Báwo Ni Ó Ṣe Yẹ Kí A Máa Gbàdúrà sí Ọlọ́run?
NÍGBÀ tí ọmọ ẹ̀yìn kán béèrè fún ìtọ́ni lórí àdúrà, Jésù kò kọ̀ láti fi fún un. Ní ìbámu pẹ̀lú Lúùkù 11:2-4, ó fèsì pé: “Nígbà tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ wí pé: Bàbá, kí a bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ. Kí ìjọba rẹ dé. Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí. Sì dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, nítorí awa pẹ̀lú a máa dárí ji olúkúlùkù ẹni tí ó jẹ wá ní gbèsè. Má sì ṣe ṣamọ̀nà wá sínú ìdẹwò.” (Douay Version ti Kátólíìkì) Èyí ni ọ̀pọ́ mọ̀ sí Àdúrà Olúwa. Ó gbé ọ̀pọ̀ ìsọfúnni yọ.
Àkọ́kọ́, ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ sọ ẹni tí a gbọ́dọ̀ darí àdúrà wa sí fún wa—sí Bàbá wa. Ṣàkíyèsí pé, Jésù lọ́nàkọnà kò fàyè gba gbígbàdúrà sí ẹlòmíràn, ère, “ẹni mímọ́,” tàbí sí òun alára pàápàá. Ó ṣe tán, Ọlọ́run ti polongo pé: “Èmi kì yóò fi ògo mi fún ẹlòmíràn, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi ìyìn mi fún ohun gbígbẹ́.” (Aísáyà 42:8, Dy) Nítorí náà, Bàbá wa ọ̀run kì í gbọ́ àdúrà tí a darí sí ohunkóhun tàbí sí ẹnikẹ́ni mìíràn yàtọ̀ sí i, láìka bí olùjọsìn náà ti lè jẹ́ olóòótọ́ ọkàn tó. Nínú Bíbélì, Jèhófà Ọlọ́run nìkan ni a pè ní ‘Olùgbọ́ àdúrà.’—Orin Dáfídì 65:2.
Àwọn kan lè sọ pé “àwọn ẹni mímọ́” wulẹ̀ ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí abániṣìpẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni. Ṣùgbọ́n, Jésù fúnra rẹ̀ kọ́ni pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹnì kan tí ó ń wá sọ́dọ̀ Bàbá bí kò ṣe nípasẹ̀ mi. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ohun yòówù kí ó jẹ́ tí ẹ bá béèrè ní orúkọ mi, èmi yóò ṣe èyí dájúdájú, kí a lè yin Bàbá lógo ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Ọmọkùnrin.” (Jòhánù 14:6, 13) Jésù tipa báyìí fagi lé èrò náà pé ẹnikẹ́ni tí a ń pè ní ẹni mímọ́ lè ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí abániṣìpẹ̀. Tún ṣàkíyèsí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa Kristi pé: “Kì í ṣe pé ó kú fún wa nìkan—ó dìde kúrò nínú òkú, ó sì wà ní ìdúró níbẹ̀ ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run, ó sì ń jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wa.” “Ó wà láàyè títí láé láti ṣìpẹ̀ fún gbogbo àwọn tí ó wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ rẹ̀.”—Róòmù 8:34; Hébérù 7:25, Jerusalem Bible ti Kátólíìkì.
Orúkọ Tí A Gbọ́dọ̀ Bọ̀wọ̀ Fún
Àwọn ọ̀rọ̀ àdúrà Jésù tí ó tẹ̀ lé e ni: “Kí a bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ.” Báwo ni ẹnì kan ṣe lè bọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn ni pé, kí ó yà á sí mímọ́, tàbí yà á sọ́tọ̀, láìjẹ́ pé ẹni náà mọ̀ ọ́n, tí ó sì ń lò ó? Ní èyí tí ó ju ìgbà 6,000 lọ nínú “Májẹ̀mú Láéláé,” a fi Ọlọ́run hàn yàtọ̀ nípasẹ̀ orúkọ ara ẹni náà, Jèhófà.
Àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé kan lórí Ẹ́kísódù 6:3 nínú Douay Version ti Kátólíìkì sọ nípa orúkọ Ọlọ́run pé: “Àwọn onígbàlódé kan ti hùmọ̀ orúkọ Jèhófà . . . , nítorí bí a ṣe ń pe orúkọ [Ọlọ́run] ní tòótọ́, bí ó ti wà nínú ìwé Hébérù, ni a kò mọ̀ nítorí pé a kò lò ó mọ́.” Nítorí náà, New Jerusalem Bible ti Kátólíìkì lo orúkọ náà, Yahweh. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan fara mọ́ pípè é lọ́nà yẹn, “Jehovah” jẹ́ ọ̀nà tí ó tọ́, tí a ti gbé kalẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́ fún pípe orúkọ àtọ̀runwá náà ní èdè Gẹ̀ẹ́sì. Àwọn èdè yòókù ní ọ̀nà tiwọn tí wọ́n gbà ń pe orúkọ àtọ̀runwá náà. Ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, a ń lo orúkọ náà kí a baà lè bọ̀wọ̀ fún un. Ṣọ́ọ̀ṣì rẹ ha ti kọ́ ọ láti lo orúkọ náà, Jèhófà, nínú àdúrà bí?
Àwọn Kókó Tí Ó Tọ́ fún Àdúrà
Lẹ́yìn èyí, Jésù kọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbàdúrà pé: “Kí ìjọba rẹ dé.” Ìhìn Rere Mátíù fi àwọn ọ̀rọ̀ náà kún un pé: “Kí a ṣe ìfẹ́ rẹ lórí ilẹ̀ ayé bí a ti ń ṣe ní ọ̀run.” (Mátíù 6:10, Dy) Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìṣàkóso kan ní ọwọ́ Jésù Kristi. (Aísáyà 9:6, 7) Ní ìbámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, yóò mú ìjọba ènìyàn kúrò láìpẹ́, yóò sì mú sànmánì àlàáfíà kárí ayé wá. (Orin Dáfídì 72:1-7; Dáníẹ́lì 2:44; Ìṣípayá 21:3-5) Nítorí náà, àwọn Kristẹni tòótọ́ ń mú kí dídé Ìjọba náà jẹ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọtúnsọ nínú àdúrà wọn. Ṣọ́ọ̀ṣì rẹ́ ha ti kọ́ ọ láti ṣe bẹ́ẹ̀ bí?
Ó dùn mọ́ni pé, Jésù tún fi hàn pé àdúrà wa lè ní àwọn ọ̀ràn ti ara ẹni tí ó kàn wá nínú. Ó sọ pé: “Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí. Sì dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, nítorí àwa pẹ̀lú a máa dárí ji olúkúlùkù ẹni tí ó jẹ wá ní gbèsè. Má sì ṣe ṣamọ̀nà wa sínú ìdẹwò.” (Lúùkù 11:3, 4, Dy) Àwọn ọ̀rọ̀ Jésù túmọ̀ sí pé a lè béèrè fún ìfẹ́ inú Ọlọ́run nínú gbogbo ọ̀ràn ojoojúmọ́, pé a lè tọ Jèhófà lọ nípa ohunkóhun tí ó lè dààmú wa tàbí da àlàáfíà ọkàn wa láàmú. Bíbẹ Ọlọ́run déédéé lọ́nà yìí ń ràn wá lọ́wọ́ láti mọrírì gbígbé tí a gbára lé e. Nípa báyìí, a túbọ̀ ń mọ ipa ìdarí rẹ̀ nínú ìgbésí ayé wa. Bíbéèrè lójoojúmọ́ pé kí Ọlọ́run dárí jì wá nítorí àwọn láìfí wa ṣàǹfààní lọ́nà kan náà. A ń tipa bẹ́ẹ̀ mọ àwọn àìlera wa sí i—a sì túbọ̀ ń fara da ìkùnà àwọn ẹlòmíràn. Ìgbaniníyànjú Jésù pé kí á gbàdúrà fún ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ ìdẹwò tún bá a mu wẹ́kú, ní pàtàkì lójú ìwòye ìwà rere ayé yìí tí ń lọ sílẹ̀. Ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà yẹn, a ń ṣọ́ra láti yẹra fún àwọn àyíká ipò àti agbègbè tí ó lè ṣamọ̀nà wa sínú ṣíṣe ohun tí kò tọ́.
Nígbà náà, ó dájú pé, Àdúrà Olúwa sọ púpọ̀ fún wa nípa gbígba àdúrà tí inú Ọlọ́run dùn sí. Ṣùgbọ́n Jésù ha ní in lọ́kàn pé kí a tẹ́wọ́ gba àdúrà yìí, kí a sì wulẹ̀ máa ṣe àsọtúnsọ rẹ̀ déédéé?
Ìmọ̀ràn Síwájú Sí I Lórí Àdúrà
Jésù fúnni ní ìtọ́ni síwájú sí i lórí àdúrà. Ní Mátíù 6:5, 6, a kà pé: “Nígbà tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ kò gbọ́dọ̀ dà bí àwọn alágàbàgebè; nítorí wọ́n fẹ́ láti máa gbàdúrà ní dídúró nínú àwọn sínágọ́gù àti ní àwọn igun ọ̀nà fífẹ̀ kí àwọn ènìyán baà lè rí wọn. . . . Ìwọ, bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí o bá ń gbàdúrà, lọ sínú yàrá àdáni rẹ àti, lẹ́yìn títi ilẹ̀kùn rẹ, gbàdúrà sí Bàbá rẹ tí ń bẹ ní ìkọ̀kọ̀; nígbà náà Bàbá rẹ tí ń wòran ní ìkọ̀kọ̀ yóò san án padà fún ọ.” Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí kọ́ wa pé kò yẹ kí a gbàdúrà lọ́nà ṣekárími, aláfẹfẹyẹ̀yẹ̀ láti fi wu ẹlòmíràn. Ìwọ́ ha ń sọ ọkàn rẹ jáde fún Jèhófà níkọ̀kọ̀, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti rọni?—Orin Dáfídì 62:8.
Jésù fúnni ní ìkìlọ̀ yìí pé: “Nínú àdúrà rẹ, má ṣe sọ wótowòto, gẹ́gẹ́ bí àwọn kèfèrí ti ń ṣe, nítorí wọ́n lérò pé nípa lílo ọ̀rọ̀ púpọ̀, a óò gbọ́ tiwọn.” (Mátíù 6:7, JB) Ní kedere, Jésù kò fọwọ́ sí kíkọ́ àdúrà sórí—ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ kíkà á láti inú àwọn ìwé kan. Àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ tún fagi lé lílo ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà.
Ìwé máàsì Kátólíìkì kan sọ ìjẹ́wọ́ yìí pé: “Àdúrà wa tí ó dára jù lọ lè jẹ́ èrò tí ó wá láti inú wa lọ́hùn ún nígbà tí a bá yíjú sí i nínú ìmoore tàbí àìní, ní àwọn àkókò ìbànújẹ́, tàbí nínú ìjọsìn wa ojoojúmọ́ sí i.” Àwọn àdúrà Jésù wá láti inú lọ́hùn-ún, kì í ṣe àkọ́sórí. Fún àpẹẹrẹ, ka àdúrà Jésù tí a kọ sílẹ̀ nínú Jòhánù orí 17. Ó dá lórí àdúrà àwòṣe náà, ní títẹnu mọ́ ìfẹ́ ọkàn Jésù láti rí i pé a sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́. Àdúrà Jésù wá láti inú lọ́hùn-ún, ó sì ti inú ọkàn jíjinlẹ̀ wá.
Àwọn Àdúrà Tí Ọlọ́run Ń Gbọ́
Bí a bá ti kọ́ ọ láti máa gba àwọn àdúrà àkọ́sórí, láti máa gbàdúrà sí “àwọn ẹni mímọ́” tàbí sí ère, tàbí láti lo àwọn ohun èlò ìsìn, irú bí ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà, èrò gbígbàdúrà lọ́nà ti Jésù là sílẹ̀ lè kọ́kọ́ bà ọ́ lẹ́rù. Síbẹ̀, kọ́kọ́rọ́ náà jẹ́ láti mọ Ọlọ́run—orúkọ rẹ̀, àwọn ète rẹ̀, àkópọ̀ ìwà rẹ̀. Ìwọ́ lè ṣàṣeparí èyí nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì aláápọn. (Jòhánù 17:3) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe tán, wọ́n sì múra tán láti ràn ọ́ lọ́wọ́ lórí èyí. Họ́wù, wọ́n ti ran àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́wọ́ kárí ayé láti ‘tọ́ ọ wò, kí wọ́n sì rí i pé, rere ni Olúwa’! (Orin Dáfídì 34:8) Bí o bá ti mọ Ọlọ́run tó, bẹ́ẹ̀ ni a óò ṣe sún ọ láti yìn ín nínú àdúrà tó. Bí o bá sì ṣe sún mọ́ Jèhófà nínú àdúrà ọlọ́wọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ní ipò ìbátan rẹ yóò ti ṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀ tó.
Nítorí náà, a rọ gbogbo olùjọsìn tòótọ́ Ọlọ́run láti “máa gbàdúrà láìdabọ̀.” (Tẹsalóníkà Kìíní 5:17) Rí i dájú pé àdúrà rẹ wà ní ìbámu tòótọ́ pẹ̀lú Bíbélì, àti ìtọ́ni Jésù Kristi. Lọ́nà yìí, o lè ní ìdánilójú pé Ọlọ́run yóò fọwọ́ sí àdúrà rẹ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Bí a bá ṣe kọ́ nípa Jèhófà tó, bẹ́ẹ̀ ni a óò ṣe sún wa láti gbàdúrà sí i látọkàn wá tó