú Sànmánì Tiwa, Babiloni, agbára ayé atẹnilóríba, wu àlàáfíà Israeli léwu. Israeli yíjú sí Egipti fún àlàáfíà. Egipti kùnà. (Jeremiah 37:5-8; Esekieli 17:11-15) Ní ọdún 607 Ṣáájú Sànmánì Tiwa, àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Babiloni bi ògiri Jerusalemu ṣubú, wọ́n sì dáná sun tẹ́ḿpìlì Jehofa. Nípa báyìí, Israeli kẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà líle koko, nípa bí gbígbára lé ètò àjọ ẹ̀dá ènìyàn ti jẹ́ ìmúlẹ̀mófo tó. Dípò gbígbádùn àlàáfíà, a wọ́ orílẹ̀-èdè náà lọ sí ìgbèkùn ní Babiloni.—2 Kronika 36:17-21.
3. Ní ìmúṣẹ àwọn ọ̀rọ̀ tí Jehofa tẹnu Jeremiah sọ, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé wo ni ó kọ́ Israeli lẹ́kọ̀ọ́ kejì pàtàkì nípa àlàáfíà?
3 Ṣùgbọ́n, kí Jerusalemu tó ṣubú, Jehofa ti ṣí i payá pé, òun ni yóò mú àlàáfíà wá fún Israeli, kì í ṣe Egipti. Ó tipasẹ̀ Jeremiah ṣèlérí pé: “Èmi óò . . . wò wọ́n sàn, èmi óò sì fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà àti òtítọ́ hàn fún wọn. Èmi óò sì mú ìgbèkùn Juda àti ìgbèkùn Israeli padà wá, èmi óò sì gbé wọn ró gẹ́gẹ́ bíi ti ìṣáájú.” (Jeremiah 33:6, 7) Ìlérí Jehofa bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìmúṣẹ ní ọdún 539 Ṣáájú Sànmánì Tiwa, nígbà tí a ṣẹ́gun Babiloni, tí a sì fún àwọn ọmọ Israeli tí wọ́n wà nígbèkùn ní òmìnira. (2 Kronika 36:22, 23) Nígbà tí yóò fi di apá ìparí ọdún 537 Ṣáájú Sànmánì Tiwa, fún ìgbà àkọ́kọ́ nínú 70 ọdún, àwùjọ àwọn ọmọ Israeli kan ṣayẹyẹ Àjọ Àgọ́ lórí ilẹ̀ Israeli! Lẹ́yìn àjọ náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í tún tẹ́ḿpìlì Jehofa kọ́. Kí ni ìmọ̀lára wọn nípa èyí? Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Gbogbo ènìyàn náà sì hó ìhó ńlá, nígbà tí wọ́n ń yin Oluwa, nítorí tí a fi ìpìlẹ̀ ilé Oluwa lélẹ̀.”—Esra 3:11.
4. Báwo ni Jehofa ṣe ru àwọn ọmọ Israeli sókè láti ṣe iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ḿpìlì náà, ìlérí wo ni ó sì ṣe nípa àlàáfíà?
4 Ṣùgbọ́n, lẹ́yìn ìbẹ̀rẹ̀ amọ́kànyọ̀ yẹn, àwọn alátakò kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn ọmọ Israeli, wọ́n sì dá iṣẹ́ kíkọ́ tẹ́ḿpìlì náà dúró. Ní àwọn ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, Jehofa gbé wòlíì Haggai àti Sekariah dìde láti ru àwọn ọmọ Israeli sókè láti parí iṣẹ́ ilé kíkọ́ náà. Ẹ wo bí yóò ti mọ́kàn wọn yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ tó láti gbọ́ tí Haggai ń sọ nípa tẹ́ḿpìlì náà tí wọn yóò tún kọ́ pé: “Ògo ilé ìkẹyìn yìí yóò pọ̀ ju ti ìṣáájú lọ, ni Oluwa àwọn ọmọ ogun wí: níhìn-ín yìí ni èmi óò sì fi àlàáfíà fúnni”!—Haggai 2:9.
Jehofa Ń Mú Ìlérí Rẹ̀ Ṣẹ
5. Kí ni ó yẹ fún àfiyèsí nípa Sekariah orí kẹjọ?
5 Nínú ìwé Sekariah nínú Bibeli, a kà nípa ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìran àti àsọtẹ́lẹ̀ tí a mí sí, tí ó fún àwọn ènìyàn Ọlọrun lókun nígbà náà lọ́hùn-ún ní ọ̀rúndún kẹfà Ṣáájú Sànmánì Tiwa. Àwọn ìlérí wọ̀nyí kan náà ń bá a nìṣó láti máa fi wá lọ́kàn balẹ̀ nípa ìtìlẹyìn Jehofa. Wọ́n ń fún wa ní gbogbo ìdí láti gbà gbọ́ pé Jehofa yóò fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní àlàáfíà ní ọjọ́ wa pẹ̀lú. Fún àpẹẹrẹ, nínú orí kẹjọ ìwé náà tí ń jẹ́ orúkọ rẹ̀, wòlíì náà, Sekariah sọ ọ̀rọ̀ náà: ‘Báyìí ni Oluwa wí,’ nígbà mẹ́wàá. Nígbà kọ̀ọ̀kan, gbólóhùn náà ń nasẹ̀ ìkéde àtọ̀runwá tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àlàáfíà àwọn ènìyàn Ọlọrun. Àwọn kan nínú ìlérí wọ̀nyí ní ìmúṣẹ nígbà náà lọ́hùn-ún ní ọjọ́ Sekariah. Gbogbo wọn ti ní ìmúṣẹ, tàbí wọ́n wà lẹ́nu níní ìmúṣẹ lónìí.
“Èmi Yóò Jowú fún Sioni”
6, 7. Ní àwọn ọ̀nà wo ni Jehofa fi ‘jowú fún Sioni pẹ̀lú ìrunú ńláǹlà’?
6 Gbólóhùn náà kọ́kọ́ fara hàn ní Sekariah 8:2 (NW), níbi tí a ti kà pé: “Báyìí ni Jehofa àwọn ọmọ ogun wí, ‘Èmi yóò jowú fún Sioni pẹ̀lú owú ńláǹlà, àti pẹ̀lú ìrunú ńláǹlà ni èmi yóò jowú fún un.’” Ìlérí Jehofa láti jowú, láti ní ìtara ńláǹlà, fún àwọn ènìyàn rẹ̀ túmọ̀ sí pé, òun yóò wà lójúfò láti mú àlàáfíà wọn padà. Mímú Israeli padà bọ̀ sí ilẹ̀ rẹ̀, àti títún tẹ́ḿpìlì rẹ̀ kọ́, jẹ́ ẹ̀rí ìtara náà.
7 Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn tí wọ́n ti ta ko àwọn ènìyàn Jehofa ńkọ́? Bí ìtara rẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ti tó, bẹ́ẹ̀ ni “ìrunú ńláǹlà” rẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá wọ̀nyí yóò ṣe tó. Nígbà tí àwọn Júù olùṣòtítọ́ bá ń jọ́sìn ní tẹ́ḿpìlì tí a tún kọ́ náà, wọn yóò lè rántí àbájáde búburú tí Babiloni alágbára, tí ó ti ṣubú nísinsìnyí ní. Wọ́n tún lè ronú nípa ìkùnà pátápátá tí o dé bá àwọn ọ̀tá wọn tí wọ́n gbìyànjú láti dí kíkọ́ tẹ́ḿpìlì náà lọ́wọ́. (Esra 4:1-6; 6:3) Wọ́n sì lè dúpẹ́ lọ́wọ́ Jehofa pé, ó ti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Ìtara rẹ̀ mú ìṣẹ́gun wá fún wọn!
“Ìlú Ńlá Òtítọ́”
8. Ní àwọn ọjọ́ Sekariah, báwo ni Jerusalemu yóò ṣe di ìlú ńlá òtítọ́ ní ìyàtọ̀ sí ti ìgbà ìjímìjí?
8 Nígbà kejì, Sekariah kọ̀wé pé: “Báyìí ni Oluwa wí.” Kí ni ohun tí Jehofa sọ lákòókò yìí? “Mo ti yí padà sí Sioni èmi óò sì gbé àárín Jerusalemu: a óò sì pe Jerusalemu ní ìlú ńlá òtítọ́; àti òkè ńlá Oluwa àwọn ọmọ ogun, òkè ńlá mímọ́ nì.” (Sekariah 8:3) Ṣáájú ọdún 607 Ṣáájú Sànmánì Tiwa, ó dájú pé, Jerusalemu kì í ṣe ìlú ńlá òtítọ́ lọ́nàkọnà. Àwọn àlùfáà àti wòlíì rẹ̀ kún fún ìwà ìbàjẹ́, àwọn ènìyàn rẹ̀ sì jẹ́ aláìṣòótọ́. (Jeremiah 6:13; 7:29-34; 13:23-27) Nísinsìnyí, àwọn ènìyàn Ọlọrun ń tún tẹ́ḿpìlì náà kọ́, ní fífi ìfọkànsìn wọn fún ìjọsìn mímọ́ gaara hàn. Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jehofa gbé ní Jerusalemu nípa tẹ̀mí. Lẹ́ẹ̀kan sí i, a sọ̀rọ̀ òtítọ́ nípa ìjọsìn mímọ́ gaara níbẹ̀, nítorí náà, a lè pe Jerusalemu ni “ìlú ńlá òtítọ́.” A lè pe ibi gíga tí ó wà ní “òkè ńlá Oluwa.”
9. Ìyípadà pípẹtẹrí wo ní ti ipò, ni “Israeli Ọlọrun” nírìírí rẹ̀ ní 1919?
9 Bí àwọn ìkéde méjì wọ̀nyí ṣe nítumọ̀ fún Israeli ìgbàanì, wọ́n tún nítumọ̀ púpọ̀ sí i fún wa pẹ̀lú bí ọ̀rúndún ogún yìí ṣe ń parí lọ. Ní nǹkan bí 80 ọdún sẹ́yìn, nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, ẹgbẹ̀rún díẹ̀ àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n ṣojú fún “Israeli Ọlọrun” nígbà náà lọ́hùn-ún, lọ sí ìgbèkùn nípa tẹ̀mí, gan-an gẹ́gẹ́ bí Israeli ìgbàanì ṣe lọ sí ìgbèkùn ní Babiloni. (Galatia 6:16) Lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀, a ṣàpèjúwe wọn bí àwọn òkú tí ó wà nílẹ̀ ní òpópónà. Síbẹ̀, wọ́n ní ìfẹ́ àtọkànwá láti jọ́sìn Jehofa “ní ẹ̀mí ati òtítọ́.” (Johannu 4:24) Nípa báyìí, ní 1919, Jehofa yí ìgbèkùn wọn padà, nípa jíjí wọn dìde láti inú ipò òkú nípa tẹ̀mí tí wọ́n wà. (Ìṣípayá 11:7-13) Nípa báyìí, Jehofa fi Bẹ́ẹ̀ ni tí ń dún léraléra dáhùn ìbéèrè alásọtẹ́lẹ̀ tí Isaiah béèrè pé: “Ilẹ̀ lè hu nǹkan jáde ní ọjọ́ kan bí? tàbí a ha lè bí orílẹ̀-èdè ní ẹ̀rìnkan?” (Isaiah 66:8) Ní 1919, lẹ́ẹ̀kan sí i, àwọn ènìyàn Jehofa wà gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan nípa tẹ̀mí nínú “ilẹ̀” tiwọn, tàbí nínú ipò tẹ̀mí lórí ilẹ̀ ayé.
10. Bẹ̀rẹ̀ ní 1919, àwọn ìbùkún wo ni àwọn Kristian ẹni àmì òróró ti ń gbádùn ní “ilẹ̀” wọn?
10 Bí wọ́n ti wà láìséwu nínú ilẹ̀ náà, àwọn Kristian ẹni àmì òróró ṣiṣẹ́ sìn nínú tẹ́ḿpìlì ńlá Jehofa nípa tẹ̀mí. A fi wọ́n hàn gẹ́gẹ́ bí “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú,” ní títẹ́wọ́ gba ẹrù iṣẹ́ bíbójú tó àwọn nǹkan ìní Jesu lórí ilẹ̀ ayé, àǹfààní kan tí wọ́n ṣì ń gbádùn bí ọ̀rúndún ogún ti ń parí lọ. (Matteu 24:45-47) Wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ náà jinlẹ̀ pé Jehofa ni “Ọlọrun àlàáfíà fúnra rẹ̀.”—1 Tessalonika 5:23.
11. Báwo ni àwọn aṣáájú ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣe fi ara wọn hàn pé wọ́n jẹ́ ọ̀tá àwọn ènìyàn Ọlọrun?
11 Ṣùgbọ́n, àwọn ọ̀tá Israeli Ọlọrun ńkọ́? Bí ìtara Jehofa fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ti tó, bẹ́ẹ̀ ni ìrunú rẹ̀ sí àwọn ọ̀tá náà ṣe tó. Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, àwọn aṣáájú ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù fúngun mọ́ wọn, wọ́n gbìyànjú—wọ́n sì kùnà—láti sọ àwùjọ kékeré ti àwọn Kristian olùsọ òtítọ́ yìí di àwáàrí. Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, ohùn àwọn òjíṣẹ́ Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣọ̀kan nínú ohun kan ṣoṣo: Ní ìhà àwọn méjèèjì tí ń bá ara wọn jà, wọ́n rọ ìjọba láti tẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa rì. Lónìí pàápàá, ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, àwọn aṣáájú ìsìn ń ru ìjọba sókè láti dá iṣẹ́ ìwàásù Kristian ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa dúró tàbí kí wọ́n fòfin dè é.
12, 13. Báwo ni Jehofa ṣe fi ìrunú rẹ̀ hàn sí Kirisẹ́ńdọ̀mù?
12 Jehofa ti ṣàkíyèsí èyí. Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní, Kirisẹ́ńdọ̀mù, pa pọ̀ pẹ̀lú ìyókù Babiloni Ńlá, ṣubú. (Ìṣípayá 14:8) Òtítọ́ náà pé Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣubú wá sí ojútáyé, bẹ̀rẹ̀ ní 1922, nígbà tí a tú ọ̀wọ́ àwọn ìyọnu ìṣàpẹẹrẹ jáde, tí ń tú àṣírí ipò òkú rẹ̀ nípa tẹ̀mí ní gbangba, tí ó sì ń kìlọ̀ ìparun rẹ̀ tí ń bọ̀. (Ìṣípayá 8:7–9: 21) Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé títú àwọn ìyọnu wọ̀nyí jáde ń bá a lọ, a sọ àsọyé náà, “Òpin Ìsìn Èké Ti Súnmọ́lé,” káàkiri àgbáyé ní April 23, 1995, tí ìpínkiri ọgọ́rọ̀ọ̀rún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ẹ̀dá àkànṣe ìtẹ̀jáde Ìròyìn Ìjọba sì tẹ̀ lé e.
13 Lónìí, Kirisẹ́ńdọ̀mù wà ní ipò tí ó ṣeni láàánú. Jálẹ̀ ọ̀rúndún ogún, àwọn mẹ́ḿbà rẹ̀ ti pa ara wọn nínú àwọn ogun rírorò tí àwọn àlùfáà àti òjíṣẹ́ rẹ̀ yà sí mímọ́. Ní àwọn ilẹ̀ kan, ipa rẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di àwátì. A ti kádàrá rẹ̀ fún ìparun pa pọ̀ pẹ̀lú ìyókù Babiloni Ńlá.—Ìṣípayá 18:21.
Àlàáfíà fún Àwọn Ènìyàn Jehofa
14. Ọ̀rọ̀ àpèjúwe alásọtẹ́lẹ̀ wo ni a fúnni nípa àwọn ènìyàn tí wọ́n wà lálàáfíà?
14 Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, ní ọdún 1996 yìí, àwọn ènìyàn Jehofa ń gbádùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà nínú ilẹ̀ wọn tí a mú padà bọ̀ sípò, bí a ti ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú ìkéde kẹta tí Jehofa ṣe pé: “Báyìí ni Oluwa àwọn ọmọ ogun wí, arúgbó ọkùnrin àti arúgbó obìnrin, yóò sáà gbé ìgboro Jerusalemu, àti olúkúlùkù tí òun ti ọ̀pá ní ọwọ́ rẹ̀ fún ogbó. Ìgboro ìlú yóò sì kún fún ọmọdékùnrin àti ọmọdébìnrin, tí ń ṣiré ní ìta wọn.”—Sekariah 8:4, 5.
15. Láìka ogun àwọn orílẹ̀-èdè sí, àlàáfíà wo ni àwọn ìránṣẹ́ Jehofa ti gbádùn?
15 Ọ̀rọ̀ dídùn yìí gbé àwòrán ohun kan tí ó pẹtẹrí nínú ayé tí ogun ti fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ yìí yọ síni lọ́kàn—àwọn ènìyàn tí wọ́n wà lálàáfíà. Láti 1919, àwọn ọ̀rọ̀ aláṣọtẹ́lẹ̀ tí Isaiah sọ ti ní ìmúṣẹ pé: “Àlàáfíà, àlàáfíà fún ẹni tí ó jìnnà réré, àti fún ẹni tí ó wà nítòsí, ni Oluwa wí; èmi óò sì mú un ní ara dá. Ṣùgbọ́n . . . àlàáfíà kò sí fún àwọn ènìyàn búburú, ni Ọlọrun mi wí.” (Isaiah 57:19-21) Àmọ́ ṣáá o, àwọn ènìyàn Jehofa, bí wọn kò ti jẹ́ apá kan ayé, kò lè yẹra fún fífara gbá rúkèrúdò àwọn orílẹ̀-èdè. (Johannu 17:15, 16) Ní àwọn ilẹ̀ kan, wọ́n ń fara da àwọn ìṣòro mímúná, a sì ti pa àwọn mélòó kan pàápàá. Síbẹ̀, àwọn ojúlówó Kristian ní àlàáfíà ní ọ̀nà méjì pàtàkì. Èkíní, wọ́n ní “àlàáfíà pẹlu Ọlọrun nípasẹ̀ Oluwa [wọn] Jesu Kristi.” (Romu 5:1) Èkejì, wọ́n ní àlàáfíà láàárín ara wọn. Wọ́n ń mú “ọgbọ́n tí ó wá lati òkè,” èyí tí ó “kọ́kọ́ mọ́níwà, lẹ́yìn naa [tí] ó lẹ́mìí-àlàáfíà,” dàgbà. (Jakọbu 3:17; Galatia 5:22-24) Ní àfikún sí i, wọ́n ń fojú sọ́nà fún gbígbádùn àlàáfíà lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ jù lọ nígbà tí ‘àwọn ọlọ́kàn tútù bá jogún ayé, tí wọ́n bá sì ń ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.’—Orin Dafidi 37:11.
16, 17. (a) Báwo ni àwọn “arúgbó ọkùnrin àti arúgbó obìnrin” àti “ọmọdékùnrin, àti ọmọdébìnrin” ṣe fún ètò àjọ Jehofa lókun? (b) Kí ní ń fi àlàáfíà àwọn ènìyàn Jehofa hàn?
16 Àwọn “arúgbó ọkùnrin àti arúgbó obìnrin” wà lára àwọn ènìyàn Jehofa, àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n rántí ìṣẹ́gun ìjímìjí tí ètò àjọ Jehofa ní. A mọrírì ìṣòtítọ́ àti ìfaradà wọn gan-an. Àwọn ọ̀dọ́ ẹni àmì òróró mú ìpò iwájú nígbà àwọn ọjọ́ gbígbóná janjan ti àwọn ọdún 1930, àti ní àkókò Ogun Àgbáyé Kejì, bákan náà sì ni ní àwọn ọdún arùmọ̀lárasókè ti ìbísí tí ó tẹ̀ lé e. Síwájú sí i, ní pàtàkì láti 1935, “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àwọn àgùtàn mìíràn” ti fi ara wọn hàn. (Ìṣípayá 7:9; Johannu 10:16) Bí àwọn Kristian ẹni àmì òróró ti ń darúgbó, tí wọ́n sì ń dín kù sí i, àwọn àgùntàn míràn ti tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìwàásù náà, wọ́n sì ti nasẹ̀ rẹ̀ jákèjádò ilẹ̀ ayé. Ní àwọn ọdún lọ́ọ́lọ́ọ́, àwọn àgùntàn míràn ti ń rọ́ wọnú ilẹ̀ àwọn ènìyàn Ọlọrun. Họ́wù, léṣìí nìkan, 338,491 lára wọn ṣe batisí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ìyàsímímọ́ wọn fún Jehofa! Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa tẹ̀mí, irú àwọn ẹni tuntun bẹ́ẹ̀ jẹ́ ọ̀dọ́ ní tòótọ́. A mọrírì ìtutù yọ̀yọ̀ àti ìtara ọkàn wọn, bí wọ́n ti ń mú ẹgbẹ́ àwọn tí ń kọrin ìyìn tí ó kún fún ìmoore sí “Ọlọrun wa, ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, ati Ọ̀dọ́ Àgùtàn naa,” pọ̀ sí i.—Ìṣípayá 7:10.
17 Lónìí, ‘ìgboro ìlú kún fún ọmọdékùnrin, àti ọmọdébìnrin,’ àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ní okun ọ̀dọ́. Nínú ìròyìn ọdún iṣẹ́ ìsìn 1995, a gba ìròyìn láti 232 ilẹ̀ àti erékùṣù okun. Ṣùgbọ́n, kò sí ìbánidíje orílẹ̀-èdè kan sí èkejì, kò sí ìkórìíra ẹ̀yà ìran kan sí èkejì, kò sí owú tí kò tọ́, láàárín àwọn ẹni àmì òróró àti àwọn àgùntàn míràn. Gbogbo wọn ń dàgbà pa pọ̀ nípa tẹ̀mí, ìfẹ́ mú wọn wà ní ìṣọ̀kan. Ní tòótọ́, lójú bí ipò ayé ṣe rí, ẹgbẹ́ ará àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa káàkiri àgbáyé jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́.—Kolosse 3:14; 1 Peteru 2:17.
Ó Ha Ṣòro Jù fún Jehofa Bí?
18, 19. Láti àwọn ọdún tí ó tẹ̀ lé 1919, báwo ni Jehofa ṣe ṣàṣeparí ohun tí ó ti lè dà bí ohun tí ó ṣòro jù, bí a bá fi ojú ẹ̀dá ènìyàn wò ó?
18 Nígbà náà lọ́hùn-ún, ní 1918, nígbà tí àwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró jẹ́ kìkì ẹgbẹ̀rún díẹ̀ ọkàn tí a mú rẹ̀wẹ̀sì nínú ìgbèkùn tẹ̀mí, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè sọ bí nǹkan yóò ti rí. Síbẹ̀síbẹ̀, Jehofa mọ̀—gẹ́gẹ́ bí ìkéde alásọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ kẹrin ti sọ pé: “Báyìí ni Jehofa àwọn ọmọ ogun wí, ‘Bí ó tilẹ̀ dà bí ohun tí ó ṣòro jù lójú àwọn ìyókù ènìyàn wọ̀nyí ní ọjọ́ wọnnì, yóò ha dà bí ohun tí ó ṣòro jù lójú mi pẹ̀lú bí?’ ni Jehofa àwọn ọmọ ogun wí.”—Sekariah 8:6, NW.
19 Ní 1919, ẹ̀mí Jehofa mú àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ jí fún iṣẹ́ tí ń bẹ níwájú. Síbẹ̀, ó béèrè ìgbàgbọ́ láti dúró ṣinṣin ti ètò àjọ kékeré ti àwọn olùjọsìn Jehofa. Wọ́n kéré jọjọ, ọ̀pọ̀ nǹkan ni ó sì rúni lójú. Bí ó ti wù kí ó rí, díẹ̀díẹ̀, Jehofa fún wọn lókun ní ti ìṣètò, ó sì mú wọn gbara dì láti ṣe iṣẹ́ Kristian ti wíwàásù ìhìn rere náà àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn. (Isaiah 60:17, 19; Matteu 24:14; 28:19, 20) Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fòye mọ àwọn ọ̀ràn pàtàkì bí àìdásítọ̀túntòsì àti ipò ọba aláṣẹ àgbáyé. Ó ha ṣòro jù fún Jehofa láti ṣàṣeparí ìfẹ́ inú rẹ̀ nípasẹ̀ àwùjọ kékeré ti àwọn Ẹlẹ́rìí yẹn bí? Dájúdájú, bẹ́ẹ̀ kọ́ ni ìdáhùn náà! Èyí hàn gbangba ní ojú ìwé 12 sí 15 ti ìwé ìròyìn yìí, èyí tí ó fi ṣáàtì ìgbòkègbodò àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fún ọdún iṣẹ́ ìsìn 1995 hàn.
“Èmi Óò Sì Jẹ́ Ọlọrun Wọn”
20. Báwo ni kíkó àwọn ènìyàn Ọlọrun jọ tí a sọ tẹ́lẹ̀ ti lọ jìnnà tó?
20 Ìkéde karùn-ún túbọ̀ fi ipò amọ́kànyọ̀ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa wà lónìí hàn: “Báyìí ni Oluwa àwọn ọmọ ogun wí pé, Kíyè sí i, èmi óò gba àwọn ènìyàn mi kúrò ní ilẹ̀ gábàsì, àti kúrò ni ilẹ̀ yámà; Èmi óò sì mú wọn wá, wọn óò sì máa gbé àárín Jerusalemu: wọn óò sì jẹ́ ènìyàn mi, èmi óò si jẹ́ Ọlọrun wọn, ní òtítọ́, àti ní òdodo.”—Sekariah 8:7, 8.
21. Ní ọ̀nà wo ni a gbà mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà àwọn ènìyàn Jehofa jọba, tí a sì mú un gbòòrò sí i?
21 Ní 1996, a lè sọ láìlọ́ tìkọ̀ pé, a ti wàásù ìhìn rere náà káàkiri ayé, láti “ilẹ̀ gábàsì” dé “ilẹ̀ yámà.” A ti sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, wọ́n sì ti rí ìmúṣẹ ìlérí Jehofa pé: “A óò sì kọ́ gbogbo àwọn ọmọ rẹ láti ọ̀dọ̀ Oluwa wá; àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò sì pọ̀.” (Isaiah 54:13) A ní àlàáfíà nítorí pé, Jehofa ti kọ́ wa. Pẹ̀lú ète yìí lọ́kàn, a ti tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ jáde ní èyí tí ó lé ní 300 èdè. Léṣìí nìkan, èdè 21 mìíràn ni a fi kún un. A ń tẹ ìwé ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà jáde lẹ́ẹ̀kan náà lóṣù nísinsìnyí ní èdè 111, àti Jí! ní èdè 54. Àwọn àpéjọpọ̀ orílẹ̀-èdè àti ti àgbáyé ń fi àlàáfíà àwọn ènìyàn Ọlọrun hàn ní gbangba. Àwọn ìpàdé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ń mù wa wà ní ìṣọ̀kan, ó sì ń fún wa ní ìṣírí tí a nílò láti dúró gbọn-in. (Heberu 10:23-25) Àní, Jehofa ń kọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ “ní òtítọ́, àti ní òdodo.” Ó ń fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní àlàáfíà. Ẹ wo bí a ti jẹ́ alábùkúnfún tó láti nípìn-ín nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà yẹn!
Ìwọ́ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?
◻ Lóde òní, báwo ni Jehofa ti ṣe ‘jowú pẹ̀lú ìrunú ńláǹlà’ fún àwọn ènìyàn rẹ̀?
◻ Báwo ni àwọn ènìyàn Jehofa ṣe ń gbádùn àlàáfíà, àní ní àwọn ilẹ̀ tí ogun ti fà ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ pàápàá?
◻ Lọ́nà wo ni ‘ìgboro ìlú fi kún fún ọmọdékùnrin, àti ọmọdébìnrin’?
◻ Àwọn ìpèsè wo ni a ti ṣe, kí a baà lè tipasẹ̀ Jehofa kọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀?
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 12-15]
ÌRÒYÌN ỌDÚN IṢẸ́ ÌSÌN 1995 TI ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JEHOFA KÁRÍ AYÉ
(Wo àdìpọ̀)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Ní ọ̀rúndún kẹfà Ṣáájú Sànmánì Tiwa, àwọn Júù olùṣòtítọ́ tí wọ́n tún tẹ́ḿpìlì kọ́, kẹ́kọ̀ọ́ pé, Jehofa ni orísun kan ṣoṣo tí ó ṣeé gbára lé fún àlàáfíà