Orí Kẹwàá
A Ṣèlérí Ọmọ Aládé Àlàáfíà
1. Kí ló ti ń ṣẹlẹ̀ sí aráyé láti ìgbà ayé Kéènì?
NÍ NǸKAN bí ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́fà sẹ́yìn, ènìyàn bí ọmọ jòjòló àkọ́kọ́. Kéènì lorúkọ rẹ̀, ohun pàtàkì gbáà ni ìbí rẹ̀ jẹ́. Yálà àwọn òbí rẹ̀ ni o, tàbí àwọn áńgẹ́lì, tàbí Ẹlẹ́dàá pàápàá kò tíì rí ọmọ jòjòló rí. Ọmọ tuntun yìí ni ì bá jẹ́ kí ìrètí wà fún ìran ènìyàn tó ti gba ìdálẹ́bi. Ìjákulẹ̀ gbáà ló wá jẹ́, nígbà tó di pé ó dàgbà tán, tó wá di apànìyàn! (1 Jòhánù 3:12) Látìgbà yẹn wá, ìpànìyàn tó ti ṣẹlẹ̀ lójú aráyé kò níye. Ọmọ aráyé, tó ń tanná wá ibi ṣíṣe kiri, kò wà lálàáfíà pẹ̀lú ọmọnìkejì wọn àti Ọlọ́run.—Jẹ́nẹ́sísì 6:5; Aísáyà 48:22.
2, 3. Àwọn àǹfààní wo ni Jésù Kristi ṣọ̀nà rẹ̀, kí la sì ní láti ṣe ká tó lè rí irú àwọn ìbùkún yẹn gbà?
2 Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́rin lẹ́yìn ìbí Kéènì, wọ́n bí ọmọ jòjòló mìíràn. Jésù lorúkọ rẹ̀, ohun pàtàkì gbáà sì ni ìbí tirẹ̀ pẹ̀lú. Wúńdíá kan ló bí i, nípasẹ̀ agbára ẹ̀mí mímọ́, ìbí rẹ̀ kò sì láfijọ nínú ìtàn. Nígbà tí wọ́n bí i, ogunlọ́gọ̀ àwọn áńgẹ́lì tó ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ kọrin ìyìn sí Ọlọ́run, pé: “Ògo fún Ọlọ́run ní àwọn ibi gíga lókè, àti lórí ilẹ̀ ayé àlàáfíà láàárín àwọn ẹni ìtẹ́wọ́gbà.” (Lúùkù 2:13, 14) Jésù yàtọ̀ gédégédé sí apànìyàn, ńṣe ló tún ṣọ́nà tí aráyé fi lè wà lálàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run kí wọ́n sì rí ìyè ayérayé gbà.—Jòhánù 3:16; 1 Kọ́ríńtì 15:55.
3 Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé a ó pe Jésù ní “Ọmọ Aládé Àlàáfíà.” (Aísáyà 9:6) Ẹ̀mí tirẹ̀ fúnra rẹ̀ ni yóò fi lélẹ̀ fún aráyé, yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí wọ́n lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. (Aísáyà 53:11) Lónìí, níní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi ló lè jẹ́ kí a wà lálàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run kí a sì rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. Àmọ́ o, irú ìbùkún bẹ́ẹ̀ kì í ṣàdédé wá. (Kólósè 1:21-23) Àwọn tó bá ń fẹ́ ẹ ní láti kọ́ bí a ti ń ṣègbọràn sí Jèhófà Ọlọ́run. (1 Pétérù 3:11; fi wé Hébérù 5:8, 9.) Nígbà ayé Aísáyà, òdìkejì èyí gan-an ni Ísírẹ́lì àti Júdà ṣe.
Yíyíjú Sọ́dọ̀ Àwọn Ẹ̀mí Èṣù
4, 5. Báwo ni ipò nǹkan ṣe rí láyé ìgbà Aísáyà, ọ̀dọ̀ ta ni àwọn kan sì yíjú sí?
4 Àìgbọ́ràn àwọn èèyàn tó wà nígbà ayé Aísáyà sún wọn di oníwàkiwà, wọ́n rì sí ọ̀gbun òkùnkùn biribiri nípa tẹ̀mí. Kódà nǹkan ò fara rọ fún ìjọba Júdà níhà gúúsù níbi tí tẹ́ńpìlì Ọlọ́run wà. Nítorí ìwà àìṣòótọ́ àwọn ènìyàn Júdà, Ásíríà fẹ́ ṣígun wá bá wọn, ìnira sì ń bẹ níwájú fún wọn. Ta ni wọ́n wá yíjú sí fún ìrànlọ́wọ́? Ó bani nínú jẹ́ pé ọ̀pọ̀ wọn ló yíjú sọ́dọ̀ Sátánì dípò Jèhófà. Wọn kò ké pe orúkọ Sátánì ní tààràtà o. Ńṣe ni wọ́n ṣe bíi Sọ́ọ̀lù Ọba àtijọ́, wọ́n kọwọ́ bọ ọ̀ràn ìbẹ́mìílò, wọ́n ń wá ojútùú sí ìṣòro wọn nípa gbígbìyànjú láti bá òkú sọ̀rọ̀.—1 Sámúẹ́lì 28:1-20.
5 Àwọn kan tiẹ̀ ń gbé àṣà yẹn lárugẹ. Irú ìpẹ̀yìndà yẹn ni Aísáyà ń tọ́ka sí nígbà tó sọ pé: “Bí ó bá sì wá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n sọ fún yín pé: ‘Ẹ béèrè fún nǹkan lọ́wọ́ àwọn abẹ́mìílò tàbí lọ́wọ́ àwọn tí ó ní ẹ̀mí ìsàsọtẹ́lẹ̀, àwọn tí ń ké ṣíoṣío, tí wọ́n sì ń sọ àwọn àsọjáde ní ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́,’ kì í ha ṣe ọwọ́ Ọlọ́run rẹ̀ ni ó yẹ kí ènìyàn ti máa béèrè fún nǹkan? Ó ha yẹ kí ìbéèrè fún nǹkan lọ́wọ́ àwọn òkú nítorí àwọn alààyè ṣẹlẹ̀ bí?” (Aísáyà 8:19) Àwọn abẹ́mìílò lè tanni jẹ, nípa ‘kíké ṣíoṣío, àti sísọ àwọn àsọjáde ní ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́.’ Dídún tí wọ́n ń dún lọ́nà bẹ́ẹ̀, tí wọ́n á ní òkú ló ń sọ̀rọ̀, kò ju itú tí adáhunṣe lè fúnra rẹ̀ pa, bó bá ti díbọ́n bíi tàwọn ọlọ́sanyìn. Àmọ́ ṣá, àwọn ẹ̀mí èṣù lè lọ́wọ́ sí i nígbà mìíràn, kí wọ́n gbé agọ̀ ẹni tó kú wọ̀, bí irú èyí tó jọ pé ó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Sọ́ọ̀lù lọ fọ̀ràn lọ abẹ́mìílò kan ní Ẹ́ń-dórì.—1 Sámúẹ́lì 28:8-19.
6. Èé ṣe tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kọwọ́ bọ ọ̀ràn ìbẹ́mìílò fi jẹ̀bi ní pàtàkì?
6 Gbogbo ìwọ̀nyí ni wọ́n ń ṣe ní Júdà bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ti ka ìbẹ́mìílò léèwọ̀. Ẹ̀ṣẹ̀ tó lakú lọ ni, lábẹ́ Òfin Mósè. (Léfítíkù 19:31; 20:6, 27; Diutarónómì 18:9-12) Kí ló fà á táwọn tó jẹ́ ohun ìní àkànṣe fún Jèhófà fi lọ ń dá irú ẹ̀ṣẹ̀ tó burú bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé wọ́n kẹ̀yìn sí Òfin Jèhófà àti ìmọ̀ràn rẹ̀, tí “agbára ìtannijẹ ẹ̀ṣẹ̀” sì wá sọ wọ́n “di aláyà líle.” (Hébérù 3:13) “Ọkàn-àyà wọn ti di aláìnímọ̀lára gẹ́gẹ́ bí ọ̀rá,” wọ́n sì sọ ara wọn dọ̀tá Ọlọ́run.—Sáàmù 119:70.a
7. Báwo ni ọ̀pọ̀ lónìí ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ayé Aísáyà, kí sì ló ń dúró de irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́jọ́ iwájú bí wọn kò bá ronú pìwà dà?
7 Bóyá èrò wọn ni pé, ‘Àǹfààní kí ni Òfin Jèhófà fẹ́ ṣe wá lákòókò yìí tí àwọn ará Ásíríà ń múra láti ṣígun wá bá wa?’ Kí ìṣòro wọn yanjú wẹ́rẹ́, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ni wọ́n ń fẹ́, wọn kò fẹ́ dúró kí Jèhófà ṣe ohun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. Bákan náà, nígbà tiwa yìí, ọ̀pọ̀ ò ka òfin Jèhófà sí, wọn a máa wá àwọn abẹ́mìílò lọ, wọn a máa wo ìràwọ̀ ọjọ́ ìbí, tàbí kí wọ́n máa yalé àwọn adáhunṣe láti lè yanjú ìṣòro wọn. Àmọ́ o, bí kò ṣe bọ́gbọ́n mu pé kí alààyè wá ojútùú ìṣòro lọ sọ́dọ̀ òkú láyé ìgbà yẹn náà ni kò ṣe bá a mu lọ́jọ́ òní. Ẹní bá ń forí kunkun bá irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ nìṣó, ìyà kan náà ní ń dúró de òun àti “àwọn òṣìkàpànìyàn àti àwọn àgbèrè àti . . . àwọn abọ̀rìṣà àti gbogbo òpùrọ́.” Wọn kò lè retí ìyè lọ́jọ́ iwájú.—Ìṣípayá 21:8.
‘Òfin’ Ọlọ́run ‘àti Ẹ̀rí Tí Ń Fìdí Ọ̀ràn Múlẹ̀’
8. Kí ni “òfin” àti “ẹ̀rí tí ń fìdí ọ̀ràn múlẹ̀” tó yẹ ká máa lọ wò fún ìtọ́sọ́nà lóde òní?
8 Òfin tí Jèhófà fi ka ìbẹ́mìílò léèwọ̀, àti àwọn àṣẹ rẹ̀ yòókù, kì í ṣe ohun tó fara sin ní Júdà. Ó wà lákọọ́lẹ̀. Lónìí, ìwé tó jẹ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ wà káàkiri. Òun ni Bíbélì, tó jẹ́ pé, yàtọ̀ sí tàwọn òfin àti ìlànà Ọlọ́run tó wà nínú rẹ̀, ìtàn bí Ọlọ́run ṣe bá àwọn èèyàn rẹ̀ lò tún wà níbẹ̀. Ìtàn inú Bíbélì yìí, nípa bí Jèhófà ṣe ń bá àwọn èèyàn rẹ̀ lò, ló jẹ́ ẹ̀rí tí ń fìdí ọ̀ràn múlẹ̀, tí ń kọ́ wa nípa ìwà àti àwọn ànímọ́ Jèhófà. Dípò wíwá àwọn òkú lọ, ibo ló yẹ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá ìtọ́sọ́nà lọ? Aísáyà dáhùn pé: “Sí òfin àti sí ẹ̀rí tí ń fìdí ọ̀ràn múlẹ̀!” (Aísáyà 8:20a) Bẹ́ẹ̀ ni, inú àkọsílẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló yẹ kí àwọn tó bá ń wá ìlàlóye tòótọ́ lọ.
9. Ǹjẹ́ fífà tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà ń fa ọ̀rọ̀ Bíbélì yọ látìgbà dégbà ṣe wọ́n láǹfààní kankan?
9 Àwọn kan lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó lọ kọwọ́ bọ ọ̀ràn ìbẹ́mìílò lè sọ pé àwọn bọ̀wọ̀ fún àkọsílẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, irọ́ gbuu àti àgàbàgebè lásán nìyẹn jẹ́. Aísáyà sọ pé: “Dájúdájú, wọn yóò máa sọ gẹ́gẹ́ bí gbólóhùn yìí tí kì yóò ní ìmọ́lẹ̀ ọ̀yẹ̀.” (Aísáyà 8:20b) Gbólóhùn wo ni Aísáyà ń tọ́ka sí níhìn-ín? Bóyá gbólóhùn yẹn ni: “Sí òfin àti sí ẹ̀rí tí ń fìdí ọ̀ràn múlẹ̀!” Ó lè jẹ́ pé ńṣe ni àwọn tí wọ́n pẹ̀yìn dà lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń tọ́ka sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, gan-an bí àwọn apẹ̀yìndà àtàwọn mìíràn ṣe lè fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ lónìí. Àmọ́ o, ọ̀rọ̀ orí ahọ́n lásán ni. Fífa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ kò lè múni “ní ìmọ́lẹ̀ ọ̀yẹ̀” tàbí ìlàlóye kankan látọ̀dọ̀ Jèhófà, bónítọ̀hún kò bá fi ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà kún un, kí ó sì yàgò fáwọn ìwà àìmọ́.b
“Ìyàn, Tí Kì Í Ṣe fún Oúnjẹ”
10. Ìyà wo ló ń jẹ àwọn ará Júdà nítorí kíkọ̀ tí wọ́n kọ Jèhófà sílẹ̀?
10 Àìgbọ́ràn sí Jèhófà a máa sọni sí òkùnkùn ní ti èrò orí. (Éfésù 4:17, 18) Àwọn ènìyàn Júdà ti fọ́jú nípa tẹ̀mí, wọn kò ní òye. (1 Kọ́ríńtì 2:14) Aísáyà ṣàpèjúwe ipò wọn pé: “Dájúdájú, olúkúlùkù yóò gba ilẹ̀ náà kọjá nínú ìnilára dé góńgó àti nínú ebi.” (Aísáyà 8:21a) Nítorí àìṣòótọ́ orílẹ̀-èdè Júdà—pàápàá nígbà ìṣàkóso Áhásì Ọba—àfàìmọ̀ ni ìjọba Júdà tó dá dúró yẹn ò fi ní fọ́ láìpẹ́. Àárín àwọn ọ̀tá ni orílẹ̀-èdè yẹn wà. Ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ásíríà ń kọ lu àwọn ìlú Júdà lọ́kọ̀ọ̀kan. Àwọn ọ̀tá ń sọ ilẹ̀ eléso di aṣálẹ̀, tí oúnjẹ fi wọ́n. Ọ̀pọ̀ wà “nínú ìnilára dé góńgó àti nínú ebi.” Àmọ́, oríṣi ebi mìíràn tún ń pa ilẹ̀ yẹn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣáájú ìgbà yẹn ni Ámósì ti sọ tẹ́lẹ̀ pé: “‘Wò ó! Àwọn ọjọ́ ń bọ̀,’ ni àsọjáde Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ‘èmi yóò sì rán ìyàn sí ilẹ̀ náà dájúdájú, ìyàn, tí kì í ṣe fún oúnjẹ, àti òùngbẹ, tí kì í ṣe fún omi, bí kò ṣe fún gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.’” (Ámósì 8:11) Àgbákò irú ìyàn tẹ̀mí yẹn gan-an ni Júdà kò yìí o!
11. Ṣé Júdà yóò fi ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́ ṣàríkọ́gbọ́n?
11 Ṣé Júdà yóò fèyí kọ́gbọ́n, kó sì padà sọ́dọ̀ Jèhófà? Ṣé àwọn èèyàn rẹ̀ yóò padà lẹ́yìn ìbẹ́mìílò àti ìbọ̀rìṣà, kí wọ́n sì padà “sí òfin àti sí ẹ̀rí tí ń fìdí ọ̀ràn múlẹ̀”? Jèhófà mọ ohun tí wọ́n máa ṣe lọ́jọ́ iwájú, ó ní: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, nítorí tí ebi ń pa á, tí ó sì ti mú kí ìkannú rẹ̀ ru, ní ti tòótọ́ òun yóò pe ibi wá sórí ọba rẹ̀ àti sórí Ọlọ́run rẹ̀, yóò sì gbójú sókè dájúdájú.” (Aísáyà 8:21b) Bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀pọ̀ yóò dẹ́bi fún ọba wọn pé òun ló kó àwọn sí yọ́yọ́. Àwọn kan yóò tilẹ̀ fi ìwà òmùgọ̀ sọ pé Jèhófà ló kó àjálù bá àwọn! (Fi wé Jeremáyà 44:15-18.) Ìyẹn náà ni ọ̀pọ̀ ènìyàn ń ṣe lónìí, bí àwọn òṣìkà bá ṣe wọ́n ní jàǹbá, wọn a ní àmúwá Ọlọ́run ni.
12. (a) Kí ni kíkẹ̀yìn sí Ọlọ́run sún Júdà ṣe? (b) Àwọn ìbéèrè pàtàkì wo ló jẹ yọ?
12 Ṣé pípè tí àwọn olùgbé Júdà ń pe ibi wá sórí Ọlọ́run yóò wá mú àlàáfíà dé bá wọn? Rárá. Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Yóò sì wo ilẹ̀, sá wò ó! wàhálà àti òkùnkùn, ìríran bàìbàì, àwọn àkókò ìnira àti ìṣúdùdù láìsí ìtànyòò.” (Aísáyà 8:22) Bí wọ́n ṣe gbójú sókè wo ọ̀run láti dẹ́bi fún Ọlọ́run tán, wọ́n tún yíjú padà sí ilẹ̀ ayé, sí hílàhílo tó bá wọn. Kíkọ tí wọ́n kẹ̀yìn sí Ọlọ́run ti kó wọn sí yọ́yọ́. (Òwe 19:3) Ìlérí tí Ọlọ́run wá ṣe fún Ábúráhámù, Ísákì, àti Jékọ́bù ńkọ́? (Jẹ́nẹ́sísì 22:15-18; 28:14, 15) Ṣé Jèhófà máa yẹ àdéhùn rẹ̀ ni? Ṣé àwọn ará Ásíríà tàbí àwọn ológun mìíràn yóò wá fòpin sí ìlà ìdílé ọba táa ṣèlérí fún Júdà àti Dáfídì ni? (Jẹ́nẹ́sísì 49:8-10; 2 Sámúẹ́lì 7:11-16) Ṣé títí ayérayé làwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò máa wà lókùnkùn ni?
Ilẹ̀ Tí Wọ́n “Fojú Tín-ínrín”
13. Kí ni “Gálílì àwọn orílẹ̀-èdè” jẹ́, báwo ni wọ́n sì ṣe “fojú tín-ínrín” rẹ̀?
13 Aísáyà wá sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kan lára ìjábá tó burú jù lọ tó tíì dé bá àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù rí, ó ní: “Ìṣókùnkùn bàìbàì náà kì yóò rí bí ìgbà tí ilẹ̀ náà ní másùnmáwo, bí ti ìgbà àtijọ́ nígbà tí ènìyàn fojú tín-ín-rín ilẹ̀ Sébúlúnì àti ilẹ̀ Náfútálì, tí ènìyàn sì wá mú kí a bọlá fún un ní ẹ̀yìn ìgbà náà—ọ̀nà òkun, ní ẹkùn ilẹ̀ Jọ́dánì, Gálílì àwọn orílẹ̀-èdè.” (Aísáyà 9:1) Gálílì jẹ́ ìpínlẹ̀ kan lára ilẹ̀ ìjọba Ísírẹ́lì níhà àríwá. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, ó nasẹ̀ dé “ilẹ̀ Sébúlúnì àti ilẹ̀ Náfútálì” àti “ọ̀nà òkun,” ìyẹn, ọ̀nà àtijọ́ kan tó gba Òkun Gálílì lọ sí Òkun Mẹditaréníà. “Gálílì àwọn orílẹ̀-èdè” ni wọ́n ń pe ẹkùn ibẹ̀ nígbà ayé Aísáyà, bóyá tìtorí pé àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì ló ń gbé ọ̀pọ̀ àwọn ìlú ibẹ̀.c Báwo ni wọ́n ṣe “fojú tín-ínrín” ilẹ̀ yẹn ná? Àwọn ará Ásíríà abọ̀rìṣà ṣẹ́gun rẹ̀, wọ́n kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ sígbèkùn, wọ́n sì wá kó àwọn abọ̀rìṣà, tí kì í ṣe ìran Ábúráhámù, tẹ̀ dó sí gbogbo àgbègbè ibẹ̀. Bí a kò ṣe gbúròó orílẹ̀-èdè tó jẹ́ ti ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá níhà àríwá mọ́ nínú ìtàn nìyẹn o!—2 Àwọn Ọba 17:5, 6, 18, 23, 24.
14. Ọ̀nà wo ni “ìṣókùnkùn bàìbàì” ti Júdà yóò fi dín kù sí ti ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá?
14 Àwọn ará Ásíríà tún ń fínná mọ́ Júdà pẹ̀lú. Ṣé yóò di ibi ‘ṣíṣókùnkùn bàìbàì’ gbére bó ṣe ṣẹlẹ̀ sí ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá tí Sébúlúnì àti Náfútálì dúró fún ni? Rárá o. Ní “ẹ̀yìn ìgbà náà,” Jèhófà yóò bù kún ẹkùn ìjọba Júdà níhà gúúsù, àní títí kan ilẹ̀ tí ìjọba àríwá ń ṣàkóso rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí pàápàá. Lọ́nà wo?
15, 16. (a) Ìgbà wo ni “ẹ̀yìn ìgbà náà” tí ipò nǹkan yóò yí padà fún “ilẹ̀ Sébúlúnì àti ilẹ̀ Náfútálì”? (b) Báwo ni ilẹ̀ tí wọ́n fojú tín-ínrín ṣe wá di èyí táa bọlá fún?
15 Àpọ́sítélì Mátíù dáhùn ìbéèrè yìí nínú àkọsílẹ̀ onímìísí tó kọ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù lórí ilẹ̀ ayé. Mátíù ṣàpèjúwe apá ìbẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ yẹn pé: “Lẹ́yìn fífi Násárétì sílẹ̀, [Jésù] wá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ní Kápánáúmù lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkun ní àgbègbè Sébúlúnì àti Náfútálì, kí a bàa lè mú ohun tí a sọ nípasẹ̀ Aísáyà wòlíì ṣẹ, pé: ‘Ìwọ ilẹ̀ Sébúlúnì àti ilẹ̀ Náfútálì, ní ojú ọ̀nà òkun, ní ìhà kejì Jọ́dánì, Gálílì àwọn orílẹ̀-èdè! àwọn ènìyàn tí ó jókòó nínú òkùnkùn rí ìmọ́lẹ̀ ńlá kan, àti ní ti àwọn tí ó jókòó ní ẹkùn ilẹ̀ òjìji ikú, ìmọ́lẹ̀ là sórí wọn.’”—Mátíù 4:13-16.
16 Bẹ́ẹ̀ ni, àkókò iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristi lórí ilẹ̀ ayé ni “ẹ̀yìn ìgbà náà” tí Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀. Gálílì ni Jésù ti lo èyí tó pọ̀ jù nínú ìgbésí ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Ẹkùn Gálílì ló ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí polongo pé: “Ẹ ronú pìwà dà, nítorí ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.” (Mátíù 4:17) Gálílì ló ti ṣe Ìwàásù olókìkí tó ṣe lórí Òkè, ibẹ̀ ló ti yan àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, ibẹ̀ ló ti ṣe àkọ́ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, ibẹ̀ ló sì ti fara han nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọmọlẹ́yìn lẹ́yìn tó jíǹde. (Mátíù 5:1–7:27; 28:16-20; Máàkù 3:13, 14; Jòhánù 2:8-11; 1 Kọ́ríńtì 15:6) Lọ́nà yìí, Jésù mú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ṣẹ nípa bíbọlá fún “ilẹ̀ Sébúlúnì àti ilẹ̀ Náfútálì.” Àmọ́ ṣá o, Jésù kò fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ mọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn Gálílì. Bí Jésù ṣe wàásù káàkiri gbogbo ilẹ̀ ibẹ̀, ó “mú kí a bọlá fún” gbogbo orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, títí kan Júdà.
“Ìmọ́lẹ̀ Ńlá” Náà
17. Báwo ni “ìmọ́lẹ̀ ńlá” ṣe tàn ní Gálílì?
17 “Ìmọ́lẹ̀ ńlá kan” tí Mátíù sọ pé ó wà ní Gálílì ńkọ́? Inú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà náà ló ti fa ìyẹn yọ. Aísáyà kọ̀wé pé: “Àwọn ènìyàn tí ń rìn nínú òkùnkùn ti rí ìmọ́lẹ̀ ńlá. Ní ti àwọn tí ń gbé ní ilẹ̀ ibú òjìji, àní ìmọ́lẹ̀ ti tàn sórí wọn.” (Aísáyà 9:2) Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, èké àwọn abọ̀rìṣà ti bo ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ mọ́lẹ̀. Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn Júù tún wá dá kún un nípa wíwonkoko mọ́ àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ inú ẹ̀sìn tiwọn, èyí tí wọ́n fi “sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di aláìlẹ́sẹ̀nílẹ̀.” (Mátíù 15:6) Àwọn “afọ́jú afinimọ̀nà” táwọn onírẹ̀lẹ̀ ń tọ̀ lẹ́yìn ń kó ìnira àti ṣìbáṣìbo bá wọn. (Mátíù 23:2-4, 16) Nígbà tí Jésù, Mèsáyà, fara hàn, ojú ọ̀pọ̀lọpọ̀ onírẹ̀lẹ̀ là lọ́nà ìyanu. (Jòhánù 1:9, 12) Ńṣe ló ṣe wẹ́kú bí àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ṣe ṣàpèjúwe iṣẹ́ tí Jésù ṣe nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé àti àwọn ìbùkún ìràpadà rẹ̀, pé wọ́n jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ ńlá” náà.—Jòhánù 8:12.
18, 19. Ìdí wo ni ayọ̀ àwọn tó kọbi ara sí ìmọ́lẹ̀ náà fi pọ̀ gan-an?
18 Ìdí ayọ̀ àwọn tó kọbi ara sí ìmọ́lẹ̀ náà pọ̀ gan-an ni. Aísáyà ń bọ́rọ̀ lọ pé: “Ìwọ ti sọ orílẹ̀-èdè náà di púpọ̀ sí i; o ti sọ ayọ̀ yíyọ̀ di púpọ̀ fún un. Wọ́n ń yọ̀ níwájú rẹ gẹ́gẹ́ bí a ti ń yọ̀ ní àkókò ìkórè, gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ó kún fún ìdùnnú nígbà tí wọ́n ń pín ohun ìfiṣèjẹ.” (Aísáyà 9:3) Ìwàásù Jésù àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mú kí àwọn olùfẹ́ òdodo jáde wá, wọ́n ń fẹ́ láti sin Jèhófà ní ẹ̀mí àti òtítọ́. (Jòhánù 4:24) Kò pọ́dún mẹ́rin rárá tí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn fi di ẹlẹ́sìn Kristẹni. Ẹgbẹ̀ẹ́dógún ni wọ́n batisí lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Láìpẹ́ lẹ́yìn náà, “iye àwọn ọkùnrin náà sì di nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún.” (Ìṣe 2:41; 4:4) Bí àwọn àpọ́sítélì ṣe ń fi ìtara tànmọ́lẹ̀ náà kiri, “iye àwọn ọmọ ẹ̀yìn . . . ń di púpọ̀ sí i ṣáá ní Jerúsálẹ́mù; ogunlọ́gọ̀ ńlá àwọn àlùfáà sì bẹ̀rẹ̀ sí di onígbọràn sí ìgbàgbọ́ náà.”—Ìṣe 6:7.
19 Ìbísí yìí mú inú àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù dùn gan-an ni, àfi bí ìdùnnú ẹni tó rí ìkórè wọ̀ǹtì-wọnti tàbí tẹni tí wọ́n pín ohun ìfiṣèjẹ oníyebíye fún lẹ́yìn ogun àjàṣẹ́gun kan. (Ìṣe 2:46, 47) Láìpẹ́, Jèhófà mú kí ìmọ́lẹ̀ náà tàn láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. (Ìṣe 14:27) Èyí sì mú káwọn ènìyàn inú ẹ̀yà gbogbo máa yọ̀ pé ọ̀nà láti tọ Jèhófà lọ tí ṣí sílẹ̀ fáwọn náà.—Ìṣe 13:48.
“Bí Ti Ọjọ́ Mídíánì”
20. (a) Àwọn ọ̀nà wo ni Mídíánì gbà fi jẹ́ ọ̀tá Ísírẹ́lì, báwo ni Jèhófà sì ṣe fòpin sí jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ ewu? (b) Ní “ọjọ́ Mídíánì” tí ń bọ̀, báwo ni Jésù yóò ṣe fòpin sí ewu tí àwọn ọ̀tá jẹ́ fáwọn ènìyàn Ọlọ́run?
20 Títí gbére ni àbájáde ìgbòkègbodò Mèsáyà yóò máa báṣẹ́ lọ, gẹ́gẹ́ bó ṣe hàn látinú ọ̀rọ̀ tí Aísáyà sọ tẹ̀ lé e pé: “Àjàgà ẹrù wọn àti ọ̀pá tí ó wà ní èjìká wọn, ọ̀gọ ẹni tí ń kó wọn ṣiṣẹ́, ni ìwọ ti ṣẹ́ sí wẹ́wẹ́ bí ti ọjọ́ Mídíánì.” (Aísáyà 9:4) Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú ìgbà ayé Aísáyà, ṣe ni àwọn ará Mídíánì lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn ará Móábù láti tan Ísírẹ́lì sọ́fìn ẹ̀ṣẹ̀. (Númérì 25:1-9, 14-18; 31:15, 16) Lẹ́yìn ìgbà náà, àwọn ará Mídíánì han àwọn ọmọ Ísírẹ́lì léèmọ̀ fọ́dún méje, wọ́n ń ya lu àwọn abúlé àti oko wọn, wọ́n sì ń kó wọn lẹ́rù. (Àwọn Onídàájọ́ 6:1-6) Àmọ́ ṣá o, Jèhófà tipasẹ̀ Gídéónì ìránṣẹ́ rẹ̀ rẹ́yìn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mídíánì. Lẹ́yìn “ọjọ́ Mídíánì” yẹn, kò tún sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé àwọn ará Mídíánì tún fìyà jẹ àwọn ènìyàn Jèhófà mọ́. (Àwọn Onídàájọ́ 6:7-16; 8:28) Láìpẹ́, Gídéónì ńlá náà, Jésù Kristi, yóò ṣá àwọn ọ̀tá ènìyàn Jèhófà tòde òní balẹ̀. (Ìṣípayá 17:14; 19:11-21) Lẹ́yìn náà, òun yóò wá fi agbára Jèhófà, láìṣe nípa mímọ̀-ọ́n ṣe tènìyàn, ṣẹ́gun wọn porogodo, tí wọn ò fi ní gbérí mọ́ láé, “bí ti ọjọ́ Mídíánì.” (Àwọn Onídàájọ́ 7:2-22) Láéláé, àjàgà àwọn aninilára ò tún ní wá sí ọrùn àwọn ènìyàn Ọlọ́run mọ́!
21. Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà fi hàn nípa ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí ogun jíjà?
21 Iṣẹ́ àrà tí Ọlọ́run ń ṣe yìí kò fi hàn pé ó ń gbárùkù ti ogun. Ọmọ Aládé Àlàáfíà ni Jésù tó jíǹde jẹ́, pípa tí yóò sì pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ run ni yóò fi mú kí àlàáfíà jọba títí ayé. Aísáyà wá sọ nípa bí ìhámọ́ra ogun ṣe di sísun ráúráú, ó ní: “Gbogbo bàtà abokókósẹ̀ ti ẹni tí ń fi ìmìjìgìjìgì fẹsẹ̀ kilẹ̀ àti aṣọ àlàbora tí a yí nínú ẹ̀jẹ̀ ti wá wà fún sísun gẹ́gẹ́ bí oúnjẹ fún iná.” (Aísáyà 9:5) Jìgìjìgì tí ilẹ̀ ń mì bí àwọn sójà ṣe ń fi bàtà abokókósẹ̀ kilẹ̀ wì-wì-wì kò ní wáyé mọ́ láé. Láéláé, a kò ní rí ẹ̀wù ẹ̀jẹ̀ táwọn ògbójú jagunjagun máa ń wọ̀ mọ́. Kò ní sógun mọ́!—Sáàmù 46:9.
“Àgbàyanu Agbani-Nímọ̀ràn”
22. Orúkọ tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀, tó sì pẹ̀ka wo ni wọ́n sọ Jésù nínú ìwé Aísáyà?
22 Nígbà tí wọ́n bí ẹni tí yóò di Mèsáyà náà lọ́nà ìyanu, wọ́n sọ ọ́ ní Jésù, tó túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Ìgbàlà.” Ṣùgbọ́n ó tún ní àwọn orúkọ mìíràn, àwọn orúkọ tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀, tó ń sọ ipa pàtàkì tí yóò kó àti ipò gíga tó máa wà. Ọ̀kan lára orúkọ yẹn ni Ìmánúẹ́lì, tó túmọ̀ sí “Ọlọ́run Wà Pẹ̀lú Wa.” (Aísáyà 7:14, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Aísáyà wá sọ orúkọ mìíràn tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀, ó ní: “A ti bí ọmọ kan fún wa, a ti fi ọmọkùnrin kan fún wa; ìṣàkóso ọmọ aládé yóò sì wà ní èjìká rẹ̀. Orúkọ rẹ̀ ni a ó sì máa pè ní Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn, Ọlọ́run Alágbára Ńlá, Baba Ayérayé, Ọmọ Aládé Àlàáfíà.” (Aísáyà 9:6) Gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìtumọ̀ orúkọ tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀, tó sì pẹ̀ka yìí yẹ̀ wò.
23, 24. (a) Ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ “Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn”? (b) Báwo làwọn Kristẹni agbani-nímọ̀ràn lóde òní ṣe lè ṣàfarawé Jésù?
23 Ẹní bá ń fúnni nímọ̀ràn tàbí tó ń báni dámọ̀ràn ni agbani-nímọ̀ràn. Jésù Kristi fúnni ní ìmọ̀ràn àgbàyanu nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. A kà á nínú Bíbélì pé, “háà ń ṣe ogunlọ́gọ̀ sí ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.” (Mátíù 7:28) Ọlọ́gbọ́n Agbani-nímọ̀ràn àti agbatẹnirò ló jẹ́, ẹni tó lóye ẹ̀dá ènìyàn lọ́nà àrà-ọ̀tọ̀. Ìmọ̀ràn rẹ̀ kò mọ sí ti bíbániwí tàbí kó nani lẹ́gba ọ̀rọ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìtọ́ni àti àmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ ló máa ń jẹ́. Ìmọ̀ràn Jésù jẹ́ àgbàyanu nítorí pé gbogbo ìgbà ló máa ń jẹ́ ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n, pípé, tí kò lè kùnà. Bí èèyàn bá fi í sílò, ìyè ayérayé ló ń sinni lọ.—Jòhánù 6:68.
24 Ìmọ̀ràn Jésù kì í ṣe èyí tó kàn tinú làákàyè rẹ̀ wá. Dípò bẹ́ẹ̀, ó ní: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.” (Jòhánù 7:16) Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Orísun ọgbọ́n Sólómọ́nì náà ni Orísun ti Jésù. (1 Àwọn Ọba 3:7-14; Mátíù 12:42) Ó yẹ kí àpẹẹrẹ ti Jésù sún àwọn olùkọ́ni àti agbani-nímọ̀ràn nínú ìjọ Kristẹni láti máa gbé ìtọ́ni wọn karí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nígbà gbogbo.—Òwe 21:30.
“Ọlọ́run Alágbára Ńlá” àti “Baba Ayérayé”
25. Kí ni orúkọ náà, “Ọlọ́run Alágbára Ńlá,” sọ fún wa nípa Jésù lọ́run?
25 Jésù tún jẹ́ “Ọlọ́run Alágbára Ńlá” àti “Baba Ayérayé.” Èyí kò túmọ̀ sí pé ó já ọlá àṣẹ àti ipò Jèhófà, tó jẹ́ “Baba wa Ọlọ́run,” gbà. (2 Kọ́ríńtì 1:2) “[Jésù] kò ronú rárá nípa ìjá-nǹkan-gbà, èyíinì ni, pé kí òun bá Ọlọ́run dọ́gba.” (Fílípì 2:6) Ọlọ́run Alágbára Ńlá ni Bíbélì pè é, kì í ṣe Ọlọ́run Olódùmarè. Jésù kò ka ara rẹ̀ sí Ọlọ́run Olódùmarè rí, nítorí ohun tó pe Baba rẹ̀ ni “Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà,” ìyẹn ni, Ọlọ́run kan ṣoṣo tí ìjọsìn tọ́ sí. (Jòhánù 17:3; Ìṣípayá 4:11) Nínú Ìwé Mímọ́, ọ̀rọ̀ náà “ọlọ́run” lè túmọ̀ sí “alágbára ńlá” tàbí “alágbára.” (Ẹ́kísódù 12:12; Sáàmù 8:5; 2 Kọ́ríńtì 4:4) Kí Jésù tó wá sáyé, ó jẹ́ “ọlọ́run kan,” ní ti pé ó “wà ní ìrísí Ọlọ́run.” Lẹ́yìn tó jíǹde, ó padà sí ipò tó tilẹ̀ tún ga jù ìyẹn lọ ní ọ̀run. (Jòhánù 1:1; Fílípì 2:6-11) Ẹ̀wẹ̀, ohun mìíràn tún rọ̀ mọ́ orúkọ náà “ọlọ́run.” Wọ́n pe àwọn onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì ní “ọlọ́run”—Jésù alára pè wọ́n bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan. (Sáàmù 82:6; Jòhánù 10:35) Jésù jẹ́ Onídàájọ́ tí Jèhófà yàn, ẹni “tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti ṣèdájọ́ àwọn alààyè àti òkú.” (2 Tímótì 4:1; Jòhánù 5:30) Dájúdájú, orúkọ náà, Ọlọ́run Alágbára Ńlá, yẹ ẹ́ gan-an ni.
26. Èé ṣe táa fi lè pe Jésù ní “Baba Ayérayé”?
26 Oyè náà “Baba Ayérayé” ń tọ́ka sí agbára àti ọlá àṣẹ tí Mèsáyà Ọba ní láti fún aráyé ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé. (Jòhánù 11:25, 26) Ikú ni ogún tí Ádámù òbí wa àkọ́kọ́ fi lé wa lọ́wọ́. Jésù, Ádámù ìkẹyìn, “di ẹ̀mí tí ń fúnni ní ìyè.” (1 Kọ́ríńtì 15:22, 45; Róòmù 5:12, 18) Gẹ́gẹ́ bí Jésù, Baba Ayérayé, yóò ṣe wà láàyè títí láé, náà ni aráyé onígbọràn yóò ṣe máa jàǹfààní jíjẹ́ tó jẹ́ baba wọn títí láé.—Róòmù 6:9.
“Ọmọ Aládé Àlàáfíà”
27, 28. Àwọn àǹfààní tó kàmàmà wo làwọn tó jẹ́ ọmọ abẹ́ “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” ní nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú?
27 Yàtọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, èèyàn tún ń fẹ́ àlàáfíà, láàárín òun àti Ọlọ́run, àtòun àti ọmọnìkejì rẹ̀ pẹ̀lú. Àní lónìí pàápàá, àwọn tó fara wọn sábẹ́ àkóso “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” ti ‘fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn sì ti fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn.’ (Aísáyà 2:2-4) Wọn kì í tìtorí ìyàtọ̀ inú ìṣèlú, ìpínlẹ̀, ẹ̀yà, tàbí ìwọ̀n owó téèyàn ní lọ́wọ́ bẹ̀rẹ̀ sí kórìíra rẹ̀. Wọ́n ṣọ̀kan nínú ìjọsìn Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà, wọ́n sì ń sapá láti wà lálàáfíà pẹ̀lú àwọn aládùúgbò wọn, nínú ìjọ àti níbikíbi.—Gálátíà 6:10; Éfésù 4:2, 3; 2 Tímótì 2:24.
28 Bó bá ti tákòókò lójú Ọlọ́run, Kristi yóò mú kí àlàáfíà wà kárí ayé, àlàáfíà tó fìdí múlẹ̀ gbọn-in, tí kò ní ṣípò padà. (Ìṣe 1:7) “Ọ̀pọ̀ yanturu ìṣàkóso ọmọ aládé àti àlàáfíà kì yóò lópin, lórí ìtẹ́ Dáfídì àti lórí ìjọba rẹ̀ láti lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in àti láti gbé e ró nípasẹ̀ ìdájọ́ òdodo àti nípasẹ̀ òdodo, láti ìsinsìnyí lọ àti títí dé àkókò tí ó lọ kánrin.” (Aísáyà 9:7a) Jésù kò ní lo agbára rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Aládé Àlàáfíà láti fi nini lára. Kò ní fi àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ ṣe ẹṣin gùn. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbogbo ohun tí yóò bá ṣe yóò jẹ́ “nípasẹ̀ ìdájọ́ òdodo àti nípasẹ̀ òdodo.” Áà, àyípadà yìí mà tuni lára o!
29. Kí ló yẹ ká ṣe bí a bá fẹ́ gba ìbùkún àlàáfíà ayérayé?
29 Lójú gbogbo ohun ìyanu tó rọ̀ mọ́ orúkọ Jésù tó bá àsọtẹ́lẹ̀ lọ yìí, ohun tí Aísáyà fi kásẹ̀ ẹ̀ka àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ yìí nílẹ̀ wúni lórí gidigidi. Ó kọ̀wé pé: “Àní ìtara Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò ṣe èyí.” (Aísáyà 9:7b) Bẹ́ẹ̀ ni, ìtara ni Jèhófà fi ń ṣe nǹkan. Kì í fi iyèméjì ṣe ohunkóhun. Ó dájú pé ohunkóhun tó bá ṣèlérí, yóò ṣe é lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Bẹ́nikẹ́ni bá wá fẹ́ gbádùn àlàáfíà títí láé, kí ó sin Jèhófà tọkàntọkàn ni o. Ǹjẹ́ kí gbogbo ìránṣẹ́ Ọlọ́run jẹ́ “onítara fún iṣẹ́ àtàtà” gẹ́gẹ́ bíi Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù, Ọmọ Aládé Àlàáfíà.—Títù 2:14.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀pọ̀ gbà gbọ́ pé Hesekáyà ló kọ Sáàmù kọkàndínlọ́gọ́fà kó tó di ọba. Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, a jẹ́ pé àkókò tí Aísáyà ń sàsọtẹ́lẹ̀ ló kọ ọ́.
b Àpólà ọ̀rọ̀ náà, “gbólóhùn yìí,” tó wà nínú Aísáyà 8:20, lè tọ́ka sí ọ̀rọ̀ nípa ìbẹ́mìílò, èyí táa fà yọ nínú Aísáyà 8:19. Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ṣe ni Aísáyà ń sọ pé àwọn tó ń gbé ìbẹ́mìílò lárugẹ ní Júdà yóò máa rọ àwọn mìíràn láti tọ àwọn abẹ́mìílò lọ, nípa bẹ́ẹ̀, wọn ò ní rí ìlàlóye kankan gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà.
c Àwọn kan sọ pé ó jọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ́ ló ń gbé nínú ogún ìlú Gálílì tí Sólómọ́nì Ọba fi fún Hírámù ọba Tírè.—1 Àwọn Ọba 9:10-13.
[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 122]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Kórásínì
Bẹtisáídà
Kápánáúmù
Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹ́nésárẹ́tì
Òkun Gálílì
Mágádánì
Tìbéríà
Odò Jọ́dánì
GÁDÁRÀ
Gádárà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 119]
Ohun pàtàkì gbáà ni ìbí Kéènì àti ti Jésù jùmọ̀ jẹ́. Ìbí ti Jésù nìkan ló já sí ayọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 121]
Ìyàn tó burú ju ebi fún oúnjẹ àti òùngbẹ fún omi ni yóò wáyé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 127]
Jésù ni ìmọ́lẹ̀ tó wà nínú ilẹ̀ náà