ORÍ KEJÌLÉLÓGÚN
Ó Dúró Ṣinṣin Nígbà Ìdánwò
1, 2. Kí ni Pétérù á máa retí pé kí àwọn ará Kápánáúmù ṣe bí Jésù ṣe ń sọ̀rọ̀, àmọ́ kí ni wọ́n ṣe?
PÉTÉRÙ ń wojú àwọn tí Jésù ń bá sọ̀rọ̀ nínú sínágọ́gù ìlú Kápánáúmù. Ìlú yìí ni ibùgbé Pétérù wà. Ibẹ̀ ló ti ń ṣiṣẹ́ ẹja pípa, ìyẹn ní etíkun àríwá Òkun Gálílì, ibẹ̀ náà sì ni ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ àtàwọn tí wọ́n jọ ń ṣòwò ń gbé. Ó dájú pé Pétérù á máa retí pé kí àwọn ará ìlú yìí fi irú ojú tí òun fi ń wo Jésù wò ó, àti pé inú tiwọn náà á dùn gan-an láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run lọ́dọ̀ olùkọ́ tó ta yọ ní gbogbo ayé yìí. Àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ tá à ń wí yìí.
2 Ọ̀pọ̀ nínú wọn kò tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ Jésù mọ́. Àwọn kan tiẹ̀ ń ráhùn, wọ́n sì ń ta kò ó. Ṣùgbọ́n ohun tí àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe ló tiẹ̀ dun Pétérù jù. Inú wọn kò dùn bó ṣe sábà máa ń dùn nígbà tí òye ohun tí wọ́n ń kọ́ bá yé wọn, tí wọ́n ń rí àwọn nǹkan tuntun kọ́, tí wọ́n sì ń láyọ̀ pé àwọn ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni inú ń bí wọn, tí ojú wọn sì fà ro. Àwọn kan lára wọn tiẹ̀ sọ̀rọ̀, wọ́n ní ọ̀rọ̀ tí Jésù ń sọ yìí kò ṣeé gbọ́ sétí. Nítorí pé wọn ò fẹ́ gbọ́ mọ́, wọ́n jáde nínú sínágọ́gù, wọ́n sì pa dà lẹ́yìn Jésù.—Ka Jòhánù 6:60, 66.
3. Kí ni ìgbàgbọ́ Pétérù jẹ́ kó lè ṣe lọ́pọ̀ ìgbà?
3 Kò rọrùn fún Pétérù àtàwọn àpọ́sítélì yòókù lọ́jọ́ náà. Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ lọ́jọ́ yẹn ò sì fi bẹ́ẹ̀ yé Pétérù náà. Òun pàápàá mọ̀ pé ọ̀rọ̀ Jésù yẹn lè bíni nínú téèyàn ò bá rò ó jinlẹ̀ dáadáa. Kí wá ni Pétérù máa ṣe? Èyí kọ́ ni ìgbà àkọ́kọ́ tí nǹkan kan máa dán Pétérù wò bóyá ó jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọ̀gá rẹ̀, èyí sì kọ́ nìgbà tírú rẹ̀ ṣẹlẹ̀ kẹ́yìn. Ẹ jẹ́ ká wo bí ìgbàgbọ́ Pétérù ṣe jẹ́ kó lè dúró ṣinṣin lójú àwọn ìṣòro yìí.
Ó Dúró Ṣinṣin Nígbà Tí Àwọn Míì Yẹsẹ̀
4, 5. Àwọn nǹkan wo ni Jésù ṣe tí àwọn èèyàn kò retí pé kó ṣe?
4 Jésù máa ń ṣe ohun tó sábà máa ń ya Pétérù lẹ́nu. Ìdí ni pé lọ́pọ̀ ìgbà, Jésù Ọ̀gá rẹ̀ máa ń ṣe ohun táwọn èèyàn kò retí tàbí kó sọ ohun tí wọn kò retí. Lọ́jọ́ tó ṣáájú ọjọ́ yẹn, Jésù bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn lọ́nà ìyanu. Ni àwọn yẹn bá fẹ́ fi Jésù jọba. Àmọ́ Jésù ṣe ohun tó ya ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́nu, ó kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì wá ní kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun wọ ọkọ̀ ojú omi, kí wọ́n kọjá lọ sí Kápánáúmù. Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn wá ń lọ lójú òkun lóru, Jésù tún ṣe ohun tó yà wọ́n lẹ́nu, ó rìn lórí Òkun Gálílì tó ń ru gùdù, ó sì wá kọ́ Pétérù ní ẹ̀kọ́ pàtàkì nípa ìgbàgbọ́.
5 Nígbà tí ilẹ̀ fi máa mọ́, wọ́n rí i pé àwọn èèyàn tí àwọn fi sílẹ̀ ní etíkun lọ́hùn-ún ti wá àwọn wá sí òdì kejì òkun náà. Ṣùgbọ́n ẹ̀rí fi hàn pé, kì í ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni wọ́n fẹ́ gbọ́ tí wọ́n fi ń wá Jésù. Ṣe ni wọ́n ń fẹ́ kí Jésù tún pèsè oúnjẹ fún àwọn lọ́nà ìyanu. Àmọ́ Jésù bá wọn wí nítorí pé wọ́n fẹ́ràn àwọn nǹkan tara jù. (Jòh. 6:25-27) Ọ̀rọ̀ yìí kan náà ni Jésù ń bá wọn sọ lọ nínú sínágọ́gù ní Kápánáúmù, níbi tó tún ti sọ ohun tí àwọn èèyàn kò retí pé kó sọ, nígbà tó fẹ́ kọ́ wọn ní òtítọ́ pàtàkì kan tí kò tà létí wọn.
6. Àpèjúwe wo ni Jésù ṣe fún àwọn èèyàn tó ń bá sọ̀rọ̀, kí ni wọ́n sì ṣe?
6 Jésù kò fẹ́ kó jẹ́ pé oúnjẹ tara lásán làwọn èèyàn yẹn á máa retí lọ́dọ̀ òun. Ṣe ló fẹ́ kí wọ́n mọ òun gẹ́gẹ́ bí ẹni tí Ọlọ́run rán wá láti di oúnjẹ tẹ̀mí fún àwọn èèyàn, ìyẹn ẹni tí àpẹẹrẹ rẹ̀ àti ikú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí èèyàn máa jẹ́ kí àwọn míì lè ní ìyè ayérayé. Torí náà, ó ṣe àpèjúwe kan fún wọn, ó fi ara rẹ̀ wé mánà, ìyẹn oúnjẹ tó wá láti ọ̀run nígbà ayé Mósè. Nígbà táwọn kan ta kò ó, ó lo àpèjúwe kan tí wọ́n lè rí kedere, pé ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n jẹ ara òun, kí wọ́n sì mu ẹ̀jẹ̀ òun kí wọ́n bàa lè ní ìyè. Nígbà tó sọ̀rọ̀ yìí wọ́n yarí pátápátá. Àwọn kan sọ pé: “Ọ̀rọ̀ yìí ń múni gbọ̀n rìrì; ta ní lè fetí sí i?” Kódà ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù pàápàá pa dà lẹ́yìn rẹ̀.a—Jòh. 6:48-60, 66.
7, 8. (a) Kí ni kò tíì yé Pétérù dáadáa nípa Jésù? (b) Báwo ni Pétérù ṣe fèsì ìbéèrè tí Jésù bi àwọn àpọ́sítélì rẹ̀?
7 Kí ni Pétérù máa wá ṣe? Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí máa ṣe òun náà ní kàyéfì. Kì í ṣe pé ó tíì yé òun náà pé Jésù ní láti kú kó bàa lè mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. Ṣé ó wá ṣe Pétérù bíi pé kó pa dà lẹ́yìn Jésù bíi tàwọn aláìnípinnu ọmọ ẹ̀yìn tó pa dà lẹ́yìn rẹ̀ lọ́jọ́ náà? Ó tì o. Ohun kan tó ṣe pàtàkì mú kí Pétérù yàtọ̀ pátápátá sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn ní tiẹ̀. Kí ni ohun náà?
8 Jésù yíjú sí àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, ó sì bi wọ́n pé: “Ẹ̀yin kò fẹ́ lọ pẹ̀lú, àbí?” (Jòh. 6:67) Gbogbo àwọn àpọ́sítélì méjìlá ló ń bá wí, àmọ́ Pétérù ló fèsì. Òun náà ló sì sábà máa ń kọ́kọ́ sọ̀rọ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Pétérù ló dàgbà jù láàárín wọn. Ṣùgbọ́n bí kò tiẹ̀ jẹ́ òun, ó dájú pé òun lẹnu ẹ̀ yá jù láàárín wọn. Ó jọ pé kì í lè pa bọ́rọ̀ ṣe rí lọ́kàn rẹ̀ mọ́ra. Ọ̀rọ̀ pàtàkì tó sì dára gan-an ló wà lọ́kàn rẹ̀ lọ́tẹ̀ yìí. Ó ní: “Olúwa, ọ̀dọ̀ ta ni àwa yóò lọ? Ìwọ ni ó ní àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòh. 6:68.
9. Báwo ni Pétérù ṣe fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin sí Jésù?
9 Ǹjẹ́ ohun tó sọ yìí kò wú ọ lórí? Ìgbàgbọ́ tí Pétérù ní nínú Jésù ti jẹ́ kó ní ànímọ́ kan tó ṣe pàtàkì gan-an, ìyẹn ni ìdúróṣinṣin. Pétérù mọ̀ dájú pé Jésù nìkan ni Olùgbàlà tí Jèhófà rán wá àti pé ọ̀rọ̀ tó máa gbani là ni Jésù ń sọ, ìyẹn ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ni nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ó mọ̀ pé ká tiẹ̀ ní àwọn ohun kan wà tí kò yé òun, kò síbòmíì tí òun lè lọ bí òun bá fẹ́ rí ojú rere Ọlọ́run, kí òun sì jèrè ìyè àìnípẹ̀kun.
A ní láti rí i pé a ò yẹsẹ̀ nínú àwọn ẹ̀kọ́ Jésù, kódà tí wọ́n bá tiẹ̀ yàtọ̀ sí ohun tá à ń retí tàbí ohun tí a fẹ́
10. Báwo ni àwa náà ṣe lè jẹ́ adúróṣinṣin bíi ti Pétérù lóde òní?
10 Ṣé bó ṣe rí lọ́kàn tìrẹ náà nìyẹn? Ó ṣeni láàánú pé, ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ayé lónìí ló ń sọ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ Jésù, àmọ́ tí wọn kì í dúró ṣinṣin nígbà tí ìdánwò bá dé. Tá a bá fẹ́ jẹ́ adúróṣinṣin sí Kristi, ojú tí Pétérù fi wo ẹ̀kọ́ Jésù làwa náà gbọ́dọ̀ máa fi wò ó. A ní láti kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ yẹn, ká lóye wọn, ká sì máa fi wọ́n sílò nígbèésí ayé, kódà tí àwọn ẹ̀kọ́ yìí bá tiẹ̀ ṣe wá ní kàyéfì torí pé wọ́n yàtọ̀ sí ohun tá à ń retí tàbí ohun tí a fẹ́. Tá a bá fẹ́ ní ìyè àìnípẹ̀kun tí Jésù ń fẹ́ ká ní, a gbọ́dọ̀ jẹ́ adúróṣinṣin.—Ka Sáàmù 97:10.
Ó Dúró Ṣinṣin Nígbà Tí Jésù Tọ́ Ọ Sọ́nà
11. Ibo ni Jésù mú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
11 Láìpẹ́ sí ìgbà tí ọwọ́ wọn dí gan-an yìí, Jésù mú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn kan lọ ìrìn àjò jíjìn kan lápá àríwá. Apá àríwá yìí, ní ìkángun Ilẹ̀ Ìlérí, ni Òkè Hámónì wà. Nígbà míì, àwọn èèyàn máa ń rí ṣóńṣó orí òkè yìí tí yìnyín bò láti orí Òkun Gálílì tó mọ́. Bí Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe ń sún mọ́ òkè yìí, lójú ọ̀nà olókè tó lọ sáwọn abúlé tó wà ní agbègbè Kesaréà ti Fílípì tí wọ́n gbà, ni wọ́n túbọ̀ ń rí bó ṣe ga tó.b Àgbègbè ilẹ̀ olókè tó fani mọ́ra yìí, tí wọ́n ti lè rí èyí tó pọ̀ jù nínú Ilẹ̀ Ìlérí níhà gúúsù, ni Jésù ti bi àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ìbéèrè pàtàkì kan.
12, 13. (a) Kí nìdí tí Jésù fi fẹ́ mọ ẹni tí àwọn èèyàn ń rò pé òun jẹ́? (b) Báwo ni èsì tí Pétérù fún Jésù ṣe fi hàn pé ó ní ojúlówó ìgbàgbọ́?
12 Ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé: “Ta ni àwọn ogunlọ́gọ̀ ń sọ pé mo jẹ́?” A lè fojú inú wo bí Pétérù á ṣe máa wojú Jésù, táá sì máa ronú nípa bí Ọ̀gá rẹ̀ yìí ṣe jẹ́ aláàánú àti onílàákàyè tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Jésù fẹ́ mọ ẹni tí àwọn èèyàn ń rò pé òun jẹ́ pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n ti rí tí wọ́n sì ti gbọ́. Ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bá fèsì, wọ́n sì sọ onírúurú èrò tí kò tọ̀nà tí wọ́n mọ̀ pé àwọn èèyàn ní nípa ẹni tí Jésù jẹ́. Àmọ́ Jésù fẹ́ mọ nǹkan míì sí i. Ó fẹ́ mọ̀ bóyá àwọn ọmọlẹ́yìn òun, tó sún mọ́ òun dáadáa, mọ ẹni tí òun jẹ́ gan-an. Torí náà, ó bi wọ́n pé: “Ṣùgbọ́n, ẹ̀yin, ta ni ẹ sọ pé mo jẹ́?”—Lúùkù 9:18-20.
13 Pétérù náà ló tún kọ́kọ́ fèsì. Ó fi ìdánilójú sọ ohun tó wà lọ́kàn ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó wà níbẹ̀, ó ní: “Ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.” A lè fojú inú wo bí Jésù ṣe rẹ́rìn-ín músẹ́ sí Pétérù bó ṣe ń yìn ín pé ó káre láé. Jésù wá rán Pétérù létí pé Jèhófà Ọlọ́run ló jẹ́ kí òye òtítọ́ tó ṣe pàtàkì yìí yé àwọn tó ní ojúlówó ìgbàgbọ́ kedere, kì í ṣe èèyàn. Jèhófà ti jẹ́ kí Pétérù fòye mọ ọ̀kan lára òtítọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ tó tíì ṣí payá, ìyẹn ẹni tó jẹ́ Mèsáyà, tàbí Kristi, tí òun ti ṣèlérí tipẹ́tipẹ́.—Ka Mátíù 16:16, 17.
14. Àwọn ojúṣe pàtàkì wo ni Jésù fà lé Pétérù lọ́wọ́?
14 Kristi yìí ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ pè ní òkúta tí àwọn akọ́lé máa kọ̀ tì. (Sm. 118:22; Lúùkù 20:17) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó ṣí i payá pé Jèhófà máa fi ìpìlẹ̀ ìjọ kan lélẹ̀ lórí òkúta tàbí àpáta ràbàtà tí Pétérù ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ pé ó jẹ́ Kristi. Ẹ̀yìn náà ló wá fa àwọn ojúṣe pàtàkì kan lé Pétérù lọ́wọ́ nínú ìjọ náà. Kì í ṣe pé ó fi Pétérù ṣe olórí àwọn àpọ́sítélì yòókù gẹ́gẹ́ bí àwọn èèyàn kan ṣe ń sọ o, ńṣe ló fa àwọn ojúṣe kan lé e lọ́wọ́. “Àwọn kọ́kọ́rọ́ ìjọba” náà ló fún Pétérù. (Mát. 16:19) Pétérù máa ní àǹfààní láti ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwùjọ èèyàn mẹ́ta nínú aráyé, kí wọ́n lè ní ìrètí àtiwọ Ìjọba Ọlọ́run. Àwùjọ àkọ́kọ́ ni àwọn Júù, lẹ́yìn náà àwọn ará Samáríà àti níkẹyìn àwọn Kèfèrí, ìyẹn àwọn tí kì í ṣe Júù.
15. Kí ló jẹ́ kí Pétérù bá Jésù wí gan-an, kí ni Pétérù sì sọ?
15 Àmọ́ lẹ́yìn náà, Jésù sọ pé a ó béèrè ohun púpọ̀ lọ́wọ́ àwọn tá a bá fún ní ohun púpọ̀. Bí ọ̀rọ̀ sì ṣe rí fún Pétérù gẹ́lẹ́ nìyẹn. (Lúùkù 12:48) Jésù wá ń bá àwọn òtítọ́ pàtàkì tó ń sọ fún wọn nípa Mèsáyà nìṣó, títí kan bó ṣe dájú pé òun máa jìyà, wọ́n á sì pa òun ní Jerúsálẹ́mù. Nígbà tí Pétérù gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ara rẹ̀ kò gbà á. Ló bá mú Jésù lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó sì bá a wí gan-an. Ó ní: “Ṣàánú ara rẹ, Olúwa; ìwọ kì yóò ní ìpín yìí rárá.”—Mát. 16:21, 22.
16. Báwo ni Jésù ṣe tọ́ Pétérù sọ́nà? Ìmọ̀ràn tó wúlò fún gbogbo wa wo ló wà nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ?
16 Ìrànlọ́wọ́ ni Pétérù fẹ́ ṣe fún Jésù, torí náà èsì Jésù ní láti yà á lẹ́nu. Jésù kọ ẹ̀yìn sí Pétérù, ó sì wo àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù, tó ṣeé ṣe kí wọ́n ní irú èrò tí Pétérù ní, ó wá sọ pé: “Dẹ̀yìn lẹ́yìn mi, Sátánì! Ohun ìkọ̀sẹ̀ ni ìwọ jẹ́ fún mi, nítorí kì í ṣe àwọn ìrònú Ọlọ́run ni ìwọ ń rò, bí kò ṣe ti ènìyàn.” (Mát. 16:23; Máàkù 8:32, 33) Ìmọ̀ràn tó wúlò fún gbogbo wa wà nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí. Kì í pẹ́ tí a fi máa ń fi ìrònú èèyàn ṣáájú ti Ọlọ́run. Tá a bá sì ti ṣe bẹ́ẹ̀, kódà tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ìrànlọ́wọ́ la fẹ́ ṣe, a lè dẹni tó ń ti ìfẹ́ ọkàn Sátánì lẹ́yìn dípò ti Ọlọ́run láìmọ̀. Kí ni Pétérù wá ṣe?
17. Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ fún Pétérù pé, “Dẹ́yìn lẹ́yìn mi, Sátánì”?
17 Pétérù máa mọ̀ dájú pé Jésù kò sọ pé òun jẹ́ olubi bíi ti Sátánì Èṣù. Ó ṣe tán, kì í ṣe ohun tí Jésù sọ fún Sátánì ló sọ fún Pétérù. Ohun tó sọ fún Sátánì ni pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi,” àmọ́ ó sọ fún Pétérù pé, “Dẹ̀yìn lẹ́yìn mi.” (Mát. 4:10) Jésù kò lé àpọ́sítélì yìí dà nù, torí ó mọ̀ pé ó ní àwọn ìwà tó dára gan-an. Ńṣe ló kàn tọ́ ọ sọ́nà lórí èrò òdì tó ní. Ó ṣe kedere pé ó yẹ kí Pétérù jáwọ́ nínú fífi ohun ìkọ̀sẹ̀ síwájú Jésù Ọ̀gá rẹ̀, kó sì máa tì í lẹ́yìn.
Ìgbà tá a bá ń gba ìbáwí, tá a sì ń kọ́gbọ́n nínú rẹ̀ nìkan la lè túbọ̀ máa sún mọ́ Jésù Kristi àti Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Baba rẹ̀
18. Báwo ni Pétérù ṣe fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin? Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?
18 Ǹjẹ́ Pétérù jiyàn, ǹjẹ́ ó sì bínú tàbí kó di kùnrùngbùn? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi ìrẹ̀lẹ̀ tẹ́wọ́ gba ìtọ́sọ́nà. Ó tún tipa báyìí fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin. Gbogbo àwọn tó bá jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi yóò máa nílò ìtọ́sọ́nà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ìgbà tá a bá ń gba ìbáwí, tá a sì ń kọ́gbọ́n nínú rẹ̀ nìkan la lè túbọ̀ máa sún mọ́ Jésù Kristi àti Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Baba rẹ̀.—Ka Òwe 4:13.
Ó Jèrè Ìdúróṣinṣin Rẹ̀
19. Ọ̀rọ̀ tó yani lẹ́nu wo ni Jésù sọ, kí sì ni Pétérù lè máa rò?
19 Kò pẹ́ sígbà náà ni Jésù tún sọ ọ̀rọ̀ míì tó yani lẹ́nu. Ó ní: “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín pé àwọn kan wà lára àwọn tí wọ́n dúró níhìn-ín tí kì yóò tọ́ ikú wò rárá títí wọn yóò fi kọ́kọ́ rí Ọmọ ènìyàn tí ń bọ̀ nínú ìjọba rẹ̀.” (Mát. 16:28) Ó dájú pé Pétérù á máa hára gàgà láti mọ ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí. Á máa rò ó pé kí ni Jésù lè ní lọ́kàn? Bóyá ó tiẹ̀ tún lè ronú pé òun kò ní lè nírú àwọn àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ yẹn mọ́, nítorí ìbáwí tó le tí òun ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà.
20, 21. (a) Ṣàlàyé ìran tí Pétérù rí. (b) Báwo ni ọ̀rọ̀ tí àwọn tó wà nínú ìran náà ń sọ ṣe túbọ̀ wá tọ́ Pétérù sọ́nà?
20 Àmọ́ nǹkan bí ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn náà, Jésù mú Jákọ́bù, Jòhánù àti Pétérù lọ sórí “òkè ńlá kan tí ó ga fíofío,” bóyá orí Òkè Hámónì tí kò ju kìlómítà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sí wọn ni. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ alẹ́, torí oorun ti ń kun àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Àmọ́ bí Jésù ṣe ń gbàdúrà, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó mú kí oorun dá lójú wọn.—Mát. 17:1; Lúùkù 9:28, 29, 32.
21 Ìrísí Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà lójú wọn. Ojú rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ mànà, ó sì wá ń tàn yanran títí tó fi mọ́lẹ̀ bí oòrùn. Ẹ̀wù rẹ̀ pàápàá di funfun tó ń dán gológoló. Lẹ́yìn náà, àwọn méjì kan fara hàn lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù. Ọ̀kan ṣàpẹẹrẹ Mósè, èkejì ṣàpẹẹrẹ Èlíjà. Wọ́n ń bá Jésù sọ̀rọ̀ nípa “lílọ rẹ̀ tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ fún un láti mú ṣẹ ní Jerúsálẹ́mù,” ẹ̀rí sì fi hàn pé ọ̀rọ̀ nípa ikú àti àjíǹde rẹ̀ ni. Pétérù wá rí i kedere pé èrò tí òun ní pé Jésù kò ní jìyà kó sì kú tó bá yá kò tọ̀nà.—Lúùkù 9:30, 31.
22, 23. (a) Báwo ni Pétérù ṣe fi hàn pé òun ní ìtara àti ọ̀yàyà? (b) Èrè wo ni Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù tún rí jẹ lálẹ́ ọjọ́ yẹn?
22 Pétérù wò ó pé ó yẹ́ kí òun kópa nínú ìran àrà ọ̀tọ̀ yìí, bóyá kí òun máà jẹ́ kó tètè parí, torí ó dà bíi pé Mósè àti Èlíjà ti fẹ́ kúrò lọ́dọ̀ Jésù. Pétérù wá sọ pé: “Olùkọ́ni, ó dára púpọ̀ fún wa láti wà níhìn-ín, nítorí náà, jẹ́ kí a gbé àgọ́ mẹ́ta nà ró, ọ̀kan fún ọ àti ọ̀kan fún Mósè àti ọ̀kan fún Èlíjà.” Ní tòdodo, àwọn tó fara hàn nínú ìran yìí, tí wọ́n ṣàpẹẹrẹ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà méjì tó ti kú tipẹ́tipẹ́, kò nílò àgọ́ kankan. Ńṣe ni Pétérù kò ro ọ̀rọ̀ yìí dáadáa kó tó sọ ọ́. Ṣùgbọ́n o, ǹjẹ́ ìtara àti ọ̀yàyà tí Pétérù ní yìí kò mú kó o fẹ́ràn rẹ̀ gan-an?—Lúùkù 9:33.
23 Pétérù, Jákọ́bù àti Jòhánù tún jèrè nǹkan míì lálẹ́ ọjọ́ yẹn. Àwọsánmà kan gbára jọ, ó sì ṣíji bò wọ́n lórí òkè náà. Wọ́n wá gbọ́ ohùn kan látinú àwọsánmà náà, ohùn Jèhófà Ọlọ́run! Ó ní: “Èyí ni Ọmọ mi, ẹni tí a ti yàn. Ẹ fetí sí i.” Bí ìran náà ṣe parí nìyẹn, tó wá ku àwọn àti Jésù nìkan lórí òkè náà.—Lúùkù 9:34-36.
24. (a) Báwo ni ìran ìyípadà ológo yìí ṣe ṣe Pétérù láǹfààní? (b) Báwo ni ìran yìí ṣe lè ṣe àwa náà láǹfààní lóde òní?
24 Ẹ ò rí i pé ẹ̀bùn àtàtà ni ìran ìyípadà ológo yìí jẹ́ fún Pétérù àti fún àwa náà! Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ó kọ̀wé nípa àǹfààní tó ní lálẹ́ ọjọ́ náà, ó ní òun wà lára àwọn tó “fi ojú rí ọlá ńlá rẹ̀.” Ó fojú ara rẹ̀ rí ìran tó ṣe àpẹẹrẹ Jésù tí a ṣe lógo gẹ́gẹ́ bí Ọba ọ̀run! Ìran yìí jẹ́rìí sí ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó sì mú kí ìgbàgbọ́ Pétérù túbọ̀ lágbára kó bàa lè borí àwọn àdánwò tó máa ní lọ́jọ́ iwájú. (Ka 2 Pétérù 1:16-19.) Ìran yìí lè mú kí ìgbàgbọ́ tiwa náà túbọ̀ lágbára, bó ṣe mú kí ti Pétérù lágbára, ìyẹn tá a bá dúró ṣinṣin sí Jésù tí Jèhófà fi jẹ Ọ̀gá wa, tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀, tá à ń gba ìbáwí àti ìtọ́sọ́nà rẹ̀, tá a sì ń fi ìrẹ̀lẹ̀ tẹ̀ lé e lójoojúmọ́.
a Tá a bá fi ohun tí àwọn èèyàn tó wà ní sínágọ́gù yìí ṣe lọ́jọ́ tí wọ́n fìtara pòkìkí Jésù pé ó jẹ́ wòlíì Ọlọ́run wé ohun tí wọ́n ṣe lọ́jọ́ kejì nígbà tí wọ́n ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ṣe kedere pé ọ̀rọ̀ wọn kò láyọ̀lé.—Jòh. 6:14.
b Bí wọ́n ṣe gbéra ní etí Òkun Gálílì tó jẹ́ pẹ̀tẹ́lẹ̀ tó lọọlẹ̀ gan-an ní nǹkan bí igba-ó-lé-mẹ́wàá [210] mítà sí ìtẹ́jú òkun, wọ́n rìnrìn àjò kìlómítà méjìdínláàádọ́ta [48] lọ sí àgbègbè olókè tó ga tó àádọ́ta-dín-nírinwó [350] mítà sí ìtẹ́jú òkun. Ibi tó fani mọ́ra gan-an ni àgbègbè ilẹ̀ olókè tí wọ́n ń gbà lọ yìí.