ORÍ 128
Pílátù àti Hẹ́rọ́dù Rí I Pé Jésù Ò Jẹ̀bi
MÁTÍÙ 27:12-14, 18, 19 MÁÀKÙ 15:2-5 LÚÙKÙ 23:4-16 JÒHÁNÙ 18:36-38
HẸ́RỌ́DÙ ÀTI PÍLÁTÙ GBỌ́ ẸJỌ́ JÉSÙ
Nígbà tí Pílátù béèrè lọ́wọ́ Jésù pé ṣé ọba ni lóòótọ́, ìdáhùn Jésù fi hàn pé kò fọ̀rọ̀ pa mọ́ fún un. Àmọ́ Ìjọba tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ìṣàkóso Róòmù. Jésù sọ fún un pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí. Ká ní Ìjọba mi jẹ́ apá kan ayé yìí, àwọn ìránṣẹ́ mi ì bá ti jà kí wọ́n má bàa fà mí lé àwọn Júù lọ́wọ́. Àmọ́, bó ṣe rí yìí, Ìjọba mi ò wá láti orísun yìí.” (Jòhánù 18:36) Bọ́rọ̀ sì ṣe rí nìyẹn, Jésù ní Ìjọba kan lóòótọ́, àmọ́ kì í ṣe ti ayé yìí.
Pílátù ò fi ọ̀rọ̀ náà mọ síbẹ̀, ó tún bi Jésù pé: “Ó dáa, ṣé ọba ni ọ́?” Jésù jẹ́ kí Pílátù mọ̀ pé òun fúnra rẹ̀ ti dáhùn ìbéèrè yẹn, ó ní: “Ìwọ fúnra rẹ ń sọ pé ọba ni mí. Torí èyí la ṣe bí mi, torí èyí sì ni mo ṣe wá sí ayé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́. Gbogbo ẹni tó bá fara mọ́ òtítọ́ ń fetí sí ohùn mi.”—Jòhánù 18:37.
Jésù ti sọ fún Tọ́másì ṣáájú ìgbà yẹn pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè.” Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, Jésù jẹ́ kí Pílátù mọ̀ pé ìdí tóun fi wá sáyé ni kóun lè jẹ́rìí sí “òtítọ́,” ní pàtàkì òtítọ́ nípa Ìjọba òun. Jésù sì ti múra tán láti dúró lórí òtítọ́ yẹn kódà tó bá máa gba pé kí ẹ̀mí rẹ̀ lọ sí i. Pílátù wá bi Jésù pé: “Kí ni òtítọ́?” àmọ́ kò dúró gbọ́ ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn. Ó gbà pé òun ti rí ẹ̀rí tóun lè fi ṣèdájọ́ Jésù.—Jòhánù 14:6; 18:38.
Pílátù wá pa dà sọ́dọ̀ àwọn èrò tó dúró síwájú ààfin rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí Jésù wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ nígbà tó sọ́ fáwọn olórí àlùfáà àtàwọn èrò náà pé: “Mi ò rí ìwà ọ̀daràn kankan tí ọkùnrin yìí hù.” Ohun tó sọ yẹn bí wọn nínú, ni wọ́n bá pariwo pé: “Ó ń ru àwọn èèyàn sókè ní ti pé ó ń kọ́ wọn káàkiri gbogbo Jùdíà, bẹ̀rẹ̀ láti Gálílì títí dé ibí yìí pàápàá.”—Lúùkù 23:4, 5.
Ó dájú pé ó máa ya Pílátù lẹ́nu báwọn Júù yẹn ò ṣe láròjinlẹ̀, tí wọ́n sì nítara òdì. Nígbà táwọn olórí àlùfáà àtàwọn àgbààgbà yẹn túbọ̀ ń pariwo, Pílátù bi Jésù pé: “Ṣé o ò gbọ́ bí ẹ̀rí tí wọ́n ń jẹ́ lòdì sí ọ ṣe pọ̀ tó ni?” (Mátíù 27:13) Jésù ò tiẹ̀ dá a lóhùn. Àmọ́, ó ya Pílátù lẹ́nu pé ọkàn Jésù balẹ̀ gan-an bí wọ́n tiẹ̀ ń fi oríṣiríṣi ẹ̀sùn èké kàn án.
Àwọn Júù yẹn sọ pé Jésù ń ru àwọn èèyàn sókè “bẹ̀rẹ̀ láti Gálílì.” Pílátù wá ronú lórí ohun tí wọ́n sọ yẹn, ó rí i pé ará Gálílì ni Jésù. Torí náà, ó ń wá ọgbọ́n tó fi máa yẹ ìdájọ́ Jésù sílẹ̀. Hẹ́rọ́dù Áńtípà (tó jẹ́ ọmọ Hẹ́rọ́dù Ńlá) ló ń ṣàkóso Gálílì, ó sì wà ní Jerúsálẹ́mù nígbà yẹn torí Àjọyọ̀ Ìrékọjá. Torí náà, Pílátù ní kí wọ́n mú Jésù lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Ẹ rántí pé Hẹ́rọ́dù Áńtípà yìí ló ní kí wọ́n bẹ́ orí Jòhánù Arinibọmi. Nígbà tí Hẹ́rọ́dù wá gbọ́ pé Jésù ń ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu lẹ́yìn ìgbà yẹn, ó ṣeé ṣe kó rò pé Jòhánù tóun pa ló pa dà di Jésù, torí náà ọkàn rẹ̀ ò balẹ̀.—Lúùkù 9:7-9.
Inú Hẹ́rọ́dù dùn gan-an nígbà tó rí Jésù. Kì í ṣe pé ó fẹ́ gba Jésù sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé ó fẹ́ wádìí bóyá ẹ̀sùn èké ni wọ́n fi kàn án. Ṣe ni Hẹ́rọ́dù wulẹ̀ fẹ́ mọ Jésù, ó sì ń “retí pé kí òun rí i kó ṣiṣẹ́ àmì díẹ̀.” (Lúùkù 23:8) Àmọ́ o, ohun tí Jésù ṣe yàtọ̀ pátápátá sóhun tí Hẹ́rọ́dù ń retí. Kódà, Jésù ò sọ ohunkóhun nígbà tí Hẹ́rọ́dù ń béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. Ohun tí Jésù ṣe yẹn ya Hẹ́rọ́dù àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ lẹ́nu, torí náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ‘kan Jésù lábùkù.’ (Lúùkù 23:11) Wọ́n wọ aṣọ tó rẹwà fún un, wọ́n sì ń fi ṣe yẹ̀yẹ́. Lẹ́yìn náà, Hẹ́rọ́dù ní kí wọ́n mú Jésù pa dà lọ sọ́dọ̀ Pílátù. Ṣáájú ìgbà yẹn, ọ̀tá ni Hẹ́rọ́dù àti Pílátù, àmọ́ ní báyìí, ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ti sọ àwọn méjèèjì di ọ̀rẹ́.
Nígbà tí wọ́n mú Jésù pa dà sọ́dọ̀ Pílátù, Pílátù pe àwọn olórí àlùfáà, àwọn aṣáájú Júù àtàwọn míì tó wà níbẹ̀, ó sọ fún wọn pé: “Mo yẹ̀ ẹ́ wò níwájú yín, àmọ́ mi ò rí ẹ̀rí pé ọkùnrin yìí jẹ̀bi ìkankan nínú ẹ̀sùn tí ẹ fi kàn án. Kódà, Hẹ́rọ́dù náà ò rí ẹ̀rí, torí ó dá a pa dà sọ́dọ̀ wa, ẹ wò ó! kò ṣe ohunkóhun tí ikú fi tọ́ sí i. Torí náà, ṣe ni màá fìyà jẹ ẹ́, màá sì tú u sílẹ̀.”—Lúùkù 23:14-16.
Ó wu Pílátù láti tú Jésù sílẹ̀, torí ó mọ̀ pé ìlara ló mú káwọn aṣáájú ẹ̀sìn yẹn mú un wá sọ́dọ̀ òun. Àmọ́ Pílátù tún wá rí ìdí míì tó fi gbà pé ó yẹ kóun tú Jésù sílẹ̀. Bó ṣe jókòó sórí ìjókòó ìdájọ́ rẹ̀, ìyàwó ẹ̀ rán ẹnì kan sí i, ó ní kí wọ́n sọ fún un pé: “Má ṣe ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú ọkùnrin olódodo yẹn, torí mo jìyà gan-an lójú àlá lónìí nítorí rẹ̀ [ó dájú pé Ọlọ́run ló fi ìran yẹn hàn án].”—Mátíù 27:19.
Báwo ni Pílátù ṣe máa wá ṣe ohun tó yẹ kó ṣe, kó lè tú ọkùnrin tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ yìí sílẹ̀?