Àkọsílẹ̀ Mátíù
16 Àwọn Farisí àti àwọn Sadusí wá bá a, wọ́n ní kó fi àmì kan han àwọn láti ọ̀run, kí wọ́n lè dá an wò.+ 2 Ó dá wọn lóhùn pé: “Tó bá di ìrọ̀lẹ́, ẹ máa ń sọ pé, ‘Ojú ọjọ́ máa dáa, torí ojú ọ̀run pọ́n bí iná,’ 3 tó bá sì di àárọ̀, ẹ máa ń sọ pé ‘Ojú ọjọ́ máa tutù, òjò sì máa rọ̀ lónìí, torí ojú ọ̀run pọ́n bí iná, àmọ́ ó ṣú dùdù.’ Ẹ mọ bí wọ́n ṣe ń túmọ̀ ojú ọjọ́, àmọ́ ẹ ò lè túmọ̀ àwọn àmì àkókò. 4 Ìran burúkú àti alágbèrè* kò yéé wá àmì, àmọ́ a ò ní fún un ní àmì kankan+ àfi àmì Jónà.”+ Ló bá kúrò níbẹ̀, ó sì fi wọ́n sílẹ̀.
5 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn sọdá sí òdìkejì, wọn ò sì rántí mú búrẹ́dì dání.+ 6 Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ la ojú yín sílẹ̀, kí ẹ sì ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisí àti àwọn Sadusí.”+ 7 Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó láàárín ara wọn pé: “A ò mú búrẹ́dì kankan dání.” 8 Jésù mọ èyí, ó wá sọ pé: “Kí ló dé tí ẹ̀ ń sọ láàárín ara yín pé ẹ ò ní búrẹ́dì, ẹ̀yin tí ìgbàgbọ́ yín kéré? 9 Ṣé ọ̀rọ̀ yẹn ò tíì yé yín ni, àbí ẹ ò rántí búrẹ́dì márùn-ún tí mo fi bọ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) àti iye apẹ̀rẹ̀ tí ẹ kó jọ?+ 10 Àbí búrẹ́dì méje tí mo fi bọ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) àti iye apẹ̀rẹ̀ ńlá* tí ẹ kó jọ?+ 11 Kí nìdí tí kò fi yé yín pé ọ̀rọ̀ búrẹ́dì kọ́ ni mò ń bá yín sọ? Àmọ́, ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisí àti àwọn Sadusí.”+ 12 Ìgbà yẹn ló wá yé wọn pé kì í ṣe ìwúkàrà búrẹ́dì ló ní kí wọ́n ṣọ́ra fún, ẹ̀kọ́ àwọn Farisí àti àwọn Sadusí ni.
13 Nígbà tó dé agbègbè Kesaríà ti Fílípì, Jésù bi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ta ni àwọn èèyàn ń sọ pé Ọmọ èèyàn jẹ́?”+ 14 Wọ́n sọ pé: “Àwọn kan sọ pé Jòhánù Arinibọmi,+ àwọn míì ń sọ pé Èlíjà,+ àwọn míì sì ń sọ pé Jeremáyà tàbí ọ̀kan lára àwọn wòlíì.” 15 Ó wá bi wọ́n pé: “Ẹ̀yin ńkọ́, ta lẹ sọ pé mo jẹ́?” 16 Símónì Pétérù dáhùn pé: “Ìwọ ni Kristi náà,+ Ọmọ Ọlọ́run alààyè.”+ 17 Jésù sọ fún un pé: “Aláyọ̀ ni ọ́, Símónì ọmọ Jónà, torí pé ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀* kọ́ ló ṣí i payá fún ọ, Baba mi tó wà lọ́run ni.+ 18 Bákan náà, mò ń sọ fún ọ pé: Ìwọ ni Pétérù,+ orí àpáta yìí+ sì ni màá kọ́ ìjọ mi sí, àwọn ibodè Isà Òkú* kò sì ní borí rẹ̀. 19 Màá fún ọ ní àwọn kọ́kọ́rọ́ Ìjọba ọ̀run, ohunkóhun tí o bá dè ní ayé máa jẹ́ ohun tí a ti dè ní ọ̀run, ohunkóhun tí o bá sì tú ní ayé máa jẹ́ ohun tí a ti tú ní ọ̀run.” 20 Ó wá kìlọ̀ gidigidi fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn pé kí wọ́n má sọ fún ẹnikẹ́ni pé òun ni Kristi náà.+
21 Látìgbà yẹn lọ, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé òun gbọ́dọ̀ lọ sí Jerúsálẹ́mù, kí òun jìyà tó pọ̀ lọ́wọ́ àwọn àgbààgbà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin, kí wọ́n sì pa òun, kí a sì jí òun dìde ní ọjọ́ kẹta.+ 22 Ni Pétérù bá mú un lọ sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá a wí, ó sọ pé: “Ṣàánú ara rẹ, Olúwa; èyí ò ní ṣẹlẹ̀ sí ọ rárá.”+ 23 Àmọ́ ó yíjú pa dà, ó sì sọ fún Pétérù pé: “Dẹ̀yìn lẹ́yìn mi,* Sátánì! Ohun ìkọ̀sẹ̀ lo jẹ́ fún mi, torí èrò èèyàn lò ń rò, kì í ṣe ti Ọlọ́run.”+
24 Jésù wá sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Tí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ máa tẹ̀ lé mi, kó sẹ́ ara rẹ̀, kó gbé òpó igi oró* rẹ̀, kó sì máa tẹ̀ lé mi.+ 25 Torí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ gba ẹ̀mí* rẹ̀ là máa pàdánù rẹ̀, àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá pàdánù ẹ̀mí* rẹ̀ nítorí mi máa rí i.+ 26 Lóòótọ́, àǹfààní wo ni èèyàn máa rí tó bá jèrè gbogbo ayé àmọ́ tó pàdánù ẹ̀mí* rẹ̀?+ Àbí kí ni èèyàn máa fi dípò ẹ̀mí* rẹ̀?+ 27 Torí Ọmọ èèyàn máa wá nínú ògo Baba rẹ̀ pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì rẹ̀, ó máa wá san èrè fún kálukú gẹ́gẹ́ bí ìwà rẹ̀.+ 28 Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín pé àwọn kan wà lára àwọn tó dúró síbí yìí tí kò ní tọ́ ikú wò rárá títí wọ́n á fi kọ́kọ́ rí Ọmọ èèyàn tó ń bọ̀ nínú Ìjọba rẹ̀.”+