Ayé Ń Móoru O!—Ǹjẹ́ Àtúnṣe Kankan Wà?
Ẹ̀RÍ fi hàn pé ńṣe ni ayé túbọ̀ ń gbóná sí i. Àpẹẹrẹ kan ni ti ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lábúlé tí wọ́n ń pè ní Newtok lórílẹ̀-èdè Alaska tó wà ní gúúsù ìpẹ̀kun àríwá ayé. Orí ilẹ̀ tí yìnyín mú kí gbogbo ìsàlẹ̀ rẹ̀ dì gbagidi ni wọ́n tẹ abúlé náà dó sí. Àmọ́ ní báyìí, yìnyín abẹ́ ilẹ̀ abúlé náà ti ń yọ́. Ọ̀gbẹ́ni Frank tó ń gbé lábúlé náà fi ẹ̀dùn ọkàn sọ pé: “Èmi ò fẹ́ gbé lórí ilẹ̀ oníyìnyín yìí [mọ́] o jàre. Ẹrẹ̀ ibẹ̀ ti wá pọ̀ jù.” Àwọn aṣèwádìí sọ pé àfàìmọ̀ lomi ò ní gba abúlé etíkun náà láàárín ọdún mẹ́wàá sígbà tá a wà yìí.
Ìgbìmọ̀ kan tó ń ṣèwádìí nípa àyípadà ojú ọjọ́ lágbàáyé, ìyẹn Intergovernmental Panel on Climate Change (IPCC) sọ pé: “Kò sí àní-àní pé ojú ọjọ́ ń gbóná sí i.” Èyí hàn kedere látinú bí ayé ṣe túbọ̀ ń móoru. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ pe èyí ní àyípadà ojú ọjọ́. Wọ́n lóun ló ń fa ipò ojú ọjọ́ tí kò bára dé káàkiri ayé, irú bí ọ̀dá, òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá, ìgbì ooru gbígbóná àti ìjì líle. Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sílé ayé wa yìí? Ǹjẹ́ àtúnṣe kankan tiẹ̀ wà?
Ìwádìí Nípa Ohun Tó Fa Ìṣòro Náà
Bí ìgbà tí dókítà ń yẹ aláìsàn tó ń gbàtọ́jú wò làwọn onímọ̀ nípa ojú ọjọ́ ṣe ń ṣàkíyèsí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ayé. Wọ́n ń fi ẹ̀rọ sátẹ́láìtì tó wà lójú òfuurufú wo bí àwọn òkìtì yìnyín inú ayé ṣe ń yọ́, àwọn awojú ọjọ́ ń díwọ̀n òjò tó ń rọ̀, àwọn ẹ̀rọ ojú agbami òkun ń díwọ̀n ìgbóná òun ìtutù ibú omi òkun, àwọn ọkọ̀ òfuurufú sì ń díwọ̀n onírúurú afẹ́fẹ́ tó wà nínú ayé. Wọ́n á wá kó gbogbo ìsọfúnni tí wọ́n rí sínú àwọn ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà ńlá. Lẹ́yìn náà, wọ́n á fi ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà gbé àpẹẹrẹ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ sí ojú ọjọ́ lọ́jọ́ iwájú jáde, àní títí kan èyí tó lè ṣẹlẹ̀ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sígbà tá a wà yìí pàápàá.
Kí ni àbábọ̀ ìwádìí wọn? Àwọn kan lára wọn gbà gbọ́ pé àwọn afẹ́fẹ́ tó ń mú ayé gbóná ti wá pọ̀ jù báyìí. Ìwé ìròyìn Time sọ pé “iye tọ́ọ̀nù” afẹ́fẹ́ carbon dioxide táráyé tú sí atẹ́gùn lọ́dún 2006 nìkan “fẹ́rẹ̀ẹ́ tó bílíọ̀nù méjìlélọ́gbọ̀n.” Bẹ́ẹ̀ sì rèé, bí gíláàsì táwọn kan fi ń kọ́ àkànṣe ilé tí wọ́n ń gbin ewébẹ̀ sí ṣe ń jẹ́ kínú ilé náà máa móoru ni àpọ̀jù àwọn afẹ́fẹ́ bíi carbon dioxide náà ṣe ń dá kún ooru inú ayé. Ìdí ni pé irú àwọn afẹ́fẹ́ bẹ́ẹ̀ kì í jẹ́ kí ooru inú ayé lè máa jáde kúrò nínú òfuurufú ayé. Ibo lọ̀rọ̀ náà máa wá já sí? Ohun tí ìgbìmọ̀ tó ń ṣèwádìí nípa àyípadà ojú ọjọ́ lágbàáyé sọ ni pé, bí aráyé ò bá dín ìwọ̀n irú afẹ́fẹ́ wọ̀nyí tí wọ́n ń tú jáde kù, ó lè kó “onírúurú àyípadà bá ojú ọjọ́,” èyí tó jọ pé ó máa ṣàkóbá tó burú ju tàtẹ̀yìnwá lọ fún ayé yìí. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé ojútùú sí ọ̀rọ̀ yìí ni pé káráyé dín ìwọ̀n afẹ́fẹ́ carbon dioxide tí wọ́n ń tú sínú afẹ́fẹ́ kù. Àmọ́ ká tiẹ̀ sọ pé àwọn èèyàn dín ìwọ̀n afẹ́fẹ́ tó ń mú kí ayé gbóná tí wọ́n ń tú jáde kù, ohun tí ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà fi hàn ni pé àfàìmọ̀ ni “àpọ̀jù ooru inú ayé àti [bó ṣe ń mú kí] omi òkun kún àkúnya kò ní máa bá a nìṣó fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún.”
Ibi Tá A Ti Máa Rí Ìdáhùn
Wíwo ojú ọjọ́ láti fi sọ bójú ọjọ́ ṣe máa rí lọ́jọ́ iwájú kì í ṣe iṣẹ́ tó rọrùn fáwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì. Ìwé kan tí wọ́n kọ sórí ẹ̀rọ Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn ìwé tí wọ́n pè ní Earth Observatory, béèrè pé: “Bí àpẹẹrẹ, kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sáwọn ìkùukùu òjò bí inú ayé ṣe ń móoru sí i? Ṣé ipele ìkùukùu tó kángun sókè pátápátá lójú sánmà, èyí tó ń gba ooru ayé mọ́ra táyé fi ń móoru, yóò wá máa pọ̀ ju àwọn ìkùukùu òjò tó ń ṣíji bo ayé lọ́wọ́ ìtànṣán oòrùn ni?” Ìwé náà wá dáhùn pé: “Lọ́wọ́ tá a wà yìí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kò lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yẹn o.”
Ṣùgbọ́n, Bíbélì fi dá wa lójú pé Jèhófà Ọlọ́run ni “Ẹni tí Ó Ṣe ọ̀run àti ilẹ̀ ayé,” títí kan “àwọn ìwọ́jọpọ̀ àwọsánmà ti òkè.” (Jẹ́nẹ́sísì 14:19; Òwe 8:28) Jèhófà ṣàkàwé ara rẹ̀ lọ́nà ewì pé òun lòun fi “ọgbọ́n sínú àwọn ipele àwọsánmà.” Láìsí àní-àní, Jèhófà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye ohun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ò mọ̀ yìí.—Jóòbù 38:36.
Ní ti ojú ọjọ́ ayé wa yìí, wo ohun tí Ọlọ́run sọ, èyí tó ti wà nínú Bíbélì láti nǹkan bí ẹgbẹ̀rìnlá ó dín ọgọ́rùn-ún [2,700] ọdún sẹ́yìn, ó ní: ‘Ọ̀yamùúmùú òjò ń rọ̀ láti ọ̀run, kì í sì í padà sí ibẹ̀, bí kò ṣe pé kí ó rin ilẹ̀ ayé gbingbin.’ (Aísáyà 55:10) Ẹ ò rí bí ẹsẹ Bíbélì yẹn ṣe sọ ọ̀rọ̀ ìyípoyípo omi wẹ́rẹ́, lọ́nà tó ṣe kedere! Bó ṣe ń ṣẹlẹ̀ rèé: Kùrukùru omi yóò gòkè lọ sójú sánmà, yóò wá di òjò. Òjò náà yóò wá rọ̀, yóò sì “rin ilẹ̀ ayé gbingbin.” Ìmọ́lẹ̀ oòrùn tó gbóná á tún sọ omi òjò tó rọ̀ náà di kùrukùru omi, èyí tó máa “padà sí ibẹ̀,” ìyẹn ojú sánmà, yóò sì tún di òjò tó máa rọ̀. Bí ìyípoyípo yẹn ṣe ń bá a lọ nìyẹn. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú ni Bíbélì Ọ̀rọ̀ Jèhófà ti sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ tó yani lẹ́nu nípa ojú ọjọ́ ayé kí ìwé èyíkéyìí tó sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ǹjẹ́ ìyẹn ò mú ọ fọkàn tán Ẹlẹ́dàá àtohun tó lè ṣe? Nítorí náà, tó bá kan ọ̀rọ̀ ibi tí ìṣòro ojú ọjọ́ ayé yìí máa já sí, ǹjẹ́ kò ní bọ́gbọ́n mu ká yíjú sí “Ẹlẹ́dàá ẹ̀fúùfù” àti ‘baba òjò,’ ẹni tó mọ bí gbogbo nǹkan inú ayé yìí ṣe ń ṣiṣẹ́?—Ámósì 4:13; Jóòbù 38:28.
Ó Nídìí Tí Ọlọ́run Fi Dá Ayé
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé èrò àwọn èèyàn yàtọ̀ síra nípa ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí ayé wa, ohun kan dájú, ìyẹn ni pé: Kò síbi tó dà bí ayé wa yìí. Ohun tó mú kí ayé yàtọ̀ sáwọn pílánẹ́ẹ̀tì yòókù nínú sánmà ni pé onírúurú ẹ̀dá alàáyè ló kúnnú rẹ̀. Kí ló jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe? Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ ìdí mélòó kan tó fi rí bẹ́ẹ̀. Ní pàtàkì, omi pọ̀ jábujàbu nínú ayé; ayé kò sún mọ́ oòrùn jù kò sì jìnnà sí i jù; ó sì tún ní ìwọ̀n onírúurú afẹ́fẹ́ tó yẹ gẹ́lẹ́, títí kan ìwọ̀n afẹ́fẹ́ ọ́síjìn tó pọ̀ gan-an.
Ó lè yà ọ́ lẹ́nu láti gbọ́ pé nínú Bíbélì, ìwé Jẹ́nẹ́sísì mẹ́nu kan irú nǹkan wọ̀nyẹn nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn nǹkan. Bí àpẹẹrẹ, Jẹ́nẹ́sísì 1:10 sọ̀rọ̀ nípa wíwà tí omi wà jábujàbu ní ayé, ó ní Ọlọ́run mú kí omi wọ́ jọ pọ̀, àti pé “ìwọ́jọpọ̀ omi [náà] ni ó pè ní Òkun.” A rí i kà nínú Jẹ́nẹ́sísì 1:3 pé: “Ọlọ́run sì tẹ̀ síwájú láti wí pé: ‘Kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà.’” Ibi tí ayé wà sún mọ́ oòrùn ní ìwọ̀n tí ìgbóná oòrun kò fi ní jẹ́ kí gbogbo omi ayé di yìnyín. Síbẹ̀ ayé kò sún mọ́ oòrùn jù kí ìgbóná rẹ̀ má bàa lá omi ayé gbẹ láú.
Ìwé Jẹ́nẹ́sísì 1:6 sọ pé Ọlọ́run ṣe “òfuurufú” sókè ayé. Ẹsẹ kọkànlá àti ìkejìlá wá sọ pé Ọlọ́run mú kí àwọn koríko, ewéko àti igi, tó jẹ́ pé ó ń mú afẹ́fẹ́ ọ́síjìn wá, hù jáde. Gbogbo èyí fi hàn pé afẹ́fẹ́ ọ́síjìn wà, èyí táwọn èèyàn àtẹranko á máa mí sínú kí wọ́n lè wà láàyè.
Kí ni gbogbo nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ká mọ̀? Òun ni pé, níwọ̀n bí Ọlọ́run ti dá ayé tòun ti alagbalúgbú omi, tó fi ayé síbi tó wà níwọ̀n tó tọ́ sí oòrùn, tó sì tún pèsè onírúurú afẹ́fẹ́ síbẹ̀ níwọ̀n tó yẹ, ìdí pàtàkì ní láti wà tó fi dá ayé. Bíbélì sọ fún wa pé: “[Ọlọ́run] kò wulẹ̀ dá [ayé] lásán, ó ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀.” (Aísáyà 45:18) Ìwé Sáàmù 115:16 sọ pé: “Ní ti ọ̀run, ti Jèhófà ni ọ̀run, ṣùgbọ́n ilẹ̀ ayé ni ó fi fún àwọn ọmọ ènìyàn.” Ńṣe ni Ọlọ́run dá ayé fún ọmọ èèyàn láti máa gbé.
Ìwé Mímọ́ sọ pé Ọlọ́run dá tọkọtaya àkọ́kọ́, ó fi wọ́n sínú ọgbà Édẹ́nì, tó jẹ́ Párádísè ẹlẹ́wà. Ṣe ló ń fẹ́ kí wọ́n “máa ro ó kí wọ́n sì máa bójú tó o.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:15) Ọlọ́run sọ fún wọn pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ìwọ wo irú àǹfààní ńláǹlà tí wọ́n ní! Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n rí sí i pé gbogbo ayé di Párádísè, kí wọ́n sì máa gbénú rẹ̀ títí láé. Ìgbádùn ayérayé nìyẹn ì bá mà jẹ́ o!
Àmọ́, ó dunni pé, dípò kí tọkọtaya yìí ṣègbọràn sí Ọlọ́run, ṣe ni wọ́n ṣe tinú ara wọn, láìfi ara wọn sábẹ́ Ọlọ́run. Irú ẹ̀mí yẹn laráyé sì ní títí dòní. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Kí ló wá yọrí sí? Dípò káwọn èèyàn máa tún ilẹ̀ ayé ṣe kí wọ́n sì máa bójú tó o, ṣe ni wọ́n “ń run ilẹ̀ ayé” lọ́nà tó burú jáì. (Ìṣípayá 11:18) Àmọ́ ṣá o, ohun kan tó ń tù wá nínú ni pé Ọlọ́run kò yí ìpinnu rẹ̀ nípa ayé padà. Bíbélì fi dá wa lójú pé: “[Ọlọ́run ti] fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀ sórí àwọn ibi àfìdímúlẹ̀ rẹ̀; a kì yóò mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n fún àkókò tí ó lọ kánrin, tàbí títí láé.” (Sáàmù 104:5) Jésù fúnra rẹ̀ ṣèlérí kan nígbà tó ń ṣe Ìwàásù Lórí Òkè, ó ní: “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 5:5) Báwo wá ni ìpinnu Ọlọ́run nípa ilẹ̀ ayé ṣe máa ṣẹ?
Ọ̀la Ń Bọ̀ Wá Dára
Ẹnì kan tó ti jẹ́ ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà rí sọ pé: “Ìṣòro tó kárí ayé lọ̀rọ̀ àyípadà ojú ọjọ́ yìí.” Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ ìwọ náà ò ní gbà pé bá a ṣe máa yanjú ìṣòro yẹn kárí ayé ló yẹ ká wá? Jésù Kristi ti sọ̀rọ̀ nípa ohun tó máa yanjú ìṣòro náà. Ohun náà ni Ìjọba Ọlọ́run. Ó ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa gbàdúrà pé: “Kí ìjọba rẹ dé.” (Mátíù 6:9, 10) Ohun tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ ni pé Ìjọba Ọlọ́run yìí jẹ́ ìjọba kan tó máa kárí ayé, àti pé láìpẹ́ yóò “fọ́ ìjọba wọ̀nyí [ìyẹn àwọn ìjọba tó ń ṣàkóso lóde òní] túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn.” (Dáníẹ́lì 2:44) Ìyẹn nìkan kọ́ o, yóò tún “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 11:18) Dájúdájú, àwọn tó ń lo ayé àti ohun àmúṣọrọ̀ inú rẹ̀ ní ìlò àpà yóò gba ìdájọ́ Ọlọ́run, wọn yóò sì pa run.
Ṣùgbọ́n kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ sí ayé wa táwọn èèyàn ti lò bà jẹ́? Ẹ jẹ́ ká rántí pé nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó ṣe iṣẹ́ ìyanu tó fi hàn pé ó lágbára lórí àwọn nǹkan bí ìjì àti òkun. Gbólóhùn méjì péré ló kàn sọ sí ìjì ńlá kan, tí ìjì náà sì rọlẹ̀ wọ̀ọ̀. (Máàkù 4:35-41) Nísinsìnyí tí Jésù ti wá di “Olúwa àwọn olúwa àti Ọba àwọn ọba” tó ń ṣàkóso látọ̀runwá, wẹ́rẹ́ báyìí ni yóò bójú tó ìṣòro ilẹ̀ ayé pátá, títí kan ìjì, ooru gbígbóná àtàwọn nǹkan yòókù. (Ìṣípayá 17:14) Kódà ìgbà “àtúndá” ni Jésù pàápàá pe àkókò ìṣàkóso rẹ̀. (Mátíù 19:28) Jésù yóò tún ipò àwọn nǹkan inú ayé dá, ìyẹn ni pé yóò sọ wọ́n dọ̀tun, tí wọ́n á fi dà bíi tinú ọgbà Édẹ́nì ìpilẹ̀ṣẹ̀. Ayé yóò sì padà di Párádísè. (Lúùkù 23:43) Gbogbo ohun tó fà á tí ayé fi ń móoru ni Ìjọba Ọlọ́run yóò tún ṣe pátá.
Ní lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí pàápàá, o lè jàǹfààní Ìjọba Ọlọ́run. Lọ́nà wo? Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Iṣẹ́ ìwàásù yìí ti mú kí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn kọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́. Ìgbésí ayé ọ̀pọ̀ nínú wọn ti yí padà sí rere. Àwọn tó ti sọ ìwàkiwà di bárakú ti kọ àwọn ìwà náà sílẹ̀. Àlàáfíà túbọ̀ ń gbilẹ̀ nínú ìdílé àwọn míì. Ẹ̀mí ìfẹ́ ń rọ́pò kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà. Àní sẹ́, ohun tí ìjọba èèyàn kò lè ṣe láéláé ni Ìjọba Ọlọ́run ti ń gbé ṣe báyìí. Ó ti sọ àwọn èèyàn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà méje látinú orílẹ̀-èdè tó ju igba ó lé márùndínlógójì [235] lọ dọ̀kan, tí wọ́n fi ń mú ara wọn bíi tẹ̀gbọ́n-tàbúrò láìfi ibi tẹ́nì kan ti wá pè! Ó dájú pé, bí wọ́n ṣe jẹ́ ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run, ńṣe ni Ọlọ́run ń múra wọn sílẹ̀ de ìgbésí ayé àìnípẹ̀kun nínú Párádísè tó máa kárí ilẹ̀ ayé yìí.
Dájúdájú, ayé yìí máa wà títí láé ni. Ǹjẹ́ kí ìwọ náà gbádùn ìwàláàyè títí láé nínú rẹ̀!
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú ni Bíbélì ti sọ bí omi ayé ṣe ń lọ yípo-yípo kí ìwé èyíkéyìí tó sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Jésù “bá ẹ̀fúùfù . . . wí lọ́nà mímúná, ó sì wí fún òkun náà pé: ‘Ṣe wọ̀ọ̀! Dákẹ́!’ Ẹ̀fúùfù náà sì rọlẹ̀, ìparọ́rọ́ ńláǹlà sì dé”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Tí ayé bá di Párádísè, gbogbo ohun tó fà á tí ayé fi ń móoru ni Ìjọba Ọlọ́run yóò tún ṣe
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]
Godo-Foto