Báwo ni Jésù Ṣe Lè Yí Ìgbésí Ayé Rẹ Padà?
JÉSÙ KRISTI jẹ́ Olùkọ́ Ńlá tó gbé Palẹ́sìnì ní nǹkan bí ẹgbàá ọdún sẹ́yìn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ̀nba díẹ̀ la mọ̀ nípa ìgbà ọmọdé rẹ̀. Ẹ̀rí tó dájú fi hàn pé nígbà tó pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láti “jẹ́rìí sí òtítọ́.” (Jòhánù 18:37; Lúùkù 3:21-23) Ọdún mẹ́ta ààbọ̀ tó tẹ̀lé e ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn mẹ́rin tó kọ àkọsílẹ̀ nípa ìgbésí ayé rẹ̀ darí àfiyèsí sí.
Nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù Kristi, ó fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní àṣẹ kan tó lè jẹ́ ẹ̀rọ̀ sí ọ̀pọ̀ lára àìsàn tó ń ṣe ayé. Kí ni nǹkan náà? Jésù sọ pé: “Èmi ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín, pé kí ẹ̀yin pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” (Jòhánù 13:34) Dájúdájú, ìfẹ́ ni ojútùú sí ọ̀pọ̀ lára ìṣòro aráyé. Ìgbà kan tún wà tí wọ́n bi Jésù pé èwo ni àṣẹ títóbi jù lọ, ó dáhùn pé: “‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.’ Èyí ni àṣẹ títóbi jù lọ àti èkíní. Èkejì, tí ó dà bí rẹ̀, nìyí, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.’”—Mátíù 22:37-40.
Jésù fi bí a ṣe lè nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa hàn wá nípa àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò, kí a sì rí ohun tí a lè kọ́ lọ́dọ̀ rẹ̀.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Rẹ̀
Nínú ọ̀kan lára ìwàásù tí a mọ̀ jù lọ nínú ìtàn, Jésù Kristi sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Kò sí ẹnì kan tí ó lè sìnrú fún ọ̀gá méjì; nítorí yálà òun yóò kórìíra ọ̀kan, kí ó sì nífẹ̀ẹ́ èkejì, tàbí òun yóò fà mọ́ ọ̀kan, kí ó sì tẹ́ńbẹ́lú èkejì. Ẹ kò lè sìnrú fún Ọlọ́run àti fún Ọrọ̀.” (Mátíù 6:24) Ǹjẹ́ ẹ̀kọ́ Jésù nípa fífi Ọlọ́run sí ipò kìíní nínú ìgbésí ayé wa ṣì gbéṣẹ́ lónìí, nínú ayé tí ọ̀pọ̀ ti gbà pé ọ̀rọ̀ tówó bá ṣe tì ilẹ̀ ló ń gbé? Lóòótọ́, a nílò owó láti gbọ́ bùkátà. (Oníwàásù 7:12) Síbẹ̀, táa bá jẹ́ ki “Ọrọ̀” jọ̀gá lé wa lórí, “ìfẹ́ owó” ni yóò máa darí wa, yóò sì jọba lórí gbogbo ìgbésí ayé wa. (1 Tímótì 6:9, 10) Ọ̀pọ̀ tó ti kó sínú pańpẹ́ yìí ló ti pàdánù ìdílé wọn, ọ̀pọ̀ ti di olókùnrùn, kódà ọ̀pọ̀ ti pàdánù ìgbésí ayé wọn pàápàá.
Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, wíwo Ọlọ́run bí Ọ̀gá wa ń jẹ́ kí ìgbésí ayé nítumọ̀. Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá, òun ni Orísun ìwàláàyè, nípa bẹ́ẹ̀, òun nìkan ni ìjọsìn wa tọ́ sí. (Sáàmù 36:9; Ìṣípayá 4:11) A ń sún àwọn tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nípa ànímọ́ rẹ̀ tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ láti pa àṣẹ rẹ̀ mọ́. (Oníwàásù 12:13; 1 Jòhánù 5:3) Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, a ń ṣe ara wa láǹfààní.—Aísáyà 48:17.
Nínú Ìwàásù Lórí Òkè, Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bí wọ́n ṣe lè fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wọn. Ó sọ pé: “Nítorí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” (Mátíù 7:12) Ọ̀rọ̀ náà “àwọn ènìyàn” tí Jésù lò níhìn-ín kan ọ̀tá ẹni pàápàá. Nínú ìwàásù kan náà, ó sọ pé: “Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín.” (Mátíù 5:43, 44) Ǹjẹ́ irú ìfẹ́ yẹn kò ní yanjú ọ̀pọ̀ lára àwọn ìṣòro táa dojú kọ lónìí? Aṣáájú ẹ̀sìn Híńdù nì, Mohandas Gandhi, ronú bẹ́ẹ̀. A ṣàyọlò ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ti sọ pé: “Nígbà tí [a] bá foríkorí lórí àwọn ẹ̀kọ́ tí Kristi fi lélẹ̀ nínú Ìwàásù orí Òkè, àwa yóò ti yanjú àwọn ìṣòro . . . àgbáyé lódindi.” Bí a bá fi àwọn ẹ̀kọ́ Jésù nípa ìfẹ́ sílò, ó lè yanjú ọ̀pọ̀ lára ìṣòro búburú tí aráyé ní.
Àwọn Ìṣe Rẹ̀
Kì í ṣe pé Jésù fi òtítọ́ jíjinlẹ̀ kọ́ni nípa bí a ṣe lè fi ìfẹ́ hàn nìkan ni, ó tún ṣe ohun tó fi ń kọ́ni pẹ̀lú. Fún àpẹẹrẹ, ó fi ire àwọn ẹlòmíràn ṣáájú ti ara rẹ̀. Lọ́jọ́ kan, ọwọ́ Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dí gan-an níbi tí wọ́n ti ń ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ débi pé wọn kò rí àyè láti jẹun pàápàá. Jésù rí i pé ó yẹ kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun sinmi díẹ̀, ó sì mú wọn lọ sí ibì kan tí ó dá. Àmọ́, nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, wọ́n rí ọ̀pọ̀ ènìyàn tó ń dúró dè wọ́n. Ká ní ìwọ lo rí ọ̀pọ̀ ènìyàn tó fẹ́ kóo ṣiṣẹ́ nígbà tóo rò pé ó yẹ kóo sinmi díẹ̀, kí lo máa ṣe? Lọ́rọ̀ kan ṣá, “àánú wọ́n ṣe” Jésù, ó sì “bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn ní ohun púpọ̀.” (Máàkù 6:34) Àníyàn tí Jésù ní fún àwọn ẹlòmíràn yìí ló ń sún un láti ràn wọ́n lọ́wọ́.
Kì í kàn ṣe pé Jésù kọ́ àwọn ènìyàn nìkan ni. Ó tún pèsè ohun tí wọ́n nílò pẹ̀lú. Fún àpẹẹrẹ, ní àkókò kan ó bọ́ àwọn ènìyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún tí wọ́n ń fetí sí i títí di àṣálẹ́. Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn ìyẹn, ó bọ́ ogunlọ́gọ̀ mìíràn—lákòókò yìí wọ́n lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rin—àwọn tí wọ́n ti ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ láti ọjọ́ mẹ́ta tí kò sì sí ohun tí wọ́n máa jẹ. Lákọ̀ọ́kọ́, ó lo ìṣù búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì, lẹ́ẹ̀kejì, ó lo ìṣù búrẹ́dì méje àti àwọn ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀. (Mátíù 14:14-22; 15:32-38) Ṣé ó tún ṣe iṣẹ́ ìyanu ni? Bẹ́ẹ̀ ni, oníṣẹ́ ìyanu ni.
Jésù tún wo ọ̀pọ̀ aláìsàn sàn. Ó la ojú afọ́jú, ó mú arọ rìn, ó wo adẹ́tẹ̀ sàn ó sì mú kí odi sọ̀rọ̀. Họ́wù, ó tún jí òkú dìde pàápàá! (Lúùkù 7:22; Jòhánù 11:30-45) Nígbà kan adẹ́tẹ̀ kan bẹ̀ ẹ́ pé: “Bí ìwọ bá sáà ti fẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ lè mú kí èmi mọ́.” Kí ni Jésù ṣe? “Látàrí ìyẹn, àánú ṣe é, ó sì na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fọwọ́ kàn án, ó sì wí fún un pé: ‘Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀. Kí ìwọ mọ́.’” (Máàkù 1:40, 41) Nípasẹ̀ irú àwọn iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀, Jésù fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn sí àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́.
Àbó ṣòro fún ọ láti gba iṣẹ́ ìyanu Jésù gbọ́ ni? Ó rí bẹ́ẹ̀ fún àwọn kan. Àmọ́, ẹ rántí o, pé gbangba ni Jésù ti ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀. Kódà àwọn alátakò rẹ̀, tí wọ́n máa ń fi gbogbo ìgbà wá ẹ̀sùn sí i lẹ́sẹ̀ kò lè sọ pé kì í ṣe oníṣẹ́ ìyanu. (Jòhánù 9:1-34) Síwájú sí i, ó nídìí tó fi ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe. Wọ́n ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti mọ̀ pé òun ni Ẹni tí Ọlọ́run rán.—Jòhánù 6:14.
Jésù kò fi àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ń ṣe pe àfiyèsí sí ara rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ń fi ògo fún Ọlọ́run, ẹni tí í ṣe Orísun agbára rẹ̀. Nígbà kan tó wà nínú ilé kan tó kún fún èrò ní Kápánáúmù. Ọkùnrin alárùn ẹ̀gbà kan fẹ́ kí ó mú òun lára dá ṣùgbọ́n kò sí ibi tó lè gbà wọlé. Ni àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ bá gba orí òrùlé gbé e sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú àkéte rẹ̀. Nígbà tí Jésù rí bí ìgbàgbọ́ wọn ti lágbára tó, ó wo alárùn ẹ̀gbà náà sàn. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé àwọn ènìyàn náà “yin Ọlọ́run lógo,” wọ́n sì wí pé: “Àwa kò tíì rí ohun tí ó dà bí rẹ̀ rí.” (Máàkù 2:1-4, 11, 12) Àwọn iṣẹ́ ìyanu Jésù fi ìyìn fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀, ó sì ṣàǹfààní fún àwọn tó ń wá ìrànlọ́wọ́.
Kẹ́ẹ sì wá wò o, kì í ṣe fífi iṣẹ́ ìyanu mu àwọn aláìsàn lára dá gan-an ni olórí iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù. Ẹní kan tó kọ àkọsílẹ̀ kan nípa ìgbésí ayé Jésù ṣàlàyé pé: “Ìwọ̀nyí ni a ti kọ sílẹ̀ kí ẹ lè gbà gbọ́ pé Jésù ni Kristi Ọmọ Ọlọ́run, àti pé, nítorí gbígbàgbọ́, kí ẹ lè ní ìyè nípasẹ̀ orúkọ rẹ̀.” (Jòhánù 20:31) Láìsí àní-àní, Jésù wá sáyé kí àwọn tó bá gbà á gbọ́ lè ní ìyè.
Ẹbọ Rẹ̀
O lè béèrè pé, ‘Jésù wá sáyé kẹ̀? Ibo ló ti wá?’ Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé: “Èmi sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run, kì í ṣe láti ṣe ìfẹ́ mi, bí kò ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi.” (Jòhánù 6:38) Ó ti wà tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọmọ bíbí kan ṣoṣo fún Ọlọ́run, kó tó wá di ènìyàn. Bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, kí wá ni ìfẹ́ Ẹni tó rán an wá sáyé? Jòhánù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ́ Ìwé Ìhìnrere sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Báwo lèyí ṣe wá ṣeé ṣe?
Bíbélì fi bí ikú ṣe wáá di ohun tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ fún ìran ènìyàn hàn. Tọkọtaya ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ gba ìwàláàyè lọ́dọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú ète láti wà láàyè títí láé. Àmọ́, wọ́n yàn láti ṣọ̀tẹ̀ sí Olùṣẹ̀dá wọn. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-19) Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí ohun tí wọ́n ṣe yìí, ìyẹn ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́, àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà jogún ikú, ogún kan tí kò bára dé. (Róòmù 5:12) Láti lè fún aráyé ní ìyè tòótọ́, ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú gbọ́dọ̀ kásẹ̀ nílẹ̀.
Kò sí onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan tó lè mú ikú kúrò nípa lílo ọgbọ́n yíyí apilẹ̀ àbùdá padà. Síbẹ̀, Ẹlẹ́dàá aráyé ní agbára láti mú ẹ̀dá ènìyàn onígbọràn wá sí ìjẹ́pípé kí wọn lè wà láàyè títí láé. Nínú Bíbélì, a pe àǹfààní yìí ní ìràpadà. Tọkọtaya ènìyàn àkọ́kọ́ ta ara wọn àti àtọmọdọ́mọ wọ́n sí oko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Wọ́n fi ìwàláàyè wọn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn pípé tó ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run ra ìgbésí ayé tí kò sí lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run, nínú èyí tí wọ́n a ti máa dá ṣe ìpinnu fúnra wọn yálà èyí tó dára tàbí èyí tó burú. Láti lè ri ìwàláàyè pípé rà padà, a gbọ́dọ̀ san iye kan tó bá ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn pípé mu rẹ́gí, èyí tí àwọn òbí wa àkọ́kọ́ pàdánù. Nítorí àìpé táa ti jogún, ẹ̀dá ènìyàn kò tóótun láti san iye náà.—Sáàmù 49:7.
Nítorí èyí, Jèhófà Ọlọ́run dá sí ọ̀ràn náà láti ṣèrànwọ́. Ó ta àtaré ìwàláàyè pípé ti Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo sínú ilé ọlẹ̀ wúńdíá kan tó bí Jésù. Ní àwọn ẹ̀wádún díẹ̀ sẹ́yìn, ó lè jẹ́ pé o kì í fẹ́ gba èrò náà wọlé, pé wúńdíá kan bímọ láìmọ ọkùnrin kankan. Àmọ́, lónìí, àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti kó àwọn ẹranko afọ́mọlọ́mú tí ànímọ́ wọn jọra pa pọ̀, tí wọ́n sì mú apilẹ̀ àbùdá láti ara ẹranko kan wọnú ẹranko mìíràn. Ta ló wá fẹ́ sọ pé Ẹlẹ́dàá kò ní agbára láti mú ìwàláàyè jáde lọ́nà tó yàtọ̀ sí bó ṣe máa ń wáyé?
Nígbà tí ẹ̀dá tó ní ìwàláàyè pípé wáá dé, iye tí a nílò láti fi ra ìran ènìyàn padà lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú di ohun tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Síbẹ̀, Jésù ọmọdé jòjòló náà táa bí ní láti dàgbà kó di “oníṣègùn” tó lè pèsè “egbòogi” láti wo àìsàn ìran ènìyàn sàn. Ó ṣe èyí nípa gbígbé ìgbésí ayé pípé, tí kò lẹ́ṣẹ̀. Kì í ṣe pé Jésù rí làásìgbò ìran ènìyàn lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ nìkan ni, àmọ́, ó mọ ohun tó túmọ̀ sí láti jẹ́ ènìyàn. Èyí mú kó túbọ̀ jẹ́ oníṣègùn tó lójú àánú gidigidi. (Hébérù 4:15) Àwọn ìwòsàn tó ṣe lọ́nà ìyanu nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé fi ẹ̀rí hàn pé ó ní agbára láti wo àwọn aláìsàn sàn, ó sì fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.—Mátíù 4:23.
Lẹ́yìn iṣẹ́ òjíṣẹ́ ọlọ́dún mẹ́ta ààbọ̀ níhìn-ín lórí ilẹ̀ ayé, àwọn alátakò Jésù pa á. Ó fi hàn pé ẹni pípé kan lè ṣègbọràn sí Ẹlẹ́dàá, kódà lójú àdánwò tó burú jù lọ. (1 Pétérù 2:22) Ìwàláàyè pípé rẹ̀ tó fi rúbọ ló wá di iye ìràpadà náà, tó lè ra ìran ènìyàn padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Jésù Kristi sọ pé: “Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.” (Jòhánù 15:13) Ọjọ́ kẹta lẹ́yìn ikú Jésù, a jí i dìde sí ìwàláàyè tẹ̀mí, ọ̀sẹ̀ díẹ̀ lẹ́yìn náà, ó gòkè lọ sí ọ̀run láti gbé iye ìràpadà náà fún Jèhófà Ọlọ́run. (1 Kọ́ríńtì 15:3, 4; Hébérù 9:11-14) Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe fún Jésù láti lo ìtóye ẹbọ ìràpadà rẹ̀ fún àwọn tó jẹ́ tirẹ̀.
Ìwọ yóò ha fẹ́ láti jàǹfààní nínú ọ̀nà ìwonisàn nípa tẹ̀mí, nípa ti ìmọ̀lára, àti ti àìsàn ara yìí bí? Ṣíṣe èyí ń béèrè ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi. O ò ṣe kúkú wá sọ́dọ̀ Oníṣègùn náà fúnra rẹ? O lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù Kristi àti ipa tí ó kó láti gba ìran ènìyàn olóòótọ́ là. Inú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Jésù lágbára láti wo àwọn aláìsàn sàn, ó sì fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Báwo ni ikú Jésù ṣe kàn ọ́?