Ó Yẹ Kí Èèyàn Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Inú Rere
“Kí . . . ni ohun tí Jèhófà ń béèrè láti ọ̀dọ̀ rẹ bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo, kí o sì nífẹ̀ẹ́ inú rere, kí o sì jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn?”—MÍKÀ 6:8.
1, 2. (a) Kí nìdí tí kò fi yà wá lẹ́nu pé Jèhófà fẹ́ káwọn èèyàn rẹ̀ máa fi inú rere hàn? (b) Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká gbé yẹ̀ wò nípa inú rere?
ỌLỌ́RUN onínúure ni Jèhófà. (Róòmù 2:4; 11:22) Ádámù àti Éfà tí wọ́n jẹ́ tọkọtaya àkọ́kọ́ ti ní láti mọyì ìyẹn gan-an! Àwọn ìṣẹ̀dá tó ṣeé fojú rí ló yí wọn ká nínú ọgbà Édẹ́nì, èyí sì fi hàn pé Ọlọ́run ní inú rere sí àwọn ẹ̀dá èèyàn tó láǹfààní àtigbádùn àwọn ìṣẹ̀dá yìí. Ọlọ́run sì ń fi inú rere yìí hàn sí gbogbo èèyàn di bá a ti ń wí yìí, kódà ó ń fi hàn sí àwọn aláìmoore àti àwọn ẹni ibi pàápàá.
2 Dídá tí a dá ènìyàn ní àwòrán Ọlọ́run mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti gbé àwọn ànímọ́ Ọlọ́run yọ. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Abájọ tí Jèhófà fi retí pé kí á máa fi inú rere hàn. Gẹ́gẹ́ bí Míkà 6:8 ṣe sọ, àwọn èèyàn Ọlọ́run ní láti “nífẹ̀ẹ́ inú rere.” Àmọ́ kí ni inú rere? Báwo ló ṣe wé mọ́ àwọn ànímọ́ mìíràn tí Ọlọ́run ní? Nígbà tó jẹ́ pé èèyàn lè fi inú rere hàn, kí wá nìdí tí ayé yìí fi jẹ́ ibi burúkú tó ṣòroó gbé? Kí nìdí tó fi yẹ kí àwa tá a jẹ́ Kristẹni gbìyànjú láti máa fi inú rere hàn nínú àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn?
Kí Ni Inú Rere?
3. Báwo ni wàá ṣe ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà inú rere?
3 A máa ń fi inú rere hàn nípa fífi gbogbo ọkàn wá ire àwọn ẹlòmíràn. Ó máa ń fara hàn nínú bá a ṣe ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ àti bá a ṣe ń bá wọn sọ ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé a gba tiwọn rò. Jíjẹ́ onínúure túmọ̀ sí kéèyàn máa ṣe rere dípò kó máa ṣe ohunkóhun tó lè pa ẹlòmíràn lára. Onínúure èèyàn máa ń kóni mọ́ra, ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́, ó lẹ́mìí ìbánikẹ́dùn, ó sì máa ń ṣoore. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ jẹ́ ọ̀làwọ́, ó sì ní ẹ̀mí ìgbatẹnirò fún àwọn ẹlòmíràn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwa Kristẹni pé: “Ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú, inú rere, ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ìwà tútù, àti ìpamọ́ra wọ ara yín láṣọ.” (Kólósè 3:12) Nítorí náà, inú rere wà lára aṣọ ìṣàpẹẹrẹ tí gbogbo Kristẹni tòótọ́ ń wọ̀.
4. Báwo ni Jèhófà ṣe mú ipò iwájú nínú fífi inú rere hàn sí aráyé?
4 Jèhófà Ọlọ́run mú ipò iwájú nínú fífi inú rere hàn. Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ, èyí jẹ́ nígbà tí “inú rere àti ìfẹ́ fún ènìyàn níhà ọ̀dọ̀ Olùgbàlà wa, Ọlọ́run, di èyí tí a fi hàn kedere” pé “ó gbà wá là nípasẹ̀ ìwẹ̀ tí ó mú wa wá sí ìyè àti nípa sísọ wa di tuntun nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́.” (Títù 3:4, 5) Ọlọ́run fi ẹ̀jẹ̀ Jésù ‘wẹ’ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tàbí pé ó fi í sọ wọ́n di mímọ́ tónítóní, tó túmọ̀ sí pé ó lo àǹfààní ẹbọ ìràpadà Kristi fún wọn. Ó tún sọ wọ́n di tuntun nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́, wọ́n sì di “ìṣẹ̀dá tuntun” gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Ọlọ́run tí a fi ẹ̀mí bí. (2 Kọ́ríńtì 5:17) Kò tán síbẹ̀ o, Ọlọ́run tún fi inú rere hàn sí “ogunlọ́gọ̀ ńlá,” tí wọ́n ti “fọ aṣọ wọn, tí wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.”—Ìṣípayá 7:9, 14; 1 Jòhánù 2:1, 2.
5. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń darí máa fi inú rere hàn sí àwọn ẹlòmíràn?
5 Inú rere tún wà lára èso ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run tàbí ipá ìṣiṣẹ́ rẹ̀. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Èso ti ẹ̀mí ni ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu. Kò sí òfin kankan lòdì sí irú nǹkan báwọ̀nyí.” (Gálátíà 5:22, 23) Nítorí náà, ǹjẹ́ kò yẹ kí àwọn tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń darí máa fi inú rere hàn sí àwọn ẹlòmíràn?
Inú Rere Tòótọ́ Kì Í Ṣe Ìwà Òmùgọ̀
6. Ìgbà wo ni inú rere jẹ́ ìwà òmùgọ̀, kí sì nìdí?
6 Àwọn kan ka inú rere sí ìwà òmùgọ̀. Wọ́n gbà pé ó yẹ kéèyàn le koko, àní kó tiẹ̀ hùwà àrífín síni nígbà mìíràn, káwọn èèyàn lè mọ̀ pé kò gba gbẹ̀rẹ́. Àmọ́, ká sọ tòótọ́, ó gba ìsapá gidi kéèyàn tó lè jẹ́ onínúure, kó sì yẹra fún fífi inú rere tí kò tọ́ hàn. Níwọ̀n bí inú rere tòótọ́ ti jẹ́ ara èso ẹ̀mí Ọlọ́run, kò lè jẹ́ ẹ̀mí ìgbọ̀jẹ̀gẹ́ tó ń gbójú fo ìwà búburú dá. Àmọ́, inú rere tí kò tọ́ ni tiẹ̀ jẹ́ ìwà òmùgọ̀ tó ń mú kéèyàn gba ìwà ibi láyè.
7. (a) Báwo ni Élì ṣe gbọ̀jẹ̀gẹ́? (b) Kí nìdí tí àwọn alàgbà fi gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún fífi inú rere tí kò tọ́ hàn?
7 Bí àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn Élì tó jẹ́ àlùfáà àgbà ni Ísírẹ́lì yẹ̀ wò. Ó gbọ̀jẹ̀gẹ́, kò bá àwọn ọmọ rẹ̀ wí, ìyẹn Hófínì àti Fíníhásì tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ àlùfáà nínú àgọ́ ìjọsìn. Ohun tí Òfin Ọlọ́run sọ pè ó jẹ́ tiwọn lára àwọn ẹran táwọn èèyàn wá fi rúbọ kò tẹ́ wọn lọ́rùn, wọ́n ní kí ìránṣẹ́ kan máa gba ẹran tútù lọ́wọ́ ẹni tó wá rúbọ kó tó di pé wọ́n mú kí ọ̀rá ẹran náà rú èéfín lórí pẹpẹ. Àwọn ọmọ Élì tún ń bá àwọn obìnrin tó ń sìn ní àbáwọlé àgọ́ ìjọsìn ṣèṣekúṣe. Àmọ́, dípò kí Élì gba iṣẹ́ lọ́wọ́ Hófínì àti Fíníhásì, ńṣe ló rọra ń bá wọn wí. (1 Sámúẹ́lì 2:12-29) Abájọ tí “ọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà . . . ṣọ̀wọ́n ní ọjọ́ wọnnì”! (1 Sámúẹ́lì 3:1) Àwọn Kristẹni alàgbà gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kí wọ́n má bàa di ẹni tó ń fi inú rere tí kò tọ́ hàn sí àwọn oníwà àìtọ́ tó lè fi ipò tẹ̀mí ìjọ sínú ewu. Inú rere tẹ̀mí kì í gbójú fo àwọn ọ̀rọ̀ búburú dá, bẹ́ẹ̀ ni kì í gba àwọn ìwà tó lòdì sí ìlànà Ọlọ́run láyè.
8. Báwo ni Jésù ṣe fi inú rere tòótọ́ hàn?
8 Jésù Kristi tó jẹ́ Àwòfiṣàpẹẹrẹ wa kò fi inú rere tí kò tọ́ hàn rí. Òun ni ẹni tó fi inú rere tòótọ́ hàn jù lọ. Bí àpẹẹrẹ, ‘ó fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn sí àwọn ènìyàn nítorí pé a bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.’ Àwọn olóòótọ́ ọkàn ò bẹ̀rù láti sún mọ́ Jésù, kódà wọ́n gbé àwọn ọmọ wọn kéékèèké wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Ìwọ ronú nípa inú rere àti àánú tó fi hàn nígbà ‘tó gbé àwọn ọmọ náà sí apá rẹ̀, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí súre fún wọn.’ (Mátíù 9:36; Máàkù 10:13-16) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé onínúure ni Jésù, síbẹ̀ kò fọwọ́ kékeré mú ohun tí ó tọ́ lójú Baba rẹ̀ ọ̀run. Jésù ò gbójú fo ìwà ibi dá rí; ó lo ìgboyà tí Ọlọ́run fún un láti fi àwọn alágàbàgebè aṣáájú ìsìn bú. Gẹ́gẹ́ bí Mátíù 23:13-26 ṣe sọ, ọ̀pọ̀ ìgbà ló ń sọ ní àsọtúnsọ pé: “Ègbé ni fún yín, ẹ̀yin akọ̀wé òfin àti ẹ̀yin Farisí, alágàbàgebè!”
Inú Rere Àtàwọn Ànímọ́ Mìíràn Tí Ẹ̀mí Ọlọ́run Ń Mú Jáde
9. Báwo ni inú rere ṣe wé mọ́ ìpamọ́ra àti ìwà rere?
9 Inú rere wé mọ́ àwọn ànímọ́ mìíràn tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń mú jáde. Níbi tá a ti sọ̀rọ̀ èso ti ẹ̀mí, àárín “ìpamọ́ra” àti “ìwà rere” ni inú rere wà. Ní ti tòótọ́, ẹni tó bá ní inú rere á máa fi ànímọ́ yẹn hàn nípa lílo ìpamọ́ra. Kódà, á máa mú sùúrù fáwọn tí ìwà wọn burú. Inú rere wé mọ́ ìwà rere ní ti pé ó sábà máa ń hàn nínú àwọn iṣẹ́ ìrànwọ́ fún àǹfààní àwọn ẹlòmíràn. Ìgbà mìíràn wà tá a lè túmọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Bíbélì lò fún “inú rere” sí “ìwà rere.” Àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ fi ànímọ́ yìí hàn débi pé ó ya àwọn kèfèrí lẹ́nu gan-an tí wọ́n fi pe àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní ‘àwọn èèyàn tó ní inú rere jù lọ’ gẹ́gẹ́ bí Tertullian ti sọ.
10. Báwo ni inú rere àti ìfẹ́ ṣe so pọ̀ mọ́ra wọn?
10 Ìsopọ̀ kan wà láàárín inú rere àti ìfẹ́. Ohun tí Jésù sọ nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Ohun tí Pọ́ọ̀lù sì sọ nípa ìfẹ́ yìí ni pé: “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra àti inú rere.” (1 Kọ́ríńtì 13:4) Inú rere àti ìfẹ́ tún wọnú ara wọn nínú ọ̀rọ̀ náà “inú rere onífẹ̀ẹ́” tí Ìwé Mímọ́ sábà máa ń lò. Èyí ni inú rere tó wá látinú ìfẹ́ dídúróṣinṣin. Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a túmọ̀ sí “inú rere onífẹ̀ẹ́” ní ìtumọ̀ tó ré kọjá ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́. Ó jẹ́ oríṣi inú rere tó máa ń rọ̀ mọ́ ohun kan tìfẹ́tìfẹ́, tí kò sì ní dẹ̀yìn títí ó fi máa mú ìdí tó fi rọ̀ mọ́ ohun náà ṣẹ. Jèhófà máa ń fi inú rere onífẹ̀ẹ́ tó ní, tàbí ìfẹ́ dídúróṣinṣin rẹ̀ hàn ní onírúurú ọ̀nà. Bí àpẹẹrẹ, a rí i nínú ọ̀nà tó gbà ń dáni nídè àti bó ṣe ń dáàbò boni.—Sáàmù 6:4; 40:11; 143:12.
11. Ìdánilójú wo ni inú rere onífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run jẹ́ kí á ní?
11 Inú rere onífẹ̀ẹ́ Jèhófà ń mú kí àwọn èèyàn sún mọ́ ọn. (Jeremáyà 31:3) Nígbà táwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run bá nílò ìdáǹdè tàbí ìrànlọ́wọ́, wọ́n mọ̀ dájú pé ó máa fi inú rere onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ hàn sí àwọn. Kò ní já wọn kulẹ̀. Nítorí náà, wọ́n lè fi ìgbàgbọ́ gbàdúrà bíi ti onísáàmù tó sọ pé: “Ní tèmi, inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé; jẹ́ kí ọkàn-àyà mi kún fún ìdùnnú nínú ìgbàlà rẹ.” (Sáàmù 13:5) Níwọ̀n bí ìfẹ́ Ọlọ́run ti jẹ́ èyí tó dúró ṣinṣin, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lè gbẹ́kẹ̀ lé e pátápátá. Ó dá wọn lójú pé: “Jèhófà kì yóò ṣá àwọn ènìyàn rẹ̀ tì, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi ogún tirẹ̀ sílẹ̀.”—Sáàmù 94:14.
Kí Nìdí Tí Ayé Fi Kún fún Ìwà Òǹrorò Tó Bẹ́ẹ̀?
12. Ìgbà wo ni ìṣàkóso tó ń fojú àwọn èèyàn gbolẹ̀ bẹ̀rẹ̀, báwo ló sì ṣe bẹ̀rẹ̀?
12 Ìdáhùn sí ìbéèrè yìí ní í ṣe pẹ̀lú ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọgbà Édẹ́nì. Kò pẹ́ sígbà tá a dá ènìyàn sórí ilẹ̀ ayé ni ẹ̀dá ẹ̀mí kan tó ti di onímọtara-ẹni-nìkan, tó sì tún jẹ́ agbéraga bẹ̀rẹ̀ sí pète bí òun ṣe máa di alákòóso ayé. Ohun tí ìwéwèé rẹ̀ yìí wá yọrí sí ni pé ó di “olùṣàkóso ayé” lóòótọ́, àní alákòóso tó ń fojú àwọn èèyàn gbolẹ̀. (Jòhánù 12:31) Ó di ẹni tá a wá mọ̀ sí Sátánì Èṣù, òun ni olórí àwọn tó ń ta ko Ọlọ́run àti ènìyàn. (Jòhánù 8:44; Ìṣípayá 12:9) Láìpẹ́ sígbà tá a dá Éfà, àṣírí ọ̀tẹ̀ onímọtara-ẹni-nìkan tí Sátánì di tú síta, ìyẹn ọ̀tẹ̀ tó dì láti gbé ìṣàkóso kan kalẹ̀ kó lè máa bá ìṣàkóso onínúure ti Jèhófà figa gbága. Nípa bẹ́ẹ̀, ìṣàkóso búburú bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Ádámù yàn láti kúrò lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run, tó kọ inú rere Rẹ̀ sílẹ̀ pátápátá. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6) Dípò kí Ádámù àti Éfà máa ṣàkóso ara wọn, Èṣù tó jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan àti agbéraga ló wá ń darí wọn, wọ́n di ọmọ abẹ́ ìṣàkóso rẹ̀.
13-15. (a) Kí ni díẹ̀ lára àwọn àbájáde kíkọ̀ táwọn èèyàn kọ ìṣàkóso òdodo Jèhófà sílẹ̀? (b) Kí nìdí tí ayé yìí fi jẹ́ ibi tó nira?
13 Gbé díẹ̀ lára àwọn àbájáde rẹ̀ yẹ̀ wò. Wọ́n lé Ádámù àti Éfà jáde kúrò ní apá ibi kan tó jẹ́ Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Wọ́n kúrò nínú ọgbà dáradára tí wọ́n ti ń gbádùn àwọn ewébẹ̀ àti èso aṣaralóore, wọ́n bọ́ sínú ipò líle koko lẹ́yìn ọgbà Édẹ́nì. Ọlọ́run sọ fún Ádámù pé: “Nítorí tí o fetí sí ohùn aya rẹ, tí o sì jẹ nínú igi náà tí mo pa àṣẹ yìí fún ọ nípa rẹ̀ pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀,’ ègún ni fún ilẹ̀ ní tìtorí rẹ. Inú ìrora ni ìwọ yóò ti máa jẹ àmújáde rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé rẹ. Ẹ̀gún àti òṣùṣú ni yóò sì máa hù jáde fún ọ.” Ègún tí Ọlọ́run fi ilẹ̀ gún yìí túmọ̀ sí pé yóò nira gan-an láti máa ṣọ̀gbìn nínú rẹ̀. Àkóbá tí ilẹ̀ tá a fi gégùn-ún yìí àti ẹ̀gún òun òṣùṣù rẹ̀ ṣe fún àtọmọdọ́mọ Ádámù pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí Lámékì bàbá Nóà fi sọ̀rọ̀ débi ‘ìrora ọwọ́ wọn tí ó jẹ́ àbáyọrí ilẹ̀ tí Jèhófà ti fi gégùn-ún.’—Jẹ́nẹ́sísì 3:17-19; 5:29.
14 Ádámù àti Éfà tún pàdánù ìfọ̀kànbalẹ̀ tí wọ́n ní, wọ́n wá bọ́ sínú wàhálà. Ọlọ́run sọ fún Éfà pé: “Èmi yóò mú ìrora ìlóyún rẹ pọ̀ sí i gidigidi; inú ìroragógó ìbímọ ni ìwọ yóò ti máa bí àwọn ọmọ, ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ sì ni ìfàsí-ọkàn rẹ yóò máa wà, òun yóò sì jọba lé ọ lórí.” Nígbà tó yá, Kéènì àkọ́bí Ádámù àti Éfà hu ìwà òǹrorò, ó pa Ébẹ́lì àbúrò rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 3:16; 4:8.
15 Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòhánù 5:19) Ayé òde òní bíi ti alákòóso rẹ̀ ń hu ìwà ibi, irú bíi ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan àti ìgbéraga. Abájọ tí ìnira àti ìwà òǹrorò fi kún inú rẹ̀! Àmọ́ kò ní máa rí bẹ́ẹ̀ títí lọ. Jèhófà yóò rí sí i pé inú rere àti ẹ̀mí ìyọ́nú ló gbilẹ̀ nínú Ìjọba òun, dípò ìnira àti ìwà òǹrorò.
Inú Rere Yóò Gbilẹ̀ Lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run
16. Kí nìdí tí ìṣàkóso Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi Jésù fi jẹ́ ti inú rere, kí ló sì yẹ kí èyí mú kí á ṣe?
16 Jèhófà àti Kristi Jésù tó yàn gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Rẹ̀ fẹ́ kí àwọn ọmọ abẹ́ wọn jẹ́ ẹni táwọn èèyàn mọ̀ sí onínúure. (Míkà 6:8) Jésù Kristi jẹ́ kí á rí àrítẹ́lẹ̀ bí ìṣàkóso tí Baba rẹ̀ gbé lé e lọ́wọ́ yóò ṣe jẹ́ ti onínúure. (Hébérù 1:3) A lè rí èyí nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù fi tú àṣírí àwọn èké aṣáájú ìsìn, tí wọ́n ń di ẹrú wíwúwo lé àwọn èèyàn lórí. Ó sọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín. Nítorí àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́.” (Mátíù 11:28-30) Ọ̀pọ̀ alákòóso ìsìn tàbí àwọn alákòóso mìíràn nínú ayé ló máa ń ni àwọn èèyàn lára nípa gbígbé àìmọye òfin kalẹ̀, tí wọ́n á sí máa mú wọn ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó. Àmọ́ ohun tí Jésù ní kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun ṣe jẹ́ ohun tó máa ṣe wọ́n láǹfààní tí kò sì ju agbára wọn lọ. Ìyẹn ni àjàgà tó tuni lára tó sì jẹ́ ti inú rere ní ti gidi! Ǹjẹ́ èyí ò mú ká fẹ́ láti dà bíi rẹ̀ nínú fífi inú rere hàn sí àwọn èèyàn?—Jòhánù 13:15.
17, 18. Kí nìdí tó fi yẹ kí ọkàn wa balẹ̀ pé àwọn tó máa bá Kristi ṣàkóso ní ọ̀run àtàwọn tó jẹ́ aṣojú rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé yóò fi inú rere hàn?
17 Àwọn ọ̀rọ̀ tó gbàfiyèsí tí Jésù sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ jẹ́ ká mọ bí ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run ṣe yàtọ̀ pátápátá sí ìṣàkóso ènìyàn. Bíbélì sọ pé: “Awuyewuye gbígbónájanjan kan tún dìde láàárín wọn lórí èwo nínú wọn ni ó dà bí ẹni tí ó tóbi jù lọ. Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé: ‘Àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè a máa jẹ olúwa lé wọn lórí, àwọn tí wọ́n sì ní ọlá àṣẹ lórí wọn ni a ń pè ní àwọn Olóore. Àmọ́ ṣá o, ẹ̀yin kò ní jẹ́ bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n kí ẹni tí ó tóbi jù lọ láàárín yín dà bí ẹni tí ó kéré jù lọ, kí ẹni tí ó sì ń ṣe gẹ́gẹ́ bí olórí dà bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́. Nítorí ta ni ẹni tí ó tóbi jù, ṣé ẹni tí ó rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì ni tàbí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́? Kì í ha ṣe ẹni tí ó rọ̀gbọ̀kú nídìí tábìlì ni? Ṣùgbọ́n èmi wà láàárín yín gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́.’”—Lúùkù 22:24-27.
18 Àwọn alákòóso èèyàn máa ń fẹ́ fi ipò ọlá wọn hàn nípa ‘jíjẹ́ olúwa lé’ àwọn èèyàn lórí àti nípa wíwá àwọn orúkọ oyè ńláńlá fún ara wọn, bí ẹni pé irú orúkọ oyè bẹ́ẹ̀ á jẹ́ kí wọn sàn ju àwọn tí wọ́n ń ṣàkóso lé lórí lọ. Àmọ́ Jésù sọ pé ṣíṣe ìránṣẹ́ fáwọn ẹlòmíràn gan-an ló ń jẹ́ kéèyàn di ẹni ńlá ní ti gidi, ìyẹn ni pé kéèyàn máa fi gbogbo ara sapá láti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn, kó sì máa ṣe é ní gbogbo ìgbà. Gbogbo àwọn tó máa bá Kristi ṣàkóso lókè ọ̀run tàbí tí wọ́n máa sìn gẹ́gẹ́ bí aṣojú rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé gbọ́dọ̀ sapá láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti inú rere rẹ̀.
19, 20. (a) Báwo ni Jésù ṣe fi bí inú rere Jèhófà ṣe pọ̀ tó hàn? (b) Báwo la ṣe lè fara wé Jèhófà nínú fífi inú rere hàn?
19 Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ mìíràn tí Jésù fúnni. Nígbà tí Jésù ń fi bí inú rere Jèhófà ṣe pọ̀ tó hàn, ó ní: “Bí ẹ bá nífẹ̀ẹ́ àwọn tí wọ́n ń nífẹ̀ẹ́ yín, ìyìn wo ni ó jẹ́ fún yín? Nítorí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá a máa nífẹ̀ẹ́ àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ wọn. Bí ẹ bá sì ń ṣe rere sí àwọn tí ń ṣe rere sí yín, ìyìn wo ni ó jẹ́ fún yín ní ti gidi? Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá a máa ṣe bákan náà. Pẹ̀lúpẹ̀lù, bí ẹ bá ń wín àwọn tí ẹ retí láti rí gbà láti ọ̀dọ̀ wọn láìsí èlé, ìyìn ọlá wo ni ó jẹ́ fún yín? Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá a máa wín àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ láìsí èlé kí wọ́n bàa lè gba ohun kan náà padà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa ṣe rere àti láti máa wínni láìsí èlé, láìretí ohunkóhun padà; èrè yín yóò sì pọ̀, ẹ ó sì jẹ́ ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ, nítorí pé ó jẹ́ onínúrere sí àwọn aláìlọ́pẹ́ àti àwọn ẹni burúkú. Ẹ máa bá a lọ ní dídi aláàánú, gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba yín ti jẹ́ aláàánú.”—Lúùkù 6:32-36.
20 Inú rere Ọlọ́run kì í hùwà ìmọtara-ẹni-nìkan. Kì í béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ ẹni, kì í sì í retí pé kí a san ohunkóhun padà. Inú rere tí Jèhófà ní ló fi “ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn ènìyàn burúkú àti rere, . . . ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.” (Mátíù 5:43-45; Ìṣe 14:16, 17) Nípa fífarawé Baba wa ọ̀run, kì í ṣe pé a kì í ṣèpalára fún àwọn aláìlọ́pẹ́ nìkan, àmọ́ a máa ń ṣe rere sí wọn, kódà à ń ṣe rere sí àwọn tó ń bá wa ṣọ̀tá pàápàá. Tá a bá ń fi inú rere hàn, a ń jẹ́ kí Jèhófà àti Jésù rí i pé ó wù wá láti gbé nínú Ìjọba Ọlọ́run nìyẹn, nígbà tí inú rere àtàwọn ànímọ́ mìíràn tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń mú jáde yóò gbilẹ̀ nínú àjọṣe ẹ̀dá ènìyàn.
Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Máa Fi Inú Rere Hàn?
21, 22. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fi inú rere hàn?
21 Ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí ẹni tó jẹ́ ojúlówó Kristẹni máa fi inú rere hàn. Èyí jẹ́ ẹ̀rí pé a ní ẹ̀mí Ọlọ́run. Àti pe, Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi là ń fara wé nígbà tá a bá fi inú rere tòótọ́ hàn. Inú rere tún jẹ́ ọ̀kan lára ohun tí àwọn tó máa di ọmọ abẹ́ Ìjọba Ọlọ́run gbọ́dọ̀ ní. Nítorí náà, ó yẹ kí á nífẹ̀ẹ́ inú rere ká sì kọ́ bí a ó ṣe máa fi hàn.
22 Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà fi inú rere hàn nínú ìgbésí ayé wa ojoojúmọ́? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò ṣàlàyé kókó yẹn.
Báwo Ló Ṣe Máa Dáhùn?
• Kí ni inú rere?
• Kí nìdí tí ayé yìí fi kún fún ìwà òǹrorò tó sì jẹ́ ibi tó nira?
• Báwo la ṣe mọ̀ pé inú rere yóò gbilẹ̀ lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run?
• Kí nìdí tí fífi inú rere hàn fi ṣe pàtàkì fún àwọn tó fẹ́ gbé lábẹ́ Ìjọba Ọlọ́run?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Àwọn Kristẹni alàgbà ń sapá láti jẹ́ onínúure nínú bí wọ́n ṣe ń bá agbo lò
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Jèhófà kò ní kùnà láti fi inú rere onífẹ̀ẹ́ hàn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní àkókò ìṣòro
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Inú rere tí Jèhófà ní ló fi ń mú kí oòrùn ràn sorí gbogbo èèyàn, tó sì ń mú kí òjò rẹ̀ rọ̀ sórí wọn pẹ̀lú