ORÍ 132
“Ó Dájú Pé Ọmọ Ọlọ́run Ni Ọkùnrin Yìí”
MÁTÍÙ 27:45-56 MÁÀKÙ 15:33-41 LÚÙKÙ 23:44-49 JÒHÁNÙ 19:25-30
JÉSÙ KÚ LÓRÍ ÒPÓ IGI ORÓ
ÀWỌN OHUN TÓ ṢÀRÀ Ọ̀TỌ̀ ṢẸLẸ̀ NÍGBÀ TÍ JÉSU KÚ
Ó ti di “wákàtí kẹfà” báyìí, ọ̀sán sì ti pọ́n. Ṣàdédé ni òkùnkùn ṣú bo “gbogbo ilẹ̀ náà títí di wákàtí kẹsàn-án,” ìyẹn ní nǹkan bí aago mẹ́ta ọ̀sán. (Máàkù 15:33) Kì í ṣe ọ̀sán ló dòru bí òkùnkùn yẹn ṣe ṣú tàbí pé òṣùpá ló bo oòrùn lójú. Ìgbà òṣùpá tuntun ni ọ̀sán sábà máa ń dòru, àmọ́ àsìkò Ìrékọjá tí òṣùpá máa ń ràn mọ́jú nìyí. Yàtọ̀ síyẹn, odindi wákàtí mẹ́ta ni òkùnkùn yìí fi ṣú, bẹ́ẹ̀ sì rèé ọ̀sándòru kì í ju ìṣẹ́jú mélòó kan lọ. Torí náà, ó dájú pé Ọlọ́run ló mú kí òkùnkùn yẹn ṣú!
Ẹ wo bí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ṣe máa rí lára àwọn tó ń fi Jésù ṣe yẹ̀yẹ́. Lásìkò tí òkùnkùn ṣú bolẹ̀ yẹn, àwọn obìnrin mẹ́rin kan lọ síbi òpó igi oró tí wọ́n kan Jésù mọ́. Àwọn obìnrin náà ni Màríà ìyá rẹ̀, Sàlómẹ̀, Màríà Magidalénì àti Màríà ìyá àpọ́sítélì kan tó ń jẹ́ Jémíìsì Kékeré.
Àpọ́sítélì Jòhánù wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìyá Jésù bó ṣe dúró sí “tòsí òpó igi oró” náà, ó dájú pé ọ̀fọ̀ ńlá ló ṣẹ obìnrin yìí. Ẹ wo bó ṣe máa rí lára Màríà bó ṣe ń wo ọmọ ẹ̀ tó ń jẹ̀rora lórí òpó igi oró. Ṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n fi “idà gígùn kan” gún ọkàn rẹ̀. (Jòhánù 19:25; Lúùkù 2:35) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù ń jẹ̀rora, ó ronú nípa bó ṣe máa bójú tó ìyá rẹ̀. Ó rọra yíjú sí Jòhánù, ó sì sọ fún ìyá rẹ̀ pé: “Obìnrin, wò ó! Ọmọ rẹ!” Lẹ́yìn náà, ó yíjú sí Màríà, ó sì sọ fún Jòhánù pe: “Wò ó! Ìyá rẹ!”—Jòhánù 19:26, 27.
Ó dájú pé opó ni Màríà nígbà yẹn, torí náà Jésù ní kí ọmọ ẹ̀yìn tó fẹ́ràn gan-an máa bójú tó ìyá òun. Jésù mọ̀ pé àwọn àbúrò òun, ìyẹn àwọn ọmọ ìyá rẹ̀ ò tíì gba òun gbọ́. Ìdí nìyẹn tó fi ṣètò ẹni táá máa bójú tó ìyá ẹ̀, táá lè máa pèsè ohun tó nílò nípa tara àti nípa tẹ̀mí. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ tó dáa nìyẹn!
Nígbà tí ojú ọjọ́ mọ́lẹ̀ lẹ́yìn òkùnkùn yẹn, Jésù sọ pé: “Òùngbẹ ń gbẹ mí.” Ohun tó sọ yìí mú àsọtẹ́lẹ̀ kan ṣẹ. (Jòhánù 19:28; Sáàmù 22:15) Lójú Jésù, ṣe ló dà bí ìgbà tí Baba rẹ̀ ò dá sí i mọ́, kí wọ́n lè dán ìwà títọ́ rẹ̀ wò lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Jésù wá sọ ọ̀rọ̀ kan, ó jọ pé èdè Árámáíkì táwọn ará Gálílì ń sọ ló fi sọ ọ́, ó ké jáde pé: “Élì, Élì, làmá sàbákìtanì?” ìyẹn túmọ̀ sí, “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí sílẹ̀?” Àwọn kan lára àwọn tó wà nítòsí ibẹ̀ ò lóye ohun tó sọ, ni wọ́n bá sọ pé: “Ẹ wò ó! Ó ń pe Èlíjà.” Ọ̀kan lára wọn wá sáré lọ rẹ kànrìnkàn sínú wáìnì kíkan, ó fi sórí ọ̀pá esùsú, ó sì fún un pé kó mu ún. Àmọ́ àwọn míì sọ pé: “Ẹ fi sílẹ̀! Ká wò ó bóyá Èlíjà máa wá gbé e sọ̀ kalẹ̀.”—Máàkù 15:34-36.
Jésù wá ké jáde pé: “A ti ṣe é parí!” (Jòhánù 19:30) Lóòótọ́, Jésù ti parí gbogbo ohun tí Baba rẹ̀ ní kó wá ṣe láyé. Lẹ́yìn náà, Jésù sọ pé: “Baba, ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé.” (Lúùkù 23:46) Jésù tipa bẹ́ẹ̀ fún Ọlọ́run ní ìwàláàyè rẹ̀, ó sì gbà pé ó máa mú kóun pa dà wà láàyè lẹ́ẹ̀kan sí i. Jésù ò ṣiyèméjì rárá, ó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, lẹ́yìn náà ó tẹ orí rẹ̀ ba, ó sì kú.
Bí Jésù ṣe kú báyìí, ìmìtìtì ilẹ̀ tó lágbára kan ṣẹlẹ̀, ó sì la àwọn àpáta sọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Ìmìtìtì ilẹ̀ yìí le débi pé ó ṣí àwọn ibojì tó wà lẹ́yìn odi Jerúsálẹ́mù, ó sì da àwọn òkú tó wà nínú wọn jáde. Nígbà táwọn tó ń gba ibẹ̀ kọjá rí àwọn òkú yìí níta, wọ́n sáré wọnú “ìlú mímọ́ náà,” wọ́n sì sọ ohun tójú wọn rí fáwọn míì.—Mátíù 12:11; 27:51-53.
Ní gbàrà tí Jésù kú, aṣọ ńlá gígùn tí wọ́n fi pààlà sáàárín Ibi Mímọ́ àti Ibi Mímọ́ Jù Lọ nínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run ya sí méjì, látòkè dé ìsàlẹ̀. Ohun ìyanu tó ṣẹlẹ̀ yẹn fi hàn pé ìbínú Ọlọ́run wà lórí àwọn tó pa Ọmọ rẹ̀, ìyẹn ló sì jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti wọ ọ̀run tó jẹ́ Ibi Mímọ́ Jù Lọ.—Hébérù 9:2, 3; 10:19, 20.
Kò ṣòro láti rí ìdí tẹ́rù fi ba àwọn èèyàn yẹn. Kódà, gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí dẹ́rù ba ọ̀gágun tó bójú tó bí wọ́n ṣe pa Jésù, ó sọ pé: “Ó dájú pé Ọmọ Ọlọ́run ni ọkùnrin yìí.” (Máàkù 15:39) Ó ṣeé ṣe kí ọkùnrin yìí wà níbi tí Pílátù ti ń gbọ́ ẹjọ́ Jésù, nígbà táwọn aṣáájú ẹ̀sìn fẹ̀sùn kàn án pé ó ń pe ara rẹ̀ ní ọmọ Ọlọ́run. Gbogbo ohun tí ọkùnrin yìí rí ti wá mú kó gbà pé olódodo ni Jésù, ó sì dá a lójú pé Ọmọ Ọlọ́run ni lóòótọ́.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí kó ẹ̀dùn ọkàn bá ọ̀pọ̀ èèyàn, ó sì kó ìtìjú bá wọn, débi pé ṣe ni “wọ́n ń lu àyà wọn” bí wọ́n ṣe ń lọ sílé wọn. (Lúùkù 23:48) Àwọn kan ń wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí láti ọ̀ọ́kán, àwọn obìnrin tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù sì wà lára wọn, ọ̀pọ̀ lára wọn ló ti fìgbà kan rí bá a rìnrìn àjò. Ó dájú pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn náà.