Wíwà Lápọ̀n-ọ́n—Ilẹ̀kùn Sí Ìgbòkègbodò Àpọkànpọ̀ṣe
“Ó túmọ̀ sí ṣíṣiṣẹ́ sin Olúwa nígbà gbogbo láìsí ìpínyà ọkàn.”—KỌ́RÍŃTÌ KÌÍNÍ 7:35.
1. Ìròyìn adaniláàmú wo ni ó dé ọ̀dọ̀ Pọ́ọ̀lù nípa àwọn Kristẹni ní Kọ́ríńtì?
ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù dàníyàn nípa àwọn Kristẹni arákùnrin rẹ̀ tí ń bẹ ní Kọ́ríńtì, ní ilẹ̀ Gíríìsì. Ní nǹkan bí ọdún márùn-ún ṣáájú, ó ti dá ìjọ tí ó wà nínú ìlú aláásìkí yẹn tí ó gbajúmọ̀ fún ìwà pálapàla rẹ̀ sílẹ̀. Wàyí o, ní nǹkan bí ọdún 55 Sànmánì Tiwa, nígbà tí ó wà ní Éfésù, ní Éṣíà Kékeré, ó gba ìròyìn adaniláàmú láti Kọ́ríńtì, nípa ìyapa ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́ àti fífàyè gba ọ̀ràn ìwà pálapàla. Síwájú sí i, Pọ́ọ̀lù ti gba lẹ́tà láti ọ̀dọ̀ àwọn Kristẹni ará Kọ́ríńtì, tí wọ́n ń béèrè fún ìtọ́sọ́nà lórí ìbálòpọ̀ takọtabo, wíwà láìṣègbéyàwó, ṣíṣègbéyàwó, pípínyà, àti títún ìgbéyàwó ṣe.
2. Báwo ni ìwà pálapàla tí ó gbilẹ̀ ní Kọ́ríńtì ṣe ń nípa lórí àwọn Kristẹni tí ń bẹ ní ìlú náà lọ́nà tí ó hàn gbangba?
2 Ìwà pálapàla bíburú lékenkà tí ó gbalẹ̀ kan ní Kọ́ríńtì dà bíi pé ó ń nípa lórí ìjọ àdúgbò náà lọ́nà méjì. Àwọn Kristẹni kan ń juwọ́ sílẹ̀ fún agbára ìdarí ti fífọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ọ̀ràn ìwà rere, wọ́n sì ń fàyè gba ìwà pálapàla. (Kọ́ríńtì Kìíní 5:1; 6:15-17) Ó ṣe kedere pé, àwọn ẹlòmíràn, nípa híhùwà padà sí ìgbádùn ìbálòpọ̀ tí ó gba ìlú náà kan, ṣe àṣerégèé ní ti dídámọ̀ràn títakété sí gbogbo ìbálòpọ̀ takọtabo, kódà fún àwọn tọkọtaya.—Kọ́ríńtì Kìíní 7:5.
3. Ọ̀ràn wo ni Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ yanjú nínú lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ sí àwọn ará Kọ́ríńtì?
3 Nínú lẹ́tà jàn-àn-ràn jan-an-ran tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Kọ́ríńtì, ó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro àìsíṣọ̀kan. (Kọ́ríńtì Kìíní, orí 1 sí 4) Ó gbà wọ́n níyànjú láti yẹra fún títẹ̀ lé ènìyàn, èyí tí ó lè wulẹ̀ yọrí sí ìyapa tí ń pani lára. Ó yẹ kí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan gẹ́gẹ́ bí “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà, ó fún wọn ní ìtọ́ni pàtó lórí mímú kí ìjọ wà ní mímọ́ tónítóní ní ti ìwà híhù. (Orí 5, 6) Lẹ́yìn èyí, àpọ́sítélì náà fèsì lẹ́tà wọn.
Ó Dámọ̀ràn Wíwà Lápọ̀n-ọ́n
4. Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tí ó wí pé “ó dáa fún ọkùnrin kí ó má ṣe fọwọ́ kan obìnrin”?
4 Bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyí: “Wàyí o ní ti àwọn ohun tí ẹ kọ̀wé nípa rẹ̀, ó dáa fún ọkùnrin kí ó má ṣe fọwọ́ kan obìnrin.” (Kọ́ríńtì Kìíní 7:1) Gbólóhùn náà “kí ó má ṣe fọwọ́ kan obìnrin” níhìn-ín túmọ̀ sí yíyẹra fún ìfarakanra pẹ̀lú obìnrin kan nítorí títẹ́ ìfẹ́ ọkàn fún ìbálòpọ̀ lọ́rùn. Níwọ̀n bí Pọ́ọ̀lù ti dẹ́bi fún àgbèrè tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, nísinsìnyí ó ń tọ́ka sí ìbálòpọ̀ takọtabo nínú ètò ìgbéyàwó. Nítorí náà, nísinsìnyí Pọ́ọ̀lù ń dábàá wíwà ní ipò àpọ́n. (Kọ́ríńtì Kìíní 6:9, 16, 18; fi wé Jẹ́nẹ́sísì 20:6; Òwe 6:29.) Ní àfikún díẹ̀ sí i, ó kọ̀wé pé: “Wàyí o èmi wí fún àwọn ènìyàn tí kò gbéyàwó àti àwọn opó pé, ó dáa fún wọn pé kí wọ́n wà àní gẹ́gẹ́ bí èmi ti wà.” (Kọ́ríńtì Kìíní 7:8) Pọ́ọ̀lù kò ní aya, ó sì lè jẹ́ pé aya rẹ̀ ti kú.—Kọ́ríńtì Kìíní 9:5.
5, 6. (a) Èé ṣe tí ó fi ṣe kedere pé kì í ṣe ìgbésí ayé ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé ni Pọ́ọ̀lù ń dámọ̀ràn? (b) Èé ṣe tí Pọ́ọ̀lù fi dámọ̀ràn wíwà lápọ̀n-ọ́n?
5 Bóyá àwọn Kristẹni ní Kọ́ríńtì ti wá mọ ohun kan nípa ọgbọ́n èrò orí Gíríìkì, nínú èyí tí àwọn elérò ìgbàgbọ́ kan náà ti gbé ìgbésí ayé ìfi-nǹkan-dura-ẹni lọ́nà àṣerégèé tàbí ìkára-ẹni-lọ́wọ́-kò gẹ̀gẹ̀. Ìyẹ́n ha lè jẹ́ ìdí tí àwọn ará Kọ́ríńtì fi béèrè lọ́wọ́ Pọ́ọ̀lù bí yóò bá “dáa” fún àwọn Kristẹni láti yẹra fún gbogbo ìbálòpọ̀ takọtabo bí? Èsì Pọ́ọ̀lù kò fi ọgbọ́n èrò orí Gíríìkì hàn. (Kólósè 2:8) Láìdà bí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Kátólíìkì, kò sí ibì kan tí ó ti dábàá ìgbésí ayé ìfi-nǹkan-dura-ẹni ti má-ṣègbéyàwó, ti gbígbé nínú ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé tàbí ti àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé, bí ẹni pé àwọn àpọ́n jẹ́ ẹni mímọ́ lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ kan, àti pé bóyá èyí lè kó ipa pàtàkì nínú ìgbàlà tiwọn fúnra wọn nípasẹ̀ ọ̀nà ìgbésí ayé wọn àti gbígbàdúrà.
6 Pọ́ọ̀lù dábàá wíwà lápọ̀n-ọ́n “nítorí ipò ìṣòro tí ń bẹ níhìn-ín pẹ̀lú wa.” (Kọ́ríńtì Kìíní 7:26) Ó ti lè máa tọ́ka sí àkókò hílàhílo tí àwọn Kristẹni ń là kọjá, èyí tí ìgbéyàwó lè túbọ̀ dá kún. (Kọ́ríńtì Kìíní 7:28) Ìmọ̀ràn rẹ̀ fún àwọn Kristẹni tí kò tí ì gbéyàwó ni pé: “Ó dáa fún wọn pé kí wọ́n wà àní gẹ́gẹ́ bí èmi ti wà.” Ní ti àwọn tí aya wọn ti kú, ó wí pé: “A ha tú ọ kúrò lọ́wọ́ aya kan bí? Dẹ́kun wíwá aya.” Ní ti Kristẹni kan tí ó jẹ́ opó, ó kọ̀wé pé: “Ó láyọ̀ jù bí ó bá dúró bí ó ti wà, gẹ́gẹ́ bí èrò mi. Dájúdájú mo rò pé èmi pẹ̀lú ní ẹ̀mí Ọlọ́run.”—Kọ́ríńtì Kìíní 7:8, 27, 40.
Kò Pọn Dandan Láti Wà Lápọ̀n-ọ́n
7, 8. Kí ni ó fi hàn pé Pọ́ọ̀lù kò fi dandan mú Kristẹni kankan láti wà lápọ̀n-ọ́n?
7 Kò sí iyè méjì pé ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ni ó ń darí Pọ́ọ̀lù nígbà tí ó ń fúnni ní ìmọ̀ràn yìí. Ọ̀nà tí ó gbà gbé wíwà láìgbéyàwó àti gbígbéyàwó kalẹ̀ fi ìwàdéédéé àti ìkóra-ẹni-níjàánu hàn. Kò fi ṣe ọ̀ràn ìṣòtítọ́ tàbí àìṣòótọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ọ̀ràn yàn-bí-o-bá-fẹ́, pẹ̀lú àbá wíwà déédéé tí ó fọwọ́ sí wíwà lápọ̀n-ọ́n, fún àwọn tí wọ́n bà lè wà ní mímọ́ ní ipò yẹn.
8 Kété lẹ́yìn sísọ pé “ó dáa fún ọkùnrin kí ó má ṣe fọwọ́ kan obìnrin,” Pọ́ọ̀lù fi kún un pé: “Síbẹ̀, nítorí ìgbòdekan àgbèrè, kí olúkúlùkù ọkùnrin ní aya tirẹ̀ kí olúkúlùkù obìnrin sì ní ọkọ tirẹ̀.” (Kọ́ríńtì Kìíní 7:1, 2) Lẹ́yìn fífún àwọn tí kò tí ì gbéyàwó àti àwọn opó nímọ̀ràn láti “wà àní gẹ́gẹ́ bí èmi ti wà,” kíá ni ó fi kún un pé: “Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá ní ìkóra-ẹni-níjàánu, kí wọ́n gbéyàwó, nítorí ó sàn láti gbéyàwó ju kí ìfẹ́ onígbòónára máa mú ara-ẹni gbiná.” (Kọ́ríńtì Kìíní 7:8, 9) Lẹ́ẹ̀kan sí i, ìmọ̀ràn rẹ̀ fún àwọn tí aya wọn ti kú ni pé: “Dẹ́kun wíwá aya. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá tilẹ̀ gbéyàwó, ìwọ kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan.” (Kọ́ríńtì Kìíní 7:27, 28) Ìmọ̀ràn wíwà déédéé yìí ń fi òmìnira ṣíṣe yíyàn hàn.
9. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Jésù àti Pọ́ọ̀lù sọ, báwo ni ìgbéyàwó àti wíwà lápọ̀n-ọ́n ṣe jẹ́ ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run?
9 Pọ́ọ̀lù fi hàn pé ìgbéyàwó àti wíwà lápọ̀n-ọ́n jẹ́ ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. “Ì bá wù mí kí gbogbo ènìyàn rí bí èmi fúnra mi ti rí. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, olúkúlùkù ní ẹ̀bùn tirẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ọ̀kan ní ọ̀nà yìí, òmíràn ní ọ̀nà yẹn.” (Kọ́ríńtì Kìíní 7:7) Kò sí iyè méjì pé ó ní ohun tí Jésù sọ lọ́kàn. Lẹ́yìn fífìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìgbéyàwó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, Jésù fi hàn pé fífínnúfíndọ̀ wà lápọ̀n-ọ́n nítorí ṣíṣiṣẹ́ sin ire Ìjọba jẹ́ ẹ̀bùn kan pàtó pé: “Kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni ń wá àyè fún àsọjáde náà, bí kò ṣe kìkì àwọn wọnnì tí wọ́n ní ẹ̀bùn náà. Nítorí àwọn ìwẹ̀fà wà tí a bí bẹ́ẹ̀ láti inú ilé ọlẹ̀ ìyá wọn, àwọn ìwẹ̀fà sì wà tí àwọn ènìyàn sọ di ìwẹ̀fà, àwọn ìwẹ̀fà sì wà tí wọ́n ti sọ ara wọn di ìwẹ̀fà ní tìtorí ìjọba àwọn ọ̀run. Kí ẹni tí ó bá lè wá àyè fún un wá àyè fún un.”—Mátíù 19:4-6, 11, 12.
Wíwá Àyè fún Ẹ̀bùn Wíwà Lápọ̀n-ọ́n
10. Báwo ni ẹnì kan ṣe lè “wá àyè” fún ẹ̀bùn wíwà lápọ̀n-ọ́n?
10 Bí Jésù àti Pọ́ọ̀lù tilẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa wíwà lápọ̀n-ọ́n pé ó jẹ́ “ẹ̀bùn,” kò sí ẹnikẹ́ni nínú wọn tí ó sọ pé ó jẹ́ ẹ̀bùn iṣẹ́ ìyanu tí kìkì àwọn díẹ̀ ní. Jésù wí pé “kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni ǹ wà àyè” fún ẹ̀bùn yẹn, ó sì gba àwọn tí ó bà lè ṣe bẹ́ẹ̀ níyànjú láti “wá àyè fún un,” èyí sì ni ohun tí Jésù àti Pọ́ọ̀lù ṣe. Lóòótọ́, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ó sàn láti gbéyàwó ju kí ìfẹ́ onígbòónára máa mú ara ẹni gbiná,” ṣùgbọ́n ó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí “kò bá ní ìkóra-ẹni-níjàánu.” (Kọ́ríńtì Kìíní 7:9) Nínú àwọn lẹ́tà rẹ̀ tí ó ti kọ ṣáájú, Pọ́ọ̀lù fi hàn pé àwọn Kristẹni lè yẹra fún mímú kí ìfẹ́ onígbòónára má mú ara wọn gbiná. (Gálátíà 5:16, 22-24) Láti rìn nípa tẹ̀mí túmọ̀ sí láti jẹ́ kí ẹ̀mí Jèhófà darí ìṣísẹ̀ wa kọ̀ọ̀kan. Àwọn Kristẹni ọ̀dọ́ ha lè ṣe èyí bí? Bẹ́ẹ̀ ni, bí wọ́n bá tẹ̀ lé Ọ̀rọ̀ Jèhófà tímọ́tímọ́. Onísáàmù náà kọ̀wé pé: “Nípa èwo ni ọ̀dọ́mọkùnrin [tàbí ọ̀dọ́mọbìnrin] yóò fi mú ọ̀nà rẹ̀ mọ́? Nípa ìkíyèsí gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ.”—Orin Dáfídì 119:9.
11. Kí ni ó túmọ̀ sí láti ‘rìn ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí’?
11 Èyí kan ṣíṣọ́ra fún àwọn èrò onígbọ̀jẹ̀gẹ́ tí àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹlifíṣọ̀n, sinimá, ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn, àwọn ìwé, àti ọ̀rọ̀ orin ń tàn kálẹ̀. Irú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ jẹ́ ti ẹran ara. Kristẹni ọ̀dọ́ kan, yálà ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó bá fẹ́ wá àyè fún wíwà lápọ̀n-ọ́n ní láti “rìn, kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara, bí kò ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí. Nítorí àwọn wọnnì tí wọ́n wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹran ara gbé èrò inú wọn ka orí àwọn ohun ti ẹran ara, ṣùgbọ́n àwọn wọnnì tí wọ́n wà ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀mí gbé e [èrò inú wọn] ka orí àwọn ohun ti ẹ̀mí.” (Róòmù 8:4, 5) Àwọn ohun ti ẹ̀mí jẹ́ òdodo, wọ́n jẹ́ mímọ́ níwà, wọ́n dára ní fífẹ́, wọ́n jẹ́ ìwà funfun. Yóò dáa kí àwọn Kristẹni, lọ́mọdé lágbà, “máa bá a lọ ní gbígba nǹkan wọ̀nyí rò.”—Fílípì 4:8, 9.
12. Kí ni wíwà àyè fún ẹ̀bùn wíwà lápọ̀n-ọ́n wé mọ́ ní pàtàkì?
12 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, wíwá àyè fún ẹ̀bùn wíwà lápọ̀n-ọ́n jẹ́ ọ̀ràn fífi ọkàn ẹni sí góńgó yẹn àti gbígbàdúrà sí Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́ nínú lílépa rẹ̀. (Fílípì 4:6, 7) Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá ti pinnu tán nínú ọkàn-àyà rẹ̀, tí kò ní àìgbọdọ̀máṣe kankan, ṣùgbọ́n tí ó ní ọlá àṣẹ lórí ìfẹ́ inú ara rẹ̀ tí ó sì ti ṣe ìpinnu yìí nínú ọkàn-àyà ara rẹ̀, láti pa ipò wúńdíá tirẹ̀ mọ́, òun yóò ṣe dáadáa. Nítorí náà ẹni náà pẹ̀lú tí ó fi ipò wúńdíá rẹ̀ fúnni nínú ìgbéyàwó ṣe dáadáa, ṣùgbọ́n ẹni náà tí kò fi í fúnni nínú ìgbéyàwó yóò ṣe dáadáa jù.”—Kọ́ríńtì Kìíní 7:37, 38.
Wíwà Lápọ̀n-ọ́n Pẹ̀lú Ète Kan
13, 14. (a) Ìfiwéra wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe láàárín àwọn Kristẹni tí ó ti gbéyàwó àti àwọn tí kò gbéyàwó? (b) Ọ̀nà kan ṣoṣo wo ni Kristẹni àpọ́n fi lè “ṣe dáadáa” ju àwọn tí wọ́n ti gbéyàwó lọ?
13 Wíwà lápọ̀n-ọ́n fúnra rẹ̀ kì í ṣe ohun tí a ń gbé gẹ̀gẹ̀. Nígbà náà, lọ́nà wo ni ó fi lè “ṣe dáadáa jù”? Gbogbo rẹ̀ sinmi lórí bí ẹnì kan bá ṣe lo òmìnira tí ó ń mú wá. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ní tòótọ́, mo fẹ́ kí ẹ wà láìní àníyàn. Ọkùnrin tí kò gbéyàwó ń ṣàníyàn fún àwọn ohun ti Olúwa, bí òún ṣe lè jèrè ojú rere ìtẹ́wọ́gbà Olúwa. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ó gbéyàwó ń ṣàníyàn fún àwọn ohun ti ayé, bí òún ṣe lè jèrè ojú rere ìtẹ́wọ́gbà aya rẹ̀, ó sì pínyà lọ́kàn. Síwájú sí i, obìnrin tí kò lọ́kọ, àti wúńdíá, ń ṣàníyàn fún àwọn ohun ti Olúwa, pé kí òun lè jẹ́ mímọ́ nínú ara rẹ̀ àti nínú ẹ̀mí rẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, obìnrin tí a ti gbé níyàwó ń ṣàníyàn fún àwọn ohun ti ayé, bí òún ṣe lè jèrè ojú rere ìtẹ́wọ́gbà ọkọ rẹ̀. Ṣùgbọ́n èyí ni èmi ń wí fún ire àǹfààní ara yín, kì í ṣe kí n lè dẹ ojóbó mú yín, ṣùgbọ́n láti sún yín sí ohun tí ó yẹ àti èyí tí ó túmọ̀ sí ṣíṣiṣẹ́sìn Olúwa nígbà gbogbo láìsí ìpínyà ọkàn.”—Kọ́ríńtì Kìíní 7:32-35.
14 Kristẹni àpọ́n kan tí ń lo ipò àìgbéyàwó rẹ̀ láti lépa góńgó onímọtara-ẹni-nìkan kò ṣe “dáadáa” ju àwọn Kristẹni tí ó gbéyàwó lọ. Ó wà lápọ̀n-ọ́n, kì í ṣe ‘ní tìtorí ìjọba náà,’ ṣùgbọ́n nítorí ohun ti ara rẹ̀. (Mátíù 19:12) Ọkùnrin tí kò gbéyàwó tàbí obìnrin tí kò lọ́kọ ní láti “ṣàníyàn fún àwọn ohun ti Olúwa,” ó ní láti ṣàníyàn láti “jèrè ojú rere ìtẹ́wọ́gbà Olúwa,” kí ó sì máa ‘ṣiṣẹ́ sin Olúwa nígbà gbogbo láìsí ìpínyà ọkàn.’ Èyí túmọ̀ sí yíya àfiyèsí tí a kò pín níyà sọ́tọ̀ pátápátá fún ṣíṣiṣẹ́ sin Jèhófà àti Kristi Jésù. Kìkì nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ nìkan ni àwọn Kristẹni lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tí wọn kò ní alábàáṣègbéyàwó fi lè ṣe “dáadáa” ju àwọn Kristẹni tí wọ́n ti gbéyàwó lọ.
Ìgbòkègbodò Àpọkànpọ̀ṣe
15. Kí ni lájorí ìjiyàn Pọ́ọ̀lù nínú Kọ́ríńtì Kìíní orí 7?
15 Lájorí ìjiyàn Pọ́ọ̀lù nínú orí yìí nìyí: Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbéyàwó tọ́, tí ó sì yẹ fún àwọn kan, lábẹ́ àwọn àyíká ipò kan, lọ́nà tí kò ṣeé já ní koro, wíwà lápọ̀n-ọ́n ṣàǹfààní fún Kristẹni ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó bá fẹ́ ṣiṣẹ́ sin Jèhófà pẹ̀lú ìpínyà ọkàn tí ó mọ níwọ̀nba. Nígbà tí ó jẹ́ pé ẹni tí ó gbéyàwó “pínyà lọ́kàn,” Kristẹni tí kò gbéyàwó lómìnira láti pọkàn pọ̀ sórí “àwọn ohun ti Olúwa.”
16, 17. Báwo ni Kristẹni àpọ́n kan ṣe lè pọkàn pọ̀ dáadáa sórí “àwọn ohun ti Olúwa”?
16 Kí ni àwọn ohun ti Olúwa tí Kristẹni tí kò gbéyàwó lè fún ní àfiyèsí fàlàlà ju ti àwọn tí wọ́n gbéyàwó lọ? Nínú àyíká ọ̀rọ̀ míràn, Jésù sọ̀rọ̀ nípa “àwọn ohun ti Ọlọ́run”—àwọn ohun tí Kristẹni kan kò lè fún Késárì. (Mátíù 22:21) Ní pàtàkì, àwọn ohun wọ̀nyí kan ìgbésí ayé, ìjọsìn, àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni.—Mátíù 4:10; Róòmù 14:8; Kọ́ríńtì Kejì 2:17; 3:5, 6; 4:1.
17 Àwọn àpọ́n ní gbogbogbòò máa ń lómìnira láti ya àkókò sọ́tọ̀ pátápátá fún iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, èyí tí ó lè ṣàǹfààní fún ipò tẹ̀mí wọn àti bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn ṣe lọ jìnnà tó. Wọ́n lè lo àkókò púpọ̀ sí i lórí ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti àṣàrò. Ó lè rọrùn fún àwọn Kristẹni àpọ́n láti wá àyè fún Bíbélì kíkà wọn nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ wọn ju bí àwọn tí ó ti gbéyàwó ṣe lè ṣe lọ. Ó lè rọrùn fún wọn láti múra sílẹ̀ dáradára fún àwọn ìpàdé àti iṣẹ́ ìsìn pápá. Gbogbo èyí jẹ́ fún “ire àǹfààní ara” wọn.—Kọ́ríńtì Kìíní 7:35.
18. Báwo ni ọ̀pọ̀ àpọ́n arákùnrin ṣe lè fi hàn pé àwọn fẹ́ ṣiṣẹ́ sin Jèhófà “láìsí ìpínyà ọkàn”?
18 Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin tí wọ́n jẹ́ àpọ́n, tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ sìn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ lómìnira láti sọ fún Jèhófà pé: “Èmi nìyí! Rán mi.” (Aísáyà 6:8, NW) Wọ́n lè kọ̀wé béèrè fún lílọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́, èyí tí ó wà fún kìkì àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti alàgbà tí wọ́n jẹ́ àpọ́n, tí wọ́n lómìnira láti ṣiṣẹ́ sìn níbi tí àìní gbé pọ̀. Àwọn arákùnrin tí kò lómìnira láti fi ìjọ wọn sílẹ̀ pàápàá lè mú ara wọn wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti ṣiṣẹ́ sin àwọn ará wọn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà.—Fílípì 2:20-23.
19. Báwo ni a ṣe bù kún ọ̀pọ̀ arábìnrin tí wọ́n jẹ́ àpọ́n, ọ̀nà kan ṣoṣo wo sì ni wọ́n lè gbà jẹ́ ìbùkún fún ìjọ?
19 Ó lè bá a mu wẹ́kú fún àwọn arábìnrin tí wọ́n jẹ́ àpọ́n, tí wọn kò ní ẹ̀dá ènìyàn tí ó jẹ́ orí fún wọn, tí wọn yóò bá fikún lukùn, tí wọn yóò sì finú tán, láti ‘kó ẹrù wọn lọ sára Olúwa.’ (Orin Dáfídì 55:22; Kọ́ríńtì Kìíní 11:3) Èyí ṣe pàtàkì gan-an fún àwọn arábìnrin tí wọ́n wá lápọ̀n-ọ́n nítorí ìfẹ́ wọn fún Jèhófà. Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n lọ́kọ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, yóò jẹ́ “kìkì nínú Olúwa,” ìyẹn ni pé, kìkì pẹ̀lú ẹnì kan tí ó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà. (Kọ́ríńtì Kìíní 7:39) Inú àwọn alàgbà dùn láti ní àwọn arábìnrin tí kò lọ́kọ nínú ìjọ wọn; àwọn wọ̀nyí máa ń fìgbà gbogbo bẹ àwọn tí ń ṣàìsàn àti àwọn àgbàlagbà wò, wọ́n sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́. Èyí ń mú ayọ̀ wá fún àwọn tí ọ̀ràn kàn.—Ìṣe 20:35.
20. Báwo ni ọ̀pọ̀ Kristẹni ṣe ń fi hàn pé àwọn ń “ṣiṣẹ́ sin Olúwa nígbà gbogbo láìsí ìpínyà ọkàn”?
20 Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni ọ̀dọ́ ti ṣètò àlámọ̀rí wọn kí wọ́n baà lè “ṣiṣẹ́ sin Olúwa nígbà gbogbo láìsí ìpínyà ọkàn.” (Kọ́ríńtì Kìíní 7:35) Wọ́n ń ṣiṣẹ́ sin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà alákòókò kíkún, míṣọ́nnárì, tàbí kí wọn máa ṣiṣẹ́ sìn ní ọ̀kan nínú ọ́fíìsì ẹ̀ka Watch Tower Society. Ẹ sì wo irú àwùjọ aláyọ̀ tí wọ́n jẹ́! Ẹ wo bí ara ṣe máa ń tù wá tó nígbà tí wọ́n bá wà láàárín wa! Họ́wù, ní ojú Jèhófà àti Jésù, wọn “dà bí ìsẹ̀ ìrì.”—Orin Dáfídì 110:3, NW.
Kò Sí Ẹ̀jẹ́ Wíwà Láìgbéyàwó Títí Lọ Gbére
21. (a) Èé ṣe tí ó fi ṣe kedere pé Pọ́ọ̀lù kò fún jíjẹ́jẹ̀ẹ́ wíwà láìgbéyàwó níṣìírí? (b) Kí ni ó ní lọ́kàn nígbà tí ó sọ̀rọ̀ nípa ‘ríré kọjá ìgbà ìtànná òdòdó èwe’?
21 Kókó pàtàkì nínú ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù ni pé àwọn Kristẹni yóò ṣe “dáadáa” láti wá àyè nínú ìgbésí ayé wọn fún wíwà lápọ̀n-ọ́n. (Kọ́ríńtì Kìíní 7:1, 8, 26, 37) Ṣùgbọ́n, ó dájú pé òun kò ké sí wọn láti wá jẹ́jẹ̀ẹ́ wíwà láìgbéyàwó. Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, ó kọ̀wé pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òún ń hùwà lọ́nà àìbẹ́tọ̀ọ́mu sí ipò wúńdíá òun, bí onítọ̀hún bá ti ré kọjá ìgbà ìtànná òdòdó èwe, tí èyí sì jẹ́ ọ̀nà tí ó yẹ kí ó gbà ṣẹlẹ̀, kí ó ṣe ohun tí ó fẹ́; òun kò dẹ́ṣẹ̀. Kí wọ́n gbéyàwó.” (Kọ́ríńtì Kìíní 7:36) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà (hy·peʹra·kmos) tí a túmọ̀ sí “ré kọjá ìgbà ìtànná òdòdó èwe” ní òwuuru túmọ̀ sí “ré kọjá ìwọ̀n gíga jù lọ,” ó sì ń tọ́ka sí òtéńté ìrusókè ìfẹ́ ọkàn fún ìbálòpọ̀ takọtabo. Nítorí náà àwọn tí wọ́n ti lo ọdún mélòó kan ní ipò àpọ́n, tí wọ́n sì wá nímọ̀lára pé ó yẹ kí àwọn gbéyàwó, lómìnira pátápátá láti gbé onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn níyàwó.—Kọ́ríńtì Kejì 6:14.
22. Èé ṣe tí ó fi ṣàǹfààní ní gbogbo ọ̀nà fún Kristẹni kan láti má ṣe tètè gbéyàwó?
22 Àwọn ọdún tí Kristẹni ọ̀dọ́ kan ń lò nínú ṣíṣiṣẹ́ sin Jèhófà láìsí ìpinyà ọkàn jẹ́ okòwò tí ó lọ́gbọ́n nínú. Wọ́n yọ̀ọ̀da fún un láti ní ọgbọ́n tí ó ṣeé múlò, ìrírí, àti òye inú. (Òwe 1:3, 4) Ẹnì kan tí ó ti wà lápọ̀n-ọ́n nítorí Ìjọba náà wà ní ipò tí ó sàn jù lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn láti tẹ́rí gba ẹrù iṣẹ́ ìgbésí ayé lọ́kọláya àti bóyá ti jíjẹ́ òbí, bí ó bá pinnu láti ṣe bẹ́ẹ̀.
23. Kí ni ẹnì kan tí ó ń wéwèé láti gbéyàwó gbọ́dọ̀ ní lọ́kàn, ṣùgbọ́n ìbéèrè wo ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e?
23 Àwọn Kristẹni kan tí wọ́n ti lo ọdún mélòó kan nínú ṣíṣiṣẹ́ sin Jèhófà fún àkókò kíkún ní ipò àpọ́n ń fi tìṣọ́ratìṣọ́ra yan alábàáṣègbéyàwó wọn ọjọ́ ọ̀la pẹ̀lú èrò bíbá a nìṣó nínú irú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún kan. Èyí yẹ fún ìgbóríyìn fún gidigidi. Àwọn kan tilẹ̀ lè ronú nípa gbígbéyàwó pẹ̀lú èrò ṣíṣàì yọ̀ọ̀da fún ìgbéyàwó wọn láti ké iṣẹ́ ìsìn wọn nígbèrí lọ́nà kọnà. Ṣùgbọ́n Kristẹni kan tí ó ti ṣègbéyàwó ha ní láti rò pé òún ṣì lómìnira láti pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ ìsìn Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí ó ṣì wà lápọ̀n-ọ́n bí? Ìbéèrè yìí ni a óò gbé yẹ̀ wò nínú àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e.
Fún Àtúnyẹ̀wò
◻ Èé ṣe tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi rí i pé ó pọn dandan láti kọ lẹ́tà sí ìjọ tí ó wà ní Kọ́ríńtì?
◻ Èé ṣe tí a fi mọ̀ pé Pọ́ọ̀lù kò dámọ̀ràn ìgbésí ayé ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé?
◻ Báwo ni ẹnì kan ṣe lè “wá àyè” fún wíwà lápọ̀n-ọ́n?
◻ Báwo ni àwọn arábìnrin tí wọ́n jẹ́ àpọ́n ṣe ń jèrè láti inú ipò wíwà lápọ̀n-ọ́n wọn?
◻ Ní àwọn ọ̀nà wo ni àwọn arákùnrin tí wọ́n jẹ́ àpọ́n fi lè lo àǹfààní tí wọ́n ní láti ṣiṣẹ́ sìn Jèhófà “láìsí ìpínyà ọkàn”?