Orí Kọkànlá
Ègbé Ni Fáwọn Ọlọ̀tẹ̀!
1. Nǹkan burúkú wo ni Jèróbóámù ṣe?
NÍGBÀ tí ìjọba àwọn èèyàn tó bá Jèhófà dá májẹ̀mú pín sí méjì, ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá níhà àríwá bọ́ sábẹ́ àkóso Jèróbóámù. Ọba tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jẹ yìí kúnjú òṣùwọ̀n, ó sì já fáfá. Àmọ́, kò ní ojúlówó ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà. Ìyẹn ló mú kó ṣe nǹkan burúkú kan tó ba ìtàn ìjọba àríwá jẹ́ látòkè délẹ̀. Lábẹ́ Òfin Mósè, wọ́n pa á láṣẹ pé ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lọ́dún ni kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa gòkè lọ́ sí tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù, ìlú tó ti wá bọ́ sábẹ́ ìjọba Júdà níhà gúúsù báyìí. (Diutarónómì 16:16) Jèróbóámù bẹ̀rù pé lílọ táwọn èèyàn ìjọba òun bá ń lọ síbẹ̀ déédéé yóò mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ronú nípa bí àwọn àti ìjọba Júdà níhà gúúsù yóò ṣe tún padà dọ̀kan, ìyẹn ló fi “ṣe ọmọ màlúù wúrà méjì, ó sì wí fún àwọn ènìyàn náà pé: ‘Ó ti pọ̀ jù fún yín láti máa gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù. Ọlọ́run rẹ rèé, ìwọ Ísírẹ́lì, tí ó mú ọ gòkè wá láti ilẹ̀ Íjíbítì.’ Nígbà náà, ó gbé ọ̀kan sí Bẹ́tẹ́lì, ó sì gbé ìkejì sí Dánì.”—1 Àwọn Ọba 12:28, 29.
2, 3. Ipa wo ni nǹkan burúkú tí Jèróbóámù ṣe ní lórí Ísírẹ́lì?
2 Ète Jèróbóámù ṣe bí ẹní ṣiṣẹ́ fún ìgbà díẹ̀. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn èèyàn ṣíwọ́ lílọ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jọ́sìn níwájú ère ọmọ màlúù méjèèjì. (1 Àwọn Ọba 12:30) Àmọ́ o, ṣíṣe ẹ̀sìn apẹ̀yìndà yìí sọ ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá náà dìbàjẹ́. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, kódà Jéhù, tó fi ìtara tó wúni lórí palẹ̀ ẹ̀sìn Báálì mọ́ kúrò ní Ísírẹ́lì, lọ ń tẹrí ba fáwọn ère ọmọ màlúù wúrà yẹn. (2 Àwọn Ọba 10:28, 29) Kí ló tún tẹ̀yìn ìpinnu tó lòdì burúkú, tí Jèróbóámù ṣe yọ? Ìjọba yẹn ò tòrò, ìyà sì ń jẹ àwọn aráàlú.
3 Nítorí pé Jèróbóámù di apẹ̀yìndà, Jèhófà sọ pé irú ọmọ rẹ̀ kò ní jọba lórí ilẹ̀ náà, pé àjálù ńláǹlà ṣì ń bọ̀ wá já lu ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá yẹn níkẹyìn. (1 Àwọn Ọba 14:14, 15) Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ṣẹ. Méje nínú àwọn ọba Ísírẹ́lì ni kò jọba ju ọdún méjì lọ tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀—àwọn kan ò lò ju ọjọ́ mélòó kan péré. Ọba kan para ẹ̀, àwọn ọ̀kánjúà afipágbàjọba sì pa ọba mẹ́fà. Inú-fu, ẹ̀dọ̀-fu, ìwà ipá, àti ìṣìkàpànìyàn gbòde kan ní Ísírẹ́lì, pàápàá lẹ́yìn ìṣàkóso Jèróbóámù Kejì, tó dópin ní nǹkan bí ọdún 804 ṣááju Sànmánì Tiwa nígbà tí Ùsáyà ń ṣàkóso Júdà. Ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí ló fà á tí Jèhófà fi fi ìkìlọ̀ tàbí “ọ̀rọ̀” ránṣẹ́ sí ìjọba àríwá nípasẹ̀ Aísáyà. Ó sọ pé: “Ọ̀rọ̀ kan wà tí Jèhófà fi ránṣẹ́ sí Jékọ́bù, ó sì bọ́ sórí Ísírẹ́lì.”—Aísáyà 9:8.a
Ìrera àti Àfojúdi Máa Ń Múni Rí Ìbínú Ọlọ́run
4. “Ọ̀rọ̀” wo ni Jèhófà sọ sí Ísírẹ́lì, èé sì ti ṣe?
4 Wọn kò ní ṣàìgbọ́ “ọ̀rọ̀” Jèhófà. Ó sọ pé: “Àwọn ènìyàn náà yóò sì mọ̀ ọ́n dájúdájú, àní gbogbo wọn, Éfúráímù àti olùgbé Samáríà, nítorí ìrera wọn àti nítorí àfojúdi ọkàn-àyà wọn.” (Aísáyà 9:9) Ìjọba Ísírẹ́lì níhà àríwá, tí Éfúráímù jẹ́ ẹ̀yà tó pọ̀ jù níbẹ̀, tí Samáríà sì jẹ́ olú ìlú rẹ̀, ni “Jékọ́bù,” “Ísírẹ́lì,” “Éfúráímù,” àti “Samáríà” tọ́ka sí. Gbólóhùn ìdájọ́ líle ni Jèhófà sọ sí ìjọba yẹn, nítorí Éfúráímù ti jingíri nínú ìpẹ̀yìndà, ìwà àfojúdi rẹ̀ sí Jèhófà sì pọ̀ jọjọ. Ọlọ́run kò ní gba àwọn èèyàn yẹn lọ́wọ́ ìyà tí ọ̀nà burúkú wọn máa fi jẹ wọ́n. Bí wọ́n fẹ́ bí wọ́n kọ̀ wọ́n á gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní túláàsì.—Gálátíà 6:7.
5. Báwo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe kọ etí ikún sí ọ̀ràn ìdájọ́ Jèhófà?
5 Bí ipò nǹkan ṣe túbọ̀ ń burú sí i fáwọn èèyàn náà, àdánù ńlá bá wọn, títí kan ilé wọn—tí wọ́n sábà máa ń fi bíríkì bàmùbàmù àti ọ̀pọ̀kúyọ̀kú igi kọ́. Ṣé ìyẹn wá jẹ́ kí ọkàn wọn rọ̀? Ṣé ìyẹn yóò mú kí wọ́n gbọ́rọ̀ sí àwọn wòlíì Jèhófà lẹ́nu, kí wọ́n sì padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run òtítọ́?b Aísáyà ṣàkọsílẹ̀ bí àwọn èèyàn náà ṣe fèsì lọ́nà àfojúdi pé: “Bíríkì ni ó ṣubú, ṣùgbọ́n òkúta gbígbẹ́ ni a ó fi kọ́ ọ. Igi síkámórè ni a gé lulẹ̀, ṣùgbọ́n kédárì ni a ó fi ṣe àfirọ́pò rẹ̀.” (Aísáyà 9:10) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tàpá sí Jèhófà, wọn ò sì tẹ́wọ́ gba àwọn wòlíì rẹ̀ tó ń sọ fún wọn nípa ìdí tí irú ìyà bẹ́ẹ̀ fi ń jẹ wọ́n. Lọ́rọ̀ kan ṣá, ohun tí wọ́n ń sọ ni pé: ‘Ilé wa táa fi bíríkì bàmùbàmù àti ọ̀pọ̀kúyọ̀kú igi kọ́ wó lóòótọ́, àmọ́, ilé ọba tó jó ẹwà ló bù sí i, àwọn ohun èlò tó tún gbayì, bíi òkúta gbígbẹ́ àti kédárì, la óò fi tún un kọ́!’ (Fi wé Jóòbù 4:19.) Wọ́n ti wá dá Jèhófà lágara wàyí, àfi kó túbọ̀ fìyà jẹ wọ́n.—Fi wé Aísáyà 48:22.
6. Báwo ni Jèhófà ṣe dènà rìkíṣí tí Síríà àti Ísírẹ́lì dì sí Júdà?
6 Aísáyà ń bọ́rọ̀ lọ pé: “Jèhófà yóò . . . gbé àwọn elénìní Résínì dìde sókè sí i.” (Aísáyà 9:11a) Alájọṣepọ̀ ni Pékà ọba Ísírẹ́lì àti Résínì ọba Síríà jẹ́. Wọ́n ń pète láti ṣẹ́gun ìjọba ẹ̀yà méjì ti Júdà, kí wọ́n sì gbé dọ̀bọ̀sìyẹẹsà ọba—ọ̀gbẹ́ni kan tó jẹ́ “ọmọkùnrin Tábéélì”—sórí ìtẹ́ Jèhófà ní Jerúsálẹ́mù. (Aísáyà 7:6) Ṣùgbọ́n, tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun wọn máa wọlẹ̀ ni. Résínì ní àwọn ọ̀tá alágbára, àwọn ọ̀tá yìí ni Jèhófà yóò sì ‘gbé dìde sókè sí i,’ ìyẹn Ísírẹ́lì. Gbólóhùn náà ‘gbé dìde sókè’ túmọ̀ sí pé yóò jẹ́ kí wọ́n jagun àjàṣẹ́gun tí yóò fọ́ àjọṣepọ̀ yẹn àti rìkíṣí tí wọ́n dì.
7, 8. Kí ni ṣíṣẹ́gun tí Ásíríà ṣẹ́gun Síríà wá yọrí sí fún Ísírẹ́lì?
7 Ìgbà tí Ásíríà kọ lu Síríà ni àjọṣepọ̀ yẹn ti bẹ̀rẹ̀ sí fọ́. “Ọba Ásíríà sì gòkè lọ sí Damásíkù [olú ìlú Síríà], ó sì gbà á, ó sì kó àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìgbèkùn lọ sí Kírì, ó sì fi ikú pa Résínì.” (2 Àwọn Ọba 16:9) Bí ikú ṣe pa alájọṣepọ̀ alágbára tí Pékà ní, ó rí i pé rìkíṣí tóun pète sí Júdà ti fọ́. Kódà, gẹ́rẹ́ lẹ́yìn ikú Résínì ni Hóṣéà pa Pékà alára, tó sì wá fipá gorí ìtẹ́ ní Samáríà.—2 Àwọn Ọba 15:23-25, 30.
8 Síríà tó jẹ́ alájọṣepọ̀ Ísírẹ́lì tẹ́lẹ̀ ti wá di ara ìgbèríko Ásíríà, ìjọba tó lágbára jù lọ lágbègbè yẹn. Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa bí Jèhófà yóò ṣe lo àwọn ìjọba tó ṣẹ̀ṣẹ̀ já pọ̀ mọ́ra yìí, pé: “Àwọn ọ̀tá ẹni yẹn [Ísírẹ́lì] . . . ni òun [Jèhófà] yóò gún ní kẹ́sẹ́, Síríà láti ìlà-oòrùn àti àwọn Filísínì láti ẹ̀yìn, wọn yóò sì fi gbogbo ẹnu jẹ Ísírẹ́lì tán. Lójú ìwòye gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíì yí padà, ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ nà jáde síbẹ̀.” (Aísáyà 9:11b, 12) Bẹ́ẹ̀ ni, Síríà ti wá dọ̀tá Ísírẹ́lì báyìí, kí Ísírẹ́lì sì máa retí ìkọlù látọ̀dọ̀ Ásíríà àti Síríà ló kù. Lóòótọ́, wọ́n ṣígun lọ bá wọn, wọ́n sì ṣẹ́gun. Ásíríà wá sọ Hóṣéà tó já ìjọba gbà di ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì gba owó orí ńláǹlà lọ́wọ́ rẹ̀. (Ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú ìgbà yẹn, Ásíríà gba owó ńlá lọ́wọ́ Ménáhémù ọba Ísírẹ́lì.) Ọ̀rọ̀ wòlíì Hóséà mà ṣẹ lóòótọ́ o, pé: “Àwọn àjèjì ti jẹ agbára rẹ̀ [ìyẹn, Éfúráímù] tán”!—Hóséà 7:9; 2 Àwọn Ọba 15:19, 20; 17:1-3.
9. Èé ṣe táa fi lè sọ pé àwọn Filísínì ń kọ lù wọ́n “láti ẹ̀yìn”?
9 Ǹjẹ́ Aísáyà ò tún sọ pé àwọn Filísínì yóò ṣígun lọ bá wọn “láti ẹ̀yìn”? Bẹ́ẹ̀ ni. Káyé tó dayé táà ń lo atọ́ka onímágínẹ́ẹ̀tì, bí àwọn Hébérù bá fẹ́ júwe ìhà ibi tí nǹkan wà fúnni ńṣe ni wọ́n máa ń júwe bíi pé ẹni tí wọ́n ń júwe fún kọjú síhà ìlà-oòrùn. Nípa bẹ́ẹ̀, iwájú ni “ìlà-oòrùn” wà, nígbà tí gúúsù, ìyẹn ibi tí àwọn Filísínì wà, ń bẹ “lẹ́yìn.” Lọ́tẹ̀ yìí, ó ṣeé ṣe kí Júdà wà nínú àwọn tí Aísáyà 9:12 pè ní “Ísírẹ́lì,” nítorí pé àwọn Filísínì ṣígun lọ bá Júdà nígbà ìjọba Áhásì, tó gbé láyé ìgbà Pékà, wọ́n sì gba ọ̀pọ̀ àwọn ìlú àti odi agbára ní Jùdíà, wọ́n sì sọ wọ́n di tiwọn. Gẹ́gẹ́ bíi ti Éfúráímù níhà àríwá, ìyà tí Jèhófà fi jẹ Júdà yìí tọ́ sí wọn nítorí pé ńṣe lòun náà ń yí gbiri nínú ọ̀gọ̀dọ̀ ìpẹ̀yìndà.—2 Kíróníkà 28:1-4, 18, 19.
Ọlọ̀tẹ̀ Orílẹ̀-Èdè Ni Wọ́n Láti ‘Orí dé Ìrù’
10, 11. Ìyà wo ni Jèhófà yóò fi jẹ Ísírẹ́lì nítorí pé wọn kò yéé ṣọ̀tẹ̀?
10 Gbogbo bí ìyà ṣe jẹ ìjọba àríwá tó àti gbogbo bí àwọn wòlíì Jèhófà ṣe kéde lọ́nà tó le koko tó, wọn ò yéé ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà. “Àwọn ènìyàn náà kò tíì padà sọ́dọ̀ Ẹni tí ń lù wọ́n, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ni wọn kò sì tíì wá.” (Aísáyà 9:13) Ìyẹn ni wòlíì yìí fi sọ pé: “Jèhófà yóò sì ké orí àti ìrù, ọ̀mùnú àti koríko etídò kúrò ní Ísírẹ́lì, ní ọjọ́ kan ṣoṣo. Àgbàlagbà àti ẹni tí a bọ̀wọ̀ fún gidigidi ni orí, wòlíì tí ń fúnni ní ìtọ́ni èké sì ni ìrù. Àwọn tí ń ṣamọ̀nà àwọn ènìyàn yìí sì ni àwọn tí ń mú wọn rìn gbéregbère; àwọn tí a sì ń ṣamọ̀nà lára wọn, àwọn ni a ń kó ìdàrúdàpọ̀ bá.”—Aísáyà 9:14-16.
11 “Orí” àti “ọ̀mùnú” dúró fún “àgbàlagbà àti ẹni tí a bọ̀wọ̀ fún gidigidi,” ìyẹn àwọn aṣáájú orílẹ̀-èdè náà. “Ìrù” àti “koríko etídò” tọ́ka sí àwọn wòlíì èké tó ń sọ̀rọ̀ dídùn-dídùn fún àwọn aṣáájú wọn. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ kan kọ̀wé pé: “Wọ́n pe àwọn Wòlíì èké ní ìrù, nítorí pé ìwà ìbàjẹ́ tiwọn ló burú jù lọ láwùjọ, àti pé wọ́n jẹ́ ẹni tó ń pá kúbẹ́kúbẹ́ tó sì ń ṣàtìlẹyìn fáwọn ìkà ọba.” Ọ̀jọ̀gbọ́n Edward J. Young sọ nípa àwọn èké wòlíì wọ̀nyí pé: “Láé, wọn kò jẹ́ ṣáájú, àfi kí wọ́n máa tọ àwọn aṣáájú lẹ́yìn gọ̀ọ́gọ̀ọ́, kí wọ́n máa sà wọ́n, kí wọ́n sì máa wárí fún wọn, ṣe ni wọ́n dà bí ìrù tí ń mì lenje-lenje nídìí ajá.”—Fi wé 2 Tímótì 4:3.
Kódà ‘Àwọn Opó àti Ọmọdékùnrin Aláìníbaba’ Ya Ọlọ̀tẹ̀
12. Báwo ni ìwà ìbàjẹ́ ṣe rinlẹ̀ tó láwùjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?
12 Jèhófà ni Olùgbèjà àwọn opó àti ọmọdékùnrin aláìníbaba. (Ẹ́kísódù 22:22, 23) Síbẹ̀, ẹ gbọ́ ohun tí Aísáyà wá sọ, ó ní: “Jèhófà kì yóò . . . yọ̀ lórí àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọn pàápàá, kì yóò sì ṣàánú fún àwọn ọmọdékùnrin wọn aláìníbaba àti fún àwọn opó wọn; nítorí pé gbogbo wọn jẹ́ apẹ̀yìndà àti aṣebi, olúkúlùkù ẹnu sì ń sọ ọ̀rọ̀ òpònú. Lójú ìwòye gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíì yí padà, ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ nà jáde síbẹ̀.” (Aísáyà 9:17) Ìpẹ̀yìndà ti ba orílẹ̀-èdè yẹn jẹ́ látòkè délẹ̀, àní títí kan àwọn opó àti ọmọdékùnrin aláìníbaba! Jèhófà fi sùúrù rán àwọn wòlíì rẹ̀ sí wọn, nírètí pé àwọn èèyàn yẹn yóò yí àwọn ọ̀nà wọn padà. Bí àpẹẹrẹ, Hóséà rọ̀ wọ́n pé, “Padà wá, ìwọ Ísírẹ́lì, sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, nítorí ìwọ ti kọsẹ̀ nínú ìṣìnà rẹ.” (Hóséà 14:1) Yóò mà dun Olùgbèjà àwọn opó àti ọmọdékùnrin aláìníbaba o, pé àwọn yìí kan náà lòun tún ní láti dá lẹ́jọ́!
13. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú bí ipò nǹkan ti rí láyé ìgbà Aísáyà?
13 Gẹ́gẹ́ bí Aísáyà, àwọn àkókò lílekoko tó ṣáájú ọjọ́ ìdájọ́ Jèhófà lórí àwọn àṣebi làwa náà ń gbé yìí. (2 Tímótì 3:1-5) Ó wá ṣe pàtàkì gidigidi nígbà náà, pé, ipòkípò tí Kristẹni tòótọ́ ì báà wà láyé, kí wọ́n jẹ́ mímọ́ nípa tẹ̀mí, nínú ìwà híhù àti nínú èrò, kí wọ́n má bàa ṣàìrójú rere Ọlọ́run. Kí olúkúlùkù máa gbé àjọṣepọ̀ òun àti Jèhófà gẹ̀gẹ̀. Kẹ́nikẹ́ni tó bá ti yè bọ́ kúrò nínú “Bábílónì Ńlá” ma ṣe tún lọ “ṣàjọpín pẹ̀lú rẹ̀ nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀” mọ́ o.—Ìṣípayá 18:2, 4.
Ìsìn Èké Ń Fa Ìwà Ipá
14, 15. (a) Kí ló ń jẹ yọ látinú jíjọ́sìn ẹ̀mí èṣù? (b) Ìyà wo ni Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé Ísírẹ́lì yóò máa jẹ lọ?
14 Ẹní bá ń ṣe ìsìn èké, ẹ̀mí èṣù ló ń sìn. (1 Kọ́ríńtì 10:20) Bóhun tó ṣẹlẹ̀ ṣáájú Ìkún Omi ṣe fi hàn, àwọn ẹ̀mí èṣù a máa tini hùwà ipá. (Jẹ́nẹ́sísì 6:11, 12) Abájọ tó fi jẹ́ pé, nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì di apẹ̀yìndà, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí jọ́sìn àwọn ẹ̀mí èṣù, ńṣe ni ìwà ipá àti ìwà ìkà kún ilẹ̀ náà.—Diutarónómì 32:17; Sáàmù 106:35-38.
15 Aísáyà fi àpèjúwe tó yéni yékéyéké sọ bí ìwà ipá àti ìwà ìkà ṣe gbilẹ̀ tó ní Ísírẹ́lì pé: “Nítorí pé ìwà burúkú ti di ajólala gẹ́gẹ́ bí iná; yóò jẹ àwọn igi kéékèèké ẹlẹ́gùn-ún àti èpò run. Yóò sì gbiná nínú àwọn ìgbòrò igbó, a ó sì gbé wọn lọ sókè gẹ́gẹ́ bí ìrútùù èéfín. A ti sọ iná sí ilẹ̀ náà nínú ìbínú kíkan Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, àwọn ènìyàn náà yóò sì dà bí oúnjẹ fún iná náà. Ẹnì kankan kì yóò fi ìyọ́nú hàn sí arákùnrin rẹ̀ pàápàá. Ẹnì kan yóò sì ṣe kíkélulẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún, ebi yóò sì máa pa á dájúdájú; ẹnì kan yóò sì jẹun ní ọwọ́ òsì, dájúdájú, wọn kì yóò yó. Olúkúlùkù wọn yóò sì jẹ ẹran ara apá tirẹ̀, Mánásè yóò jẹ ti Éfúráímù, Éfúráímù yóò sì jẹ ti Mánásè. Wọn yóò para pọ̀ gbéjà ko Júdà. Lójú ìwòye gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíì yí padà, ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ nà jáde síbẹ̀.”—Aísáyà 9:18-21.
16. Báwo ni ọ̀rọ̀ Aísáyà 9:18-21 ṣe ṣẹ?
16 Bí iná ọyẹ́ tápá ò ká mọ́, tó ń tara igi kéékèèké ẹlẹ́gùn-ún kan ràn mọ́ ìkejì, tó sì ràn mọ́ “ìgbòrò igbó,” tó fi di àgbáàràgbá iná ẹgàn, ni ìwà ipá ṣe ń gbilẹ̀ lọ ràì títí tó fi gbòde kan. Keil àti Delitzsch ti wọ́n jẹ́ alálàyé lórí Bíbélì júwe bí ìwà ipá náà ṣe ga tó pé ó jẹ́ “ogun abẹ́lé tóníkálùkù ń fẹ̀mí ṣòfò bó ṣe wù ú lọ́nà tó burú jáì. Wọ́n kàn ń pa ara wọn lọ pẹ̀ẹ́pẹ̀ẹ́ láìdábọ̀, láìṣàánú ẹnikẹ́ni rárá ni.” Bóyá ohun tó jẹ́ kí wọ́n dárúkọ Éfúráímù àti Mánásè nìkan ni pé àwọn ni aṣojú pàtàkì fún ìjọba àríwá àti pé bí wọ́n ṣe jùmọ̀ jẹ́ àtọmọdọ́mọ ọmọ Jósẹ́fù méjèèjì, àwọn ló jẹ́ ìbátan tímọ́tímọ́ jù lọ nínú ẹ̀yà mẹ́wẹ̀ẹ̀wá. Síbẹ̀síbẹ̀, ìgbà tí tẹ̀gbọ̀ntàbúrò yìí fẹ́ bá Júdà jagun níhà gúúsù nìkan ni wọ́n dáwọ́ fífi ipá kọ lu ara wọn dúró fúngbà díẹ̀.—2 Kíróníkà 28:1-8.
Àwọn Ọ̀bàyéjẹ́ Onídàájọ́ Pàdé Ẹní Máa Dájọ́ Tàwọn Náà
17, 18. Ìwà ìbàjẹ́ wo ló wà nínú ètò òfin àti àkóso ìlú ní Ísírẹ́lì?
17 Àwọn onídàájọ́ àti olóyè yòókù ní Ísírẹ́lì ni Jèhófà wá yíjú ìdájọ́ rẹ̀ sí báyìí. Wọ́n ń ṣi agbára wọn lò nípa fífi àwọn ẹni rírẹlẹ̀ àti akúùṣẹ́ tó bá ké gbàjarè tọ̀ wọ́n lọ ṣe ìjẹ. Aísáyà sọ pé: “Ègbé ni fún àwọn tí ń fi àwọn ìlànà tí ń pani lára lélẹ̀ àti àwọn tí ó jẹ́ pé, ní kíkọ̀wé ṣáá, wọ́n ti kọ̀wé ìjàngbọ̀n gbáà, kí wọ́n lè ti ẹni rírẹlẹ̀ dànù nínú ẹjọ́, kí wọ́n sì lọ́ ìdájọ́ òdodo gbà lọ́wọ́ àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ nínú àwọn ènìyàn mi, kí àwọn opó lè di ohun ìfiṣèjẹ wọn, kí wọ́n sì lè piyẹ́ àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba pàápàá!”—Aísáyà 10:1, 2.
18 Òfin Jèhófà ka gbogbo àìṣèdájọ́ òdodo léèwọ̀, ó sọ pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣe àìṣèdájọ́ òdodo nínú ìdájọ́. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi ojúsàájú bá ẹni rírẹlẹ̀ lò, ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ ṣe ojúsàájú ẹni ńlá.” (Léfítíkù 19:15) Àwọn olóyè wọ̀nyí ṣàìka òfin yìí sí, wọ́n gbé òfin tiwọn “tí ń pani lára” kalẹ̀, láti lè dá ìwà olè tó burú jù lọ láre, ìyẹn ni, gbígbà tí wọ́n ń gba ìwọ̀nba ohun tí àwọn opó àti ọmọdékùnrin aláìníbaba ní. Lóòótọ́, àwọn òrìṣà Ísírẹ́lì kò rí àìṣèdájọ́ òdodo yìí, ṣùgbọ́n Jèhófà rí i. Jèhófà wá tipasẹ̀ Aísáyà yí àfiyèsí sí àwọn olubi onídàájọ́ wọ̀nyí.
19, 20. Báwo ni ipò àwọn ọ̀bàyéjẹ́ onídàájọ́ ní Ísírẹ́lì yóò ṣe yí padà, kí sì ni yóò ṣẹlẹ̀ sí “ògo” wọn?
19 Ó sọ pé: “Kí . . . ni ẹ ó ṣe ní ọjọ́ tí a óò fún yín ní àfiyèsí àti nígbà ìparun, nígbà tí ó bá dé láti ibi jíjìnnàréré? Ọ̀dọ̀ ta ni ẹ óò sá lọ fún ìrànwọ́, ibo sì ni ẹ ó fi ògo yín sílẹ̀ sí, bí kò ṣe pé ènìyàn yóò tẹrí ba lábẹ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n àti pé àwọn ènìyàn yóò máa ṣubú lábẹ́ àwọn tí a ti pa?” (Aísáyà 10:3, 4a) Kò sí onídàájọ́ olóòótọ́ táwọn opó àtàwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba lè fọ̀ràn lọ̀. Ìyẹn gan-an ló fi tọ́ bí Jèhófà ṣe wá bi àwọn ọ̀bàyéjẹ́ onídàájọ́ yẹn léèrè pé ta ni wọ́n fẹ́ sá tọ̀ lọ bóun Jèhófà ṣe fẹ́ pè wọ́n wá jẹ́jọ́ wàyí. Bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n máa tó mọ̀ pé “ó jẹ́ ohun akúnfẹ́rù láti ṣubú sí ọwọ́ Ọlọ́run alààyè.”—Hébérù 10:31.
20 “Ògo” àwọn olubi onídàájọ́ wọ̀nyí, ìyẹn, iyì, ọlá, àti agbára tó ń bá ọlà àti ipò wọn rìn, kò ní tọ́jọ́. Ojú ogun ni wọn yóò ti mú àwọn kan lára wọn lóǹdè, àwọn pẹ̀lú àwọn òǹdè yòókù ni yóò sì jùmọ̀ máa “tẹrí ba” tàbí wólẹ̀ pọ̀, ṣùgbọ́n àwọn yòókù ni wọn yóò pa, àwọn òkú tí ogun pa yóò sì bo òkú tiwọn mọ́lẹ̀. Ọrọ̀ tí wọ́n fi bìrìbìrì kó jọ náà tún wà lára “ògo” wọn, èyí tí àwọn ọ̀tá yóò fi ṣe ìjẹ.
21. Lójú ìyà tó ti jẹ Ísírẹ́lì, ṣé Jèhófà ò wá bínú sí wọn mọ́?
21 Aísáyà wá fi ìkìlọ̀ pàtàkì yìí kádìí ẹsẹ ewì tó kẹ́yìn yìí pé: “Lójú ìwòye gbogbo èyí [gbogbo àjálù tó ti ń bá orílẹ̀-èdè yẹn látẹ̀yìnwá], ìbínú rẹ̀ kò tíì yí padà, ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ nà jáde síbẹ̀.” (Aísáyà 10:4b) Bẹ́ẹ̀ ni o, Ísírẹ́lì ṣì máa gbọ́ dẹndẹ ọ̀rọ̀ lẹ́nu Jèhófà. Jèhófà kò ní fa ọwọ́ tó nà jáde padà títí tí yóò fi mú kí àjálù ìkẹyìn tí yóò fọ́ ìjọba àríwá já lù ú.
Má Ṣe Jìn Sọ́fìn Èké Ṣíṣe àti Ìmọtara-Ẹni-Nìkan
22. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ísírẹ́lì?
22 Jèhófà tipasẹ̀ Aísáyà sọ̀rọ̀ kàbìtìkàbìtì lu Ísírẹ́lì, kò sì ‘padà sọ́dọ̀ Jèhófà láìní ìyọrísí.’ (Aísáyà 55:10, 11) Bí ìjọba Ísírẹ́lì níhà àríwá ṣe fọ́ níkẹyìn wà lákọsílẹ̀ nínú ìtàn, ìyà tó sì jẹ àwọn tí ń gbé ibẹ̀ kọjá wẹ́rẹwẹ̀rẹ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò ṣe ṣẹ sórí ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí pẹ̀lú, pàápàá sórí Kirisẹ́ńdọ̀mù apẹ̀yìndà. Ó mà wá ṣe pàtàkì nígbà náà o, pé kí àwọn Kristẹni má ṣe tẹ́tí rárá sí ìgbékèéyíde tí ń múni ṣòdì sí Ọlọ́run o! A dúpẹ́ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti táṣìírí ètekéte Sátánì tipẹ́tipẹ́, tí kò fi yẹ kí wọ́n borí wa bí wọ́n ṣe borí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì àtijọ́. (2 Kọ́ríńtì 2:11) Ǹjẹ́ kí gbogbo wa má ṣe ṣíwọ́ jíjọ́sìn Jèhófà “ní ẹ̀mí àti òtítọ́” láé. (Jòhánù 4:24) Ṣíṣàìṣíwọ́ yìí ni kò fi ní fi ọwọ́ rẹ̀ tó nà jáde lu àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ bó ṣe kọ lu àwọn Éfúráímù ọlọ̀tẹ̀; kàkà bẹ́ẹ̀ yóò fi apá kó wọn mọ́ra, tí yóò sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́ nìṣó lójú ọ̀nà ìyè àìnípẹ̀kun nínú párádísè orí ilẹ̀ ayé.—Jákọ́bù 4:8.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ẹsẹ ewì (àyọkà adúnbárajọ) mẹ́rin ló wà nínú Aísáyà 9:8–10:4, ègbè tó fi hàn pé ìjàngbọ̀n ń bọ̀, tó parí ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ lọ báyìí pé: “Lójú ìwòye gbogbo èyí, ìbínú rẹ̀ kò tíì yí padà, ṣùgbọ́n ọwọ́ rẹ̀ nà jáde síbẹ̀.” (Aísáyà 9:12, 17, 21; 10:4) Ọ̀nà ìgbà kọ̀wé yìí ló so Aísáyà 9:8–10:4 pa pọ̀ di ọ̀wọ́ “ọ̀rọ̀” kan ṣoṣo. (Aísáyà 9:8) Tún ṣàkíyèsí pé “ọwọ́” Jèhófà tó “nà jáde síbẹ̀,” kì í ṣe láti yanjú ọ̀ràn ní ìtùnbí-ìnùbí, bí kò ṣe láti dá wọn lẹ́jọ́.—Aísáyà 9:13.
b Lára àwọn wòlíì tí Jèhófà rán sí ìjọba Ísírẹ́lì níhà àríwá ni Jéhù (kì í ṣe èyí tó jọba o), Èlíjà, Mikáyà, Èlíṣà, Jónà, Ódédì, Hóséà, Ámósì, àti Míkà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 139]
Ìwà ibi àti ìwà ipá ń gbilẹ̀ lọ ràì bí iná ọyẹ́ ní Ísírẹ́lì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 141]
Jèhófà yóò mú káwọn tó ń fi ọmọnìkejì wọn ṣe ìjẹ jẹ́jọ́