ORÍ 98
Àwọn Àpọ́sítélì Tún ń wá Ipò Ọlá
MÁTÍÙ 20:17-28 MÁÀKÙ 10:32-45 LÚÙKÙ 18:31-34
JÉSÙ TÚN SỌ̀RỌ̀ NÍPA IKÚ RẸ̀
JÉSÙ KỌ́ ÀWỌN ỌMỌ Ẹ̀YÌN RẸ̀ LÁTI MÁ ṢE MÁA WÁ IPÒ ỌLÁ
Lẹ́yìn tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe tán ní Pèríà, wọ́n sọdá Odò Jọ́dánì nítòsí Jẹ́ríkò, wọ́n sì forí lé Jerúsálẹ́mù láti lọ ṣe Àjọyọ̀ Ìrékọjá ti ọdún 33 S.K. Kì í ṣe àwọn nìkan ló ń lọ sí Jerúsálẹ́mù, àwọn míì náà wà pẹ̀lú wọn.
Torí pé Jésù fẹ́ tètè dé síbi àjọyọ̀ náà, ṣe ló ń lọ kánmọ́kánmọ́ níwájú àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀. Àmọ́ ṣe làwọn ń fà sẹ́yìn torí pé ẹ̀rù ń bà wọ́n. Ẹ rántí pé nígbà tí Lásárù kú, tí Jésù ń múra àti kúrò ní Pèríà lọ sí Jùdíà, Tọ́másì sọ fáwọn tó kù pé: “Ẹ jẹ́ kí àwa náà lọ, ká lè bá a kú.” (Jòhánù 11:16, 47-53) Torí náà, ó léwu gan-an bí wọ́n ṣe fẹ́ lọ sí Jerúsálẹ́mù, kò sì yani lẹ́nu pé ẹ̀rù ba àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà.
Kí Jésù lè múra ọkàn wọn sílẹ̀ de ohun tó máa ṣẹlẹ̀, ó pè wọ́n sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó sì sọ fún wọn pé: “À ń gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì máa fa Ọmọ èèyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin lọ́wọ́. Wọ́n máa dájọ́ ikú fún un, wọ́n sì máa fà á lé àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́ kí wọ́n lè fi ṣe yẹ̀yẹ́, kí wọ́n nà án, kí wọ́n sì kàn án mọ́gi; a sì máa jí i dìde ní ọjọ́ kẹta.”—Mátíù 20:18, 19.
Ìgbà kẹta nìyí tí Jésù máa sọ̀rọ̀ nípa ikú àti àjíǹde rẹ̀ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀. (Mátíù 16:21; 17:22, 23) Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, ó dìídì sọ fún wọn pé wọ́n máa kan òun mọ́gi. Wọ́n gbọ́ ohun tó sọ, àmọ́ kò yé wọn. Bóyá wọ́n ń retí pé kí Jésù dá ìjọba Ísírẹ́lì pa dà, káwọn lè máa gbádùn ògo àti ọlá nínú Ìjọba yẹn láyé.
Sàlómẹ̀ tó jẹ́ ìyá méjì lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, ìyẹn Jémíìsì àti Jòhánù náà wà pẹ̀lú àwọn tó ń rìnrìn àjò yẹn. Ìgbà kan wà tí Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn méjèèjì yìí ní orúkọ kan tó túmọ̀ sí “Àwọn Ọmọ Ààrá,” bóyá torí ìtara wọn tó múná. (Máàkù 3:17; Lúùkù 9:54) Ó ṣe díẹ̀ táwọn méjèèjì ti ń wá ipò ọlá nínú Ìjọba Kristi, ìyá wọn sì mọ̀ bẹ́ẹ̀. Ó wá lọ bá Jésù, ó kúnlẹ̀ síwájú rẹ̀, ó sì ń bẹ̀ ẹ́ pé kó fojúure hàn sáwọn ọmọ òun. Jésù bi í pé: “Kí lo fẹ́?” Ó wá sọ pé: “Pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ mi méjèèjì yìí jókòó, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ àti ọ̀kan ní òsì rẹ, nínú Ìjọba rẹ.”—Mátíù 20:20, 21.
Ó dájú pé Jémíìsì àti Jòhánù ló rán ìyá wọn sí Jésù. Pẹ̀lú ohun tí Jésù ti sọ fún wọn tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn máa fìyà jẹ òun, wọ́n á sì pa òun ní ìpa ìkà, ó wá sọ fún wọn pé: “Ẹ ò mọ ohun tí ẹ̀ ń béèrè. Ṣé ẹ lè mu ife tí mo máa tó mu?” Wọ́n dáhùn pé: “A lè mu ún.” (Mátíù 20:22) Síbẹ̀ náà, ó hàn pé wọn ò lóye ohun tíyẹn túmọ̀ sí fún wọn.
Àmọ́ Jésù sọ fún wọn pé: “Ó dájú pé ẹ máa mu ife mi, àmọ́ èmi kọ́ ló máa sọ ẹni tó máa jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún mi àti sí òsì mi, ṣùgbọ́n ó máa wà fún àwọn tí Baba mi ti ṣètò rẹ̀ fún.”—Mátíù 20:23.
Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn mẹ́wàá tó kù gbọ́ nípa ohun tí wọ́n ń béèrè, inú bí wọn. Ṣé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohùn Jémíìsì àti Jòhánù ló le jù nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn ń jiyàn nípa ẹni tó tóbi jù? (Lúùkù 9:46-48) Èyí ó wù ó jẹ́, ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí fi hàn pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kò tíì fi ohun tó kọ́ wọn sílò pé kí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Ó ṣe kedere pé wọ́n ṣì ń wá ipò ọlá.
Jésù wá ọ̀nà láti kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ kí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí má bàa da àárín wọn rú. Ó wá pe àwọn Méjìlá náà sọ́dọ̀, ó sì gbà wọ́n níyànjú pé: “Ẹ mọ̀ pé àwọn tí wọ́n kà sí àwọn alákòóso orílẹ̀-èdè máa ń jẹ ọ̀gá lé àwọn èèyàn lórí, àwọn èèyàn ńlá wọn sì máa ń lo àṣẹ lórí wọn. Kò gbọ́dọ̀ rí bẹ́ẹ̀ láàárín yín; àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ di ẹni ńlá láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ìránṣẹ́ yín, ẹnikẹ́ni tó bá sì fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹrú gbogbo yín.”—Máàkù 10:42-44.
Jésù wá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àpẹẹrẹ òun ló yẹ kí wọ́n tẹ̀ lé. Ó sọ pé: “Ọmọ èèyàn ò . . . wá ká lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, àmọ́ kó lè ṣe ìránṣẹ́, kó sì fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.” (Mátíù 20:28) Ó ti tó bí ọdún mẹ́ta báyìí tí Jésù ti ń wàásù, tó sì ń lo ara rẹ̀ fún àwọn èèyàn. Kódà, ó ṣì máa fi ẹ̀mí ẹ̀ lélẹ̀ fún aráyé! Irú ẹ̀mí yìí kan náà ló yẹ káwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní, kí wọ́n ṣe tán láti ṣèránṣẹ́ fáwọn míì, dípò káwọn míì ṣèránṣẹ́ fún wọn, kí wọ́n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, dípò kí wọ́n máa wá ipò ọlá.