Ẹ Kó Gbogbo Àníyàn Yín Lé Jehofa
“Ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọrun, kí oun lè gbé yín ga ní àkókò yíyẹ; bí ẹ̀yin ti ń kó gbogbo àníyàn yín lé e, nitori ó ń bìkítà fún yín.”—1 PETERU 5:6, 7, NW.
1. Báwo ni àníyàn ṣe lè nípa lórí wa, ọ̀nà wo sì ni a lè gbà ṣàpèjúwe èyí?
ÀNÍYÀN lè ní ipa jíjinlẹ̀ lórí ìgbésí-ayé wa. A lè fi wé ariwo tí ń ṣèdíwọ́ fún orin dídára kan tí ń tunilára tí a ń gbọ́ lórí redio nígbà mìíràn. Bí ohunkóhun kò bá ṣèdíwọ́ fún ìgbì afẹ́fẹ́ rédíò, a lè gbádùn àwọn orin tí ń tunilára wọ́n sì lè mú ara tuni pẹ̀sẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, dídún kọ̀rọ̀-kọ̀rọ̀ ariwo náà lè yí ìró ohun orin kan tí a nífẹ̀ẹ́ sí jùlọ padà, ní mímú kí a bínú kí a sì nímọ̀lára ìjákulẹ̀. Àníyàn lè ní irú ìyọrísí kan náà lórí ìparọ́rọ́ wa. Ó lè rìn wá mọ́lẹ̀ gan-an débi pé a kò ní lè bójútó àwọn ọ̀ràn ṣíṣekókó. Níti tòótọ́, “[àníyàn, NW] ní àyà ènìyàn níí dorí rẹ kọ odò.”—Owe 12:25.
2. Kí ni Jesu Kristi sọ nípa “awọn àníyàn ìgbésí-ayé”?
2 Jesu Kristi sọ̀rọ̀ nípa ewu tí ń bẹ nínú jíjẹ́ kí àníyàn tí ó rékọjá ààlà pín ọkàn wa níyà. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, ó rọni pé: “Ẹ kíyèsí ara yín kí ọkàn-àyà yín má baà di èyí tí a dẹrùpa pẹlu àjẹjù ati ìmutíyó kẹ́ri ati awọn àníyàn ìgbésí-ayé, lójijì tí ọjọ́ yẹn yoo sì dé bá yín ní ìṣẹ́jú akàn gẹ́gẹ́ bí ìdẹkùn. Nitori yoo dé bá gbogbo awọn wọnnì tí ń gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀-ayé. Ẹ máa wà lójúfò, nígbà naa, ní rírawọ́ ẹ̀bẹ̀ ní gbogbo ìgbà kí ẹ lè kẹ́sẹjárí ní yíyèbọ́ ninu gbogbo nǹkan wọnyi tí a ti yàntẹ́lẹ̀ lati ṣẹlẹ̀, ati ní dídúró níwájú Ọmọkùnrin ènìyàn.” (Luku 21:34-36, NW) Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ pé àjẹjù àti ìmutíyó kẹ́ri lè múni ṣe kántan-kàntan níti èrò-orí, bẹ́ẹ̀ ni dídi ẹni tí a dẹrùpa pẹ̀lú “awọn àníyàn ìgbésí-ayé” lè mú kí ẹnìkan pàdánù agbára ìwòye jíjágeere, pẹ̀lú àwọn ìyọrísí tí ń mú ìbànújẹ́ wá.
Ohun tí Àníyàn Jẹ́
3. Báwo ni a ṣe túmọ̀ “àníyàn,” kí sì ni díẹ̀ lára àwọn okùnfà rẹ̀?
3 “Àníyàn” ni a túmọ̀ sí “àìbalẹ̀ ọkàn tí ó kún fún ìrora tàbí tí ń kọni lóminú tí ó sábà máa ń jẹ́ nítorí àgbákò kan tí ó rọ̀dẹ̀dẹ̀ tàbí tí a ń fojúsọ́nà fún.” Ó jẹ́ “ìdàníyàn tàbí ọkàn-ìfẹ́ tí ó kún fún ìbẹ̀rù” ó sì tún jẹ́ “òye ìmọ̀lára tí kò báradé àti ìkọminú tí ń bonimọ́lẹ̀ ṣíbáṣíbá àti ìbẹ̀rù tí a sábà máa ń sàmìsí nípasẹ̀ àwọn àmì inú ara (bí ìlàágùn, pákáǹleke, àti ìlùkìkì ọkàn-àyà tí ń ga síi), iyèméjì nípa ìjótìítọ́ àti irú ìrọ̀dẹ̀dẹ̀ wàhálà náà, àti nípasẹ̀ iyèméjì nípa agbára ẹni láti kojú rẹ̀.” (Webster’s Ninth New Collegiate Dictionary) Nítorí náà, àníyàn lè jẹ́ ìṣòro kan tí ó díjú. Lára ọ̀pọ̀ àwọn okùnfà rẹ̀ ni àìsàn, ọjọ́ ogbó, ìbẹ̀rù ìwà ọ̀daràn, ìpàdánù iṣẹ́, àti ìdàníyàn fún ire ìdílé ẹni.
4. (a) Kí ni ó dára láti máa rántí nípa àwọn ènìyàn àti àwọn àníyàn wọn? (b) Bí a bá ń ṣàníyàn, kí ni a lè ṣe?
4 Ní kedere, onírúurú ìpele àníyàn ni ó wà, gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ pé onírúurú àwọn ipò tàbí àyíká-ipò ni ó lè fà á. Kìí ṣe gbogbo ènìyàn ní ń hùwàpadà sí ipò kan ní ọ̀nà kan náà. Fún ìdí yìí, ó yẹ kí a mọ̀ pé kódà bí ohun kan kò bá kó ìdààmú bá wa, ó lè jẹ́ okùnfà àníyàn lílekoko fún díẹ̀ lára àwọn ẹlẹgbẹ́ wa olùjọ́sìn Jehofa. Kí ni a lè ṣe bí àníyàn bá dé orí kókó kan tí kò fi ṣeéṣe fún wa mọ́ láti pọkànpọ̀ sórí àwọn òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí ó báramuṣọ̀kan tí ó sì gbádùn mọ́ni? Bí a bá di ẹni ti àníyàn débá débi tí kò fi ṣeéṣe fún wa láti máa rí àwọn àríyànjiyàn nípa ipò ọba-aláṣẹ Jehofa àti ìwàtítọ́ Kristian gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ ńkọ́? Ó lè má ṣeéṣe fún wa láti yí àwọn àyíká ipò wa padà. Kàkà bẹ́ẹ̀, àìní wà fún wa láti wá àwọn kókó Ìwé Mímọ́ tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àníyàn tí kò yẹ èyí tí àwọn ìṣòro gbígbẹgẹ́ nínú ìgbésí-ayé jẹ́ okùnfà fún.
Ìrànlọ́wọ́ Wà Lárọ̀ọ́wọ́tó
5. Báwo ni a ṣe lè hùwà ní ìbámu pẹ̀lú Orin Dafidi 55:22?
5 Nígbà tí àwọn Kristian bá nílò ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí tí a sì di ẹrù-ìnira àníyàn rù wọ́n, wọ́n lè rí ìtùnú láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ó ń pèsè ìtọ́sọ́nà tí ó ṣeé gbáralé ó sì ń fún wa ní ìfọkànbalẹ̀ tí ó pọ̀ pé a kò dáwà gẹ́gẹ́ bí adúróṣinṣin ìránṣẹ́ Jehofa. Fún àpẹẹrẹ, onipsalmu náà Dafidi kọrin pé: “Kó ẹrù rẹ lọ sí ara Oluwa, òun ni yóò sì mú ọ dúró: òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ olódodo kí ó yẹ̀ láé.” (Orin Dafidi 55:22) Báwo ni a ṣe lè hùwà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí? Nípa kíkó gbogbo àwọn àníyàn, ìdààmú ọkàn, ìbẹ̀rù, àti ìjákulẹ̀ wa lé Bàbá wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́. Èyí yóò ṣèrànlọ́wọ́ láti fún wa ní ìmọ̀lára àìléwu àti ìparọ́rọ́ ọkàn-àyà.
6. Gẹ́gẹ́ bí Filippi 4:6, 7 ti wí, kí ni àdúrà lè ṣe fún wa?
6 Àdúrà déédéé látọkànwá ṣe kókó bí a bá níláti kó ẹrù ìnira wa, títíkan gbogbo àníyàn wa pátá, lé Jehofa. Èyí yóò fún wa ní àlàáfíà inú lọ́hùn-ún, nítorí tí aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Ẹ máṣe máa ṣàníyàn nipa ohunkóhun, ṣugbọn ninu ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà ati ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ papọ̀ pẹlu ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ awọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọrun; àlàáfíà Ọlọrun tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yoo sì máa ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn-àyà yín ati agbára èrò-orí yín nípasẹ̀ Kristi Jesu.” (Filippi 4:6, 7, NW) “Àlàáfíà Ọlọrun” tí kò ní àfiwé yìí jẹ́ ìfọkànbalẹ̀ àrà-ọ̀tọ̀ kan tí àwọn olùṣèyàsímímọ́ ìránṣẹ́ Jehofa ń gbádùn nínú àwọn ipò tí ń dánniwò jùlọ pàápàá. Ó ń jẹyọ láti inú ipò ìbátan ara-ẹni tímọ́tímọ́ wa pẹ̀lú Ọlọrun. Bí a ti ń gbàdúrà fún ẹ̀mí mímọ́ tí a sì ń jẹ́ kí ó sún wa ṣiṣẹ́, kìí ṣe pé a ń rí ìtura kúrò nínú gbogbo àwọn ìṣòro ìgbésí-ayé, ṣùgbọ́n a ń gbádùn ìṣùpọ̀ èso tẹ̀mí ti àlàáfíà. (Luku 11:13; Galatia 5:22, 23) Àníyàn kò bò wá mọ́lẹ̀ ṣíbáṣíbá, nítorí tí a mọ̀ pé Jehofa ń mú kí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olùṣòtítọ́ “jókòó ní àìléwu” kì yóò sì jẹ́ kí ohunkóhun tí yóò fa ìpalára wíwà títí lọ fún wa ṣẹlẹ̀.—Orin Dafidi 4:8.
7. Ipa wo ni àwọn Kristian alàgbà lè kó nínú ríràn wá lọ́wọ́ láti kojú àníyàn?
7 Síbẹ̀, bí àníyàn wa bá ń bá a nìṣó ńkọ́, àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ń ṣe àṣàrò lórí Ìwé Mímọ́ tí a sì ń ní ìforítì nínú àdúrà? (Romu 12:12) Àwọn alàgbà tí a yàn sípò nínú ìjọ pẹ̀lú jẹ́ ìpèsè Jehofa láti ràn wá lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. Wọ́n lè tù wá nínú kí wọ́n sì ràn wá lọ́wọ́ nípa lílo Ọ̀rọ̀ Ọlọrun àti nípa gbígbàdúrà pẹ̀lú wa àti fún wa. (Jakọbu 5:13-16) Aposteli Peteru rọ àwọn alàgbà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti ṣe olùṣọ́ àgùtàn agbo Ọlọrun tìfẹ́-inú tìfẹ́-inú, pẹ̀lú ìháragàgà, àti ní ọ̀nà àwòfiṣàpẹẹrẹ. (1 Peteru 5:1-4, NW) Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ní ire wa dídára jùlọ lọ́kàn wọ́n sì fẹ́ láti ṣèrànlọ́wọ́. Àmọ́ ṣáá ó, láti jàǹfààní ní kíkún láti inú ìrànlọ́wọ́ àwọn alàgbà àti kí a ba à lè ṣe dáradára nípa tẹ̀mí nínú ìjọ, àìní wà fún gbogbo wa láti fi ìmọ̀ràn Peteru sọ́kàn pé: “Ẹ̀yin ọ̀dọ́ ọkùnrin, ẹ wà ní ìtẹríba fún awọn àgbà ọkùnrin. Ṣugbọn gbogbo yín ẹ fi ìrẹ̀lẹ̀ èrò-inú di ara yín lámùrè sí ara yín lẹ́nìkínní kejì, nitori Ọlọrun kọ ojú ìjà sí awọn onírera, ṣugbọn ó ń fi inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún awọn onírẹ̀lẹ̀.”—1 Peteru 5:5, NW.
8, 9. Ìtùnú wo ni a lè rí gbà láti inú 1 Peteru 5:6-11?
8 Peteru fikún un pé: “Nitori naa, ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọrun, kí oun lè gbé yín ga ní àkókò yíyẹ; bí ẹ̀yin ti ń kó gbogbo àníyàn yín lé e, nitori ó ń bìkítà fún yín. Ẹ pa awọn agbára ìmòye yín mọ́, ẹ máa kíyèsára. Elénìní yín, Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà lati pa ẹni kan jẹ. Ṣugbọn ẹ mú ìdúró yín lòdì sí i, ní dídúró gbọn-in ninu ìgbàgbọ́, ní mímọ̀ pé awọn ohun kan naa ní ọ̀nà ìyà jíjẹ ni a ń ṣe ní àṣeparí ninu gbogbo ẹgbẹ́ awọn arákùnrin yín ninu ayé. Ṣugbọn, lẹ́yìn tí ẹ bá ti jìyà fún ìgbà díẹ̀, Ọlọrun inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí gbogbo, ẹni tí ó pè yín sí ògo àìnípẹ̀kun rẹ̀ ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu Kristi, yoo fúnra rẹ̀ parí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yín, oun yoo fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in, yoo mú yín lókunlágbára. Oun ni kí agbára ńlá jẹ́ tirẹ̀ títí láé. Àmín.”—1 Peteru 5:6-11, NW.
9 Ẹ wo bí ó ti tuninínú tó láti mọ̀ pé a lè ‘kó gbogbo àníyàn wa lé Ọlọrun nítorí pé ó ń bìkítà fún wa’! Bí díẹ̀ lára àwọn àníyàn wa bá sì jẹ́ ìyọrísí àwọn ìgbìdánwò Eṣu láti ba ipò-ìbátan wa pẹ̀lú Jehofa jẹ́ nípa mímú inúnibíni àti àwọn ìjìyà mìíràn wá sórí wa, kìí ha ṣe ohun àgbàyanu láti mọ̀ pé ohun gbogbo yóò yọrísí rere fún àwọn olùpa ìwàtítọ́ mọ́? Bẹ́ẹ̀ni, lẹ́yìn tí a bá ti jìyà fún ìgbà díẹ̀, Ọlọrun inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí gbogbo yóò parí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wa yóò fí ìdí wa múlẹ̀ gbọn-in yóò sì mú wa lókun.
10. Àwọn ànímọ́ mẹ́ta wo tí 1 Peteru 5:6, 7 mẹ́nubà ni ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú àníyàn fúyẹ́?
10 Peteru Kìn-ín-ní 5:6, 7 (NW) mẹ́nuba àwọn ànímọ́ mẹ́ta tí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àníyàn. Ọ̀kan ni ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn, tàbí “ìrẹ̀lẹ̀ èrò-inú.” Ẹsẹ̀ 6 parí pẹ̀lú gbólóhùn náà “ní àkókò yíyẹ,” tí ń dámọ̀ràn àìní náà fún sùúrù. Ẹsẹ̀ 7 fihàn pé a lè fi ìgbọ́kànlé kó gbogbo àníyàn wa lé Ọlọrun ‘nítorí tí ó ń bìkítà fún wa,’ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn sì fún wa ní ìṣírí láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jehofa. Nítorí náà ẹ jẹ́ kí a wo bí ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn, sùúrù, àti ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Ọlọrun ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú àníyàn fúyẹ́.
Bí Ìrẹ̀lẹ̀-Ọkàn Ṣe Lè Ṣèrànlọ́wọ́
11. Báwo ni ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àníyàn?
11 Bí a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ọkàn, àwa yóò gbà pé èrò Ọlọrun ju tiwa lọ fíìfíì. (Isaiah 55:8, 9) Ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn ń ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ibi tí agbára ìrònú wa mọ ní ìfiwéra pẹ̀lú agbára ìwòye Jehofa tí ó ríran dé ibi gbogbo. Ó ń rí àwọn nǹkan tí àwa kò lè fi òye ronú wọn, gẹ́gẹ́ bí a ti fihàn nínú ọ̀ràn ti Jobu ọkùnrin olódodo nì. (Jobu 1:7-12; 2:1-6) Nípa rírẹ ara wa sílẹ̀ “lábẹ́ ọwọ́ agbára ńlá Ọlọrun,” a ń jẹ́wọ́ ipò rírẹlẹ̀ wa ní ìbámu pẹ̀lú Ọba-Aláṣẹ Onípò Àjùlọ náà. Ní ìdàkejì, èyí ń ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn àyíká ipò tí òun bá yọ̀ọ̀da. Ọkàn-àyà wa lè yánhànhàn fún ìtura ojú-ẹsẹ̀, ṣùgbọ́n níwọ̀n bí àwọn ànímọ́ Jehofa ti wà déédéé lọ́nà pípé pérépéré, ó mọ ìgbà náà ní pàtó tí ó yẹ kí òun gbé ìgbésẹ̀ àti bí ó ṣe yẹ kí òun gbé e nítorí tiwa. Nígbà náà, bí àwọn ọmọ kékeré, ẹ jẹ́ kí a fi ìrẹ̀lẹ̀ rọ̀ mọ́ ọwọ́ agbára ńlá Jehofa, pẹ̀lú ìdánilójú pé òun yóò ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn àníyàn wa.—Isaiah 41:8-13.
12. Bí a bá fi àwọn ọ̀rọ̀ Heberu 13:5 sílò pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn ipa wo ni ó lè ní lórí àníyàn níti àìléwu nípa ohun ti ara?
12 Ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn wémọ́ ìmúratán láti fi ìmọ̀ràn láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sílò, èyí tí ó lè máa fìgbà gbogbo dín àníyàn kù. Fún àpẹẹrẹ, bí àníyàn wa bá ti jẹ́ ìyọrísí rírì tí a ri ara wa bọ inú àwọn ìlépa ohun ti ara, a lè ṣe dáradára láti ronú lórí ìmọ̀ràn Paulu pé: “Kí ọ̀nà ìgbésí-ayé yín wà láìsí ìfẹ́ owó, bí ẹ ti ń ní ìtẹ́lọ́rùn pẹlu awọn nǹkan ìsinsìnyí. Nitori [Ọlọrun] ti wí pé: ‘Dájúdájú emi kì yoo fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tabi ṣá ọ tì lọ́nàkọnà.’” (Heberu 13:5, NW) Nípa fífi ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn fi irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ sílò, ọ̀pọ̀ ti sọ ara wọn di òmìnira kúrò lọ́wọ́ àníyàn púpọ̀ níti àìléwu nípa ohun ti ara. Nígbà tí ó jẹ́ pé ipò wọn níti ọ̀ràn ìnáwó lè ṣaláì tíì sunwọ̀n síi, kò gba gbogbo ìrònú wọn ní ṣíṣokùnfà ìpalára wọn nípa tẹ̀mí.
Ipa tí Sùúrù Ń Kó
13, 14. (a) Níti ìfaradà tí ń bá sùúrù rìn, àpẹẹrẹ wo ni ọkùnrin náà Jobu pèsè? (b) Kí ni fífi sùúrù dúró de Jehofa lè ṣe fún wa?
13 Gbólóhùn náà “ní àkókò yíyẹ” nínú 1 Peteru 5:6 dámọ̀ràn àìní náà fún ìfaradà tí ń bá sùúrù rìn. Ní àwọn ìgbà mìíràn ìṣòro kan lè máa bá a nìṣó fún àkókò gígùn, ìyẹn sì lè mú kí àníyàn pọ̀ síi. Ní ìgbà yẹn gan-an ni ó yẹ kí a fi ọ̀ràn lé Jehofa lọ́wọ́. Ọmọ-ẹ̀yìn náà Jakọbu kọ̀wé pé: “Awọn wọnnì tí wọ́n lo ìfaradà ní a ń pè ní aláyọ̀. Ẹ ti gbọ́ nipa ìfaradà Jobu ẹ sì ti rí àbárèbábọ̀ tí Jehofa mú wá, pé Jehofa jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi ninu ìfẹ́ni ó sì jẹ́ aláàánú.” (Jakọbu 5:11, NW) Jobu ní ìrírí ọrọ̀-ajé tí ó wọmi, àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́wàá kú, ó jìyà òkùnrùn tí ń kóninírìíra, àwọn olùtùnú èké sì dẹ́bi fún un lọ́nà òdì. Ó kérétán àníyàn díẹ̀ yóò jẹ́ ohun yíyẹ lábẹ́ irúfẹ́ àwọn àyíká ipò bẹ́ẹ̀.
14 Lọ́nàkọnà, Jobu jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ níti ìfaradà tí ń bá sùúrù rìn. Bí a bá ń ní ìrírí ìdánwò ìgbàgbọ́ lílekoko, ó lè béèrè pé kí a dúró de ìtura, àní gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe. Ṣùgbọ́n Ọlọrun gbé ìgbésẹ̀ nítorí tirẹ̀, ní mímú kí Jobu rí ìtura gbà kúrò nínú ìjìyà rẹ̀ àti sísan èrè fún un lọ́pọ̀ yanturu ní àṣẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀. (Jobu 42:10-17) Fífi sùúrù dúró de Jehofa ń mú kí sùúrù wa gbèrú ó sì ń ṣípayá bí ìfọkànsìn wa sí i ṣe jinlẹ̀ tó.—Jakọbu 1:2-4.
Ní Ìgbẹ́kẹ̀lé Nínú Jehofa
15. Èéṣe tí a fi níláti ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jehofa?
15 Peteru rọ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti ‘kó gbogbo àníyàn wọn lé Ọlọrun nítorí tí ó bìkítà fún wọn.’ (1 Peteru 5:7, NW) Àwa pẹ̀lú lè ṣe bẹ́ẹ̀ ó sì yẹ kí a ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jehofa. Owe 3:5, 6 sọ pé: “Fi gbogbo àyà rẹ gbẹ́kẹ̀lé Oluwa; má sì ṣe tẹ̀ sí ìmọ̀ ara rẹ. Mọ̀ ọ́n ní gbogbo ọ̀nà rẹ: òun ó sì máa tọ́ ipa-ọ̀nà rẹ.” Nítorí àwọn ìrírí àtẹ̀yìnwá, àwọn kan tí wọ́n kún fún àníyàn rí i pé ó ṣòro láti gbẹ́kẹ̀lé àwọn ẹ̀dá ènìyàn mìíràn. Ṣùgbọ́n a ní ìdí púpọ̀ láti gbẹ́kẹ̀lé Ẹlẹ́dàá wa, Orísun àti Olùgbé ìwàláàyè wa gan-an ró. Kódà bí a kò bá ní ìgbẹ́kẹ̀lẹ́ nínú ọ̀nà tí a gbà hùwà padà nínú ọ̀ràn pàtó kan, a lè máa gbáralé Jehofa nígbà gbogbo láti gbà wá kúrò nínú àwọn àjálù-ibi wa.—Orin Dafidi 34:18, 19; 36:9; 56:3, 4.
16. Kí ni Jesu Kristi sọ nípa àníyàn lórí àwọn ohun ti ara?
16 Níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọrun wémọ́ ṣíṣègbọràn sí Ọmọkùnrin rẹ̀, Jesu Kristi, tí ó fi ohun tí ó kọ́ lọ́dọ̀ Bàbá rẹ̀ kọ́ni. (Johannu 7:16) Jesu rọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti “to awọn ìṣúra jọ pamọ́ . . . ní ọ̀run” nípa ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa. Ṣùgbọ́n àwọn àìní nípa ti ara tí wọ́n wémọ́ oúnjẹ, aṣọ, àti ibùgbé ńkọ́? Jesu gbani nímọ̀ràn pé: “Ẹ dẹ́kun ṣíṣàníyàn.” Ó ṣàlàyé pé Ọlọrun ń bọ́ àwọn ẹyẹ. Ó ń wọ àwọn òdòdó láṣọ lọ́nà rírẹwà. Àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun tí wọ́n jẹ́ ènìyàn kò ha níyelórí jú àwọn wọ̀nyí lọ bí? Dájúdájú wọn níyelórí jù wọ́n lọ. Nítorí náà, Jesu rọni pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà naa, ní wíwá ìjọba naa ati òdodo [Ọlọrun] lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọnyi ni a óò sì fikún un fún yín.” Jesu ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ nìṣó pé: “Nitori naa, ẹ máṣe ṣàníyàn láé nipa ọ̀la, nitori ọ̀la yoo ní awọn àníyàn tirẹ̀.” (Matteu 6:20, 25-34, NW) Bẹ́ẹ̀ni, a nílò oúnjẹ, omi, aṣọ, àti ibùgbé, ṣùgbọ́n bí a bá ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jehofa, àwa kò ní máa ṣàníyàn tí kò yẹ nípa àwọn nǹkan wọ̀nyí.
17. Báwo ni a ṣe lè ṣàpèjúwe àìní náà láti wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ̀?
17 Láti wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́, a gbọ́dọ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọrun kí a sì jẹ́ kí àwọn ohun tí ó gba ipò iwájú fún wa wà ní ààyè tí ó yẹ. Amòòkùn kan tí kò ní ohun èlò tí a fi ń mí lè bẹ́ sómi kí ó sì lọ sí ìsàlẹ̀ ní wíwá ìsán tí ó ní péálì nínú. Èyí ni ọ̀nà ìgbà gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ̀. Nítòótọ́, èyí jẹ́ ohun tí ó gba ipò iwájú lọ́nà gíga! Ṣùgbọ́n kí ni ó ṣe pàtàkì ju ìyẹn lọ? Afẹ́fẹ́! Ó gbọ́dọ̀ máa yọ orí jáde nínú omi déédéé láti lè fi afẹ́fẹ́ kún inú ẹ̀dọ̀fóró rẹ̀. Afẹ́fẹ́ jẹ́ ohun tí ó gbà ipò iwájú lọ́nà gíga jù. Bákan náà, ó lè dàbí ẹni pé a ti mú ọwọ́ wa dí lọ́nà kan ṣá nínú ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí kí a baà lè ní àwọn ohun kòṣeémánìí ìgbésí-ayé. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn ọ̀ràn tẹ̀mí gbọ́dọ̀ wà ní ipò àkọ́kọ́ nítorí pé ìgbésí-ayé ìdílé wa gan-an sinmi lé orí àwọn nǹkan wọ̀nyí. Láti yẹra fún níní àníyàn tí kò yẹ lórí àwọn àìní ti ara, a gbọ́dọ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Ọlọrun. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ‘níní púpọ̀ rẹpẹtẹ lati ṣe ninu iṣẹ́ Oluwa’ lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú àníyàn fúyẹ́ bí “ayọ̀ Oluwa” tí ń jásí odi-agbára wa.—1 Korinti 15:58, NW; Nehemiah 8:10.
Ẹ Máa Bá A Nìṣó ní Kíkó Àníyàn Yín Lé Jehofa
18. Ẹ̀rí wo ni ó wà níbẹ̀ pé kíkó gbogbo àníyàn wa lé Jehofa lè ràn wá lọ́wọ́ nítòótọ́?
18 Láti jẹ́ kí ojú wa máa wo ọ̀kánkán gan-an ní rekete nípa tẹ̀mí, a gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó ní kíkó gbogbo àníyàn wa lé Jehofa. Ẹ máa rántí nígbà gbogbo pé nítòótọ́ ni ó ń bìkítà nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Láti ṣàpèjúwe: Nítorí pé ọkọ rẹ̀ kò jẹ́ olóòótọ́ sí i, àníyàn Kristian obìnrin kan pọ̀ síi dé orí kókó náà tí ó fi jẹ́ pé kò ṣeéṣe fún un láti sùn. (Fiwé Orin Dafidi 119:28.) Bí ó ti wù kí ó rí, lórí ibùsùn òun yóò kó gbogbo àníyàn rẹ̀ lé Jehofa. Òun yóò ṣípayá ohun tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà rẹ̀ fún Ọlọrun, ní sísọ fún un nípa ìrora náà tí òun àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjì ń jìyà rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó bá ti fi àdúrà onígbòóná ọkàn ké jáde fún ìtura, ó sábà máa ń ṣeéṣe fún un láti sùn, nítorí tí ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Jehofa yóò bójútó òun àti àwọn ọmọ òun. Obìnrin tí ó ṣe ìkọ̀sílẹ̀ lọ́nà tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu yìí ti kówọnú ìgbéyàwó aláyọ̀ pẹ̀lú alàgbà kan báyìí.
19, 20. (a) Kí ni àwọn ọ̀nà díẹ̀ tí a lè gbà kojú àníyàn? (b) Kí ni a níláti máa bá a nìṣó láti ṣe nípa gbogbo àníyàn wa?
19 Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Jehofa, a ní onírúurú ọ̀nà tí a lè gbà kojú àníyàn. Fífi Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sílò máa ń rannilọ́wọ́ ní pàtàkì. A ní oúnjẹ tẹ̀mí dídọ́ṣọ̀ tí Ọlọrun ń pèsè nípasẹ̀ “olùṣòtítọ́ ati ọlọ́gbọ́n-inú ẹrú” náà, títíkan àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ń rannilọ́wọ́ tí wọ́n sì ń tunilára tí a ń tẹ̀ jáde nínú Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! (Matteu 24:45-47, NW) A ní ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun. Àdúrà onígbòóná ọkàn tí a ń gbà déédéé ń ṣàǹfààní fún wa gidigidi. Àwọn Kristian alàgbà tí a yàn sípò wà ní sẹpẹ́ wọ́n sì múratán láti pèsè ìrànlọ́wọ́ àti ìtùnú tẹ̀mí.
20 Ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn àti sùúrù tiwa ń ṣàǹfààní gidigidi fún kíkojú àníyàn tí ó lè máa dààmú wa. Èyí tí ó ṣe pàtàkì jùlọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jehofa, nítorí pé ìgbàgbọ́ wa ni a ń gbéró bí a ti ń ní ìrírí ìrànlọ́wọ́ àti ìdarísọ́nà rẹ̀. Ní ìdàkejì, ìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun lè pa wá mọ́ kúrò nínú dídi ẹni tí ń dààmú láìyẹ. (Johannu 14:1) Ìgbàgbọ́ ń ta wá jí láti wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́ àti láti mú ọwọ́ wa dí nínú iṣẹ́ aláyọ̀ ti Oluwa, èyí tí ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àníyàn. Irúfẹ́ ìgbòkègbodò bẹ́ẹ̀ ń mú kí a ní ìmọ̀lára àìléwu láàárín àwọn wọnnì tí yóò kọrin ìyìn Ọlọrun títí ayérayé. (Orin Dafidi 104:33) Nítorí náà ẹ jẹ́ kí a máa bá a nìṣó ní kíkó gbogbo àníyàn wa lé Jehofa.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùnpadà?
◻ Báwo ni a ṣe lè túmọ̀ àníyàn?
◻ Kí ni díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí a lè gbà kojú àníyàn?
◻ Báwo ni ìrẹ̀lẹ̀-ọkàn àti sùúrù ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti mú àníyàn fúyẹ́?
◻ Ní kíkojú àníyàn, èéṣe tí ó fi ṣe kókó láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jehofa?
◻ Èéṣe tí a fi níláti máa bá a nìṣó ní kíkó gbogbo àníyàn wa lé Jehofa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ǹjẹ́ o mọ ìdí rẹ̀ tí Jesu fi wí pé, “Ẹ dẹ́kun ṣíṣàníyàn”?