Ohun Tá a Kọ́ Lọ́dọ̀ Jésù
Bí A Ṣe Lè Láyọ̀
Ohun tó ń fúnni láyọ̀?
▪ Jésù mẹ́nu kan ayọ̀ nínú ọ̀rọ̀ tó kọ́kọ́ sọ nínú ìwàásù rẹ̀ tí àwọn èèyàn mọ̀ dáadáa. Ó ní: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn.” (Mátíù 5:3) Kí ló ní lọ́kàn? Kí ni nǹkan tẹ̀mí tó ń jẹ wá lọ́kàn?
Tá a bá fẹ́ máa wà láàyè nìṣó, a nílò pé ká máa mí, ká máa mu omi, ká sì máa jẹun bíi tàwọn ẹranko. Àmọ́ tá a bá fẹ́ láyọ̀, ohun kan wà tá a nílò tí kò kan àwọn ẹranko, ìyẹn ni pé ká lóye ìdí tá a fi wà láàyè. Ẹlẹ́dàá wa nìkan ló sì lè jẹ́ ká lóye ìdí tá a fi wà láàyè. Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ pé: “Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.” (Mátíù 4:4) Àwọn tó fọwọ́ pàtàkì mú àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run máa ń láyọ̀ torí pé wọ́n sún mọ́ Jèhófà, “Ọlọ́run aláyọ̀,” ó sì fún wọn ní ìrètí tó jẹ́ ohun pàtàkì tó ń fúnni láyọ̀.—1 Tímótì 1:11.
Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ káwọn èèyàn nírètí?
▪ Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 5:5) Jésù jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé ìrètí ń bẹ nípa wíwo àwọn aláìsàn sàn àti jíjí àwọn òkú dìde kí wọ́n lè máa gbé lẹ́ẹ̀kan sí i. Ohun tó wàásù tún fún àwọn èèyàn nírètí. Ó ṣàlàyé pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Àwọn èèyàn tó bá ṣègbọràn sí Ọlọ́run yóò gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé. Fojú inú wò ó pé ò ń gbé láàárín àwọn èèyàn tó jẹ́ ọlọ́kàn tútù, tí kò sì sí pé wàá darúgbó! Abájọ tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi sọ pé: “Ẹ máa yọ̀ nínú ìrètí.” (Róòmù 12:12) Àmọ́ Jésù tún sọ bá a ṣe lè rí ayọ̀ nísinsìnyí.
Irú ìgbé ayé wo ni Jésù kọ́ni pé ó lè fúnni láyọ̀?
▪ Jésù fúnni ní ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́ lórí àwọn ọ̀ràn bí àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, ìgbéyàwó, ìrẹ̀lẹ̀ àti èrò tó yẹ kéèyàn ní nípa àwọn nǹkan ìní. (Mátíù 5:21-32; 6:1-5, 19-34) Téèyàn bá ń tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn Jésù, èèyàn máa láyọ̀.
Téèyàn bá jẹ́ ọ̀làwọ́, ó máa ń fúnni láyọ̀. (Ìṣe 20:35) Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ pé: “Nígbà tí ìwọ bá se àsè, ké sí àwọn òtòṣì, amúkùn-ún, arọ, afọ́jú; ìwọ yóò sì láyọ̀, nítorí tí wọn kò ní nǹkan kan láti fi san án padà fún ọ.” (Lúùkù 14:13, 14) Àwọn tó bá ń wá báwọn èèyàn ṣe máa láyọ̀ ló máa ń láyọ̀.
Kí ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tó máa jẹ́ kéèyàn láyọ̀?
▪ Ṣíṣe nǹkan fún àwọn èèyàn lè fúnni láyọ̀, àmọ́ ṣíṣe nǹkan fún Ọlọ́run ló ń fúnni láyọ̀ tó ga jù lọ. Kódà, ayọ̀ yìí pọ̀ ju ayọ̀ tí òbí kan tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ máa ń ní. A rí èyí nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ lákòókò kan nígbà tí Jésù ń kọ́ àwọn èèyàn ní gbangba. Bíbélì sọ pé: “Obìnrin kan láti inú ogunlọ́gọ̀ náà gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì wí fún un pé: ‘Aláyọ̀ ni ilé ọlẹ̀ tí ó gbé ọ àti ọmú tí ìwọ mu!’ Ṣùgbọ́n ó wí pé: ‘Ó tì o, kàkà bẹ́ẹ̀, Aláyọ̀ ni àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!’”—Lúùkù 11:27, 28.
Jésù fúnra rẹ̀ rí ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn nínú ṣíṣe ohun tí Baba rẹ̀ ọ̀run fẹ́. Nítorí pé, ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí gbogbo èèyàn gbọ́ nípa ìrètí tó wà pé ìyè àìnípẹ̀kun dájú lọ́jọ́ iwájú. Lákòókò kan, lẹ́yìn tí Jésù ti ṣàlàyé ìrètí yìí fún ẹnì kan tó fetí sílẹ̀, Jésù sọ pé: “Oúnjẹ mi ni kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi.” (Jòhánù 4:13, 14, 34) Ìwọ̀ náà lè láyọ̀ tó o bá ń ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ nípa sísọ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì fáwọn ẹlòmíì.
Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 1 nínú ìwé yìí, Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Èèyàn máa ní ayọ̀ tòótọ́ téèyàn bá lóye ìdí tá a fi wà láàyè